A Máa Lo Ìwé Pẹlẹbẹ Tuntun Lóde Ẹ̀rí!
1. Ìtẹ̀jáde wo la máa lò lóṣù November, kí sì nìdí tá a fi ṣe ìtẹ̀jáde náà?
1 Ní Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ Máa Ṣọ́nà!” tá a ṣe lọ́dún 2009 sí 2010, a mú ìwé pẹlẹbẹ tuntun kan jáde tá a pè ní Kí Ló Wà Nínú Bíbélì? Ní oṣù November, gbogbo ìjọ kárí ayé máa lo ìwé pẹlẹbẹ yìí lóde ẹ̀rí fún ìgbà àkọ́kọ́. Àǹfààní wo ni ìtẹ̀jáde yìí máa ṣe fáwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa?Ohun tí ọ̀pọ̀ mọ̀ nípa Bíbélì kò tó nǹkan, pàápàá jù lọ àwọn tí kì í ṣe ẹlẹ́sìn Kristẹni. Torí náà, a sọ lójú ìwé 3 nínú ìwé pẹlẹbẹ náà pé a ṣe ìwé pẹlẹbẹ yìí kó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti “wo Bíbélì gààràgà, kó o lè mọ ohun tó wà nínú ẹ̀.”
2. Kí la lè sọ tá a bá fẹ́ fún àwọn èèyàn ní ìwé pẹlẹbẹ náà?
2 Bá A Ṣe Lè Lò Ó Lóde Ẹ̀rí: A lè sọ pé: “A fẹ́ mọ èrò rẹ nípa ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ. [Ka 2 Tímótì 3:16.] Ọ̀pọ̀ àwọn tá a ti bá sọ̀rọ̀ gbà pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ tá a kà yìí, àwọn míì sì rò pé Bíbélì wulẹ̀ jẹ́ ìwé kan tó dára. Kí lèrò tìẹ nípa Bíbélì? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìdí púpọ̀ ló wà tó fi yẹ ká fúnra wa ṣàyẹ̀wò ohun tó wà nínú Bíbélì, láìka ohun tá a gbà gbọ́ sí. [Ka ìpínrọ̀ tá a fi nasẹ̀ ọ̀rọ̀ ní ojú ìwé 3, nínú ìwé pẹlẹbẹ náà.] Ìwé yìí ṣàkópọ̀ ohun tó wà nínú Bíbélì ní ṣókí. Bó o bá kà á wàá rí ohun kàn tó máa fà ẹ́ lọ́kàn mọ́ra, ìyẹn ni pé: Ẹṣin ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo ni Ìwé Mímọ́ ní látòkèdélẹ̀.”
3. Ọ̀nà míì wo la lè gbà gbé ọ̀rọ̀ wa kalẹ̀, pàápàá jù lọ níbi tí ọ̀pọ̀ kì í ti í ṣe ẹlẹ́sìn Kristẹni?
3 Ọ̀nà míì tún wà tá a lè gbà gbé ọ̀rọ̀ wa kalẹ̀, pàápàá jù lọ níbi tí ọ̀pọ̀ kì í ti í ṣe ẹlẹ́sìn Kristẹni. A lè sọ pé: “A fẹ́ mọ èrò rẹ nípa ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ. [Ka Sáàmù 37:11.] Báwo lo ṣe rò pé ayé máa rí nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí bá ní ìmúṣẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Èyí jẹ́ àpẹẹrẹ ìrètí àti ìtùnú tí àwa èèyàn lè rí látinú Bíbélì láìka àṣà ìbílẹ̀ tàbí ẹ̀sìn wa sí.” Ka ìpínrọ̀ tá a fi nasẹ̀ ọ̀rọ̀ ní ojú ìwé 3, kó o sì fún onílé ní ìwé pẹlẹbẹ náà.
4. Báwo la ṣe lè fí ìwé pẹlẹbẹ náà bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
4 Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: Nígbà tá a bá pa dà lọ, a lè rán onítọ̀hún létí ohun tá a bá a sọ nígbà àkọ́kọ́, lẹ́yìn náà a lè jíròrò ìpínrọ̀ kan tàbí méjì tó dá lórí ohun tá a jọ jíròrò nípa lílo ìbéèrè tó wà ní ìparí apá tá a jíròrò náà. Bá a bá sì fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, a lè ka ohun tó wà lẹ́yìn ìwé pẹlẹbẹ náà, ká sì fún onílé ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, ká wá bi í pé, èwo nínú àwọn àkòrí tó wà níbẹ̀ ló nífẹ̀ẹ́ sí jù lọ. Lẹ́yìn náà ká jíròrò ìpínrọ̀ kan tàbí méjì látinú orí yẹn pẹ̀lú rẹ̀. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa kópa ní kíkún nínú lílo ìwé pẹlẹbẹ yìí lóde ẹ̀rí lóṣù November!