Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Ṣeé Gbára Lé, Ìtàn Inú Rẹ̀ sì Péye
Àwọn ẹ̀rí wo ló fi hàn pé àwọn ìtàn tó wà nínú Bíbélì péye? Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ti ní ìmúṣẹ wo ló jẹ́ kó dá wa lójú pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú máa ní ìmúṣẹ? Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí wà nínú fídíò náà, The Bible—Accurate History, Reliable Prophecy. Fídíò yìí ni ìkẹta nínú ọ̀wọ́ àwọn fídíò tá a ṣe sórí àwo DVD tó dá lórí Bíbélì, ìyẹn The Bible—A Book of Fact and Prophecy. Ṣé wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí lẹ́yìn tó o bá wo fídíò náà?
(1) Ta ni Orísun ìsọfúnni tó ṣeé gbára lé tó wà nínú Bíbélì? (Dán. 2:28) (2) Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe tó péye nípa Íjíbítì ayé àtijọ́, báwo sì ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Aísáyà 19:3, 4 ṣe já sí òótọ́? (3) Báwo ni ẹ̀kọ́ ìwalẹ̀pìtàn ṣe jẹ́rìí sí àpèjúwe tí Bíbélì ṣe nípa àwọn ará Ásíríà, àwọn ọba wọn àti bí ilẹ̀ Ásíríà ṣe parun? (Náh. 3:1, 7, 13) (4) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wo nípa ìlú Bábílónì ni ẹ̀rí fi hàn pé ó ti ní ìmúṣẹ? (Jer. 20:4; 50:38; 51:30) (5) Àsọtẹ́lẹ̀ wo nípa ilẹ̀ Mídíà òun Páṣíà ló ní ìmúṣẹ? (Aísá. 44:28) (6) Báwo ni Dáníẹ́lì 7:6 àti 8:5, 8 ṣe ní ìmúṣẹ sí ilẹ̀ Gíríìsì lára? (7) Báwo ni Dáníẹ́lì 7:7 ṣe ní ìmúṣẹ nígbà tí ilẹ̀ Róòmù di agbára ayé? (8) Àwọn Késárì wo ni Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn? (9) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn Kristẹni nígbà tí Olú Ọba Nérò ń ṣàkóso? (10) Báwo ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Ìṣípayá 13:11 àti 17:11 ṣe ní ìmúṣẹ? (11) Kí la fi dá ọba kẹjọ mọ̀? (12) Nínú fídíò náà, àwọn ìran wo ló fi hàn pé òótọ́ ni ohun tí Oníwàásù 8:9 sọ? (13) Èwo nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó máa nímùúṣẹ lọ́jọ́ iwájú lò ń fojú sọ́nà fún? (14) Báwo lo ṣe lè lo fídíò yìí láti jẹ́ kó dá àwọn èèyàn lójú pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá?