ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 10/15 ojú ìwé 20-24
  • Jíjẹ́ Bàbá àti Alàgbà—Ṣíṣe Ojúṣe Méjèèjì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jíjẹ́ Bàbá àti Alàgbà—Ṣíṣe Ojúṣe Méjèèjì
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jíjẹ́ Bàbá àti Alàgbà
  • “Tí Ó Ní Àwọn Ọmọ Tí Wọ́n Gbà Gbọ́”
  • Tí Ó Bá Ní “Aya Tí Kò Gbà Gbọ́”
  • ‘Tí Ń Ṣe Àbójútó Agbo Ilé Rẹ̀ Lọ́nà Tí Ó Dára Lọ́pọ̀lọpọ̀’
  • Àbójútó Wíwà Déédéé
  • Àwọn Bàbá Rere Tí Wọ́n Tún Jẹ́ Alàgbà Rere
  • Ó Yẹ Kí Àwọn Alàgbà Wa Jẹ́ Ẹni Ọ̀wọ́n fún Wa
  • Jíjẹ́ Ọkọ àti Alàgbà—Mímú Kí Àwọn Ẹrù Iṣẹ́ náà Wà Déédéé
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ẹ Fi Imuratan Bojuto Agbo Ọlọrun
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àwọn Alábòójútó Tó Ń Ṣe Olùṣọ́ Àgùntàn Agbo
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • “Ẹ Ní Ẹ̀mí Ìkanisí Fún Àwọn Tí Ń Ṣiṣẹ́ Kára Láàárín Yín”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 10/15 ojú ìwé 20-24

Jíjẹ́ Bàbá àti Alàgbà—Ṣíṣe Ojúṣe Méjèèjì

“Ní tòótọ́ bí ọkùnrin èyíkéyìí kò bá mọ agbo ilé ara rẹ̀ bójú tó, báwo ni òun yóò ṣe bójú tó ìjọ Ọlọ́run?”—TÍMÓTÌ KÌÍNÍ 3:5.

1, 2. (a) Ní ọ̀rúndún kìíní, báwo ni ó ṣe ṣeé ṣe fún àwọn àpọ́n alábòójútó àti àwọn alábòójútó tí wọ́n ti gbéyàwó láìlọ́mọ láti ṣiṣẹ́ sin àwọn arákùnrin wọn? (b) Báwo ni Ákúílà àti Pírísílà ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ kan fún àwọn tọkọtaya tí wọ́n ti gbéyàwó lónìí?

ÀWỌN alábòójútó ní ìjọ Kristẹni ìjímìjí lè jẹ́ àpọ́nkùnrin tàbí àwọn ọkùnrin tí wọ́n gbéyàwó ṣùgbọ́n tí wọn kò bímọ, tàbí kí wọ́n jẹ́ ọkùnrin onídìílé tí ó ní àwọn ọmọ. Kò sí iyè méjì pé, ó ṣeé ṣe fún àwọn kan lára àwọn Kristẹni wọ̀nyẹn láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fúnni nínú lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sí àwọn ará Kọ́ríńtì, orí 7, ní wíwà lápọ̀n-ọ́n. Jésù ti wí pé: “Àwọn ìwẹ̀fà . . . wà tí wọ́n ti sọ ara wọn di ìwẹ̀fà ní tìtorí ìjọba àwọn ọ̀run.” (Mátíù 19:12) Irú àwọn àpọ́nkùnrin bẹ́ẹ̀, bíi Pọ́ọ̀lù àti bóyá àwọn kan nínú àwọn arìnrìn àjò ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, yóò lómìnira láti rin ìrìn àjò láti ran àwọn arákùnrin wọn lọ́wọ́.

2 Bíbélì kò sọ bóyá Bánábà, Máàkù, Sílà, Lúùkù, Tímótì, àti Títù jẹ́ àpọ́nkùnrin. Bí wọ́n bá gbéyàwó, ó hàn gbangba pé wọ́n lómìnira tí ó tó, kúrò lọ́wọ́ ẹrù iṣẹ́ ìdílé láti lè rin ìrìn àjò gbígbòòrò lọ sí onírúurú iṣẹ́ àyànfúnni. (Ìṣe 13:2; 15:39-41; Kọ́ríńtì Kejì 8:16, 17; Tímótì Kejì 4:9-11; Títù 1:5) Àwọn aya wọn ti lè bá wọn lọ, bíi Pétérù àti “àwọn àpọ́sítélì yòó kù,” tí ó hàn gbangba pé wọ́n mú aya wọn lọ́wọ́ bí wọ́n ṣe ń lọ láti ibì kan sí ibì kejì. (Kọ́ríńtì Kìíní 9:5) Ákúílà àti Pírísílà jẹ́ àpẹẹrẹ tọkọtaya tí wọ́n múra tán láti ṣí kiri, ní títẹ̀ lé Pọ́ọ̀lù láti Kọ́ríńtì lọ sí Éfésù, lẹ́yìn náà wọ́n lọ sí Róòmù, wọ́n sì tún padà sí Éfésù. Bíbélì kò sọ bóyá wọ́n ní ọmọ kankan. Ìṣẹ́ ìsìn tí wọ́n fara jìn pátápátá fún àwọn arákùnrin wọn jẹ́ kí wọ́n rí ìmoore “gbogbo ìjọ àwọn orílẹ̀-èdè” gbà. (Róòmù 16:3-5; Ìṣe 18:2, 18; Tímótì Kejì 4:19) Lónìí, kò sí iyè méjì pé àwọn tọkọtaya bí Ákúílà àti Pírísílà ń bẹ, tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ sin àwọn ìjọ mìíràn, bóyá nípa ṣíṣí lọ sí ibi tí àìní ti gbé pọ̀.

Jíjẹ́ Bàbá àti Alàgbà

3. Kí ni ó fi hàn pé ọ̀pọ̀ alàgbà ní ọ̀rúndún kìíní jẹ́ àwọn ọkùnrin tí ó gbéyàwó, tí wọ́n sì ní ìdílé?

3 Ó dà bíi pé ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Kristẹni alàgbà jẹ́ àwọn ọkùnrin tí wọ́n gbéyàwó, tí wọ́n sì bímọ. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù la ohun àbéèrèfún lọ́wọ́ ọkùnrin kan tí “ń nàgà fún ipò iṣẹ́ alábòójútó” sílẹ̀, ó wí pé irú Kristẹni bẹ́ẹ̀ ní láti jẹ́ “ọkùnrin kan tí ń ṣe àbójútó agbo ilé ara rẹ̀ lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, tí ó ní àwọn ọmọ ní ìtẹríba pẹ̀lú gbogbo ìwà àgbà.”—Tímótì Kìíní 3:1, 4.

4. Kí ni a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn alàgbà tí wọ́n ti gbéyàwó, tí wọ́n sì ní ọmọ?

4 Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i, kò pọn dandan fún alábòójútó kan láti ní ọmọ, tàbí láti gbéyàwó pàápàá. Ṣùgbọ́n bí ó bá gbéyàwó, kí ó tó lè tóótun gẹ́gẹ́ bí alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, Kristẹni kan ní láti lo ipò orí lórí aya rẹ̀ lọ́nà yíyẹ àti lọ́nà tí ó fi ìfẹ́ hàn, kí ó sì fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó dáńgájíá láti mú kí àwọn ọmọ rẹ̀ wà ní ìtẹríba tí ó yẹ. (Kọ́ríńtì Kìíní 11:3; Tímótì Kìíní 3:12, 13) Ìmẹ́hẹ èyíkéyìí lọ́nà tí ó wúwo, nínú bíbójú tó agbo ilé rẹ̀, yóò sọ arákùnrin kan di aláìtóótun fún àwọn àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ nínú ìjọ. Èé ṣe? Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Ní tòótọ́ bí ọkùnrin èyíkéyìí kò bá mọ agbo ilé ara rẹ̀ bójú tó, báwo ni òun yóò ṣe bójú tó ìjọ Ọlọ́run?” (Tímótì Kìíní 3:5) Bí àwọn tí ó jẹ́ ẹran ara rẹ̀ kò bá múra tán láti tẹrí ba fún àbójútó rẹ̀, báwo ni àwọn mìíràn yóò ṣe hùwà padà?

“Tí Ó Ní Àwọn Ọmọ Tí Wọ́n Gbà Gbọ́”

5, 6. (a) Kí ni ohun àbéèrèfún, ní ti ọmọ, tí Pọ́ọ̀lù sọ fún Títù? (b) Kí ni à ń retí láti ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà tí wọ́n ní ọmọ?

5 Nígbà tí ó ń fún Títù nítọ̀ọ́ni láti yan àwọn alábòójútó sípò nínú ìjọ àwọn ará Kírétè, Pọ́ọ̀lù gbé ohun àbéèrèfún náà kalẹ̀ pé: “Bí ọkùnrin èyíkéyìí bá wà láìní ẹ̀sùn lọ́rùn, ọkọ aya kan, tí ó ní àwọn ọmọ tí wọ́n gbà gbọ́ tí wọn kò sí lábẹ́ ọ̀ràn ẹ̀sùn ìwà wọ̀bìà tàbí ya ewèlè. Nítorí alábòójútó gbọ́dọ̀ wà láìní ẹ̀sùn lọ́rùn gẹ́gẹ́ bí ìríjú Ọlọ́run.” Ṣùgbọ́n, kí tilẹ̀ ni ohun àbéèrèfún náà, “tí ó ní àwọn ọmọ tí wọ́n gbà gbọ́,” túmọ̀ sí?—Títù 1:6, 7.

6 Ọ̀rọ̀ náà, “àwọn ọmọ tí wọ́n gbà gbọ́,” ń tọ́ka sí àwọn ògo wẹẹrẹ tí wọ́n ti ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ sí Jèhófà, tí a sì ti batisí, tàbí sí àwọn èwe tí wọ́n ń tẹ̀ síwájú síhà ṣíṣe ìyàsímímọ́ àti batisí. Àwọn mẹ́ḿbà ìjọ ń retí pé kí ọmọ àwọn alàgbà jẹ́ ọmọlúwàbí àti onígbọràn. Ó yẹ kí ó hàn gbangba pé alàgbà kan ń ṣe gbogbo ohun tí ó lè ṣe láti gbé ìgbàgbọ́ ró nínú àwọn ọmọ rẹ̀. Ọba Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀: nígbà tí ó sì dàgbà tán, kì yóò kúrò nínú rẹ̀.” (Òwe 22:6) Ṣùgbọ́n bí ọ̀dọ́ kan tí ó ti gba irú ìdálẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ bá kọ̀ láti ṣiṣẹ́ sin Jèhófà ńkọ́, tàbí tí ó tilẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ búburú jáì?

7. (a) Èé ṣe tí ó fi hàn kedere pé Òwe 22:6 kò fi ìlànà tí kò ṣeé tẹ̀ síhìn-ín sọ́hùn-ún hàn? (b) Bí ọmọ alàgbà kan kò bá yàn láti ṣiṣẹ́ sin Jèhófà, èé ṣe tí alàgbà náà kò fi lè pàdánù àǹfààní rẹ̀ lójú ẹsẹ̀?

7 Ó ṣe kedere pé, òwe tí a ṣàyọlò rẹ̀ lókè yìí kò gbé ìlànà tí kò lè yí padà kalẹ̀. Kò fagi lé ìlànà òmìnira ìfẹ́ inú. (Diutarónómì 30:15, 16, 19) Nígbà tí ọmọkùnrin kan tàbí ọmọbìnrin kan bá dàgbà tó ẹni tí ó lé jíhìn fún ìgbésẹ̀ rẹ̀, ó gbọ́dọ̀ ṣe ìpinnu ti ara rẹ̀ ní ti ìyàsímímọ́ àti batisí. Bí alàgbà kan bá ti fún un ní ìrànlọ́wọ́, ìtọ́sọ́nà, àti ìbáwí nípa tẹ̀mí tí ó nílò, síbẹ̀ tí ọ̀dọ́ náà kò yàn láti ṣiṣẹ́ sin Jèhófà, ìyẹn kò sọ bàbá náà di aláìtóótun lójú ẹsẹ̀ láti ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, bí alàgbà kan bá ní ọ̀pọ̀ ọmọ aláìtójúúbọ́ tí ń gbé pẹ̀lú rẹ̀, tí wọ́n ń di aláìsàn nípa tẹ̀mí, tí wọ́n sì ń kó sínú ìṣòro lọ́kọ̀ọ̀kan, a lè má kà á sí “ọkùnrin kan tí ń ṣe àbójútó agbo ilé ara rẹ̀ lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀” mọ́. (Tímótì Kìíní 3:4) Kókó náà ni pé, ó ní láti hàn gbangba pé alábòójútó kan ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti ní “àwọn ọmọ tí wọ́n gbà gbọ́ tí wọn kò sí lábẹ́ ọ̀ràn ẹ̀sùn ìwà wọ̀bìà tàbí ya ewèlè.”a

Tí Ó Bá Ní “Aya Tí Kò Gbà Gbọ́”

8. Báwo ni alàgbà kan ṣe lè hùwà sí aya rẹ̀ tí kò gbà gbọ́?

8 Ní ti àwọn Kristẹni ọkùnrin tí wọ́n bá ní aya tí kò gbà gbọ́, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí arákùnrin èyíkéyìí bá ní aya tí kò gbà gbọ́, síbẹ̀ tí obìnrin náà sì fara mọ́ bíbá a gbé, kí òun má ṣe fi obìnrin náà sílẹ̀. . . . Nítorí . . . aya tí kò sì gbà gbọ́ ni a sọ di mímọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú arákùnrin náà; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwọn ọmọ yín ì bá jẹ́ aláìmọ́ ní ti gidi, ṣùgbọ́n nísinsìnyí wọ́n jẹ́ mímọ́. Nítorí, . . . ọkọ, báwo ni o ṣe mọ̀ bóyá ìwọ yóò gba aya rẹ là?” (Kọ́ríńtì Kìíní 7:12-14, 16) Ọ̀rọ̀ náà “tí kò gbà gbọ́” níhìn-ín kò tọ́ka sí aya tí kò ní ìgbàgbọ́ kankan ní ti ìsìn, ṣùgbọ́n ó ń tọ́ka sì ẹnì kan tí kò ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. Ó ti lè jẹ́ onísìn Júù, tàbí onígbàgbọ́ nínú àwọn ọlọ́run kèfèrí. Lónìí, alàgbà kan ti lè ní aya kan tí ń ṣe ìsìn tí ó yàtọ̀, tí ó jẹ́ onígbàgbọ́-Ọlọ́run-kò-ṣeé-mọ̀, tàbí kí ó tilẹ̀ jẹ́ aláìgbọlọ́rungbọ́ pàápàá. Bí ó bá ń fẹ́ láti máa gbé pẹ̀lú ọkùnrin náà, kò ní láti fi í sílẹ̀ kìkì nítorí pé ìgbàgbọ́ wọn yàtọ̀. Kí òun ṣì ‘máa bá a lọ ní bíbá a gbé ní irú ọ̀nà kan náà ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀, kí ó máa fi ọlá fún un gẹ́gẹ́ bí fún ohun ìlò aláìlerató, ọ̀kan tí ó jẹ́ abo,’ ní bíbá a gbé pẹ̀lú ìrètí gbígbà á là.—Pétérù Kìíní 3:7; Kólósè 3:19.

9. Ní àwọn ilẹ̀ tí òfin ti fún ọkọ àti aya ní ẹ̀tọ́ láti fojú àwọn ọmọ wọn mọ ìgbàgbọ́ ìsìn àwọn méjèèjì, báwo ni ó ṣe yẹ kí alàgbà kan hùwà, báwo sì ni èyí yóò ṣe nípa lórí àǹfààní rẹ̀?

9 Bí alábòójútó kan bá ní àwọn ọmọ, yóò lo ipò ọkọ àti ipò orí gẹ́gẹ́ bí bàbá lọ́nà yíyẹ ní títọ́ wọn dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, òfin yọ̀ọ̀da fún àwọn méjèèjì tí wọ́n jẹ́ alábàáṣègbéyàwó láti pèsè ìtọ́ni ní ti ìsìn fún àwọn ọmọ wọn. Nínú ọ̀ràn yìí, aya náà lè fi dandan béèrè fún lílo ẹ̀tọ́ rẹ̀ láti fojú àwọn ọmọ mọ ìgbàgbọ́ àti àṣà ìsìn rẹ̀, èyí tí ó lè ní mímú wọn lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ nínú.b Àmọ́ ṣáá o, àwọn ọmọ ní láti tẹ̀ lé ẹ̀rí ọkàn wọn tí a ti fi Bíbélì kọ́ ní ti ṣíṣàìlọ́wọ́ nínú àwọn ayẹyẹ ìsìn èké. Gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé, bàbá náà yóò lo ẹ̀tọ́ tìrẹ láti kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, nígbà tí ó bà sì ṣeé ṣe yóò mú wọn lọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Nígbà tí wọ́n bá dàgbà dé ibi tí wọ́n ti lè ṣe ìpinnu tiwọn fúnra wọn, àwọn fúnra wọn yóò pinnu ọ̀nà tí wọn yóò tọ̀. (Jóṣúà 24:15) Bí àwọn alàgbà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ àti àwọn mẹ́ḿbà ìjọ bá rí i pé ó ń ṣe gbogbo ohun tí òfin yọ̀ọ̀da fún un láti ṣe ní fífún àwọn ọmọ rẹ̀ nítọ̀ọ́ni lọ́nà yíyẹ ní ọ̀nà òtítọ́, a kì yóò mú un kúrò ní ipò alábòójútó.

‘Tí Ń Ṣe Àbójútó Agbo Ilé Rẹ̀ Lọ́nà Tí Ó Dára Lọ́pọ̀lọpọ̀’

10. Bí ọkùnrin kan tí ó ní ìdílé bá jẹ́ alàgbà, kí ni ojúṣe rẹ̀ tí ó ṣe pàtàkì jù lọ?

10 Àní fún alàgbà kan tí ó jẹ́ bàbá, tí aya rẹ̀ sì jẹ́ Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, kò rọrùn láti pín àkókò àti àfiyèsí rẹ̀ láàárín aya rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀, àti àwọn ẹrù iṣẹ́ ìjọ lọ́nà yíyẹ. Ìwé Mímọ́ mú un ṣe kedere pé, Kristẹni kan tí ó jẹ́ bàbá ní iṣẹ́ ọ̀ranyàn kan, láti bójú tó aya rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Dájúdájú bí ẹnì kan kò bá pèsè fún àwọn wọnnì tí wọ̀n jẹ́ tirẹ̀, àti ní pàtàkì fún àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà agbo ilé rẹ̀, òún ti sẹ́ níní ìgbàgbọ́ ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.” (Tímótì Kìíní 5:8) Nínú lẹ́tà kan náà, Pọ́ọ̀lù sọ pé, kìkì àwọn ọkùnrin tí wọ́n ti gbéyàwó, tí wọ́n sì ti fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí ọkọ àti bàbá rere ni a lè dámọ̀ràn láti ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó.—Tímótì Kìíní 3:1-5.

11. (a) Ní àwọn ọ̀nà wo ni ó yẹ kí alàgbà kan gbà “pèsè fún àwọn wọnnì tí wọ̀n jẹ́ tirẹ̀”? (b) Báwo ni èyí ṣe lè ran alàgbà kan lọ́wọ́ láti bójú tó ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ nínú ìjọ?

11 Alàgbà kan ní láti “pèsè” fún àwọn tí wọ́n jẹ́ tirẹ̀, kì í ṣe nípa ti ara nìkan, ṣùgbọ́n nípa tẹ̀mí àti ti èrò ìmọ̀lára pẹ̀lú. Ọlọgbọ́n Ọba Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Múra iṣẹ́ rẹ sílẹ̀ lóde, kí o sì fi ìtara tulẹ̀ ní oko rẹ; níkẹyìn èyí, kí o sì kọ́ ilé rẹ.” (Òwe 24:27) Nítorí náà bí ó ti ń pèsè nípa ti ara, nípa ti èrò ìmọ̀lára, tí ó sì ń pèsè àìní aya àti àwọn ọmọ rẹ̀ ní ti eré ìnàjú, alábòójútó kan tún ní láti gbé wọn ró nípa tẹ̀mí. Èyí ń gba àkókò—àkókò tí òun kì yóò lè yà sọ́tọ̀ fún ọ̀ràn ìjọ. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ àkókò tí ó lè mú èrè ńlá wá ní ti ayọ̀ àti ipò tẹ̀mí ìdílé. Ní àbárèbábọ̀, bí ìdílé rẹ̀ bá di alágbára nípa tẹ̀mí, ó lè jẹ́ pé àkókò díẹ̀ ni alàgbà náà yóò máa lò láti yanjú àwọn ìṣòro ìdílé. Èyí yóò mú kí ọkàn rẹ̀ balẹ̀ láti bójú tó àwọn ọ̀ràn ìjọ. Àpẹẹrẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkọ rere àti bàbá rere yóò jẹ́ àǹfààní nípa tẹ̀mí fún ìjọ.—Pétérù Kìíní 5:1-3.

12. Nínú ọ̀ràn ìdílé wo ni ó yẹ kí àwọn bàbá tí wọ́n jẹ́ alàgbà fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀?

12 Ṣíṣe àbójútó lórí agbo ilé lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ ní wíwéwèé àkókò láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé nínú. Ó ṣe pàtàkì gidigidi pé kí àwọn alàgbà fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ ní ti èyí, nítorí pé ìdílé tí ó lágbára ni ó ń di ìjọ tí ó lágbára. Kò yẹ kí àwọn àǹfààní iṣẹ́ isìn míràn fìgbà gbogbo gba àkókò alábòójútó kan tó bẹ́ẹ̀ tí òun kì yóò fi ní àkókò láti kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú aya àti àwọn ọmọ rẹ̀. Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ó tún ìwéwèé rẹ̀ gbé yẹ̀ wò. Ó lè ní láti tún àkókò tí ó ń yà sọ́tọ̀ fún àwọn nǹkan mìíràn tò tàbí kí ó dín in kù, àní nígbà míràn, kí ó tilẹ̀ kọ àwọn àǹfààní kan pàtó sílẹ̀ pàápàá.

Àbójútó Wíwà Déédéé

13, 14. Ìmọ̀ràn wo ni “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú” fún àwọn alàgbà tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin tí ó ní ìdílé?

13 Ìmọ̀ràn mímú kí ẹrù iṣẹ́ ìdílé àti ti ìjọ wà déédéé kì í ṣe tuntun. Fún ọ̀pọ̀ ọdún “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú” ti ń fún àwọn alàgbà nímọ̀ràn lórí ọ̀ràn yìí. (Mátíù 24:45) Ní èyí tí ó lé ní ọdún 36 sẹ́yìn, Ile-Iṣọ Na ti September 1, 1960, ojú ìwé 265 rọni pé: “Nitotọ, njẹ eyi ko ha di ọran ki a diwọn akoko wa lati pin wọn dede pẹlu gbogbo ohun ti a bere lọdọ wa bayi? Ninu idiwọn yi ki [o fi] iwọn ti o yẹ ki o fifun ire awọn ara ile tirẹ [fún wọn]. Dajudaju Jehofa Ọlọrun ko ni reti pe ki ẹnikan lo gbogbo akoko rẹ ninu igbokegbodo iṣẹ́ ijọ, ní riran awọn arakunrin rẹ̀ ati awọn aladugbo rẹ̀ lọwọ lati jere igbala sibẹ ki o maṣe bojuto igbala awọn ara ile rẹ̀. Aya ati awọn ọmọ ẹnikan ni ẹrù ekini.”

14 Ilé-Ìṣọ́nà ti November 1, 1986, ojú ìwé 22, gbani nímọ̀ràn pé: “Lilọwọsi iṣẹ-ojiṣẹ pápá-oko gẹgẹ bi idile kan yoo tubọ fà yin sunmọra, sibẹ aini ailẹgbẹ ti awọn ọmọ nbeere fun ifara-ẹni-sabẹ-ìdè iṣẹ-aigbọdọmaṣe niti akoko ara-ẹni tiyin ati okun-inu ẹmi-ero yin. Nitori naa, ìwọ̀n-déédéé ni a nilo lati ronupinnu iye akoko tí iwọ lè lò fun ìlà-iṣẹ́ ijọ, lẹsẹkan naa tí ó sì ṣe abojuto tẹmi, ti ẹmi-ero, ati nipa ti ara fun ‘awọn wọnni tí wọn jẹ́ tirẹ.’ [Kristẹni kan] gbọdọ ‘kẹkọọ lakọkọ lati maa sọ ifọkansin oniwa-bi-Ọlọrun dàṣà ninu agbo-ile [tirẹ̀] funraarẹ.’ (1 Timothy 5:4, 8)”

15. Èé ṣe tí alàgbà kan tí ó ní aya àti ọmọ fi nílò ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀?

15 Òwe inú Ìwé Mímọ́ kan sọ pé: “Ọgbọ́n ni a fi í kọ́ ilé; òye ni a sì fi í fi ìdí rẹ̀ kalẹ̀.” (Òwe 24:3) Bẹ́ẹ̀ ni, kí alábòójútó kan tó lè ṣe ojúṣe rẹ̀ ní ti ìṣàkóso Ọlọ́run, kí ó sì gbé agbo ilé rẹ̀ ró lọ́wọ́ kan náà, ó dájú gbangba pé ó nílò ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀. Lójú ìwòye Ìwé Mímọ́, agbègbè àbójútó tí ó ní ju ẹyọ kan lọ. Ó wé mọ́ ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ nínú ìdílé àti nínú ìjọ. Ó nílò ìfòyemọ̀ láti lè wà déédéé láàárín àwọn nǹkan wọ̀nyí. (Fílípì 1:9, 10) Ó nílò ọgbọ́n láti to àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì lẹ́sẹẹsẹ. (Òwe 2:10, 11) Bí ó ti wù kí àwọn àǹfààní rẹ̀ nínú ìjọ mú un lẹ́mìí tó, ó ní láti mọ̀ dájú pé, gẹ́gẹ́ bí ọkọ àti bàbá, ẹrù iṣẹ́ àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run fún un ni àbójútó àti ìgbàlà ìdílé rẹ̀.

Àwọn Bàbá Rere Tí Wọ́n Tún Jẹ́ Alàgbà Rere

16. Àǹfààní wo ni alàgbà kan ní bí ó bá tún lọ jẹ́ bàbá?

16 Alàgbà kan tí ó ní àwọn ọmọ tí wọ́n jẹ́ ọmọlúwàbí lè jẹ́ ẹni ṣíṣeyebíye gidigidi. Bí ó bá ti ń bójú tó ìdílé rẹ̀ dáradára, ó wà ní ipò àtiran àwọn ìdílé mìíràn nínú ìjọ lọ́wọ́. Yóò rọrùn fún un láti lóye ìṣòro wọn, kí ó sì fún wọn ní ìmọ̀ràn tí yóò fi ìrírí tirẹ̀ hàn. Ó dùn mọ́ni pé, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn alàgbà jákèjádò ayé ń ṣe iṣẹ́ rere gẹ́gẹ́ bí ọkọ, bàbá, àti alábòójútó.

17. (a) Kí ni ọkùnrin kan tí ó jẹ́ bàbá àti alàgbà kò gbọdọ̀ gbàgbé láé? (b) Báwo ni àwọn mẹ́ḿbà yòó kù nínú ìjọ ṣe lè fi ìgbatẹnirò hàn?

17 Kí ọkùnrin kan tí ó ní ìdílé tó lè di alàgbà, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ Kristẹni kan tí ó dàgbà dénú, ẹni tí ó jẹ́ pé, bí ó ṣe ń bójú tó aya àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó lè ṣètò àwọn àlámọ̀rí rẹ̀ láti lè yọ̀ọ̀da àkókò àti àfiyèsí fún àwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ. Kò gbọdọ̀ gbàgbé láé pé, ilé ni iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀. Ní mímọ̀ pé àwọn alàgbà tí wọ́n ní aya àti àwọn ọmọ ní ẹrù iṣẹ́ ti inú ìdílé wọn àti ojúṣe wọn nínú ìjọ, àwọn mẹ́ḿbà ìjọ yóò gbìyànjú láti má ṣe fi ohun tí kò yẹ gbà wọ́n lákòókò. Fún àpẹẹrẹ, alàgbà kan tí ó ní àwọn ọmọ tí wọn yóò lọ sí ilé ẹ̀kọ́ láàárọ̀ ọjọ́ kejì lé má lè fìgbà gbogbo dúró fún ìgbà díẹ̀ lẹ́yìn ìpàdé ìrọ̀lẹ́. Àwọn mẹ́ḿbà ìjọ yòó kù ní láti lóye èyí, kí wọ́n sì fi ìgbatẹnirò hàn.—Fílípì 4:5.

Ó Yẹ Kí Àwọn Alàgbà Wa Jẹ́ Ẹni Ọ̀wọ́n fún Wa

18, 19. (a) Kí ni àyẹ̀wò wa nípa Kọ́ríńtì Kìíní, orí 7 ràn wá lọ́wọ́ láti mọ̀? (b) Ojú wo ni ó yẹ kí a fi wo irú àwọn Kristẹni ọkùnrin bẹ́ẹ̀?

18 Àyẹ̀wò tí a ti ṣe nínú orí 7 lẹ́tà àkọ́kọ́ Pọ́ọ̀lù sí àwọn ará Kọ́ríńtì ti ràn wá lọ́wọ́ láti rí i pé, ní títẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù, ọ̀pọ̀ àwọn àpọ́nkùnrin ń bẹ tí wọ́n ń lo òmìnira wọn láti ṣiṣẹ́ sin ire Ìjọba. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn arákùnrin tí wọ́n ti gbéyàwó tún wà tí wọn kò ní ọmọ, tí ó jẹ́ pé, bí wọ́n ṣe ń fún àwọn aya wọn ní àfiyèsí tí ó yẹ, wọ́n ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó rere nínú iṣẹ́ àgbègbè, àyíká, nínú ìjọ, àti ní ẹ̀ka Watch Tower, pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn aya wọn tí ó yẹ kí a gbóríyìn fún. Paríparí rẹ̀, ní èyí tí ó fẹ̀rẹ̀ẹ́ tó 80,000 ìjọ àwọn ènìyàn Jèhófà, ọ̀pọ̀ bàbá ń bẹ tí kì í ṣe pé wọ́n ń fi ìfẹ́ bójú tó àwọn aya àti àwọn ọmọ wọn nìkan ni, ṣùgbọ́n wọ́n tún ń lo àkókò láti ṣiṣẹ́ sin àwọn arákùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn tí ó bìkítà.—Ìṣe 20:28.

19 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí a ka àwọn àgbà ọkùnrin tí ń ṣe àbójútó lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ yẹ fún ọlá onílọ̀ọ́po méjì, ní pàtàkì àwọn wọnnì tí ń ṣiṣẹ́ kára nínú ọ̀rọ̀ sísọ àti kíkọ́ni.” (Tímótì Kìíní 5:17) Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn alàgbà tí ń ṣàbójútó lọ́nà rere nínú ilé wọn àti nínú ìjọ yẹ fún ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀. Ní tòótọ́, ó yẹ kí a “máa ka irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ sí ẹni ọ̀wọ́n.”—Fílípì 2:29.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Ile-Iṣọ Na, August 1, 1978, ojú ìwé 31 àti 32.

b Wo Ile-Iṣọ Na, July 1, 1963, ojú ìwé 223.

Fún Àtúnyẹ̀wò

◻ Báwo ni a ṣe mọ̀ pé ọ̀pọ̀ alàgbà ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, jẹ́ ọkùnrin onídìílé?

◻ Kí ni a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn alàgbà tí wọ́n gbéyàwó, tí wọ́n sì ní ọmọ, èé sì ti ṣe?

◻ Kí ni ó túmọ̀ sí láti ní “àwọn ọmọ tí wọ́n gbà gbọ́,” ṣùgbọ́n bí ọmọ alàgbà kan kò bá yàn láti ṣiṣẹ́ sin Jèhófà ńkọ́?

◻ Lọ́nà wo ni alàgbà kan fi yẹ kí ó “pèsè fún àwọn wọnnì tí wọ̀n jẹ́ tirẹ̀”?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ìdílé tí ó lágbára ní ń di ìjọ tí ó lágbára

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́