ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 8/22 ojú ìwé 21-23
  • ‘Ahọ́n Àwọn Akólòlò Pàápàá Yóò Sọ̀rọ̀’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Ahọ́n Àwọn Akólòlò Pàápàá Yóò Sọ̀rọ̀’
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìṣòro Ọ̀rọ̀ Sísọ Tí Mo Ní
  • Wíwá Ìrànwọ́ Kiri
  • Bíbá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Pàdé
  • Ọ̀nà sí Ìbàlẹ̀ Ọkàn
  • Kíkojú Àwọn Ìpèníjà Àrà Ọ̀tọ̀
  • Bí Mo Ṣe Kojú Ìkólòlò
    Jí!—1998
  • Ìgbàgbọ́ Nínú Ọlọrun Ṣàkóso Mi Ní Ilẹ̀ Kọ́múníìsì
    Jí!—1996
  • Mo ti lè ran àwọn míì lọ́wọ́ báyìí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Mo Kún fun Ìmoore fun Itilẹhin Jehofa tí Kìí Kùnà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 8/22 ojú ìwé 21-23

‘Ahọ́n Àwọn Akólòlò Pàápàá Yóò Sọ̀rọ̀’

Ó JẸ́ nígbà ìjókòó ọ̀sán ọjọ́ àpéjọ àkànṣe àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kan ní Czechoslovakia (Ilẹ̀ Olómìnira Czech nísinsìnyí), ọgọ́rọ̀ọ̀rún ènìyàn sì ti pàdé pọ̀ láti gba ìtọ́ni Bíbélì. Mo dúró lẹ́yìn pèpéle, mo sì ń ṣàtúnyẹ̀wò iṣẹ́ tí mo ní nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Kì í ṣe ọ̀kan tí ó fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì. Àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí méjì yóò sọ ìrírí, èmi yóò sì wulẹ̀ jẹ́ alága fún iṣẹ́ náà. Ní òwúrọ̀ yẹn, mo ní àìfararọ inú lọ́hùn-ún, ó sì ń pọ̀ sí i nísinsìnyí. Ní ṣákálá, mo nímọ̀lára àìlè ṣe nǹkan kan, ìdààmú ńlá bá mi, n kò sì lè sọ̀rọ̀.

O lè máa rò pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ẹni tí kò níí ṣojora lábẹ́ irú ipò bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n eléyìí jú ọ̀ràn ṣíṣojora lásán lọ. Jẹ́ kí n ṣàlàyé ìdí rẹ̀.

Ìṣòro Ọ̀rọ̀ Sísọ Tí Mo Ní

Nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún 12, mo ṣubú, ìpalára sì bá orí, ọrùn, àti egungun ẹ̀yìn mi. Lẹ́yìn ìgbà náà, mo máa ń kólòlò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tàbí kí n ní ìṣòro láti sọ ọ̀rọ̀ jáde, ní pàtàkì àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn wóróhùn p, k, t, d, àti m. Nígbà míràn, n kì í tilẹ̀ lè sọ̀rọ̀ rárá.

Ìṣòro náà kò dà mí láàmú tó bẹ́ẹ̀ nígbà náà; ó wulẹ̀ dà bí ìdíwọ́ kékeré kan lásán ni. Ṣùgbọ́n bí ọdún tí ń gorí ọdún, sísọ̀rọ̀ níwájú àwùjọ olùgbọ́ ń bà mi lẹ́rù gidigidi. Mo dá kú lẹ́ẹ̀kan níbi tí mo ti ń jábọ̀ iṣẹ́ ìwádìí kan nílé ẹ̀kọ́. Nígbà míràn tí mo bá sì ń rajà, tí àwọn akọ̀wé ilé ìtajà bá béèrè ohun tí mo fẹ́, n kì í lè dá wọn lóhùn. Níbi tí mo bá sì ti dúró, tí mo ń tiraka láti sọ̀rọ̀, inú wọn á túbọ̀ ru sí i: “Ṣe kíá. N ò lè dúró máa fi gbogbo ọjọ́ ṣòfò. Àwọn oníbàárà míràn wà ní ìdúró.” Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, n kì í lè ra àwọn ohun tí mo nílò.

Àwọn ọdún ti mo lò nílé ẹ̀kọ́ le koko gan-an. Nígbà tí mo bá ní láti ṣe àwọn ìròyìn ọlọ́rọ̀ ẹnu, àwọn ẹlẹgbẹ́ mi máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí bí mo ṣe ń kólòlò. Síbẹ̀, mo jáde nílé ẹ̀kọ́ gíga, mo si lọ kẹ́kọ̀ọ́ ní yunifásítì kan ní Prague, Czechoslovakia, ní 1979. Níwọ̀n bí mo ti máa ń gbádùn eré sísá, mo lọ kọ́ ẹ̀kọ́ iṣẹ́ olùkọ́ eré ìdárayá. Ṣùgbọ́n báwo ni ọwọ́ mi ṣe lè tẹ góńgó ìlépa mi? Láìbìkítà fún iyè méjì, mo tẹ̀ síwájú.

Wíwá Ìrànwọ́ Kiri

Ọ̀nà kan gbọ́dọ̀ wà tí mo lè fi bọ́ lọ́wọ́ ìṣòro ọ̀rọ̀ sísọ tí mo ní. Nítorí náà, lẹ́yìn tí mo ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní yunifásítì, mo pinnu láti wá ìrànwọ́ àwọn amọṣẹ́dunjú. Mo wá ilé ìtọ́jú kan tí a ti máa ń ṣètọ́jú àwọn tí ó bá ní ìṣòro ọ̀rọ̀ sísọ kàn ní Prague. Nígbà ìfojúkojú àkọ́kọ́ gan-an ni olùtọ́jú aláìsàn kan ti jágbe mọ́ mi pé: “Àrà ọ̀tọ̀ ni àìṣiṣẹ́ déédéé ọpọlọ tìrẹ yìí!” Ó dùn mí wọra láti ronú pé ó kà mí sí ẹni tí ọpọlọ rẹ̀ kò ṣiṣẹ́ déédéé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ògbógi gbà pé ìkólòlò kì í ṣe ìṣòro àìṣiṣẹ́ déédéé ọpọlọ. Kò gba àkókò púpọ̀ láti mọ̀ pé mo dojú kọ ìpèníjà àrà ọ̀tọ̀ kan: mo jẹ́ ọ̀dọ́kùnrin ẹni ọdún 24, gbogbo àwọn olùgbàtọ́jú yòó kù sì jẹ́ àwọn ọmọ wẹ́wẹ́.

Láìpẹ́, gbogbo òṣìṣẹ́, títí kan afìṣemọ̀rònú, ń ṣiṣẹ́ láti ràn mí lọ́wọ́. Wọ́n gbìyànjú ohun gbogbo. Nígbà kan, wọ́n kì mí nílọ̀ láti má ṣe sọ̀rọ̀ sí ẹnikẹ́ni fún ọ̀sẹ̀ márùn-ún. Nígbà míràn kan, wọ́n gbà mí láyè láti máa sọ̀rọ̀ ní ohùn títẹ́ nìkan, tí ó sì falẹ̀ g-i-d-i-g-i-d-i. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà yìí ṣàǹfààní, ó tún mú kí n gba orúkọ Atujú Ejò, nítorí ọ̀pọ̀ ló máa ń sùn nígbà tí mo bá ń ròyìn àwọn ìwádìí mi.

Bíbá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Pàdé

Ní ọjọ́ kan nígbà ẹ̀ẹ̀rùn 1984, tí mo ń fẹsẹ̀ palẹ̀ lọ sí ìhà ìsàlẹ̀ ìlú, àwọn ọ̀dọ́kùnrin méjì kan sún mọ́ mi. Kì í ṣe ìrísí wọn ló ṣe mí ní kàyéfì, bí kò ṣe ohun tí wọ́n sọ. Wọ́n sọ pé Ọlọ́run ní ìṣàkóso kan, Ìjọba kan, tí yóò fòpin sí gbogbo ìṣòro aráyé. Wọ́n fún mi ní nọ́ḿbà fóònù wọn, mo sì tẹ̀ wọ́n láago lẹ́yìn náà.

A kò ka àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí lábẹ́ òfin gẹ́gẹ́ bí ètò ìsìn kan ní Czechoslovakia nígbà náà. Síbẹ̀, láìpẹ́ láìjìnnà, mo túbọ̀ lọ́kàn ìfẹ́ sí i tó bẹ́ẹ̀ ti mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ìpàdé wọn. Mo wulẹ̀ lè mọ ìfẹ́ àti àníyàn tí àwọn Ẹlẹ́rìí ní fún ẹnì kíní kejì lára.

Ọ̀nà sí Ìbàlẹ̀ Ọkàn

Ìrànwọ́ nípa ìṣòro ọ̀rọ̀ sísọ mi wá lọ́nà ohun tí a pè ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, ilé ẹ̀kọ́ kan tí a máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nínú gbogbo ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. A rọ̀ mí láti forúkọ sílẹ̀, mo sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìdámọ̀ràn tí a fúnni nínú ọ̀kan lára àwọn ìwé ilé ẹ̀kọ́ náà, Iwe-Amọna Ile Ẹkọ Iṣẹ Ojiṣẹ Ijọba Ọlọrun, mo ṣiṣẹ́ lórí irú àwọn ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ bíi yíyọ̀ mọ́ni lẹ́nu ọ̀rọ̀, pípe ọ̀rọ̀, ìtẹnumọ́ òye ọ̀rọ̀, àti yíyí ohùn padà nínú ọ̀rọ̀ sísọ.a

Ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ tí mo sọ gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́, tí ó jẹ́ Bíbélì kíkà, kùnà pátápátá. Ojora mú mi pátápátá, agbára káká ni mo sì fi padà délé. Ẹ wo bí mo ti kún fún ọpẹ́ tó nítorí ìtura tí mo ní nígbà tí mo fi omi gbígbóná ṣanra!

Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ yẹn, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ náà fún mi ní àfiyèsí ara ẹni, pẹ̀lú inú rere. Kì í ṣe kìkì pé ó fún mi ní ìmọ̀ràn tí ń mú nǹkan sunwọ̀n lásán ni, ṣùgbọ́n, ó gbóríyìn fún mi. Ìyẹn fún mi ní ìṣírí láti máa gbìyànjú sí i. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, ní 1987, mo di Ẹlẹ́rìí tí ó ti ṣèrìbọmi. Oṣù mélòó kan lẹ́yìn náà, mo kó kúrò ní Prague lọ sí ìlú kékeré Žďár nad Sázavou píparọ́rọ́. Àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí àdúgbò kékeré náà fi ọyàyà kí mi káàbọ̀. Wọ́n tún tẹ́wọ́ gba ìsọ̀rọ̀ mi tí ń kọsẹ̀ síbẹ̀síbẹ̀ náà, ìyẹn sì túbọ̀ fi kún ọ̀wọ̀ ara ẹni mi.

Bí àkókò ti ń lọ, mo bẹ̀rẹ̀ sí í darí àwùjọ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kékeré kan, mo sì sọ ọ̀rọ̀ àwíyé Bíbélì mi àkọ́kọ́. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, lẹ́yìn ìyípadà ìjọba ní Czechoslovakia, mo bẹ̀rẹ̀ sí í sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ní àwọn ìjọ àdúgbò. Lábẹ́ àwọn ipò tí kò wọ́pọ̀, ìṣòro ọ̀rọ̀ sísọ mi tún padà wá. Ṣùgbọ́n n kò bọ́hùn.

Kíkojú Àwọn Ìpèníjà Àrà Ọ̀tọ̀

Lọ́jọ́ kan, Kristẹni alàgbà kan ké sí mi wá síbi iṣẹ́ rẹ̀. Ó wí pé: “Petr, o jẹ́ mọ̀ pé mo ní ìròyìn rere fún ọ! A óò fẹ́ kí o kópa nínú àpéjọ àyíká tí ń bọ̀.” Mo nímọ̀lára àìlágbára, mo sì ní láti jókòó. Sí ìjákulẹ̀ ọ̀rẹ́ mi, mo kọ ìfilọni náà.

Kíkọ̀ tí mo kọ̀ yẹn máa ń wá sọ́kàn mi léraléra. N kò lè mú un kúrò nínú èrò inú mi. Nígbà àwọn ìpàdé Kristẹni, nígbàkúùgbà tí a bá ti mẹ́nu ba gbígbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, ó máa ń jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn fún mi láti rántí kíkọ̀ tí mo kọ̀ yẹn. Nínú àwọn ìpàdé, nígbà púpọ̀ ni a máa ń tọ́ka sí Gídéónì, ẹni tí ó lọ fi kìkì 300 ọkùnrin kojú odindi ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Mídíánì, lábẹ́ ìdarí Ọlọ́run. (Àwọn Onídàájọ́ 7:1-25) Ó jẹ́ ọkùnrin kan, tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run rẹ̀, Jèhófà, ní tòótọ́! Ǹjẹ́ mo ha ti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ti Gídéónì nígbà tí mo ń kọ iṣẹ́ àyànfúnni yẹn bí? Láìṣàbòsí, n kò lè sọ pé mo ti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó tì mí lójú.

Síbẹ̀, àwọn Kristẹni arákùnrin mi kò sọ̀rètí nù láti ràn mí lọ́wọ́. Wọ́n tún fún mi ní àǹfààní mìíràn. Wọ́n ké sí mi láti kópa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ àpéjọ àkànṣe kan. Lọ́tẹ̀ yìí, mo gbà. Bí mo ti kún fún ọpẹ́ fún àǹfààní yìí tó, kí n má fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, ìrònú bíbá àwùjọ ènìyàn tí ó kún inú gbọ̀ngàn kan sọ̀rọ̀ ń mú mi ṣojora. Ní ti gidi, mo ní láti ṣiṣẹ́ láti mú ìgbẹ́kẹ̀lé mi nínú Jèhófà pọ̀ sí i. Ṣùgbọ́n lọ́nà wo?

Nípa ṣíṣàgbéyẹ̀wò ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé tí àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn ti ní nínú rẹ̀ fínnífínní ni. Ṣíṣe èyí fún mi lágbára. Àní lẹ́tà kan tí ọmọ ọdún mẹ́fà tí ń jẹ́ Verunka, ọmọbìnrin ọ̀rẹ́ kan kọ, ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ rere kan fún mi. Ó kọ̀wé pé: “Ní September, mo ń lọ sílé ẹ̀kọ́. Èmi kò mọ bí ọ̀ràn orin ògo orílẹ̀-èdè yóò ti rí. Mo gbà gbọ́ pé Jèhófà yóò jà fún mi, bí ó ṣe jà fún Ísírẹ́lì.”

Tóò, ìwọ̀nyẹn jẹ́ díẹ̀ lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣamọ̀nà sí ìjókòó ọ̀sán ọjọ́ àpéjọ àkànṣe tí mo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀. Mo ti gbàdúrà kíkankíkan. Nísinsìnyí, n kò dàníyàn tó bẹ́ẹ̀ mọ́ nípa yíyọ̀ mọ́ni lẹ́nu ọ̀rọ̀ mi tó bí mo ṣe ń dàníyàn nípa yíyin orúkọ ńlá Ọlọ́run níwájú àwùjọ ńlá yìí.

Nítorí náà, mo dúró síbẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀rọ gbohùngbohùn tí a gbé kalẹ̀ níwájú mi, tí mo sì dojú kọ ọgọ́rọ̀ọ̀rún ènìyàn. Lẹ́yìn náà, ní mímọ̀ pé ìhìn iṣẹ́ náà ṣe pàtàkì ju òjíhìn rẹ̀ lọ, mo mí kanlẹ̀ dáradára, mo sì bẹ̀rẹ̀. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, mo ní àkókò láti díye lé àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Mo ha ṣojora bí? Dájúdájú, mo tilẹ̀ kólòlò nígbà mélòó kan pẹ̀lú. Síbẹ̀, mo mọ̀ pé n kì bá tí lè sọ̀rọ̀ rárá, bí kò bá sí ìtìlẹ́yìn Ọlọ́run ni.

Lẹ́yìn náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lórí ohun tí Kristẹni arákùnrin kan sọ fún mi nígbà kan rí pé: “Máa yọ̀ pé o ní ìṣòro ìkólòlò.” Nígbà tí ó sọ gbólóhùn yẹn, ó yà mí lẹ́nu ní ti gidi. Ó ṣe lè sọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀? Ní ríronú sẹ́yìn, mo wáá lóye ohun tí ó ní lọ́kàn nísinsìnyí. Ìṣòro ọ̀rọ̀ sísọ tí mo ní ti ràn mí lọ́wọ́ láti gbára lé Ọlọ́run kàkà tí ǹ bá fi gbára lé ara mi.

Ọdún mélòó kan ti ré kọjá lọ láti ọ̀sán ọjọ́ àpéjọ àkànṣe yẹn. La àwọn ọdún wọ̀nyí já, mo ti ní àwọn àǹfààní mìíràn láti sọ̀rọ̀ níwájú àwọn àwùjọ ńláńlá. A yàn mí gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni alàgbà kan ní Žďár nad Sázavou, àti gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà kan pẹ̀lú, bí a ti ń pe àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ronú nípa rẹ̀ ná! Nígbà náà, mo máa ń lò lé ní ọgọ́rùn-ún wákàtí lóṣooṣù, ní bíbá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run, kí a má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ nípa àkókò tí mo ń lò lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti kọ́ni nínú àwọn ìpàdé Kristẹni wa. Mo sì ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká nísinsìnyí, ní sísọ̀rọ̀ ní ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.

Ọkàn àyà mi wulẹ̀ ń kún fún ìmọrírì nígbàkúùgbà tí mo bá ń ka àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní pàtó nínú ìwé Aísáyà nínú Bíbélì pé: “Ahọ́n àwọn akólòlò yóò sọ̀rọ̀ kedere.” (Aísáyà 32:4; Ẹ́kísódù 4:12) Láìṣe àníàní, Jèhófà ti fẹ̀rí hàn pé òun wà pẹ̀lú mi, ní ríràn mí lọ́wọ́ láti ‘sọ̀rọ̀ kedere’ sí ọlá, ìyìn, àti ògo rẹ̀. Mo ní ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀ láti lè yin Ọlọ́run wa, aláàánú jù lọ.—Gẹ́gẹ́ bí Petr Kunc ṣe sọ ọ́.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́