ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/97 ojú ìwé 3
  • Àpótí Ìbéèrè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àpótí Ìbéèrè
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fi Ara Rẹ fún Ìwé Kíkà
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Sọ̀rọ̀ Bí Ọlọ́run Ṣe Dá Ọ
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Kí Ọ̀rọ̀ Yọ̀ Mọ́ni Lẹ́nu
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Bí Akẹ́kọ̀ọ́ Ṣe Lè Múra Iṣẹ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Sílẹ̀
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
km 7/97 ojú ìwé 3

Àpótí Ìbéèrè

◼ Kí ni ó yẹ kí a fi sọ́kàn ní ti kíka àwọn ìpínrọ̀ ní ìpàdé?

A máa ń lo púpọ̀ nínú àkókò tí a yàn fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ láti ka àwọn ìpínrọ̀. Èyí túmọ̀ sí pé gẹ́gẹ́ bí olùkọ́, ẹrù iṣẹ́ wíwúwo já lé arákùnrin tí a yàn láti kàwé léjìká. Ó gbọ́dọ̀ kàwé lọ́nà kan tí yóò mú kí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà ‘nítumọ̀’ kí ó baà lè jẹ́ pé kì í ṣe pé àwọn tí ń tẹ́tí sílẹ̀ yóò lóye àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà nìkan ni ṣùgbọ́n a óò sún wọn láti gbégbèésẹ̀ pẹ̀lú. (Neh. 8:8) Nítorí náà, òǹkàwé ní láti múra sílẹ̀ dáradára fún iṣẹ́ àyànfúnni rẹ̀. (1 Tím. 4:13; wo ìkẹ́kọ̀ọ́ 6 nínú Iwe-Amọna Ile Ẹkọ.) Àwọn kókó pàtàkì díẹ̀ nìyí fún kíkàwé fún gbogbo ènìyàn lọ́nà tí ó nítumọ̀.

Lo Ìtẹnumọ́ Òye Ọ̀rọ̀ Tí Ó Yẹ: Pinnu ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí ń fẹ́ ìtẹnumọ́ ṣáájú kí o baà lè gbé òye tí ó tọ̀nà yọ.

Pe Àwọn Ọ̀rọ̀ Bí Ó Ti Tọ́: Pípe ọ̀rọ̀ bí ó ti tọ́ àti lọ́nà tí ó ṣe ketekete pọn dandan bí àwùjọ yóò bá lóye àwọn gbólóhùn tí ó wà nínú ìtẹ̀jáde náà. Lo ìwé atúmọ̀ èdè láti wo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ṣàjèjì, tàbí tí a kì í sábàá lò tàbí kí ó tẹ́tí sí àwọn ọ̀rọ̀ tí Society gbá sílẹ̀ sórí kásẹ́ẹ̀tì.

Sọ̀rọ̀ Sókè Kí O Sì Lo Ìtara Ọkàn: Fífi ìtara ọkàn sọ̀rọ̀ sókè ketekete máa ń mú ọkàn ìfẹ́ wá, ó máa ń ru ìmọ̀lára sókè, ó sì máa ń sún ẹni tí ń tẹ́tí sílẹ̀ ṣiṣẹ́.

Jẹ́ Ọlọ́yàyà Kí O Sì Kà Á Bí Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀: Bí ọ̀rọ̀ bá yọ̀ mọ́ni lẹ́nu sísọ̀rọ̀ lọ́nà tí ó rọrùn yóò ṣeé ṣe. Bí òǹkàwé bá múra sílẹ̀ tí ó sì ṣe ìfidánrawò, ara yóò tù ú, èyí yóò sì mú kí ó kàwé lọ́nà tí ó ń fani mọ́ra dípò lílo ohùn kan ṣoṣo kí ó sì súni.—Háb. 2:2.

Ka Àkójọpọ̀ Ọ̀rọ̀ Náà Bí A Ṣe Tẹ̀ Ẹ́: Bí ó ti máa ń rí, àlàyé ẹsẹ̀ ìwé àti ìsọfúnni tí ó wà nínú àkámọ́ ni a máa ń kà sókè ketekete bí wọ́n bá ṣàlàyé ọ̀rọ̀ tí a tẹ̀. Àyàfi kan ṣoṣo tí ó wà níbẹ̀ ni bí ó bá jẹ́ pé ìtọ́kasí tí ó wulẹ̀ ń fi orísun tí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà ti wá hàn ni. A gbọ́dọ̀ ka àlàyé ẹsẹ̀ ìwé níbi tí a bá ti tọ́ka sí i nínú ìpínrọ̀, ní bíbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ nípa sísọ pé: “Àlàyé ẹsẹ̀ ìwé kà pé . . .” Lẹ́yìn kíkà á tán, máa bá kíka ìyókù ìpínrọ̀ náà nìṣó.

Nígbà tí a bá kàwé fún gbogbo ènìyàn lọ́nà tí ó dára, ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà ṣíṣe kókó tí a lè gbà ‘kọ́ àwọn ẹlòmíràn láti máa pa gbogbo ohun tí’ Atóbilọ́lá Olùkọ́ wa ‘ti pa láṣẹ mọ́.’—Mát. 28:20.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́