ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 5/22 ojú ìwé 11-13
  • Mo Ti Rí Ọ̀pọ̀ Ọlọ́run Kí N Tó Wá Rí Ọlọ́run Tòótọ́ Náà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mo Ti Rí Ọ̀pọ̀ Ọlọ́run Kí N Tó Wá Rí Ọlọ́run Tòótọ́ Náà
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ̀rí Ọkàn Mi Bẹ̀rẹ̀ Sí í Ṣiṣẹ́
  • Àwọn Ẹlẹ́rìí Ké sí Mi
  • Sísìn Níbi Tí Àìní Gbé Pọ̀
  • Sínú Etí Ọmọdé Kan
    Jí!—1997
  • Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Ìdílé Wa Ṣọ̀kan!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • “Jèhófà, O Wá Mi Kàn!”
    Jí!—2004
Jí!—1997
g97 5/22 ojú ìwé 11-13

Mo Ti Rí Ọ̀pọ̀ Ọlọ́run Kí N Tó Wá Rí Ọlọ́run Tòótọ́ Náà

WỌ́N bí mi ní Croydon, England, ní 1921, èmi sì ni ọmọ obìnrin tí ó dàgbà jù lọ láàárín ọmọ obìnrin mẹ́ta àti ọkùnrin méjì. Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́ta, àwa kan lára àwa ọmọ ní àrùn gbọ̀fungbọ̀fun. Wọ́n dá mi dúró sí ilé ìwòsàn. Àbúrò mi ọkùnrin, Johnnie, kú, nítorí pé kò ti ṣèrìbọmi, Ìjọ Áńgílíkà kò jẹ́ kí a ṣe ìsìn ìsìnkú rẹ̀. Èyí bí bàbá mi nínú, ó sì béèrè bí ọ̀kan lára àwọn àlùfáà náà yóò bá gbàdúrà nígbà tí wọ́n ń gbé pósí Johnnie sínú kòtò. Ó kọ̀.

Ìyá mi sọ pé, èyí mú kí bàbá mi kẹ̀yìn sí ìsìn pátápátá. Ẹ̀rù ba ìyá mi bóyá nǹkan kan lè ṣẹlẹ̀ sí èmi tàbí àwọn àbúrò mi obìnrin débi pé, láìjẹ́ kí bàbá mi mọ̀, ìyá mi kó wa lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, ó sì ní kí wọ́n ṣèrìbọmi fún wa. Bàbá mi di ògbóṣáṣá mẹ́ńbà ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì, ó sì rọ̀ wá láti máa ka àwọn ìwé tí ó jẹ mọ́ ìpìlẹ̀ ìjótìítọ́ àyípoyípo ìyípadà, títí kan àwọn ìwé tí Huxley, Lenin, àti Marx kọ. A kò mẹ́nu kan Ọlọ́run mọ́ nínú ilé yàtọ̀ sí ìgbà tí Bàbá bá fẹ́ sọ pé kò sí Ọlọ́run.

Ní 1931, nígbà tí mo wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́wàá, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, mo máa ń rìn lọ ní ojú pópó láti bẹ àwọn òbí bàbá mi wò. Àwọn ẹlòmíràn sábà máa ń ṣe àríwísí Bàbáàgbà, àmọ́ ó ní ẹyinjú aláwọ̀ búlúù tí ń ṣe wiriwiri, ó sì máa ń láyọ̀ nígbà gbogbo. Ó sábà máa ń fún mi ní mindin-mín-ìndìn àti àwọn ìwé láti kà nígbà tí mo bá ń lọ sí ilé. N óò jẹ mindin-mín-ìndìn, n óò sì sọ ìwé náà nù. N kò lóye ìdí tí àwọn ẹlòmíràn fi máa ń sọ àwọn ohun tí kò dára nípa rẹ̀.

Nígbà tí mo di ọ̀dọ́langba, mo dara pọ̀ mọ́ Ẹgbẹ́ Ọ̀dọ́ Kọ́múníìsì, láìpẹ́, mo di akọ̀wé ẹgbẹ́. Mo máa ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ ní gbọ̀ngàn ìlú, mo sì máa ń bá ilé iṣẹ́ tí ń ṣe ìwé agbéròyìnjáde Challenge ṣiṣẹ́ ní òpópónà ní fífún ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ láti gbọ́. Nígbà yẹn, ìgbòkègbodò ẹgbẹ́ kan tí ń jẹ́ Blackshirts nínú Ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀ fara hàn, wọ́n sì fi tipátipá lòdì sí ètò ìjọba Kọ́múníìsì. Mo rántí pé bí mo ti jókòó lórí pèpéle, tí mo ń fún àwọn ènìyàn ní ìwé agbéròyìnjáde Challenge, àwọn mẹ́ńbà ẹgbẹ́ Blackshirts yóò wá bá mi sọ̀rọ̀, ní pípè mí ní Sunshine, orúkọ ìnagijẹ tí wọ́n fún mi. Àwọn mẹ́ńbà ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì tí wọ́n dàgbà, tí mo ń bá rìn, gbọ́ pé àwọn ẹgbẹ́ Ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀ ń gbèrò láti fi ìbọ̀wọ́ oníṣòó lù mí, nítorí náà, wọ́n fún mi ní àwọn ènìyàn láti máa dáabò bò mí.

Ní ìgbà kan, a gbọ́ pé àwọn ẹgbẹ́ Ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀ yóò yan gba ìhà East End ní London (tí àwọn Júù wà jù lọ nígbà náà). Wọ́n ní kí a kò wọ́n lójú, kí a sì kó òkúta mábìlì dání sínú àpò, tí a óò máa jù sí ẹsẹ̀ ẹṣin àwọn ọlọ́pàá bí wọ́n ti ń sáré láti tú àwọn ìhà méjèèjì tí ń jà náà ká. Wọ́n fàṣẹ ọba kó ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́jọ́ náà, àmọ́, mo dúpẹ́ n kò sí lára wọn, nítorí pé mo pinnu láti má lọ.

Ẹ̀rí Ọkàn Mi Bẹ̀rẹ̀ Sí í Ṣiṣẹ́

Nígbà ìṣẹ̀lẹ̀ míràn, wọ́n ní kí n sọ ohun kan tí mo mọ̀ pé kì í ṣe òtítọ́ níbi ìpàdé ìta gbangba kan. Mo kọ̀, wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ mi pé, “Ṣé ó ṣe nǹkan kan ni, àní ká ṣáà ti sọ ohun tí a fẹ́ sọ?” Ní àkókò yí nínú ìgbésí ayé mi ni ẹ̀rí ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí í dà mí láàmú, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kàyéfì nípa àwọn ohun bíi mélòó kan.

Nígbà kan, nígbà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ọjọ́ orí ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ọ̀dọ́langba, ìyá mi rọ̀ mí láti lọ sí ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì kan, kìkì láti rí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní ṣọ́ọ̀ṣì. Mo rántí pé wọ́n ní kí n lọ sí iwájú pẹpẹ láti jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi. Nígbà tí mo wà níbẹ̀, mo ṣàkíyèsí pé iṣẹ́ ọnà tí ó wà lára ohun tí wọ́n fi bo pẹpẹ náà ní irin roboto mẹ́ta tí a lọ́ pọ̀. Mo béèrè nípa ohun tí wọ́n dúró fún, wọ́n sì wí fún mi pé, wọ́n dúró fún “Mẹ́talọ́kan Mímọ́—Ọlọ́run Baba, Ọlọ́run Ọmọ, àti Ọlọ́run Ẹ̀mí Mímọ́.” Mo ronú pé, ‘Èyí mà ṣàjèjì o. Wọ́n gbà gbọ́ nínú ọlọ́run mẹ́ta, àmọ́ bàbá mi sọ pé kò sí ọ̀kan pàápàá!’ Nígbà tí mo béèrè àwọn ìbéèrè míràn, wọ́n ṣàlàyé pé, ẹyin kan ní ẹ̀yà mẹ́ta, àmọ́ ẹyin kan ṣoṣo ni. Èyí pẹ̀lú kò tẹ́ mi lọ́rùn. Wọ́n wá wí fún mi lẹ́yìn náà pé mo ti ń béèrè ìbéèrè jù. Mo lọ sí ilé, mo sì wí fún ìyá mi pé, n kò fẹ́ láti lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì mọ́, n kò sì lọ mọ́!

Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ́ sílẹ̀, n kò sí nínú Ẹgbẹ́ Ọ̀dọ́ Kọ́múníìsì mọ́. Mo fẹ́ ọmọ ilẹ̀ Kánádà kan tí ń ṣiṣẹ́ nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun nígbà náà lọ́kọ, a sì bí ọmọkùnrin kan. Wọ́n ju bọ́ǹbù sí ilé wa àkọ́kọ́ ní London. Èmi àti ọmọkùnrin mi wà nílé nígbà tí bọ́ǹbù V-1 kan já bọ́ síwájú ilé wa. Gbogbo ohun ìní wa la pàdánù. Àwọn èérún àfọ́kù ilé bò wá mọ́lẹ̀, àmọ́ a dúpẹ́ gan-an pé a kò pàdánù ẹ̀mí wa. Ọkọ mi wà ní Normandy, ilẹ̀ Faransé, lákòókò náà.

Ní nǹkan bí àkókò yẹn, mo rántí pé mo bá àwọn obìnrin méjì kan sọ̀rọ̀, mo sì ń bi wọ́n pé, “Bí Ọlọ́run kan bá wà, kí ló dé tí ó ń jẹ́ kí gbogbo ìjìyà yí ṣẹlẹ̀?” Wọ́n sọ ohun kan nípa pé Sátánì ni ọlọ́run ayé yìí. Mo ronú pé, “Óò, ọlọ́run mìíràn tí n kò mọ ohunkóhun nípa rẹ̀!” Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ́kùnrin kan wá. Mo da ìbéèrè bò ó, ó sì wí pé, àwọn àgùntàn ni òun ń wá, kì í ṣe àwọn ewúrẹ́. Nítorí pé n kò mọ àwọn òwe àkàwé Jésù dáradára, mo bi í léèrè bóyá òjíṣẹ́ ni tàbí àgbẹ̀. Ọdún bíi mélòó kan tún lọ, Ogun Àgbáyé Kejì sì parí. Ọkọ mi wá sílé lẹ́yìn tí ó rí i tí ìpín 95 nínú ọgọ́rùn-ún lára Ẹgbẹ́ Jagunjagun Olóhun Ìjà Pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ ní Ibùdó Saskatoon, tí ó ti ń sìn, pa run nínú ogun náà. A kó lọ sí ilé mìíràn ní Croydon.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Ké sí Mi

Ní ọjọ́ Sunday kan, méjì lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá, wọ́n sì kan ilẹ̀kùn wa. Ọkọ mi lọ ṣí ilẹ̀kùn fún wọn, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ fún àkókò gígùn gan-an. Inú rẹ̀ kò dùn sí gbogbo ìsìn nítorí àgàbàgebè tí ó rí nígbà ogun. Òtítọ́ náà pé Àwọn Ẹlẹ́rìí mú ìdúró àìdásí-tọ̀túntòsì ṣí i lórí. Ó wí fún mi pé, òun ní kí wọ́n pa dà wá fún ìjíròrò nínú Bíbélì. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn gidigidi, mo sì béèrè ohun tí ó yẹ kí n ṣe lọ́wọ́ bàbá mi. Ó wí pé, kí n má ṣe dá sí i, àti pé, bí ọkọ mi bá ń bá a lọ nínú ìsìn aṣiwèrè yí, yóò sàn kí n pẹjọ́ ìkọ̀sílẹ̀.

