Ẹ Jìnnà Pátápátá Sí Ìsìn Èké!
“‘Ẹ jáde kúrò láàárín wọn, kí ẹ sì ya ara yín sọ́tọ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘kí ẹ sì jáwọ́ nínú fífọwọ́kan ohun àìmọ́.’”—2 KỌ́RÍŃTÌ 6:17.
1. Kí làwọn nǹkan tí ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ èèyàn ń sapá láti mọ̀ lójú méjèèjì?
Ọ̀PỌ̀ olóòótọ́ èèyàn ni kò mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti nípa ọjọ́ iwájú ìran ènìyàn. Àìmọ nǹkan méjì yìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń sapá láti mọ̀ ọ́n lójú méjèèjì, mú kí gbogbo nǹkan pòrúurùu mọ́ wọn lọ́kàn, wọn ò sì mọ ohun tí wọn ì bá ṣe. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ni ìgbàgbọ́ nínú ohun asán, àwọn ààtò àtàwọn ayẹyẹ tí Ẹlẹ́dàá wa kórìíra ti mú lẹ́rú. Ó ṣeé ṣe kí àwọn kan lára àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ tàbí aládùúgbò rẹ gbà gbọ́ pé ọ̀run àpáàdì oníná wà, pé Ọlọ́run jẹ́ mẹ́talọ́kan, pé ọkàn kì í kú, tàbí kí wọ́n gba àwọn ẹ̀kọ́ irọ́ míì bẹ́ẹ̀ gbọ́.
2. Kí làwọn aṣáájú ẹ̀sìn ń ṣe, kí lèyí sì yọrí sí?
2 Kí ló fa àìmọ̀kan nípa Ọlọ́run tó gbilẹ̀ kárí ayé yìí? Ẹ jẹ́ mọ̀ pé ẹ̀sìn ni, ní pàtàkì àwọn ẹ̀sìn àti aṣáájú ẹ̀sìn tó ń kọ́ni láwọn ẹ̀kọ́ tó ta ko èrò ọkàn Ọlọ́run. (Máàkù 7:7, 8) Ẹ̀kọ́ wọn ti ṣi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà débi pé ohun tí Ọlọ́run kórìíra gan-an ni wọ́n ń ṣe tí wọ́n rò pé àwọn ń sin Ọlọ́run tòótọ́. Ohun tí ẹ̀sìn èké sọ àwọn èèyàn dà nìyẹn o.
3. Ta lẹni tó wà nídìí ìsìn èké gan-an, báwo ni Bíbélì sì ṣe ṣàpèjúwe rẹ̀?
3 Ẹ̀dá kan tá ò lè fojú rí ló wà lẹ́yìn ẹ̀sìn èké. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀dá yìí, ó ní “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí ti fọ́ èrò inú àwọn aláìgbàgbọ́ lójú, kí ìmọ́lẹ̀ ìhìn rere ológo nípa Kristi, ẹni tí ó jẹ́ àwòrán Ọlọ́run, má bàa mọ́lẹ̀ wọlé.” (2 Kọ́ríńtì 4:4) Láìsí àní-àní, Sátánì Èṣù ni “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí.” Òun gan-an ló wà nídìí ìsìn èké. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Sátánì fúnra rẹ̀ a máa pa ara rẹ̀ dà di áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀. Nítorí náà, kì í ṣe ohun ńlá bí àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú bá ń pa ara wọn dà di òjíṣẹ́ òdodo.” (2 Kọ́ríńtì 11:14, 15) Sátánì máa ń mú kí ohun burúkú dà bí ohun tó dáa, ó sì ń tan àwọn èèyàn láti mú kí wọ́n gba irọ́ gbọ́.
4. Kí ni Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì sọ nípa àwọn wòlíì èké?
4 Abájọ tí Bíbélì fi ka ìsìn èké sí ohun tó burú jáì! Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run tipasẹ̀ Mósè fún àwọn èèyàn rẹ̀, ìyẹn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní òfin pé wọn ò gbọ́dọ̀ fetí sílẹ̀ sáwọn wòlíì èké. Ó ní kí wọ́n “fi ikú pa” ẹnikẹ́ni tó bá ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ èké, tó ní káwọn èèyàn máa bọ̀rìṣà “nítorí pé ó ti sọ̀rọ̀ nípa ìdìtẹ̀ sí Jèhófà.” Òfin yẹn sọ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ‘mú ohun tí ó jẹ́ ibi kúrò ní àárín wọn.’ (Diutarónómì 13:1-5) Dájúdájú, ohun burúkú ni Jèhófà ka ìsìn èké sí.—Ìsíkíẹ́lì 13:3.
