Rọ́bà Kíkọ—Iṣẹ́ Kan Tí Ó Kan Ìgbésí Ayé Rẹ
Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyin Jí! ní Nàìjíríà
NÍ AGOGO márùn-ún òwúrọ̀, ẹgàn ilẹ̀ Nàìjíríà máa ń ṣókùnkùn, ó sì máa ń tutù nini. Nínú ilé alábàrá kan láàárín igbó náà, John jí, ó sì kó aṣọ rẹ̀ wọ̀. Lẹ́yìn náà, ó bọ́ sínú òkùnkùn náà, pẹ̀lú àtùpà kan, korobá oníke kan, àti ọ̀bẹ tí ẹnu rẹ̀ tẹ̀ kọdọrọ kan lọ́wọ́. Ní gbogbo wákàtí mẹ́rin tí ó tẹ̀ lé e, ó ń lọ láti ìdí igi kan sí òmíràn, tí ó ń kọ àwọn ilà gígùn tẹ́ẹ́rẹ́ àkọwálẹ̀ sára èèpo igi kọ̀ọ̀kan.
Àkọ́kọ́ nìyí lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ rẹpẹtẹ tí ó lè kan ìgbésí ayé rẹ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Nítorí pé àwọn igi tí John ń kọ lára náà jẹ́ igi rọ́bà. Rọ́bà tí ó ní agbára láti pa ohun tí a bá fi pẹ́ńsùlù kọ rẹ́ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun àmúṣọrọ̀ tí ó níye lórí jù lọ, tí a sì ń lò ní ọ̀nà púpọ̀ jù lọ.
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún Ohun Tí A Ń Fi Rọ́bà Ṣe
Ṣáà wulẹ̀ ronú lórí ipa tí rọ́bà ń kó nínú ìgbésí ayé rẹ. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé rọ́bà ni a fi ṣe ìtẹ̀lẹ̀ àti gìgíṣẹ bàtà rẹ. Ó lè jẹ́ pé ìfóòfó rọ́bà la fi ṣe ẹ̀yin kápẹ́ẹ̀tì àti ìjókòó rẹ. Bóyá rọ́bà ni a fi ṣe rọ́bà tí ń ràn nínú aṣọ rẹ. Nígbà tí òjò bá ń rọ̀, o lè nawọ́ gán aṣọ òjò àti bàtà àwọ̀dórúnkún tí a fi rọ́bà ṣe. Ṣé o fẹ́ẹ́ lọ lúwẹ̀ẹ́ ni? Àwọn aṣọ ìlúwẹ̀ẹ́, awò ojú, àti lẹbẹ ìlúwẹ̀ẹ́ ní rọ́bà nínú. Ìwọ kò fẹ́ẹ́ lúwẹ̀ẹ́? Bóyá yóò wù ọ́ pé kí o wulẹ̀ máa léfòó lójú omi pẹ̀lú agbéniléfòó onírọ́bà tàbí kí o máa gbá bọ́ọ̀lù onírọ́bà létíkun. Nínú ilé rẹ, àwọn ohun ìdiǹkan onírọ́bà, àwọn ìpàwérẹ́ onírọ́bà, àti àwọn àtè onírọ́bà wà káàkiri. Nígbà tí o bá sùn lálẹ́ òní, ó ṣeé ṣe kí o sùn lórí tìmùtìmù àti ìrọ̀rí tí a fi nǹkan onírọ́bà ṣe. Bí òtútù bá ń mú ọ, o lè gbá ìrọmi gbígbóná tí a fi rọ́bà ṣe mọ́ra.
Yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ohun wọ̀nyẹn, ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan ni ó dájú pé kì yóò ṣiṣẹ́ dáradára láìsí àwọn ẹ̀yà ara onírọ́bà—àwọn wọ́ṣà, àwọn bẹ́líìtì ẹ̀rọ, àwọn ìbòrí onírọ́bà, àwọn páìpù onírọ́bà, àwọn ọ̀pá ẹ̀rọ ìtẹ̀wé onírọ́bà, tàbí àwọn páìpù oníhò. Fún àpẹẹrẹ, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ abọ́ọ́dé kan ń ní nǹkan bí 600 ẹ̀yà ara onírọ́bà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia ṣe sọ, lápapọ̀, a ń ṣe àwọn nǹkan onírọ́bà tí iye wọ́n wà láàárín 40,000 sí 50,000.
