ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ol apá 1 ojú ìwé 4-5
  • Ǹjẹ́ Gbogbo Ìsìn Ló Ń Fi Òtítọ́ Kọ́ni?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Gbogbo Ìsìn Ló Ń Fi Òtítọ́ Kọ́ni?
  • Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Òtítọ́ La Gbọ́dọ̀ Gbé Ìsìn Wa Kà
  • Ẹ̀sìn Èké Kò Ṣojú fún Ọlọ́run
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Isin Eyikeyii Ha Dara Tó Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Ìròyìn Ayọ̀ Wo Ló Wà Nípa Ìsìn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Àwọn Míì
Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?
ol apá 1 ojú ìwé 4-5

APÁ 1

Ǹjẹ́ Gbogbo Ìsìn Ló Ń Fi Òtítọ́ Kọ́ni?

1. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe ní Áfíríkà?

Ó FẸ́RẸ̀Ẹ́ jẹ́ gbogbo èèyàn tó wà nílẹ̀ Áfíríkà ló gbà pé ó ṣe pàtàkì láti sin Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, ẹnu àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ kò lórí bó ṣe yẹ ká máa sìn ín. Inú mọ́ṣáláṣí làwọn kan ti ń forí balẹ̀ fún un, àwọn mìíràn sì máa ń lọ sí ojúbọ òrìṣà. Àwọn mìíràn sì rèé, ṣọ́ọ̀ṣì ni wọ́n ń lọ ní tiwọn. Àmọ́, ká má rò pé ìsìn mẹ́ta péré ló wà nílẹ̀ Áfíríkà o. Láàárín àwọn Mùsùlùmí, onírúurú òfin ló wà, onírúurú nǹkan ni wọ́n sì gbà gbọ́. Àwọn ẹ̀sìn àbáláyé yàtọ̀ síra wọn gidigidi láti ibì kan dé òmíràn. Ìyapa tó wà láàárín ìjọ àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì kò sì kéré. Yàtọ̀ sáwọn ṣọ́ọ̀ṣì kàǹkà-kàǹkà, onírúurú ṣọ́ọ̀ṣì kéékèèké ló wà káàkiri ilẹ̀ Áfíríkà.

Obìnrin kan kúnlẹ̀ síwájú ère; ọkùnrin kan kúnlẹ̀ síwájú ojúbọ

Òtítọ́ La Gbọ́dọ̀ Gbé Ìsìn Wa Kà

2. (a) Kí ló sábà máa ń pinnu ẹ̀sìn téèyàn ń ṣe? (b) Kí ni kì í ṣe ẹ̀rí pé ẹ̀sìn wa dùn mọ́ Ọlọ́run nínú?

2 Kí nìdí táwọn èèyàn fi ń jọ́sìn lọ́nà tí wọ́n ń gbà jọ́sìn? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé ẹ̀sìn àwọn òbí wọn ni wọ́n gbà. Àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn tún ń nípa lórí ìsìn táwọn èèyàn ń ṣe lónìí. Ìwé náà, The Africans—A Triple Heritage, sọ pé: “Ṣíṣẹ́gun táwọn orílẹ̀-èdè ẹlẹ́sìn Ìsìláàmù ṣẹ́gun lápá àríwá Sàhárà ló mú kí ẹ̀sìn Ìsìláàmù gbilẹ̀ níbẹ̀, . . . ohun tó mú kí ẹ̀sìn Kristẹni gbilẹ̀ ní gúúsù Sàhárà náà nìyẹn. Ohun tó kàn ṣẹlẹ̀ ni pé idà ni wọ́n fi halẹ̀ mọ́ àwọn èèyàn kí wọ́n lè gba ẹ̀sìn Ìsìláàmù ní àríwá Sàhárà, ṣùgbọ́n ìbọn ni wọ́n fi halẹ̀ mọ́ àwọn èèyàn kí wọ́n lè gba ẹ̀sìn Kristẹni ní gúúsù Sàhárà.” Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ lára wa gbà gbọ́ pé ẹ̀sìn wa dùn mọ́ Ọlọ́run nínú. Ṣùgbọ́n a ò lè sọ pé ẹ̀sìn kan tọ̀nà kìkì nítorí pé òun la bá lọ́wọ́ àwọn òbí wa tàbí nítorí pé orílẹ̀-èdè kan ti òkèèrè wá fagbára mú àwọn baba ńlá wa láti tẹ́wọ́ gbà á.

3-5. Àkàwé wo ló ràn wá lọ́wọ́ láti mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ìsìn ló ń fi òtítọ́ kọ́ni?

3 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìsìn ló ń sọ pé àwọn ń tọ́ni sọ́nà nípa bí a ṣe lè sin Ọlọ́run lọ́nà tó yẹ, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lohun tí wọ́n fi ń kọ́ni. Ohun tí wọ́n fi ń kọ́ni nípa ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ àti ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ wa pọ̀, wọ́n sì yàtọ̀ síra. Ronú nípa ọ̀rọ̀ yìí ná: Jẹ́ ká sọ pé o ríṣẹ́ sílé iṣẹ́ ńlá kan. Lọ́jọ́ àkọ́kọ́ tó o lọ síbi iṣẹ́ náà, o gbọ́ pé ọ̀gá ibẹ̀ wà ní àkókò ìsinmi kúrò lẹ́nu iṣẹ́. Lo bá bi àwọn òṣìṣẹ́ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nípa iṣẹ́ tó o máa ṣe. Òṣìṣẹ́ àkọ́kọ́ sọ pé ilẹ̀ ni ọ̀gá wọn fẹ́ kó o gbá. Ìkejì sọ pé ilé lọ̀gá fẹ́ kó o kùn. Nígbà tí ìkẹta sọ pé ìwé ni ọ̀gá fẹ́ kó o pín kiri.

4 Lẹ́yìn náà, o wádìí lọ́wọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ọ̀hún nípa ìrísí ọ̀gá ibi iṣẹ́ náà. Òṣìṣẹ́ àkọ́kọ́ sọ fún ọ pé, ọ̀dọ́ èèyàn kan tó ga tó sì le lẹ́dàá ni. Òṣìṣẹ́ kejì sọ pé, àgbàlagbà kúkúrú kan tó ṣèèyàn gan-an ni. Òṣìṣẹ́ kẹta sọ fún ọ pé ọ̀gá ibi iṣẹ́ ọ̀hún kì í màá ṣe ọkùnrin, pé obìnrin ni. Ó dájú pé ohun tí wàá sọ ni pé kì í ṣe gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ọ̀hún ló ń sọ òtítọ́. Àmọ́ bí o bá fẹ́ máa bá iṣẹ́ tí o ṣẹ̀ṣẹ̀ rí yìí lọ, ǹjẹ́ o kò ní ṣèwádìí síwájú sí i láti mọ irú ẹni tí ọ̀gá náà jẹ́ gan-an àti ohun tó fẹ́ kó o ṣe?

5 Bó ṣe rí nínú ọ̀ràn ìsìn náà nìyẹn. Nítorí pé ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn èèyàn ń sọ nípa ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ àti ohun tó fẹ́ ká ṣe, ó yẹ ká rí i dájú pé ọ̀nà tí a gbà ń jọ́sìn bá òtítọ́ mu. Ṣùgbọ́n báwo la ṣe lè mọ ohun tó jẹ́ òótọ́ nípa Ọlọ́run?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́