Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Rí Ìtùnú
1 Gbígbọ́ nípa ìjàǹbá, ogun, ìwà ọ̀daràn, àti ìjìyà ti sú ọ̀pọ̀ ènìyàn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, lọ́nà tí ó hàn gbangba, ìtùnú kò sí nínú àwọn ìròyìn òde òní, ó jẹ́ ohun kan tí aráyé ń fẹ́ ní ti gidi. Láti tuni nínú túmọ̀ sí “láti fúnni ní okun àti ìrètí” àti “láti mú ìdínkù bá ẹ̀dùn ọkàn tàbí ìṣòro tí” ẹlòmíràn ní. Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a mú wa gbára dì láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ lọ́nà yí. (2 Kọ́r. 1:3, 4) Àwọn ìwé wa pẹlẹbẹ, tí a gbé karí Bíbélì, tí a óò fi lọni ní July àti August ní àwọn ìhìn iṣẹ́ òtítọ́ tí ń tuni nínú. (Róòmù 15:4) Àwọn àbá díẹ̀ nìyí fún fífi wọ́n lọni lábẹ́ onírúurú àyíká ipò:
2 Ìròyìn nípa ohun ìbànújẹ́ kan tí ó ṣẹlẹ̀ lè ṣí àǹfààní sílẹ̀ láti jẹ́rìí kí a sì tu àwọn ẹlòmíràn nínú, bóyá nípa sísọ tí o bá sọ ohun kan bí èyí:
◼ “Nígbà tí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, àwọn kan máa ń ṣe kàyéfì bóyá Ọlọ́run wà ní tòótọ́, bí òun bá sì wà, bóyá òun bìkítà nípa wa. Kí ni èrò rẹ? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ọ̀nà kan láti pinnu bóyá Ọlọ́run wà ni nípa fífi ìlànà kan tí ó fìdí múlẹ̀ ṣinṣin sílò.” Ka Hébérù 3:4. Tọ́ka sí àwọn ohun mìíràn tí ó wà ní àyíká wa tí ó ṣe kedere pé ẹnì kan ni ó gbọ́dọ̀ dá wọn. Lẹ́yìn náà máa bá a nìṣó pé: “Mo ní ìwé pẹlẹbẹ kan tí mo mọ̀ pé ìwọ yóò rí i pé ó ń tuni nínú. A pe àkọlé rẹ̀ ní Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? [Ka àwọn ìbéèrè tí ń bẹ lẹ́yìn ìwé pẹlẹbẹ náà.] Ó ní ẹ̀rí tí ó dáni lójú pé kì í ṣe pé Ọlọ́run wà nìkan ni ṣùgbọ́n pé láìpẹ́, òun yóò mú òpin dé bá gbogbo àwọn ipò àìsí ìdájọ́ òdodo tí a ń dojú kọ lónìí. Ẹ̀dà yí lè jẹ́ tìrẹ fún ọrẹ ₦15.” Ṣètò láti pa dà lọ.
3 Nígbà ìpadàbẹ̀wò, o lè sọ pé:
◼ “Mo fi ìwé pẹlẹbẹ náà, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? lé ọ lọ́wọ́ nígbà tí a ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀rí tí ó fi hàn pé Ọlọ́run wà. Bóyá o ṣàkíyèsí kókó yìí ní ojú ìwé 7. [Fi àwòrán tí ó wà níbẹ̀ hàn án kí o sì ṣàkópọ̀ ìpínrọ̀ 15.] Àpẹẹrẹ kan péré ni èyí tí ń fi hàn pé Ọlọ́run kan tí ó bìkítà gbọ́dọ̀ wà ní tòótọ́. [Ka ìpínrọ̀ 27 ní ojú ìwé 9.] Ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti ràn mí lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé ojoojúmọ́ nítorí pé ó ń pèsè ojú ìwòye Ọlọ́run nípa àwọn ọ̀ràn.” Fi àṣefihàn bí a ti ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ̀ ọ́.
