Kíkẹ́kọ̀ọ́ Látinú Fídíò Náà, The Bible—Accurate History, Reliable Prophecy
Lẹ́yìn tí o wo fídíò yìí tán, ǹjẹ́ o lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí? (1) Ta ni Orísun ìsọfúnni tó ṣeé gbára lé tó wà nínú Bíbélì? (Dán. 2:28) (2) Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe tó péye nípa Íjíbítì ayé àtijọ́, báwo sì ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Aísáyà 19:3, 4 ṣe já sí òótọ́? (3) Báwo ni ẹ̀kọ́ ìwalẹ̀pìtàn ṣe jẹ́rìí sí àpèjúwe tí Bíbélì ṣe nípa àwọn ará Ásíríà, àwọn ọba wọn, àti òpin Ásíríà? (Náh. 3:1, 7, 13) (4) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wo nípa Bábílónì ni ẹ̀rí fi hàn pé wọ́n ṣeé gbára lé? (5) Ipa wo ni Mídíà òun Páṣíà ní lórí àwọn èèyàn Ọlọ́run? (6) Báwo ni Dáníẹ́lì 8:5, 8 ṣe ní ìmúṣẹ, ó sì tó ìgbà wo tí a ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣáájú? (7) Báwo ni Jésù ṣe fẹ̀rí hàn pé òun ni Mèsáyà tòótọ́? (8) Ìjọba ìṣèlú wo lóde òní ló mú kí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Ìṣípayá 13:11 àti 17:11 ní ìmúṣẹ? (9) Ìran wo nínú fídíò yìí ló fi hàn pé òtítọ́ lọ̀rọ̀ tó wà nínú Oníwàásù 8:9? (10) Báwo ni ohun tí o wò yìí ṣe fún ìgbàgbọ́ rẹ nínú àwọn ìlérí Bíbélì nípa ọjọ́ iwájú lókun? (11) Báwo lo ṣe lè lo irin iṣẹ́ yìí láti mú kí ó dá àwọn ẹlòmíràn lójú pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wa?