ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 11/22 ojú ìwé 24-27
  • Lílóye Ìbẹ̀rù Kíkólòlò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lílóye Ìbẹ̀rù Kíkólòlò
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ipò Tí Ó Lè Fa Ìbẹ̀rù
  • Tí A Bá Ń Gbìyànjú Láti Ṣèrànwọ́
  • Mímú Ìnira Wọn Dẹrùn
  • Ó Yé Ẹlẹ́dàá Wa
  • Ohun Téèyàn Lè Ṣe Tó Bá Ń Kólòlò
    Jí!—2010
  • Bí Mo Ṣe Kojú Ìkólòlò
    Jí!—1998
  • Láti Ọwọ́ Òǹkàwé Wa
    Jí!—1998
  • Kò Kólòlò Mọ́!
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 11/22 ojú ìwé 24-27

Lílóye Ìbẹ̀rù Kíkólòlò

O HA lè mọ ìyàtọ̀ láàárín olùbánisọ̀rọ̀ kan tí ọ̀rọ̀ yọ̀ mọ́ lẹ́nu àti ọ̀kan tí ń bẹ̀rù kíkólòlò? O lè dáhùn pé, ‘Kínla, bẹ́ẹ̀ ni.’ Ṣùgbọ́n ronú nípa ohun tí Peter Louw kọ nínú ìwé rẹ̀ tí ó kọ lédè Afrikaans náà, Hhhakkel (Ssstutter) pé: “Lára gbogbo àwọn akólòlò ‘tí kò lè fi bò,’ ó ṣeé ṣe kí àwọn mẹ́wàá lára wọn máà fẹ́ kí a mọ̀ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó, kí wọ́n sì máa lo onírúurú ọ̀nà láti fi àbùkù ọ̀rọ̀ sísọ wọn pa mọ́.” Kí wọ́n máa fi àbùkù ọ̀rọ̀ sísọ wọn pa mọ́ kẹ́? Báwo ni ìyẹn ṣe lè ṣeé ṣe?

Àwọn akólòlò kan máa ń rọ́nà gbé e gbà láti fi àbùkù ọ̀rọ̀ sísọ wọn pa mọ́ nípa ríronú ṣáájú nípa àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ti fún wọn ní ìṣòro nígbà kan rí. Nígbà náà, dípò sísọ ọ̀rọ̀ yẹn, wọn óò tún gbólóhùn náà tò tàbí kí wọ́n lo ọ̀rọ̀ míràn tí ó ní ìtumọ̀ kan náà. Ọkọ kan fi ìṣòro kíkólòlò rẹ̀ pa mọ́ fún ọdún 19 àkọ́kọ́ nínú ìgbéyàwó rẹ̀. Nígbà tí ìyàwó rẹ̀ mọ̀, ó béèrè lọ́wọ́ olùtọ́jú àbùkù ọ̀rọ̀ sísọ kan pé: “Ṣe o rò pé òun ló fà á tí ó fi ń ní kí n máa ṣe ìkésíni orí tẹlifóònù, tí ó sì ń fìgbà gbogbo jẹ́ èmi ni mo máa ń béèrè fún oúnjẹ ní àwọn ilé àrójẹ, tí kì í sì í sọ̀rọ̀ ní . . . àwọn ìpàdé?”

Tún ṣàgbéyẹ̀wò Gerard àti Maria, àwọn tọkọtaya kan ní Gúúsù Áfíríkà, tí wọ́n láyọ̀ nínú ìgbéyàwó wọn.a Lọ́pọ̀ ìgbà, Maria gbìyànjú láti ṣàlàyé fún ọkọ rẹ̀ pé òun kì í fẹ́ láti sọ̀rọ̀ níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nítorí ìbẹ̀rù kíkólòlò. Ọkọ rẹ̀ yóò fi agídí sọ pé: “Ọ̀rọ̀ játijàti, o kì í ṣe akólòlò.” Gerard gbé èrò rẹ̀ karí pé ìyàwó rẹ̀ sábà máa ń sọ̀rọ̀ láìdábọ̀. Kìkì àwọn ipò àyíká tí a ti máa ń sọ̀rọ̀ kan ní pàtó ní ń mú kí ó máa bẹ̀rù kíkólòlò. Fún ìgbà àkọ́kọ́, lẹ́yìn ọdún márùn-ún tí wọ́n ti ṣègbéyàwó, Gerard wá mọ èyí, ó sì jẹ́wọ́ pé: “N kò kà á sí, n kò sì jẹ́ olùgbatẹnirò.” Nísinsìnyí, dípò kí ó máa ṣàríwísí ìyàwó rẹ̀, ó máa ń yìn ín fún àwọn àkókò tí ó máa ń lo ìgboyà láti sọ̀rọ̀ níwájú àwùjọ títóbi kan.

David Compton, tí ó jẹ́ akólòlò, ṣàlàyé nínú ìwé rẹ̀ Stammering pé, lọ́nà tí ó ṣeé lóye, ọ̀pọ̀ àwọn akólòlò máa ń “bẹ̀rù . . . nígbà míràn wọ́n máa ń dààmú, ó sì ń jẹ́ lọ́nà lílekoko lọ́pọ̀ ìgbà. Ní àkókò tí ó lè ṣẹlẹ̀ sí i jù lọ, àkókò tí ó pọn dandan fún un jù lọ láti kàn sí àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, nígbà tí ó bá fẹ́ bá wọn sọ̀rọ̀, yálà ó jẹ́ ọ̀rọ̀ eré tàbí ọ̀rọ̀ pàtàkì, irú àkókò yẹn ni akólòlò lè retí níní ìṣòro, kí ó sì tijú . . . Kódà àwọn tí wọ́n ń kojú rẹ̀ lọ́nà tí ó ní àṣeyọrí jù lọ ṣì gbà pé ìbẹ̀rù àwọn ṣì ń yọ àwọn lẹ́nu, kò sì fi àwọn sílẹ̀ pátápátá.”

Àwọn Ipò Tí Ó Lè Fa Ìbẹ̀rù

Nígbà tí a bá pe akólòlò kan láti dáhùn ìbéèrè kan níwájú àwùjọ kan, bíi ní kíláàsì kan ní ilé ẹ̀kọ́, níbi ìpàdé àwọn oníṣòwò kan, tàbí níbi ìkórajọ onísìn kan, ó lè fa hílàhílo tí ń yọrí sí kíkólòlò ní kólekóle. Nínú ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò orí rédíò kan, a béèrè lọ́wọ́ akólòlò ọmọ ọdún 15 kan, tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gúúsù Áfíríkà, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Rosanne, pé: “Àwọn àkókò kan ha wà tí o rò pé ó wúlẹ̀ rọrùn jù láti dákẹ́ bí?” Ó fèsì pé, “Lọ́pọ̀ ìgbà, fún àpẹẹrẹ, nígbà tí a bá wà nínú kíláàsì, nígbà tí mo bá ní ìdáhùn dáradára kan tí mo mọ̀ ní ti gidi pé yóò jẹ́ kí n gba máàkì, àmọ́ tí mo mọ̀ pé yóò gba ìsapá tí ó pọ̀ jù láti sọ̀rọ̀.”

A tún fọ̀rọ̀ wá ọkùnrin oníṣòwò kan tí ń jẹ́ Simon lẹ́nu wò lórí ètò orí rédíò tí a mẹ́nu kan lókè. Bíi Rosanne, ọ̀ràn Simon ti ṣẹ́ pẹ́rẹ́ nípasẹ̀ ìtọ́jú àbùkù ọ̀rọ̀ sísọ. Ṣùgbọ́n lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó ṣì máa ń ní ìṣòro kíkólòlò. Ìṣarasíhùwà àwọn olùgbọ́ rẹ̀ lè mú kí èyí burú sí i. Ó ṣàlàyé pé: “Bí o bá wà níbi ìpàdé àwọn alábòójútó, níbi tí o ní láti sọ̀rọ̀ nígbà bíi mélòó kan, tí ọ̀rọ̀ rẹ kò sì ń já gaara, ńṣe ni àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ní ìpàdé náà máa ń wára pàpà.”

