ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 6/8 ojú ìwé 11-14
  • Sínú Etí Ọmọdé Kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Sínú Etí Ọmọdé Kan
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìyánhànhàn fún Ìsìn
  • Ìgbéyàwó àti Ìdílé
  • Fífi Ṣọ́ọ̀ṣì Sílẹ̀
  • Kíkẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́ Bíbélì
  • Àtakò Láti Ọ̀dọ̀ Ìdílé
  • Ìbápàdé Mánigbàgbé Kan
  • Sún Mọ́ Olùgbọ́ Àdúrà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • “Jèhófà, O Wá Mi Kàn!”
    Jí!—2004
  • Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Mo Ti Wá Mọ Ọlọ́run Tí Mo Ń Sìn Wàyí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 6/8 ojú ìwé 11-14

Sínú Etí Ọmọdé Kan

LỌ́JỌ́ kan, nígbà tí mo ṣì jẹ́ ọmọdébìnrin kékeré kan, ọkùnrin kan wá sí ilé wa ní Coeburn, Virginia, U.S.A., nígbà tí ó sì ń bá bàbá mi sọ̀rọ̀, ẹnì kejì rẹ̀ bá mi sọ̀rọ̀ kí n má wulẹ̀ máa ṣeré lásán. Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ yàwòrán párádísè ilẹ̀ ayé kan, níbi tí mo ti lè máa bá àwọn ẹranko ẹhànnà tí kò ní pa mí lára ṣeré. (Aísáyà 11:6-9) Ó ṣàlàyé pé n kò tilẹ̀ ní ní láti kú, ṣùgbọ́n pé mo lè wà láàyè títí láé níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé. Ọjọ́ iwájú náà dà bí àgbàyanu! Ohun tí ọkùnrin náà sọ nípa wíwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé wọ̀ mí lọ́kàn ṣinṣin.—Aísáyà 25:8; Ìṣípayá 21:3, 4.

Ìyánhànhàn fún Ìsìn

Àwọn òbí mi, tí wọ́n ní ọ̀pọ̀ ìṣòro nínú ìgbésí ayé lọ́kọláya wọn, kọ ara wọn sílẹ̀ lọ́dún mélòó kan lẹ́yìn náà, mo sì gbé ọ̀dọ̀ Màmá. Màmá kò ní ìfẹ́ sí ìsìn rárá. Nítorí náà, mo ń dá lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi ní ṣọ́ọ̀ṣì èyíkéyìí tí ó bá ṣeé fẹsẹ̀ rìn lọ láti ilé wa. Láìpẹ́, Màmá tún lọ́kọ mìíràn, a sì kó lọ sí Indiana pẹ̀lú ọkọ màmá mi. Bí ó ti wù kí ó rí, ní gbogbo ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, mo máa ń pa dà wá sí Virginia láti wá bẹ bàbá mi wò.

Bàbá di onísìn Mormon láìpẹ́ lẹ́yìn ìkọ̀sílẹ̀ náà, ó sì gbìyànjú láti gbin ìsìn rẹ̀ tuntun sí mi lọ́kàn. Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1960, tí mo jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ, ó batisí mi. Síbẹ̀ nígbà tí mo bá wà ní Indiana, mo ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì èyíkéyìí tó bá sún mọ́lé. Gbogbo wọn fi kọ́ni pé bí a bá ń hùwà rere, a ó lọ sọ́run, bí a bá sì ń hùwà búburú, a ó lọ sí hẹ́ẹ̀lì, níbi tí a ó ti máa dá wa lóró. Níwọ̀n bí n kò ti rò pé ẹnikẹ́ni yóò lóye ìmọ̀lára mi nípa fífẹ́ tí mo fẹ́ láti gbé orí ilẹ̀ ayé dípò kí n lọ gbé ọ̀run, n kò bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

