Ogún Wa Nípa Tẹ̀mí Tí Ó Dọ́ṣọ̀
GẸ́GẸ́ BÍ PHILLIP F. SMITH ṢE SỌ Ọ́
“Àtùpà kan ti tàn tí yóò mọ́lẹ̀ jákèjádò Africa tí ó ṣókùnkùn biribiri.” Ẹ wo bí inú wa ti dùn tó láti ka ọ̀rọ̀ tí ó wà lókè yìí nínú ìwé 1992 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú-ìwé 75! Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ni bàbá wa àgbà, Frank W. Smith, kọ sílẹ̀ ní 1931, nínú lẹ́tà kan sí Arákùnrin Joseph F. Rutherford, tí ó jẹ́ ààrẹ Watch Tower Society nígbà náà lọ́hùn-ún. Bàbá Àgbà kọ̀wé láti ròyìn ìrìn-àjò ìwàásù kan tí òun àti arákùnrin rẹ̀ ṣe.
ÌWÉ 1992 Yearbook ṣàlàyé pé: “Gray Smith àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin Frank, àwọn onígboyà òjíṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà méjì láti Cape Town [South Africa], gbéra lọ sí East Africa tí ó wà lábẹ́ Britain láti ṣàyẹ̀wò ìṣeéṣe náà láti tan ìhìnrere kálẹ̀. Wọ́n gbé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan, De Soto, tí wọ́n ti yípadà sí ilé alágbèéká (ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́ onílé), wọ́n gbé e sínú ọkọ-ojú-omi pẹ̀lú 40 àpótí ìwé, wọ́n sì tukọ̀ lọ sí Mombasa, ibùdókọ̀ etíkun Kenya.”
Nínú lẹ́tà rẹ̀ sí Arákùnrin Rutherford, Bàbá Àgbà ṣàpèjúwe ìrìn-àjò náà láti Mombasa sí Nairobi, olú-ìlú Kenya pé: “A bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò kan tí ìrántí rẹ̀ bani lẹ́rù jùlọ tí mo tí ì lọ rí. Láìdúró rárá, ó gbà wá ní ọjọ́ mẹ́rin láti rin kìlómítà 580 . . . Lẹ́yìn kìlómítà kọ̀ọ̀kan mo níláti sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ṣọ́bìrì láti tún ọ̀nà ṣe, dí kòtò, àti láti gé koríko àti igi láti fi dí àwọn ibi tí ẹrọ̀fọ̀ wá kí àwọn táyà mọ́tò lè rí ọ̀nà kọjá.”
Lẹ́yìn dídé Nairobi, Frank àti Gray ṣiṣẹ́ fún ọjọ́ 21 tẹ̀léra-tẹ̀léra láti pín àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wọn. Bàbá Àgbà kọ̀wé pé: “Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a gbọ́, iṣẹ́ náà ti yí àwọn onísìn ní Nairobi nínú po.” Lẹ́yìn ìgbà náà, Bàbá Àgbà háragàgà láti padà sílé sọ́dọ̀ ọmọkùnrin rẹ̀ ọlọ́dún méjì, Donovan, àti ìyàwó rẹ̀, Phyllis, ẹni tí ó lóyún ọmọ wọn kejì, bàbá wa, Frank. Bàbá Àgbà wọ ọkọ̀ ojú-omi tí ó kọ́kọ́ wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti Mombasa, ṣùgbọ́n àrùn ibà pa á kí ó tó délé.
