Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ September 5
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ SEPTEMBER 5
Orin 75 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 9 ìpínrọ̀ 1 sí 7, àti àpótí tó wà lójú ìwé 68 àti 70 (25 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Sáàmù 119 (10 min.)
No. 1: Sáàmù 119:49-72 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìdí Tí Ìwé Mímọ́ Fi Sọ Pé Ká Bẹ̀rù Jèhófà—Diu. 5:29 (5 min.)
No. 3: Ṣé Ẹni Gidi Ni Èṣù?—td 10A (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀.
10 min: Kí La Rí Kọ́? Ìjíròrò. Ẹ ka Ìṣe 5:17-42, kẹ́ ẹ sì jíròrò bí ìtàn tó wà níbẹ̀ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
10 min: Àwọn Ọ̀ràn Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ.
10 min: Ẹ Máa Múra Òde Ẹ̀rí Sílẹ̀ Pa Pọ̀ Gẹ́gẹ́ Bí Ìdílé. Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò àti àṣefihàn. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu tọkọtaya kan àti ìdílé kan tó lọ́mọ nípa bí wọ́n ṣe máa ń múra òde ẹ̀rí sílẹ̀ nígbà Ìjọsìn Ìdílé wọn. Lẹ́yìn náà, jẹ́ kí ọ̀kan lára àwọn olórí ìdílé náà ṣe àṣefihàn ṣókí pẹ̀lú ìdílé rẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń ṣe é.
Orin 88 àti Àdúrà