“Jèhófà, O Wá Mi Kàn!”
Gẹ́gẹ́ bí Nelly Lenz ṣe sọ ọ́
Mo bi àwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n wá sílé wa pé: “Ṣé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni yín?” Wọ́n dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.” Mi ò mọ̀gbà tí mo ké pàrá pé, “Àtèmi náà!” Ọmọ ọdún mẹ́tàlá ni mí, àmọ́ n kì í lọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwọn òbí mi kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kí ló wá fà á tí mo fi sọ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí?
ỌPẸ́LỌPẸ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, màmá mi ì bá tí bí mi. Màmá mi lóyún mi nígbà tó ń gbé ní ìlú Montreal, ní ìpínlẹ̀ Quebec, lórílẹ̀-èdè Kánádà. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún péré ni. Gbogbo ẹbí ló dìde sí i pé kó lọ ṣẹ́ oyún náà. Òun náà sì gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Kí màmá mi bàa lè lọ ṣẹ́ oyún náà, ó gbàyè ọjọ́ kan lẹ́nu iṣẹ́. Ṣùgbọ́n ọ̀gá màmá mi tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mọ ìdí tó fi fẹ́ pa ibi iṣẹ́ jẹ. Ó ṣàlàyé ṣókí fun màmá mi nípa bí ẹ̀bùn ìwàláàyè ti ṣeyebíye tó. (Sáàmù 139:13-16) Bí màmá mi ti mórí lé ọ̀nà ilé ìwòsàn, ó bẹ̀rẹ̀ sí ronú lórí ohun tí ọ̀gá rẹ̀ sọ fún un. Ló bá kúkú pinnu pé òun ò ní ṣẹ́ oyún náà. Lẹ́yìn tí màmá mi bí mi lọ́dún 1964, ó gbé mi lọ sílé ìtọ́jú àwọn ọmọ aláìlóbìí.
Bí Mo Ṣe Kọ́kọ́ Gbọ́ Nípa Òtítọ́ Bíbélì
Nígbà tí mi ò ju nǹkan bí ọmọ ọdún méjì lọ, màmá mi àti ọkọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ wá mú mi kúrò nílé ìtọ́jú àwọn ọmọ aláìlóbìí. Nígbà tí a sì ń gbé ní ìlú Sainte-Marguerite-du-Lac-Masson, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ń lọ sáwọn ìpàdé ìjọ. Àmọ́, kò pẹ́ púpọ̀ tá a fi kó lọ sí ìlú Boisbriand, níbẹ̀ làwọn òbí mi ò ti kẹ́kọ̀ọ́ mọ́.
Lọ́dún mélòó kan lẹ́yìn náà, wọ́n tún ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn nìṣó. Mo máa ń tẹ́tí sí ohun tí wọ́n ń sọ nípa Párádísè orí ilẹ̀ ayé tí Bíbélì ṣèlérí. (Lúùkù 23:43) Bí mo ṣe dẹni tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an nìyẹn.
Àfìgbà tó di ọjọ́ kan báyìí, tí Màmá sọ fún mi pé àwọn ò gbà káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́ àti pé a ò tún ní lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba mọ́. Inú mi kọ́kọ́ dùn. Nítorí pé ọmọ ọdún mẹ́jọ péré ni mí nígbà náà, àwọn ìpàdé yẹn ti máa ń gùn jù lójú mi. Àmọ́, nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, mo fẹ́ bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa gbígbàdúrà sí i, ó ń ṣe mí bíi pé bóyá ló máa tẹ́tí sí mi.
Ní ọ̀sán ọjọ́ Sunday tó tẹ̀ lé e, mo rí àwọn aládùúgbò wa tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ń lọ ṣèpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Mo bá ń sunkún, mo sì ń bi Ọlọ́run pé, “Kí ló fà á táwọn ọmọ tiwọn fi ń lọ sípàdé ṣùgbọ́n témi ò lè lọ?” Síbẹ̀, ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 33:18 pàpà ní ìmúṣẹ. Onísáàmù náà sọ pé: “Wò ó! Ojú Jèhófà ń bẹ lọ́dọ̀ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, lọ́dọ̀ àwọn tí ń dúró de inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́.”
Bí Mo Tún Ṣe Dẹni Tó Ń Lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba
Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́tà, mo lọ sọ́dọ̀ àwọn tó wà ládùúgbò wa mo sì sọ fún Lilianne, màmá wọn pé mo fẹ́ máa bá wọn lọ sí ìpàdé. Ó ṣàlàyé fún mi pé ìyẹn ò lè ṣeé ṣe, níwọ̀n bí màmá mi ò ti fẹ́ ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́. Mo ṣáà kọ̀ jálẹ̀. Nítorí náà, ó bá mi wálé, ó sì béèrè lọ́wọ́ màmá mi bóyá òun lè máa mú mi lọ. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi nígbà tí màmá mi sọ pé òun fara mọ́ ọn. Ó ní àwọn ìpàdé wọ̀nyẹn á kọ́ mi ní àwọn ìlànà rere. Bó ṣe di pé mò ń lọ sí ìpàdé ní gbogbo ọjọ́ Sunday nìyẹn o.
Fún nǹkan bí ọdún mẹ́ta, ìpàdé lílọ mi ò já létí. Ṣùgbọ́n nígbà tí mo di ọmọ ọdún mọ́kànlá, àwọn òbí mi kọra wọn sílẹ̀, èmi àti ìyá mi sì kó lọ síbòmíràn. Bí mi ò tún ṣe gbúròó àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ nìyẹn o.
Mo Ṣàdédé Pàdé Wọn
Lọ́jọ́ kan, níbi tí mo jókòó sí lórí àtẹ̀gùn iwájú ilé wa làwọn Ẹlẹ́rìí méjì, Eddie Besson àti Don Fisher, ti wá bá mi tí wọ́n sì béèrè bóyá àwọn òbí mi wà nílé. Nígbà tí mo sọ pé wọn ò sí nílè, àwọn ọkùnrin náà yísẹ̀ padà wọ́n fẹ́ máa lọ. Ṣùgbọ́n mo gbá yá wọn, ìgbà yẹn gan-an ni ìjíròrò tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí wáyé.
Gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe lè retí, ó ya àwọn ọkùnrin méjèèjì lẹ́nu nígbà tí mo sọ fún wọn pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí. Mo ṣàlàyé bí ọ̀ràn mi ṣe rí fún wọn mo sì bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n padà wá nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn. Nígbà tí mo sọ fún màmá mi pé àwọn Ẹlẹ́rìí náà ń padà bọ̀, inú bí i gan-an, ó sì sọ fún mi pé òun ò ní jẹ́ kí wọ́n wọlé. Àní sẹ́, ó ti múra láti jáde nílé kí wọ́n tó dé. Pẹ̀lú omijé lójú ni mo fi ń bẹ màmá mi pé kó dúró. Bó ṣe kù díẹ̀ kó jáde báyìí ni agogo ẹnu ọ̀nà dún, Eddie Besson sì yọ sí wa ganbóro. Ìdùnnú ṣubú lu ayọ̀ fún mi nígbà tí màmá mi gbà láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì!
Àbùṣe bùṣe wàyí, mo tún dẹni tó lè máa lọ sáwọn ìpàdé ìjọ! Àmọ́, kò tíì tó ọdún kan lẹ́yìn náà ni màmá mi ò bá tún kẹ́kọ̀ọ́ mọ́. Lọ́tẹ̀ yìí, ó lóun ò gbọ́dọ̀ rẹ́sẹ̀ mi lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́, ó sì kó gbogbo ìtẹ̀jáde àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tọ́wọ́ rẹ̀ tẹ̀ dà nù. Ṣùgbọ́n, mo dọ́gbọ́n fi Bíbélì kan, ìwé orin kan, ìdìpọ̀ Ilé Ìṣọ́ méjì, ìwé ọdọọdún Yearbook of Jehovah’s Witnesses méjì àti ìwé kan tó ní àkọlé náà, Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiyea pa mọ́. Nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ tí Eddie Besson bá mi ṣe gbẹ̀yìn, mo béèrè ohun tí mo lè ṣe lọ́wọ́ rẹ̀, níwọ̀n bí mo ti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gidigidi. Ó gbà mí níyànjú pé kí n máa dá kẹ́kọ̀ọ́ kí n sì máa gbàdúrà déédéé. Ó mú un dá mi lójú pé Jèhófà á máa bójú tó mi. Nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́rìnlá ni mí lákòókò yìí.
Dídá “Ìpàdé” Ṣe
Látìgbà náà lọ ni mo ti máa ń wọ yàrá mi lọ ní gbogbo ọjọ́ Sunday tí màá sì ṣe bí ẹni pé mo wà ní ìpàdé. Màá kọ orín “Tẹjumọ Ere na!” ní ìbẹ̀rẹ̀ àti ní ìparí nítorí pé òun nìkan ni orin Ìjọba Ọlọ́run tí mo lè rántí. Títí dòní olónìí, mi ò lè kọ orin náà kí omijé má dà pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀ lójú mi. Mo tún máa ń kẹ́kọ̀ọ́ àpilẹ̀kọ tó wà nínú àwọn ìdìpọ̀ Ilé Ìṣọ́ tó wà lọ́wọ́ mi. Màá sì fi àdúrà parí “ìpàdé” mi. Nítorí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé jọ mọ́, mo mọ̀ pé Jèhófà ò jìnnà sí mi.
Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, èmi àti màmá mi kó lọ sí ìlú Montreal. Àwọn ọdún tá a lò níbẹ nira fún mi gan-an, nítorí pé gbínríngbínrín ni ilé wá kan kò sì sí ìfẹ́ kankan níbẹ̀.
Ó Wá Mi Kàn!
Lọ́jọ́ kan, màmá mi gba ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tí mo délé, mo rí ìwé náà lórí tábìlì mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣí i wò. Nígbà tí mo rí i pé ó lo orúkọ Ọlọ́run, Jèhófà, mo bẹ̀rẹ̀ sí ké, mo sì gbàdúrà wúyẹ́wúyẹ́ sí Jèhófà pé, “Jèhófà, o wá mi kàn!”
Ó wù mí kí n wá àwọn arákùnrin àti arábìnrin mi tí wọ́n jẹ́ Kristẹni kàn. Ṣùgbọ́n báwo ni màá ṣe rí wọn? Màmá mi sọ fún mi pé ó ṣeé ṣe ká rí lára àwọn aládùúgbò wa tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nítorí náà, nígbà tí mò ń lọ síbi iṣẹ́, mo yà sílé aládùúgbò wa kan mo sì tẹ agogo ẹnu ilẹ̀kùn. Ọkùnrin kan tí oorun ò tíì dá lójú ẹ̀ ló wá dá mi lóhùn. Ó yanu ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má lè pa á dé nígbà tí mo sọ fún un pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí àti pé mo fẹ́ ṣèrìbọmi! Ó ní kí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Josée Miron, máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ni màmá mi bá mà tún fárígá o. Ó sọ pé mo gbọ́dọ̀ ní sùúrù tí màá fi pé ọmọ ọdún méjìdínlógún kí n tó lè di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Ṣé Jèhófà Ni Kí N Yàn Ni àbí Kí N Fọwọ́ Mú Ìdílé?
Ọ̀gá tó gbà mí síṣẹ́ kíyè sí i pé nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ rọgbọ fún mi mọ́ nínú ilé. Ó sábà máa ń ké sí mi pé kí n wá gbádùn òpin ọ̀sẹ̀ pẹ̀lú òun àti ìyàwó òun. Èmi kúkú fẹ́ran ẹṣin ní tèmí, nítorí náà a jọ́ máa ń gẹṣin káàkiri. Bí òbí ni wọ́n sì rí fún mi.
Lọ́jọ́ kan, ọ̀gá mi yìí, sọ fún mi pé òun àti ìyàwó òun fẹ́ràn mi gan-an, àwọn á sì fẹ́ kí n wá máa gbé lọ́dọ̀ àwọn. Wọ́n fi ohun tí mo ti ń wá látọjọ́ yìí lọ̀ mí, ìyẹn ni ìdílé onífẹ̀ẹ́. Kiní kan wá ni o, wọ́n ò ní fẹ́ kí ń máa dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́. Wọ́n láwọn fún mi ní ọ̀sẹ̀ kan kí n fi ronú lé e lórí, ṣùgbọ́n ọjọ́ kan gan-an ti pẹ́ jù. Lójú ẹsẹ̀ ni mo sọ èrò ọkàn mi fún wọn. Jèhófà ò fi mi sílẹ̀ nígbà kan rí, èmi náà ò sì ní fí i sílẹ̀.
Iṣẹ́ Ìsìn Mi sí Ọlọ́run
Nítorí ìṣòro tó ń bá mi fínra nínú ilé, mo kó lọ sọ́dọ̀ ọkùnrin tóun àti màmá mi jọ kọra wọn sílẹ̀. Ó gbà mí níyànjú láti máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ mi nìṣó, nígbà tó sì di December 17, 1983, tí mo ti pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún, mo ṣèrìbọmi. Inú mi dùn gan-an láti rí Eddie Besson lọ́jọ́ tí mo ṣèrìbọmi. Ó ti wá rí i kedere báyìí pé mo ti di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà!
Àmọ́ ṣá o, mi ò tún rójú ẹni tó jẹ́ bàbá fun mi nílẹ̀ mọ́ lẹ́yìn tí mo ti ṣèrìbọmi. Nígbàkigbà tí mo bá ń gbàdúrà, á máa sọ̀rọ̀ sókè fatafata, á sì máa sọ nǹkan lù mí! Ó tiẹ̀ fi dandan lé e pé mo gbọ́dọ̀ máa bá ìwé kíkà mi nìṣó lọ́nà tí kò ní jẹ́ kí n lè di áṣáájú ọ̀nà, ìyẹn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Nígbà tó tiẹ̀ wá yá ó ní kí n kúrò nílé òun. Ó fún mi ní ìwé sọ̀wédowó ọgọ́rùn-ún dọ́là [$100], ó sì sọ fún mi pé nígbà tí mo bá rí i pé Jèhófà ò lọ́wọ́ sọ́ràn mi mọ́, kíá ni màá lọ gba owó náà ní báńkì.
Mo di aṣáájú ọ̀nà ní September 1, 1986, mi ò sì tíì lọ gba owó tí wọ́n kọ sínú ìwé sọ̀wédowó náà títí dòní olónìí! Nígbà míì, ó máa ń nira láti ṣe aṣáájú ọ̀nà láwọn àgbègbè àrọko láìní ọkọ ayọ́kẹ́lẹ́. Ṣùgbọ́n adúrótini-lọ́jọ́-ìṣòro làwọn tá a jọ wà nínú ìjọ àdúgbò, ìrànlọ́wọ́ wọn kì í sì í já létí.
Nígbà tó ṣe, mo bá arákùnrin onínúure kan tó ń jẹ́ Ruben Lenz pàdé. A ṣègbéyàwó lọ́dún 1989. Ní báyìí, Ruben ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nílùú Milton, tó wà ní Ontario, lórílẹ̀-èdè Kánádà níbi tá à ń gbé láti ọdún 2002. Ìgbéyàwó wa ni ọ̀kan lára oore títóbi jù lọ tí Jèhófà tíì ṣe fún mi. Mò ń bá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà mi lọ títí tá a fi bí ọmọ wa àkọ́kọ́, Erika, lọ́dún 1993. Ọdún mẹ́tà ó lé díẹ̀ lẹ́yìn náà lá tó wá bí ọmọ wa ọkùnrin tó ń jẹ́ Mika. Lẹ́yìn ọdún gbọọrọ ti mo fi nìkàn wà, Jèhófà Ọlọ́run ti fi ìdílé tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bíi tèmí jíǹkí mi.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni mo máa ń pé jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn Jèhófà nígbà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà, n kò fìgbà kan rí ṣíwọ́ láti máa gbẹ́kẹ̀ mi lé Ọlọ́run. Mi ò sì gbà gbé ìlérí tó ṣe nípa ìyè ayérayé nínú Párádísè. (Jòhánù 3:36) Mo dúpẹ́ mo tún ọpẹ́ dá pé Jèhófà “wá” mi rí!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Èmi rèé lórí ẹṣin ọ̀gá mi
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Nelly Lenz rèé pẹ̀lú ọkọ rẹ̀, Ruben, àtàwọn ọmọ wọn méjèèjì, Erika àti Mika