Ẹ̀KỌ́ 14
Sọ̀rọ̀ Bí Ọlọ́run Ṣe Dá Ọ
TÓ O bá ń sọ̀rọ̀ bí Ọlọ́run ṣe dá ọ, ọ̀rọ̀ rẹ á fi ọkàn àwọn èèyàn balẹ̀. Ṣé wàá ní ìgbọ́kànlé nínú ọ̀rọ̀ tí ẹni tó fi nǹkan bojú bá sọ? Ṣé tí ohun tí ẹni yẹn fi bojú bá lẹ́wà ju ojú onítọ̀hún fúnra rẹ̀, wàá tìtorí ìyẹn ní ìgbọ́kànlé nínú ohun tó ń sọ? Kò dájú pé wàá ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, dípò tí wàá fi lọ máa sín bí ẹlòmíràn ṣe ń sọ̀rọ̀ jẹ, sọ̀rọ̀ bí ìwọ fúnra rẹ ṣe máa ń sọ̀rọ̀ gan-gan.
Sísọ̀rọ̀ bí Ọlọ́run ṣe dáni yàtọ̀ sí sísọ̀rọ̀ lọ́nà àìbìkítà o. Sísọ̀rọ̀ wúruwùru láìtẹ̀lé ìlànà ẹ̀hun gbólóhùn, ṣíṣi ọ̀rọ̀ pè, àti ríránu sọ̀rọ̀ kò dára. O tún gbọ́dọ̀ yẹra fún lílo èdè aṣa. Gbogbo ìgbà la gbọ́dọ̀ sapá láti rí i pé ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa wuyì. Ẹni tó bá ń sọ̀rọ̀ bí Ọlọ́run ṣe dá a kì í yá ọ̀nà ìgbàsọ̀rọ̀ tó jẹ́ àṣerégèé lò bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣàníyàn púpọ̀ jù nípa bí òun yóò ṣe gbayì lójú àwọn ẹlòmíràn.
Lóde Ẹ̀rí. Nígbà tí o bá dé ilé kan tàbí nígbà tí o bá tọ ẹnì kan lọ ní gbangba láti wàásù, ṣé àyà rẹ máa ń kọ́kọ́ là gààrà? Ọ̀pọ̀ nínú wa ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí, ṣùgbọ́n ti àwọn kan máa ń pọ̀ ju tàwọn mìíràn lọ. Ìjayà lè mú kí ohùn ẹni há tàbí kí ó máa gbọ̀n, tàbí kẹ̀ àyà jíjá lè mú kéèyàn máa gbé ọwọ́ tàbí kó máa mi orí lódì-lódì.
Onírúurú ìdí ló lè mú kí akéde kan ní irú ìṣòro yìí. Bóyá ńṣe ló ń ronú nípa èrò tí àwọn èèyàn máa ní nípa òun tàbí kó máa ṣiyè méjì bóyá òun á lè sọ̀rọ̀ yẹn bó ṣe yẹ. Kò sóhun tó burú nínú èyíkéyìí lára rẹ̀, àmọ́ ìgbà tí a bá kó irú nǹkan wọ̀nyẹn lé ọkàn púpọ̀ jù ló máa ń di ìṣòro. Bí àyà rẹ bá ń là gààrà kí o tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní pápá, kí ló lè ṣèrànwọ́? Fífarabalẹ̀ múra sílẹ̀ àti gbígbàdúrà kíkankíkan sí Jèhófà ni. (Ìṣe 4:29) Ronú nípa àánú ńláǹlà tí Jèhófà ní tó fi ń ké sí àwọn èèyàn pé kí wọ́n wá gbádùn ìlera pípé àti ìyè ayérayé nínú Párádísè. Ronú nípa àwọn tí ò ń ṣakitiyan láti ràn lọ́wọ́ àti bó ti yẹ kí wọ́n gbọ́ nípa ìhìn rere.
Tún rántí pé àwọn èèyàn lómìnira láti yan ohun tó wù wọ́n, nítorí náà wọ́n lè tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ tó o fẹ́ jẹ́, wọ́n sì lè ṣàìtẹ́wọ́ gbà á. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ rí nígbà tí Jésù wàásù ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́. Iṣẹ́ tìrẹ ni pé kí o ṣáà ti wàásù. (Mát. 24:14) Kódà nígbà táwọn èèyàn kò bá jẹ́ kí o sọ̀rọ̀ pàápàá, rírí tí wọ́n rí ọ á jẹ́ ẹ̀rí fún wọn. O ti ṣàṣeyọrí nìyẹn nítorí pé o jẹ́ kí Jèhófà lò ọ́ láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Láwọn ìgbà tó o bá wá ní àǹfààní láti sọ̀rọ̀ ńkọ́, ọ̀nà wo lo máa gbà sọ̀rọ̀? Bó o bá jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ dá lórí ohun tó jẹ àwọn èèyàn lógún, ohun tí ò ń sọ á fani mọ́ra, wàá sì sọ ọ́ bí o ṣe máa ń sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́.
Nígbà tí o bá ń wàásù, bí ìṣe rẹ àti ọ̀nà tó o gbà ń sọ̀rọ̀ bá jẹ́ bí o ṣe máa ń ṣe lójoojúmọ́, yóò jẹ́ kí ara tu àwọn tí ń tẹ́tí sí ọ. Wọ́n tilẹ̀ lè túbọ̀ tẹ́tí sí ohun tí o fẹ́ sọ fún wọn látinú Ìwé Mímọ́. Dípò tí wàá fi máa sọ̀rọ̀ lọ láìjẹ́ kí wọ́n dá sọ́rọ̀ náà, ńṣe ni kí o bá wọn fọ̀rọ̀ wérọ̀. Ṣọ̀yàyà sí wọn. Fi ìfẹ́ hàn sí wọn, kí o sì jẹ́ kí wọ́n dá sí ọ̀rọ̀ yẹn. Àmọ́ ṣá o, níbi tí èdè tàbí àṣà àdúgbò náà bá ti ní àwọn ìlànà bíbọ̀wọ̀ fún ẹni tí a kò mọ̀ rí nígbà tí a bá ń bá wọn sọ̀rọ̀, yóò dára kí o pa ìlànà yẹn mọ́. Ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ẹ̀rín músẹ́ jìnnà sí ẹnu rẹ.
Ní Orí Pèpéle. Nígbà tí o bá ń bá àwùjọ kan sọ̀rọ̀, ohun tó dára jù lọ ni pé kí o sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ò ń gbà sọ̀rọ̀, bí ìgbà tí èèyàn bá ń báni fọ̀rọ̀ wérọ̀. Àmọ́ ṣá o, nígbà tí àwùjọ bá tóbi, ó yẹ kí o túbọ̀ gbóhùn sókè. Bí o bá gbìyànjú láti há ọ̀rọ̀ rẹ sórí tàbí tí o kọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ sílẹ̀, á jẹ́ pé o ti ń ṣàníyàn jù nípa ọ̀rọ̀ pàtó tó o fẹ́ lò. Ó ṣe pàtàkì pé kí èèyàn lo ọ̀rọ̀ tó yẹ, ṣùgbọ́n bí ìyẹn bá gbàfiyèsí ẹni jù, onítọ̀hún á máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ pè, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ní dán mọ́rán, kò sì ní lè sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa ń gbà sọ̀rọ̀. Ó yẹ kí o fara balẹ̀ ronú ṣáájú lórí ohun tí o fẹ́ sọ, ṣùgbọ́n èrò tí o fẹ́ gbé jáde ni kí o fún ní àfiyèsí jù lọ kì í ṣe ọ̀rọ̀ pàtó tí o máa lò.
Bákan náà lọ̀ràn ṣe rí nígbà tí wọ́n bá ń fọ̀rọ̀ wá ọ lẹ́nu wò ní ìpàdé. Múra sílẹ̀ dáadáa, ṣùgbọ́n má ṣe ka àwọn ìdáhùn rẹ, má sì há wọn sórí. Ohùn ara rẹ gan-an ni kí o lò kí ìdáhùn rẹ lè jẹ́ látọkànwá.
Kódà, bí èèyàn bá ṣàṣejù nínú àwọn ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ tó dára, àwùjọ lè kà á sí pé ńṣe lonítọ̀hún ń ṣakọ. Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ kí o sọ̀rọ̀ ketekete kí o sì pe ọ̀rọ̀ bí ó ṣe yẹ, ṣùgbọ́n kì í ṣe pé kí o wá máa yun ẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ tàbí kí o máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ pè ṣáá bí o ṣe ń sọ̀rọ̀. Bí èèyàn bá ń fi ìtẹnumọ́ ọ̀rọ̀ ṣàpèjúwe tàbí tí ó ń fi ara ṣàpèjúwe, tó sì ṣe é dáadáa, ó lè mú kí ọ̀rọ̀ rẹ tani jí, ṣùgbọ́n bí àṣejù bá ti wọ ìfaraṣàpèjúwe, ńṣe ló máa tàbùkù ohun tí onítọ̀hún ń sọ. Gbóhùn sókè dáadáa, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ó pọ̀ jù. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó yẹ kí o máa fi ìtara sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n yẹra fún àṣerégèé. Lo ìròkèrodò ohùn, ìtara, àti fífi bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára hàn lọ́nà tí kì yóò fi pe àfiyèsí sí ọ tí kì yóò sì dá àwùjọ lágara.
Àwọn kan wà tó jẹ́ pé, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá tiwọn, ńṣe ni wọ́n máa ń ṣọ́ ọ̀rọ̀ pè láìtiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń sọ̀rọ̀ níwájú àwùjọ pàápàá. Àwọn míì sì wà tó jẹ́ pé bí ìgbà tí èèyàn ń fọ̀rọ̀ wérọ̀ ni wọ́n ṣe máa ń sọ̀rọ̀. Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé kí o máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tó dára lójoojúmọ́ kí o sì máa hu ìwà tó yẹ Kristẹni. Nígbà náà, tí o bá wà lórí pèpéle, yóò túbọ̀ rọrùn fún ọ láti máa sọ̀rọ̀ kí o sì máa fara ṣàpèjúwe lọ́nà fífanimọ́ra, bí Ọlọ́run ṣe dá ọ.
Nígbà Tó O Bá Ń Kàwé fún Àwùjọ. Kíkàwé fún àwùjọ lọ́nà tí èèyàn ń gbà sọ̀rọ̀ gba ìsapá. Láti lè ṣe é, dá àwọn èrò pàtàkì inú ibi tí o fẹ́ kà mọ̀, kí o sì kíyè sí bí wọ́n ṣe ṣàlàyé wọn. Jẹ́ kí èrò wọ̀nyẹn ṣe kedere lọ́kàn rẹ; àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wàá kàn máa pe ọ̀rọ̀ sókè lásán. Ṣàyẹ̀wò bí wọ́n ṣe ń pe àwọn ọ̀rọ̀ tí o kò mọ̀ tẹ́lẹ̀. Fi kíkà á sókè dánra wò kí o lè mọ bó ṣe yẹ láti gbóhùn sókè sódò àti bí wàá ṣe ka àwọn ọ̀rọ̀ pa pọ̀ lọ́nà tí yóò fi gbé èrò ibẹ̀ jáde lọ́nà tó ṣe kedere. Ṣe bẹ́ẹ̀ léraléra títí wàá fi lè kà á lọ́nà tó yọ̀ mọ́ ọ lẹ́nu. Rí i pé o mọ ibi tí ò ń kà dunjú débi pé nígbà tí o bá ń kà á sókè, ńṣe ni yóò dà bí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ alárinrin. Béèyàn ṣe máa ń kàwé lọ́nà tó gbà ń sọ̀rọ̀ nìyẹn.
Ó dájú pé inú àwọn ìtẹ̀jáde wa tá a gbé karí Bíbélì ni ọ̀pọ̀ jù lọ ohun tí a máa ń kà fún àwùjọ ti ń wá. Yàtọ̀ sí iṣẹ́ ìwé kíkà tí a máa ń yàn fún wa ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, a tún máa ń ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ lóde ẹ̀rí àti nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ látorí pèpéle. A máa ń yanṣẹ́ fún àwọn arákùnrin láti ka ibi tí à ń gbé yẹ̀ wò nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ àti ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Àwọn arákùnrin kan tó tóótun máa ń gba iṣẹ́ láti ka ìwé níwájú àwùjọ ní àpéjọ. Yálà Bíbélì lò ń kà ni o tàbí àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn, bí o bá fẹ́ ka apá ibi tó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n fa ọ̀rọ̀ yọ láti ibì kan, kà á lọ́nà tí yóò fi tani jí. Bí wọ́n bá dárúkọ àwọn èèyàn mélòó kan, yí ohùn rẹ padà díẹ̀ bí o bá ṣe ń pe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Ohun kan tí wàá wá ṣọ́ra fún nìyí o: Má ṣe jẹ́ kí bí o ṣe ń kà á pe àfiyèsí tí kò yẹ, ṣùgbọ́n jẹ́ kí ó tani jí bó ṣe yẹ.
Béèyàn bá kàwé lọ́nà tó gbà ń sọ̀rọ̀ ńṣe ló máa ń dà bíi pé onítọ̀hún ń fọ̀rọ̀ wérọ̀. Kò ní dún bíi pé èèyàn ń ṣọ́ ọ̀rọ̀ pè lọ́kọ̀ọ̀kan, ṣùgbọ́n yóò kà á gẹ́gẹ́ bí ohun tó dá a lójú.