Kí ló mú kí rọ́bà wúlò tó bẹ́ẹ̀? Ó máa ń pẹ́ kí ó tóó jẹ tán, ooru kò ràn án, ó máa ń ràn, omi kò rí i gbé ṣe, afẹ́fẹ́ kò lè wọ̀ ọ́, ó sì rára gba ìtẹ̀lọtẹ̀bọ̀ sí. Ṣàgbéyẹ̀wò táyà, ì báà jẹ́ ti kẹ̀kẹ́, ti ọkọ̀ ìrìnnà, tàbí ti ọkọ̀ òfúúrufú. Nítorí pé rọ́bà ni, táyà kì í yára jẹ nítorí ìfarakanra ìgbà gbogbo pẹ̀lú títì, bẹ́ẹ̀ ni ìfarahara kì í mú un jó. Bí o bá ń wakọ̀ lọ ní ilẹ̀ ẹlẹ́rọ̀fọ̀, kò sí ìdí fún ọ láti bẹ̀rù pé táyà yóò mumi yó, yóò sì jẹrà; bẹ́ẹ̀ ni kò níí jẹ pẹ̀lú. Kì í ṣe pé rọ́bà kì í jẹ́ kí omí wọ táyà nìkan ni, ṣùgbọ́n kò tún ń jẹ́ kí afẹ́fẹ́ tí a sé mọ́ inú lóhùn-ún jò jáde. Ní àfikún sí i, bí o ti ń lọ, ìtóótun rọ́bà tí a fi ṣe táyà rẹ láti rára gba ìtẹ̀lọtẹ̀bọ̀ sí gbà ọ́ lọ́wọ́ ìwọkòtò wọ gegele ojú títì. Ní ti gidi, láìsí rọ́bà, àwọn olùṣèmújáde yóò ní ìṣòro gidigidi láti ṣe táyà jáde.
Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kí o gbà pé àwọn tí ń kọ rọ́bà bíi John ń ṣe iṣẹ́ kan tí ó wúlò gidigidi, tí ó sì ń kan ìgbésí ayé wa lọ́nà rere. Àmọ́ ṣá, kì í ṣe gbogbo rọ́bà ní ń wá láti ara igi. Rọ́bà àtọwọ́dá, tí a ń fi àwọn kẹ́míkà ṣe, ń kó ìpín púpọ̀ nínú iṣẹ́ rọ́bà. Oríṣi rọ́bà méjèèjì ní àǹfààní àti ìkùdíẹ̀káàtó tiwọn. Ọ̀pọ̀ àwọn ohun àṣemújáde ni a lè fi èyíkéyìí wọn ṣe, yíyàn náà sì sinmi lórí iye owó tí a lè rí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn rá lọ́jà lákòókò náà. A ń fi àpòpọ̀ rọ́bà àtọwọ́dá àti ti àdánidá ṣe àwọn ohun àṣemújáde mìíràn. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn táyà ohun ìrìnnà ń ní rọ́bà àtọwọ́dá púpọ̀ nínú ju rọ́bà àdánidá lọ. Bí ó ti wù kí ó rí, nítorí pé àtọwọ́dá kò lẹ́mìí ooru púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀, a ń lo ìpín púpọ̀ jù lọ rọ́bà àdánidá nínú àwọn táyà ọkọ̀ eré ìje, ọkọ̀ akẹ́rù, bọ́ọ̀sì, àti ọkọ̀ òfúúrufú.
Kíkọ Igi Rọ́bà
Àwọn igi rọ́bà máa ń hù dáradára ní ibi ojú ọjọ́ tútù, ilẹ̀ olóoru, nítòsí ìlàjì ayé. Púpọ̀ gan-an lára rọ́bà àdánidá lágbàáyé ń wá láti àwọn oko rọ́bà ní Ìlà Oòrun Gúúsù ilẹ̀ Éṣíà, ní pàtàkì, Malaysia àti Indonesia. Àwọn yòó kù ń wá láti Gúúsù America, pẹ̀lú Ìwọ̀ Oòrùn àti Àárín Gbùngbùn Áfíríkà.
John kì í kọ igi tí kò bá tó ọdún mẹ́fà. Lẹ́yìn ìyẹn, igi náà yóò máa mú rọ́bà jáde fún ọdún 25 sí 30 tí ó tẹ̀ lé e, yóò sì ga tó nǹkan bí 20 mítà. Nígbà tí igi rọ́bà náà bá ti “fẹ̀yìn tì” lẹ́nu mímú rọ́bà jáde, ó lè máa dàgbà sí i, kí ó ga tó 40 mítà, ó sì lè wà láàyè, kí ó gbó tó 100 ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Rọ́bà tí a bá ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ lára igí máa ń dà bíi wàrà, kì í ṣe bíi táyà ọkọ̀. Ohun tí ó dà bíi wàrà yìí, tí a ń pè ní oje rọ́bà ní àwọn ẹ̀rún rọ́bà wẹ́wẹ́ nínú. Nǹkan bí ìpín 35 nínú ọgọ́rùn-ún oje náà ni rọ́bà. Gbogbo èyí tó kù fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ omi lásán.
