Àwọn Òbí Wa Kọ́ Wa Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run
GẸ́GẸ́ BÍ ELIZABETH TRACY ṢE SỌ Ọ́
Àwọn ọkùnrin tó dìhámọ́ra, tí wọ́n ti kọ́kọ́ kó àwọn èèyànkéèyàn kan sòdí láti bá wa jà láàárọ̀ ọjọ́ yẹn, fa Mọ́mì àti Dádì jáde nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa. Èmi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tí wọ́n fi sílẹ̀ sínú ọkọ̀ wá ń ṣe kàyéfì bóyá a ó tún padà rí àwọn òbí wa. Kí ló fa ìrírí tí ń dáyà foni yìí nítòsí Selma, Alabama, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ní ọdún 1941? Kí sì ni ẹ̀kọ́ táa gbà látọ̀dọ̀ àwọn òbí wa ní í ṣe pẹ̀lú rẹ̀?
ÌBÁTAN kan ló tọ́ baba mí, Dewey Fountain, dàgbà ní abúlé kan ní Texas lẹ́yìn tí àwọn òbí rẹ̀ ti kú nígbà tó ṣì wà lọ́mọ ọwọ́. Ẹ̀yìn ìyẹn ló lọ ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń wa epo. Ní ọdún 1922, nígbà tó wà lẹ́ni ọdún mẹ́tàlélógún, ó fẹ́ Winnie, ọmọbìnrin arẹwà kan láti Texas, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wéwèé láti wá ibì kan tí yóò máa gbé, kó sì ní ìdílé tirẹ̀.
Ó kọ́ ilé kan sí àgbègbè kan tí igi gẹdú pọ̀ sí ní ìlà oòrùn Texas nítòsí ìletò tí ń jẹ́ Garrison. Ibẹ̀ ló gbin onírúurú ohun ọ̀gbìn sí, títí kan òwú àti àgbàdo. Ó tún ní ọ̀pọ̀ ẹran ọ̀sìn. Láìpẹ́, wọ́n bí àwa ọmọ—wọ́n bí Dewey kékeré ní May 1924, wọ́n bí Edwena ní December 1925, wọ́n sì bí èmi náà ní June 1929.
Kíkọ́ Òtítọ́ Bíbélì
Mọ́mì àti Dádì rò pé àwọn mọ Bíbélì, nítorí pé wọ́n ń dara pọ̀ mọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Kristi. Àmọ́, ní ọdún 1932, G. W. Cook kó ìwé Deliverance àti Government, tí Watch Tower Society tẹ̀ jáde, fún ẹ̀gbọ́n Dádì [Dádì àgbà] tó ń jẹ́ Monroe Fountain. Nítorí ìháragàgà tí Dádì àgbà ní láti ṣàjọpín ohun tó ń kọ́ pẹ̀lú àwọn òbí mi, ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń wá lákòókò táa ń jẹ oúnjẹ àárọ̀, yóò ka àpilẹ̀kọ kan láti inú Ilé Ìṣọ́, yóò wá ṣe bí ẹni pé òun “gbàgbé” ìwé ìròyìn náà sílẹ̀. Lẹ́yìn náà, Mọ́mì àti Dádì yóò kà á.
Ní òwúrọ̀ Sunday kan, Dádì àgbà pe Dádì mi lọ sí ilé aládùúgbò wa kan fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó mú un dá a lójú pé Ọ̀gbẹ́ni Cook lè dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀ láti inú Bíbélì. Bí Dádì ṣe ń dé láti ibi ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, ló fi tayọ̀tayọ̀ sọ fún wa pé: “Mo rí ìdáhùn sí gbogbo àwọn ìbéèrè mi, mo sì tún gbọ́ àwọn ìsọfúnni mìíràn pẹ̀lú! Mo rò pé kò sí nǹkan tí n kò mọ̀, àmọ́, nígbà tí Ọ̀gbẹ́ni Cook bẹ̀rẹ̀ sí ṣàlàyé nípa ọ̀run àpáàdì, ọkàn, ète Ọlọ́run nípa ayé, àti bí Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣe mú àwọn ète náà ṣẹ, mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé n ò tiẹ̀ mọ ohunkóhun nípa Bíbélì!”