A kò gbọ́dọ̀ ṣi ìbẹ̀rù tí akólòlò kan ní gbé fún ìbẹ̀rù tí onítìjú kan lè ní ní bíbá àwọn àjèjì sọ̀rọ̀. Ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀ràn ti Lisa, tí ó ti pé ọdún méjì tí ó ti ń lọ sí ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tí ó bá ń bá àwọn ọ̀rẹ́ sọ̀rọ̀ lásán, ó sábà máa ń gbìyànjú láti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yọ̀ mọ́ òun lẹ́nu. Ó tún máa ń fi ìtara ṣàjọpín nínú iṣẹ́ ajíhìnrere tí ó béèrè títọ àwọn àjèjì lọ láìjẹ́ pé wọ́n ké sí i. Ṣùgbọ́n ó ní ìbẹ̀rù kan tí ọ̀pọ̀ àwọn akólòlò sábà máa ń ní—bíbá àwùjọ ńlá kan sọ̀rọ̀. Lisa ṣàlàyé pé: “Ní àwọn ìpàdé wa, n kì í fi bẹ́ẹ̀ tiraka láti nawọ́ láti dáhùn ìbéèrè. Bí mo bá máa dáhùn rárá, lọ́pọ̀ ìgbà jù lọ, ó máa ń jẹ́ ọ̀rọ̀ kan tàbí gbólóhùn ọ̀rọ̀ kúkúrú kan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè jẹ́ ìwọ̀nba, gbogbo ohun tí agbára mi gbé nìyẹn. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ìdáhùn náà ti ń wà lórí mi, mo sì máa ń jẹ ẹ́ lẹ́nu nítorí pé mo sábà máa ń múra sílẹ̀. Ṣùgbọ́n ahọ́n mi sáà máa ń kọ̀ láti ṣe ohun tí mo fẹ́ ni.”

Ìrírí kan tí ó burú jáì tí àwọn akólòlò máa ń ní ni ti níní láti kàwé sókè. Èyí ń fagbára mú wọn láti lo àwọn ọ̀rọ̀ tí wọn óò yẹra fún lábẹ́ ipò tí ó wọ̀. Lisa ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ní ọ̀kan lára àwọn ìpàdé wa, wọ́n máa ń ní kí a pín àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a ń jíròrò kà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ní irú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀, ẹ̀rù máa ń bà mí níjokòó, tí ara mi kò ní balẹ̀, tí mo ń retí kí ó kàn mí, láìmọ̀ bóyá n óò tiraka láti ka ẹsẹ náà tàbí n kò ní lè kà á. Nígbà míràn, n óò kà á, àmọ́ n kò ní lè pe ọ̀rọ̀ kan. N óò wulẹ̀ fò ó, n óò sì máa ka ìyókù lọ.”

Ó ṣe kedere pé, a ní láti ronú tìṣọ́ratìṣọ́ra kí a tó gba akólòlò kan níyànjú láti kàwé sókè. Irú “ìyànjú” bẹ́ẹ̀ lè mú kí akólòlò náà banú jẹ́ gan-an. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí a yin ẹni náà gan-an fún ṣíṣe èyí tí agbára rẹ̀ ká.