Nígbà tí mo di ọmọ ọdún 11, Bàbá kó lọ sí Oregon. Ó bà mí lọ́kàn jẹ́, ó sì bí mi nínú. Ọkọ ìyá mi jẹ́ aláìgbọlọ́run-gbọ́ àti onímukúmu-ọtí, ó sì máa ń mọ̀ọ́mọ̀ dá mi lágara nítorí ìgbàgbọ́ mi. Ó ń pè mí ní Omidan Onítara-Ìsìn kékeré, tí mo bá sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún, yóò wí pé: “O kò ṣe ké pe Ọlọ́run rẹ kí ó ràn ọ́ lọ́wọ́?” Nílé, kò jọ pé ẹnì kankan bìkítà nípa Ọlọ́run. Àwọn ọdún wọ̀nyẹn múni rẹ̀wẹ̀sì, wọ́n sì ṣòro. Wọ́n lù mí nílùkilù, wọ́n bú mi gidigidi, wọ́n sì bá mi ṣèṣekúṣe. Mo ní ìtùnú nínú bíbá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nítorí pé, lọ́pọ̀ ìgbà ni mo rò pé òun nìkan ni ó bìkítà fún mí.

Màmá fi ọkọ rẹ̀ náà sílẹ̀, ìfìyàjẹni náà sì dáwọ́ dúró. Síbẹ̀, a tálákà gan-an, ó sì ṣòro fún Màmá láti gbọ́ bùkátà wa. Nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún 13, a pa dà lọ sí Virginia láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́nbìnrin màmá mi. Ó jẹ́ onínúure, ọmọ ìjọ Onítẹ̀bọmi. Mo fẹ́ràn rẹ̀ gidigidi. Nígbà tí ó ní kí n bá òun lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, mo gbà. Màmá bá wa lọ pàápàá, mo sì rántí bí ó ti jẹ́ àgbàyanu tó láti wà pẹ̀lú ìdílé mi níbẹ̀. Nígbà tí ìbẹ̀wò wa fi parí, ẹ̀rù bà mí láti pa dà lọ sílé. Ẹ̀rù bà mí pé bí mo bá ṣe bẹ́ẹ̀, n óò di ẹni tí ń lọ́wọ́ sí ìwà pálapàla. Nítorí náà, mo bẹ ẹ̀gbọ́nbìnrin màmá mi láti gbà mí sọ́dọ̀, Màmá sì gbà pé kí n máa gbé ibẹ̀.

Ẹ̀gbọ́nbìnrin màmá mi ra Bíbélì ìtumọ̀ King James kan fún mi. Ó dùn mọ́ mi gan-an, mo sì máa ń ka apá kan rẹ̀ lálaalẹ́. Ní orí tí ó kẹ́yìn nínú Bíbélì náà, mo kà á pé “bí ẹnikẹ́ni bá fi kún wọn, Ọlọ́run yóò fi kún àwọn ìyọnu tí a kọ sínú ìwé yìí fún un.” (Ìṣípayá 22:18, 19, King James Version) Nítorí náà, mo ronú pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè gbà gbọ́ pé Ìwé Mormon jẹ́ apá kan Ìwé Mímọ́ ọlọ́wọ̀ náà?’ Nítorí náà, mo pinnu láti di ọmọ ìjọ Onítẹ̀bọmi.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó dá mi lójú pé ọ̀rọ̀ náà ba Bàbá nínú jẹ́ nígbà tí mo kọ̀wé sí i, tí mo sí sọ ìpinnu mi fún un, ohun kan ṣoṣo tí o sọ ni pé, inú òun dùn pé mo ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Mo sábà máa ń bá òjíṣẹ́ ìjọ Onítẹ̀bọmi wa lọ sílé àwọn ènìyàn láti ké sí wọn wá sí àgọ́ ìsọjí wa. Mo rò pé mo ń ṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run nípa ṣíṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn nínú ilé wọn, tí mo sì ń bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà tí Jésù gbà ṣe bẹ́ẹ̀.

Síbẹ̀, mo ṣì ní ìfẹ́ àtọkànwá láti gbé nínú párádísè ilẹ̀ ayé kan kàkà kí ó jẹ́ ní ọ̀run. Ṣùgbọ́n nígbà náà ni mo ka ẹsẹ Bíbélì yí pé: “Bèèrè, a ó sì fi fún yín; wá kiri, ẹ̀yin ó sì rí; kànkùn, a ó sì ṣí i sílẹ̀ fún yín. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó béèrè ń rí gbà; ẹni tí ó bá sì wá kiri ń rí: ẹni tí ó bá sì ń kànkùn, ni a óò ṣí i sílẹ̀ fún,” ó sì fún mi nírètí.—Mátíù 7:7, 8, KJ.

Ìgbéyàwó àti Ìdílé

Ní ọdún tó tẹ̀ lé e, mo pa dà lọ gbé lọ́dọ̀ Màmá ní Indiana. Nígbà tí mo ṣì jẹ́ ọmọ ọdún 15 péré, mo ṣègbéyàwó, mo lóyún, mo sì ń rìnrìn àjò nínú bọ́ọ̀sì lọ sí ìhà gúúsù California. N kò mọ ìdílé ọkọ mi dáradára, àmọ́ mo fẹ́ kí wọ́n tẹ́wọ́ gbà mí. Onísìn Pentecostal ni wọ́n, ẹ̀gbọ́nbìnrin ọkọ mi sì sọ fún mi nípa ẹ̀bùn ìfèdèfọ̀. Nítorí náà, mo bá wọn lọ síbi ìsìn àdúrà wọn lálẹ́ ọjọ́ kan, mo gbàdúrà pé kí n lè máa fèdè fọ̀.

Lójijì, ìmọ̀lára ṣíṣàjèjì kan bò mí mọ́lẹ̀ níbi ìsìn náà. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, ahọ́n mi sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ wótòwótò láìṣeé-ṣàkóso. Oníwàásù náà pariwo pé ẹ̀mí mú mi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fọwọ́ gbá mi lẹ́yìn pẹ́pẹ́ẹ́pẹ́. Lẹ́yìn náà, gbogbo wọn ń rọ̀ mọ́ mi, wọ́n sì ń sọ bí ó ti jẹ́ ohun àgbàyanu tó pé Ọlọ́run ti lò mí lọ́nà yí fún mi. Àmọ́ ọkàn mí dà rú, ẹ̀rù sì bà mí. N kò mọ ohun tí mo ti sọ.

Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, mo ní ìṣòro nígbà ìrọbí ọmọ wa àkọ́kọ́. Pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì náà sọ fún ọkọ mi pé, nítorí tí kì í ṣe Kristẹni ni Ọlọ́run ṣe ń sọ ìpọ́njú ìrọbí mi di púpọ̀. Pẹ̀lú omijé lójú, ọkọ mi wá bá mi, ó sì sọ pé, bí mo bá rò pé yóò dín ìpọ́njú ìrọbí mi kù, òun yóò batisí. Mo sọ fún un pé mo mọ̀ pé Ọlọ́run kì í fipá mú àwọn ènìyàn láti sìn ín.

Fífi Ṣọ́ọ̀ṣì Sílẹ̀

Lẹ́yìn ìwàásù rẹ̀ ní Sunday kan, pásítọ̀ rọ ìjọ láti ṣèdáwó. Ṣọ́ọ̀ṣì náà nílò àtúnṣe nítorí bí ìsẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ kan ṣe bà á jẹ́. Nígbà tí wọ́n gbé àwo dé iwájú mi, mo da gbogbo owó tí mo ní sínú rẹ̀. Lẹ́yìn tí pásítọ̀ ka owó náà, dípò kí ó dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ, ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n tú àpò wọn jáde, kí wọ́n sì túbọ̀ fi ọ̀làwọ́ hàn nítorí ohun yíyẹ yìí. Ó tún gbé àwo náà kiri lẹ́ẹ̀kan sí i. N kò ní owó kankan lọ́wọ́ mọ́, nítorí náà, tìtìjú-tìtìjú ni mo yára gbé àwo náà fún ẹni tí ó kan. Pásítọ̀ náà yára ka owó ọ̀hún lẹ́ẹ̀kan sí i, ó sì tún wulẹ̀ sọ pé kò tó, láìsí pé ó dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn. Ó ní: “Ó dájú pé kò sí ẹni tí yóò jáde kúrò níbí títí a óò fi rí owó tí a nílò láti ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run.”

