ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 10/1 ojú ìwé 19-24
  • Títẹ̀ Lé Ipasẹ̀ Àwọn Òbí mi

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Títẹ̀ Lé Ipasẹ̀ Àwọn Òbí mi
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìtara Bàbá fún Ìjọba Náà
  • Iṣẹ́ Ìsìn Olùṣòtítọ́ Tí Màmá Ṣe
  • Iṣẹ́ Ìsìn ní Ìgbà Ọ̀dọ́
  • Ogun Àgbáyé II Bẹ́ Sílẹ̀
  • Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún Tí Ó Mú Ayọ̀ Wá
  • Ogún Wa Nípa Tẹ̀mí Tí Ó Dọ́ṣọ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ogún-Ìní Ṣíṣọ̀wọ́n ti Kristian Kan
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àwọn Òbí Wa Kọ́ Wa Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • “Mi Ò Ní Yí Ohunkóhun Padà!”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 10/1 ojú ìwé 19-24

Títẹ̀ Lé Ipasẹ̀ Àwọn Òbí mi

GẸ́GẸ́ BÍ HILDA PADGETT TI SỌ Ọ́

Ìròyìn náà kà pé: “Mo ti ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún iṣẹ́ ìsìn Ẹni Giga Jù Lọ náà, èmi kò sì lè sin ọ̀gá méjì.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, láti inú ọ̀rọ̀ mi sí àwọn aláṣẹ Ilé Iṣẹ́ Àbójútó Òṣìṣẹ́ àti Ìsìnrú Ìlú ní Britain, ní 1941, ṣàlàyé ìdí tí mo fi kọ ìdarísọ́nà wọn láti ṣe iṣẹ́ ní ilé ìwòsàn nígbà Ogun Àgbáyé II. Kété lẹ́yìn náà, a dá mi lẹ́bi, a sì fi mí sẹ́wọ̀n oṣù mẹ́ta fún kíkọ̀ tí mọ kọ̀.

KÍ NI ó sún mi sí ipò tí ó ṣòro yìí? Kì í ṣe ìwà àìgbọ́n ti ọmọdé tàbí ìwà ọ̀tẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ nítorí àwọn ohun kan tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà tí mo wà ní ọmọdé.

Ìtara Bàbá fún Ìjọba Náà

A bí mi ní June 5, 1914, ní Horsforth lẹ́bàá Leeds, ní àríwá England. Àwọn òbí mi, Atkinson àti Pattie Padgett, jẹ́ olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ ọjọ́ Ìsinmi, wọ́n sì tún jẹ́ mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ akọrin ní Primitive Methodist Chapel, níbi tí Bàbá ti ń tẹ dùùrù. Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọwọ́, ilé wa jẹ́ ilé aláyọ̀, ṣùgbọ́n ohun kan ni ó bà á jẹ́. Ipò ayé dààmú Bàbá. Ó kórìíra ogun àti ìwà ipá, ó sì gba àṣẹ Bibeli náà gbọ́ pé: “Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn.”—Eksodu 20:13.

Ní 1915, ìjọba rọ gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin láti fínnúfíndọ̀ dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun, kí wọ́n sì tipa báyìí yẹra fún fífipámúni. Pẹ̀lú iyèméjì, Bàbá dúró nínú òjò ní gbogbo ọjọ́ náà, ó ń dúró de àsìkò tí yóò kàn án láti forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí sójà. Ní ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e gan-an, gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ yí padà!

Níbi tí ó ti ń ṣiṣẹ́ afamisílé ní ilé ńlá kan, ó bá àwọn òṣìṣẹ́ yòókù sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayé. Olùṣọ́gbà náà fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú kan, Gathering the Lord’s Jewels. Bàbá mú un wá sí ilé, ó sì kà á ní àkàtúnkà. Ó sọ pé: “Bí ìyẹn bá jẹ́ òtítọ́, nígbà náà, gbogbo èyí tí ó kù ní láti jẹ́ èké.” Ní ọjọ́ kejì, ó béèrè ìsọfúnni síwájú sí i, ọ̀sẹ̀ mẹ́ta ni ó sì fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, títí di ìdájí. Ó mọ̀ pé òun ti rí òtítọ́! Ní Sunday, January 2, 1916, ìwé àkọsílẹ̀ ojoojúmọ́ rẹ̀ sọ pé: “Mo lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì ní òwúrọ̀, mo lọ sí I.B.S.A. [Ẹgbẹ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli Káàkiri Orílẹ̀ Èdè, gẹ́gẹ́ bí a ti mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sí nígbà náà lọ́hùn-ún ní England] ní alẹ́—mo kẹ́kọ̀ọ́ Heberu 6:9-20—ìbẹ̀wò mi àkọ́kọ́ sọ́dọ̀ àwọn ará.”