Mo pinnu láti jókòó tì wọ́n nígbà ìjíròrò kan láti rí ohun tí gbogbo rẹ̀ dá lé lórí. Gbogbo wa jókòó yí tábìlì ká, Ẹlẹ́rìí náà sì wí pé: “Lọ́jọ́ kan, ẹ óò lè fi ọwọ́ kọ́ kìnnìún lọ́rùn gẹ́gẹ́ bí ẹ ti lè ṣe fún ajá.” Mo ronú pé, ‘Óò, orí wọn ti dà rú.’ N kò lè pọkàn pọ̀ lórí ohunkóhun tí wọ́n ń sọ nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn. Lẹ́yìn náà, mo wí fún ọkọ mi pé, n kò fẹ́ kí wọ́n pa dà wá mọ́. A sunkún gan-an, a sì jíròrò kíkọ ara wa sílẹ̀.

Láìpẹ́ lẹ́yìn èyí, Ẹlẹ́rìí mìíràn tún wá. A wá mọ̀ nígbà tó yá pé alábòójútó àyíká tí ń bẹ ìjọ àdúgbò wò nígbà náà ni, ó sì ti gbọ́ nípa wa. Mo rántí rẹ̀ dáradára. Ó ní ẹyinjú aláwọ̀ búlúù, ó sì jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́, tí ó nínúure gan-an. Ó mú mi rántí bàbáàgbà mi. Mo fa ìwé kan, tí mo kọ ìbéèrè 32 tí mo ní sí, yọ. Ó sọ pé, “A óò máa jíròrò wọn ní ọ̀kọ̀ọ̀kan,” a sì bẹ̀rẹ̀ sí i ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ràn mí lọ́wọ́ láti mọrírì pé láti lóye ohun tí Bíbélì sọ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, mo ní láti máa kà á, kí n sì máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Ó dábàá pé, ó yẹ kí ẹni kan máa bẹ̀ wá wò déédéé láti máa bá wa ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo wí fún un pé kò burú.

Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í lóye nípa Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run, díẹ̀díẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Mo rántí pé mo wọ inú iyàrá lọ, mo sì gbàdúrà sí Jèhófà pé kí ó jọ̀wọ́ dárí jì mí, kí ó sì ràn mí lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì àti àwọn ète rẹ̀. Èmi, ọkọ mi, àti ọmọkùnrin mi ṣèrìbọmi ní 1951. Ìyọnu bá bàbá mi gan-an nígbà tí ó gbọ́ nípa èyí, ó sì wí pé ó tẹ́ òun lọ́rùn pé kí n kú ju pé kí n jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Sísìn Níbi Tí Àìní Gbé Pọ̀

Ọkọ mi pinnu láti pa dà lọ sí Kánádà, nígbà tí ó sì di 1952, a kó lọ sí Vancouver, British Columbia. Bàbá mi kọ̀, kò kí wa pé ó dàbọ̀, n kò sì rí i mọ́ tàbí kí n gbọ́ ohunkóhun mọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀. Lẹ́yìn tí a ti ń gbé ní Vancouver fún ọdún bíi mélòó kan, ìpè kan jáde fún lílọ sí ibi tí àìní gbé pọ̀, pàápàá jù lọ, láti lọ sí àwọn àgbègbè bíi Quebec, níbi tí Olórí Ìjọba Duplessis ti ń hùwà sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bí Hitler ṣe hùwà sí wọn.

Ní 1958, a kó gbogbo ohun tí a ní láyé sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa, a sì wakọ̀ lọ sí àpéjọpọ̀ àgbáyé tí a ṣe ní New York. Láti ibẹ̀, a wakọ̀ lọ sí Montreal, Quebec, níbi tí wọ́n ti yàn wá síṣẹ́ ní ìjọ kan tí ń sọ èdè Faransé ní Ville de Jacques-Cartier. A ní àwọn ìrírí gbígbádùn mọ́ni púpọ̀ nígbà tí a ń ṣiṣẹ́ sin Jèhófà ní Quebec. Nígbà kan, àwọn ènìyàn dojú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa dé, wọ́n ń ju òkúta lù wá, obìnrin kan sì ṣí omi dà sí wa lára. Èyí ṣẹlẹ̀ níbi tí a ń pè ní Magog.

Nígbà míràn, èmi àti alájọṣepọ̀ mi kọjá lẹ́bàá ṣọ́ọ̀ṣì kan ní àkókò tí àwọn ènìyàn ń jáde gẹ́lẹ́. Ẹnì kan dá wa mọ̀, ó sì lọgun pé: “Témoins de Jéhovah!” (“Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà!”) Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í lé wa, àlùfáà ló ṣíwájú, àmọ́ àwọn èrò náà kò lè lé wa bá. Wọ́n fàṣẹ ọba mú wa lọ́pọ̀ ìgbà. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, inú mi dùn láti ran àwọn ènìyàn díẹ̀ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, ọ̀pọ̀ lára wọn ṣì ń ṣiṣẹ́ sìn ín síbẹ̀síbẹ̀.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1960, ọ̀gá ọkọ mi gbé e lọ sí Los Angeles, a sì sìn ní ìjọ kan níbẹ̀ fún ohun tí ó lé ní 30 ọdún. Ẹ wo bí ó ti dùn mọ́ wa nínú tó láti sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́ fún àwọn ènìyàn tí wọ́n kó wá sí Los Angeles láti apá ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé! Mo ní àǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n wá láti Lébánónì, Íjíbítì, China, Japan, ilẹ̀ Faransé, àti Ítálì, kí a dárúkọ díẹ̀. Mo rántí pípàdé ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan tí kò lè sọ Gẹ̀ẹ́sì rárá—a dúpẹ́ pé ọkọ rẹ̀ lè sọ. Nítorí náà, èmi àti ọkọ mi bá àwọn méjèèjì ṣèkẹ́kọ̀ọ́ pọ̀. Lẹ́yìn-ò-rẹ́yìn, mo wá ń bá obìnrin náà nìkan ṣèkẹ́kọ̀ọ́. Mo lo ìwé náà, Jẹki Ọlọrun Jẹ Olõtọ, lédè Gẹ̀ẹ́sì, obìnrin náà sì ń ṣí àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ wò nínú Bíbélì èdè China tirẹ̀, yóò sì dáhùn ìbéèrè náà lédè China. Lẹ́yìn náà, n óò sọ ìdáhùn náà lédè Gẹ̀ẹ́sì, òun náà yóò sì tún un sọ lédè Gẹ̀ẹ́sì. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, èdè Gẹ̀ẹ́sì ń já geere lẹ́nu rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń fi ohùn ìpè ọ̀rọ̀ ti Britain sọ ọ́. Ó jẹ́ ìdùnnú mi láti sọ pé, òun àti ọkọ rẹ̀ ti di olùṣèyàsí-mímọ́, ìránṣẹ́ Jèhófà nísinsìnyí.

A ṣẹ̀ṣẹ̀ kó lọ sí Tucson, Arizona, mo sì ní àfikún àǹfààní ti rírí i tí gbogbo àwọn mẹ́ńbà ìdílé wa ń ṣiṣẹ́ sin Jèhófà, títí kan àwọn àtọmọdọ́mọ wa, tí a ti kọ́ nípa Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà.

Lọ́nà kan ṣá, inú mi dùn láti gbọ́ lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin ní Croydon pé bàbáàgbà mi tí ó ní ẹyinjú aláwọ̀ búlúù tí ń ṣe wiriwiri jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.—Gẹ́gẹ́ bí Cassie Bright ṣe sọ ọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́