Bí Mo Ṣe Kojú Ìkólòlò
Bí Sven Sievers ṣe sọ ọ́
LÁTI ìgbà tí mo ṣì kéré gan-an ni mo ti ń kólòlò. Ní ríronú pa dà, mo mọrírì ọ̀nà tí àwọn òbí mi gbà kojú ìṣòro náà. Bí mo bá ń kólòlò, wọ́n máa ń gbìyànjú láti fọkàn sí gbígbọ́ ohun tí mo fẹ́ láti sọ dípò kí wọ́n máa ṣàtúnṣe ọ̀nà tí mo ń gbà sọ̀rọ̀. Gẹ́gẹ́ bí àwọn olùtọ́jú àbùkù ọ̀rọ̀ sísọ ti sọ, àwọn òbí tí wọ́n máa ń pe àfiyèsí sí ìkólòlò ọmọ wọn léraléra lè mú kí ìṣiṣẹ́gbòdì náà burú sí i.a
Ìyá mi di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́ta. Ní àwọn ọdún tí mo jẹ́ ọ̀dọ́langba, mo pinnu láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, mo sì rí ìrànlọ́wọ́ gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kínníkínní. Ní July 24, 1982, mo ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí ó ti ṣe ìyàsímímọ́ ní àpéjọpọ̀ kan ní Neumünster, Germany. Lẹ́yìn náà, mo kó lọ sí Gúúsù Áfíríkà, níbi tí mo ti ń bá a lọ nínú iṣẹ́ ìwàásù ìtagbangba, èyí tí a pàṣẹ pé kí gbogbo Kristẹni tòótọ́ máa ṣe. (Mátíù 28:19, 20) O lè ṣe kàyéfì pé, báwo ni èmi tí mo jẹ́ akólòlò ṣe rọ́nà gbé e gbà?
Èrè fún Dídá Ara Mi Lójú
Mo ní láti jẹ́wọ́ pé ó máa ń le fún mi láti dá ara mi lójú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ mo ti wá mọ̀ pé dídá ara mi lójú jẹ́ àrànṣe ńlá kan ní ti gidi. Òkodoro òtítọ́ náà ni pé mo máa ń lè bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ bákan ṣáá. Bí kì í bá ṣe nípa ìsọ̀rọ̀ ẹnu, mo máa ń bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ ìwé kíkọ tàbí kìkì nípa fífi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn wọ́n. Dídá ara mi lójú ràn mí lọ́wọ́ láti borí ìṣòro bíbẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. Mo ń gbìyànjú láti mú kí ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ mi rọrùn gan-an. Bí mo bá bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò kan, mo ń jẹ́ kí onílé sọ̀rọ̀ púpọ̀ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Àwọn ènìyàn fẹ́ràn láti máa sọ̀rọ̀, èyí sì ń fún mi ní àǹfààní láti mọ bí wọ́n ṣe ń ronú. Lẹ́yìn náà ni n óò máa bá ìjíròrò náà lọ nípa sísọ àwọn ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí, n óò sì máa ṣàlàyé ìhìn iṣẹ́ Bíbélì. Fífọkàn sí ohun tí wọ́n ń sọ ń ràn mí lọ́wọ́ láti gbàgbé nípa ìṣòro ọ̀rọ̀ sísọ tí mo ní, n kì í sì í kólòlò púpọ̀.
Dídá ara mi lójú tún máa ń ràn mí lọ́wọ́ láti lè sọ̀rọ̀ ní àwọn ìpàdé Kristẹni. Mo ti wá rí i pé bí mo bá ṣe ń kópa nínú ìjíròrò Bíbélì tó ni ọ̀rọ̀ mi máa ń yé àwùjọ àti olùdarí ìpàdé tó, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n máa ń tẹ́tí sí ohun tí mo ń sọ tó dípò kí wọ́n fiyè sí bí mo ṣe ń sọ ọ́.
Láti nírìírí ayọ̀ tí ó wà nínú àṣeyọrí, mo ní láti máa bá a lọ ní gbígbìyànjú. Èyí kì í jẹ́ kí n lè juwọ́ sílẹ̀ fún ṣíṣàánú ara mi àti àìfẹ́sọ̀rọ̀síta. Gbígbógunti ṣíṣàánú ara ẹni jẹ́ ìjàkadì tí kò lópin. A ti sọ ọ́ pé bí ẹṣin bá dáni, ó ṣe pàtàkì láti tún ta lé ẹṣin náà kí a má ba pàdánù ìdára-ẹni-lójú. Nítorí náà, bí mo bá ní láti dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ nígbà tí mo bá ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ nítorí kíkólòlò, mo máa ń gbìyànjú láti tún ta lé ẹṣin náà, lédè ìṣàpẹẹrẹ, nípa sísọ̀rọ̀ ní àkókò tí mo bá tún láǹfààní rẹ̀.
Bí Àwọn Mìíràn Ṣe Lè Ṣèrànwọ́
Nígbà tí mo bá ní láti bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù tàbí láti béèrè fún ìsọfúnni lọ́wọ́ àwọn àjèjì, mo máa ń mọrírì ìrànlọ́wọ́ tí ó gbọgbọ́n. Àmọ́ àwọn kan máa ń ṣàṣejù tí wọ́n bá fẹ́ ràn mí lọ́wọ́, wọ́n sì máa ń ṣe mí bí ọmọdé tí kò lè dá ìpinnu ṣe.
Mo mọrírì ìrànlọ́wọ́ Tracy, ìyàwó mi olùfẹ́. Kí ó tó máa “ṣẹnu” fún mi, a jíròrò ọ̀ràn náà lẹ́kùn ún rẹ́rẹ́, ó sì mọ ohun tí mo fẹ́ láti ṣàṣeparí rẹ̀. (Fi wé Ẹ́kísódù 4:10, 14, 15.) Lọ́nà yẹn, ó ń fún mi ní ọ̀wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkọ rẹ̀, ó sì jẹ́ kí ń nímọ̀lára pé mo ṣì ń darí ìgbésí ayé mi.
Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run ti jẹ́ ìrànlọ́wọ́ ńlá mìíràn. Ní ìpàdé tí a ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ yí, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń kópa nínú Bíbélì kíkà fún àwùjọ, àti bíbánisọ̀rọ̀ kúkúrú lórí àwọn kókó inú Bíbélì. Ó yà mí lẹ́nu láti mọ̀ pé mo lè kàwé kí n sì sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ó já gaara bẹ́ẹ̀ níwájú àwùjọ kan lọ́pọ̀ ìgbà. Ká ní n kò tí ì forúkọ sílẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ náà ni, bóyá n kì bá má mọ̀ pé mo tóótun lọ́nà yí.
Nígbà tí mo bá ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, ó máa ń ṣí mi lórí gan-an tí olùdarí ilé ẹ̀kọ́ bá tẹnu mọ́ ohun tí mo sọ, tí kì í ṣe bí mo ṣe sọ ọ́. Mo ti jàǹfààní ńláǹlà láti inú Iwe-Amọna Ile Ẹkọ Iṣẹ Ojiṣẹ Ijọba Ọlọrun,b bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn apá kan nínú ìwé yìí gbé àwọn ìṣòro tí ó tóbi gan-an síwájú àwọn tí ń kólòlò ju àwọn tí wọn kò ní ìṣòro ọ̀rọ̀ sísọ lọ. Fún àpẹẹrẹ, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, n kì í lè parí iṣẹ́ mi láàárín àkókò tí a là sílẹ̀ fún iṣẹ́ náà nítorí bí mo ṣe máa ń kólòlò tó. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó máa ń fún mi níṣìírí gan-an tí olùdarí ilé ẹ̀kọ́ bá tẹnu mọ́ àwọn kókó tí mo lágbára láti ṣiṣẹ́ lé lórí.
Àwọn Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Púpọ̀ Sí I
Nígbà kan, mo ní àǹfààní kíka ìtẹ̀jáde Kristẹni kan tí a ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní àwọn ìpàdé wa sétígbọ̀ọ́ àwùjọ. Mo tún ní àǹfààní dídarí ìpàdé bí òjíṣẹ́ mìíràn tí ó tóótun kò bá sí níbẹ̀, àti pé, lónìí, mo máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ déédéé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ní ìbẹ̀rẹ̀, ojora máa ń ṣe mí, Ọlọ́run ti ràn mí lọ́wọ́ láti lè ṣe irú àwọn iṣẹ́ bẹ́ẹ̀.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àǹfààní tí mo ń ní láti kàwé tàbí láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ láti orí pèpéle nínú ìjọ ní ààlà fún ọ̀pọ̀ ọdún. Èyí ṣeé lóye níwọ̀n bí àwọn àkókò kan ti wà tí ó máa ń pẹ́ kí àwùjọ tó gbọ́ mi lágbọ̀ọ́yé. Nítorí náà, mo máa ń lo agbára mi dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ní ṣíṣe àwọn iṣẹ́ àyànfúnni mìíràn. Lákọ̀ọ́kọ́, mo ń sìn gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ fún ẹni tí ń bójú tó Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tí ń dé sọ́wọ́ ìjọ. Nígbà tó yá, lẹ́yìn tí wọ́n yàn mí gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, mo ń bójú tó àwọn Bíbélì, ìwé ńlá, àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tí ń dé sọ́wọ́ ìjọ. Lẹ́yìn náà, wọ́n fún mi ní iṣẹ́ yíyẹ àwọn káàdì ìpínlẹ̀ ìṣiṣẹ́ tí a ń lò nínú iṣẹ́ ìwàásù ìtagbangba wa wò. Bí mo ti ń fún àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí láfiyèsí, tí mo ń gbìyànjú láti máa ṣiṣẹ́ taápọntaápọn, ó ń mú inú mi dùn gan-an.
