Ìròyìn Ìjọba No. 37
Ìkéde Kárí Ayé
Òpin Ìsìn Èké Sún Mọ́lé!
▪ Kí ni ìsìn èké?
▪ Báwo ni òpin ṣe máa dé bá ìsìn èké?
▪ Kí ni wàá ṣe tí ò fi ní kàn ọ́?
Kí Ni Ìsìn Èké?
Ṣé ìwà ọ̀daràn tí wọ́n ń hù lórúkọ ìsìn máa ń bà ọ́ lọ́kàn jẹ́? Ṣé ogun, ìpániláyà, àti ìwà ìbàjẹ́ tó kún ọwọ́ àwọn tó láwọn ń sin Ọlọ́run máa ń dùn ọ́? Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìsìn ló sábà máa ń wà nídìí ọ̀pọ̀ wàhálà tó ń ṣẹlẹ̀?
Kì í ṣe gbogbo ìsìn ló jẹ̀bi ọ̀rọ̀ yìí o, ìsìn èké nìkan ló jẹ̀bi rẹ̀. Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìsìn, Jésù Kristi jẹ́ ẹnì kan pàtàkì táwọn èèyàn nílé-lóko mọ̀. Ó sọ pé àwọn oníṣẹ́ ibi ni ọmọ tí ìsìn èké máa ń bí gẹ́gẹ́ bí “igi jíjẹrà [ṣe máa ń] mú èso tí kò ní láárí jáde.” (Mátíù 7:15-17) Irú èso wo ni ìsìn èké máa ń so?
◼ ÌSÌN ÈKÉ MÁA Ń DÁ SÍ OGUN ÀTI Ọ̀RÀN ÌṢÈLÚ: Ìwé ìròyìn Asiaweek sọ pé: “Jákèjádò Éṣíà àti láwọn ibòmíràn, àwọn aṣáájú tó ń wá agbára lójú méjèèjì máa ń fi ọgbọ́n àrékérekè lo ìgbàgbọ́ tí àwọn onísìn ní láti fi mú wọn fa wàhálà kí ọwọ́ tiwọn lè tẹ ohun tí wọ́n ń wá.” Ìdí nìyẹn tí ìwé ìròyìn náà fi kìlọ̀ pé: “Àìmọnúúrò ti di àjàkálẹ̀ àrùn láyé báyìí o.” Aṣáájú ìsìn kan tó gbajúmọ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tiẹ̀ kéde pé: “Bẹ́ ò bá pa gbogbo àwọn apániláyà, wọn ò ní yéé pààyàn.” Kí wá ní àbá rẹ̀? Ó fi ìkórìíra sọ pé: “Ẹ pa gbogbo wọn dà nù ní orúkọ Olúwa.” Èyí yàtọ̀ sí irú ẹ̀mí tí Bíbélì fẹ́ ká ní. Bíbélì sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá sọ gbólóhùn náà pé: ‘Mo nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run,’ síbẹ̀ tí ó kórìíra arákùnrin rẹ̀, òpùrọ́ ni.” (1 Jòhánù 4:20) Jésù pàápàá sọ pé: “Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín.” (Mátíù 5:44) Mélòó nínú àwọn ìsìn tó wà láyé lónìí làwọn èèyàn inú rẹ̀ kì í lọ sógun?
◼ ÌSÌN ÈKÉ MÁA Ń TAN Ẹ̀KỌ́ ÈKÉ KÁLẸ̀: Ọ̀pọ̀ jù lọ ìsìn ló ń kọ́ni pé ọkàn jẹ́ ohun kan tí kò ṣeé fojú rí tó wà nínú èèyàn. Wọ́n ní kì í kú, pé ó máa ń jáde kúrò nínú ara nígbà tá a bá kú. Ọ̀pọ̀ ìsìn ń lo ẹ̀kọ́ yìí láti fi gba tọwọ́ àwọn ọmọ ìjọ, wọ́n á sọ pé kí wọ́n mówó wá kí wọ́n lè bá wọn gbàdúrà nítorí ọkàn àwọn èèyàn wọn tó ti kú. Àmọ́, Bíbélì ò fìyẹn kọ́ni. Bíbélì sọ pé: “Ọkàn tí ń dẹ́ṣẹ̀-òun gan-an ni yóò kú.” (Ìsíkíẹ́lì 18:4) Bíbélì tún sọ pé: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5) Jésù kọ́ni pé àwọn òkú yóò jíǹde. Ǹjẹ́ àjíǹde á pọn dandan tó bá jẹ́ pé èèyàn ní ọkàn tí kì í kú? (Jòhánù 11:11-25) Ṣé ìsìn tìrẹ kì í kọ́ni pé ọkàn kì í kú?
◼ ÌSÌN ÈKÉ MÁA Ń FÀYÈ GBA ÌṢEKÚṢE: Láwọn ilẹ̀ kan, àwọn onísìn máa ń fi àwọn ọkùnrin tó ń bá ọkùnrin lò pọ̀ àtàwọn obìnrin tó ń bá obìnrin lò pọ̀ jẹ àlùfáà wọ́n sì máa ń rọ ìjọba pé kí ìjọba fọwọ́ sí kí ọkùnrin àti ọkùnrin máa fẹ́ra àti kí obìnrin àti obìnrin máa fẹ́ra. Kódà àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ń sọ pé ìṣekúṣe ò dáa máa ń fàyè gba àwọn aṣáájú ìsìn tí wọ́n ń báwọn ọmọdé ṣèṣekúṣe. Àmọ́, kí ni Bíbélì fi kọ́ni? Bíbélì sọ ọ́, ó là á, pé: “Kí a má ṣì yín lọ́nà. Kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí a pa mọ́ fún àwọn ète tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin dà pọ̀, . . . ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) Ǹjẹ́ o mọ àwọn ìsìn tí wọ́n ń fàyè gba ìṣekúṣe?
Kí ló máa gbẹ̀yìn àwọn ìsìn tó ń so èso burúkú? Jésù kìlọ̀ pé: “Gbogbo igi tí kì í mú èso àtàtà jáde ni a óò ké lulẹ̀, tí a ó sì sọ sínú iná.” (Mátíù 7:19) Bẹ́ẹ̀ ni, ìsìn èké yóò pa run! Àmọ́ báwo ni èyí yóò ṣe ṣẹlẹ̀, ìgbà wo sì ni? A óò rí ìdáhùn nínú Bíbélì, nínú ìran kan tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nínú ìwé Ìṣípayá (tàbí Ìfihàn) orí 17 àti 18.
Báwo ni òpin ṣe máa dé bá ìsìn èké
Fojú inú wo ìran yìí ná: Aṣẹ́wó kan jókòó lórí ẹranko ẹhànnà bíbanílẹ́rù kan. Ẹranko ẹhànnà náà ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá. (Ìṣípayá 17:1-4) Ta ni aṣẹ́wó náà dúró fún? Aṣẹ́wó náà ń lo agbára “lórí àwọn ọba ilẹ̀ ayé.” Ó wọ aṣọ aláwọ̀ àlùkò, ó ń lo tùràrí, ọlọ́rọ̀ ni, ọrọ̀ rẹ̀ sì yamùrá. Kò mọ síbẹ̀ o, oníṣẹ́ ìbẹ́mìílò tún ni, ó fi iṣẹ́ ìbẹ́mìílò rẹ̀ “ṣi gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà.” (Ìṣípayá 17:18; 18:12, 13, 23) Bíbélì ràn wá lọ́wọ́ láti rí i pé aṣẹ́wó yìí jẹ́ ètò ìsìn àgbáyé. Ìsìn kan ṣoṣo kọ́ ló dúró fún, kàkà bẹ́ẹ̀, ó dúró fún gbogbo ìsìn tó ń so èso burúkú.
Ẹranko ẹhànnà tí aṣẹ́wó náà ń gùn dúró fún àwọn agbára ìṣèlú ayé.a (Ìṣípayá 17:10-13) Ìsìn èké ń gun ẹranko ẹhànnà yìí, ó máa ń gbìyànjú láti darí ẹranko náà nínú àwọn ìpinnu tí ẹranko náà ń ṣe àti ibi tí ẹranko náà ń lọ.
Àmọ́, ìṣẹ̀lẹ̀ yíyanilẹ́nu kan yóò ṣẹlẹ̀ láìpẹ́. “Ìwo mẹ́wàá tí ìwọ sì rí, àti ẹranko ẹhànnà náà, àwọn wọ̀nyí yóò kórìíra aṣẹ́wó náà, wọn yóò sì sọ ọ́ di ìparundahoro àti ìhòòhò, wọn yóò sì jẹ àwọn ibi kìkìdá ẹran ara rẹ̀ tán, wọn yóò sì fi iná sun ún pátápátá.” (Ìṣípayá 17:16) Lójijì, àwọn agbára ìṣèlú ayé yóò dojú kọ ìsìn èké wọn yóò sì pa á run pátápátá! Kí ló máa mú kí wọ́n ṣe èyí? Ìwé Ìṣípayá sọ pé: ‘Ọlọ́run fi í sínú ọkàn wọn láti mú ìrònú òun ṣẹ.’ (Ìṣípayá 17:17) Bẹ́ẹ̀ ni, ìsìn èké yóò jẹ́jọ́ látàrí gbogbo láabi tó ti ṣe lórúkọ Ọlọ́run. Ọlọ́run yóò ṣèdájọ́ òdodo, yóò lo ètò ìṣèlú tí í ṣe olólùfẹ́ ìsìn èké láti pa ìsìn èké run.
Kí lo gbọ́dọ̀ ṣe tí o kò bá fẹ́ nípìn-ín nínú ohun tó máa gbẹ̀yìn ìsìn èké? Ońṣẹ́ Ọlọ́run pàrọwà pé: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi.” (Ìṣípayá 18:4) Ìsinsìnyí gan-an ló yẹ kó o sá kúrò nínú ìsìn èké! Àmọ́, ibo lo máa sá lọ? Kì í ṣe ọ̀ràn pé kí inú rẹ sáà ti mọ́, kó o má ṣe ìsìn kankan mọ́ o. Torí pé kò sí ọjọ́ ọ̀la fún àwọn tí kò bá jọ́sìn Ọlọ́run. (2 Tẹsalóníkà 1:6-9) Ibi ààbò kan ṣoṣo tó o lè sá lọ ni inú ìsìn tòótọ́. Àmọ́, báwo ló ṣe lè dá ìsìn tòótọ́ mọ̀?
Bó o ṣe lè dá ìsìn tòótọ́ mọ̀
Èso rere wo ni ìsìn tòótọ́ gbọ́dọ̀ máa so?—Mátíù 7:17.
◼ ÌSÌN TÒÓTỌ́ MÁA Ń LO ÌFẸ́: Àwọn olùjọsìn tòótọ́ “kì í ṣe apá kan ayé,” ẹ̀yà àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tó yàtọ̀ síra kì í fa ìyapa, ‘ìfẹ́ sì wà láàárín wọn.’ (Jòhánù 13:35; 17:16; Ìṣe 10:34, 35) Wọn kì í para wọn, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣe tán láti kú fún ara wọn.—1 Jòhánù 3:16.
◼ ÌSÌN TÒÓTỌ́ GBÁRA LÉ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN: Ìsìn tòótọ́ kì í fi “òfin àtọwọ́dọ́wọ́” àti “àṣẹ ènìyàn kọ́ni bí ẹ̀kọ́,” kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló máa ń gbé àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ kà. (Mátíù 15:6-9) Kí nìdí? Ìdí ni pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́.”—2 Tímótì 3:16.
◼ ÌSÌN TÒÓTỌ́ MÁA Ń MÚ KÍ ÌDÍLÉ DÚRÓ SÁN-ÚN Ó SÌ MÁA Ń GBÉ ÌWÀ RERE LÁRUGẸ: Ìsìn tòótọ́ máa ń kọ́ àwọn ọkọ láti máa ‘nífẹ̀ẹ́ aya wọn bí ara wọn,’ ó máa ń kọ́ àwọn aya lati máa ní ‘ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ wọn,’ ó sì máa ń kọ́ àwọn ọmọ pé kí wọ́n máa ‘gbọ́ràn sí àwọn òbí wọn lẹ́nu.’ (Éfésù 5:28, 33; 6:1) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tó ń ṣe àmójútó nínú ìsìn tòótọ́ máa ń fi àpẹẹrẹ ìwà rere lélẹ̀.—1 Tímótì 3:1-10.
Ǹjẹ́ ìsìn kankan wà tó kún ojú òṣùwọ̀n ohun tá a sọ yìí? Ìwé kan tí wọ́n tẹ̀ jáde lọ́dún 2001 tí wọ́n pe àkọ́lé rẹ̀ ní Holocaust Politics sọ pé: “Tó bá jẹ́ pé a tún rí àwọn tí wọn ń ṣe bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni, ìpànìyàn nípakúpa tó ṣẹlẹ̀ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì ì bá má ṣẹlẹ̀, ìpẹ̀yàrun ì bá sì ti dohun ìgbàgbé.”
Ká sòótọ́, ní ọgọ́rùn-ún méjì ó lé márùndínlógójì [235] ilẹ̀, kì í wulẹ̀ẹ́ ṣe pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù ìwà rere tí Bíbélì fi kọ́ni nìkan ni, àmọ́ wọ́n tún ń tẹ̀ lé ohun tí wọ́n ń wàásu. A gbà ọ́ níyànjú pé kó o sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kí wọ́n ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ rẹ kó o bàa lè jọ́sìn rẹ̀ lọ́nà tó fẹ́. Ìsinsìnyí gan-an ni kó o ṣe bẹ́ẹ̀ o. Má ṣe jáfara. Òpin ìsìn èké ti sún mọ́lé!—Sefanáyà 2:2, 3.
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ìhìn Bíbélì tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù, jọ̀wọ́, kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ.
□ Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà lójú ewé yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Kó o lè rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa èyí, wo ìwé kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe tí àkọlé rẹ̀ sọ pé, Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbi Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀!
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 3]
Ìsìn èké ń lo agbára “lórí àwọn ọba ilẹ̀ ayé”
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 3]
“Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi”