Ṣíṣèbẹ̀wò Sọ́dọ̀ Àwọn Ìnàkí Orí Òkè
Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyìn Jí! ní Tanzania
NǸKAN bí 320 péré nínú wọn ló ń gbé àgbègbè òkè ayọnáyèéfín ní ààlà Rwanda àti Democratic Republic of Congo. Ọ̀ọ́dúnrún mìíràn ń gbé inú igbó dídí ilẹ̀ Uganda tí kò ṣeé wọ̀. Àwọn ìnàkí orí òkè—lára àwọn ẹranko afọ́mọlọ́mú tí a wu léwu àkúrun jù lọ lágbàáyé—ni!
Onímọ̀ nípa ẹranko, tó tún jẹ́ ará Amẹ́ríkà náà, Dian Fossey, ṣe gudugudu méje láti ta àwọn ènìyàn jí sí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹ̀dá wọ̀nyí. Fossey wá sí Áfíríkà ní apá ìparí àwọn ọdún 1960 láti ṣèwádìí nípa àwọn ìnàkí orí òkè. Ìpẹran-láìgbàṣẹ ń mú kí iye wọn máa yára dín kù nígbà yẹn. Onígboyà onímọ̀ sáyẹ́ǹsì náà bẹ̀rẹ̀ sí í gbé bí ayẹrafẹ́gbẹ́ ní Àwọn Òkè Ńlá Virunga, ó sì yára ń bá àwọn ìnàkí tó wà níbẹ̀ ṣọ̀rẹ́. Fossey tẹ àwọn àwárí rẹ̀ jáde nínú àwọn àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn àti nínú ìwé náà, Gorillas in the Mist. Bí àkókò ṣe ń lọ, ó túbọ̀ pinnu láti dáàbò bo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ abirunlára, nípa gbígbógunti àwọn apẹran-láìgbàṣẹ. Bí ó ti wù kí ó rí, inú ìjìjàdù onítara tirẹ̀ fúnra rẹ̀ yí ló kú sí, tí agbóguntini kan tí a kò mọ̀ pa á ní 1985.
Bí ìrètí wa láti fojú ara wa rí àwọn ẹ̀dá alálàáfíà wọ̀nyí ti sún wa gbégbèésẹ̀, èmi àti aya mi pinnu láti lọ sí ibùgbé àwọn ìnàkí náà ní 1993. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí a ròyìn ohun tí a rí fún yín.
A bẹ̀rẹ̀ bí àwọn afinimọlẹ̀ wa ṣe mú wa gòkè ayọnáyèéfín Visoke tó ga ní 3,700 mítà, tí a fi wákàtí kan gùn, tí a sì dé etí Ọgbà Ohun Alààyè Orílẹ̀-Èdè ti Volcanoes, ní Rwanda. Nígbà tí a ń sinmi lọ́wọ́, àwọn afinimọlẹ̀ wa ṣàlàyé bí a ti ní láti máa ṣe nígbà tí a bá wà ní sàkáání àwọn ìnàkí náà. Wọ́n sọ fún wa pé àwọn olùbẹ̀wò mẹ́jọ péré la ń gbà láyè lóòjọ́ láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwùjọ àwọn ẹranko yìí. Èyí ń dín ewu bí ó ti ṣeé ṣe tó pé kí wọ́n kó àrùn kù, ó sì tún ń dènà ìdíwọ́ nínú ọ̀nà tí wọ́n gbà ń hùwà.
Afinimọlẹ̀ kan rán wa létí pé: “Bí a bá ti wọnú igbó náà, a kò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ sókè. Èyí yóò mú kí a tún lè wo àwọn ẹranko mìíràn àti ẹyẹ, nítorí pé yàtọ̀ sí àwọn ìnàkí orí òkè náà, àwọn ọ̀bọ olómiwúrà, ẹtu, ìgalà, erin, àti ẹfọ̀n pàápàá, tún wà nínú igbó náà.”
Wọ́n tún fi yé wa pé àwọn èsìsì jónijóni àti àwọn kòkòrò tanitani wà nínú ọgbà náà àti pé a lè ní láti rìn la àwọn ibi tí ìrì bò àti ibi ẹlẹ́rẹ̀ inú igbó náà já. Èmi àti ìyàwó mi wo ojú ara wa. A kò múra fún ìyẹn tẹ́lẹ̀! Ṣùgbọ́n àwọn afinimọlẹ̀ ẹlẹ́mìí ọ̀rẹ́ náà ràn wá lọ́wọ́ nípa yíyá wa ní aṣọ òjò àti bàtà àwọ̀dórúnkún.
Afinimọlẹ̀ wa wá ṣàlàyé fún wa pé àwọn ìnàkí tètè máa ń kó àrùn ẹ̀dá ènìyàn jù, nítorí náà, láti dáàbò bò wọ́n, kí ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣàìsàn tàbí tó bá mọ̀ pé òun ní àrùn tí ń ranni má tẹ̀ lé wa. Ọ̀kan nínú àwọn afinimọlẹ̀ náà sọ pé: “Bí o bá fẹ́ wúkọ́ tàbí tí o fẹ́ sín nígbà tí a bá wà lọ́dọ̀ àwọn ìnàkí náà, jọ̀wọ́ yí dà kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹranko náà, kí o sì gbìyànjú láti bo imú àti ẹnu rẹ. Rántí! Àlejò la jẹ́ nínú ibùgbé àdánidá wọn tó kún fún ìrì.”
A Sún Mọ́ Wọn Tó Láti Fọwọ́ Kàn Wọ́n!
Gígun òkè náà túbọ̀ ń nira sí i. A dé ibi tó ga tó 3,000 mítà. Afẹ́fẹ́ kò ní èròjà oxygen púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ mọ́, tó mú kí ó ṣòro láti mí, àwọn ipa ọ̀nà sì tóóró. Àmọ́, ó ṣeé ṣe fún wa láti gbádùn ẹwà igi hagenia, tí ó ní àwọn ẹ̀ka tó tẹ́ rẹrẹ, tí àwọn èpò eléwé wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́, àwọn ewéko olókùn tí ń nà mọ́ igi, àti àwọn ewéko orchid, bò bámúbámú. Ó fún igbó náà ní ẹwà bíi ti párádísè.
Àwọn afinimọlẹ̀ náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í wá ọ̀gangan ibi tí wọ́n ti rí àwọn ìnàkí náà lánàá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìnàkí náà máa ń lọ kiri ni, bí wọ́n ti ń wá oúnjẹ kiri lọ́tun. Ẹnì kan wí pé: “Ẹ wo ọ̀hún yẹn!” Ibùsùn, tàbí ìtẹ́, ìnàkí ẹlẹ́yìnfàdákà náà ló wà lórí àwọn ewéko rẹ́súrẹ́sú níbẹ̀.
Afinimọlẹ̀ náà ṣàlàyé pé: “Umugome ni wọ́n ń pè é. Nígbà tí akọ ìnàkí kan bá dàgbà tó ọdún 14, ẹ̀yìn rẹ̀ máa ń di funfun bíi fàdákà. Ìgbà náà ni wọ́n máa ń kà á sí aṣíwájú agbo náà. Ẹlẹ́yìnfàdákà náà nìkan ló sì ń gun gbogbo abo ìnàkí. Wọ́n ń lé àwọn tí kò dàgbà tó o tí wọ́n bá gbìyànjú láti gun abo kúrò nínú agbo náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀! Bí ó ti wù kí ó rí, bí abánidíje kan bá pa ẹlẹ́yìnfàdákà náà, yóò tún pa gbogbo irú ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú. Nígbà náà, aṣíwájú tuntun náà yóò gbapò, yóò sì mú irú ọmọ jáde nípasẹ̀ àwọn abo inú agbo náà.”
Bí a ti ń tẹ̀ lé àwọn afinimọlẹ̀ náà wọ inú igbó ọparun rírẹwà kan, ẹnì kan nínú wa béèrè pé: “Báwo ni ìnàkí kan ṣe lè pẹ́ láyé tó?”
Ìdáhùn tí a fẹ̀sọ̀ mú wá náà ni pé: “Ó lè tó nǹkan bí 40 ọdún.”
Bí a ti gbọ́ ìró kan tó wọni lára, ẹnì kan sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ pé: “Ṣṣṣ! Ṣṣṣ! Kí nìyẹn? Ṣé ìnàkí ni?” Rárá o, ọ̀kan lára àwọn afinimọlẹ̀ ló ń dún bí ìnàkí, tó ń gbìyànjú láti gbọ́ ìdáhùnpadà. A gbọ́dọ̀ ti sún mọ́ wọn gan-an ni!
Ní gidi, ní nǹkan bíi mítà márùn-ún péré sí ibi tí a wà ni nǹkan bí 30 ìnàkí wà! Wọ́n sọ fún wa pé kí a jókòó sílẹ̀, kí a sì dákẹ́. Afinimọlẹ̀ kan rọ̀ wá pé: “Ẹ má nàka sí wọn, nítorí wọ́n lè rò pé ẹ ń ju nǹkan sí wọn ni. Ẹ dákun, ẹ má pariwo. Nígbà tí ẹ bá ń yàwòrán, ẹ rọra ṣe, kí ẹ sì máa ṣọ́ra, ẹ má sì lo iná kámẹ́rà tí ń bù yẹ̀rì.”
A sún mọ́ wọn tó pé kí a fọwọ́ kàn wọ́n! Ṣùgbọ́n kí ẹnikẹ́ni nínú wa tó dágbá lé ṣíṣe bẹ́ẹ̀, afinimọlẹ̀ kan yọ́ ọ̀rọ̀ sọ pé: “Ẹ má fọwọ́ kàn wọ́n o!” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tó sọ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìnàkí kéékèèké mélòó kan rìn sún mọ́ wa láti ṣàyẹ̀wò wa. Afinimọlẹ̀ náà rọra fi ẹ̀ka igi kan nà wọ́n kẹ́rẹ́, àwọn ọmọ ẹran olójúmìító náà sì ń yí gbiiri lọ sísàlẹ̀, tí wọ́n ń bá ara wọn wọ ẹkẹ bí àwọn ọmọdé. Nígbà tí eré náà bẹ̀rẹ̀ sí í le jù, “Mọ́mì” bá wọn dá sí i.
Ẹlẹ́yìnfàdákà náà ń wò wá láti òkèèrè. Lójijì, ó rìn sún mọ́ wa, ó sì jókòó, ní mítà mélòó kan péré sí ibi tí a jókòó. Ó tóbi gan-an, ó sì gbọ́dọ̀ tẹ̀wọ̀n tó 200 kìlógíráàmù! Oúnjẹ ti gbà á lọ́kàn tí kò fi ráyè pàfiyèsí sí wa tó bẹ́ẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń fi ojú ẹ̀gbẹ́ kan ṣọ́ wa. Ní gidi, oúnjẹ jíjẹ ni lájorí ìgbòkègbodò ìnàkí! Ìnàkí ẹlẹ́yìnfàdákà kan lè jẹ oúnjẹ tó pọ̀ tó 30 kìlógíráàmù lóòjọ́. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹranko inú agbo náà ni ọwọ́ rẹ̀ dí níbi tí ó ti ń wá oúnjẹ kiri látàárọ̀ ṣúlẹ̀. Nígbà míràn, ènìyàn lè rí wọn níbi tí wọ́n ti ń jà lórí “àwọn ohun ọdẹ” tí ọwọ́ wọn tẹ̀.
Oúnjẹ tí wọ́n kúndùn jù ni fùkùfùkù inú irúgbìn senecio ńlá. Wọ́n tún fẹ́ràn irúgbìn celery ìgbẹ́, gbòǹgbò àwọn irúgbìn kan, àti ọ̀mùnú ọparun. Nígbà míràn, wọ́n ń ṣe “sàláàdì,” nípa ṣíṣe àdàlù ọ̀mùnú ọparun òun àwọn ewé òṣùṣu, èsìsì, ewéko galium, àti onírúurú gbòǹgbò àti àjàrà. Ẹnì kan béèrè pé: “Èé ṣe tí àwọn èsìsì tí àwọn ìnàkí ń gbá jọ, tí wọ́n sì ń jẹ kì í fi í jó wọn?” Afinimọlẹ̀ kan ṣàlàyé pé: “Awọ àtẹ́lẹwọ́ wọn yi.”
Bí a ti ń gbádùn ìran alálàáfíà yí lọ, lójijì ni akọ ńlá náà dìde dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì, tó da ìkúùkù bo ara rẹ̀ láyà, tó ké tagbáratagbára lọ́nà tó múni gbọ̀n rìrì! Ó pa kuuru mọ́ ọ̀kan lára àwọn afinimọlẹ̀ náà, ó sì dúró ṣì nígbà tó kù díẹ̀ kó dé ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ó ranjú mọ́ ọn! Ṣùgbọ́n afinimọlẹ̀ wa kò ṣojo rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jókòó, ó kùn hùnnùhùnnù, ó sì sún sẹ́yìn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́. Ó jọ pé ẹlẹ́yìnfàdákà náà wulẹ̀ fẹ́ fi okun àti agbára rẹ̀ hàn wá ni. Ká sọ òótọ́, ó ṣàṣeyọrí!
Àwọn afinimọlẹ̀ náà wá ṣàpẹẹrẹ fún wa pé kí a múra láti máa lọ. A ti lo wákàtí kan ó lé díẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àlejò “nínú ìrì” lọ́dọ̀ àwọn àgbàyanu ẹ̀dá alálàáfíà wọ̀nyí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣókí ni ìbẹ̀wò wa, ó ti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìrírí tí a kò lè gbàgbé jù lọ. Ó mú wa ronú lórí ìlérí inú Bíbélì nípa ayé tuntun tí ń bọ̀, níbi tí ènìyàn àti ẹranko yóò ti jọ wà lálàáfíà títí!—Aísáyà 11:6-9.
[Àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 18]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Àgbègbè Ibùgbé Àwọn Ìnàkí Orí Òkè
DEMOCRATIC REPUBLIC OF CONGO
Adágún Kivu
UGANDA
RWANDA
ÁFÍRÍKÀ
Àgbègbè Tí A Mú Tóbi
[Credit Line tó wà ní ojú ìwé 18]
Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.