Ọkọ mi ń dúró níta, mo sì mọ̀ pé ojú ti ń kán an. Òun nìkan sì kọ́. Àìmoore pásítọ̀ náà ti tán èmi náà ní sùúrù. Nítorí náà, bí mo ti gbé ọmọ mi sọ́wọ́, tí omijé sì ń ṣàn lójú mi, mo jáde kúrò nínú ṣọ́ọ̀ṣì náà, tí gbogbo ènìyàn sì ń wò mí. Mo pinnu nígbà náà pé n kò tún ní ohunkóhun í ṣe pẹ̀lú ṣọ́ọ̀ṣì kankan mọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣíwọ́ lílọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, n kò ṣíwọ́ gbígba Ọlọ́run gbọ́. Mo ṣì ń ka Bíbélì mi, mo sì ń sapá láti jẹ́ aya rere.

Kíkẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́ Bíbélì

Lẹ́yìn tí a bí ọmọ wa kejì, àwọn ọ̀rẹ́ wa tí ń kó lọ sí Texas bá onílé wọn sọ ọ́ pé kí ó fi ilé rẹ̀ tí wọ́n ń gbé tẹ́lẹ̀ yá wa gbé. Bí ọ̀rẹ́ mi, Pat, ti ń kó lọ, ó sọ pé obìnrin kan jẹ òun lówó, yóò sì kó o wá. Pat sọ pé kí n fi ránṣẹ́ sí òun ní Texas. Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, àwọn obìnrin méjì kanlẹ̀kùn. Bí mo ṣe ń rò pé owó náà ni wọ́n kó wá, lọ́gán ni mo pè wọ́n wọlé. Mo ṣàlàyé pé Pat ti kó lọ, ṣùgbọ́n ó ti sọ fún mi pé wọn yóò wá. Ọ̀kan lára àwọn obìnrin náà, Charlene Perrin, sọ pé: “Tóò, Pat ṣe ìyẹn dáadáa. A gbádùn bíbá a kẹ́kọ̀ọ́ gan-an ni.”

Mo béèrè pé: “Kí ni? Kíkẹ́kọ̀ọ́ kẹ̀? Ẹ ń ṣe àṣìṣe ni.” Charlene ṣàlàyé pé àwọn àti Pat ti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan. Lẹ́yìn tí wọ́n sì wá mọ̀ pé Pat ti kó lọ, Charlene béèrè bóyá n óò fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo fìdánilójú dáhùn pé “Dájúdájú. N óò kọ́ yín ní ohunkóhun tí ẹ bá fẹ́ láti mọ̀.” Bíbélì tí mo ti kà tẹ́ mi lọ́rùn, mo sì rò pé n óò lè fún wọn níṣìírí.

Charlene fi ìwé Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye hàn mí, a sì ka Orin Dáfídì 37:9 (NW) pé: “Nítorí pé àwọn aṣebi ni a óò ké kúrò, ṣùgbọ́n àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà ni yóò ni ilẹ̀ ayé.” Ó yà mí lẹ́nu. Níbẹ̀, nínú Bíbélì tèmi fúnra mi, ó sọ pé àwọn ènìyàn yóò ni ilẹ̀ ayé. Lẹ́yìn ìyẹn, mo da ìbéèrè rẹpẹtẹ bolẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà. Charlene rẹ́rìn-ín músẹ́, ó sì wí pé: “Rọra tẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́! A óò máa dáhùn àwọn ìbéèrè rẹ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan tẹ̀lératẹ̀léra.” Ó ṣàlàyé pé ó yẹ kí a máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, létòlétò. Lọ́gán, ó ké sí mi láti wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, orúkọ ibi ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Mo sọ fún Charlene nípa ìrírí tí mo ní nípa àwo ìdáwó, mo sì sọ pé n kò fẹ́ láti pa dà lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì mọ́. Ó bá mi jíròrò Mátíù 10:8, tí ó sọ pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.” Ó ṣàlàyé pé a kì í gbé àwo ìdáwó kiri ní àwọn ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àti pé ìfínnúfíndọ̀ ni gbogbo ọrẹ. Ó tún sọ pé àpótí ọrẹ kan wà nínú gbọ̀ngàn náà, àti pé àwọn ènìyàn tí ó bá fẹ́ lè fi ọrẹ sínú rẹ̀. Mo pinnu láti tún dán ìsìn wò lẹ́ẹ̀kan sí i.

Bí mo ti ń kẹ́kọ̀ọ́, mo lóye ìdí tí ara kò fi rọ̀ mí nígbà tí mo ń fèdè fọ̀ ní ṣọ́ọ̀ṣì Pentecostal. Ẹ̀bùn fífi onírúurú èdè sọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run fúnni ni a fi fún àwọn Kristẹni ìjímìjí láti pèsè ẹ̀rí pé wọ́n ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Ẹ̀bùn oníṣẹ́-ìyanu yìí tún ṣiṣẹ́ fún ète gidi ti mímú kí òtítọ́ Bíbélì wà lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn ènìyàn onírúurú ilẹ̀ tí wọ́n pé jọ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa. (Ìṣe 2:5-11) Bí ó ti wù kí ó rí, Bíbélì sọ pé ẹ̀bùn ìfèdèfọ̀ tí Ọlọ́run fúnni yóò kásẹ̀ nílẹ̀, èyí tí ó ṣe ní kedere lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì. (Kọ́ríńtì Kíní 13:8) Ṣùgbọ́n kí Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ lè fọ́ èrò inú àwọn ènìyàn lójú, wọ́n ń mú kí àwọn kan máa sọ̀rọ̀ wótòwótò, lọ́nà kan tí ó ti mú kí ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà gbọ́ pé àwọn wọ̀nyí ní ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run.—Kọ́ríńtì Kejì 4:4.

Àtakò Láti Ọ̀dọ̀ Ìdílé

Láìpẹ́, mo wá lóye ète Ọlọ́run fún ilẹ̀ ayé, àti pé n kò gbọ́dọ̀ jẹ́ apá kan ayé oníwà ibi. (Jòhánù 17:16; 18:36) Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ pé mo ní láti já gbogbo ìdè tí ó dè mí mọ́ Bábílónì Ńlá, tí ó jẹ́ ohun àfiṣàpẹẹrẹ kan tí a lò nínú Bíbélì fún ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé. (Ìṣípayá 18:2, 4) Ọkàn Bàbá dà rú nígbà tí mo sọ fún un pé, lọ́tẹ̀ yí, n ó ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó bẹ̀ mí pé kí n má ṣe di Ẹlẹ́rìí. Ó jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí mo rí i tí ó sunkún. Mo bá a sunkún, nítorí pé, ní tòótọ́, n kò fẹ́ láti bà á lọ́kàn jẹ́. Ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé mo ti rí òtítọ́, àti pé n kò lè kọ ẹ̀yìn sí Jèhófà láéláé.

Gbogbo ìdílé mi ló lòdì sí pé kí n di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Fún ìgbà díẹ̀, n kò lọ sípàdé mọ́. Èyí dá àtakò tí ìdílé mi ń ṣe dúró, àmọ́ n kò láyọ̀ rárá. Mo mọ̀ pé n kò lè lálàáfíà láé, títí di ìgbà tí mo bá ń ṣe ìfẹ́ inú Jèhófà. Lọ́jọ́ kan, ní àkókò ìsinmi oúnjẹ ọ̀sán, mo yà ní ilé Charlene, mo sì sọ fún un pé mo fẹ́ láti ṣèrìbọmi. Ó béèrè pé: “Ǹjẹ́ o kò rò pé ó yẹ kí o tún bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí àwọn ìpàdé lákọ̀ọ́kọ́ ná?” Mo sọ fún un pé mo ti pinnu tán nísinsìnyí pé kò sí ohun tí yóò tún dí mi lọ́wọ́ sísin Jèhófà mọ́. Mo ṣèrìbọmi ní September 19, 1973.

Ìyẹn ti lé ní ọdún 23 sẹ́yìn báyìí. Ọpẹ́ ni pé ìdílé mi ti wá bọ̀wọ̀ fún ìpinnu mi láti ìgbà náà wá, kò sì sí ẹnikẹ́ni lára wọn tí ń yọ mí lẹ́nu pé kí n kọ òtítọ́ sílẹ̀, mo mọrírì ìyẹn gan-an. Síbẹ̀, Kim, ọmọbìnrin mi tí ó dàgbà jù lọ, nìkan ni ó tí ì di Ẹlẹ́rìí. Iṣẹ́ ìsìn onídùúró-ṣinṣin rẹ̀ sí Jèhófà ti jẹ́ orísun ìṣírí gidigidi fún mi láàárín àwọn ọdún wọ̀nyí.