5. Ìkìlọ̀ wo la gbọ́dọ̀ kọbi ara sí lóde òní?
5 Bí Jèhófà ṣe ka ìsìn èké sí ohun tí kò dáa rárá náà ni Jésù Kristi àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ṣe kà á sí ohun àìdáa. Jésù kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn wòlíì èké tí ń wá sọ́dọ̀ yín nínú aṣọ àgùntàn, ṣùgbọ́n ní inú, wọ́n jẹ́ ọ̀yánnú ìkookò.” (Mátíù 7:15; Máàkù 13:22, 23) Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ìrunú Ọlọ́run ni a ń ṣí payá láti ọ̀run lòdì sí gbogbo àìṣèfẹ́ Ọlọ́run àti àìṣòdodo àwọn ènìyàn tí wọ́n ń tẹ òtítọ́ rì.” (Róòmù 1:18) Ó ṣe pàtàkì gan-an ni o pé káwọn Kristẹni tòótọ́ kọbi ara sí ìkìlọ̀ yìí kí wọ́n sì jìnnà pátápátá sí ẹnikẹ́ni tó bá ń tẹ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rì tàbí tó ń tan ẹ̀kọ́ èké káàkiri!—1 Jòhánù 4:1.
Ẹ Sá Kúrò Nínú “Bábílónì Ńlá”
6. Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe “Bábílónì Ńlá”?
6 Wo bí ìwé Ìṣípayá ṣe ṣàpèjúwe ìsìn èké. Ó pè é ní aṣẹ́wó kan tó ti mutí yó, ó sì sọ pé ó lágbára lórí ìjọba púpọ̀ àtàwọn tó wà lábẹ́ wọn. Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọba ló ń bá obìnrin ìṣàpẹẹrẹ yìí ṣàgbèrè, àti pé ó ti mu ẹ̀jẹ̀ àwọn olùjọsìn tòótọ́ ní àmupara. (Ìṣípayá 17:1, 2, 6, 18) Bíbélì sọ pé orúkọ kan wà níwájú orí rẹ̀ tó bá ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà ìríra tó ń hù mu. Orúkọ náà ni: “Bábílónì Ńlá, ìyá àwọn aṣẹ́wó àti ti àwọn ohun ìríra ilẹ̀ ayé.”—Ìṣípayá 17:5.
7, 8. Ọ̀nà wo ni ẹ̀sìn èké gbà sọ ara rẹ̀ di aṣẹ́wó, kí ló sì yọrí sí?
7 Ọ̀nà tí Ìwé Mímọ́ gbà ṣàpèjúwe Bábílónì Ńlá bá gbogbo ẹ̀sìn èké àgbáyé lápapọ̀ mu gan-an ni. Kì í ṣe pé ọ̀kẹ́ àìmọye ẹ̀sìn inú ayé kúkú da ẹ̀sìn wọn pọ̀ sọ́nà kan o, àmọ́ ọ̀kan náà ni wọ́n nítorí ohun kan náà ni wọ́n jọ ń lépa, ìwà kan náà ni wọ́n sì ń hù. Ẹ̀sìn èké sì lágbára tó pọ̀ gan-an lórí àwọn ìjọba ayé gẹ́gẹ́ bí àpèjúwe aṣẹ́wó obìnrin inú ìwé Ìṣípayá ṣe fi hàn. Ẹ̀sìn èké ayé ò yàtọ̀ sí obìnrin tí kò jẹ́ olóòótọ́ sí ọkọ, tó ń ṣe aṣẹ́wó kiri torí pé ńṣe ló ń bá ìjọba ayé kan tẹ̀ lé òmíràn ní àjọṣepọ̀. Ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù sọ pé: “Ẹ̀yin panṣágà obìnrin, ẹ kò ha mọ̀ pé ìṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú ayé jẹ́ ìṣọ̀tá pẹ̀lú Ọlọ́run? Nítorí náà, ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé ń sọ ara rẹ̀ di ọ̀tá Ọlọ́run.”—Jákọ́bù 4:4.