Àtakò bẹ̀rẹ̀ láìpẹ́. Àwọn ìbátan wa àti àwọn ọ̀rẹ́ wa ní ṣọ́ọ̀ṣì rò pé orí Bàbá ti yí ni. Ṣùgbọ́n ó ti pinnu. Ìpàdé àti ìkẹ́kọ̀ọ́ ni ó jẹ ẹ́ lógún nínú ìgbésí ayé, nígbà tí ó sì fi di March, ó ti fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ rẹ̀ sí Jehofa hàn nípa ìbatisí nínú omi. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tí Bàbá ti ń dá lọ sí ìpàdé lóun nìkan, ó ti sú Màmá. Ó gbé mi sínú kẹ̀kẹ́ ọmọdé mi, ó sì fi ẹsẹ̀ rin kìlómítà mẹ́jọ lọ sí Leeds, ó dé ibẹ̀ kété tí ìpàdé parí. Finú wòye bí ìdùnnú Bàbá ti pọ̀ tó. Láti ìgbà náà lọ, ìdílé wa wà ní ìsopọ̀ṣọ̀kan nínú ṣíṣiṣẹ́ sin Jehofa.

Ipò Bàbá ṣòro gan-an—olùyọ̀ọ̀da ara ẹni fún iṣẹ́ ológun àti láàárín ọ̀sẹ̀ díẹ̀, ó di ẹni tí ó kọ̀ láti jagun nítorí ẹ̀rí ọkàn. Nígbà tí wọ́n pè é, ó kọ̀ láti gbé ìbọn, nígbà tí yóò sì fi di July 1916, ó ti ń jẹ́jọ́ níwájú àkọ́kọ́ nínú ilé ẹjọ́ márùn-ún, a sì fi í sẹ́wọ̀n 90 ọjọ́. Lẹ́yìn tí ó parí àkókò ẹ̀wọ̀n àkọ́kọ́, Bàbá ní ìsinmi fún ọ̀sẹ̀ méjì, lẹ́yìn náà ni ìgbẹ́jọ́ mìíràn wáyé, wọ́n sì ní kí ó lo 90 ọjọ́ sí i ní ọgbà ẹ̀wọ̀n. Lẹ́yìn ìfisẹ́wọ̀n ẹlẹ́ẹ̀kejì yìí, a gbé e lọ sí Ilé Ìṣègùn Àwọn Ọmọ Ogun Ilẹ̀ Britain, ní February 12, 1917, ó wọkọ̀ ojú omi àwọn ológun lọ sí Rouen, France. Ìwé àkọsílẹ̀ ojoojúmọ́ rẹ̀ fi hàn pé, inú rẹ̀ ń bàjẹ́ sí i lójoojúmọ́ nítorí ipò rẹ̀. Ó wá rí i pé òun wulẹ̀ ń tọ́jú àwọn sójà, kí wọ́n lè padà lọ jagun ni.

Lẹ́ẹ̀kan sí i, ó kọ̀ láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Lọ́tẹ̀ yìí ilé ẹjọ́ rán an lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún, ní ọgbà ẹ̀wọ̀n àwọn ológun ti Britain, ní Rouen. Nígbà tí Bàbá tẹpẹlẹ mọ́ bíbéèrè pé kí a gbé òun lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ti ìjọba gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó kọ̀ láti jagun, a fìyà jẹ ẹ́ nípa fífún un ní kìkì búrẹ́dì àti omi fún oṣù mẹ́ta, lẹ́yìn náà ni a wá ń fún un ní oúnjẹ tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n ń jẹ títí ti ó fi bọ̀ sípò; lẹ́yìn náà ni a tún ṣe é bí i ti tẹ́lẹ̀. Wọ́n ń fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ so ọwọ́ rẹ̀ sí ẹ̀yìn ní ọ̀sán, wọn yóò sì so ó sí iwájú ní alẹ́ àti nígbà tí ó bá fẹ́ jẹun. Títí ó fi kú, àpá egbò wa ní ọrùn ọwọ́ rẹ̀ níbi tí ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ tí ó fún un ti yun awọ ara rẹ̀, tí ó sì yọrí sí egbò kíkẹ̀. A tún so ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ ẹsẹ̀ mọ́ ìbàdí rẹ̀.

Àwọn aláṣẹ ọmọ ogun ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti mú kí ó juwọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n pàbó ni ó já sí. Wọ́n gba Bibeli àti àwọn ìwé rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. Kò rí lẹ́tà kankan gbà láti ilé, kò sì lè fi ọ̀kankan ránṣẹ́ sílé. Lẹ́yìn ọdún méjì, ó pinnu láti fi ìṣòtítọ́ rẹ̀ hàn nípa kíkọ̀ láti jẹun. Fún ọjọ́ méje, ó dúró ti ìpinnu rẹ̀, láìjẹ láìmu, èyí sì yọrí sí gbígbé e lọ sí ilé ìwòsàn àwọn ẹlẹ́wọ̀n, nítorí ara rẹ̀ kò yá gan-an. Ó fi ẹ̀rí hàn pé òun jẹ́ olóòótọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítorí èyí. Ní àwọn ọdún tí ó tẹ̀ lé e, ó gbà pé òun ṣe àṣìṣe láti fi ìwàláàyè òun sínú ewu ní ọ̀nà yìí, àti pé òun kì yóò ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́ láé.

Ogun náà parí ní November 1918, síbẹ̀ Bàbá ṣì wà lẹ́wọ̀n ní Rouen, ṣùgbọ́n ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún tí ó tẹ̀ lé e, a gbé e lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ti ìjọba ní England. Finú wòye bí ìdùnnú rẹ̀ ti pọ̀ tó láti gba gbogbo àwọn lẹ́tà Màmá àti awọn ìdì ẹrù tí ó ti ṣẹ́jọ, papọ̀ pẹ̀lú Bibeli rẹ̀ tí ó ṣeyebíye àti àwọn ìwé rẹ̀! A gbé e lọ sí Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Winchester, níbi tí ó ti pàdé arákùnrin ọ̀dọ́ kan, ẹni tí ìrírí rẹ̀ nígbà ogun fara jọ tirẹ̀. Orúkọ rẹ̀ ni Frank Platt, tí ó ṣiṣẹ́ sìn lẹ́yìn náà ní Bétélì ti London fún ọ̀pọ̀ ọdún. Wọn ṣàdéhùn pé kí àwọn pàdé ní ọjọ́ kejì, ṣùgbọ́n nígbà tí yóò fi di ìgbà náà, a ti gbé Frank lọ sí ibòmíràn.

Ní April 12, 1919, Màmá rí wáyà gbà pé: “Halelujah! Mo ń padà bọ̀ wálé—mo ń fóònù London.” Ẹ wo bí ó ti jẹ́ àkókò aláyọ̀ tó, lẹ́yìn ọdún mẹ́ta ti ìdánwò, ìpèlẹ́jọ́, àti ìpinyà! Ohun tí ó kọ́kọ́ wá sọ́kàn Bàbá ni láti tẹlifóònù, kí ó sì lọ pàdé àwọn arákùnrin ní Bétélì ti London. Wọ́n kí i káàbọ̀ tìfẹ́tìfẹ́ ní 34 Craven Terrace. Lẹ́yìn tí ó wẹ̀, tí ó fárùngbọ̀n, tí ó sì wọ aṣọ àti fìlà tí wọ́n yá a, Bàbá padà wá sí ilé. Ìwọ ha lè finú wòye pípadà wà papọ̀ wa bí? Mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọmọ ọdún márùn un nígbà náà, èmi kò dá a mọ̀ mọ́.

Ìṣe Ìrántí ni ìpàdé àkọ́kọ́ tí Bàbá lọ lẹ́yìn tí o ti gba òmìnira. Bí ó ti gun òkè lọ sí gbọ̀ngàn náà, ta ni ó kọ́kọ́ rí bí kò ṣe Frank Platt, ẹni tí a ti gbé lọ sí ilé ìwòsàn àwọn ológun ní Leeds. Ẹ wo bí inú wọn ti dùn tó láti ṣàjọpín àwọn ìrírí wọn! Láti ìgbà náà wá títí wọ́n fi dá a sílẹ̀, Frank sọ ilé wa di ilé rẹ̀ kejì.

Iṣẹ́ Ìsìn Olùṣòtítọ́ Tí Màmá Ṣe

Ní gbogbo ìgbà tí Bàbá kò sí nílé, Màmá ń ṣe iṣẹ́ àgbàfọ̀ láti lè rí owó kún ìwọ̀nba owó tí ijọba ń fún un. Àwọn arákùnrin fi inú rere hàn sí wa púpọ̀. Ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ díẹ̀ sí ara wọn, ọ̀kan lára àwọn alàgbà ìjọ ń fún wa ní àpò ìwé, tí ó ní ẹ̀bùn, tí kò sí orúkọ lára rẹ̀. Màmá máa ń sọ pé ìfẹ́ àwọn arákùnrin ni ó mú òun sún mọ́ Jehofa tímọ́tímọ́, tí ó sì ran òun lọ́wọ́ láti fara dà á la gbogbo àwọn àkókò tí ó ṣòro kọjá. Ó fi ìdúróṣinṣin lọ sí gbogbo àwọn ìpàdé ìjọ jálẹ̀ gbogbo ìgbà tí Bàbá kò sí nílé. Ìdánwò rẹ̀ tí ó le jù lọ dé nígbà tí kò mọ̀ bóyá Bàbá wà láàyè tàbí ó ti kú, fún èyí tí ó lé ní ọdún kan. Gẹ́gẹ́ bí àfikún ìṣòro, àrùn gágá kọ lu èmi àti Màmá ní 1918. Àwọn ènìyàn ń kú láyìíká wa. Àwọn aládùúgbò tí wọ́n lọ láti lọ ran aládùúgbò lọ́wọ́ kó àrùn náà, wọ́n sì kú. Kò sí àníàní pé, ọ̀wọ́n oúnjẹ tí ó wà nígbà náà kò jẹ́ kí àwọn ènìyàn ri ara gba àrùn náà.

Àwọn ọ̀rọ̀ aposteli Peteru ṣẹ sí ìdílé wa lára pé: “Lẹ́yìn tí ẹ bá ti jìyà fún ìgbà díẹ̀, Ọlọrun . . . yoo fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in, yoo mú yín lókunlágbára”! (1 Peteru 5:10) Ìjìyà àwọn òbí mi ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú ìgbàgbọ́ tí kò yẹsẹ̀ nínú Jehofa dàgbà, ìdánilójú pátápátá pé ó bìkítà fún wa àti pé kò sí ohun tí ó lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọrun. Mo láyọ̀, ní pàtàkì pé a tọ́ mi dàgbà nínú irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀.—Romu 8:38‚ 39; 1 Peteru 5:7.

Iṣẹ́ Ìsìn ní Ìgbà Ọ̀dọ́

Lẹ́yìn tí a dá Bàbá sílẹ̀, iṣẹ́ ìsìn Ìjọba wá di ohun pàtàkì nínú ìgbésí ayé wa. Èmi kò rántí ìgbà kankan rí tí a pa ìpàdé jẹ, àyàfi nítorí àìsàn. Kété lẹ́yìn tí ó padà wá sílé, Bàbá ta kámẹ́rà rẹ̀ àti góòlù ọrùn Màmá, láti lè rí owó láti lọ sí ìpàdé agbègbè. Bí kò tilẹ̀ sí agbára láti lọ fún àkókò ìsinmi, a kò pa àpéjọpọ̀ kankan jẹ, títí kan àwọn tí a ṣe ní London.

Ọdún méjì tàbí mẹ́ta àkọ́kọ́ lẹ́yìn ogun jẹ́ àkókò ìtura. Bàbá àti Màmá lo àǹfààní tí wọ́n ní dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́ láti dara pọ̀ àti láti kẹ́gbẹ́ pọ̀. Mo rántí bí a ti máa ń bẹ àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin mìíràn wo, tí èmi, gẹ́gẹ́ bí ọmọbìnrin kékeré, yóò jókòó tí n óò máa ya àwòrán, tí ń óò sì máa kùn un, nígbà tí àwọn àgbàlagbà yóò máa fọ̀rọ̀ wérọ̀ fún ọ̀pọ̀ wákàtí nípa òye òtítọ́ tuntun. Sísọ̀rọ̀ papọ̀, kíkọrin tẹ̀ lé dùùrù, gbígbádùn ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tí ó dùn mọ́ni, mú kí wọ́n láyọ̀, kí ara sì tù wọ́n.

Ní ti ìkẹ́kọ̀ọ́ mi, àwọn òbí mi kò gba gbẹ̀rẹ́. Ní ilé ẹ̀kọ́, mo dá yàtọ̀, àní nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún pàápàá, mo máa ń ka “Májẹ̀mú Tuntun” nígbà tí àwọn ọmọ kíláàsì bá ń kọ́ katikísìmù. Lẹ́yìn náà, a fi mi han gbogbo àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gẹ́gẹ́ bí “ẹni tí ó kọ̀ láti kópa” nítorí n kò lọ́wọ́ nínú ayẹyẹ Ọjọ́ Ìrántí.a N kò kábàámọ̀ bí a ti tọ́ mi dàgbà. Ní tòótọ́, ààbò ni ó jẹ́, ó sì mú kí ó túbọ̀ rọrùn láti dúró sí ‘ojú ọ̀nà tóóró’ náà. Ibikíbi tí àwọn òbí mi bá lọ, bóyá ìpàdé tàbí nínú iṣẹ́ ìsìn, mo máa ń wà níbẹ̀.—Matteu 7:13‚ 14.

Ní pàtàkì, mo rántí òwúrọ̀ ọjọ́ Sunday náà nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí dá wàásù. Mo jẹ́ ọmọ ọdún 12 péré. Nígbà tí mo wà ní ọ̀dọ́langba, mo rántí òwúrọ̀ ọjọ́ Sunday kan tí mo sọ pé èmi yóò dúró sílé. Kò sí ẹni tí ó bá mi wí tàbí fipá mú mi lọ, nítorí náà, mo jókòó sínú ọgbà, mo ń ka Bibeli mi, mo sì ń nímọ̀lára àìbalẹ̀ ọkàn. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan tàbí méjì tí mo fi ṣe èyí, mo sọ fún Bàbá pé: “Mo rò pé èmi yóò bá yín lọ ní òwúrọ̀ yìí!” Láti ìgbà náà lọ n kò bojú wẹ̀yìn.

Ẹ wo ọdún àgbàyanu tí 1931 jẹ́! Kì í ṣe kìkì pé a gba orúkọ wa tuntun, Ẹlẹ́rìí Jehofa nìkan ni, ṣùgbọ́n mo ṣe batisí ní àpéjọpọ̀ àgbáyé náà ní Alexandra Palace, London. N kò ní gbàgbé ọjọ́ náà láé. A wọ aṣọ dúdú tí ó gùn, tèmi sì jẹ́ tútù, tí ẹnì kan ti lò tẹ́lẹ̀!

Góńgó mi gẹ́gẹ́ bí ọmọdé ní gbogbo ìgbà ni láti di olùpín ìwé ìsìn kiri, gẹ́gẹ́ bí a ti mọ àwọn oníwàásù alákòókò kíkún sí nígbà náà. Bí mo ti ń dàgbà sí i, mo rò pé ó yẹ kí ń ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jehofa. Nítorí náà, ní March 1933, ní ẹni ọdún 18, mo wọ ẹgbẹ́ àwọn ìránṣẹ́ alákòókò kíkún.

“Ọ̀sẹ̀ Aṣáájú-Ọ̀nà” ní àwọn ìlú ńlá máa ń jẹ́ àkókò aláyọ̀ fún wa, nígbà tí nǹkan bí àwọn ìránṣẹ́ alákòókò kíkún 12 yóò pé jọ, tí wọn yóò dé sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin ní àdúgbò, tí wọn yóò sì ṣiṣẹ́ papọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwùjọ òṣìṣẹ́ kan. A ń fún àwọn aṣáájú ìsìn àti àwọn ènìyàn tí wọ́n lórúkọ ní àwọn ìwé pẹlẹbẹ. Ó ń béèrè ìgboyà láti lè bá wọn sọ̀rọ̀. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, a máa ń kẹ́gàn wa, èyí tí ó pọ̀ jù lọ lára wa ni a sì ti ti ilẹ̀kùn mọ́ lójú rí. Kì í ṣe pé a banú jẹ́ nítorí èyí, nítorí ìtara ọkàn wá pọ̀ púpọ̀ débi pé a láyọ̀ pé a kẹ́gàn wa, nítorí orúkọ Kristi.—Matteu 5:11‚ 12.

Ní Leeds a yí kẹ̀kẹ́ ọmọdé, kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́ta, àti alùpùpù Bàbá àti èyí tí a so mọ́ ọn lẹ́gbẹ̀ẹ́, àti lẹ́yìn náà ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀ padà láti máa kó àwọn ẹ̀rọ ìkọrin àti gbohungbohun. Àwọn arákùnrin méjì yóò lọ sí òpópónà pẹ̀lú ẹ̀rọ ìkọrin náà, wọn yóò gbé àwo orin kan sí láti ta àwọn ènìyàn náà jí, kí ó sì mú kí wọ́n wá sí ẹnu ọ̀nà wọn, lẹ́yìn èyí ni àsọyé oníṣẹ̀ẹ́jú márùn-ún tí Arákùnrin Rutherford ti gbohùn rẹ̀ sílẹ̀ yóò tẹ̀ lé e. Lẹ́yìn náà ni wọn yóò lọ sí òpópónà tí ó tẹ̀ lé e, nígbà tí àwa akéde yóò máa pín ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli.

Fún ọ̀pọ̀ ọdún, ní gbogbo ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Sunday, lẹ́yìn ìpàdé, a óò lọ sí Oríta Gbọ̀ngàn Ìlú, níbi tí Olùsọ̀rọ̀ Ń Dúró Sí láti sọ̀rọ̀, a óò sì ṣètìlẹyìn nípa fífetí sílẹ̀ sí àsọyé oníwákàtí kan ti Arákùnrin Rutherford, a óò mú àwọn ìwé pẹlẹbẹ dání, tí a óò sì máa nà án sí àwọn tí wọ́n bá fìfẹ́ hàn. A di gbajúmọ̀ níbẹ̀. Àwọn ọlọ́pàá pàápàá bọ̀wọ̀ fún wa. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, nígbà tí a péjọ pọ̀ bí a ti máa ń ṣe, a gbọ́ ìró ìlù àti bẹ̀m̀bẹ́ ní òkèèrè. Láìpẹ́ ìwọ́de àwọn Ajàfọ́ba tí wọ́n tó ọgọ́rùn-ún yan wá láti ìsàlẹ̀. Wọ́n yan yí wa ká, wọ́n sì dúró gbọn-in pẹ̀lú àsíá wọ́n tí wọ́n nà sókè. Ìlù náà dáwọ́ dúró, kẹ́kẹ́ sì pa rére bí ohùn Arákùnrin Rutherford ti ń bú pé: “Ẹ jẹ́ kí wọ́n máa kí àsíá wọn, kí wọ́n sì máa yin ènìyàn bí wọ́n bá fẹ́. Àwa yóò jọ́sìn, a óò sì yin kìkì Jehofa Ọlọrun wa!” A ń ṣe kàyéfì lórí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé e! Kò sí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n wulẹ̀ gbọ́ ìwàásù tí ó dára, àwọn ọlọ́pàá sì mú kí wọ́n dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí a ba lè gbọ́ ìyókù àsọyé gbogbo ènìyàn náà.

Nísinsìnyí, a bẹ̀rẹ̀ sí lo ẹ̀rọ ìkọrin láti ràn wá lọ́wọ́ láti fún wọn ní ìjẹ́rìí tí ó ga lọ́lá. Ní ẹnú ọ̀nà, a ń fìṣọ́ra tẹ ojú wa mọ́ àwo ìkọrin náà láti fún àwọn ènìyàn ní ìṣírí láti tẹ́tí sílẹ̀ fún ìṣẹ́jú márùn-ún gbáko sí ìwàásù Bibeli tí a ti gba ohùn rẹ̀ sílẹ̀. Àwọn onílé sábà máa ń ké sí wa wọlé, inú wọn sì máa ń dùn pé kí a padà wá láti wá tẹ àwo sí i.