Bí èmi, àǹtí mi, àti àbúrò mi ọkùnrin ti ń ronú nípa àkọsílẹ̀ ìwé Yearbook náà, ọkàn wa padà lọ sọ́dọ̀ bàbá wa ọ̀wọ́n. Ní May 1991, oṣù díẹ̀ péré ṣáájú kí a tó gba ìwé 1992 Yearbook, àrùn ọkàn-àyà tí ó lekoko ti ṣekúpa á. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò fojú kan bàbá rẹ̀ rí, ó ṣàjọpín ìfẹ́ tí ó jinlẹ̀ tí bàbá rẹ̀ ní fún Jehofa. Ẹ wo bí Bàbá Àgbà ìbá ti yọ̀ tó láti mọ̀ pé ọdún 28 lẹ́yìn náà, ní 1959, ọmọkùnrin rẹ̀ yóò tẹ̀lé ipasẹ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristian òjíṣẹ́ lọ sí East Africa!
Ìbẹ̀rẹ̀ Pẹ̀pẹ̀ Ìgbésí-Ayé Bàbá
A bí bàbá wa ní July 20, 1931, ní Cape Town, oṣù méjì lẹ́yìn ikú bàbá rẹ̀, ẹni tí a sọ ọ́ lórúkọ rẹ̀. Láti kékeré, Bàbá fi ìfẹ́ rẹ̀ fún Jehofa hàn. Nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án péré, ó dúró sí ọ̀gangan ibùdókọ̀ ojú-irin Cape Town ó ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù nípa gbígbé káàdì kọ́rùn nígbà tí àwọn ọmọ ilé-ẹkọ́ ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ sì ń fi ṣe yẹ̀yẹ́. Nígbà tí ó di ọmọ ọdún 11, ó fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ rẹ̀ sí Jehofa hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi nínú omi. Nígbà mìíràn Bàbá ni a yàn láti dá ṣiṣẹ́ ní odindi òpópónà kan nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́. Nígbà tí yóò fi di ẹni ọdún 18, ó ti ń darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé-Ìṣọ́nà pẹ̀lú àwùjọ àwọn Kristian arábìnrin àgbàlagbà kan ní ìgbèríko Cape Town.
Ní 1954 Watch Tower Society kéde pé àpéjọpọ̀ àgbáyé ni a óò ṣe ní ọdún tí ó tẹ̀lé e ní Europe. Ó wu Bàbá gidigidi láti lọ, ṣùgbọ́n kò ní owó tí ó tó láti rin ìrìn-àjò lọ sí ibẹ̀ láti Cape Town. Nítorí náà ó gbà láti ṣiṣẹ́ fún oṣù mẹ́ta gẹ́gẹ́ bí apòògùn nínú ilé-iṣẹ́ ìwakùsà bàbà ní Northern Rhodesia (tí a mọ̀ sí Zambia báyìí). Ibi tí a kọ́ ilé-isẹ́ tí a ti ń ṣàyẹ̀wò ẹta ọrọ̀-ilẹ̀ nínú àwọn igbó Africa.
Bàbá mọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí púpọ̀ rẹpẹtẹ tí wọ́n jẹ́ ọmọ Africa wà ní Northern Rhodesia, nítorí náà nígbà tí ó dé, ó wá wọn rí ó sì mọ ibi tí wọ́n ti ń ṣe ìpàdé wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò lè sọ èdè ìbílẹ̀ náà, bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ ó darapọ̀ pẹ̀lú wọn ó sì ń lọ sí ìpàdé déédéé pẹ̀lú Ìjọ Mine ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Àwọn ará Europe tí wọ́n wà ní ilé-iṣẹ́ ìwakùsà ní ẹ̀tanú níti ẹ̀yà-ìran wọ́n sì fi ẹ̀tanú wọn hàn ní ọ̀pọ̀ ìgbà nípa bíbú àwọn ará Africa. Bí ó ti wù kí ó rí, Bàbá jẹ́ onínúrere nígbà gbogbo.
Lẹ́yìn oṣù mẹ́ta náà, òṣìṣẹ́ ará Africa kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí tọ Bàbá wá ó sì béèrè pé: “O ha mọ ohun tí a ń pè ọ́ bí?” Ọkùnrin náà rẹ́rìn-ín ó sì wí pé: “A ń pè ọ́ ní Bwana [Ọ̀gbẹ́ni] Ilé-Ìṣọ́nà.”
Ní 1955, ó ṣeé ṣe fún Bàbá láti lọ sí Àpéjọ “Ìjọba Aṣẹ́gun” ní Europe. Níbẹ̀ ni ó ti pàdé Mary Zahariou, ẹni tí ó di ìyàwó rẹ̀ ní ọdún tí ó tẹ̀lé e. Lẹ́yìn ìgbéyàwó wọn, wọ́n fìdíkalẹ̀ sí Parma, Ohio, U.S.A.
Sí East Africa
Nígbà àpéjọpọ̀ àgbègbè kan ní United States, a nawọ́ ìkésíni kan sí àwọn olùpéjọpọ̀ láti ṣiṣẹ́sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ jù fún àwọn òjíṣẹ́. Àwọn òbí wa pinnu láti lọ sí East Africa. Wọ́n ṣe ohun ti Watch Tower Society dábàá gẹ́lẹ́. Wọ́n tọ́jú owó tí ó tó láti ra ìwé ìrìnnà àlọ àti àbọ̀ bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé Bàbá kò kẹ́sẹjárí nínú rírí iṣẹ́, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé kìkì àwọn tí wọ́n ní ìwé àṣẹ láti ṣiṣẹ́ ni a yọ̀ǹda fún láti dúró ní àgbègbè ìpínlẹ̀ náà.
Lẹ́yìn gbígba ìwé ìrìnnà, ìwé ìwọlé, àti abẹ́rẹ́ àjẹsára, ní July 1959, Bàbá àti Màmá wọ ọkọ̀-ojú-omi tí ń kó àwọn oníṣòwò láti New York City lọ sí Mombasa tí yóò gba Cape Town kọjá. Ìrìn-àjò náà gbà wọ́n ní ọ̀sẹ̀ mẹ́rin. Ní Mombasa àwọn Kristian arákùnrin tí wọ́n ti dé ṣáájú wọn láti ṣiṣẹ́sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ jù, kí wọn káàbọ̀ tọ̀yàyà-tọ̀yàyà ní ìdíkọ̀. Nígbà tí wọ́n dé Nairobi, Bàbá rí lẹ́tà kan tí ń dúró dè é. Ó jẹ́ èsì sí ìbéèrè rẹ̀ fún ipò kan gẹ́gẹ́ bí apòògùn ní Ẹ̀ka Ilé Iṣẹ́ Tí Ń Ṣàyẹ̀wò Nǹkan Inú Ilẹ ní Entebbe, Uganda. Bàbá àti Màmá wọ ọkọ̀-ojú-irin lọ sí Kampala, Uganda, níbi tí a ti fọ̀rọ̀ wá Bàbá lẹ́nu wò tí a sì gbà á síṣẹ́. Nígbà náà lọ́hùn-ún, Ẹlẹ́rìí kanṣoṣo mìíràn péré ni ó wà ní àdúgbò Entebbe-Kampala, George Kadu.
Ìjọba tí ń gbókèèrè ṣàkóso sanwó fún Bàbá láti kọ́ èdè ìbílẹ̀ náà, Luganda. Inú rẹ̀ dùn gan-an, níwọ̀n bí ó ti pète láti kọ́ ọ lọ́nàkọnà tẹ́lẹ̀ kí ó baà lè túbọ̀ gbéṣẹ́ nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́. Lẹ́yìn náà, Bàbá tilẹ̀ ṣèrànwọ́ láti túmọ̀ ìwé-pẹlẹbẹ náà “Ihinrere Ijọba Yi” sí èdè Luganda.
Bàbá kò bẹ̀rù láti jẹ́rìí fún àwọn ẹlòmíràn. Ó bá gbogbo àwọn ará Europe tí wọ́n wà ní ẹ̀ka ibi iṣẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó sì kópa déédéé nínú wíwàásù fún àwọn ará Uganda. Ó tilẹ̀ jẹ́rìí fún olórí amòfin ilẹ̀ Africa ní Uganda. Kì í ṣe pé ọkùnrin náà fetísílẹ̀ sí ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà nìkan ni ṣùgbọ́n ó tún pé Bàbá àti Màmá wá láti bá òun jẹun.