Láti kọ oje náà, John ń kọ ilà tẹ́ẹ́rẹ́ wá sílẹ̀ lára èèpo igi náà. Ilà yìí máa ń gba ìdajì òbírí igi náà. Ó ń ṣọ́ra kí ó má kọ ọ́ wọnú jù, níwọ̀n bí ìyẹn yóò ti ba igi náà jẹ́. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ti a bá ti kọ ọ́ ni oje náà ń bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàn; ó ń ṣàn gba ojú ihò ilà tí a kọ náà, ó sì ń dà sínú ife ọlọ́parun ti John ti so rọ̀ mọ́ ara igi náà. Ó máa ń ṣàn bẹ́ẹ̀ fún wákàtí méjì tàbí mẹ́ta; lẹ́yìn náà ni ó máa ń dúró.
Ní ọjọ́ kan tàbí méjì lẹ́yìn náà, nígbà tí John bá tún ń kọ igi náà, yóò tún kọ ìlà míràn ní gẹ́rẹ́ ìsàlẹ ti àkọ́kọ́. Abẹ́ ìyẹn ni yóò tún kọ sí nígbà míràn. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, yóò ti kọ ojú ihò fífẹ̀ kan kúrò lára èèpo igi náà. Nígbà yìí ni John yóò tún bẹ̀rẹ̀ sí í kọ apá mìíràn lára igi náà, tí yóò sì fi ojú ihò náà sílẹ̀ láti tún dí, kí ó sì ṣeé kọ lọ́jọ́ iwájú.
John máa ń yára ṣiṣẹ́ gan-an ni, tí ó máa ń dá lọ nínú igbó píparọ́rọ́ náà, tí ó ń kọ àwọn igi náà kí oje wọ́n lè ṣàn. Lẹ́yìn náà, yóò tún lọ sídìí igi kọ̀ọ̀kan, yóò sì da oje tí ó ti ṣàn jọ náà sínú korobá rẹ̀. Lẹ́yìn náà, John yóò fi èròjà formic acid àti omi sí oje náà. Èyí ń mú kí ó nípọn kí ó sì dì pọ̀ bí ọtí kíkan ti ń dì pọ̀ mọ́ wàrà. John yóò wáá fi orí ru korobá oje rọ́bà náà lọ sí etí títì, níbi tí ọkọ̀ akẹ́rù ilé iṣẹ́ aṣerọ́bà kan ti ń kó o.
Nígbà yìí ni John yóò wáá darí relé lọ wẹ̀, kí ó jẹun, kí ó sì sinmi. Ní ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, nígbà tí ó bá tún jáde nílé lẹ́ẹ̀kan sí i, ìmúra rẹ̀ ń mọ́ nigínnigín, ó sì ń fa àpò kan lọ́wọ́ rẹ̀. Nígbà yìí, kì í lọ láti ìdí igi kan sí òmíràn, ṣùgbọ́n ó ń lọ láti ilé dé ilé. Gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà alákòókò kíkún, John ń nípìn-ín kíkún nínú iṣẹ́ ìwàásù àti ìsọni di ọmọ ẹ̀yìn.
Bí John ṣe ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀ àkọ́kọ́ fún ọjọ náà, oje tí ó kọ yóò ti dé ilé iṣẹ́ aṣerọ́bà. Níbẹ̀ ni wọn yóò ti yọ rọ́bà náà kúrò lára omi, tí wọn yóò gbẹ ẹ́, tí wọn yóò sì kì í pọ̀ di òkìtì ẹrù fún ọkọ̀ láti kó. Láìpẹ́, yóò wà lójú ọ̀nà sí England, Japan, tàbí United States. Ilé iṣẹ́ rọ́bà àdánidá kárí ayé ń pèse rọ́bà tí ó ju mílíọ̀nù márùn-ún tọ́ọ̀nù lọ lọ́dọọdún. Bí ó tilẹ̀ lè máà rí bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kí rọ́bà tí a fi ṣe àtẹ́sẹ̀ bàtà tí o tún máa ní láìpẹ́ wá láti ara igi tí John kọ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
John níbi tí ó ti ń kọ rọ́bà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
John ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni