ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ol apá 2 ojú ìwé 5-7
  • Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Ohun Tó Jẹ́ Òtítọ́ Nípa Ọlọ́run?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Ohun Tó Jẹ́ Òtítọ́ Nípa Ọlọ́run?
  • Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdí Tó O Fi Lè Gba Bíbélì Gbọ́
  • Ǹjẹ́ Bíbélì Ti Yí Padà?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ẹ̀kọ́ Òtítọ́ Tínú Ọlọ́run Dùn Sí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Gbára Lé Bíbélì?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Gbára Lé Bíbélì?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìbẹ̀rẹ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì
Àwọn Míì
Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?
ol apá 2 ojú ìwé 5-7

APÁ 2

Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Ohun Tó Jẹ́ Òtítọ́ Nípa Ọlọ́run?

Ọkùnrin kan ń ka Bíbélì

1, 2. Àkàwé wo ló fi hàn pé ó yẹ kí ìlànà kan wà fún ṣíṣe ìpinnu lórí ọ̀ràn ìsìn?

BÁWO la ṣe lè mọ Ọlọ́run? Ṣé ó di ìgbà tí a bá tó ṣàyẹ̀wò gbogbo ẹ̀kọ́ tó wà nínú ọ̀pọ̀ ìsìn wọ̀nyí tán? Ìyẹn ò lè ṣeé ṣe. Ká tiẹ̀ sọ pé a lè ṣe bẹ́ẹ̀ pàápàá, báwo la ṣe fẹ́ mọ ẹ̀kọ́ tó tọ̀nà?

2 Nítorí pé onírúurú nǹkan ni wọ́n fi ń kọ́ni nípa Ọlọ́run, ó yẹ ká wá ọ̀nà tá a lè fi mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́, èyí tí í ṣe ìlànà kan tí àwọn èèyàn á lè tẹ́wọ́ gbà. Wo àkàwé yìí ná: Jẹ́ ká sọ pé àríyànjiyàn kan ṣẹlẹ̀ láàárín ọjà nítorí ìwọ̀n aṣọ kan. Ẹni tó ń tà á sọ pé ọ̀pá mẹ́ta ni, ṣùgbọ́n ẹni tó fẹ́ rà á rò pé kò tó bẹ́ẹ̀. Ọ̀nà wo ni wọ́n lè gbà yanjú ọ̀ràn ọ̀hún? Ńṣe ni wọ́n á fi ohun tí wọ́n fi ń wọn aṣọ wọ̀n ọ́n.

3. Kí nìdí tá a fi kọ Bíbélì?

3 Ṣé irú ọ̀pá ìdíwọ̀n tàbí ìlànà bẹ́ẹ̀ wà fún ṣíṣe ìpinnu lórí ọ̀ràn ìsìn? Bẹ́ẹ̀ ni o. Bíbélì ni. Ọlọ́run mú kí á kọ Bíbélì kí àwọn èèyàn níbi gbogbo lè mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa òun. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ rẹ̀ la ti tẹ̀ jáde. A ti túmọ̀ rẹ̀ lódindi tàbí lápá kan sí àwọn èdè tó ju ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún kan [2,100] lọ. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé olúkúlùkù ló lè rí ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run kà ní èdè tirẹ̀.

4. Ìsọfúnni wo ló wà nínú Bíbélì?

4 Bíbélì jẹ́ ẹ̀bùn iyebíye látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ó ṣàlàyé àwọn nǹkan tó jẹ́ pé a kì bá mọ̀ ká ní kò sí Bíbélì. Ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ń gbé ní ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí. Ó ṣàlàyé èrò Ọlọ́run, ìwà rẹ̀ àti ète rẹ̀. Ó ṣàlàyé bó ṣe bá àwọn èèyàn lò fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún. Ó sọ àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ó sì sọ bí a ṣe lè rí ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.

Ìdí Tó O Fi Lè Gba Bíbélì Gbọ́

5. Àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé Bíbélì bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu?

5 Ìdí pọ̀ tá a fi lè gbà gbọ́ pé Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní tòótọ́. Ìdí kan ni pé Bíbélì bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu. Ní ìgbà àtijọ́, àwọn èèyàn jákèjádò ayé rò pé orí nǹkan kan ni ayé jókòó lé. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà gbà gbọ́ nígbà kan rí pé orí ejò kan tó ká jọ ni ayé jókòó lé, pé ejò ọ̀hún ká jọ ní ìṣẹ́po ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ sókè ayé, ó sì tún ká jọ ní ìṣẹ́po ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ sábẹ́ ayé. Àmọ́, ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì kọ̀wé ní ohun tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ ọdún sẹ́yìn pé Ọlọ́run “so . . . ayé rọ̀ sórí òfo.” Èyí ló sì bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu.—Jóòbù 26:7.

6. Kí ni ẹ̀rí títóbi jù lọ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá?

6 Àkọsílẹ̀ pípé tó wà nínú Bíbélì tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la ni ẹ̀rí títóbi jù lọ pé lóòótọ́ ni Bíbélì wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Láìdàbí àwọn woṣẹ́woṣẹ́ tàbí àwọn ọlọ́pẹ̀lẹ̀, Ọlọ́run mọ ọjọ́ ọ̀la ní tòótọ́; gbogbo ohun tó bá ti sọ ló máa ń ṣẹ nígbà gbogbo.

7. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ní ìmúṣẹ nígbà àtijọ́?

7 Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ló ní ìmúṣẹ nígbà àtijọ́. Bí àpẹẹrẹ, ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ọdún ṣáájú, Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù la ó ti bí Jésù, ó sì rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. (Míkà 5:2; Mátíù 2:3-9) Láfikún sí ọ̀pọ̀ nǹkan mìíràn tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa Jésù, Bíbélì tún sọ tẹ́lẹ̀ pé wúńdíá ni yóò bí i àti pé a ó dà á nítorí ọgbọ̀n ẹyọ owó fàdákà. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ní ìmúṣẹ pẹ̀lú. Ó dájú pé kò sí ẹ̀dá èèyàn kankan tó lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ nǹkan wọ̀nyẹn!—Aísáyà 7:14; Sekaráyà 11:12, 13; Mátíù 1:22, 23; 27:3-5.

8. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ń ní ìmúṣẹ lónìí, kí sì ni wọ́n fi hàn?

8 Ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ló ń ní ìmúṣẹ ní àkókò tiwa. Díẹ̀ nìyí lára wọn:

  • “Orílẹ̀-èdè yóò dìde [ogun] sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba; ìsẹ̀lẹ̀ ńláǹlà yóò sì wà, àti àwọn àjàkálẹ̀ àrùn àti àìtó oúnjẹ láti ibì kan dé ibòmíràn.”—Lúùkù 21:10, 11.

  • “Pípọ̀ sí i ìwà àìlófin” yóò wáyé.—Mátíù 24:12.

  • “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn . . . àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, . . . aṣàìgbọràn sí òbí, . . . aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, . . . awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.”—2 Tímótì 3:1-5.

Ọmọ kan tó ti rù kan eegun; ọkùnrin kan ń jagun

Ǹjẹ́ o ò gbà pé àwọn nǹkan wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ nísinsìnyí? Bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe ń ní ìmúṣẹ, tí wọn kì í sì í tàsé, fi hàn pé Bíbélì kì í ṣe ìwé lásán. Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí ni!—2 Tímótì 3:16.

Ǹjẹ́ Bíbélì Ti Yí Padà?

9, 10. Kí ló fi hàn pé Ọlọ́run ò jẹ́ kí àwọn ènìyàn yí Bíbélì padà?

9 Jẹ́ ká sọ pé o ní ilé iṣẹ́ kan, tó o sì lẹ òfin tó o fẹ́ kí àwọn òṣìṣẹ́ rẹ máa tẹ̀ lé mọ́ ibì kan. Bí ọ̀tá rẹ bá wá yí ohun tó o kọ padà, kí lo máa ṣe? Ṣé o ò ní ṣàtúnṣe ohun tí ó yí padà náà? Lọ́nà kan náà, Ọlọ́run kò jẹ́ káwọn èèyàn yí òtítọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí í ṣe Bíbélì padà.

10 Gbogbo àwọn tó ti gbìyànjú láti yí àwọn ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run padà kò ṣàṣeyọrí rárá. Bí a bá sì fi Bíbélì tá a ní lónìí wé ẹ̀dà ti ìgbà àtijọ́, wọn kò yàtọ̀ síra. Èyí fi hàn pé Bíbélì kò yí padà rárá láti gbogbo ọdún wọ̀nyí wá.

Ǹjẹ́ Ìtàn Àtẹnudẹ́nu Ṣeé Gbára Lé?

Ẹ̀sìn àbáláyé ti ilẹ̀ Áfíríkà kò ní ìwé mímọ́ ìgbà àtijọ́ kankan. Àṣà àtọwọ́dọ́wọ́, ààtò àti èrò tí wọ́n ní nípa Ọlọ́run ni wọ́n ta àtaré rẹ̀ látẹnudẹ́nu láti ìran kan sí òmíràn. Ìwé náà, West African Traditional Religion, sọ pé: “Ìsọfúnni tí a fẹnu sọ lè máà pé pérépéré. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tá a sọ látẹnudẹ́nu lè ní àwọn àfikún àti àyọkúrò, wọ́n lè bù mọ́ ọn, wọ́n sì lè yí i padà, kódà wọ́n lè sọ ọ́ ní àsọrégèé, kí wọ́n sì dojú rẹ̀ rú tí yóò fi di pé kò ní ṣeé ṣe láti mọ òótọ́ yàtọ̀ sí ìtàn àròsọ.”

Àpótí: Kí ni ìwé kan sọ nípa bóyá ìtàn àtẹnudẹ́nu ṣeé gbára lé tàbí kò ṣeé gbára lé?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́