Nílé wa, ọjọ́ gbogbo bí ọdún ni. Àwọn ìbátan àtàwọn ọ̀rẹ́ kì í wọ́n nílé wa, bí wọ́n ti ń dín midin-míìdìn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n a máa yan gúgúrú olóyin, tí wọ́n a sì máa bá Mọ́mì kọrin bó ṣe ń tẹ dùùrù olóhùn gooro. Díẹ̀díẹ̀ la wá fi ìjíròrò Bíbélì dípò gbogbo àwọn nǹkan tí wọ́n ń ṣe wọ̀nyẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwa ọmọdé ò lóye gbogbo ohun tí wọ́n ń jíròrò rẹ̀, síbẹ̀ ìfẹ́ lílágbára tí àwọn òbí wa ní fún Ọlọ́run àti Bíbélì kò fara sin rárá débi pé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwa ọmọ ló ní irú ìfẹ́ kan náà fún Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Àwọn ìdílé mìíràn tún gbà ká máa jíròrò Bíbélì nínú ilé wọn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, orí kókó kan nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tó jáde kẹ́yìn sì ni ìjíròrò náà máa ń dá lé. Nígbà tó bá jẹ́ pé ilé àwọn ìdílé tó wà ní àwọn ìlú tó yí wa ká bíi Appleby àti Nacogdoches la ó ti ṣèpàdé, a ó rọ́ kún inú ọkọ̀ Model A Ford wa, a ó sì rìnrìn àjò lọ síbẹ̀ láìka bójú ọjọ́ ṣe wù kó rí sí.
Wọ́n Ṣiṣẹ́ Lórí Ohun Tí Wọ́n Kọ́
Kò pẹ́ tí àwọn òbí wa fi rí i pé ó yẹ kí àwọn gbé ìgbésẹ̀. Ìfẹ́ fún Ọlọ́run béèrè pé kí a ṣàjọpín ohun tí a ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. (Ìṣe 20:35) Ṣùgbọ́n ìpèníjà ní àṣà kí a máa sọ ìgbàgbọ́ ẹni dí mímọ̀ fún gbogbo gbòò yìí jẹ́, àti pàápàá bó ṣe jẹ́ pé onítìjú àti onírẹ̀lẹ̀ ènìyàn làwọn òbí wá jẹ́. Síbẹ̀, ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, èyí sì tún ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kọ́ wa láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé jíjìnlẹ̀ nínú Jèhófà. Ọ̀nà tí Dádì gbà sọ ọ́ nìyí: “Jèhófà ń sọ àwọn àgbẹ̀ di oníwàásù!” Ni ọdún 1933, Mọ́mì àti Dádì fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọ́n fún Jèhófà hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi ní odò ẹja kan nítòsí Henderson, Texas.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1935, Dádì kọ̀wé sí Watch Tower Society, ó sì béèrè àwọn ìbéèrè bíi mélòó kan lórí ìrètí àwọn Kristẹni nípa ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòhánù 14:2; 2 Tímótì 2:11, 12; Ìṣípayá 14:1, 3; 20:6) Ó gba èsì tààràtà látọ̀dọ̀ Joseph F. Rutherford, tó jẹ́ ààrẹ fún Society nígbà náà. Kàkà tí Arákùnrin Rutherford ì bá fi dáhùn àwọn ìbéèrè náà, ńṣe ló ní kí Dádì wá sí àpéjọpọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Washington, D.C., ní May.
Dádì ronú pé: ‘Ìyẹn ò lè ṣeé ṣe láé! Àgbẹ̀ ni wá, a sì ti gbin ẹ̀fọ́ sórí hẹ́kítà mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ilẹ̀. A ní láti kórè wọn ká sì tà wọ́n lákòókò yẹn.’ Àmọ́, kò pẹ́ sí àkókò yẹn tí àkúnya omi kan fi dé tó sì gbá gbogbo ohun tó tìtorí ẹ̀ ń ṣàwáwí lọ—ìyẹn àwọn ohun ọ̀gbìn, ọgbà, àti afárá. La bá kúkú dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí yòókù nínú bọ́ọ̀sì ilé ìwé kan táa háyà, tó gbé wa rin ìrìn ẹgbẹ̀jọ [1,600] kìlómítà lọ sí àríwá ìlà oòrùn níbi àpéjọpọ̀ náà.