Ìbápàdé Mánigbàgbé Kan

Ní 1990, nígbà tí mo pa dà ṣèbẹ̀wò sí Coeburn, Virginia, mo ní kí Màmá dúró ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, kí n lè wo ìgbà tí ìpàdé yóò bẹ̀rẹ̀ ní Sunday. Bí a ṣe bọ́ sí ọ̀nà tí ọkọ̀ ń tọ̀, ó sọ fún mi pé a ti gbé inú ilé kan tí ó wà lẹ́yìn gbọ̀ngàn náà nígbà kan rí, ní òdì kejì ọ̀nà ojú irin. Ilé náà ti jóná tipẹ́, kìkì ògiri iyàrá ìdáná ló kù. Ó sọ pé: “O kéré gan-an nígbà yẹn, o kò ju ọmọ ọdún mẹ́ta tàbí mẹ́rin lọ.”

Ní Sunday, tọ̀yàyàtọ̀yàyà ni wọ́n kí mi káàbọ̀ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba náà. Nígbà tí mo ń bá Stafford Jordan sọ̀rọ̀, mo kàn mẹ́nu bà á fẹ́rẹ́ pé nígbà tí mo wà lọ́mọdé, mo gbé inú ilé kan tí ó wà lẹ́yìn Gbọ̀ngàn Ìjọba náà tẹ́lẹ̀ rí. Ó tẹjú mọ́ mi. Ó kígbe pé: “Mo rántí rẹ! Ìwọ ni ọmọbìnrin kékeré tí irun rẹ̀ lọ́, tí ó ga tó báyìí [ó fi ọwọ́ rẹ̀ díwọ̀n rẹ̀]. A ń ṣiṣẹ́ ní àgbègbè ìpínlẹ̀ yí nígbà tí ẹnì kejì mi ń bá bàbá rẹ jíròrò. Mo gbìyànjú láti bá ọ sọ̀rọ̀ nípa Párádísè ki o má wulẹ̀ máa ṣeré lásán.”

Mo sọ̀rọ̀ tì. Ohùn mi kò já gaara bí mo ti ń sọ fún un nípa bí mo ṣe wá òtítọ́ Bíbélì kiri. Mo wí pé: “Nígbà tí mo jẹ́ ọmọdé kan, o gbin irúgbìn òtítọ́ sínú ọkàn àyà ọmọdé mi!” Ó wá sọ fún mi pé mo ní ìbátan kan nínú àwọn ẹbí bàbá mi àgbà, Stephen Dingus, tí ó ti jẹ́ Ẹlẹ́rìí olóòótọ́. Ìdílé náà kì í sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nítorí pé, wọ́n lòdì sí i gidigidi. Arákùnrin Jordan sọ pé: “Inú rẹ̀ yóò dùn púpọ̀ nítorí rẹ!”

Bí mo ti ń ronú ṣéyìn lórí àwọn ọdún tí mo ti lò nínú ètò Jèhófà, mo kún fún ìmoore ní tòótọ́ fún ìfẹ́ àti inúrere tí a ti fi hàn sí mi. Dájúdájú, àwọn àkókò ṣì wà tí inú mi máa ń bà jẹ́ nígbà tí mo bá wà nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba, tí mo sì rí àwọn ìdílé tí ó jùmọ̀ ń ṣiṣẹ́ sin Jèhófà, nítorí pé, mo sábà máa ń wà níbẹ̀ lémi nìkan. Ṣùgbọ́n mo máa ń yára rántí pé, Jèhófà wà pẹ̀lú mi. Ó máa ń wo ohun tí ń ṣẹlẹ̀, nígbà tí ó sì ṣeé ṣe fún ọkàn àyà mi láti gba òtítọ́ tí a sọ̀ sínú etí ọmọdé kan ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ó yọ̀ǹda fún un láti hù, kí ó sì dàgbà.

Mo wí pé: “O ṣeun, Arákùnrin Jordan, pé o lo àkókò láti bá ọmọdébìnrin tí ń ta pọ́n-ún-pọ́n-ún kiri kan sọ̀rọ̀ nípa Párádísè!”—Bí Louise Lawson ṣe sọ ọ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Pẹ̀lú Stafford Jordan nígbà tí mo tún bá a pàdé ní 1990

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́