8 Ìyà tí dída ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn èké pọ̀ mọ́ tàwọn ìjọba ayé ti fi jẹ ọmọ aráyé kì í ṣe kékeré. Ọ̀jọ̀gbọ́n Xolela Mangcu, ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà kan tó ń ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ ìṣèlú, sọ pé: “Tá a bá wo ìtàn ayé, a óò rí i pé àìmọye ìgbà ni ọ̀rọ̀ dída ẹ̀sìn pọ̀ mọ́ ìṣèlú ti fa ogun táwọn èèyàn ti fẹ̀mí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn ṣòfò.” Láìpẹ́ yìí, ìwé ìròyìn kan sọ pé: “Lóde òní, ìjà tó máa ń burú jù lọ, tí wọ́n sì ti máa ń tàjẹ̀ sílẹ̀ jù lọ ni ìjà lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn.” Ẹ̀mí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ti pa rẹ́ sínú àwọn ogun táwọn onísìn ń rúná sí. Àní Bábílónì Ńlá ti ṣenúnibíni sáwọn tó jẹ́ olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run, ó sì ń pa wọ́n nípakúpa, ńṣe ló dà bíi pé ó ń mu ẹ̀jẹ̀ wọn lámupara.—Ìṣípayá 18:24.
9. Báwo ni ìwé Ìṣípayá ṣe fi bí Jèhófà ṣe kórìíra ìsìn èké tó hàn?
9 Ohun tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí Bábílónì Ńlá jẹ́ ká rí i kedere pé Jèhófà kórìíra ìsìn èké. Ìṣípayá 17:16 sọ pé: “Ìwo mẹ́wàá tí ìwọ sì rí, àti ẹranko ẹhànnà náà, àwọn wọ̀nyí yóò kórìíra aṣẹ́wó náà, wọn yóò sì sọ ọ́ di ìparundahoro àti ìhòòhò, wọn yóò sì jẹ àwọn ibi kìkìdá ẹran ara rẹ̀ tán, wọn yóò sì fi iná sun ún pátápátá.” Bẹ́ẹ̀ ni o, ẹranko ńlá kan yóò kọ́kọ́ fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, yóò sì jẹ ẹran ara rẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n yóò wá fi iná sun ìyókù ara rẹ̀ pátápátá. Ohun tí ìjọba ayé máa ṣe sí gbogbo ẹ̀sìn èké gẹ́lẹ́ nìyẹn láìpẹ́. Ọlọ́run yóò rí sí i pé wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. (Ìṣípayá 17:17) Láìsí àní-àní, Bábílónì Ńlá, ìyẹn àpapọ̀ ìsìn èké àgbáyé, máa tó pa run. “A kì yóò sì tún rí i mọ́ láé.”—Ìṣípayá 18:21.
10. Ìhà wo ló yẹ ká kọ sí ẹ̀sìn èké?
10 Ìhà wo ló yẹ kí àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ kọ sí Bábílónì Ńlá? Bíbélì sọ ohun tí wọn gbọ́dọ̀ ṣe kedere. Ó pàṣẹ pé: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi, bí ẹ kò bá fẹ́ ṣàjọpín pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, bí ẹ kò bá sì fẹ́ gbà lára àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀.” (Ìṣípayá 18:4) Àwọn tó bá fẹ́ rí ìgbàlà gbọ́dọ̀ jáde kúrò nínú ẹ̀sìn èké kó tó pẹ́ jù. Nígbà tí Jésù Kristi wà láyé, ó sọ tẹ́lẹ̀ pé ní ìkẹyìn ọjọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ni yóò kàn máa fẹnu lásán jẹ́ ọmọlẹ́yìn òun. (Mátíù 24:3-5) Àmọ́ ó lóun yóò sọ fún wọn pé: “Èmi kò mọ̀ yín rí! Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin oníṣẹ́ ìwà àìlófin.” (Mátíù 7:23) Jésù Kristi tó ti di Ọba báyìí kórìíra ẹ̀sìn èké gan-an ni.
Ọ̀nà Wo La Ó Gbà Jìnnà sí Ìsìn Èké?
11. Kí la ní láti ṣe ká lè jìnnà pátápátá sí ìsìn èké?
11 Kristẹni tòótọ́ máa ń jìnnà pátápátá sí ìsìn èké àti gbogbo ẹ̀kọ́ táwọn ẹlẹ́sìn èké ń kọ́ni. Ó fi hàn pé a kò ní máa fetí sí ètò táwọn onísìn ń ṣe lórí rédíò tàbí ká máa wò ó lórí tẹlifíṣọ̀n, a ò sì ní máa ka àwọn ìwé ìsìn tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ èké nípa Ọlọ́run àti Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Sáàmù 119:37) Ó tún bọ́gbọ́n mu pé ká má ṣe lọ síbi ètò tàbí eré ìnàjú kankan tí ẹgbẹ́ tàbí àjọ èyíkéyìí tó jẹ mọ́ ti ẹ̀sìn èké bá ṣonígbọ̀wọ́ rẹ̀. Bákan náà, a ò ní ṣètìlẹyìn fún ẹ̀sìn èké lọ́nàkọnà. (1 Kọ́ríńtì 10:21) Tá a bá ń yẹra fún nǹkan wọ̀nyí, ẹnikẹ́ni ò ní lè gbé wa lọ “gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé, tí kò sì sí ní ìbámu pẹ̀lú Kristi.”—Kólósè 2:8.
12. Báwo lẹnì kan ṣe lè yọwọ́ pátápátá kúrò nínú ẹ̀sìn èké?
12 Bí orúkọ ẹnì kan tó fẹ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá ṣì wà nínú ìwé ẹ̀sìn èké kan pé ó jẹ́ ọmọ ìjọ wọn ńkọ́, kí ni kí ó ṣe? Onítọ̀hún kàn lè kọ lẹ́tà sí wọn pé òun kì í ṣe ọmọ ìjọ wọn mọ́, láti fi hàn pé òun ò fẹ́ kí wọ́n máa ka òun mọ́ àwọn tó wà nínú ẹ̀sìn èké mọ́. Ó sì ṣe pàtàkì gan-an pé kónítọ̀hún gbé ìgbésẹ̀ tó ṣe gúnmọ́ láti rí i dájú pé òun jáwọ́ pátápátá nínú ohunkóhun tó bá jẹ́ ti ìsìn èké kó bàa lè wà láìlábààwọ́n. Ìwà àti ìṣe ẹni tó fẹ́ di Ẹlẹ́rìí náà gbọ́dọ̀ jẹ́ kó hàn kedere sí àwọn tó wà nínú ẹ̀sìn èké náà àti gbogbo èèyàn pé kò sí lára àwọn ẹlẹ́sìn èké yẹn mọ́.
13. Ìmọ̀ràn wo ni Bíbélì fúnni lórí yíyẹ tó yẹ ká jìnnà sí ìsìn èké?
13 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́. Nítorí àjọṣe wo ni òdodo àti ìwà àìlófin ní? Tàbí àjọpín wo ni ìmọ́lẹ̀ ní pẹ̀lú òkùnkùn? Síwájú sí i, ìbáramu wo ni ó wà láàárín Kristi àti Bélíálì? Tàbí ìpín wo ni olùṣòtítọ́ ní pẹ̀lú aláìgbàgbọ́? Ìfohùnṣọ̀kan wo sì ni tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ní pẹ̀lú àwọn òrìṣà? . . . ‘Nítorí náà, ẹ jáde kúrò láàárín wọn, kí ẹ sì ya ara yín sọ́tọ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘kí ẹ sì jáwọ́ nínú fífọwọ́kan ohun àìmọ́.’” (2 Kọ́ríńtì 6:14-17) Bá a ṣe lè tẹ̀ lé ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí wí ni pé ká jìnnà pátápátá sí ìsìn èké. Ṣé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù yìí wá ń fi hàn pé a ò gbọ́dọ̀ bá àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn èké ṣe nǹkan kan pọ̀ ni?
“Ẹ Máa Bá A Lọ ní Rírìn Nínú Ọgbọ́n”
14. Ǹjẹ́ a ní láti kúkú yàgò pátápátá fáwọn èèyàn tó ń ṣe ìsìn èké? Ṣàlàyé.
14 Ṣé kí àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ pa àwọn èèyàn tó ń ṣe ìsìn èké tì pátápátá ni? Ṣé ká kúkú wá ta kété sí gbogbo àwọn tí kò bá fara mọ́ ẹ̀sìn wa ni? Ó tì o. Ohun tí èkejì nínú òfin méjì tó tóbi jù lọ sọ ni pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Mátíù 22:39) Bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn aládùúgbò tàbí ọmọnìkejì wa, à ń fi hàn pé a fẹ́ràn wọn nìyẹn. A sì tún ń fi hàn pé a fẹ́ràn wọn nípa bá a ṣe ń bá wọn ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí a sì ń jẹ́ kí wọ́n rí i pé ó yẹ kí wọ́n jáwọ́ nínú ìsìn èké.
15. Kí ni ṣíṣàìjẹ́ “apá kan ayé” túmọ̀ sí?
15 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń wàásù ìhín rere fún ọmọnìkejì wa, àwa tá a jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù “kì í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 15:19) Àwùjọ ọmọ aráyé tó ti sọ ara wọn di àjèjì sí Ọlọ́run ni ọ̀rọ̀ náà “ayé” tá a lò nínú ẹsẹ Bíbélì yìí ń tọ́ka sí o. (Éfésù 4:17-19; 1 Jòhánù 5:19) A yàtọ̀ sí ayé ní ti pé a ti kọ gbogbo ìwà, ọ̀rọ̀ àti ìṣe tí Jèhófà ò fẹ́ sílẹ̀ pátápátá. (1 Jòhánù 2:15-17) Bákan náà, níwọ̀n bí Bíbélì ti sọ pé “ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́,” a kì í bá àwọn tí ìgbé ayé wọn ò bá ìlànà Kristẹni mu ṣe wọléwọ̀de. (1 Kọ́ríńtì 15:33) Ohun tí ṣíṣàìjẹ́ apá kan ayé túmọ̀ sí ni pé ká pa ara wa mọ́ “láìní èérí kúrò nínú ayé.” (Jákọ́bù 1:27) Nítorí náà, yíyàtọ̀ tá a yàtọ̀ sí ayé kò túmọ̀ sí pé a kò ní ní àjọṣe kankan pẹ̀lú àwọn èèyàn.—Jòhánù 17:15, 16; 1 Kọ́ríńtì 5:9, 10.
16, 17. Báwo ló ṣe yẹ káwa Kristẹni máa hùwà sáwọn tí kò mọ ẹ̀kọ́ òtítọ́?
16 Báwo ló wá ṣe yẹ ká máa hùwà sáwọn tí kò mọ ẹ̀kọ́ òtítọ́? Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí ìjọ tó wà ní Kólósè pé: “Ẹ máa bá a lọ ní rírìn nínú ọgbọ́n sí àwọn tí ń bẹ lóde, kí ẹ máa ra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín. Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ kí ẹ fi ìdáhùn fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.” (Kólósè 4:5, 6) Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Ẹ sọ Kristi di mímọ́ gẹ́gẹ́ bí Olúwa nínú ọkàn-àyà yín, kí ẹ wà ní ìmúratán nígbà gbogbo láti ṣe ìgbèjà níwájú olúkúlùkù ẹni tí ó bá fi dandan béèrè lọ́wọ́ yín ìdí fún ìrètí tí ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n kí ẹ máa ṣe bẹ́ẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” (1 Pétérù 3:15) Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni nímọ̀ràn pé kí wọ́n “má sọ̀rọ̀ ẹnì kankan lọ́nà ìbàjẹ́, [kí wọ́n] má ṣe jẹ́ aríjàgbá, [kí wọ́n] jẹ́ afòyebánilò, kí wọ́n máa fi gbogbo ìwà tútù hàn sí ènìyàn gbogbo.”—Títù 3:2.
17 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í yájú síni bẹ́ẹ̀ ni a kì í fojú tín-ínrín ẹnikẹ́ni. A kì í fi orúkọ ẹ̀gàn pe àwọn ẹlẹ́sìn míì rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la máa ń fòye báni lò báwọn tá a fẹ́ wàásù fún, àwọn aládùúgbò wa tàbí àwọn tá a jọ wà níbi iṣẹ́ bá tiẹ̀ kanra mọ́ wa tàbí tí wọ́n bú wa pàápàá.—Kólósè 4:6; 2 Tímótì 2:24.