Ní àpéjọpọ̀ náà, inú Dádì àti Mọ́mì dùn láti gbọ́ àlàyé tó ṣe kedere nípa bí a ṣe dá “ògìdìgbó ńlá” mọ̀, ìyẹn àwọn tí yóò la “ìpọ́njú ńlá” já. (Ìṣípayá 7:9, 14, King James Version) Ní gbogbo ìyókù nínú ìgbésí ayé wọn, ìrètí ìyè ayérayé nínú párádísè orí ilẹ̀ ayé ló ń sún Mọ́mì àti Dádì ṣiṣẹ́, wọ́n sì gba àwa ọmọ níyànjú láti “di ìyè tòótọ́ mú gírígírí,” èyí tó túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé tí Jèhófà ṣèlérí rẹ̀. (1 Tímótì 6:19; Sáàmù 37:29; Ìṣípayá 21:3, 4) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọdún márùn-ún péré ni mí nígbà náà, síbẹ̀, mo gbádùn bí mo ṣe wà pẹ̀lú ìdílé mi níbi ìṣẹ̀lẹ̀ aláyọ̀ yìí gan-an ni.
Lẹ́yìn táa ti àpéjọpọ̀ náà dé la wá tún àwọn nǹkan ọ̀gbìn wa gbìn, a sì kórè ohun tó pọ̀ gan-an ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Èyí wá mú un dá Mọ́mì àti Dádì lójú pé níní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jèhófà kò ní ṣaláì fúnni lérè. Wọ́n tẹ́wọ́ gba àkànṣe iṣẹ́ ìwàásù kan nínú èyí tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọ́n gbà láti máa lo wákàtí méjìléláàádọ́ta nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lóṣooṣù. Lẹ́yìn náà, nígbà tí àkókò ọ̀gbìn tó tẹ̀ lé e dé, gbogbo ohun tí wọ́n fi ń dáko pátá ni wọ́n tà! Dádì wá ṣe ọkọ̀ àfiṣelé kan tí gígùn rẹ̀ jẹ́ mítà mẹ́fà tí fífẹ̀ rẹ̀ sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mítà méjì àbọ̀, kí àwa márààrún lè máa gbé inú rẹ̀, ó sì ra ọkọ̀ Ford tuntun tó ní ilẹ̀kùn méjì láti máa fi fà á. Dádì àgbà náà ṣe bẹ́ẹ̀, òun àti ìdílé rẹ̀ náà kó lọ sínú ọkọ̀ àfiṣelé kan.
Kíkọ́ Wa Ní Òtítọ́
Ní October 1936, Dádì àti Mọ́mì bẹ̀rẹ̀ ṣí í ṣe aṣáájú ọ̀nà, bí a ti máa ń pé iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan, a bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ní àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tó wà ní ìlà oòrùn Texas tí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà kò tíì fi bẹ́ẹ̀ dé. Fún odindi ọdún kan la fí ń lọ láti ibì kan sí ibòmíràn, àmọ́, táa bá wo gbogbo rẹ̀ lápapọ̀, a gbádùn irú ìgbésí ayé yìí gan-an ni. Mọ́mì àti Dádì fi ọ̀rọ̀ àti àpẹẹrẹ tiwọn kọ́ wa láti dà bí àwọn Kristẹni ìjímìjí tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn láti mú òtítọ́ Bíbélì tọ àwọn ẹlòmíràn lọ.
Àwa ọmọ kan sáárá sí ìyá wa ní pàtàkì fún ìrúbọ tó ṣe nípa fífi ilé rẹ̀ sílẹ̀. Àmọ́, ohun kan wà tí kò lè fi sílẹ̀, ìyẹn ni maṣín-ìn tó fi ń ránṣọ. Ìpinnu rẹ̀ yẹn sì dára. Nítorí aṣọ tó mọ̀ ọ́n rán yẹn, gbogbo ìgbà ló máa ń wọṣọ tó dára sí wa lọ́rùn. Àpéjọpọ̀ kan ò ní lọ ká má wọ aṣọ tó fani mọ́ra.
Mo rántí ìgbà tí Herman G. Henschel àti ìdílé rẹ̀ gbé ọkọ̀ tí Watch Tower Society fi ń kó ẹ̀rọ gbohùn-gbohùn wá sí àgbègbè wa. Wọn óò gbé ọkọ̀ náà sí àgbègbè tí àwọn èèyàn pọ̀ sí, wọn á sì fi àwíyé kúkurú sínú ẹ̀rọ náà fún àwọn ènìyàn láti gbọ́, ẹ̀yìn ìgbà yẹn làwọn fúnra wọn yóò wá máa bẹ àwọn ènìyàn náà wo láti fún wọn ní ìsọfúnni síwájú sí i. Dewey kékeré gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ ọmọ Herman, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Milton, to ṣẹ̀ṣẹ̀ lé lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nígbà náà. Milton ni ààrẹ Watch Tower Society báyìí.
Nígbà àpéjọpọ̀ tí 1937 ní Columbus, Ohio, Edwena ṣe ìrìbọmi, wọ́n sì fún Mọ́mì àti Dádì láǹfààní láti sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe. Lákòókò náà, iṣẹ́ yẹn máa ń gba kí ènìyàn lo ó kéré tán igba wákàtí nínú iṣẹ́ ìwàásù náà lóṣù kan. Bí mo ṣe ń bojú wẹ̀yìn, mo mọ bí àpẹẹrẹ rere tí Mọ́mì fi lélẹ̀ ṣe ràn mí lọ́wọ́ láti ṣètìlẹ́yìn fún ọkọ mi nínú iṣẹ́ tí a yàn fún un gẹ́gẹ́ bí Kristẹni.
Nígbà tí Dádì bá ti bẹ̀rẹ̀ sí bá ìdílé kan ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó máa ń mú àwa ọmọ lọ́wọ́ lọ síbẹ̀ láti pèsè àpẹẹrẹ rere fún àwọn ọmọ wọn. Ó máa ń jẹ́ ká ṣí Bíbélì ká sì ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà, a ó tún dáhùn àwọn kan lára àwọn ìbéèrè tó ṣe kókó. Nítorí ìdí èyí, ọ̀pọ̀ lára àwọn èwe táa bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ nígbà yẹn ló ń fi tọkàntọkàn sin Jèhófà títí di òní olónìí. Láìsí àní-àní, ìpìlẹ̀ tó dára ni wọ́n fi lélẹ̀ fún wa, ká lè máa bá a lọ láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.
Bí Dewey kékeré ṣe ń dàgbà, kò rọrùn fún un láti máa gbé nínú ibi tó fún báyẹn pẹ̀lú àwọn àbúrò rẹ̀ obìnrin méjì. Nítorí náà, ní ọdún 1940, ó yàn láti máa gbé pẹ̀lú Ẹlẹ́rìí mìíràn kí wọ́n sì jọ máa ṣe aṣáájú ọ̀nà pa pọ̀. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó fẹ́ Audrey Barron. Àwọn òbí wa sì tipa bẹ́ẹ̀ kọ́ Audrey ní ọ̀pọ̀ nǹkan, ó sì nífẹ̀ẹ́ Mọ́mì àti Dádì gan-an ni. Ó tiẹ̀ wá gbé pẹ̀lú wa fúngbà díẹ̀ nínú ọkọ̀ àfiṣelé wa tó há gádígádí, lẹ́yìn tí wọ́n ju Dewey kékeré sẹ́wọ̀n ní ọdún 1944 nítorí tí kò dá sí tọ̀tún tòsì.
Ní àpéjọpọ̀ ńlá táa ṣe ní St. Louis, Missouri, ní ọdún 1941, Arákùnrin Rutherford bá àwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọ́n wà láàárín ọdún márùn-ún sí méjìdínlógún, tí wọ́n jókòó síbi àkànṣe kan níwájú sọ̀rọ̀ ní tààràtà. Èmi àti Edwena fetí sí ohùn rẹ̀ tó tutù, tó sì yéni yékéyéké; ó dà bí baba onífẹ̀ẹ́ kan tó ń fún àwọn ọmọ rẹ̀ nítọ̀ọ́ni nínú ilé. Ó fún àwọn òbí níṣìírí pé: “Lónìí, Kristi Jésù kó àwọn ènìyàn májẹ̀mú rẹ̀ jọ síwájú rẹ̀, ó sì ń sọ fún wọn lọ́nà tó lágbára jù lọ pé kí wọn tọ́ àwọn ọmọ wọn lọ́nà òdodo.” Ó fi kún un pé: “Ẹ kó wọn sínú ilé, kí ẹ sì fi òtítọ́ kọ́ wọn!” A layọ̀ pé àwọn òbí wa ṣe bẹ́ẹ̀!
Ní àpéjọpọ̀ yẹn, a layọ̀ láti gba ìwé kékeré náà, Jehovah’s Servants Defended, tó ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ẹjọ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti jàre nílé ẹjọ́ títí kan àwọn ti Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Dádì bá wa fi ìwé náà ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé. A ò mọ̀ rara pé wọ́n ń múra wa sílẹ̀ de ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ láwọn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn náà ní Selma, Alabama.
Ìgbésẹ̀ Àwọn Ènìyànkénìyàn ní Selma
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ táa ní ìrírí ẹlẹ́rù jẹ̀jẹ̀ yẹn, Dádì lọ kó àwọn ẹ̀dà lẹ́tà kan tó ṣàlàyé ẹ̀tọ́ táa ní láti máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa nìṣó lábẹ́ ààbò òfin fún adájọ́, olórí ìlú, àti olórí àwọn ọlọ́pàá ní Selma. Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n pinnu láti lé wa jáde nílùú.
Nígbà tó ń dọwọ́ ìrọ̀lẹ́, àwọn ọkùnrin márùn-un tí wọ́n di ìhámọ́ra wá síbi ọkọ̀ àfiṣelé wa, wọ́n sì mú èmi, Màmá àti arábìnrin mi ní òǹdè. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í tú gbogbo ohun tó wà nínú ilé, wọ́n ń wá ohun kan tó lòdì sófin ìjọba. Dádì wà níta, wọ́n sì ń pàṣẹ fún un pé kó so ọkọ̀ àfiṣelé náà mọ́ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, bí wọ́n ti ń sọ èyí ni wọ́n na ìbọn sí i. Àkókò yìí gan-an lẹ̀rù ò wá bà mí mọ́. Bí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ṣe rò pé eléwu ènìyàn ni wá kàn ń pani lẹ́rìn-ín ni, débi pé èmi àti arábìnrin mi wa ń rẹ́rìn-ín. Àmọ́, kíá la dákẹ́, nígbà tí Dádì fojú bá wa sọ̀rọ̀.
Nígbà táa fẹ́ máa lọ, àwọn ọkùnrin náà fẹ́ kí èmi àti Edwena bá wọn wọ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tiwọn. Dádì kọ̀ jálẹ̀. Ó ní: “Kì í ṣe lójú ayé mi!” Lẹ́yìn ìjíròrò díẹ̀, wọ́n gbà kí ìdílé wa wọkọ̀ kan náà, àwọn ọkùnrin tó dìhámọ́ra náà sì ń gbé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tiwọn tẹ̀ lé wa. Nígbà táa rin nǹkan bí kìlómítà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n kúrò nílùú, wọ́n ni ká dúró lẹ́gbẹ́ kan lójú ọ̀nà, wọ́n sì mú Mọ́mì àti Dádì lọ. Àwọn ọkùnrin náà wá ń gbà wọ́n nímọ̀ràn lọ́kan-ò-jọ̀kan pé: “Ẹ fi ẹ̀sìn yẹn sílẹ̀. Kẹ́ẹ padà sínú oko, kẹ́ẹ sì tọ́ àwọn ọmọbìnrin yín lọ́nà tó dáa!” Dádì gbìyànjú láti ṣàlàyé fún wọn, àmọ́, òtúbáńtẹ́ ní gbogbo rẹ̀ já sí.
Níkẹyìn, ọkùnrin kan sọ pé: “Ẹ máa lọ, tẹ́ẹ bá sì tún padà wá sí Ìjọba Ìbílẹ̀ Dallas, a óò pa gbogbo yín láìku ẹnì kan!”
Ìgbà yẹn lọkàn wa ṣẹ̀ṣẹ̀ balẹ̀, a wá rìnrìn àjò fún ọ̀pọ̀ wákàtí kó tó di pé a dúró nígbà tí ilẹ̀ ṣú. A kọ nọ́ńbà ọkọ̀ wọn sílẹ̀. Kíá ni Dádì ròyìn gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ fún Watch Tower Society, oṣù díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn làṣírí wọn tú, tí wọ́n sì fàṣẹ ọba mú wọn.
A Lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead fún Àwọn Míṣọ́nnárì
Edwena gba ìkésíni láti wá sí kíláàsì keje tí Watchtower Bible School of Gilead ní South Lansing, New York, ní 1946. Albert Schroeder, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ níbẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ànímọ́ rere rẹ̀ fún Bill Elrod tí òun pẹ̀lú rẹ̀ jọ ń ṣe iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà tẹ́lẹ̀, àmọ́, lákòókò yẹn, ó ti ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, orílé iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn, New York.a Wọ́n fojú Edwena àti Bill mọra wọn, wọ́n sì ṣe ìgbéyàwó ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Gilead. Ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n lò nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, títí kan ọdún márùn-ún tí wọ́n fi sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Lẹ́yìn náà, lọ́jọ́ kan lọ́dún 1959, Arákùnrin Schroeder kéde fún àwọn tó wà ní kíláàsì kẹrìnlélọ́gbọ̀n ti Gilead pé ọ̀rẹ́ òun ọ̀wọ́n ti di baba ìbejì, ọkùnrin kan àtobìnrin kan.
Nígbà tí mo ń sìn pẹ̀lú àwọn òbí mi ní Meridian, Mississippi, ní òpin ọdún 1947, àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta rí ìkésíni kan gbà pé ká wá sí kíláàsì kọkànlá ti ilé ẹ̀kọ́ Gilead. Ó yà wá lẹ́nu gan-an ni, nítorí táa bá wo ohun tí wọ́n ń béèrè fún, ọjọ́ orí mi ṣì kéré gan-an, Mọ́mì àti Dádì náà sì ti dàgbà jù. Àmọ́, àrà ọ̀tọ̀ ni tiwa, a sì rí àǹfààní àìlẹ́tọ̀ọ́sí ti ìtọ́ni tó ga látinú Bíbélì yẹn gbà.
Mo Ṣe Iṣẹ́ Ìsìn Míṣọ́nnárì Pẹ̀lú Àwọn Òbí Mi
Ibi tí wọ́n yàn wá sí láti lọ ṣe iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì wa ni Colombia, ní Gúúsù Amẹ́ríkà. Àmọ́, December 1949, lẹ́yìn tó ti lé lọ́dún kan táa ti kẹ́kọ̀ọ́ yege, la ṣẹ̀ṣẹ̀ gúnlẹ̀ sí Bogotá nílé míṣọ́nnárì kan tí àwọn mẹ́ta mìíràn ti ń gbé. Lákọ̀ọ́kọ́, díẹ̀ ló kù kí Dádì parí èrò sí pé yóò rọrùn láti kọ́ àwọn ènìyàn náà lédè Gẹ̀ẹ́sì ju kí òun kọ́ èdè Spanish lọ! Dájúdájú, àwọn àdánwò wà, àmọ́, àwọn ìbùkún rẹ̀ mà ga o! Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Colombia kò tó ọgọ́rùn-ún ní 1949, ṣùgbọ́n nísinsìnyí wọ́n ti lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún!
Lẹ́yìn tí Mọ́mì àti Dádì sìn ní Bogotá, fún ọdún márùn-ún, a rán wọn lọ sí ìlú ńlá Cali. Láàárín àkókò kan náà, ní 1952, Robert Tracy, tó jẹ́ míṣọ́nnárì bíi tiwa ní Colombia, gbé mi níyàwó.b A wà ní Colombia títí di 1982, nígbà tí wọ́n ní ká lọ sí Mexico, níbi táa ti ń sìn láti ìgbà yẹn. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, nígbà tó di 1968 àwọn òbí mi ní láti padà sí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà kí wọ́n lè gba ìtọ́jú. Lẹ́yìn tí ara wọn ti yá, wọ́n ń bá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe lọ nítòsí Mobile, Alabama.
