ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w15 9/1 ojú ìwé 16
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Ṣeé Gbára Lé, Ìtàn Inú Rẹ̀ sì Péye
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Ohun Tá A Rí Kọ́ Nínú Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Bá A Ṣe Lè Lóye Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
w15 9/1 ojú ìwé 16

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ àsọtẹ́lẹ̀?

Jésù ń bá díẹ̀ nínú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sọ̀rọ̀ lórí Òkè Ólífì

KÍ nìdí tí bíbélì fi sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní àkókò wa?​—Lúùkù 21:​10, 11.

Kò sí èèyàn kankan tó lè sọ bí ọlà ṣe máa rí. Àmọ́ ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó kún rẹ́rẹ́ ló wà nínú Bíbélì. Gbogbo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà ló ṣẹ, èyí sì jẹ́ ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì.​—Ka Jóṣúà 23:14; 2 Pétérù 1:​20, 21.

Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì tó ti ṣẹ jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká gba Ọlọ́run gbọ́. (Hébérù 11:1) Ó tún fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa máa ṣẹ. Torí náà, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì máa ń fún wa ní ìrètí tó dájú.​—Ka Sáàmù 37:29; Róòmù 15:4.

Àǹfààní wo ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì ṣe wá?

Ọlọ́run fi àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan kìlọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àwọn Kristẹni ayé ọjọ́un rí i pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa ìparun ìlú Jerúsálẹ́mù ti ń ṣẹ, wọ́n sá kúrò ní ìlú náà. Nígbà tó yá, ìlú Jerúsálẹ́mù pa run torí pé ọ̀pọ̀ lára àwọn aráàlú yẹn kọ Jésù. Àmọ́, àwọn Kristẹni tó fiyè sí àsọtẹ́lẹ̀ náà ti wá ibòmíì forí pa mọ́ sí kí ìlú náà tó pa run.​—Ka Lúùkù 21:​20-22.

Lóde òní, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ti ṣẹ fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run máa tó fòpin sí gbogbo ìjọba èèyàn. (Dáníẹ́lì 2:44; Lúùkù 21:31) Torí náà, ó yẹ ká tètè ṣe ohun tó máa jẹ́ ká rí ojúure Ọba tí Ọlọ́run yàn, ìyẹn Jésù Kristi.​—Ka Lúùkù 21:​34-36.

Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 2 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é

Ó tún wà lórí ìkànnì www.jw.org/yo

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́