Ilé Ìwòran Orin Aláré Nínú Igbó Kìjikìji
Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyìn Jí! ní Brazil
BÍ A ti ń wò láti ojú fèrèsé ọkọ̀ òfuurufú, a rí odò méjì tí ń ṣàn lọ pàdé ara wọn—Solimões aláwọ̀ ìyeyè ràkọ̀ràkọ̀ àti Negro aláwọ̀ ẹrẹ̀. Nígbà tí wọ́n pàdé, wọ́n kọ̀ láti lú mọ́ra pátápátá àyàfi lẹ́yìn kìlómítà mẹ́wàá sísàlẹ̀ odò. Níbì kan tí kò jìnnà, ọkọ̀ òfuurufú náà balẹ̀ sí Manaus, olú ìlú Ìpínlẹ̀ Amazonas ní Brazil.
Àwọn ènìyàn Manaus sọ pé: “A máa ń ní ìgbà méjì níhìn-ín. Òjò máa ń rọ̀ lójoojúmọ́, tàbí láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.” Àmọ́ òjò náà kì í dí àwọn 1.5 mílíọ̀nù olùgbé ibẹ̀ lọ́wọ́ láti fò jàn-án-jàn-án kiri ní ìlú ńlá tí ohun yíyàtọ̀síra wà yí. Bí a ti ń kọjá níwájú àwọn ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ onímọ̀ gíga ní àwọn òpópónà ńláńlá àti níwájú àwọn ilé àti àwọn ilé gbéetán ní àwọn òpópónà olókè, kò pẹ́ tí a kó sínú sún-kẹrẹ-fà-kẹrẹ ọkọ̀ ní àárín ìlú ńlá náà, níbi tí àwọn ilé àwòṣífìlà àti àwọn ohun ìrántí gígalọ́lá ti gba àfiyèsí. A lè rí ìdí tí ó fi jẹ́ pé nígbà kan rí, a ń pe Manaus ní Paris inú igbó kìjikìji. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ilé rírẹwà kan gba àfiyèsí pàtàkì—ilé ìwòran orin aláré.
Olùdarí ilé ìwòran náà, Inês Lima Daou, sọ pé: “Àwọn ilé ìwòran orin aláré wà ní ibi púpọ̀, àmọ́ Teatro Amazonas yàtọ̀. Ó dá wà ní ibi jíjìnnà réré.” Báwo ni ilé ìwòran tí ó fi ẹwà ṣọlá bẹ́ẹ̀ ṣe dé àárín igbó kìjikìji tí ó tóbi jù lọ lágbàáyé?
Ọ̀rọ̀ Ti Rọ́bà
Ní 1669, Ọ̀gákọ̀ Francisco da Mota Falcão, ará Potogí, ṣàwárí igbó kìjikìji kan tí a sọ ní Fortaleza de São José do Rio Negro. Lẹ́yìn yíyí orúkọ rẹ̀ pa dà nígbà bíi mélòó kan, ní 1856, wọ́n tún sọ ọ ní Manaus, orúkọ àwọn ẹ̀yà Ámẹ́ríńdíà kan ládùúgbò, tí wọ́n ń pè ní Manáos. Nígbà tí ó di 1900, àwọn 50,000 ènìyàn ti rọ́ lọ sí Manaus. Kí ló fa àwọn èrò náà mọ́ra? Igi Hevea brasiliensis, tàbí igi rọ́bà, tí ń hù ní àgbègbè Amazon.
Àwọn agbókèèrè-ṣàkóso láti ilẹ̀ Potogí ṣàkíyèsí pé àwọn Ámẹ́ríńdíà ń fi àwọn bọ́ọ̀lù wíwúwo, tí wọ́n fi oje tí wọ́n kọ lára àwọn igi náà ṣe, ṣeré. Bí àkókò ti ń lọ, àwọn agbókèèrè-ṣàkóso náà rí ọ̀nà míràn tí wọ́n lè gbà lo ohun olómi kíki náà. Ní 1750, Ọba Dom José ti Potogí máa ń fi àwọn bàtà aláwọ̀tán rẹ̀ ránṣẹ́ sí Brazil pé kí wọ́n ṣe é lọ́nà tí yóò fi máa ta omi dà nù. Nígbà tí ó fi di 1800, Brazil ti ń kó bàtà rọ́bà lọ tà ní New England ní Àríwá America. Síbẹ̀síbẹ̀, àwárí lílẹ rọ́bà tí Charles Goodyear ṣe ní 1839 àti ẹ̀tọ́ oníǹkan ti John Dunlop lórí táyà tí a fẹ́ afẹ́fẹ́ sínú rẹ̀ ní 1888 súnná sí ‘ìsárélé rọ́bà.’ Ayé ń béèrè fún rọ́bà.
Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, àwọn ará Brazil tí wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 200,000 ń ṣiṣẹ́ bíi seringueiro, tàbí akọrọ́bà, tí ń kọ 80 mílíọ̀nù igi rọ́bà tí wọ́n wà káàkiri igbó kìjikìji tí ó wà lágbègbè Manaus.
Àwọn ọdún tí ọrọ̀ ń ti àwọn ènìyàn gọ̀ọ́gọ̀ọ́ náà mú kí iná mànàmáná, tẹlifóònù, àti ọkọ̀ ojú irin wọ ìlú—àkọ́kọ́ ní Gúúsù America. Àwọn mọ́gàjí nínú òwò rọ́bà náà kọ́ àwọn ilé ńláńlá, wọ́n sì ń tẹ́ aṣọ tí ó wá láti Ireland sórí tábìlì ìjẹun, àwọn ìdílé wọn sì ń rìnrìn àjò lọ sí Europe léraléra láti gbádùn àṣà ìbílẹ̀ ibẹ̀—títí kan orin aláré. Kò pẹ́ kò jìnnà, wọ́n fẹ́ láti ní irú àwọn ilé ìwòran orin aláré tó wà ní Europe.
Gbígbé Díẹ̀ Lára Ohun Tó Wà Ní Europe Wá
Àlá náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ ní 1881, nígbà tí ìlú ńlá náà yan ilẹ̀ kan lórí òkè kan tí ó wà láàárín àwọn odò méjì tí ń ṣàn wọnú odò ńlá kan, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ṣọ́ọ̀ṣì kan, tí igbó sì yí i ká. Lẹ́yìn náà, àwọn ọkọ̀ òkun tí a di àwọn ohun èlò ìkọ́lé sí gba orí Òkun Àtìláńtíìkì, wọ́n sì rin 1,300 kìlómítà sí i gba Odò Amazon dé Manaus.
Àmọ́, gbọ́ ná! Kí ló dé tí ilé tuntun ọlọ́rọ̀ ìtàn yí fi ní òrùlé rìbìtì? Lóòótọ́, kò sí lára ìdáwọ́lé àtètèkọ́ṣe náà, àmọ́ ọ̀kan lára àwọn onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ náà lọ síbi ìpàtẹ ọjà kan ní ilẹ̀ Faransé, ó rí òrùlé rìbìtì kan, ó nífẹ̀ẹ́ sí i, ó sì rà á. Wọ́n fi nǹkan bí 36,000 àwo ìbolé aláwọ̀ ewéko àti aláwọ̀ ìyeyè tí ó wá láti Germany ṣe òrùlé rìbìtì náà lọ́ṣọ̀ọ́.
Gbọ̀ngàn àpéjọ rẹ̀ tí ó ní ìrísí pátákò ẹṣin ní àyè tí ó gba 700 àga tí a fi pankẹ́rẹ́ ṣe ẹ̀yìn rẹ̀, tí a kó sí ilẹ̀ẹ́lẹ̀, àga 12 wà ní ibi ìjókòó àwọn òṣìṣẹ́, àga 5 sì wà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn 90 ibi ìjókòó ọlọ́lá, tí ó wà ní àkọ́yọ àjà lókè kẹta. Láti lè gba àyè sí àwọn ibi ìjókòó ọlọ́lá, àwọn ìdílé ọlọ́rọ̀ fi agọ̀ 22 tí ó wá láti ilẹ̀ Gíríìsì ṣètọrẹ, èyí tí wọ́n gbé sókè àwọn òpó láti fọlá fún àwọn ará Europe tí ń ronú ṣàkọsílẹ̀ orin, àwọn akọrin, àti àwọn tí ń kọ eré.
Ìmọ́lẹ̀ tí ó wà nínú ilé ìwòran orin aláré náà mú kí ó jẹ́ ohun àfihàn kan. Iná onídẹ alásokọ́ ràgàjì kan tí wọ́n ṣe ní ilẹ̀ Faransé, tí a sì fi ìgò tí ń dán gbinrin kan láti Ítálì ṣe lọ́ṣọ̀ọ́, wà láàárín gbọ̀ngàn àpéjọ náà. A lè sún un sísàlẹ̀ láti pààrọ̀ àwọn gílóòbù rẹ̀ àti láti nù ún. Àwọn iná 166 onídẹ náà tí wọ́n ní 1,630 ìbòrí onígíláàsì tó ní ìrísí òdòdó tulip náà mú kí ara ògiri rẹ̀ sunwọ̀n sí i, ó sì mú kí àwọn àwòrán náà máa dán yanran.
Crispim do Amaral, ọmọ ilẹ̀ Brazil, tí ń gbé ní Paris, tí ó sì kàwé ní Ítálì, tí ó máa ń ya àwòrán ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, mú ohun ìyàwòrán rẹ̀ lọ sí òkè àjà ilé náà, ó sì ya àwòrán àwọn ìran mẹ́rin—orin aláré, ijó, orin, àti ọ̀ràn ìbìnújẹ́. Ó ṣàṣeyọrí ní kíkóni nígàn-án pé ènìyàn wà lábẹ́ Ilé Gogoro Eiffel. Lára aṣọ ìkélé orí pèpéle náà, ó ya àwòrán ṣíṣàrà-ọ̀tọ̀ kan—ibi tí àwọn odò méjì tí ó di Amazon ti pàdé. Aṣọ ìkélé tí ó ti pé 100 ọdún náà kì í ká, àmọ́ ó máa ń gbéra lọ sókè sínú òrùlé rìbìtì náà—èyí dín bí ó ṣe lè bà àwòrán tí ó ya náà jẹ́ tó kù.
Iyàrá ijó ńlá wà ní àjà kejì ilé náà, níbi tí dígí onígò gíga kan tí ń dán gbinrin láti ilẹ̀ Faransé ń fi àwọn iná alásokọ́ 32 láti Ítálì hàn ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì. Ìdányanran náà tànmọ́lẹ̀ sára àwòrán ẹranko àti ewéko inú Amazon tí ọmọ Ítálì tí ń ya àwòrán náà, Domenico de Angelis, yà. Fún ìrísí tí ó níyì, wọ́n fi sìmẹ́ǹtì rẹ́ òpó àwọn irin tí a ṣe, wọ́n sì yà wọ́n kí wọ́n lè rí bíi mábìlì. Tí o bá fi ọwọ́ gbá àwọn irin ibi àkọ́yọ tí ó ní ìrísí mábìlì náà; pákó ni wọ́n. Ilẹ̀ tí a dán náà ni a ṣe lọ́nà ti àwọn ará Faransé, 12,000 igi tí a tò pọ̀ láìlo ìṣó tàbí àtè. Ohun kan ṣoṣo tí ó wá láti Brazil níbẹ̀ ni àwọn igi tí a fi ṣe ilẹ̀, àpótí, àti àwọn tábìlì. A lè finú wòye pé olúkúlùkù ènìyàn tó wà níbẹ̀ lára yóò tù—wọn óò sì fara balẹ̀. Fara balẹ̀ nítorí kí ni?
Àwọn ògbóǹkangí kọ́lékọ́lé ti tẹ́ àwọn òkúta pèpéle àwọn àdúgbò tí ó yí ilé ìwòran náà ká sínú ohun olóje kan tẹ́lẹ̀ rí. Èyí ń fọgbọ́n dín ariwo tí àwọn ọmọlanke tí ẹṣin àwọn apẹ́lẹ́yìn ń fà kù. Ó tún jẹ́ kí a lè ṣí àwọn ilẹ̀kùn sílẹ̀ kí atẹ́gùn ba lè fẹ́ gba àárín àwọn àga tí a fi pankẹ́rẹ́ ṣe ẹ̀yìn wọn wọlé láti lè fúnni ní ìtura díẹ̀ lọ́wọ́ ooru.
Láti Ṣanpéènì Ríru Gùdù sí Ohun Atọ́ka Ìṣẹ̀lẹ̀ Ibi
Ní alẹ́ ọjọ́ tí wọ́n ṣí ilé ìwòran orin aláré náà ní 1896, ṣanpéènì ń tú jáde láti inú àwọn ìsun omi tí ó wà níwájú rẹ̀ bí àwọn ilẹ̀kùn náà ṣe ṣí. Iṣẹ́ náà gbà wọ́n ní ọdún 15, ó sì ná wọn ní mílíọ̀nù 10 dọ́là. Ilé alárinrin fún àwọn ohùn alárinrin ló jẹ́. Nípasẹ̀ àwọn akọrin láìlégbè fún ọdún náà àti ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ àwọn òṣèré láti Ítálì, ilẹ̀ Faransé, Potogí, àti Sípéènì wá láti ṣeré La Bohème tí Puccini kọ àti Rigoletto àti Il Trovatore tí Verdi kọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àrùn ilẹ̀ olóoru bí àrùn onígbáméjì, ibà, àti ibà pọ́njú lé àwọn òṣèré kan sá, ohun mìíràn tí ó halẹ̀ mọ́ ilé ìwòran náà yọjú—òpin ìbúrẹ́kẹ́ rọ́bà. Ohun atọ́ka ìṣẹ̀lẹ̀ ibi rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí Manaus.—Wo àpótí náà, “Ìjígbé Tí Ó Dáwọ́ Ìbúrẹ́kẹ́ Rọ́bà àti Orin Aláré Náà Dúró.”
Ní 1923, ìdájẹgàba lórí rọ́bà ilẹ̀ Brazil dòfo. Àwọn ènìyàn jàǹkànjàǹkàn, àwọn alásọtẹ́lẹ̀, àwọn oníṣòwò, àti àwọn aṣẹ́wó kó ẹrù wọn, wọ́n sì fi ìlú náà sílẹ̀ bíi mànàmáná, èyí sì sọ Manaus di àgbègbè onígbó kíkún tí ó rẹ̀yìn. Ilé ìwòran orin aláré náà ńkọ́? Àwọn ilé tí a kọ́ mọ́ ilé ìwòran náà wá di ibi tí a ń kó rọ́bà pa mọ́ sí, wọ́n sì ń lo orí pèpéle náà fún eré àṣedárayá bọ́ọ̀lù títa lórí ohun pẹrẹsẹ!
Àwọn Àkókò Ológo Tún Dé
Lẹ́yìn náà, Manaus yí pa dà di ibi tí àwọn arìnrìn-àjò tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ nínú àjọṣepọ̀ àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn, tí wọ́n wá láti ṣàwárí àwọn ohun àràmàǹdà inú igbó kìjikìji náà, ti ń bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Àwọn mìíràn wá lo ọjọ́ bíi mélòó kan láti nírìírí mímú ejò dání, láti fi oúnjẹ bọ́ ayékòótọ́ kan, tàbí láti fi ọwọ́ lu ẹrankọ sloth pẹ́pẹ́. Mímú ilé ìwòran orin aláré náà pa dà bọ̀ sípò yóò sọ Manaus di ibi dídánilọ́rùn tí ń fani mọ́ra yíyàtọ̀ kan!
Nítorí náà, ní 1974, àtúnṣe olówó gọbọi kan dé bá ilé ìwòran náà láti mú kí ọ̀nà ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àtètèkọ́ṣe máa wà bẹ́ẹ̀ nìṣó àti láti mú ọ̀nà ìkọ́lé rẹ̀ sunwọ̀n sí i. Wọ́n nu àwọn iná, dígí, àti àwọn ohun ọ̀ṣọ́ ilé. Àwọn amọṣẹ́dunjú gbé ẹ̀rọ kan kalẹ̀ láti máa gbé àyè ọ̀wọ́ àwọn akọrin tí ń lo ohun èlò orin sókè sódò. Wọ́n ṣe ilẹ̀ pèpéle tuntun, wọ́n sì ṣe ohun èlò orin, iná, àti ohun ẹ̀rọ fídíò tuntun sí ọwọ́ ẹ̀yìn pèpéle. Wọ́n ṣe ẹ̀rọ amúlétutù sí ilé ìsàlẹ̀ lábẹ́ àwọn àga.
Lẹ́yìn náà ẹgbẹ́ akọrin tí ń lo ohun èlò orin láti kọ orin olóhùn ṣíṣọ̀kan láti Rio de Janeiro kó àṣà ìbílẹ̀ pa dà wá sí ilé ìwòran náà. Lẹ́yìn náà, Margot Fonteyn, olókìkí oníjó alálọ̀ọ́yípo gbé pèpéle náà lárugẹ nípa jíjó ijó Swan Lake, ó sì fi bàtà ijó alálọ̀ọ́yípo rẹ̀ sílẹ̀ fún àfihàn ní ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí ti ilé ìwòran náà.
Láti mú kí ó túbọ̀ dẹrùn, kí ó lẹ́wà, kí ó sì láàbò, ó pọn dandan láti ṣe àwọn àtúnṣe síwájú sí i. Lẹ́yìn ìwádìí púpọ̀ àti ìwéwèé àfìṣọ́raṣe, àwọn 600 òṣìṣẹ́ àti 30 oníṣẹ́ ọwọ́ ń rọ́ lọ sí ilé ìwòran náà fún ọdún mẹ́rin. Wọ́n rí àwọ̀ rose àtètèkọ́ṣe náà lábẹ́ ìpele ọ̀dà oríṣi mẹ́jọ. Iwájú òrùlé rìbìtì náà nílò àtúnṣe. Wọ́n yọ àwọn ègé amọ̀ pẹlẹbẹ ti tẹ́lẹ̀ kúrò. Wọ́n fi ègé amọ̀ pẹlẹbẹ tuntun jíjọra, tí wọ́n ṣe ní Brazil, rọ́pò wọn. Wọ́n fi àrán pupa tuntun láti ilẹ̀ Faransé bo àwọn àga ibẹ̀. Wọ́n lo ọ̀bẹ tín-ín-rín kékere àti búrọ́ọ̀ṣì ìkunlé láti tún àwọn iṣẹ́ ọnà ṣíṣẹlẹgẹ́ àti àwọn àwòrán ibẹ̀ ṣe. Ó dunni pé, ọ̀rinrin ti ba iṣẹ́ ọnà tí ó wà ní àwọn ọ̀dẹ̀dẹ̀ rẹ̀ jẹ́, nítorí náà, wọ́n yan aṣọ ṣẹ́dà aláwọ̀ àdàlú búlúù òun àwọ̀ ewéko tí ó wá láti China láti bo àwọn igi palaba. Síwájú sí i, ikán ti bo àwọn òpó onígi àti àkọ́yọ ilé náà. Láti kápá wọn, wọ́n da 3,640 gálọ̀nù oògùn apakòkòrò sínú igi náà.
Ní 1990, a tún gbọ́ àwọn ohùn alárinrin nínú ilé alárinrin kan. Àwọn orin aládùn oníròó ohùn tín-ín-rín láti Brazil tí Celine Imbert kọ àti àkọ́sórí orin piano tí Nelson Freire kọ sọ ilé ìwòran náà di olókìkí.
Ṣé ìró agogo nìyẹn? Bẹ́ẹ̀ ni, agogo tó ń wí fún wa pé eré yóò bẹ̀rẹ̀ ní ìṣẹ́jú márùn-ún sí àsìkò náà.
Olùdarí ilé ìwòran náà, Daou, sọ pé: “Láti ṣayẹyẹ 100 ọdún Teatro Amazonas, a ké sí olókìkí olóhùn gbẹ̀du náà, José Carreras, láti wá. Ó dán àwọn ìgbì ohùn orin rẹ̀ wò, (‘wọ́n sì wà ní pípé’).” Ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà wá sópin pẹ̀lú ijó nínú iyàrá ijó. Àjọyọ̀ náà ń bá a lọ pẹ̀lú ìbẹ̀wò tí olùdarí orin náà, Zubin Mehta, ṣe síbẹ̀, olóhùn gbẹ̀du náà, Luciano Pavarotti, àti ẹgbẹ́ eléré kan láti Ajẹntínà, tí wọ́n ṣe eré orin aláré adùnyùngbà náà, Carmen.
Agogo tí ń sọ fún wa pé, ó ku ìṣẹ́jú mẹ́ta nìyẹn. Yóò dára kí a jókòó.
Ní gbogbo ọjọ́ náà, àwọn 60 òṣìṣẹ́ ti ń lọ sókè sódò lẹ́yìn ìtàgé láti múra sílẹ̀ fún eré náà. Wọn óò sì ní eré púpọ̀ láti ṣètò fún—orin jazz, àwọn eré ìbílẹ̀, àti àwọn eré orí ìtàgé. Àmọ́ ijó alálọ̀ọ́yípo ni ti alẹ́ yìí.
Agogo tí ń sọ fún wa pé, ó ku ìṣẹ́jú kan lù. Ó di wẹ́lo.
Nítorí náà, ìgbà wo ni ìwọ ń bọ̀ ní ilé ìwòran orin aláré tí ó wà nínú igbó kìjikìji náà?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ìjíǹkangbé Tí Ó Dáwọ́ Ìbúrẹ́kẹ́ Rọ́bà àti Orin Aláré Náà Dúró
Ní 1876, Henry Wickham, ọ̀dọ́ ọmọ ilẹ̀ England kan, tí ó jẹ́ amúniṣèjẹ, hùmọ̀ ìwà jìbìtì kan tí ó ba ìbúrẹ́kẹ́ rọ́bà ilẹ̀ Brazil jẹ́. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn Ámẹ́ríndíà, ó “jí” 70,000 irúgbìn Hevea brasiliensis kéékèèké níníyelórí jù lọ, tí ó kó jọ láti inú igbó kìjikìji Amazon, “gbé,” ó dì wọ́n sínú ọkọ̀ eléèédú kan, ó sì yọ́ gbé wọn kọjá àwọn aṣọ́bodè Brazil láìlófin lábẹ́ ìdíbọ́n pé wọ́n jẹ́ “àpẹẹrẹ irúgbìn ṣíṣọ̀wọ́n fún Ayaba Victoria.” Ó ṣètọ́jú wọn nínú ọkọ̀ tí ń la Àtìláńtíìkì kọjá náà, ó sì ṣètọ́jú wọn nínú ọkọ̀ ojú irin àkànṣe kan tí ó háyà lọ sí àwọn ibi ìtọ́jú irúgbìn ti Ọgbà Irúgbìn Aláyélúwà ní Kew, England, níbi tí àwọn irúgbìn náà ti hù ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn náà. Láti ibẹ̀, ó kó wọn lọ sí Éṣíà, ó sì gbìn wọ́n sí ilẹ̀ àbàtà ní Ceylon àti níbi Ìyawọlẹ̀ Omi Malay. Nígbà tí ó di 1912, àwọn irúgbìn tí wọ́n jí gbé náà ti dàgbà di oko ọ̀gbìn rọ́bà tí kò lárùn, nígbà tí àwọn igi wọ̀nyẹn sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèmújáde oje, orísun ìsọfúnni kan sọ pé, “ìbúrẹ́kẹ́ rọ́bà ní Brazil [ti forí ṣánpọ́n] títí lọ fáàbàdà.”
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 14]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Manaus
[Credit Line]
Mountain High Maps® Copyright © 1995 Digital Wisdom, Inc.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Àwọn odò méjèèjì kò lú mọ́ra
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Òrùlé rìbìtì ilé ìwòran náà—ohun ìjúwe kan tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ilé tí ó fi ẹwà ṣọlá nínú igbó kìjikìji
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ó tún pa dà di ilé alárinrin kan lẹ́ẹ̀kan sí i