Òtítọ́ fún Mi ní Ìwàláàyè Mi Padà
Àrùn AIDS ti pa ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ọ̀rẹ́ mi àtijọ́. Ṣáájú ikú wọn, mo sábà máa ń rí wọn ní àwọn òpópónà. Èmi pẹ̀lú ì bá ti kú bí kì í bá ṣe ti òtítọ́ ni. Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé.
WỌ́N bí mi ní December 11, 1954, èmi ni ọmọ kejì, mo sì jẹ́ àbígbẹ̀yìn John àti Dorothy Horry. Wọ́n sọ mí ní Dolores, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bí mi, Mọ́mì pè mí ní Dolly, nítorí pé ó ronú pé mo jọ ọmọlangidi (doll). Orúkọ ìnagijẹ náà mọ́ mi lórí, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn kò mọ̀ nígbà náà pé n óò wá di orísun ìṣòro bíburú jù lọ fún Mọ́mì.
A ń gbé ilé gbéetán gbọọrọ kan—tí a pè bẹ́ẹ̀ nítorí ìrísí gígùn, tóóró tí ó ní. Ó wà ní Òpópónà 61 ní New York City. Ilé gbéetán náà kò fi bẹ́ẹ̀ tuni lára; àwọn eku wà níbẹ̀. Àmọ́ lẹ́yìn tí ọ̀kan gé mi jẹ lálẹ́ ọjọ́ kan, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni a kó kúrò níbẹ̀.
Ní 1957, a kó lọ sí ìhà ìlà oòrùn ìsàlẹ̀ Manhattan. Tí a bá fi wé ibi tí a ti kó kúrò, ibí yìí kàmàmà—àwọn iyàrá dáradára, ọgbà ńlá kan ní ojúde fèrèsé mi, àti ìran Odò Ìlà Oòrùn. Mo lè máa wo àwọn ọkọ̀ tí ń kọjá lọ àti àwọn ọmọdé tí ń gbá bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá àti bọ́ọ̀lù orí kọnkéré nínú ọgbà ńlá náà. Dájúdájú, párádísè ni èyí jẹ́ fún mi. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, ìgbésí ayé aláìléwu mi bẹ̀rẹ̀ sí í dojú dé.
Ìmukúmu Ọtí àti Oògùn Líle
Mọ́mì àti Dádì máa ń jiyàn gan-an. N kò lóye ìdí rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, ṣùgbọ́n láìpẹ́ lẹ́yìn náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkíyèsí pé tọ̀sántòru ni dádì mi máa ń mutí yó kẹ́ri. Ìgbà gbogbo ni iṣẹ́ ń bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀, Mọ́mì nìkan ló sì ń ṣiṣẹ́. Nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ mi mọ̀ pé onímukúmu-ọtí ni Dádì, ẹlẹ́yà tí wọ́n ń fi mí ṣe mú kí ìgbésí ayé mi kún fún ìbànújẹ́.
Ńṣe ni nǹkan ń burú sí i. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Dádì di oníwà ipá, Mọ́mì sì lé e dànù. Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe di ìdílé olóbìíkan. Mo ti tó nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́jọ tàbí mẹ́sàn-án, ipò tí ìdílé wa wà sì ń dà mí lọ́kàn rú. Mọ́mì ní láti máa ṣiṣẹ́ léraléra láti mú kí nǹkan gbára, ní fífi èmi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin sílẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn ará àdúgbò lẹ́yìn ilé ẹ̀kọ́.
Nígbà tí mo wà ní ìpele ẹ̀kọ́ kẹfà, mo di ẹlẹ́mìí ọ̀tẹ̀ gan-an. Mo máa ń pa kíláàsì jẹ, n óò sì lọ sí Ọgbà Gbàgede Tompkins, tí n óò sì mu ọtí gbàgbé ìṣẹ́. Láìpẹ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú agbo àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n dàgbà gan-an jù mí lọ. Ọmọ ọdún 11 péré ni mí nígbà náà, ṣùgbọ́n mo wú ju ọjọ́ orí mi lọ, nítorí náà, ó ṣeé ṣe pé wọ́n ń kà mí sí ọmọ ọdún 16 tàbí 17. Agbo àwọn ọ̀rẹ́ tuntun yìí máa ń mutí, wọ́n máa ń mugbó, wọ́n máa ń lo èròjà LSD, wọ́n sì máa ń gún abẹ́rẹ́ oògùn líle heroin. Ní gidi, mo fẹ́ láti bá ẹgbẹ́ mu, nítorí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn èròjà wọ̀nyí dánra wò. Ní ọmọ ọdún 14, wọ́n ti di bárakú fún mi láti lè máa gbé ayé lọ.
Ìyá Mi Mọ̀
“Èmi ni mo bí ọ, n óò sì pa ọ́.” Ọ̀rọ̀ tí àwọn ìyá àdúgbò wa, tí àwọn ọmọ wọn ti kó wàhálà àti ìjákulẹ̀ púpọ̀ bá, máa ń sọ nìyẹn. Nígbà tí Mọ́mì, tí ó máa ń fìgbà gbogbo jẹ́ ẹni jẹ́jẹ́, tí ó sì ń kóra rẹ̀ níjàánu, mọ̀ pé ọmọ rẹ̀ ọlọ́dún 14 ń lo oògùn líle heroin, ó sọ pé òun yóò ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́—láti pa mí.
Mo sá wọ ilé ìwẹ̀, mo sì gbìyànjú láti tilẹ̀kùn mọ́ ara mi nípa fífi ẹsẹ̀ ti agbada ìwẹ̀, ṣùgbọ́n n kò yára tó. Wàyí, mo ti wọ gàù gan-an! Láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ ọ́, ó fi lílù pá mi lórí. Ohun kan ṣoṣo tí ó gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ìbínú Mọ́mì ni pé ẹ̀gbọ́n mi obìnrin, àti ẹni tí ó fẹjọ́ mi sùn, lè wọ inú ilé ìwẹ̀ náà, tí wọ́n sì di ìyá mi mú tí mo fi lè sá lọ kúrò nínú ilé gbéetán náà. Nígbà tí mo padà sílé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn—mo ti sá kúrò nílé fún ọ̀sẹ̀ díẹ̀—mo gbà láti gba ìrànlọ́wọ́ díẹ̀ nítorí ìṣòro oògùn líle mi.
Gbígba Ìrànlọ́wọ́ Amọṣẹ́dunjú
Ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, mo rí ìpolówó ọjà kan lórí tẹlifíṣọ̀n nípa ibùdó ìrànwọ́ lórí ìkọ́fẹpadà kúrò nínú ìjoògùnyó. Ó jẹ́ ibì kan tí àwọn ènìyàn tí wọ́n ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ ní ti gidi láti borí ìṣòro ìjoògùnyó ti lè rí i. Mo jíròrò ohun tí mo rí pẹ̀lú Mọ́mì, ó sì mú mi lọ sí ọ̀kan lára àwọn ibùdó wọn ní New York City. Ibùdó náà jẹ́ kí ènìyàn ní àyíká tí ó jọ ti ìdílé, níbi tí àwọn ènìyàn tí ń gba ìsúnniṣe láti yí gbogbo ọ̀nà ìgbésí ayé wọn padà. Mo gbé ibẹ̀ fún nǹkan bí ọdún méjì ààbọ̀.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo jàǹfààní láti inú ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n pèsè, mo ní ìjákulẹ̀ gidigidi nígbà tí mo gbọ́ pé àwọn kan lára àwọn òṣìṣẹ́ tí mo gbẹ́kẹ̀ lé, tí mo sì bọ̀wọ̀ fún—tí ó sì yẹ kí wọ́n ti jáwọ́ lílo oògùn líle—tún ti bẹ̀rẹ̀ sí í lò wọ́n. Mo nímọ̀lára pé a dà mí, mo sì jẹ́ òmùgọ̀. Wọ́n ti kọ́ wa pé irọ́ ni òwe àtijọ́ náà pé, “Bí ẹnì kan bá ti jẹ́ ajoògùnyó rí, kò lè fi í sílẹ̀ mọ́.” Ṣùgbọ́n mo wá ń rí wọn bí ẹ̀rí tí ń fi hàn pé kì í ṣe irọ́.
Síbẹ̀síbẹ̀, nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún 17, mo padà sí ilé láìjoògùnyó mọ́, mo sì pinnu láti sapá láti má ṣe lo oògùn líle heroin mọ́ láé. Láàárín àkókò yìí, ìyá mi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Mo Ṣì Jẹ́ Aláìníwàrere Nínú Ìdílé
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ń kò lo oògùn líle mọ́, mo ṣì máa ń nímọ̀lára jíjẹ́ aláìníwàrere nínú ìdílé. Èyí jẹ́ nítorí pé ń kò ṣe tán láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà tuntun ní agbo ilé wa, tí ó ní nínú, láti má ṣe mu sìgá, láti má ṣe máa lọ sí òde dísíkò, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Láìpẹ́ láìjìnnà, Mọ́mì lé mi kúrò ní ilé gbéetán wa, nítorí pé mo kọ̀ jálẹ̀ láti yí ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ àti ẹ̀mí ìrònú ti ayé tí mo ní padà. Mo kórìíra rẹ̀ gan-an fún ohun tí ó ṣe yìí, ṣùgbọ́n ní ti gidi, ohun tí ó dára jù lọ tí ó yẹ kí ó ṣe fún mi nìyẹn. Ó dúró gangan lórí àwọn ìlànà òdodo, kò sì jẹ́ mikàn láé.
Nítorí náà, mo fi ilé sílẹ̀ láti lọ gbé ìgbésí ayé tuntun, tí ó sì sunwọ̀n sí i fún ara mi. Mo padà sí ilé ẹ̀kọ́ láti kọ́ iṣẹ́ kan láti lè gbọ́ bùkátà ara mi lákòókò tí mo bá wà ní kọ́lẹ́ẹ̀jì. Mo ṣe dáradára gan-an, mo sì padà di ẹni tí ó wúlò láwùjọ. Mo rí iṣẹ́ tí ó dára àti ilé gbéetán tèmi. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà ni eré ìfẹ́ bẹ̀rẹ̀ nígbà tí mo pàdé ọ̀rẹ́kùnrin mi àtijọ́ kan. A tún kó wọnú ìbáṣepọ̀ wa, a sì ní in lọ́kàn láti ṣe àwọn nǹkan lọ́nà títọ́, kí a sì ṣègbéyàwó.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ọ̀rẹ́kùnrin mi bẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn líle, nǹkan sì bẹ̀rẹ̀ sí í burú fún àwa méjèèjì. Nítorí pé n kò lè forí ti ìrora èrò ìmọ̀lára náà, mo ṣe ohun tí mo mọ̀ ọ́n ṣe jù lọ—mo fi oògùn líle pa ìmọ̀lára mi. Mo kira bọ lílo kokéènì, tí ó pèsè ohun tí a ń pè ní gbáná olówó. Kokéènì gbajúmọ̀ nígbà náà lọ́hùn-ún nítorí pé ọ̀pọ̀ ènìyàn kò kà á sí ìjoògùnyó. Ṣùgbọ́n ó burú ju oògùn líle heroin lọ fún mi.
Ní agbedeméjì àwọn ọdún 1970, mo mu kokéènì fún nǹkan bí ọdún mẹ́ta. Níkẹyìn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í rí i bí àwọn ìṣòro mi ṣe ń gbé òmíràn pọ̀n, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kàyéfì pé, ‘Ṣe gbogbo ohun tí ìgbésí ayé dá lé nìyí?’ Mo parí èrò sí pé bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, nígbà náà ó ti sú mi. Mo padà sọ́dọ̀ Mọ́mì, mo sì sọ fún un pé irú ọ̀nà ìgbésí ayé yìí ti tó àti pé mo fẹ́ padà sí ibùdó ìrànwọ́ lórí ìkọ́fẹpadà náà. Lẹ́yìn ọdún kan ààbọ̀ míràn níbẹ̀, mo tún bọ́ lọ́wọ́ ìjoògùnyó.
Mo Fẹ́rẹ̀ẹ́ Rí Òtítọ́
Mo tún rí iṣẹ́ tí ó dára, mo sì rí ilé gbéetán dáradára àti ọ̀rẹ́kùnrin kan. A di àfẹ́sọ́nà ara wa. Láàárín àkókò náà, Mọ́mì máa ń kàn sí mi déédéé. Ó máa ń bá mi sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì, ó sì máa ń fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ránṣẹ́ sí mi, ṣùgbọ́n n kò gbé wọn kà rí. Mo sọ fún Mọ́mì nípa ìwéwèé mi láti lọ́kọ, kí n sì ní ìdílé. Nítorí náà, ó fi ìwé kan tí ó yí ìgbésí ayé mi padà títí ayé ránṣẹ́ sí mi—Mimu Ki Igbesi Ayé Idile Rẹ Jẹ Alayọ.
Bí mo ṣe ń ka ìwé yìí, mo mọ ohun tí mo fẹ́ àti pé mo ti ń wá ọ̀nà àtirí i lọ́nà tí kò tọ́. Níkẹyìn, ẹnì kan lóye bí ìmọ̀lára mi ṣe rí àti ohun tí ó wà nínú ọkàn mi ní ti gidi. N kì í ṣe ẹ̀dá àràmàǹdà nítorí pé mo ní irú ìmọ̀lára tí mo ní—ara mi le! Bí ó ti wù kí ó rí, ẹni tí mo kó wọnú ìfẹ́ pẹ̀lú rẹ̀ máa ń fi mí rẹ́rìn-ín tí mo bá gbìyànjú láti fi ìwé Igbesi Ayé Idile àti Bíbélì hàn án. Kò ṣe àwọn ìyípadà tí ó pọn dandan láti gbádùn ìgbésí ayé ìdílé aláyọ̀. Nítorí náà, mo ní ìpinnu tí ó ṣòro láti ṣe—láti wà lọ́dọ̀ rẹ̀ tàbí láti fi í sílẹ̀. Mo pinnu pé ó ti tó àkókò láti fi í sílẹ̀.
Inú ọ̀rẹ́kùnrin mi ru. Nígbà tí mo padà sí ilé lọ́jọ́ kan, mo rí i pé ó ti fi bíléèdì gé gbogbo aṣọ mi wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ohun tí mo ní ló ti pòórá—bàtà, kóòtù, ohun ọ̀ṣọ́ ilé—ó ti ya wọ́n tàbí kí ó ti tà wọ́n. Aṣọ tí mo wọ̀ sọ́rùn ló ṣẹ́ kù. Mo fẹ́ẹ́ dùbúlẹ̀, kí n sì kú. Nígbà míràn, gbogbo ìgbìyànjú nínú ìgbésí ayé yóò sú ọ. Nítorí náà, ìwọ yóò tún padà sórí ṣíṣe ohun tí o ti máa ń ṣe láti kojú rẹ̀—ìwọ yóò fi oògùn líle pa ìmọ̀lára rẹ. Mo ronú pé yóò jẹ́ yálà ìyẹn tàbí ìṣekúpara-ẹni.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo padà sórí oògùn lílé, Mọ́mì kò jẹ́ sọ̀rètí nù nípa mi. Ó máa ń bẹ̀ mí wò, yóò sì mú àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti Jí! wá. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, nígbà tí a ń sọ̀rọ̀, mo sọ ìmọ̀lára mi fún un—pé gbígbìyànjú ti sú mi àti pé ìṣòro náà ti bò mí mọ́lẹ̀ pátápátá. Ńṣe ni ó kàn sọ pé: “O ti gbìyànjú ohun gbogbo, kí ló ṣe tí o kò gbìyànjú ti Jèhófà?”
Òtítọ́ Gbà Mí Sílẹ̀
Ọdún 1982 ni mo gbà láti ṣe ohun tí ó ti ń rọ̀ mí láti ṣe fún ọ̀pọ̀ ọdún. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lemọ́lemọ́. Láìpẹ́, ohun tí mo ń kọ́ ń ru ọkàn mi sókè. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í mọrírì pé ìwàláàyè mi ṣeyebíye gan-an sí Jèhófà àti pé ète gidi kan wà nínú ìgbésí ayé. Ṣùgbọ́n mo wá mọ̀ pé bí mo bá fẹ́ láti sin Jèhófà, mo ní ọ̀pọ̀ ìyípadà láti ṣe àti pé mo nílò ìtìlẹ́yìn ní ti èrò ìmọ̀lára àti tẹ̀mí. Nítorí náà, mo bi Mọ́mì bí mo bá lè kó padà wálé.
Mọ́mì lo ìṣọ́ra, níwọ̀n bí mo ti já a kulẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Ó bá Kristẹni alàgbà kan sọ̀rọ̀ nípa ìbéèrè mi láti kó padà sọ́dọ̀ rẹ̀. Nígbà tí ó rí i pé Mọ́mì nímọ̀lára pé ó ṣeé ṣe gan-an pé kí n yí padà ní tòótọ́ lọ́tẹ̀ yìí, ó rọ̀ ọ́ pé: “O kò ṣe fún un láyè lẹ́ẹ̀kan sí i?”
Ọpẹ́ ni pé lọ́tẹ̀ yìí n kò já Mọ́mì kulẹ̀. Mo ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, mo yí ìgbésí ayé mi padà pátápátá. Àmọ̀ràn tí Bíbélì, Ọ̀rọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run, pèsè, jẹ́ kí n la àwọn àkókò líle koko náà já. (Jòhánù 17:17) Mo tilẹ̀ jáwọ́ sìgá mímu, ìsọdibárakú tí ó le jù fún mi láti borí ju ìsọdibárakú heroin àti kokéènì lọ. Fún ìgbà àkọ́kọ́, inú mi dùn gan-an pé mo wà láàyè.
Ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, ní December 24, 1983, mo fi àmì ẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi sí Jèhófà hàn nípa ìrìbọmi. Ní oṣù April tí ó tẹ̀ lé e, mo bẹ̀rẹ̀ ṣí í ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, ó jẹ́ ọ̀nà mímú iṣẹ́ òjíṣẹ́ gbòòrò sí i. Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ mi tẹ́lẹ̀ rí máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ tí wọ́n bá rí mi nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ó rí gan-an bí àpọ́sítélì Pétérù ti kìlọ̀ tẹ́lẹ̀ pé: “Nítorí ẹ kò máa bá a lọ ní sísáré pẹ̀lú wọn ní ìlà ipa ọ̀nà yìí sínú kòtò ẹ̀gbin jíjìnwọlẹ̀ kan náà tí ó kún fún ìwà wọ̀bìà, ó rú wọn lójú wọ́n sì ń bá a lọ ní sísọ̀rọ̀ yín tèébútèébú.”—Pétérù Kìíní 4:4.
Ní September 1984, mo di aṣáájú ọ̀nà déédéé, kò sì pẹ́ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá. Díẹ̀ lára àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyí jẹ́ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ti fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ nígbà tí mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Àkókò tí ń ru ọkàn sókè gan-an ni èyí jẹ́ nínú ìgbésí ayé mi nítorí pé ó ṣeé ṣe fún mi láti ran ọ̀pọ̀ àwọn èwe lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Bíbélì. Ìgbà gbogbo ni mo máa ń fẹ́ láti ní àwọn ọmọ, nítorí náà, lọ́nà àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́, dídi ìyá fún àwọn ọmọ nípa tẹ̀mí ti jẹ́ orísun ìdùnnú fún mi nígbà gbogbo.—Fi wé Kọ́ríńtì Kìíní 4:15.
Bí ọdún ti ń gorí ọdún, mo máa ń rí àwọn ọ̀rẹ́ mi àtijọ́ tí a jùmọ̀ máa ń lo oògùn líle nígbà kan rí ní òpópónà nítòsí ilé wa. Ní àbáyọrí lílo abẹ́rẹ́ kan náà pẹ̀lú àwọn ẹni tí wọ́n ní àkóràn, wọ́n ti kó àrùn AIDS, wọn kò sì ṣeé rí lójú. Ọ̀pọ̀ lára wọ́n ti kú tipẹ́. Mo mọ̀ pé èmi pẹ̀lú ì bá ti kú bí kì í bá ṣe ti òtítọ́ Bíbélì ni. Ní tòótọ́, ó ti fún mi ní ìwàláàyè mi padà.
Yẹra fún Ìrora Náà
Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń dàníyàn pé kí n ti mọ òtítọ́ nígbà tí mo wà lọ́mọdé, kí n sì ti yẹra fún ìgbésí ayé tí ó kún fún ìrora àti ìbànújẹ́. Jèhófà ń ràn mí lọ́wọ́ nísinsìnyí láti kojú àwọn ìrora tí lílo ìgbà èwe lọ́nà tí kò tọ́ ń mú wá, ṣùgbọ́n mo ní láti dúró títí di inú ètò àwọn nǹkan tuntun fún ìwòsàn pátápátá kúrò nínú àwọn àpá èrò ìmọ̀lára. (Ìṣípayá 21:3, 4) Lónìí, mo máa ń gbìyànjú gan-an láti sọ fún àwọn ọ̀dọ́ pé ìbùkún ni ó jẹ́ fún wọn láti mọ Jèhófà àti láti máa rí ìtìlẹ́yìn ètò àjọ rẹ̀ gbà ní ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣàmúlò ohun tí ó ń fi kọ́ni.
Ayé lè fara hàn bí èyí tí ń ṣe yòyòyìnyìn, tí ó sì ń fani mọ́ra. Ó sì fẹ́ kí o gbà gbọ́ pé o lè gbádùn ìmóríyá lọ́nà tirẹ̀ láìsí ìrora. Ṣùgbọ́n èyí kò wulẹ̀ lè ṣeé ṣe. Ayé yóò ṣe ọ́ báṣubàṣu, tí ó bá sì ti ṣe tán, yóò já ọ dà nù. Bíbélì sọ ní tòótọ́ pé Èṣù ni alákòóso ayé—ní gidi, ọlọ́run rẹ̀—àti pé a kò gbọdọ̀ fẹ́ràn ayé tàbí àwọn ohun tí ó wà nínú rẹ̀. (Jòhánù 12:31; 14:30; 16:11; Kọ́ríńtì Kejì 4:4; Jòhánù Kìíní 2:15-17; 5:19) Níwọ̀n bí àwọn ènìyàn ayé ti wà gẹ́gẹ́ bí ẹrú ìdibàjẹ́, ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú wọn kò lè fún ọ ní ayọ̀ tòótọ́.—Pétérù Kejì 2:19.
Ìrètí mi ni pé sísọ àwọn ohun wọ̀nyí nípa ara mi yóò ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti rí i pé “ìyè tòótọ́ gidi”—ìyè ayérayé nínú ayé tuntun Ọlọ́run—ni ìgbésí ayé kan ṣoṣo tí ó tóyeyẹ láti làkàkà fún. Láìka ire àti ibi tí a lè kojú bí a ti ń rìn nínú òtítọ́ sí, ipò nǹkan kò sàn jù ní òdì kejì, nínú ayé Sátánì. Sátánì wulẹ̀ ń gbìyànjú láti mú kí ó jọ bẹ́ẹ̀ ni. Mo gbàdúrà pé, pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin mi, kí n lè tẹjú mi mọ́ ìyè gidi náà, bẹ́ẹ̀ ni, mọ́ ìyè ayérayé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Tímótì Kìíní 6:19)—Gẹ́gẹ́ bí Dolly Horry ti sọ ọ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Pẹ̀lú ìyá mi, a ń wàásù ní Ọgbà Gbàgede Tompkins