Tí A Bá Ń Gbìyànjú Láti Ṣèrànwọ́

Kíkólòlò jẹ́ ìṣiṣẹ́gbòdì tí ó ta kókó gan-an. Ohun tí ó gbéṣẹ́ fún ẹnì kan lè máà gbéṣẹ́ fún ẹlòmíràn. Ní ti gidi, ọ̀pọ̀ àwọn akólòlò tí wọ́n ti ní “ìwòsàn” lákòókò kan tún máa ń pa dà ní ìṣòro náà. A ti ṣe ìwádìí púpọ̀ lórí ìkólòlò ju lórí ìṣiṣẹ́gbòdì ọ̀rọ̀ sísọ èyíkéyìí mìíràn lọ. Síbẹ̀, àwọn ògbógi kò tí ì rí ohun pàtó kan tí ń ṣokùnfà rẹ̀. Ní ti gidi, ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn gbà pé ohun púpọ̀ ló lè fa ìkólòlò. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà nínú àwọn ìwádìí lọ́ọ́lọ́ọ́ tí a ṣe, àbá èrò orí kan ni pé ó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbékalẹ̀ àwọn sẹ́ẹ̀lì ọpọlọ lọ́nà tí kò dára ní kùtùkùtù ìgbésí ayé akólòlò náà. Gẹ́gẹ́ bí Dókítà Theodore J. Peters àti Barry Guitar ti sọ, nínú ìwé wọn náà, Stuttering—An Intergrated Approach to Its Nature and Treatment, àwọn ojú ìwòye lọ́ọ́lọ́ọ́ nípa àwọn okùnfà rẹ̀ “yóò di ti àtijọ́ bí àwọn ìwádìí púpọ̀ sí i yóò ti máa dí àwọn àlàfo ńlá inú ohun tí a mọ̀ nípa ìkólòlò.”

Níwọ̀n bí ohun tí ènìyàn mọ̀ nípa ìkólòlò ti kéré gan-an, a ní láti ṣọ́ra nígbà tí a bá ń dábàá ọ̀kan lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà tí a lè gbà tọ́jú àwọn tí ìṣiṣẹ́gbòdì náà ń pọ́n lójú. Ìwé tí a sọ lókè náà fi kún un pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí ìṣòro ìkólòlò wọn le gan-an yóò wulẹ̀ kọ́fẹ pa dà fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ ni. Wọn óò kọ́ láti túbọ̀ máa rọra ṣọ̀rọ̀ tàbí kí wọ́n máa kólòlò lọ́nà tí ó túbọ̀ rọrùn, kí wọ́n má sì jẹ́ kí ó fi bẹ́ẹ̀ dà wọ́n láàmú. . . . Nítorí àwọn ìdí tí a kò mọ̀, àwọn akólòlò mélòó kan kì í wulẹ̀ yí pa dà lọ́nà tó lámì rárá bí a bá tọ́jú wọn.”b

Nígbà tí ìtọ́jú kò bá gbéṣẹ́, àwọn olùtọ́jú kan ti dẹ́bi fún akólòlò náà pé kò gbìyànjú púpọ̀ tó. Ọ̀kan sọ pé: “Ohun kan ṣoṣo tí ó lè fa ìkùnà ni ìṣarasíhùwà àláìfigbogbo-ọkàn-ṣe láti ọ̀dọ̀ akólòlò náà.” Òǹkọ̀wé David Compton sọ nípa irú ohun tí ẹni yẹn sọ pé: “N kò mọ ohun tí mo lè fi ṣàlàyé bí irú ọ̀rọ̀ yí ṣe lè bí àwọn akólòlò nínú tó. Lákọ̀ọ́kọ́, nítorí pé ó hàn gbangba pé kì í ṣe òtítọ́. Kò sí irú ìtọ́jú kan ṣoṣo tí yóò gbéṣẹ́ fún gbogbo àwọn akólòlò, kódà irú èyí tí yóò tọ́ fún akólòlò kan pàtó kò lè dára tán láìkùsíbìkan. Èkejì, nítorí pé àwọn akólòlò ń mú ìkùnà mọ́ra . . . Ohunkóhun tí ó bá ń mú kí [ìkùnà wọn] pọ̀ sí i láìnídìí, láìyẹ, jẹ́ ohun tí ń dójú tini.”