A bí arábìnrin mi Anthe, ní 1960, a bí èmi náà tẹ̀lé e ní 1965. Ìdílé wa wà tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin nínú ìjọ kékeré ṣùgbọ́n tí ń gbèrú náà ní olú-ìlú náà, Kampala. Gẹ́gẹ́ bí àwọn Ẹlẹ́rìí aláwọ̀ funfun kanṣoṣo ní àyíká Entebbe, a ní àwọn ìrírí apanilẹ́rìn díẹ̀. Nígbà kan, ọ̀rẹ́ Bàbá kan yà sọ́dọ̀ wa láìròtẹ́lẹ̀ ní Entebbe ó sì gbìyànjú láti rí Bàbá. Ó ṣòro fún un àfi ìgbà tí ó béèrè pé: “Ǹjẹ́ o mọ tọkọtaya kan tí wọ́n jẹ́ ará Europe níhìn-ín tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa?” Ẹni náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ wà á wá tààràtà sí ilé Màmá àti Bàbá.
A tún ní àwọn ìrírí tí ó ṣòro, èyí tí ó ní nínú líla ìdìtẹ̀ méjì já nínú èyí tí wọ́n ti lo nǹkan ìjà. Ní ìgbà kan, ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun ìjọba ń yìnbọn fún ẹnikẹ́ni tí ó bá wá láti àwùjọ ẹ̀yà kan pàtó. Jálẹ̀ ọ̀sán àti òru, ìbọn yínyìn ń bá a lọ láìdáwọ́ dúró. Níwọ̀n bí òfin kónílé-gbélé ti wà láti agogo 6 ìrọ̀lẹ́ sí agogo 6 òwúrọ̀, a ń ṣe ìpàdé ní ilé àwọn òbí mi ní ọ̀sán ní Entebbe.
Lẹ́yìn náà, nígbà tí a fagilé òfin kónílé-gbélé náà, Bàbá wà wá lọ sí Kampala fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé-Ìṣọ́nà. Sójà kan na ìbọn sí wa, ó dá ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa dúró, ó sì béèrè ibi tí a ń lọ. Ìkókó ni mí nígbà náà, Anthe sì jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún. Nígbà tí Bàbá rọra ṣàlàyé, tí ó sì fi Bibeli àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa han sójà náà, ó yọ̀ǹda kí a máa lọ.
Ní 1967, lẹ́yìn nǹkan bí ọdún mẹ́jọ ní Uganda, àwọn òbí wa pinnu láti padà sí United States nítorí ìṣòro ìlera àti ẹrù-iṣẹ́ ìdílé. A di apákan Ìjọ Canfield, ní Ohio, níbi tí Bàbá ti ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà. Níbẹ̀ àwọn òbí mi mú ìfẹ́ fún àwọn arákùnrin dàgbà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ kékeré náà ní Kampala.
Ìdàgbàsókè Onífẹ̀ẹ́ ti Kristian
A bí David arákùnrin mi ní 1971. Bí a ti ń dàgbà, a tọ́ wa nínú àyíká ilé tí ó kún fún ìfẹ́ àti ọ̀yàyà. Kò sí iyèméjì pé èyí wá láti inú ìbáṣepọ̀ onífẹ̀ẹ́ tí àwọn òbí wa gbádùn pẹ̀lú ara wọn.
Nígbà tí a kéré, Bàbá máa ń ka ìtàn Bibeli kan fún wa nígbà tí a bá fẹ́ sùn, yóò gbàdúrà, àti lẹ́yìn náà, yóò fún wa ní ṣokoléètì tí a fi bébà tí ń dán yinrin yinrin wé, láìjẹ́ kí Màmá mọ̀. Nígbà gbogbo a máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ilé-Ìṣọ́nà wa papọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé, ibi yòówù kí a lè wà. Nígbà tí a wà lẹ́nu ìsinmi ìdílé, a ti kẹ́kọ̀ọ́ lẹ́ẹ̀kan rí lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè-ńlá àti nígbà mìíràn bí a ti ń wo òkun. Bàbá máa ń sọ nígbà gbogbo pé àwọn ìgbà wọ̀nyẹn jẹ́ àwọn ìrántí tí ó mú òun láyọ̀ jùlọ. Ó sọ pé o ṣe òun láàánú fún àwọn wọnnì tí wọ́n pàdánù ìdùnnú-ayọ̀ ńláǹlà tí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé lè mú wá.
Nígbà tí ó bá kan ọ̀ràn ti fífi ìfẹ́ hàn fún Jehofa, Bàbá fi àpẹẹrẹ kọ́ni. Nígbàkigbà tí ẹ̀dà titun Ilé-Ìṣọ́nà tàbí Jí! bá dé tàbí tí a bá gba ìtẹ̀jáde Watchtower mìíràn, Bàbá yóò fi ìháragàgà ka gbogbo rẹ̀. A kẹ́kọ̀ọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé òtítọ́ Bibeli ni a kò níláti fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ṣùgbọ́n a níláti gbé e gẹ̀gẹ̀ bí ìṣúra tí ó ṣeyebíye. Ọ̀kan lára àwọn ohun-ìní wa tí ó ṣeyebíye ni Reference Bible Bàbá. Ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ojú-ìwé ni ó kún fún àkọsílẹ̀ tí ó ti tejọ láti ara àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Nísinsìnyí nígbà tí a bá ka àwọn àkíyèsí tí ó kọ sétí ìwé, a fẹ́rẹ̀ẹ́ lè máa gbọ́ ọ tí ó ń kọ wa tí ó sì ń fún wa ní ìmọ̀ràn.
Ó Jẹ́ Olùṣòtítọ́ Títí Dé Òpin
Ní May 16, 1991, nígbà tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá, àrùn ọkàn-àyà kọlu Bàbá. Ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn náà, a ṣe iṣẹ́-abẹ ọkàn-àyà tí ó dàbí pé ó yọrí sí rere fún un. Bí ó ti wù kí ó rí, ní òru tí ó tẹ̀lé iṣẹ́-abẹ náà, a gba ìkésíni orí fóònù kan láti ilé-ìwòsàn náà. Ẹ̀jẹ̀ bẹ̀rẹ̀ síi dà lára Bàbá, àwọn dókítà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàníyàn gidi gan-an. Wọ́n gbé e padà sí yàrá iṣẹ́-abẹ lẹ́ẹ̀mejì ní òru náà láti gbìyànjú láti dá ẹ̀jẹ̀ tí ń dà náà dúró ṣùgbọ́n pàbó ni ó bọ́ sí. Ẹ̀jẹ̀ Bàbá kò dì.
Ní ọjọ́ kejì, bí ipò Bàbá ti ń burú síi kíákíá, àwọn dókítà kọ́kọ́ pé màmá mi àti lẹ́yìn náà àbúrò mi ọkùnrin sẹ́yìn láti gbìyànjú láti yí wọn lérò padà kí wọ́n lè fọwọ́ sí fífa ẹ̀jẹ̀ sí Bàbá lára. Síbẹ̀, Bàbá ti sọ fún àwọn dókítà náà tẹ́lẹ̀rí pé òun kì yóò gba ìfàjẹ̀sínilára lábẹ́ àyíká ipò èyíkéyìí. Ó ṣàlàyé àwọn ìdí rẹ̀ tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu fún wọn fún kíkọ ẹ̀jẹ̀ ṣùgbọ́n ó sọ pé òun yóò gba àfidípò ẹ̀jẹ̀.—Lefitiku 17:13, 14; Ìṣe 15:28, 29.
Ìkóguntini lábẹ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn mẹ́ḿbà òṣìṣẹ́ ìṣègùn kan dá ìkìmọ́lẹ̀ sílẹ̀ ní ICU (ẹ̀ka ìtọ́jú àkànṣe). Èyí, pẹ̀lú ipò Bàbá tí ń burú síi, nígbà mìíràn dàbí ohun tí ó ju nǹkan tí a lè faradà lọ. A bẹ Jehofa fún ìrànlọ́wọ́ a sì tún gbìyànjú láti fi àwọn àbá gbígbéṣẹ́ tí a ti rí gbà sílò. Nítorí náà nígbà tí a bá ń ṣèbẹ̀wò sí ICU, a máa ń múra dáradára a sì ń fi ọ̀wọ̀ hàn fún àwọn mẹ́ḿbà òṣìṣẹ́ ìṣègùn. A ní ọkàn-ìfẹ́ mímúná nínú ipò Bàbá nípa bíbéèrè àwọn ìbéèrè tí ó mọ́gbọ́n wá, a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn mẹ́ḿbà òṣìṣẹ́ tí wọ́n lọ́wọ́ nínú ìtọ́jú Bàbá.
Àwọn ìsapá wa ni kò lọ láìsí àkíyèsí láti ọ̀dọ̀ àwọn mẹ́ḿbà òṣìṣẹ́ ìṣègùn. Ní ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, àyíká ọ̀ràn tí ó lekoko náà yípadà sí ti onínúrere. Àwọn nọ́ọ̀sì tí wọ́n bójútó Bàbá máa ń yẹ bí ó ṣe ń ṣe sí wò àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò yàn wọ́n láti bójútó o mọ́. Dókítà kan tí ó ti hùwà sí wa lọ́nà tí kò dára tẹ́lẹ̀ tilẹ̀ wá rọ̀ débi pé ó ń béèrè lọ́wọ́ Màmá bí ó ti ń ṣe sí. Ìjọ wa àti àwọn ìbátan wa pẹ̀lú tì wá lẹ́yìn lọ́nà onífẹ̀ẹ́. Wọ́n fi ọ̀pọ̀ oúnjẹ àti àwọn káàdì ìtuninínú ránṣẹ́, wọ́n sì gbàdúrà nítorí tiwa.
Ó ṣeniláàánú pé, ìtọ́jú náà kò ṣe ìyípadà kankan sí ìlera Bàbá. Ó kú ní ọjọ́ kẹwàá lẹ́yìn iṣẹ́-abẹ àkọ́kọ́. A kẹ́dùn gidi gan-an nítorí Bàbá. Nígbà mìíràn, ìmọ̀lára ìpàdánù ń bò wá mọ́lẹ̀. Lọ́nà tí ó dùnmọ́ninínú, Ọlọrun wa ṣèlérí pé òun yóò ‘bá wa gbé ẹrù wa lójoojúmọ́,’ a sì ti kẹ́kọ̀ọ́ láti faratì í ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.—Orin Dafidi 68:19, NW.
Gbogbo wa ti pinnu pé àwa pẹ̀lú yóò máa bá a lọ ní ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa pẹ̀lú ìṣòtítọ́ kí a baà lè rí ìdùnnú-ayọ̀ láti rí Bàbá nínú ayé titun náà.—Marku 5:41, 42; Johannu 5:28; Ìṣe 24:15.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Frank Smith pẹ̀lú ìyá rẹ̀, Phyllis, ní Cape Town
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Bàbá àti Màmá nígbà ìgbéyàwó wọn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Fún ìbatisí àkọ́kọ́ ní Entebbe, àwọn arákùnrin háyà odò-adágún olóyè Africa kan
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ìkíni ní ọ̀nà àṣà-ìbílẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Bàbá àti Màmá kété ṣáájú ikú Bàbá