Ẹ̀KỌ́ 28
Sísọ̀rọ̀ Bí Ẹní Ń Báni Fọ̀rọ̀ Wérọ̀
NÍ GBOGBO gbòò, àwọn èèyàn sábà máa ń túra ká sọ̀rọ̀ fàlàlà bí wọ́n bá ń bá ọ̀rẹ́ wọn fọ̀rọ̀ wérọ̀. Wẹ́rẹ́ lọ̀rọ̀ kàn máa ń wá sí wọn lẹ́nu láti fi sọ èrò wọn. Àwọn èèyàn kan máa ń fi ìtara sọ̀rọ̀; àwọn mìíràn a máa sọ̀rọ̀ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́. Àmọ́ sísọ tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tí wọ́n ń gbà sọ̀rọ̀ déédéé máa ń fani mọ́ra.
Ṣùgbọ́n, bí o bá fẹ́ bá ẹni tó ò mọ̀ rí sọ̀rọ̀, kò ní dára pé kí o dédé nawọ́ àwàdà sí i tàbí kí o fi gbogbo ẹnu sọ̀rọ̀ láìṣẹ́nupo. Kódà, ní àwọn ilẹ̀ kan, bí wọ́n bá máa bá àjèjì èyíkéyìí sọ̀rọ̀, àṣà wọn ni pé kí wọ́n kọ́kọ́ ṣọ́ ọ̀rọ̀ lò dáadáa ná. Bí wọ́n bá sì ti wá kí onítọ̀hún tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ tán, ìṣarasíhùwà onítọ̀hún yóò jẹ́ kí wọ́n mọ̀ bóyá kí àwọn túra ká bá a sọ̀rọ̀.
Nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀ lórí pèpéle, o ní láti kíyè sára pẹ̀lú. Bí o bá ń sọ̀rọ̀ lórí pèpéle bí ẹni tó ń báni tàkúrọ̀sọ, ìyẹn yóò bu iyì ìpàdé Kristẹni àti ọwọ́ pàtàkì tó yẹ ká fi mú ohun tí ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí kù. Nínú àwọn èdè kan, wọ́n ní àwọn gbólóhùn kan tó jẹ́ èdè ọ̀wọ̀ tí wọ́n máa ń lò fún ẹni tó dàgbà juni lọ, fún olùkọ́, fún ẹni tó wà nípò àṣẹ, tàbí fún òbí kan. (Kíyè sí àwọn gbólóhùn tí a lò nínú Ìṣe 7:2 àti 13:16.) Ọ̀tọ̀ sì ni gbólóhùn tí àwọn tọkọtaya tàbí àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ jọ máa ń lò fún ara wọn bí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a kò ní máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ lò púpọ̀ jù tí a bá wà lórí pèpéle, síbẹ̀ ó yẹ ká máa lo ọ̀rọ̀ tó buyì kúnni.
Ṣùgbọ́n àwọn nǹkan kan wà tó máa ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹni le kankan létí tàbí tí á jẹ́ kó dà bí ẹni pé a ń kà á láti inú ìwé. Ọ̀kan nínú nǹkan wọ̀nyí ni ọ̀nà tí a gba ń sọ gbólóhùn tàbí àpólà ọ̀rọ̀. Bó bá di pé olùbánisọ̀rọ̀ ń gbìyànjú láti máa sọ gbólóhùn ọ̀rọ̀ jáde bí ó ṣe wà nínú ìwé gẹ́lẹ́, kò ní ṣàìko ìṣòro yìí. Ọ̀nà tí a máa ń gba kọ ọ̀rọ̀ sílẹ̀ sábà máa ń yàtọ̀ pátápátá sí bí a ṣe ń sọ̀rọ̀. Lóòótọ́, ohun tó wà nínú ìwé lo máa kà láti fi múra ọ̀rọ̀ tí o fẹ́ sọ. Ó tiẹ̀ lè jẹ́ pé ìwé àsọyé tí a tẹ̀ jáde lo máa gbé ọ̀rọ̀ náà kà. Ṣùgbọ́n tó o bá ń tún ọ̀rọ̀ inú ìwé sọ gẹ́lẹ́ bí wọ́n ṣe kọ ọ́ síbẹ̀ tàbí tí ò ń kà á jáde látinú ìwé àsọyé tí a tẹ̀, kò dájú pé ọ̀rọ̀ rẹ á dún bí ìfọ̀rọ̀wérọ̀. Láti lè sọ̀rọ̀ bí ẹní ń fọ̀rọ̀ wérọ̀, ọ̀rọ̀ ara rẹ ni kí o fi sọ èrò inú ìwé náà, kí o sì yàgò fún sísọ àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ lọ́nà tó lọ́jú pọ̀.