Ní ọdún 1939, ọwọ́ wa dí púpọ̀, ó sì ṣòro gan-an, pẹ̀lú àtakò àti ìwa ipá tí ó bẹ́ sílẹ̀. Ṣáájú ọ̀kan lára àwọn àpéjọpọ̀ agbègbè wa, àwọn arákùnrin ní ìrírí àwọn ènìyàn tí ń dàlú rú àti ariwo gèè ní òpópónà. Nítorí náà, ní ìgbà àpéjọ náà, wọ́n ṣètò pé kí àwọn arákùnrin kan tí a ti yàn wà nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, kí wọ́n sì wàásù ní àwọn ibi tí ìjàngbọ̀n wà, nígbà tí àwọn arábìnrin àti àwọn arákùnrin yòókù yóò lọ sí àwọn ibi tí kò sí ewu. Nígbà tí mo ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwùjọ kan ní òpópónà kan, mo gba ọ̀nà tóóró kan láti lọ bẹ àwọn ilé tí wọ́n wà ní ẹ̀yìn wò. Nígbà tí mo wà ní ẹnu ọ̀nà kan, mo gbọ́ tí ìdàrúdàpọ̀ ń ṣẹlẹ̀—ariwo àti igbe wà ní òpópónà náà. Mo kàn ń bá a lọ láti máa bá ẹni tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà sọ̀rọ̀ ni, mo sì ń fa ìjíròrò náà gùn títí mo fi gbọ́ pé nǹkan ti lọ sílẹ̀. Nígbà náà ni mo rìn gba ọ̀nà tóóró náà padà sí òpópónà, mo rí i pé àwọn arákùnrin àti arábìnrin yòókù ti dààmú nígbà tí wọn kò rí mi! Bí ó ti wù kí ó rí, ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, àwọn oníjàngbọ̀n náà gbìyànjú láti da ìpàdé wa rú, ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin fàyà pẹ́ wọn jáde.

Ogun Àgbáyé II Bẹ́ Sílẹ̀

Nísinsìnyí, wọn ti ń fipá mú àwọn ènìyàn láti forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ológun, ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin ni a sì fi sẹ́wọ̀n oṣù 3 sí 12. Nígbà náà, Bàbá gba àfikún ẹrù iṣẹ́, láti máa bẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n wò. Ní gbogbo ọjọ́ Sunday, ó máa ń darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé-Ìṣọ́nà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n àdúgbò. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Wednesday, yóò bẹ àwọn arákùnrin náà wo ní yàrá ẹ̀wọ̀n wọn. Ní ti pé òun fúnra rẹ̀ ti ní irú ìrírí líle koko bẹ́ẹ̀ fún ìgbà pípẹ́ nígbà ogun àgbáyé kìíní, ó láyọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ láti ṣiṣẹ́ sin àwọn tí ń dojú kọ irú ìdánwò báyìí. Ó ṣe èyí fún 20 ọdún, títí di ìgbà ikú rẹ̀ ní 1959.

Nígbà tí ó fi di 1941 ìkórìíra àti ìkóguntini tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ń fi hàn nítorí ìdúró àìdá sí tọ̀túntòsì wa ti ń mọ́ra. Kò rọrùn láti dúró sí òpópónà pẹ̀lú ìwé ìròyìn wa lọ́wọ́, kí a sì dojú kọ èyí. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a láyọ̀ pé a fi àwọn olùwá-ibi-ìsádi wọ̀ ní àdúgbò wa. Àwọn ará Latvia, Poland, Estonia, àti Germany—ẹ wo irú ayọ̀ tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n rí Ilé-Ìṣọ́nà tàbí Consolation (tí a mọ̀ sí Jí! nísinsìnyí) ní èdè ìbílẹ̀ wọn!

Lẹ́yìn náà ni a pè mí lẹ́jọ́ fún ìdúró àìdá sí tọ̀túntòsì tí mo dì mú nígbà Ogun Àgbáyé II. A ń tì mí mọ́ inú yàrá ẹ̀wọ̀n fún wákàtí 19 nínú wákàtí 24 lójoojúmọ́, ìgbésí ayé inú ẹ̀wọ̀n ṣòro púpọ̀. Ọjọ́ mẹ́ta àkọ́kọ́ ni ó ṣòro jù lọ, nítorí mo dá wà ni. Ní ọjọ́ kẹrin, a pè mí lọ sí ọ́fíìsì gómìnà, níbi tí mo ti bá àwọn ọmọbìnrin méjì mìíràn ní ìdúró. Ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin náà béèrè kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ pé: “Nítorí kí ni o ṣe wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n?” Mo sọ pé: “Yóò yà ọ́ lẹ́nu bí o bá mọ̀ ọ́n.” Ó béèrè ní ọ̀nà tí ó túbọ̀ ṣe kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ pé: “Ṣé ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni ọ́ ni?” Ọmọbìnrin kan yòókù gbọ́ ohun tí ó sọ, ó sì béèrè lọ́wọ́ àwa méjèèjì pé: “Ṣé Ẹlẹ́rìí Jehofa ni yín ni?” àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta dì mọ́ ara wa. A kò dá wà mọ́!

Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún Tí Ó Mú Ayọ̀ Wá

Nígbà tí a dá mi sílẹ̀ kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n, mo ń bá iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún mi lọ, ọmọbìnrin kékeré ọlọ́dún 16 kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde ní ilé ẹ̀kọ́ sì dara pọ̀ mọ́ mi. A ṣí lọ sí Ilkley, ìlú kan tí ó rẹwà ní bèbè Yorkshire Dales. Fún odindi oṣù mẹ́fà gbáko, a tiraka kíkankíkan láti rí ibi tí ó dára fún ìpàdé wa. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, a háyà ibi ìgbọ́kọ̀sí kékeré kan, tí a yí padà sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bàbá ràn wá lọ́wọ́, nípa pípèsè iná àti ohun ìmúlémóoru. Ó sì tún ṣe ilé náà lọ́ṣọ̀ọ́ fún wa. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, ìjọ tí ó wà nítòsí ṣètìlẹyìn fún wa, nípa ṣíṣètò kí àwọn arákùnrin máa wá sọ àsọyé fún gbogbo ènìyàn ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Pẹ̀lú ìbùkún Jehofa, a tẹ̀ síwájú, a sì gbèrú sí i, àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, a dá ìjọ kan sílẹ̀.

Ní January 1959, Bàbá déédé dùbúlẹ̀ àìsàn. A pè mí wá sí ilé, ó sì kú ní April. Àwọn ọdún tí ó tẹ̀ lé e lè koko gan-an. Ìlera Màmá kò dára mọ́, iyè rẹ̀ sì ra, èyí mú kí ó ṣòro fún mi. Ṣùgbọ́n ẹ̀mí Jehofa ràn mí lọ́wọ́, ó ṣeé ṣe fún mi láti bójú tó o títí di ìgbà ikú rẹ̀ ní 1963.

Mo ti rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ Jehofa ní àwọn ọdún yìí wá. Ó ti pọ̀ jù ohun tí mo lè rántí lọ. Mo ti rí ìjọ ilú mi, tí ó ti gbèrú, tí a sì pín ní ẹ̀ẹ̀mẹrin, tí ó rán àwọn akéde àti àwọn aṣáájú ọ̀nà jáde, àwọn kan gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì lọ sí àwọn orílẹ̀ èdè tí ó jìnnà sí ara wọ́n bí Bolivia, Laos, àti Uganda. Àyè àtilọ́kọ kí n sì fìdí kalẹ̀ kò yọ sílẹ̀ fún mi. Kò mú mi banú jẹ́ rí; ọwọ́ mi dí púpọ̀. Bí n kò tilẹ̀ ní ìbátan tí ó jẹ́ ti ẹ̀jẹ̀ mi, mo ní àwọn ọmọ àti ọmọ-ọmọ nínú Oluwa, àní ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún pàápàá.—Marku 10:29‚ 30.

Mo sábà máa ń pe àwọn ọ̀dọ́ aṣáájú ọ̀nà àti ọ̀dọ́ mìíràn wá sí ilé mi láti lè ní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ Kristian papọ̀. A máa ń múra Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé-Ìṣọ́nà papọ̀. A tún máa ń sọ àwọn ìrírí, a sì tún ń kọrin Ìjọba papọ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn òbí mi ti máa ń ṣe. Mo ní ojú ìwòye ọ̀dọ́, mo sì ń láyọ̀, ní ti pé àwùjọ àwọn ọ̀dọ́ ènìyàn ni ó yí mi ká. Kò sí ìgbésí ayé tí ó sunwọ̀n fún mi ju ti iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà lọ. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jehofa pé mo ní àǹfààní láti tẹ̀ lé ipasẹ̀ àwọn òbí mi. Àdúrà mi ni pé, ki ń lè máa bá a lọ ní ṣíṣiṣẹ́ sin Jehofa títí ayérayé.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ní ìrántí òpin ìkóguntini ní 1918 àti, lẹ́yìn náà, ní 1945.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Hilda Padgett pẹ̀lú àwọn òbí rẹ̀, Atkinson àti Pattie

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ìwé àṣàrò kúkúrú tí ó ru ọkàn-ìfẹ́ Bàbá sókè sí òtítọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́