ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 12/1 ojú ìwé 6-8
  • Isin Eyikeyii Ha Dara Tó Bi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Isin Eyikeyii Ha Dara Tó Bi?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Iyatọ Pataki Kan
  • Aini naa Lati ṣe Yiyan
  • Bi a ṣe Lè Yan Isin Tootọ
  • Otitọ ati Eso
  • Isin Tootọ Ni a Nṣe Lonii
  • Ẹ̀sìn Èké Kò Ṣojú fún Ọlọ́run
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Òpin Ìsìn Èké Sún Mọ́lé!
    Òpin Ìsìn Èké Sún Mọ́lé!
  • Jija Àjàbọ́ Kuro Ninu Isin Èké
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ǹjẹ́ Gbogbo Ẹ̀sìn ni Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà?
    Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 12/1 ojú ìwé 6-8

Isin Eyikeyii Ha Dara Tó Bi?

“Àtúbọ̀tán awọn akoko wa jẹ́ abanininujẹ. Awa nilo isin kan, ṣugbọn kò si ibi ti a ti ri Ọlọrun kan tí ó ba a mu.”—Lucian Blaga, akéwì ati ọmọran ara Roomu

“Isin ati awujọ alufaa ti wà, ó sì ṣeeṣe ki ó wà fun akoko gigun kan, laaarin awọn ọta itẹsiwaju ati ominira titobi julọ.”—Khristo Botev, akéwì ara Bulgaria

AWỌN ifayọ ọrọ ti o ba a rin yii ṣe gbohungbohun ẹtì naa ninu eyi ti ọpọlọpọ awọn eniyan alailabosi ọkàn bá araawọn. Jinlẹjinlẹ ninu wọn lọhun-un wọn nimọlara aini naa fun isin, ṣugbọn Ọlọrun ijinlẹ tí ẹgbẹ alufaa fi nkọni kii ṣe Ọlọrun kan ti wọn le loye ti wọn sì lè nifẹẹ. Siwaju sii, wọn mọ lẹkun-unrẹrẹ pe ẹgbẹ alufaa ati awọn isin wọn ti ṣe ohun pupọ lati ṣediwọ fun itẹsiwaju ati ominira eniyan. Bẹẹni, nigba ti aini naa fun isin di eyi ti a mọ lọna ti ó roke sii, awọn eniyan alailabosi ọkan ki yoo wulẹ tẹwọgba isin eyikeyii.

Iyatọ Pataki Kan

Isin kó apa pataki ninu igbekalẹ araye ati itan. Iwe The New Encyclopædia Britannica sọrọ nipa isin “gẹgẹ bi otitọ kan ninu iriri eniyan, iṣẹdalẹ, ati isin” ti o sì fikun un pe: “Awọn ẹ̀rí iṣarasihuwa ati iṣotitọ si isin wà ni gbogbo apa igbesi-aye eniyan.” Ṣugbọn itan fihan pe ko si ọkan ninu awọn isin pataki aye ti ó ti jẹ́ ibukun fun araye.

Aṣiwaju iṣelu ara India Jawaharlal Nehru sọ nigba kan pe: “Ohun agbafiyesi naa ti a npe ni isin, tabi lọna miiran isin ti a ṣeto, ni India ati ni apa ibomiran, ti fi ẹrujẹjẹ kun inu wa.” Gbe awọn ogun ti a ti gbe dide yẹwo ati awọn iwa ipa ti a ti dá ni orukọ isin, iwọ ha le fi ailabosi ṣaifohunṣọkan pẹlu rẹ bi?

Ni ọrundun kejidinlogun, ọmọran ara Faranse naa Voltaire ṣe iyatọ ti nrunilọkansoke kan. Oun kọwe pe: “Isin, bi iwọ ṣe wi, ti mu ailonka awọn iṣe iwa buruku jade. Dipo bẹẹ o yẹ ki o sọ pe igbagbọ ninu ohun asan, igbagbọ ninu ohun asan ti nṣakoso lori agbaye onibanujẹ wa. Igbagbọ ninu ohun asan jẹ ọta riroro julọ fun ijọsin mimọgaara tí a jẹ Alaaye Ẹni giga julọ ní gbese rẹ̀.” Voltaire bá ìgbọ̀jẹ̀gẹ́ isin ọjọ rẹ̀ jà, ṣugbọn oun di igbagbọ rẹ̀ mú ninu Ọlọrun gẹgẹ bi Ẹlẹdaa agbaye. Oun ri iyatọ kan laaarin isin tootọ ati eke.

Aini naa Lati ṣe Yiyan

Kii ṣe gbogbo eniyan ni o fohunṣọkan pẹlu Voltaire. Awọn kan sọ pe wọn ri rere ninu gbogbo isin; nipa bayii, wọn ko nimọlara gidi eyikeyii lati ṣawari ijọsin tootọ. Iru awọn ẹni bẹẹ nilati kọbiara si ikilọ naa ti a fifunni lati ọwọ wolii Aisaya, ẹni ti o kọwe pe: “Egbe ni fun awọn ti npe ibi ni rere, ati rere ni ibi, ti nfi okunkun ṣe imọlẹ, ati imọlẹ ṣe okunkun: ti nfi ìkorò pe adùn, ati adùn pe ìkorò!” (Aisaya 5:20) Isin eke ti mu ohun ti o buru jade fun iran eniyan. O ti yọrisi okunkun nipa tẹmi ti o si ti fi itọwo kíkorò kan silẹ ni ẹnu awọn eniyan alailabosi ọkàn.

Nitori naa, yiyan naa kii ṣe laaarin jijẹ alaigba Ọlọrun gbọ kan ati gbigbagbọ ninu isin eyikeyii. Kii ṣe ohun ti o rọrun bi iyẹn. Gbara ti ẹnikan ba ti mọ aini fun Ọlọrun, iru ẹni yẹn gbọdọ ṣawari ijọsin tootọ. Gẹgẹ bi oluwadii Émile Poulat ṣe sọ ọ lọna ti o dara ninu Le Grand Atlas des Religions (Aworan apejuwe Nla ti Isin) pe: “Awọn ohun ti [awọn isin] nkọni ti wọn si nbeere fun jẹ oniruuru lọna titobi debi pe ko ṣeeṣe lati gba gbogbo wọn gbọ tan.” Ni ifohunṣọkan pẹlu eyi, iwe Encyclopædia Universalis (Iwe Agbedegbẹyọ Agbaye) lede Faranse sọ pe: “Bi ọrundun kọkanlelogun ba pada si isin, . . . eniyan nilati pinnu yala awọn ohun mimọ ti a fifun oun jẹ́ otitọ tabi eke.”

Bi a ṣe Lè Yan Isin Tootọ

Ki ni ohun ti o le ṣamọna wa ninu yiyan isin ti o tọ́? Iwe naa Encyclopædia Universalis tọna nigba ti o tẹnumọ ijẹpataki otitọ. Isin ti o nkọni ni irọ ko le jẹ otitọ. Wolii titobilọla julọ naa ti o tii rin lori ilẹ aye ri wi pe: “Ẹmi ni Ọlọrun: awọn ẹni ti nsin in ko le ṣe alaisin in ni ẹmi ati ni otitọ.”—Johanu 4:24.

Wolii yẹn ni Jesu Kristi, oun si polongo pẹlu pe: “Ẹ wa ni iṣọra lodisi awọn olukọni isin eke, ti wọn nwa sọdọ yin ni wiwọsọ bi agutan ṣugbọn niti gidi wọn jẹ awọn ìkookò oniwọra. Iwọ le sọ ohun ti wọn jẹ nipa eso wọn. . . . Gbogbo igi rere nmu eso ti o yekooro jade, ṣugbọn igi jijẹra nmu eso buburu jade.” (Matiu 7:15-17, Phillips (Gẹẹsi) Ni riri eso buburu awọn isin “jàǹkànjàǹkàn” aye, ati ti awọn ẹ̀yà isin ati isin awo ti wọn ti gbèrú, ọpọ eniyan olotiitọ ọkàn ti bẹrẹsii wo gbogbo wọn gẹgẹ bi ‘awọn igi jijẹra,’ ti ko wulẹ dara tó. Ṣugbọn bawo ni wọn ṣe le ri isin tootọ?

Lọna ti o han gbangba yoo jẹ ohun ti ko ṣeeṣe lati kẹkọọ nipa gbogbo ẹgbẹẹgbẹrun awọn isin ninu ati lode Kristẹndọmu ṣaaju ṣiṣe yiyan kan. Bi o ti wu ki o ri—gẹgẹ bi Jesu ti wi—bi awa ba lo otitọ ati eso gẹgẹ bi awọn ọpa idiwọn, o ṣeeṣe lati da isin tootọ mọ.

Otitọ ati Eso

Jesu mẹnukan otitọ. Nipa ti eyi, awujọ awọn onigbagbọ wo ni o kọ awọn irọ isin ti a mujade lati inu arosọ atọwọdọwọ igbaani ati imọ-ọran Giriiki ti o ti tankalẹ wọnu awọn isin ti o pọ julọ? Ọkan ninu iru awọn irọ́ bẹẹ ni ẹkọ naa pe ọkàn eniyan jẹ alaileeku lọna ajogunba.a Ẹkọ yii ti mu igbagbọ alaibọwọ fun Ọlọrun ti ina ọrun apaadi jade.

Jesu pẹlu mẹnukan awọn eso. Nipa eyii, iwọ ha mọ isin kan ti o ti mu ojulowo ibakẹgbẹpọ agbaye jade nibi ti ẹ̀yà iran, ede, ati awọn ohun idena laaarin awọn orilẹ-ede ti di eyi ti a bori nipasẹ ifẹ ati ìlóye tọtuntosi? Iwọ ha mọ awujọ isin yika aye kan ti awọn mẹmba rẹ̀ yoo gba ki a ṣe inunibini si wọn kaka ti wọn iba fi yọọda fun awọn oṣelu tabi awọn aṣaaju isin lati sun wọn lati koriira awọn arakunrin ati arabinrin wọn ati lati pa wọn lorukọ ifẹ orilẹ-ede ẹni tabi isin? Isin kan ti o kọ iru awọn irọ́ isin bẹẹ ti o si mu iru awọn eso bẹẹ jade yoo funni ni ẹ̀rí alagbara ti jíjẹ́ otitọ, ki yoo ha ṣe bẹẹ bi?

Isin Tootọ Ni a Nṣe Lonii

Iru isin kan bẹẹ ha wà bi? Bẹẹni, o wà. Ṣugbọn iwọ nilati gba pe kii ṣe ọ̀kan ninu awọn isin jàǹkànjàǹkàn inu aye. Eyi ha nilati ya wa lẹnu bi? Rara. Ninu Iwaasu olokiki rẹ̀ lori Oke, Jesu sọ pe: “Ẹ ba ẹnu-ọna hiha wọle; gbooro ni ẹnu-ọna naa, ati oníbùú ni oju-ọna naa ti o lọ si ibi iparun; ọpọlọpọ ni awọn ẹni ti nba ibẹ wọle. Nitori hiha ni ẹnu-ọna naa, tooro sì ni oju-ọna naa, ti o lọ si ibi ìyè, diẹ ni awọn ẹni ti o nrin in.”—Matiu 7:13, 14.

Nitori naa nibo ni a ti lè rí isin tootọ? Pẹlu gbogbo irẹlẹ ati ailabosi, awa nilati sọ pe awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa parapọ jẹ awujọ agbaye kan ti wọn nrin ni ‘oju-ọna tooro ati hiha’ yii. Nitootọ, awọn isin jàǹkànjàǹkàn nfi ẹ̀gàn pe awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni ẹ̀yà isin. Ṣugbọn ohun naa gẹlẹ niyẹn ti awọn aṣaaju isin apẹhinda ni ọrundun kìn-ín-ní C.E. pe awọn Kristẹni ijimiji.—Iṣe 24:1-14.

Eeṣe ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi ni igboya pe awọn ni isin tootọ? O dara, wọn parapọ jẹ́ ẹgbẹ́ ará kari aye ti ó gbooro de eyi ti o ju 200 ilẹ ti o sì nbori ipinya orilẹ-ede, ẹya iran, ede, ati ipo ẹgbẹ-oun-ọgba. Wọn si kọ̀ lati gbagbọ ninu awọn ẹkọ—bi o ti wu ki o jẹ ti igbaani tó—ti o forigbari lọna kedere pẹlu ohun ti Bibeli wi. Ṣugbọn bawo ni wọn ṣe wá sinu iru ipo ti o yẹ ni fifẹ gidigidi kan bẹẹ? Ki si ni ohun ti ṣiṣe isin tootọ mulọwọ? Eyi ati awọn ibeere miiran nipa isin ni a o jiroro ninu awọn ọrọ ẹkọ meji ti o tẹ̀lé e.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fun alaye ti o kun fun isọfunni daradara nipa ipilẹṣẹ alarosọ atọwọdọwọ ti ero igbagbọ yii, wo iwe naa Mankind’s Search for God, ti a tẹjade lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., oju-iwe 52 sí 57.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Awọn Ogun mimọ jẹ apakan awọn eso buburu ti isin eke

[Credit Line]

Bibliothèque Nationale, Paris

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Isin tootọ mu awọn eso didara jade

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́