ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 12/1 ojú ìwé 25
  • Ìmúgbòòrò Ìṣàkóso Ọlọ́run ní Namibia

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìmúgbòòrò Ìṣàkóso Ọlọ́run ní Namibia
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ibi Tá A Ti Ń Ṣiṣẹ́ Míṣọ́nnárì Di Ilé Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Bánábà àti Pọ́ọ̀lù Sọ Àwọn Èèyàn Tó Wà Láwọn Ọ̀nà Jíjìn Di Ọmọlẹ́yìn
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 12/1 ojú ìwé 25

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

Ìmúgbòòrò Ìṣàkóso Ọlọ́run ní Namibia

ÀWỌN ọdún tó kẹ́yìn àwọn ọdún 1920 ni ìgbà àkọ́kọ́ tí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run dé Namibia. Àtìgbà yẹn làwọn ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn tí wọ́n jẹ́ aláìlábòsí ti ń tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìgbàlà Ọlọ́run. Àwọn ìrírí tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí fi hàn bí Jèhófà ṣe ń kó àwọn ẹni fífani lọ́kàn mọ́ra jọ sínú agbo rẹ̀.—Hágáì 2:7.

◻ Ìgbà tí Paulus, àgbẹ̀ paraku kan tó ń gbé ìhà àríwá ìlà oòrùn Namibia, ṣèbẹ̀wò sí Windhoek, tó jẹ́ olú ìlú náà, ni ìgbà àkọ́kọ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn sí i. Kíá ni Paulus gbà pé òun ti rí òtítọ́. Ó mú ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye lọ sílé. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Paulus lọ sí Rundu, tó jẹ́ ìlú tó sún mọ́ ọn jù lọ, tí Gbọ̀ngàn Ìjọba kan wà, ó rí àwọn Ẹlẹ́rìí, ó sì bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n ṣe ìbẹ̀wò sí ọ̀dọ̀ òun.

Àmọ́, ọ̀nà náà jìn jù fún àwọn Ẹlẹ́rìí náà láti wá máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Paulus lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Láìrẹ̀wẹ̀sì, Paulus bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fúnra rẹ̀. Láfikún sí i, ó tún ń fìtara wàásù nípa ohun tó ń kọ́ fún àwọn ẹlòmíràn. Láìpẹ́, ó dá àwùjọ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan sílẹ̀. Nígbà tí àwùjọ kékeré náà gbọ́ lórí rédíò pé àpéjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò wáyé ní Rundu, wọ́n ṣa gbogbo tọ́rọ́ kọ́bọ̀ tí wọ́n ní jọ wọ́n sì ṣètò bí wọn yóò ṣe débẹ̀.

Ẹ wo bí ayọ̀ wọn ti pọ̀ tó láti dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ìgbà àkọ́kọ́! Kò pẹ́ táa fi ṣètò pé kí arákùnrin kan tó dáńgájíá máa bẹ àwùjọ yìí wò déédéé. Lónìí, akéde mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà ní abúlé tí Paulus ń gbé.

◻ Ọ̀rọ̀ burúkú tí ẹnì kan ń sọ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló tanná ran ìfẹ́ tí Johanna ní sí orúkọ Ọlọ́run. Ó rántí pé: “Ìgbà àkọ́kọ́ pàá tí mo gbọ́ orúkọ náà Jèhófà ló ti di ohun tí n kò lè gbàgbé mọ́, mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kàyéfì nípa ẹni tí Jèhófà jẹ́. Ọ̀dọ̀ ọkọ mi ni mò ń gbé nígbà yẹn nítòsí Ìyawọlẹ̀ Omi Òkun Walvis tó wà létíkun Namibia. Nígbà kan táa lọ sáàárín ìlú, mo rí àwọn Ẹlẹ́rìí kan tí wọ́n ń pín ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ lójú pópó. Mo gba ẹ̀dà kan, mo sì ní kí wọ́n wá máa bá mi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nítorí pé mo ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè. Mo sunkún nígbà tí wọ́n sọ pé wọn ò ní lè wá nítorí pé ọkọ̀ wọ́n ti bà jẹ́. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn tí ọkọ mí kú, tí mo sì lọ ń gbé ní Keetmanshoop. Wọ́n ti rán aṣáájú ọ̀nà àkànṣe (ajíhìnrere alákòókò kíkún) kan láti wá máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀, mo sì gba ìwé Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye lọ́wọ́ rẹ̀. Láti ìbẹ̀rẹ̀ yẹn gan-an ni mo ti ri ẹ̀rí ìdánilójú pé òtítọ́ nìyí.

“Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n pè mí kí n wá nípìn-ín nínú iṣẹ́ wíwàásù, àmọ́, ìbẹ̀rù ènìyàn bò mí mọ́lẹ̀. Nígbà tí mo ń lọ láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà, mo gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ kí n kú dípò tí màá fi wàásù. Nígbà àkọ́kọ́ tí mo kópa nínú ìjẹ́rìí òpópónà, mo fara pa mọ́ sínú igbó ṣúúrú kan ní ìrètí pé kò sí ẹni tó lè rí mi níbẹ̀. Níkẹyìn, mo ṣọkàn mi gírí láti fi ìwé ìròyìn lọ ẹni kan tó ń kọjá, ìgbà yẹn ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbìyànjú àtisọ̀rọ̀. Lọ́jọ́ yẹn, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, mo sọ ìrètí mi tí a gbé ka Bíbélì fún ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn.

“Lónìí, tó jẹ́ ọdún méjìlá lẹ́yìn ìgbà yẹn, mo ṣì gbá àǹfààní iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà mú ṣinṣin, bẹ́ẹ̀ ni mo ṣì ń rí ayọ̀ tí kò ṣeé díye lé látinú sísọ òtítọ́ Ìjọba náà fún àwọn ẹlòmíràn bí n kò tilẹ̀ lówó lọ́wọ́.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́