4 Ní lílo ìwé pẹlẹbẹ náà, “Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?” o lè sọ ẹni tí o jẹ́ kí o sì sọ pé:
◼ “Mo ń ké sí ọ nípa ìhìn iṣẹ́ pàtàkì kan tí a ṣàlàyé nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?” Ka ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ ní ojú ewé 4 nínú ìwé pẹlẹbẹ náà. Béèrè èrò onílé, kí o sì jẹ́ kí ó fèsì. “Bíbélì fi hàn ní Aísáyà 45:18 pé tìtorí tiwa ni a ṣe dá ilẹ̀ ayé.” [Kà á.] Lẹ́yìn náà, ṣàlàyé ète ìwé pẹlẹbẹ náà kí o sì fi ẹ̀dà kan lọ̀ ọ́ fún ọrẹ ₦15.
5 Nígbà tí o bá tún ké sí i, o lè gbìyànjú ìyọsíni yìí láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́:
◼ “Èmi yóò fẹ́ láti tẹ̀ síwájú lórí ìjíròrò wa tí ó kẹ́yìn nípa ṣíṣàlàyé ẹni náà tí ó lè sọ ète ìgbésí ayé fún wa. [Tún ìpínrọ̀ 1 àti 2 ní ojú ewé 6 nínú ìwé pẹlẹbẹ Ète Igbesi-Aye sọ lọ́rọ̀ míràn.] Ìṣípayá 4:11 ṣàlàyé pé Jèhófà Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá wa. [Kà á.] Dájúdájú, òun gbọ́dọ̀ ní ìdí kan tí ó ṣe dá wa. Àwọn ènìyàn tí wọ́n fẹ́ láti mọ ìdí náà ti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a kọ sílẹ̀, Bíbélì. Èmi yóò fẹ́ láti nawọ́ àǹfààní yẹn sí ọ.” Ṣàlàyé bí a ṣe ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé tí a ń ṣe lọ́fẹ̀ẹ́, kí o sì ṣètò láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà.
6 Ìyọsíni gbígbéṣẹ́ yìí lè tu àwọn tí wọ́n ti nírìírí ikú olólùfẹ́ kan nínú:
◼ “Mo ń ṣe iṣẹ́ kan tí ó kan gbogbo ènìyàn nítorí àwọn tí wọ́n ti pàdánù olólùfẹ́ kan nínú ikú. Níwọ̀n bí èyí ti lè jẹ́ ọ̀kan nínú ohun tí ó le koko jù lọ tí ẹnikẹ́ni lára wa lè dojú kọ, a ti pèsè ìwé pẹlẹbẹ yìí, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú. Ó ti ran àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn lọ́wọ́. Èmi yóò fẹ́ láti fi ohun tí ó sọ nípa ìlérí tí ń ru ìmọ̀lára ẹni sókè tí Jésù Kristi ṣe hàn ọ́. [Ka ìpínrọ̀ karùn ún lójú ewé 26, àti Jòhánù 5:21, 28, 29.] Kíyè sí àwòrán yìí ní ojú ewé 29 tí ń ṣàpèjúwe àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere ní ti bí Jésù ṣe jí Lásárù dìde ní ti gidi láti inú òkú. Èmi yóò láyọ̀ láti fi ìwé pẹlẹbẹ tí ń tuni nínú yìí sílẹ̀ fún ọ fún ọrẹ ₦15.”
7 Nígbà tí o bá pa dà lọ, o tún lè fi àwòrán tí ó wà ní ojú ewé 29 ìwé pẹlẹbẹ náà, “Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú,” hàn án lẹ́ẹ̀kan sí i kí o sì sọ pé:
◼ “Rántí ìjíròrò wa nípa jíjí tí Kristi jí Lásárù dìde. [Ka àkọlé àwòrán tí ó wà ní ojú ewé 28, kí o sì ṣàyẹ̀wò àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí ó wà lábẹ́ ìsọ̀rí orí ọ̀rọ̀ náà, “Ó Ha Ṣẹlẹ̀ Níti Gidi Bí?”] Bí ọkàn àyà rẹ bá yán hànhàn láti gbà gbọ́ pé o lè rí olólùfẹ́ kan tí ó ti kú lẹ́ẹ̀kan sí i, jẹ́ kí n ràn ọ́ lọ́wọ́ kí o lè ní ìgbàgbọ́ nínú ìrètí àjíǹde.” Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ̀ ọ́.
8 Ǹjẹ́ kí a ṣe gbogbo ohun tí a bá lè ṣe nínú àwọn oṣù tí ń bẹ níwájú láti ṣàfarawé Jésù nípa ‘títu gbogbo àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú.’—Aísá. 61:2.