‘Máa Di Àpẹẹrẹ Àwọn Ọ̀rọ̀ Afúnni-Nílera Mú’
18. Ipò burúkú wo làwọn tó bá tún padà sínú ìsìn èké ń bọ́ sí?
18 Ohun tó burú gbáà ni pé kéèyàn mọ ẹ̀kọ́ òtítọ́ tán kó tún wá padà sínú ìsìn èké! Bíbélì sọ irú aburú tó ń bá àwọn tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó ní: “Dájúdájú, bí ó bá jẹ́ pé, lẹ́yìn tí wọ́n ti yèbọ́ kúrò nínú àwọn ẹ̀gbin ayé nípasẹ̀ ìmọ̀ pípéye nípa Jésù Kristi Olúwa àti Olùgbàlà, wọ́n tún kó wọnú nǹkan wọ̀nyí gan-an, tí a si ṣẹ́pá wọn, àwọn ipò ìgbẹ̀yìn ti burú fún wọn ju ti àkọ́kọ́. . . . Òwe tòótọ́ náà ti a máa ń pa ti ṣẹ sí wọn lára: ‘Ajá ti padà sínú èébì ara rẹ̀, àti abo ẹlẹ́dẹ̀ tí a ti wẹ̀ sínú yíyígbiri nínú ẹrẹ̀.’”—2 Pétérù 2:20-22.
19. Kí nìdí tó fi yẹ ká wà lójúfò kí ohunkóhun má bàa tẹ ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa rì?
19 A gbọ́dọ̀ wà lójúfò kí ohunkóhun má bàa tẹ ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa rì. Àní sẹ́, ó yẹ ká fura o! Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé: “Àsọjáde onímìísí sọ ní pàtó pé ní ìkẹyìn àwọn sáà àkókò, àwọn kan yóò yẹsẹ̀ kúrò nínú ìgbàgbọ́, ní fífi àfiyèsí sí àwọn àsọjáde onímìísí tí ń ṣini lọ́nà àti àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù.” (1 Tímótì 4:1) “Ìkẹyìn àwọn sáà àkókò” ọ̀hún là ń gbé yìí. Àwọn tí kò bá jìnnà pátápátá sí ìsìn èké lè dẹni tí “a ń bì kiri gẹ́gẹ́ bí nípasẹ̀ àwọn ìgbì òkun, tí a sì ń gbé síhìn-ín sọ́hùn-ún nípasẹ̀ gbogbo ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ́ nípasẹ̀ ìwà àgálámàṣà àwọn ènìyàn, nípasẹ̀ àlùmọ̀kọ́rọ́yí nínú dídọ́gbọ́n hùmọ̀ ìṣìnà.”—Éfésù 4:13, 14.
20. Báwo la ṣe lè dáàbò bo ara wa kí ẹ̀sìn èké má bàa kéèràn ràn wá?
20 Báwo la ṣe lè dáàbò bo ara wa kí ẹ̀sìn èké má bàa kéèràn ràn wá? Ẹ wo àwọn ohun tí Jèhófà ti pèsè fún wa ná. Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà níbẹ̀ fún wa. (2 Tímótì 3:16, 17) Jèhófà tún ń pèsè ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí fún wa nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Mátíù 24:45) Bá a ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú òtítọ́, ǹjẹ́ kò yẹ ká fẹ́ràn láti máa jẹ ‘oúnjẹ líle tó jẹ́ ti àwọn ènìyàn tí ó dàgbà dénú,’ kó sì máa wù wá láti máa pàdé pọ̀ déédéé níbi tá a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? (Hébérù 5:13, 14; Sáàmù 26:8) Ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé à ń lo gbogbo àwọn ohun tí Jèhófà ń pèsè fún wa ká bàa lè ‘máa di àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera tá a ti gbọ́ mú.’ (2 Tímótì 1:13) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a óò lè jìnnà pátápátá sí ìsìn èké.
Ẹ̀kọ́ Wo Lo Rí Kọ́?
• Kí ni “Bábílónì Ńlá”?
• Kí la ní láti ṣe láti lè jìnnà pátápátá sí ẹ̀sìn èké?
• Àwọn ohun tó lè tẹ ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa rì wo la ní láti yàgò fún?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí Bíbélì fi fi obìnrin oníṣekúṣe ṣàpẹẹrẹ “Bábílónì Ńlá”?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Láìsí àní-àní, Bábílónì Ńlá máa tó pa run
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
“Inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀” la fi máa ń bá àwọn tí kò fara mọ́ ẹ̀sìn wa lò