Ẹ̀KỌ́ 4
Kí Ọ̀rọ̀ Yọ̀ Mọ́ni Lẹ́nu
BÍ O bá ń kàwé sókè, ǹjẹ́ àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ kan máa ń kọ́ ọ lẹ́nu? Tàbí nígbà tó o bá dúró níwájú àwùjọ láti sọ ọ̀rọ̀ tí a yàn fún ọ, ǹjẹ́ o sábà máa ń wá ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ sọ tì? Bó bá ń ṣe ọ́ bẹ́ẹ̀, ìṣòro rẹ lè jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kò yọ̀ mọ́ ọ lẹ́nu. Ńṣe lẹni tí ọ̀rọ̀ bá yọ̀ mọ́ lẹ́nu máa ń kàwé geerege, ọ̀rọ̀ àti èrò rẹ̀ yóò sì máa jáde lọ́nà tó já gaara. Ìyẹn ò túmọ̀ sí pé onítọ̀hún ò ní máa dánu dúró, tàbí pé kí ó kàn máa da ọ̀rọ̀ sílẹ̀ wuuruwu. Kì í sì í ṣe pé kì í ronú kó tó máa sọ̀rọ̀. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa ń lárinrin. Àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀ ni yíyọ̀mọ́nilẹ́nu-ọ̀rọ̀ gbà nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run.
Oríṣiríṣi nǹkan ló lè fa kí ọ̀rọ̀ má yọ̀ mọ́ni lẹ́nu. Èwo nínú àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí ló yẹ kó o fún ní àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀? (1) Nígbà tó o bá ń kàwé sétígbọ̀ọ́ àwọn èèyàn, tí o bá ń bá ọ̀rọ̀ tí o kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ pàdé, ìyẹn lè mú kí o máa dánu dúró. (2) Dídánudúró níhìn-ín lọ́hùn-ún lè mú kó o máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ń dákú-dájí. (3) Àìmúrasílẹ̀ lè dá kún ìṣòro yẹn. (4) Lára ohun tí kì í sábà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yọ̀ mọ́ni lẹ́nu níwájú àwùjọ ni àìto àwọn kókó ọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ. (5) Àìní àkójọ ọ̀rọ̀ púpọ̀ lágbárí lè mú kí èèyàn máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ń dákú-dájí nítorí pé ó máa ń wá ọ̀rọ̀ tó bá ohun tó fẹ́ sọ mu tì. (6) Bó bá di pé ọ̀rọ̀ téèyàn ń tẹnu mọ́ ti pọ̀ jù, ìyẹn lè ṣàìjẹ́ kí ọ̀rọ̀ yọ̀ mọ́ni lẹ́nu. (7) Àìmọ òfin ẹ̀hun èdè tó bẹ́ẹ̀ lè dá kún ìṣòro yẹn.
Bí ọ̀rọ̀ ò bá yọ̀ mọ́ ọ lẹ́nu, àwùjọ inú Gbọ̀ngàn Ìjọba lè má dìde lọ o, àmọ́ wọn ò ní fọkàn sí ọ̀rọ̀ rẹ, nǹkan ọ̀tọ̀ pátápátá gbáà ni wọn ó sì máa rò. Nípa bẹ́ẹ̀, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ ni kò ní wọ̀ wọ́n létí.
Ṣùgbọ́n o, a ní láti ṣọ́ra kí ọ̀rọ̀ tó yẹ kó tani jí kí ó sì yọ̀ mọ́ni lẹ́nu má lọ di èyí tí à ń pariwo sọ bóyá lọ́nà tó tiẹ̀ ń dá àwùjọ lágara pàápàá. Tó bá di pé àwọn èèyàn ń ka ọ̀nà tó o gbà ń sọ̀rọ̀ sí ti ẹni tí kò kani kún tàbí sí ti ẹni tí kò fi òótọ́ inú sọ̀rọ̀, ìyẹn yóò tako ète tí o fi ń sọ̀rọ̀, nítorí pé báyìí là ń ṣe nílẹ̀ wa, èèwọ̀ ni nílẹ̀ ibòmíràn. Ó yẹ ká rántí pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé olùbánisọ̀rọ̀ tó ní ìrírí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, síbẹ̀ “nínú àìlera àti nínú ìbẹ̀rù àti pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìwárìrì” ló ti bá àwọn ará Kọ́ríńtì sọ̀rọ̀ kí ó má bàa di pé ó ń pàfiyèsí tí kò yẹ sí ara rẹ̀.—1 Kọ́r. 2:3.