Láàárín ọdún mẹ́jọ tó kọjá, bákan náà ni mo ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere alákòókò kíkún pẹ̀lú Tracy. Dájúdájú, Jèhófà ti bù kún mi lọ́nà yí pẹ̀lú. Ní gidi, mo máa ń ṣe kàyéfì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan bóyá Jèhófà ń lo àìlera ìkólòlò mi. Méjì lára àwọn márùn-ún tí mo ti ní àǹfààní láti ràn lọ́wọ́ láti di Kristẹni tí ó ṣèyàsímímọ́, ló jẹ́ akólòlò.
Tayọ̀tayọ̀ ni mo ṣì fi ń rántí ọjọ́ tí wọ́n yàn mí sípò láti sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà kan nínú ìjọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé agbára mi láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ lórí pèpéle ní ààlà, mo ń gbìyànjú láti fọkàn sí ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Kíkólòlò kò pààlà sí agbára mi láti ṣe ìwádìí nínú Ìwé Mímọ́ láti ṣèrànlọ́wọ́ fún àwọn mẹ́ńbà ìjọ tí wọ́n ń kojú ìṣòro lílekoko.
Láàárín ọdún márùn-ún tó kọjá, wọ́n ti ké sí mi láti bá àwùjọ púpọ̀ sọ̀rọ̀. Yàtọ̀ sí ṣíṣe iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, mo ti ṣe àwọn ìfilọ̀ tí kò gùn ní àwọn ìpàdé mìíràn. Ọ̀rọ̀ ti ń yọ̀ mọ́ mi lẹ́nu díẹ̀díẹ̀. Àmọ́ ó tún jó rẹ̀yìn gan-an. Ní ṣíṣàníyàn, mo ronú pé, ‘wọn kò ní yan iṣẹ́ fún mi mọ́,’ àmọ́ ó yà mí lẹ́nu pé orúkọ mi wà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí ó jáde lẹ́yìn náà! Alábòójútó olùṣalága ìjọ wa sọ pé bí ìkólòlò mi bá bẹ̀rẹ̀, mo kàn lè wo òun, òun óò sì wá sórí pèpéle láti ṣe iṣẹ́ náà parí. Mo ṣàmúlò àmọ̀ràn yí lẹ́ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀mejì, àmọ́ n kò ṣe bẹ́ẹ̀ ní àwọn oṣù lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí. Bí ọ̀rọ̀ mi ti ń já gaara sí i, wọ́n ń fún mi ní àwọn iṣẹ́ tí ó túbọ̀ gùn díẹ̀, títí kan àwíyé fún gbogbo ènìyàn. Ẹnu àìpẹ́ yìí tí wọ́n ní kí n wá kópa nínú àwòkẹ́kọ̀ọ́ méjì ní ọ̀kan lára àwọn àpéjọ àyíká ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ bí mo ti tẹ̀ síwájú tó ní kíkún.
Láìṣàwàdà, n kò mọ̀ ní kíkún ìdí tí ọ̀rọ̀ sísọ mi fi ń já gaara sí i. Bákan náà, ó tún lè jó rẹ̀yìn lọ́jọ́ iwájú. Ní gidi, nígbà tí ó bá jọ pé ọ̀rọ̀ sísọ mi ti ń já gaara lọ́nà kan pàtó nígbà tí mo bá ń sọ̀rọ̀ lórí pèpéle, ó tún máa ń burú sí i gan-an nígbà tí mo bá ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ láwọn nìkan. Nítorí náà, èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ àṣeyọrí bí a bá ń sọ nípa pé mo ti ṣẹ́gun ìkólòlò. Nígbà tí ó bá ń jó rẹ̀yìn, mo ń gbìyànjú láti rán ara mi létí pé mo ní láti gbà pé mo ní ààlà, kí n sì ‘jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rìn.’—Míkà 6:8.
Ohun yòó wù kí ó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, n óò máa gbìyànjú, ní mímọ̀ pé nínú ayé tuntun Ọlọ́run tí ń bọ̀, a óò ṣẹ́gun ìkólòlò pátápátá. Bíbélì sọ pé: “Ahọ́n àwọn akólòlò yóò sọ̀rọ̀ kedere.” Mo ní ìdánilójú pé èyí yóò jẹ́ òtítọ́ lọ́nà olówuuru àti lọ́nà ti ẹ̀mí àti pé, “ahọ́n odi yóò kọrin.”—Aísáyà 32:4; 35:6.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Lílóye Ìbẹ̀rù Kíkólòlò,” nínú ìtẹ̀jáde wa ti November 22, 1997.
b Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Èmi àti ìyàwó mi, Tracy