Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní August: Ẹ lè lo èyíkéyìí lára àwọn ìwé olójú ìwé 32 yìí tí àwọn èèyàn máa ń nífẹ̀ẹ́ sí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Ẹ Máa Ṣọ́nà!, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀ (ó máa fa àwọn Mùsùlùmí mọ́ra), Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!, Ki Ni Ète Igbesi-Aye—Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun”. September: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tẹ́ ẹ bá fún àwọn èèyàn ní ìwé náà. Bí onílé bá ti ní ìwé náà, tí kò sì fẹ́ kí á wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹ lè fún un ní àwọn ìwé ìròyìn tí ọjọ́ wọn ti pẹ́ tàbí ìwé pẹlẹbẹ èyíkéyìí tó sọ̀rọ̀ nípa ohun tí onílé nífẹ̀ẹ́ sí. October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ẹ fún ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?, kẹ́ ẹ sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. November: Kí Ló Wà Nínú Bíbélì? Láfikún sí èyí tàbí gẹ́gẹ́ bí àfidípò, ẹ tún lè lo ìwé olójú ewé 32 èyíkéyìí tá a tò sókè yìí fún oṣù August 2011.
◼ A máa jíròrò fídíò méjì tó jáde láìpẹ́ yìí, ìyẹn Jehovah’s Witnesses—Faith in Action, Part 1: Out of Darkness àti The Wonders of Creation Reveal God’s Glory ní àwọn ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tó ń bọ̀ lọ́nà. Tẹ́ ẹ bá nílò rẹ̀, ẹ lè béèrè fún un nípasẹ̀ ìjọ kó tó pẹ́ jù.