Àwọn Àṣà Tó Yẹ Ká Yẹra Fún. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ní àṣà kí wọ́n máa ṣe “ẹn-in, ẹn-in” nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀. Ó ti mọ́ àwọn mìíràn lára pé bí wọ́n bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀, wọ́n á kọ́kọ́ sọ pé “nísinsìnyí,” tàbí kí wọ́n máa fi ọ̀rọ̀ bí “ṣẹ́ ẹ mọ̀” tàbí “ẹ ẹ̀ rí nǹkan,” há gbogbo ọ̀rọ̀ yòówù kí wọ́n máa sọ. Bóyá o lè má mọ bí o ṣe ń lo irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lemọ́lemọ́ tó. O lè dán ara rẹ wò, kí o ní kí ẹnì kan tẹ́tí sí ọ, kí ó sì máa tún gbólóhùn wọ̀nyẹn sọ nígbàkigbà tó o bá ti lò ó nínú ọ̀rọ̀ rẹ. Àbájáde rẹ̀ lè yà ọ́ lẹ́nu.
Àwọn èèyàn kan máa ń kàwé, wọn sì máa ń sọ̀rọ̀ ní àsọpadàsẹ́yìn. Ìyẹn ni pé, bí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀, wọ́n á dánu dúró lágbedeméjì ọ̀rọ̀ wọn, wọ́n á tún wá padà sọ díẹ̀, ó kéré tán, lára ohun tí wọ́n ti sọ tẹ́lẹ̀.
Àwọn mìíràn sì wà tó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tiwọn máa ń já geere, ṣùgbọ́n bí wọ́n bá ń bá ọ̀rọ̀ kan bọ̀, wọ́n á tún ta mọ́ ọ̀rọ̀ mìíràn lágbedeméjì ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń bá bọ̀. Òótọ́ ni pé ọ̀rọ̀ wọn máa ń já geere, àmọ́ bí wọ́n ṣe ń yí èrò padà lójijì máa ń ṣèdíwọ́ fún yíyọ̀ tó yẹ kí ọ̀rọ̀ máa yọ̀ mọ́ wọn lẹ́nu.
Bí O Ṣe Lè Ṣàtúnṣe. Bí ìṣòro rẹ bá jẹ́ pé o máa ń wá ọ̀rọ̀ tó yẹ kó o lò tì, ńṣe ló yẹ kí o sapá gidigidi láti mọ àkójọ ọ̀rọ̀ púpọ̀ sí i. Túbọ̀ máa fojú ṣọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí o kò bá fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nínú Ilé Ìṣọ́, Jí!, tàbí àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn tó o bá ń kà. Yẹ̀ wọ́n wò nínú ìwé atúmọ̀ èdè, wo bí wọ́n ṣe ń pè wọ́n, àti ìtumọ̀ wọn, wá mú lára wọn kún àkójọ ọ̀rọ̀ tó o ti mọ̀ sórí. Bí kò bá sí ìwé atúmọ̀ èdè lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ, bẹ ẹnì kan tó bá mọ èdè náà sọ dáadáa pé kó ràn ọ́ lọ́wọ́.
Tí o bá sọ ọ́ dàṣà láti máa kàwé sókè déédéé, ìyẹn á jẹ́ kó o túbọ̀ ṣe dáadáa sí i. Máa ṣàkíyèsí ọ̀rọ̀ tó bá ṣòro fún ọ, kí o sì pè é sókè lọ́pọ̀ ìgbà.
Kí ìwé kíkà lè yọ̀ mọ́ ọ lẹ́nu, ó yẹ kó o mọ bí ọ̀rọ̀ inú gbólóhùn ṣe máa ń bá ara wọn rìn pọ̀. Ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ ni a sábà máa ń kà pa pọ̀ láti lè gbé èrò òǹkọ̀wé jáde bó ṣe yẹ. Fún ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní àfiyèsí pàtàkì. Bí ó bá jẹ́ pé sísàmì sí wọn ni yóò ràn ọ́ lọ́wọ́, sàmì sí wọn. Kì í ṣe nítorí kí o ṣáà ti pe ọ̀rọ̀ bó ṣe tọ́ nìkan lo fi ń kàwé bí kò ṣe pé kí o tún gbé èrò ibẹ̀ jáde kedere. Lẹ́yìn tí o bá ti ṣàyẹ̀wò gbólóhùn ọ̀rọ̀ kan tán, bọ́ sí òmíràn, kí o sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ lọ títí tí wàá fi parí àyẹ̀wò ìpínrọ̀ kan délẹ̀. Mọ bí èrò ibẹ̀ ṣe so mọ́ra wọn. Lẹ́yìn náà, wá fi ìwé kíkà sókè dánra wò. Ka ìpínrọ̀ yẹn léraléra títí tí wàá fi lè kà á láìkọsẹ̀ àti láìdánudúró níbi tí kò tọ́. Lẹ́yìn náà kí o bọ́ sí àwọn ìpínrọ̀ yòókù.
Èyí tó kàn ni pé kó o wá fi kún bí o ṣe ń yára kàwé. Bí o bá ti ní òye bí ọ̀rọ̀ inú gbólóhùn ṣe máa ń bá ara wọn rìn pọ̀, wàá lè máa rí ju ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo lọ lẹ́ẹ̀kan, wàá sì tún lè máa fọkàn ro ohun tó yẹ kó tẹ̀ lé e. Èyí á jẹ́ kó o túbọ̀ lè kàwé lọ́nà tó mọ́yán lórí.
Fífi kọ́ra láti máa kàwé geerege ní gbàrà tó o bá kọ́kọ́ fojú kàn án, jẹ́ ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó ṣeyebíye. Bí àpẹẹrẹ, láìmúratẹ́lẹ̀ rárá, ka ẹsẹ ojoojúmọ́ tòní àti àlàyé rẹ̀ sókè; máa ka ẹsẹ ojoojúmọ́ sókè bẹ́ẹ̀ déédéé. Jẹ́ kó mọ́ ọ lára láti máa fi ojú kó ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ tó ń gbé èrò kọ̀ọ̀kan jáde pọ̀ dípò tí wàá fi máa wo ọ̀rọ̀ lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan.
Kí ọ̀rọ̀ lè yọ̀ mọ́ ọ lẹ́nu nígbà ìfọ̀rọ̀wérọ̀, máa ronú kó o tó sọ̀rọ̀. Máa ṣe bẹ́ẹ̀ déédéé nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tó o bá ń sọ lójoojúmọ́. Kọ́kọ́ pinnu ohun tó o fẹ́ sọ ná àti bí o ṣe máa sọ wọ́n tẹ̀ léra wọn; lẹ́yìn náà kó o wá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀. Má kàn ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ lọ gbuurugbu. Gbìyànjú láti máa sọ èrò kọ̀ọ̀kan délẹ̀ láìdánudúró, kí o má sì ta mọ́ èrò mìíràn lágbedeméjì ọ̀rọ̀. Bí o bá ń lo àwọn gbólóhùn kéékèèké, ìyẹn lè ràn ọ́ lọ́wọ́.
Ńṣe ló yẹ kí ọ̀rọ̀ máa wá sí ọ lẹ́nu wẹ́rẹ́ bí o bá mọ ohun tó o fẹ́ sọ gan-an. Ní pàtàkì, kò fi bẹ́ẹ̀ sídìí láti máa yan ọ̀rọ̀ pàtó tó o máa lò nínú ọ̀rọ̀ sísọ. Kódà, ká ní o fẹ́ ṣe ìdánrawò, ohun tó ti dára jù ni pé kí o kàn jẹ́ kí ohun tó o fẹ́ sọ ṣe kedere lọ́kàn rẹ, kí o wá máa ro ọ̀rọ̀ tó o máa fi gbé e jáde bí o ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ. Bí o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, tí o sì ń fọkàn sí èrò tó wà lọ́kàn rẹ dípò ríronú lórí irú ọ̀rọ̀ pàtó tó ń jáde lẹ́nu rẹ, ńṣe lọ̀rọ̀ tó o máa sọ á kàn máa wá sí ọ lẹ́nu, wàá sì lè máa sọ èrò inú rẹ jáde bó ṣe rí lọ́kàn rẹ gan-an. Ṣùgbọ́n tó bá ti di pé ọ̀rọ̀ tó o máa lò ní pàtó lò ń rò dípò fífọkàn sí èrò tó o fẹ́ gbé yọ, wàá máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ń dákú-dájí. Bí o bá fi kọ́ra, ó dájú pé wàá lè dẹni tí ọ̀rọ̀ yọ̀ mọ́ lẹ́nu, èyí tí í ṣe ànímọ́ pàtàkì fún sísọ̀rọ̀ àti kíkàwé lọ́nà tó múná dóko.
Nígbà tí Jèhófà yan Mósè pé kó lọ ṣojú òun lọ́dọ̀ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àti níwájú Fáráò ilẹ̀ Íjíbítì, ńṣe ni Mósè ka ara rẹ̀ sí ẹni tí kò kúnjú òṣùwọ̀n. Kí nìdí rẹ̀? Ìdí ni pé kì í ṣe ẹni tí ọ̀rọ̀ yọ̀ mọ́ lẹ́nu; bóyá ó ní ìṣòro ọ̀rọ̀ sísọ. (Ẹ́kís. 4:10; 6:12) Mósè ṣàwáwí lóríṣiríṣi, àmọ́ Ọlọ́run ò gba èyíkéyìí lára rẹ̀ wọlé. Jèhófà ní kí Áárónì lọ máa bá a gbọ̀rọ̀ sọ, àmọ́ Ó ran Mósè lọ́wọ́ láti dẹni tó ń fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀. Kódà, yàtọ̀ sí pé Mósè bá ẹnì kọ̀ọ̀kan àti àwùjọ kéékèèké sọ̀rọ̀, ó tún bá odindi orílẹ̀-èdè sọ̀rọ̀ léraléra lọ́nà tó múná dóko. (Diu. 1:1-3; 5:1; 29:2; 31:1, 2, 30; 33:1) Bí o bá ń sa ipá tìrẹ lójú méjèèjì láti lè dẹni tí ọ̀rọ̀ sísọ yọ̀ mọ́ lẹ́nu tí o sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ìwọ náà yóò lè fi ọ̀rọ̀ sísọ tìrẹ bọlá fún Ọlọ́run.