Bíbójútó Àwọn Òbí Wa
Bí ọdún ti ń gorí ọdún, Mọ́mì àti Dádì ò lágbára bíi tàtẹ̀yìnwá mọ́, wọ́n sì túbọ̀ nílò ìtìlẹ́yìn àti àbójútó. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n béèrè fún, a yàn wọ́n láti máa sìn nítòsí Edwena àti Bill ni Áténì, Alabama. Lẹ́yìn náà, Dewey kékeré, tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n wa ọkùnrin, rò ó pé ó dára kí ìdílé náà máa gbé pa pọ̀ ní Gúúsù Carolina. Nítorí náà, Bill kó ìdílé rẹ̀ lọ sí Greenwood, pẹ̀lú Mọ́mì àti Dádì. Bí a ṣe tún ètò ṣe lọ́nà onífẹ̀ẹ́ yìí mú kó rọrùn fún èmi àti Robert láti máa bá iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì wá lọ ní Colombia, nígbà táa rí i pé àwọn òbí wa ń rí ìtọ́jú tó dára gbà.
Lẹ́yìn náà, ní 1985, àrùn ẹ̀gbà ṣe Dádì tó fi jẹ́ pé kò lè sọ̀rọ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kó sì lè kúrò lójú kan. Báa ṣe pe ìpàdé ìdílé nìyẹn ká lè mọ ọ̀nà tó dára jù lọ láti tọ́jú àwọn òbí wa. A wá pinnu pé kí Audrey máa tọ́jú Dádì, àti pé ìrànlọ́wọ́ tí èmi àti Robert lè ṣe ni pé kí a máa kọ lẹ́tà tó ní àwọn ìrírí tí ń gbéni ró lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ kí a sì máa ṣèbẹ̀wò ní gbogbo ìgbà tó bá ṣeé ṣe.
Mo sì rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí mo bẹ Dádì wò kẹ́yìn dáadáa. Kò lè sọ̀rọ̀ jáde, àmọ́, lẹ́yìn táa sọ fún un pé a tí ń padà lọ sí Mexico, lọ́nà kan ṣá, pẹ̀lú agbára káká àti ìmọ̀lára tó ní, ó sọ pé: “Ó dìgbà!” Nípa èyí, a mọ̀ pé, nínú ọkàn rẹ̀, ó fara mọ́ ìpinnu wa láti máa bá iṣẹ́ míṣọ́nnárì wa lọ. Ó kú ní July 1987, oṣù mẹ́sàn-án lẹ́yìn ìyẹn ni Mọ́mì náà kú.
Lẹ́tà kan tí mo gbà látọ̀dọ̀ arábìnrin mi tó jẹ́ opó ṣàkópọ̀ bí ẹnì kọ̀ọ̀kan wá ṣe mọrírì àwọn òbí wa tó. Ó sọ pé: “Mo mọrírì ìṣúra ogún Kristẹni tó ṣeyebíye tí mo ní, n kò sì fìgbà kan ronú pé ǹ bá láyọ̀ jùyẹn lọ ká ní pé ọ̀nà mìíràn làwọn òbí wa gbà tọ́ wa ni. Àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tó lágbára, ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ, àti níní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jèhófà ti ràn mí lọ́wọ́ láti la àwọn àkókò ìsoríkọ́ tí mo ní nínú ìgbésí ayé já.” Edwena parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé mo ní àwọn òbí tó jẹ́ pé wọ́n fi ayọ̀ tí a lè rí bí a bá lo ìgbésí ayé wa fún sísìn Jèhófà, Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ hàn wá nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ àti àpẹẹrẹ wọn.”
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Ilé Ìṣọ́ March 1, 1988, ojú ìwé 11 sí 12.
b Wo Ilé Ìṣọ́ March 15, 1960, ojú ìwé 189 sí 191 (Gẹ̀ẹ́sì).
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22, 23]
Ìdílé Fountain: (láti apá òsì sí ọ̀tún) Dewey, Edwena, Winnie, Elizabeth, Dewey kékeré; lápá ọ̀tún: Elizabeth àti Dewey kékeré níbi irin tó wà lórí ọkọ̀ tí Henschel fi ń kó àwọn ohun èlò gbohùn-gbohùn rẹ̀ (1937); nísàlẹ̀ lápá ọ̀tún: Elizabeth ń wàásù nípa gbígbé páálí tí a kọ nǹkan sí kọ́rùn nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún