ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 10/1 ojú ìwé 5-9
  • Ogún-Ìní Ṣíṣọ̀wọ́n ti Kristian Kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ogún-Ìní Ṣíṣọ̀wọ́n ti Kristian Kan
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bàbá Mi Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́ Bibeli
  • Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Nínú Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Náà
  • Ṣíṣiṣẹ́sin Ọlọrun Pẹ̀lú Àwọn Òbí Mi
  • Ìdálẹ́kọ̀ọ́ Láti Ọ̀dọ̀ Àwọn Òbí Mi Àgbà
  • Àwọn Ọdún Inúnibíni
  • Mo Kún fún Ìmoore fún Ìdarí Àwọn Òbí Mi
  • Ìgbéyàwó àti Iṣẹ́ Arìnrìn-Àjò
  • Títọ́jú Àwọn Òbí
  • Àwọn Òbí Wa Kọ́ Wa Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ogún Wa Nípa Tẹ̀mí Tí Ó Dọ́ṣọ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Mo Ní Àjọṣe Tó Dáa Pẹ̀lú Ọlọ́run àti Pẹ̀lú Màmá Mi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Òbí Mi Bá Ń Ṣàìsàn?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 10/1 ojú ìwé 5-9

Ogún-Ìní Ṣíṣọ̀wọ́n ti Kristian Kan

GẸ́GẸ́ BÍ BLOSSOM BRANDT TI SỌ Ọ́

Òjò yìnyín ń rọ̀ ní San Antonio, Texas, ní January 17, 1923, tí ó jẹ́ ọjọ́ tí a bí mi. Ìta tutù nini, ṣùgbọ́n a kí mi káàbọ̀ sínú ọwọ́ lílọ́wọ́ọ́wọ́ ti àwọn òbí onífẹ̀ẹ́ tí wọ́n jẹ́ Kristian, Judge àti Helen Norris. Láti inú ìrántí mi ìjímìjí, gbogbo nǹkan tí àwọn òbí mí ṣe rọ̀gbà yíká ìjọsìn wọn sí Jehofa Ọlọrun.

NÍ 1910 nígbà tí ìyá mi jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ, àwọn òbí rẹ̀ ṣíkúrò láti ẹ̀bá Pittsburgh, Pennsylvania, lọ sí oko kan lẹ́yìn-òde Alvin, Texas. Níbẹ̀ ni wọ́n ti láyọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bibeli lọ́dọ̀ aládùúgbò kan. Màmá mi lo ìyókù ìgbésí-ayé rẹ̀ ní wíwá ọ̀nà láti mú àwọn ènìyàn nífẹ̀ẹ́-ọkàn nínú ìrètí Ìjọba náà. Òun ni a baptisi ní 1912 lẹ́yìn tí ìdílé náà ti ṣí lọ sí Houston, Texas.

Ìyá mi àti àwọn òbí rẹ̀ kọ́kọ́ pàdé Charles T. Russell, ààrẹ àkọ́kọ́ ti Watch Tower Bible and Tract Society, nígbà tí ó ṣèbẹ̀wò sí ìjọ wọn ní Houston. Ìdílé náà sábà máa ń fààyè gba àwọn aṣojú arìnrìn-àjò fún Society, tí a ń pè ní arìnrìn-àjò ìsìn nígbà yẹn sínú ilé wọn. Ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, màmá mi ṣíkúrò pẹ̀lú àwọn òbí rẹ̀ lọ sí Chicago, Illinois, Arákùnrin Russell ni yóò sì tún bẹ ìjọ tí ó wà níbẹ̀ wò.

Ní 1918, àrùn gágá kọlu Ìyá-Àgbà, àti nítorí ìyọrísí ipa àìlera tí ó ní lórí ìlera rẹ̀, àwọn dókítà dámọ̀ràn pé kí ó máa gbé ní ibi tí ipò ojú-ọjọ́ ti túbọ̀ lọ́wọ́ọ́wọ́. Níwọ̀n bí Bàbá-àgbà ti ń ṣiṣẹ́ fún ilé-iṣẹ́ ọkọ̀ ojú-irin Pullman, ó gba ìṣípòpadà padà sí Texas ní 1919. Níbẹ̀, ní San Antonio, màmá mi pàdé mẹ́ḿbà ìjọ kan tí ó jẹ́ ọ̀dọ́, onítara tí ń jẹ́ Judge Norris. Wọ́n wu araawọn lójú-ẹsẹ̀, nígbà tí ó sì yá wọ́n ṣègbéyàwó, Judge sì di bàbá mi.

Bàbá Mi Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́ Bibeli

Judge (adájọ́) ni a fún ní orúkọ rẹ̀ tí ó ṣàjèjì nígbà ìbí rẹ̀. Nígbà tí bàbá rẹ̀ kọ́kọ́ gán-án-ní rẹ̀, ó sọ pé: “Ara ọmọ yẹn balẹ̀ bi ara adájọ́,” ìyẹn sì di orúkọ rẹ̀. Ní 1917, nígbà tí bàbá mi jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, a fún un ní àwọn ìwé-àṣàrò-kúkúrú náà Where Are the Dead? àti What Is the Soul? tí Watch Tower Bible and Tract Society tẹ̀jáde. Bàbá bàbá mi ti kú ní ọdún méjì ṣáájú, àwọn ìwé-àṣàrò-kúkúrú náà sì pèsè ìdáhùn tí ó ti ń wá kiri nípa ipò àwọn òkú fún un. Ní kété lẹ́yìn náà ó bẹ̀rẹ̀ síí lọ sí ìpàdé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, gẹ́gẹ́ bí a ti mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sí nígbà náà.

Bàbá mi yára fẹ́ láti ṣàjọpín nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ. Ó gba ìpínlẹ̀ ibi tí ó ti lè wàásù, òun yóò sì gun kẹ̀kẹ́ rẹ̀ lọ síbẹ̀ lẹ́yìn ilé-ẹ̀kọ́ láti pín àwọn ìwé-àṣàrò-kúkúrú kiri. Ṣíṣàjọpín ìrètí Ìjọba náà gbà á lọ́kàn pátápátá, nígbà tí ó sì di March 24, 1918, ó fàmì ṣàpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ rẹ̀ sí Jehofa nípa ìrìbọmi nínú omi.

Ní ọdún tí ó tẹ̀lé e nígbà tí màmá mi ṣí lọ sí San Antonio, bàbá mi ni a fà mọ́ra pẹ̀lú ohun tí ó sọ pé ó jẹ́ “ẹ̀rín-múṣẹ́ àti ojú tí ń dánilọ́rùn jùlọ” tí òun tíì rí rí. Wọ́n sọ ọ́ di mímọ̀ láìpẹ́ pé àwọn fẹ́ láti ṣègbéyàwó, ṣùgbọ́n kò rọrùn fún wọn láti mú ọ̀ràn dá àwọn òbí ìyá mi lójú. Síbẹ̀, ní April 15, 1921, ètò-ìgbéyàwó náà wáyé. Àwọn méjèèjì ní iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bíi góńgó wọn.

Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Nínú Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Náà

Nígbà tí ọwọ́ màmá àti bàbá mi dí fún ìwéwèé láti lọ sí àpéjọpọ̀ Cedar Point, Ohio, ní 1922, ó hàn sí wọn pé màmá mi ti lóyún mi. Ní kété lẹ́yìn ìbí mi, nígbà tí bàbá mi jẹ́ kìkì ẹni ọdún méjìlélógún, òun ni a yàn ní olùdarí iṣẹ́-ìsìn ìjọ. Èyí túmọ̀sí pé òun ni ó ń ṣe gbogbo ètò iṣẹ́-ìsìn pápá. Ní ẹnu ìwọ̀nba ọ̀sẹ̀ bíi mélòókan, màmá mi ti gbé mi jáde lọ sínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ ẹnu-ọ̀nà-dé-ẹnu-ọ̀nà. Òtítọ́ náà ni pé, àwọn òbí mi àgbà pẹ̀lú fẹ́ràn láti mú mi dání pẹ̀lú wọn lọ sẹ́nu iṣẹ́-òjíṣẹ́.

Nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún méjì péré, àwọn òbí mi ṣí lọ sí Dallas, Texas, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà ní ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà. Ní alẹ́ wọ́n yóò sùn lórí àkéte kan lẹ́bàá ọ̀nà wọ́n yóò sì gbé mi sí ààyè ìjókòó ẹ̀yìn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́. Àmọ́ ṣa o, eré ni ó jọ ní ojú mi, ṣùgbọ́n ó ṣe kedere láìpẹ́ pé wọn kò tíì ṣetán fún ìgbésí-ayé aṣáájú-ọ̀nà síbẹ̀. Nítorí náà bàbá mi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-ajé kan. Bí àkókò ti ń lọ, ó kan ọkọ̀ àgbérìn kékeré kan ní ìmúrasílẹ̀ fún bíbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lẹ́ẹ̀kan síi.

Kí n tó bẹ̀rẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́, ìyá mí kọ́ mi láti mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà, mo sì mọ ìsọdipúpọ̀ nọ́ḿbà látorí oókan sí ẹẹ́rin. Ó pa ọkàn rẹ̀ pọ̀ sórí ríràn mí lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́. Yóò gbé mi nàró sórí àga lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀ kí n lè nu àwọn àwo gbẹ bí ó ti ń fọ̀ wọ́n, yóò sì kọ́ mi láti ka àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ sórí àti láti kọ àwọn orin Ìjọba, tàbí orin mímọ́ bí a ti ń pè wọ́n nígbà náà.

Ṣíṣiṣẹ́sin Ọlọrun Pẹ̀lú Àwọn Òbí Mi

Ní 1931 gbogbo wa lọ sí àpéjọpọ̀ gbígbádùnmọ́ni náà ní Columbus, Ohio, níbi tí a ti gba orúkọ náà Ẹlẹ́rìí Jehofa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ péré, mo ronú pé ó jẹ́ orúkọ tí ó lẹ́wà jùlọ tí mo tíì gbọ́ rí. Ní kété lẹ́yìn tí a padà sí ilé, iná run iṣẹ́-ajé bàbá mi, bàbá mi àti màmá mi sì gba èyí sí “ìfẹ́-inú Oluwa” pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lẹ́ẹ̀kan síi. Nípa báyìí, bẹ̀rẹ̀ ní ìgbà òjò 1932, a gbádùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.

Àwọn òbí mi ṣe aṣáájú-ọ̀nà ní àárín gbùngbùn Texas nítorí àtiwà nítòsí àwọn òbí màmá mi, tí wọ́n ṣì wà ní San Antonio. Ṣíṣí kúrò níbi iṣẹ́-àyànfúnni kan síbi iṣẹ́-àyànfúnni mìíràn túmọ̀sí pé mo níláti máa yí ilé-ẹ̀kọ́ padà lemọ́lemọ́. Nígbà mìíràn àwọn ọ̀rẹ́ tí kò ronújinlẹ̀ yóò sọ pé, “Èéṣe tí ẹ kò fi fìdíkalẹ̀ síbì kan kí ẹ sì ní ilé kan fún ọmọ yẹn,” bí ẹni pé a kò bójútó mi lọ́nà yíyẹ. Ṣùgbọ́n mo ronú pé ìgbésí-ayé wa múniláyọ̀ àti pé mo ń ran bàbá àti màmá mi lọ́wọ́ nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ wọn. Níti gàsíkíyá, wọ́n ń kọ́ mi wọ́n sì ń múra mi sílẹ̀ fún ohun tí yóò di ọ̀nà ìgbésí-ayé tèmi fúnraàmi nígbà tí ó bá yá.

Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù mo ń sọ fún bàbá àti màmá mi pé mo fẹ́ láti di ẹni tí a baptisi, wọ́n sì sábà máa ń bá mi sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Wọ́n fẹ́ rí i dájú pé mo mọ bí ìpinnu mi ti ṣe pàtàkì tó. Ní December 31, 1934, ọjọ́ náà dé fún ìṣẹ̀lẹ̀ ṣíṣe pàtàkì gidi yìí nínú ìgbésí-ayé mi. Bí ó ti wù kí ó rí, ní alẹ́ tí ó kángun sí òwúrọ̀ ọjọ́ ìrìbọmi, bàbá mi rí i dájú pé mo ti tọ Jehofa lọ nínú àdúrà. Lẹ́yìn náà ó ṣe ohun dídára kan. Ó mú kí gbogbo wa kúnlẹ̀ lórí eékún wa, ó sì gba àdúrà kan. Ó sọ fún Jehofa pé inú òun dùn nípa ìpinnu ọmọdébìnrin òun kékeré láti ya ìgbésí-ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Un. Ó lè dá ọ lójú pé, ní gbogbo sànmánì tí ń bọ̀, èmi kò jẹ́ gbàgbé alẹ́ yẹn láé!

Ìdálẹ́kọ̀ọ́ Láti Ọ̀dọ̀ Àwọn Òbí Mi Àgbà

Láàárín 1928 àti 1938, mo lo àkókò púpọ̀ ní ṣíṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn òbí mi àgbà ní San Antonio. Ọ̀nà ìgbàṣe nǹkan déédéé pẹ̀lú wọn fi púpọ̀ rí bákan náà pẹ̀lú ti àwọn òbí mi. Ìyá-Àgbà ti jẹ́ olùpín-ìwé ìsìn kiri, bí wọ́n ti máa ń pe àwọn aṣáájú-ọ̀nà, ó sì di aṣáájú-ọ̀nà aláàbọ̀ àkókò lẹ́yìn náà. A yan bàbá-àgbà ní aṣáájú-ọ̀nà ní December 1929, nítorí náà iṣẹ́-ìsìn pápá ni ó sábà máa ń lòde.

Bàbá-Àgbà yóò fi ọwọ́ rẹ̀ gbá mi mú ní alẹ́ yóò sì kọ́ mi ní orúkọ àwọn ìràwọ̀. Òun yóò ka ewì fún mi láti orí. Mo rin ọ̀pọ̀ ìrìn-àjò pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú-irin ti Pullman nígbà tí ó ń ṣiṣẹ́ fún ojú-ọ̀nà irin náà. Òun sábà máa ń jẹ́ ẹnìkan tí mo lè yíjú sí nígbà tí mo bá wà nínú ìṣòro; òun yóò tù mi nínú yóò sì nu omijé mi nù kúrò. Síbẹ̀, nígbà tí a bá bá mi wí fún híhùwà tí kò tọ́ tí mo sì wá ìtùnú lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, òun yóò wulẹ̀ sọ (àwọn ọ̀rọ̀ tí èmi kò lóye nígbà náà, ṣùgbọ́n tí dídún wọn ṣe kedere) pé: “Onítèmi, ọ̀nà oníláìfí kìí dán mọ́rán.”

Àwọn Ọdún Inúnibíni

Ní 1939, Ogun Àgbáyé Keji bẹ̀rẹ̀, àwọn ènìyàn Jehofa sì jìyà inúnibíni àti ìwà-ipá àwùjọ ènìyànkénìyàn. Ní òpin ọdún 1939, màmá mi ṣàìsàn gidigidi ó sì nílò iṣẹ́-abẹ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, nítorí náà a padà ṣí lọ sí San Antonio.

Àwọn àwùjọ ènìyànkénìyàn yóò gbárajọ bí a ti ń ṣe iṣẹ́ ìwé-ìròyìn lójú àwọn pópó San Antonio. Ṣùgbọ́n lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan, a ń wà níbẹ̀, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ní igun tí a yàn fún wa. Mo sábà máa ń wo bí a ti ń wọ́ bàbá mi lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá.

Bàbá mi gbìyànjú láti máa bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé màmá mi níláti dáwọ́ dúró. Bí ó ti wù kí ó rí, owó tí ó tó kò lè wọlé fún un lẹ́nu iṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́, nítorí náà ó níláti dáwọ́ dúró pẹ̀lú. Mo parí ilé-ẹ̀kọ́ ní 1939, èmi pẹ̀lú sí ń ṣiṣẹ́.

Orúkọ bàbá mi Judge (adájọ́) wá wúlò gidigidi ní àwọn ọdún wọnnì. Fún àpẹẹrẹ, àwùjọ àwọn ọ̀rẹ́ kan lọ jẹ́rìí nínú ìlú kan tí ó wà ní àríwá San Antonio, olóyè pàtàkì ibẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ síí da gbogbo wọn sí àtìmọ́lé. Ó ti fàṣẹ-ọba mú nǹkan bíi márùndínlógójì, papọ̀ pẹ̀lú àwọn òbí mi àgbà. Wọ́n fi tó bàbá mi létí, ó sì wakọ̀ lọ síbẹ̀. Ó rìn wọnú ọ́fíìsì olóyè pàtàkì náà ó sì sọ pé: “Èmi ni Judge (Adájọ́) Norris láti San Antonio.”

“Yẹsà, Adájọ́, kí ni kí n ṣe fún yín?” ni olóyè pàtàkì náà béèrè.

“Mo wá láti rí sí dídá àwọn ènìyàn wọ̀nyí sílẹ̀ kúrò nínú àtìmọ́lé,” ni èsì tí ó ti ẹnu bàbá mi jáde. Lọ́gán olóyè pàtàkì náà jẹ́ kí wọ́n jáde láìsí onídùúró—kò sì sí ìbéèrè síwájú síi mọ́!

Bàbá mi nífẹ̀ẹ́ sí ṣíṣiṣẹ́ ìjẹ́rìí nínú àwọn ilé ọ́fíìsì tí ó wà ní àwọn àgbègbè ilé-iṣẹ́, òun ní pàtàkì sì fẹ́ láti máa tọ àwọn adájọ́ àti lọ́yà lọ. Òun yóò sọ fún olùgbàlejò pé: “Emi ni Judge (Adájọ́) Norris, mo wá láti rí Adájọ́ Báyìí-Báyìí.”

Lẹ́yìn náà, nígbà tí ó bá rí adájọ́ náà, òun yóò kọ́kọ́ sọ pé: “Nísinsìnyí, kí n tó sọ̀rọ̀ nípa ohun tí mo bá wá, mo fẹ́ láti ṣàlàyé pé mo ti jẹ́ Adájọ́ fún àkókò gígùn jù ọ́ lọ. Mo ti jẹ́ ọ̀kan fún gbogbo ìgbésí-ayé mi.” Òun yóò sì wá ṣàlàyé bí ó ṣe gba orúkọ rẹ̀. Èyí máa ń jẹ́ ìnasẹ̀-ọ̀rọ̀ bí-ọ̀rẹ́ kan, ó sì mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ipò-ìbátan rere dàgbà pẹ̀lú àwọn adájọ́ ní àwọn ọjọ́ wọnnì.

Mo Kún fún Ìmoore fún Ìdarí Àwọn Òbí Mi

Mo ti wà nínú àwọn ọdún onírọ̀ọ́kẹ̀kẹ̀ ti ọ̀dọ́langba wọnnì, mo sì mọ̀ pé bàbá àti màmá mi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò àníyàn bí wọ́n ti ń wò tí wọ́n sì ń ṣe kàyéfì ohun tí èmi yóò ṣe tẹ̀lé e. Bí gbogbo àwọn ọmọ ti ń ṣe, mo dán bàbá àti màmá mi wò ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ní bíbéèrè láti ṣe ohun kan tàbí lọ sí ibikàn tí mo ti mọ̀ ṣáájú pé ìdáhùn wọn yóò jẹ́ bẹ́ẹ̀kọ́. Nígbà mìíràn èmi yóò sọkún. Níti gàsíkíyá, ìbá ti bù jó mi lójú bí wọ́n bá ti sọ pé: “Máṣe jáfara, ṣe ohun tí o fẹ́ ṣe. Àgunlá.”

Mímọ̀ pé èmi kò lè tì wọ́n láti yí àwọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n wọn padà fún mi ní ìmọ̀lára ààbò. Ní tòótọ́, èyí mú kí ó túbọ̀ rọrùn fún mi nígbà tí àwọn ọ̀dọ́ mìíràn bá dámọ̀ràn eré-ìnàjú tí kò bọ́gbọ́nmu, nítorí pé mo lè sọ pé: “Bàbá mi kò ní gbà.” Nígbà tí mo jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún, bàbá mi rí i dájú pe mo mọ ọkọ̀ wà àti pé mo gba ìwé-àṣẹ ọkọ̀ wíwà mi. Pẹ̀lúpẹ̀lú, ní nǹkan bí àkókò yìí ó fún mi ní kọ́kọ́rọ́ ilé kan. Ó wú mi lórí tóbẹ́ẹ̀ pé ó fọkàn tán mi. Mo nímọ̀lára pé àgbà ti ń dé náà nìyẹn, ó sì fún mi ní ìmọ̀lára ẹrù-iṣẹ́ àti ìfẹ́-ọkàn láti máṣe da ìfọkàntánni wọn.

Ní àwọn ọjọ́ wọnnì kò sí ìmọ̀ràn púpọ̀ tí a fifúnni nípa ìgbéyàwó, ṣùgbọ́n bàbá mi mọ Bibeli àti ohun tí ó sọ nípa gbígbéyàwó “kìkì nínú Oluwa.” (1 Korinti 7:39) Ó mú un ṣe kedere fún mi pé bí mo bá jẹ́ lọ gbé ọmọkùnrin ayé kan wálé, tàbí tilẹ̀ wo ọ̀kan lójú, ìjákulẹ̀ tí òun yóò ní yóò ti pọ̀ jù. Mo mọ̀ pé ó tọ̀nà, nítorí mo ti rí ayọ̀ àti ìṣọ̀kan tí ó wà nínú ìgbéyàwó wọn nítorí pé wọ́n gbéyàwó “nínú Oluwa.”

Ní 1941, nígbà tí mo jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlógún, mo ronú pé mo nífẹ̀ẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin kan nínú ìjọ. Aṣáájú-ọ̀nà ni ó sì ń kàwé láti di lọ́yà. Inú mi ń dáádùn. Nígbà tí a sọ fún àwọn òbí mi pé a fẹ́ láti ṣègbéyàwó, dípò fífi àìfọwọ́sí i hàn tàbí dídi ẹni tí ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni, wọ́n wulẹ̀ sọ pé: “Àwa yóò fẹ́ láti bẹ̀bẹ̀ ohun kan lọ́wọ́ rẹ̀, Blossom. A nímọ̀lára pé o kére jù, àwa yóò sì fẹ́ láti sọ fún ọ pé kí o dúró fún ọdún kan síi. Bí ìfẹ́ bá wọ̀ ọ́ lọ́kàn níti gidi, ọdún kan kò pẹ́ jù.”

Mo kún fún ọpẹ́ gidigidi pé mo fetísílẹ̀ sí ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n yẹn. Láàárín ọdún náà, mo dàgbàdénú díẹ̀ síi mo sì bẹ̀rẹ̀ síí rí i pé ọ̀dọ́mọkùnrin yìí kò ní àwọn ànímọ́ tí yóò mú kí ó jẹ́ alábàáṣègbéyàwó rere. Òun lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn fi ètò-àjọ náà sílẹ̀, mo sì bọ́ lọ́wọ́ ohun tí ìbá ti jẹ́ ìjábá nínú ìgbésí-ayé mi. Ó ti jẹ́ àgbàyanu tó láti ní àwọn òbí ọlọgbọ́n tí a lè gbáralé ìṣèdíyelé wọn!

Ìgbéyàwó àti Iṣẹ́ Arìnrìn-Àjò

Ní ìgbà ìwọ́wé 1946, lẹ́yìn ìgbà tí mo ti lo ọdún mẹ́fà nínú iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àti ṣíṣiṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́, ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó rẹwà jùlọ tí èmi tíì rírí rìn wọnú Gbọ̀ngàn Ìjọba wa. Gene Brandt ni a ti yàn gẹ́gẹ́ bí ẹnìkejì ìráńṣẹ́ arìnrìn-àjò fún àwọn ará, gẹ́gẹ́ bí a ti ń pe alábòójútó àyíká nígbà náà. Ìfàmọ́ra tọ̀tún-tòsì ni ó jẹ́, tí a sì ṣègbéyàwó ní August 5, 1947.

Láìpẹ́-láìjìnnà, bàbá mi àti Gene ṣí ọ́fíìsì ìṣirò-owó kan. Ṣùgbọ́n bàbá mi sọ fún Gene pé: “Ọjọ́ tí ọ́fíìsì yìí bá dí wa lọ́wọ́ fún ìpàdé tàbí iṣẹ́-àyànfúnni ti ìṣàkóso Ọlọrun kan, èmi yóò ti ilẹ̀kùn rẹ̀ pa tí èmi yóò sì sọ kọ́kọ́rọ́ rẹ̀ nù.” Jehofa bùkún ojú-ìwòye tẹ̀mí yìí, ọ́fíìsì náà sì pèsè lọ́nà tí ó pọ̀tó fún àwọn àìní ohun ti ara wa ó sì fààyè sílẹ̀ láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Bàbá mi àti Gene jẹ́ oníṣòwò rere, a sì ti lè fi tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn di ọlọ́rọ̀, ṣùgbọ́n èyí kìí ṣe góńgó wọn.

Ní 1954, Gene ni a késí sínú iṣẹ́ àyíká, èyí tí ó túmọ̀sí ìyípadà ńlá nínú ìgbésí-ayé wa. Báwo ni àwọn òbí mi yóò ṣe hùwàpadà? Lẹ́ẹ̀kan síi, ìdàníyàn wọn kìí ṣe fún araawọn ṣùgbọ́n fún ire Ìjọba Ọlọrun àti fún ire áásìkí tẹ̀mí àwọn ọmọ wọn. Wọn kò sọ fún wa rí pé: “Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi bí ọmọ kí á lè ní ọmọ-ọmọ?” Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sábà máa ń jẹ́: “Kí ni a lè ṣe láti ràn yín lọ́wọ́ nínú iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún?”

Nítorí náà nígbà tí ọjọ́ náà dé fún wa láti lọ, àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí àti ayọ̀ ni wọ́n ní fún wa fún àǹfààní ńláǹlà tí a ní. Wọn kò jẹ́ kí á nímọ̀lára rí láé pé a ń pa àwọn tì ṣùgbọ́n wọ́n máa ń wà lẹ́yìn wa gbágbágbá ni ní gbogbo ìgbà. Lẹ́yìn tí a lọ tán, wọ́n mú ọwọ́ araawọn dí nínú iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fún ọdún mẹ́wàá mìíràn síi. Bàbá mi ni a yàn ní alábòójútó ìlú San Antonio, ipò tí ó dìmú fún ọgbọ̀n ọdún. Ó láyọ̀ láti rí ìbísí láti orí ìjọ kan nínú ìlú-ńlá náà ní àwọn ọdún 1920 sí ìjọ mọ́kànléláàádọ́rìn kí ó tó kú ní 1991.

Fún èmi àti Gene, ìgbésí-ayé kún fún ìtara ayọ̀. A ní ayọ̀ jìgbìnnì ti ṣíṣiṣẹ́sin àwọn arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n ní ìpínlẹ̀-ìlú tí ó ju mọ́kànlélọ́gọ̀n lọ, àti bóyá kókó pàtàkì nínú gbogbo rẹ̀ ni, àǹfààní lílọ sí kíláàsì kọkàndínlọ́gbọ̀n ti Watchtower Bible School of Gilead ní 1957. Lẹ́yìnwá ìgbà náà a padà sẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn-àjò. Ní 1984, lẹ́yìn ọgbọ̀n ọdún nínú iṣẹ́ àyíká àti àgbègbè, Society fi inúrere fún Gene ní iṣẹ́-àyànfúnni àyíká kan ní San Antonio, níwọ̀n bí àwọn òbí wa ti lé ní ọgọ́rin ọdún tí ìlera wọn kò sì dára.

Títọ́jú Àwọn Òbí

Ní kìkì ọdún kan àti ààbọ̀ péré lẹ́yìn tí a ti padà sí San Antonio ni màmá mi dákú gbári tí ó sì kú. Ó yára ṣẹlẹ̀ gan-an débi pé èmi kò lè sọ díẹ̀ lára àwọn ohun tí mo fẹ́ láti sọ fún un. Èyí kọ́ mi láti bá bàbá mi sọ̀rọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀. Lẹ́yìn ọdún márùndínláàádọ́rin ìgbéyàwó, ó nímọ̀lára àìsíníbẹ̀ màmá mi gidigidi, ṣùgbọ́n a wà níbẹ̀ láti fún un ní ìfẹ́ àti ìtìlẹ́yìn.

Àpẹẹrẹ pípésẹ̀ sí ìpàdé, ìkẹ́kọ̀ọ́, àti iṣẹ́-ìsìn bàbá mi tí ó ti wà fún gbogbo ìgbésí-ayé rẹ̀ ń báa lọ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. Ó fẹ́ràn láti kàwé. Bí ó ti níláti dánìkanwà nígbà tí a bá wà nínú iṣẹ́-ìsìn, èmi yóò wá sí ilé èmi yóò sì béèrè pé, “Ìwọ ha nímọ̀lára ìdánìkanwà bí?” Ọwọ́ rẹ̀ ti dí tóbẹ́ẹ̀ ní kíkàwé àti kíkẹ́kọ̀ọ́, èrò náà kò tilẹ̀ tíì wá sí i lọ́kàn.

Àṣà gbogbo àkókò ìgbésí-ayé mìíràn wà tí a kò jẹ́ kí ó bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́. Bàbá mi ti sábà máa ń tẹpẹlẹ mọ́ ọn pé kí ìdílé jẹun papọ̀, ní pàtàkì lákòókò oúnjẹ àárọ̀, nígbàtí a ń ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ojoojúmọ́. A kò fún mi láàyè rí láé láti fi ilé sílẹ̀ láì ṣe é. Nígbà mìíràn èmi yóò sọ pé: “Bàbá mi, ṣùgbọ́n èmi yóò pẹ́ dé ilé-ẹ̀kọ́ (tàbí ibi iṣẹ́).”

“Kìí ṣe ọ̀rọ̀ ẹsẹ ìwé mímọ́ ni ó ń mú ọ pẹ́; oò tètè jí ni,” ni òun yóò sọ. Mo sì níláti dúró kí n sì gbọ́ ọ. Ó rí i dájú pé àpẹẹrẹ rere yìí wà títí di ọjọ́ tí ó kẹ́yìn ìgbésí-ayé rẹ̀. Èyí ni ìní mìíràn tí ó fi sílẹ̀ fún mi.

Bàbá wà lójúfò níti èrò-orí títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. Ohun tí ó mú kí títọ́jú rẹ̀ túbọ̀ rọrùn ni pé òun kò jẹ́ wúgbọ tàbí ráhùn láé. Óò, nígbà mìíràn òun yóò mẹ́nukan àrùn oríkèé ara rẹ̀, ṣùgbọ́n èmi yóò rán an létí pé ohun tí ó ní níti gidi ni “àrùn Adamu,” òun yóò sì rẹ́rìn-ín. Bí èmi àti Gene ti jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, bàbá mi rọra fọwọ́rọrí kú ní òwúrọ̀ November 30, 1991.

Ọjọ́-orí mi ti ju àádọ́rin ọdún lọ nísinsìnyí mo sì ń jàǹfààní síbẹ̀ láti inú àpẹẹrẹ rere àwọn òbí mi onífẹ̀ẹ́ tí wọ́n jẹ́ Kristian. Ó sì jẹ́ àdúrà onífọkànsí mi pé èmi yóò fẹ̀rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìmọrírì mi hàn fún ogún-ìní yìí nípa lílò ó lọ́nà yíyẹ la gbogbo àwọn sànmánì tí ń bọ̀ já.—Orin Dafidi 71:17, 18.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Màmá mi pẹ̀lú mi

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

1. Àpéjọpọ̀ mi àkọ́kọ́: San Marcos, Texas, September 1923

2. Àpéjọpọ̀ tí bàbá mi lọ kẹ́yìn: Fort Worth, Texas, June 1991 (Bàbá mi ni ó jókòó)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Gene àti Blossom Brandt

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́