Má Ṣe Jẹ́ Kí Ànímọ́ Rere Rẹ Di Àbùkù Rẹ
Wọ́n rò pé ọkọ̀ afẹ́ Tìtáníìkì kò lè rì nítorí yàrá mẹ́rìndínlógún tó wà nínú rẹ̀, tí wọ́n sé pinpin débi tí omi kankan kò ti lè wọ̀ ọ́. Nígbà àkọ́kọ́ tó máa rìn lórí òkun ní ọdún 1912, nǹkan bí ìdajì péré ló kó lára iye ọkọ̀ tí wọ́n fi ń gbẹ̀mí là tó nílò. Ẹnu ìrìn àjò yìí ni ọkọ̀ òkun náà wà tó ti kọlu òkìtì yìnyín, bó ṣe rì nìyẹn, ẹ̀mí tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] sì ṣègbè sínú rẹ̀.
Ọ̀GÁGUN tí orí rẹ̀ pé ní Ùsáyà Ọba tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run ní Jerúsálẹ́mù ìgbàanì. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ó ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀ láìkẹyọkan. “Nítorí náà, òkìkí [Ùsáyà] kàn dé ọ̀nà jíjìnréré, nítorí a ràn án lọ́wọ́ lọ́nà àgbàyanu títí ó fi di alágbára.” Àmọ́, “ọkàn-àyà rẹ̀ di onírera . . . tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣe àìṣòótọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.” Nítorí ìgbéraga Ùsáyà, a fi ẹ̀tẹ̀ kọlù ú.—2 Kíróníkà 26:15-21; Òwe 16:18.
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ méjèèjì yìí kọ́ wa pé àwọn ànímọ́ rere táa ní, tí a ò bá fi ọgbọ́n lò ó, tí a ò sì ṣe nǹkan níwọ̀ntúnwọ̀nsì, táà tún lọ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀, kíá ló máa di àbùkù wa tàbí kó di wàhálà sí wa lọ́rùn. Èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ eré rárá, nítorí pé lọ́nà kan tàbí òmíràn, gbogbo wa la ní àwọn ànímọ́ kan tó dára tàbí àwọn ẹ̀bùn kan, a sì fẹ́ kí èyí ṣe wá láǹfààní, kó jẹ́ orísun ayọ̀ fún àwa alára àti àwọn ẹlòmíràn, ní pàtàkì fún Ẹlẹ́dàá wa. Láìsí àní-àní, ó yẹ ká lo ẹ̀bùn èyíkéyìí tí Ọlọ́run bá fún wa dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, àmọ́, lọ́wọ́ kan náà, ká lò ó kó bàa lè jẹ́ ohun tó lè mú àǹfààní wá.
Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ rẹ̀ gan-an lè di ẹni tí ẹ̀bùn yìí di àbùkù rẹ̀ nípa sísọ ara rẹ̀ dí oníṣẹ́ àṣekúdórógbó. Ó lè má rọrùn láti tan ẹnì kan tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n jẹ, àmọ́, ọgbọ́n yìí lè wá di ọgbọ́n àgbọ́njù débi tí kò fi ni le ṣe ìpinnu. Ànímọ́ kan tó dára ni jíjáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ ẹni jẹ́, ṣùgbọ́n tó bá tún ti pọ̀ jù débi pé onítọ̀hún kò ní ẹ̀mí ìgbatẹnirò mọ́, ó lè sọ ibi iṣẹ́ náà di ibi táwọn èèyàn kì í ti í túra ká, tí wọ́n ti ń fọwọ́ tó le koko mú nǹkan, tí ayọ̀ ò ní sí níbẹ̀. Nítorí náà, lo àkókò díẹ̀ láti ronú lórí àwọn ànímọ́ rere tóo ní. Ṣé o ń lò wọ́n dáadáa? Ṣé àwọn ẹlòmíràn ń jàǹfààní nínú rẹ̀? Lékè gbogbo rẹ̀, ǹjẹ́ o ń lò wọ́n láti bọlá fún Jèhófà, Orísun “gbogbo ẹ̀bùn rere”? (Jákọ́bù 1:17) Láti ṣe èyí, ẹ jẹ́ kí a fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àpẹẹrẹ àwọn ànímọ́ rere mìíràn tó lè di àbùkù ẹni, àní tó tiẹ̀ lè kó wàhálà bólúwa ẹ̀ pàápàá, tí ò bá wá nǹkan ṣe sí i.
Fi Ọgbọ́n Lo Ọpọlọ Tóo Ní
Ó dájú pé ohun iyebíye ni ọpọlọ tó jí pépé jẹ́. Síbẹ̀, ó lè sọni di alábùkù tó bá di pé a lọ dára wa lójú jù, tàbí táa wá lẹ́mi èmi-ni-mo-tó-báyìí, pàápàá jù lọ nígbà táwọn mìíràn bá ń yìn wá tàbí tí wọ́n bá ń pọ́n wa lápọ̀n-ọ́n jù. A sì tún lè di ẹni tó ń fojú táa fi ń wo ìwé ayé wo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a gbé karí Bíbélì.
Onírúurú ọ̀nà ni dídára ẹni lójú jù ti lè yọjú. Fún àpẹẹrẹ, nígbà táa bá fún ẹnì kan tí ọpọlọ rẹ̀ jí pépé níṣẹ́ nínú ìjọ Kristẹni, ó lè jẹ́ àsọyé tàbí ọ̀rọ̀ kan ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè dúró dìgbà tí gbogbo ọjọ́ bá lọ tán kó tó wá bẹ̀rẹ̀ sí í múra iṣẹ́ táa fún un, ó tiẹ̀ lè má gbàdúrà fún ìbùkún Jèhófà pàápàá. Kó jẹ́ pé ìmọ̀ àti agbára tó ní láti dá ronú fúnra rẹ̀ ló gbẹ́kẹ̀ lé. Ẹ̀bùn tó ní yìí lè máà jẹ́ kí ẹ̀mí àìka-nǹkan-sí tó ní tètè hàn sáráyé, àmọ́, láìsí ìbùkún Jèhófà, yóò di ẹni tí ìdàgbàsókè rẹ̀ nípa tẹ̀mí ń dín kù tàbí kó má tiẹ̀ kúrò lójú kan pàápàá. Fífi ẹ̀bùn tó dára ṣòfò gbáà lèyí!—Òwe 3:5, 6; Jákọ́bù 3:1.
Ẹnì kan tó jẹ́ ọlọ́pọlọ pípé lè máa fojú táa fi ń wo àwọn ìwé ayé wo Bíbélì àti àwọn ìwé mìíràn tí a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bó ti wù kó rí, irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ kàn máa ń “wú fùkẹ̀” ni tàbí kó gbéni gẹṣin aáyán lásán; kì í ‘gbé’ àjọṣepọ̀ onífẹ̀ẹ́ ti Kristẹni ‘ró.’ (1 Kọ́ríńtì 8:1; Gálátíà 5:26) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, bó ti wù kí ọkùnrin tẹ̀mí ní ọpọlọ tó, kò lè ṣe kó má gbàdúrà fún ẹ̀mí Ọlọ́run, ó sì máa ń gbọ́kàn lé e. Ànímọ́ rere tó ní yóò túbọ̀ di ohun tó ń mú àǹfààní wá, bó ṣe ń dàgbà nínú ìfẹ́, ìrẹ̀lẹ̀, ìmọ̀, àti ọgbọ́n—gbogbo rẹ̀ yóò sì wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì.—Kólósè 1:9, 10.
Ànímọ́ rere táa ní lè wá di àbùkù wa, bó bá lọ jẹ́ pé ó ti mú ká bẹ̀rẹ̀ sí ní èrò èmi-ló-tó-báyìí, tí èyí yóò sì fi hàn pé a kò lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Ẹni tó ní ẹ̀bùn rere—àtẹni tó ń pọ́n ọn lé jù bó ti yẹ lọ—le gbàgbé pé Jèhófà “kò ka àwọn ènìyàn èyíkéyìí tí ó gbọ́n ní ọkàn-àyà ara wọn sí,” bó ti wù kí ẹ̀bùn wọn pọ̀ tó. (Jóòbù 37:24) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.” (Òwe 11:2) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọpọlọ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ, tó sì tún jẹ́ ọ̀mọ̀wé, síbẹ̀ ó sọ fún àwọn ara Kọ́ríńtì pé: “Nígbà tí mo wá sí ọ̀dọ̀ yín, ẹ̀yin ará, èmi kò wá pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àsọrégèé tàbí ọgbọ́n . . . Mo wá sí ọ̀dọ̀ yín nínú àìlera àti nínú ìbẹ̀rù àti pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìwárìrì; àti ọ̀rọ̀ mi àti ohun tí mo ń wàásù kì í ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tí ń yíni lérò padà bí kò ṣe pẹ̀lú ìfihàn ẹ̀mí àti agbára, kí ìgbàgbọ́ yín má bàa wà nínú ọgbọ́n ènìyàn, bí kò ṣe nínú agbára Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 2:1-5.
Bí ẹnì kan bá jẹ́ onílàákàyè lóòótọ́, yóò ṣòro láti fi ojú ìwòye aráyé nípa ọgbọ́n orí tàn án jẹ́, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò ní lè fi èrò wọn nípa ohun tí àṣeyọrí jẹ́ tàn án jẹ. Nítorí náà, dípò tí ì bá fi máa lo ẹ̀bùn rẹ̀ láti wá ojú rere àwọn ènìyàn tàbí láti kó ọrọ̀ jọ fún ara rẹ̀, ṣe ni yóò kúkú máa ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe láti mú inú Ẹni tó fún un ní ẹ̀mí àti ẹ̀bùn náà dùn. (1 Jòhánù 2:15-17) Nípa bẹ́ẹ̀, yóò máa fi ire Ìjọba sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé rẹ̀, yóò wá dà bí “igi tí a gbìn sẹ́bàá àwọn ìṣàn omi,” tí ń mú èso jáde. Jèhófà ni yóò máa fìyìn fún nítorí àwọn ẹ̀bùn tó fi jíǹkí rẹ̀, kò ní máa fi àwọn ẹ̀bùn tó ní ṣe fọ́ńté, “gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.”—Sáàmù 1:1-3; Mátíù 6:33.
Jẹ́ Kí Ìsìn Kristẹni Fi Kún Ànímọ́ Rere Tóo Ní
Lọ́nà táa gbà gbé e kalẹ̀, ìsìn Kristẹni kún fún ànímọ́ tó dára tó jẹ́ pé ọgbọ́n ayé kò já mọ́ nǹkankan lára rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀nà ìgbésí ayé Kristẹni ló ń sọni di tọkọtaya tó dára jù lọ, ó sì tún ń sọni di aládùúgbò àti òṣìṣẹ́ tó dára ju lọ—ìyẹn àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, tí wọ́n ń bọ̀wọ̀ fúnni, tí wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà, àti aláápọn. (Kólósè 3:18-23) Ní àfikún sí i, ìdálẹ́kọ̀ọ́ Kristẹni nínú ọ̀rọ̀ sísọ àti ẹ̀kọ́ kíkọ́ ń ranni lọ́wọ́ láti mọ báa ti ń báni sọ̀rọ̀ lọ́nà tó dán mọ́rán. (1 Tímótì 4:13-15) Abájọ táwọn tó jẹ́ ọ̀gá lẹ́nu iṣẹ́ fún àwọn Kristẹni fi sábà máa ń fẹ́ láti túbọ̀ fún wọn ní ẹrù iṣẹ́ sí i, tí wọ́n sì máa ń gbé wọn ga lẹ́nu iṣẹ́. Àmọ́, a tún lè ṣi irú ànímọ́ rere bẹ́ẹ̀ lò tí a kò bá ṣọ́ra. Ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́ tàbí nídìí iṣẹ́ kan tó fani mọ́ra lè túmọ̀ sí fífi ara ẹni jìn fún ilé iṣẹ́ náà pátápátá, kí a wá sọ pípa ìpàdé jẹ dàṣà, tàbí ká wá bẹ̀rẹ̀ sí lo àkókò tó yẹ ká lò pẹ̀lú ìdílé ẹni fún iṣẹ́.
Ní Ọsirélíà, Kristẹni alàgbà kan tó tún ní ìdílé jẹ́ oníṣòwò tó ti rọ́wọ́ mú, tó sì tún “láǹfààní àtilówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀,” báwọn èèyàn ṣe máa ń sọ ọ́. Síbẹ̀ ó kọ̀ láti di ọlọ́rọ̀ nínú ètò nǹkan ìsinsìnyí. Ó sọ pé: “Mó túbọ̀ fẹ́ lo àkókò tó pọ̀ sí i pẹ̀lú ìdílé mí àti nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Nítorí náà, èmi àti ìyàwó mi fohùn ṣọ̀kan pé kí n dín díẹ̀ kù lára àkókò tí mò ń lò lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́.” Ó tún fi kún un pé: “Èé ṣe ti mo fi ní láti fi ọjọ́ márùn-ún ṣiṣẹ́ láàárín ọ̀sẹ̀ tí kì í bá ṣe pé ó pọndandan fún mi láti ṣe bẹ́ẹ̀?” Nípa ṣíṣe àtúnṣe tó ronú jinlẹ̀ lé lórí yìí nínú ìgbésí ayé rẹ̀, alàgbà yìí rí i pé òun ṣì lè gbọ́ bùkátà ìdílé òun nípa ṣíṣe iṣẹ́ ọjọ́ mẹ́ta sí mẹ́rin péré láàárín ọ̀sẹ̀. Nígbà tó yá, wọ́n pè é láti nípìn-ín nínú àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn mìíràn, bíi sísìn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Gbọ̀ngàn Àpéjọ, ó sì tún wà lára ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó àpéjọpọ̀. Bó ṣe fi ọgbọ́n lo ànímọ́ rẹ̀ yìí fún òun àti ìdílé rẹ̀ ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn.
Níní Ẹ̀mí Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì Nípa Àwọn Àǹfààní
A gba àwọn Kristẹni ọkùnrin níyànjú láti nàgà fún àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ. “Bí ọkùnrin èyíkéyìí bá ń nàgà fún ipò iṣẹ́ alábòójútó, iṣẹ́ àtàtà ni ó ń fẹ́.” (1 Tímótì 3:1) Gẹ́gẹ́ bó ti yẹ ká lo ànímọ́ rere táa ní ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, bẹ́ẹ̀ náà la ṣe gbọ́dọ̀ jẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì nígbà táa bá ń tẹ́wọ́ gba ẹrù iṣẹ́. Kì í ṣe pé kí ẹnì kan wá gba ẹrù iṣẹ́ tó pọ̀ sọ́wọ́ débi tí kò ní láyọ̀ mọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Dájúdájú, a gbóríyìn fún ẹ̀mí tó múra tán láti ṣiṣẹ́, ó sì ṣe pàtàkì pé ká ní irú ẹ̀mí yìí, nítorí pé Jèhófà kórìíra ẹ̀mí ìmẹ́lẹ́; ṣùgbọ́n ẹ̀mí ìmúratán tún gbọ́dọ̀ fi ẹ̀mí ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti “ìyèkooro èrò inú” hàn.—Títù 2:12; Ìṣípayá 3:15, 16.
Ìwà tútù, ìjìnlẹ̀ òye, àti ẹ̀mí ìbìkítà tí Jésù ní ló mú kí ara àwọn táwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ kà sí láwùjọ pàápàá balẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀. Bákan náà ni lónìí, ara àwọn ènìyàn máa ń balẹ̀ nígbà tí wọ́n bá wà lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n jẹ́ aláàánú, tí wọ́n sì lẹ́mìí ìgbatẹnirò. Nínú ìjọ Kristẹni, irú àwọn alàgbà bẹ́ẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọlọ́yàyà, tí wọ́n sì ṣeé sún mọ́ bẹ́ẹ̀ la kà sí “àwọn ẹ̀bùn [tí ó jẹ́] ènìyàn.” Wọ́n jẹ́ “ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù àti ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò, bí àwọn ìṣàn omi ní ilẹ̀ aláìlómi, bí òjìji àpáta gàǹgà ní ilẹ̀ gbígbẹ táútáú.”—Éfésù 4:8; Aísáyà 32:2.
Àmọ́, àwọn alàgbà kò ní wá jẹ́ kí àkókò tí wọ́n fi ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ wá pọ̀ ju èyí tí wọn yóò lò fún ìdákẹ́kọ̀ọ́, ṣíṣe àṣàrò, gbígba àdúrà, àti lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìta gbangba. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá, ó tún yẹ kí àwọn alàgbà tó ti láya sílé máa lo àkókò pẹ̀lú ìdílé wọn, ó sì yẹ kí wọ́n mú kó rọrùn fáwọn mẹ́ńbà ìdílé wọn láti lè bá wọn sọ̀rọ̀.
Àwọn Obìnrin Tó Dáńgájíá —Àgbàyanu Ìbùkún Ni Wọ́n
Bíi ti àwọn alàgbà tó dáńgájíá, ohun iyebíye ni àwọn obìnrin tí nǹkan tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn jẹ́ nínú ètò Jèhófà pẹ̀lú. Ní gbogbo gbòò, àwọn obìnrin ní ẹ̀bùn láti ní ìfẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn—èyí jẹ́ ànímọ́ kan tí Jèhófà fojú ribiribi wò, tó sì fẹ́ ká ní. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.” (Fílípì 2:4) Síbẹ̀, “ire ara ẹni” yìí níwọ̀n, nítorí pé kò sí Kristẹni kan tí yóò fẹ́ jẹ́ “olùyọjúràn sí ọ̀ràn àwọn ẹlòmíràn”; bẹ́ẹ̀ ni kò sí èyí tí yóò fẹ́ jẹ́ olófòófó.—1 Pétérù 4:15; 1 Tímótì 5:13.
Àwọn obìnrin tún ní ọ̀pọ̀ ẹ̀bùn mìíràn. Fún àpẹẹrẹ, Kristẹni kan tó jẹ́ ìyàwó ilé lè ní ọpọlọ pípé ju ọkọ̀ rẹ̀ lọ. Síbẹ̀síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí “aya tí ó dáńgájíá” tí ó bẹ̀rù Jèhófà, yóò máa bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀, yóò sì máa lo àwọn ẹ̀bùn tó ní láti jẹ́ àṣekún fún un, kò ní lò ó láti figa gbága pẹ̀lú rẹ̀. Kàkà tí ọkọ tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tó sì jẹ́ ọlọgbọ́n yóò fi máa ṣe ìlara tàbí kó bẹ̀rẹ̀ sí nínú burúkú sí i, ńṣe ni yóò máa fojú ribiriri wo àwọn ànímọ́ rere tí aya rẹ̀ ní, tí yóò sì máa dunnú sí wọn. Yóò máa fún un níṣìírí láti lo àwọn ẹ̀bùn rẹ̀ dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ láti gbé ìdílé rẹ̀ ró, kí ó sì ran àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ láti ‘bẹ̀rù Jèhófà,’ bí òun fúnra rẹ̀ tó jẹ́ aya ti ń ṣe. (Òwe 31:10, 28-30; Jẹ́nẹ́sísì 2:18) Irú àwọn ọkọ àti aya onírẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń kẹ́sẹ járí nínú ìgbéyàwó tó bọlá fún Jèhófà.
Ṣíṣàkóso Ẹ̀bùn Mímọ̀rọ̀ọ́sọ
Ẹ̀bùn mímọ̀rọ̀ọ́sọ tó dá lórí òdodo àti ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà tọkàntọkàn lè di ohun iyebíye bí a bá fi ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ṣàkóso rẹ̀. Síbẹ̀, ó tún lè di àbùkù tó bá mú kí ẹnì kan fẹ́ máa jẹ gàba lé àwọn mìíràn lórí tàbí kó máa fipá mú wọn ṣe ohun tí wọn kò fẹ́ ṣe. Èyí ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni. Ńṣe ló yẹ kí ọkàn àwọn Kristẹni balẹ̀ tí wọ́n bá wà láàárín ara wọn, títí kan ìgbà tí wọ́n bá wà láàárín àwọn alàgbà ìjọ.—Mátíù 20:25-27.
Bákan náà ló ṣe yẹ kí ọkàn àwọn alàgbà máà balẹ̀ nígbà tí wọ́n bá wà láàárín ara wọn. Nígbà tí wọ́n bá sì pàdé pọ̀, ẹ̀mí mímọ́ ló yẹ kó máà darí àwọn ìpinnu tí wọ́n bá ṣe kì í ṣe ẹ̀mí èmi-n-mo-wà-ńbẹ̀. Láìsí àní-àní, ẹ̀mí mímọ́ lè darí alàgbà èyíkéyìí nínú ẹgbẹ́ àwọn alàgbà, títí kan èyí tó kéré jù lọ láàárín wọn tàbí èyí tí kò fi bẹ́ẹ̀ lágbaja ọ̀rọ̀ sísọ. Nítorí náà, bí àwọn tó lẹ́bùn mímọ̀rọ̀ọ́sọ bá tilẹ̀ ri pé ọ̀rọ̀ àwọn ló tọ̀nà jù lọ, wọ́n gbọ́dọ̀ fọgbọ́n lo ànímọ́ wọn nípa kíkọ́ bí a ti ń fara mọ́ èrò tó yàtọ̀ sí tẹni, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ máa “bu ọlá” fún àwọn ẹlòmíràn. (Róòmù 12:10) Oníwàásù 7:16 kìlọ̀ pé: “Má di olódodo àṣelékè, tàbí kí o fi ara rẹ hàn ní ẹni tí ó gbọ́n ní àgbọ́njù. Èé ṣe tí ìwọ yóò fi fa ìsọdahoro wá bá ara rẹ?”
Jèhófà tó jẹ́ Orísun “gbogbo ẹ̀bùn rere,” ń lo àwọn ànímọ́ rẹ̀ tó gadabú lọ́nà pípé jù lọ. (Jákọ́bù 1:17; Diutarónómì 32:4) Òun sì ni Olùkọ́ wa o! Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a kẹ́kọ̀ọ́ lára rẹ̀, kí a sì sapá gidigidi láti rí i pé a mú ẹ̀bùn, tàbí ànímọ́ táa ní dàgbà, kí a sì máa fi ọgbọ́n, ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, àti ìfẹ́ lò wọ́n. Báa bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ wo bí a ó ṣe jẹ́ ìbùkún ńlá fáwọn ẹlòmíràn tó!
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Ìlọsíwájú nípa tẹ̀mí sinmi lórí fífi tàdúràtàdúrà kẹ́kọ̀ọ́ àti gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Jíjẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú fífi ìfẹ́ hàn nínú ọ̀ràn àwọn ẹlòmíràn jẹ́ ìbùkún kan
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure ti The Mariners’ Museum, Newport News, VA