Mímú Ìnira Wọn Dẹrùn

Àwọn akólòlò kì í sábà fẹ́ kí a wo àwọn tàánútàánú. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ohun púpọ̀ wà tí a lè ṣe láti mú ìnira wọn dẹrùn. Nígbà tí wọ́n bá ń kólòlò, má ṣe fi ojútì gbójú kúrò lọ́dọ̀ wọn. Dípò wíwo ẹnu wọn, wo ojú wọn. Wọ́n sábà máa ń tètè hùwà pa dà sí ìṣarasíhùwà àwọn tí ń gbọ́ wọn. Bí o bá fara hàn bí ẹni tí ó sinmẹ̀dọ̀, yóò ṣèrànwọ́ láti dín ìbẹ̀rù wọn kù. Olùtọ́jú àbùkù ọ̀rọ̀ sísọ kan sọ pé: “Fi han ẹni náà pé o ti múra tán láti tẹ́tí sí i bí ìwọ yóò ṣe múra tán láti tẹ́tí sí ẹnikẹ́ni.”

Àwọn olùkọ́ tí akólòlò kan wà lára àwọn ọmọ tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lè ṣe púpọ̀ láti mú ìbẹ̀rù onítọ̀hún dẹrùn. Nínú ìwé agbéròyìnjáde nípa ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ní Gúúsù Áfíríkà náà, Die Unie, a fún àwọn olùkọ́ ní àmọ̀ràn tí ó tẹ̀ lé e yìí pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn akólòlò kì í fi bẹ́ẹ̀ kólòlò tí wọ́n bá mọ̀ pé ẹni tí ń gbọ́ wọn kò retí ìyọ̀mọ́nilẹ́nu-ọ̀rọ̀.”

Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde òkè náà ti sọ, ó tún ṣe pàtàkì fún olùkọ́ kan láti mọ èrò akẹ́kọ̀ọ́ náà. Dípò yíyẹra fún irú akẹ́kọ̀ọ́ náà nítorí ìkójútìbáni, a gba àwọn olùkọ́ nímọ̀ràn láti bá wọn sọ̀rọ̀, kí wọ́n sì fún wọn níṣìírí láti sọ èrò ọkàn wọn nípa ìṣòro náà jáde. Lọ́nà yí, olùkọ́ náà lè mọ irú ipò àyíká tí sísọ̀rọ̀ ti máa ń ba akẹ́kọ̀ọ́ náà lẹ́rù jù lọ. Ìwé agbéròyìnjáde náà sọ pé: “Bí ọ̀rọ̀ yóò ṣe yọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu sinmi lórí ìwọ olùkọ́ rẹ̀ ní ìwọ̀n ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún.” Ọ̀rọ̀ yóò túbọ̀ yọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu bí ó bá mọ̀ pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ní ìṣòro, a ṣì tẹ́wọ́ gba òun. Ìwé agbéròyìnjáde náà ṣàlàyé síwájú sí i pé: “Kì í ṣe akólòlò náà nìkan ni ipò àyíká tí ó tura, tí ń fún ẹ̀kọ́ kíkọ́ níṣìírí nínú kíláàsì yóò ṣe láǹfààní, àmọ́ yóò ṣe gbogbo àwọn yòó kù ní kíláàsì náà láǹfààní pẹ̀lú.”

Dájúdájú, a lè ṣàmúlò àwọn àbá wọ̀nyí lọ́nà tí ó kẹ́sẹ járí nínú àwọn ipò ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí ó kan àwọn àgbàlagbà.

Ó Yé Ẹlẹ́dàá Wa

Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run, lóye àìpé ẹ̀dá ènìyàn lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Ó yanṣẹ́ fún Mósè láti jẹ́ agbẹnusọ rẹ̀ ní ṣíṣatọ́nà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì. Ó ṣe èyí bí ó ti mọ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ pé Mósè ní àbùkù ọ̀rọ̀ sísọ tí ó mú kí ọ̀rọ̀ sísọ ni ín lára. Ọlọ́run tún mọ̀ pé ọ̀rọ̀ yọ̀ mọ́ Áárónì lẹ́nu gan-an ju Mósè àbúrò rẹ̀ lọ. Ọlọ́run sọ pé: “Èmi mọ̀ pé ó lè sọ̀rọ̀ jọjọ.” (Ẹ́kísódù 4:14) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Mósè ní àwọn ìwà yíyẹ mìíràn tí ó ṣe pàtàkì gan-an, bí ìdúróṣinṣin, inúrere, ìgbàgbọ́, àti ọkàn tútù. (Númérì 12:3; Hébérù 11:24, 25) Láìka àwáwí Mósè sí, Ọlọ́run rọ̀ mọ́ yíyàn tí ó yan Mósè gẹ́gẹ́ bí aṣáájú àwọn ènìyàn Rẹ̀. Nígbà kan náà, Ọlọ́run gba ti ìbẹ̀rù Mósè rò nípa yíyan Áárónì gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ fún Mósè.—Ẹ́kísódù 4:10-17.