Kókó mìíràn ni yíyí ìwọ̀n ìyárasọ̀rọ̀ padà bí o ṣe ń sọ̀rọ̀. Ọ̀rọ̀ tó le kankan tí a sì ń sọ bí ẹní kàwé sábà máa ń yá kánkán, àwọn gbólóhùn rẹ̀ a sì máa dún bákan náà tẹ̀ léra. Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ wa ojoojúmọ́, ìwọ̀n ìyárasọ̀rọ̀ wa kì í rí bákan náà jálẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ wa, a sì tún máa ń dánu dúró látìgbàdégbà ní ìwọ̀n tó gùn ju ara wọn lọ.
Àmọ́ ṣá o, bí o bá ń bá àwùjọ ńlá sọ̀rọ̀, láti lè mú kí wọ́n máa fọkàn bá ọ lọ bí o ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́nà ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ńṣe ni kí o gbóhùn sókè, kí ohùn rẹ máa dún ketekete, kí o sì túbọ̀ fi ìtara sọ̀rọ̀.
Láti lè sọ̀rọ̀ bí ẹní ń báni fọ̀rọ̀ wérọ̀ bó ṣe yẹ lóde ẹ̀rí, ńṣe ni kí o jẹ́ kó mọ́ ọ lára láti máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tó dára lójoojúmọ́. Èyí kò sọ ọ́ di dandan pé o ní láti kàwé rẹpẹtẹ. Ṣùgbọ́n ó dára kí o jẹ́ kí ó mọ́ ọ lára láti máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tí àwọn èèyàn yóò fi máa fẹ́ fara balẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ. Ìyẹn ni yóò fi dára pé kí o wò ó bóyá wàá ní láti ṣiṣẹ́ lórí àwọn kókó tó wà nísàlẹ̀ yìí nínú ọ̀rọ̀ sísọ rẹ ojoojúmọ́.
Yẹra fún sísọ̀rọ̀ lọ́nà tí kò bá ọ̀nà ìgbàsọ̀rọ̀ tó dára mu, tàbí sísọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa jẹ́ kí àwọn èèyàn kà ọ́ mọ́ ara àwọn oníwàkiwà. Yẹra pátápátá fún àwọn èdè aṣa àti ọ̀rọ̀ àsé sísọ gẹ́gẹ́ bí Kólósè 3:8 ṣe gbani níyànjú pé kí á ṣe. Àmọ́, kò sóhun tó burú tí a bá sọ̀rọ̀ lọ́nà tó bá bí àwọn èèyàn ṣe máa ń sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́ láwùjọ mu. Bí a ṣe máa ń sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́ láwùjọ lè máà bá èdè ìwé mu, ṣùgbọ́n wọ́n bá ọ̀nà ìgbàsọ̀rọ̀ tó ṣètẹ́wọ́gbà mu.
Yẹra fún lílo gbólóhùn tàbí ọ̀rọ̀ kan náà léraléra láti máa fi sọ gbogbo onírúurú èrò tí o bá fẹ́ sọ. Kọ́ bí wàá ṣe lè máa lo ọ̀rọ̀ tó sọ èrò ọkàn rẹ ní kedere.
Yẹra fún sísọ ọ̀rọ̀ ní àsọpadàsẹ́yìn láìnídìí. Ńṣe ni kí o jẹ́ kí ohun tó o fẹ́ sọ kọ́kọ́ ṣe kedere lọ́kàn rẹ ná; lẹ́yìn náà, kí o ṣẹ̀ṣẹ̀ wá gbẹ́nu lé ọ̀rọ̀ rẹ.
Yẹra fún fífi ọ̀rọ̀ púpọ̀ ṣàlàyé nǹkan nítorí ó máa ń bo kókó pàtàkì ọ̀rọ̀ mọ́lẹ̀. Jẹ́ kí o mọ́ ọ lára láti máa fi gbólóhùn ọ̀rọ̀ ṣókí ṣàlàyé kókó tó yẹ kí àwọn èèyàn rántí.
Sọ̀rọ̀ lọ́nà tó buyì kún àwọn ẹlòmíràn.