A lè ṣàfarawé Ọlọ́run nípa fífi òye hàn. Fi iyì bá àwọn akólòlò lò, má sì ṣe jẹ́ kí àbùkù ọ̀rọ̀ sísọ kan di ojú rẹ sí ohun tí ẹni náà já mọ́ ní ti gidi. Ìrírí ọmọdébìnrin kékeré kan àti bàbá rẹ̀ tí ó jẹ́ akólòlò fi èyí hàn. Bàbá náà kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀nà kan tí yóò máa gbà kàwé lọ́nà tí ó túbọ̀ yọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu. Lálẹ́ ọjọ́ kan, ó gbìyànjú lílò ó fún ọmọbìnrin rẹ̀ ọlọ́dún mẹ́fà nípa kíka ìtàn kan fún un, inú ọkùnrin náà sì dùn gan-an sí bí ó ṣe yọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu.

Nígbà tí bàbá rẹ̀ kà á tán, ọmọdébìnrin náà sọ pé: “Dádì, ẹ máa sọ̀rọ̀ dáadáa.”

Ó fi ìkannú fèsì pé: “Mo ti ń sọ̀rọ̀ dáadáa gan-an.”

Ọmọdébìnrin náà rin kinkin mọ́ ọn pé: “Rárá, ẹ sọ̀rọ̀ bí ẹ ṣe máa ń sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀.”

Bẹ́ẹ̀ ni, ọmọdébìnrin kékeré yìí gba bàbá rẹ̀ bí ó ti rí, ó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kódà pẹ̀lú àbùkù ọ̀rọ̀ sísọ tí ó ní. Nítorí náà, ìgbà tí o bá tún ń bá akólòlò kan ṣe ohun kan pọ̀, rántí pé ẹni náà lè ní àwọn èrò ṣíṣeyebíye àti àwọn ìwà yíyẹ fífani-lọ́kànmọ́ra. Dájúdájú, ó ní ìmọ̀lára. Mú sùúrù, sì fi òye hàn sí i.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí lára àwọn orúkọ tí a lò nínú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.

b Ìfojúsọ́nà fún ìkọ́fẹpadà sàn fún àwọn ọmọdé ju fún àwọn àgbàlagbà lọ. Olùtọ́jú àbùkù ọ̀rọ̀ sísọ náà, Ann Irwin, ṣàlàyé nínú ìwé rẹ̀ Stammering in Young Children pé: “Mẹ́ta lára àwọn ọmọdé mẹ́rin ni kì í kólòlò mọ́ lọ́nà àdánidá bí wọ́n ti ń dàgbà sí i. Bí ọmọ rẹ bá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìpín 25 nínú ọgọ́rùn-ún tí ìkólòlò wọn kì í lọ lọ́nà àdánidá bí wọ́n ti ń dàgbà, ó ṣeé ṣe gan-an pé kí ó máà kólòlò mọ́ bí ó ti ń dàgbà sí i tí ó bá ń gba Ìtọ́jú Aṣèdíwọ́.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Akólòlò kan lè máa bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ níbi tí èrò pọ̀ sí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Sinmẹ̀dọ̀ bí ó bá ń ni akólòlò kan lára láti bá ọ sọ̀rọ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Àwọn akólòlò sábà máa ń bẹ̀rù tẹlifóònù

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́