ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 10/15 ojú ìwé 15-19
  • Jíjẹ́ Ọkọ àti Alàgbà—Mímú Kí Àwọn Ẹrù Iṣẹ́ náà Wà Déédéé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jíjẹ́ Ọkọ àti Alàgbà—Mímú Kí Àwọn Ẹrù Iṣẹ́ náà Wà Déédéé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ipò Alàgbà àti Ìgbéyàwó Bára Mu
  • ‘Ọkùnrin Tí Ó Gbéyàwó Pínyà Lọ́kàn’
  • Àwọn Ọkọ Rere Tí Wọ́n Tún Jẹ́ Alàgbà Rere
  • Ojúṣe Tí Ìwé Mímọ́ Là Sílẹ̀ Láti Ṣe sí Aya
  • “Ìpọ́njú Nínú Ẹran Ara”
  • Àwọn Aya Tí Ń Fara Wọn Rúbọ
  • Jíjẹ́ Bàbá àti Alàgbà—Ṣíṣe Ojúṣe Méjèèjì
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Má Ṣe Ya Ohun Tí Ọlọ́run Ti So Pọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìmọ̀ràn Ọlọgbọ́n Fún Àwọn Tọkọtaya
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ṣáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Tú Ìgbéyàwó Ká?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 10/15 ojú ìwé 15-19

Jíjẹ́ Ọkọ àti Alàgbà—Mímú Kí Àwọn Ẹrù Iṣẹ́ náà Wà Déédéé

“Alábòójútó ní láti jẹ́ . . . ọkọ aya kan.”—TÍMÓTÌ KÌÍNÍ 3:2.

1, 2. Èé ṣe tí wíwà láìgbéyàwó nítorí jíjẹ́ àlùfáà kò ṣe bá Ìwé Mímọ́ mu?

NÍ Ọ̀RÚNDÚN kìíní, mímú kí onírúurú ẹrù iṣẹ́ wọn wà déédéé jẹ àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́ lógún. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wí pé Kristẹni kan tí ó bá wà lápọ̀n-ọ́n “yóò ṣe dáadáa jù,” ó ha ní in lọ́kàn pé irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ wà ní ipò tí ó sàn jù láti ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó nínú ìjọ Kristẹni bí? Ní ti gidi, ó ha ń sọ wíwà lápọ̀n-ọ́n di ohun àbéèrèfún fún ipò alàgbà bí? (Kọ́ríńtì Kìíní 7:38) A béèrè pé kí àwọn àlùfáà Kátólíìkì wà láìgbéyàwó. Ṣùgbọ́n wíwà láìgbéyàwó nítorí jíjẹ́ àlùfáà ha bá Ìwé Mímọ́ mu bí? Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Ìlà Oòrùn fàyè gba àwọn àlùfáà ẹkùn wọn láti jẹ́ àwọn ọkùnrin tí wọ́n gbéyàwó, ṣùgbọ́n àwọn bíṣọ́ọ̀bù wọn kò gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. Ìyẹ́n ha bá Bíbélì mu bí?

2 Ọ̀pọ̀ lára àwọn àpọ́sítélì Kristi 12, àwọn ìpìlẹ̀ mẹ́ḿbà ìjọ Kristẹni, jẹ́ àwọn ọkùnrin tí wọ́n gbéyàwó. (Mátíù 8:14, 15; Éfésù 2:20) Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àwa ní ọlá àṣẹ láti máa mú arábìnrin kan káàkiri gẹ́gẹ́ bí aya, àní gẹ́gẹ́ bí àwọn àpọ́sítélì yòó kù àti àwọn arákùnrin Olúwa àti Kéfà [Pétérù], àbí a kò ní?” (Kọ́ríńtì Kìíní 9:5) Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, New Catholic Encyclopedia, gbà pé “òfin wíwà láìgbéyàwó pilẹ̀ṣẹ̀ lọ́dọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì” àti pé “a kò fi dandan mú àwọn òjíṣẹ́ M[ájẹ̀mú] T[untun] láti wà láìgbéyàwó.” Ìlànà Ìwé Mímọ́ ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé dípò òfin ṣọ́ọ̀ṣì.—Tímótì Kìíní 4:1-3.

Ipò Alàgbà àti Ìgbéyàwó Bára Mu

3. Àwọn òkodoro òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́ wo ni ó fi hàn pé àwọn Kristẹni alábòójútó lè jẹ́ àwọn ọkùnrin tí wọ́n ti gbéyàwó?

3 Dípò sísọ pé kí àwọn ọkùnrin tí a yàn sípò alábòójútó wà láìgbéyàwó, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Títù pé: “Fún ìdí yìí ni mo fi fi ọ́ sílẹ̀ ní Kírétè, kí ìwọ lè ṣe àtúnṣe àwọn ohun tí ó ní àbùkù kí o sì lè ṣe ìyànsípò àwọn àgbà ọkùnrin [ní èdè Gíríìkì, pre·sbyʹte·ros,] láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá, gẹ́gẹ́ bí mo ti fún ọ ní àwọn àṣẹ ìtọ́ni; bí ọkùnrin èyíkéyìí bá wà láìní ẹ̀sùn lọ́rùn, ọkọ aya kan, tí ó ní àwọn ọmọ tí wọ́n gbà gbọ́ tí wọn kò sí lábẹ́ ọ̀ràn ẹ̀sùn ìwà wọ̀bìà tàbí ya ewèlè. Nítorí alábòójútó [ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, e·piʹsko·pos, inú ibi tí ọ̀rọ̀ náà “bíṣọ́ọ̀bù” ti jáde] gbọ́dọ̀ wà láìní ẹ̀sùn lọ́rùn gẹ́gẹ́ bí ìríjú Ọlọ́run.”—Títù 1:5-7.

4. (a) Báwo ni a ṣe mọ̀ pé ìgbéyàwó kì í ṣe ohun àbéèrèfún lọ́wọ́ àwọn Kristẹni alábòójútó? (b) Àǹfààní wo ni arákùnrin àpọ́n kan tí ó jẹ́ alàgbà ní?

4 Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ìgbéyàwó kì í ṣe ohun tí Ìwé Mímọ́ ń béèrè fún ipò alàgbà. Jésù wà lápọ̀n-ọ́n. (Éfésù 1:22) Pọ́ọ̀lù, alábòójútó títa yọ lọ́lá nínú ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, kò gbéyàwó nígbà náà. (Kọ́ríńtì Kìíní 7:7-9) Lónìí, ọ̀pọ̀ Kristẹni àpọ́n ń bẹ tí ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà. Ipò àpọ́n tí wọ́n wà ti lè fún wọn ní àkókò púpọ̀ láti ṣe ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó.

‘Ọkùnrin Tí Ó Gbéyàwó Pínyà Lọ́kàn’

5. Òkodoro òtítọ́ wo nínú Ìwé Mímọ́ ni àwọn arákùnrin tí wọ́n ti gbéyàwó ní láti mọ̀?

5 Nígbà tí Kristẹni ọkùnrin kan bá gbéyàwó, ó yẹ kí ó mọ̀ pé òún ń tẹ́rí gba ẹrù iṣẹ́ tuntun, tí yóò gba àkókò àti àfiyèsí òun. Bíbélì sọ pé: “Ọkùnrin tí kò gbéyàwó ń ṣàníyàn fún àwọn ohun ti Olúwa, bí òún ṣe lè jèrè ojú rere ìtẹ́wọ́gbà Olúwa. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ó gbéyàwó ń ṣàníyàn fún àwọn ohun ti ayé, bí òún ṣe lè jèrè ojú rere ìtẹ́wọ́gbà aya rẹ̀, ó sì pínyà lọ́kàn.” (Kọ́ríńtì Kìíní 7:32-34) Lọ́nà wo ni ó fi pínyà lọ́kàn?

6, 7. (a) Ọ̀nà kan wo ni ọkùnrin tí ó gbéyàwó fi “pínyà lọ́kàn”? (b) Ìmọ̀ràn wo ni Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni tí ó ti gbéyàwó? (d) Báwo ni èyí ṣe lè nípa lórí ìpinnu ọkùnrin kan láti tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ àyànfúnni?

6 Ọ̀nà kan ni pé, ọkùnrin kan tí ó ti gbéyàwó ń jọ̀wọ́ ọlá àṣẹ tí ó ní lórí ara òun fúnra rẹ̀. Pọ́ọ̀lù mú èyí ṣe kedere pé: “Aya kì í lo ọlá àṣẹ lórí ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ọkọ rẹ̀ a máa ṣe bẹ́ẹ̀; bákan náà, pẹ̀lú, ọkọ kì í lo ọlá àṣẹ lórí ara rẹ̀, ṣùgbọ́n aya rẹ̀ a máa ṣe bẹ́ẹ̀.” (Kọ́ríńtì Kìíní 7:4) Àwọn kan tí ń wéwèé láti gbéyàwó lè rò pé èyí kò tó nǹkan, nítorí pé ìbálòpọ̀ kì yóò jẹ́ olórí ohun àjọṣe nínú ìgbéyàwó. Ṣùgbọ́n, níwọ̀n bí ìjẹ́mímọ́ ṣáájú ìgbéyàwó ti jẹ́ ohun tí Ìwé Mímọ́ béèrè fún, ní ti gidi, àwọn Kristẹni kò lè mọ àwọn àìní ìdákọ́ńkọ́ ti ẹni tí wọ́n ń wéwèé láti bá ṣègbéyàwó.

7 Pọ́ọ̀lù fi hàn pé tọkọtaya ‘tí wọ́n gbé èrò inú wọn ka àwọn ohun ti ẹ̀mí’ pàápàá gbọ́dọ̀ gba àìní ẹnì kíní kejì wọn ní ti ìbálòpọ̀ rò. Ó rọ àwọn Kristẹni ní Kọ́ríńtì pé: “Kí ọkọ máa fi ohun ẹ̀tọ́ aya rẹ̀ fún un; ṣùgbọ́n kí aya pẹ̀lú ṣe bákan náà fún ọkọ rẹ̀. Ẹ má ṣe máa fi du ara yín lẹ́nì kíní kejì, àyàfi nípasẹ̀ ìjọ́hẹn tọ̀tún tòsì fún àkókò tí a yàn kalẹ̀, kí ẹ lè ya àkókò sọ́tọ̀ fún àdúrà kí ẹ sì tún lè jùmọ̀ wà pa pọ̀, kí Sátánì má baà máa dẹ yín wò nítorí àìfètò ṣàkóso ara yín.” (Róòmù 8:5; Kọ́ríńtì Kìíní 7:3, 5) Ó bani nínú jẹ́ pé, àwọn ọ̀ràn panṣágà ti ṣẹlẹ̀ nígbà tí a kò tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí. Nítorí èyí, ó yẹ kí Kristẹni kan tí ó ti gbéyàwó gbé àwọn ọ̀ràn yẹ̀ wò dáradára ṣáájú kí ó tó tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ àyànfúnni tí yóò yà á nípa kúrò lọ́dọ̀ aya rẹ̀ fún sáà gígùn kan. Kò ní òmìnira rírìn bí ó ṣe wù ú mọ́, gẹ́gẹ́ bí ó ti ní in nígbà tí ó wà lápọ̀n-ọ́n.

8, 9. (a) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tí ó wí pé àwọn Kristẹni tí wọ́n ti gbéyàwó “ń ṣàníyàn fún àwọn ohun ti ayé”? (b) Kí ni ó yẹ kí àwọn Kristẹni tí wọ́n ti gbéyàwó máa ṣàníyàn láti ṣe?

8 Lọ́nà wo ni a fi lè sọ pé àwọn ọkùnrin Kristẹni tí wọ́n ti gbéyàwó, títí kan àwọn alàgbà, “ń ṣàníyàn fún àwọn ohun ti ayé [koʹsmos]”? (Kọ́ríńtì Kìíní 7:33) Ó ṣe kedere pé, kì í ṣe àwọn ohun búburú nínú ayé ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ bá, èyí tí gbogbo Kristẹni gbọ́dọ̀ yẹ̀ sílẹ̀. (Pétérù Kejì 1:4; 2:18-20; Jòhánù Kìíní 2:15-17) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wa nítọ̀ọ́ni “láti kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run jù sílẹ̀ àti àwọn ìfẹ́ ọkàn ti ayé [ko·smi·kosʹ] àti láti gbé pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú àti òdodo àti ìfọkànsin Ọlọ́run nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí.”—Títù 2:12.

9 Nítorí náà, Kristẹni kan tí ó ti gbéyàwó “ń ṣàníyàn fún àwọn ohun ti ayé” ní ti pé, àwọn ohun ti ayé tí ó jẹ́ apá kan ìgbésí ayé ìdílé ojoojúmọ́ jẹ ọkọ tàbí aya náà lógún lọ́nà ẹ̀tọ́. Èyí ní ilé, oúnjẹ, aṣọ, eré ìnàjú, nínú—kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ nǹkan mìíràn tí ó kàn wọ́n bí ọ̀rọ̀ ọmọ bá ti wọ̀ ọ́. Ṣùgbọ́n fún tọkọtaya tí kò tí ì bímọ pàápàá, bí ìgbéyàwó náà yóò bá yọrí sí rere, ọkọ àti aya náà gbọ́dọ̀ ṣàníyàn nípa ‘jíjèrè ojú rere ìtẹ́wọ́gbà’ alábàáṣègbéyàwó wọn. Èyí jẹ àwọn Kristẹni alàgbà lógún gidigidi bí wọ́n ṣe ń mú kí àwọn ẹrù iṣẹ́ wọn wà déédéé.

Àwọn Ọkọ Rere Tí Wọ́n Tún Jẹ́ Alàgbà Rere

10. Kí Kristẹni kan tó lè tóótun gẹ́gẹ́ bí alàgbà, kí ni àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn ará ìta gbọ́dọ̀ lè ṣàkíyèsí?

10 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbéyàwó kì í ṣe ohun àbéèrèfún fún ipò alàgbà, bí Kristẹni ọkùnrin kan bá ti gbéyàwó, kí a tó lè dámọ̀ràn rẹ̀ fún ìyànsípò gẹ́gẹ́ bí alàgbà, ó dájú pé, ó ní láti fi ẹ̀rí sísakun láti jẹ́ ọkọ rere, ọkọ onífẹ̀ẹ́ hàn, bí ó ti ń lo ipò orí rẹ̀ lọ́nà yíyẹ. (Éfésù 5:23-25, 28-31) Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí ọkùnrin èyíkéyìí bá ń nàgà fún ipò iṣẹ́ alábòójútó, iṣẹ́ àtàtà ni ó ní ìfẹ́ ọkàn sí. Nítorí náà alábòójútó ní láti jẹ́ aláìlẹ́gàn, ọkọ aya kan, oníwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú àṣà ìhùwà.” (Tímótì Kìíní 3:1, 2) Ó gbọ́dọ̀ hàn gbangba pé alàgbà kan ń ṣe gbogbo ohun tí ó lè ṣe láti jẹ́ ọkọ rere, yálà aya rẹ̀ jẹ́ Kristẹni bíi tirẹ̀ tàbí kò jẹ́ bẹ́ẹ̀. Ní tòótọ́, àwọn tí ń bẹ́ lẹ́yìn òde ìjọ pàápàá ní láti lè ṣàkíyèsí pé ó ń tọ́jú aya rẹ̀ dáradára, tí ó sì ń bójú to àwọn ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ míràn. Pọ́ọ̀lù fi kún un pé: “Òún tún ní láti ní gbólóhùn ẹ̀rí tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ní òde, kí òun má baà ṣubú sínú ẹ̀gàn àti ìdẹkùn Èṣù.”—Tímótì Kìíní 3:7.

11. Kí ni àpólà ọ̀rọ̀ náà “ọkọ aya kan” túmọ̀ sí, nítorí náà kí ni àwọn alàgbà ní láti ṣọ́ra fún?

11 Dájúdájú, àpólà ọ̀rọ̀ náà “ọkọ aya kan” fagi lé ìkóbìnrinjọ, ṣùgbọ́n ó tún túmọ̀ sí ìṣòtítọ́ nínú ìgbéyàwó. (Hébérù 13:4) Àwọn alàgbà ní pàtàkì ní láti ṣọ́ra gidigidi nígbà tí wọ́n bá ń ran àwọn arábìnrin lọ́wọ́ nínú ìjọ. Wọ́n ní láti yẹra fún dídáwà nígbà tí wọ́n bá ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ arábìnrin kan tí ó nílò ìmọ̀ràn àti ìtùnú. Yóò dára kí alàgbà míràn, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan, tàbí bí ó bá jẹ́ ọ̀ràn ṣíṣe ìbẹ̀wò afúnniníṣìírí, aya wọn pàápàá lè tẹ̀ lé wọn lọ.—Tímótì Kìíní 5:1, 2.

12. Àpèjúwe wo ni aya àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní láti sakun láti bá mu?

12 Lọ́nà àyàbá, nígbà tí ó ń tó àwọn ohun àbéèrèfún lọ́wọ́ àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ lẹ́sẹẹsẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tún ní ọ̀rọ̀ ìmọ̀ràn kan fún aya àwọn tí a óò gbé yẹ̀ wò fún irú àǹfààní bẹ́ẹ̀. Ó kọ̀wé pé: “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ àwọn obìnrin ní láti jẹ́ oníwà àgbà, kì í ṣe afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, oníwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú àṣà ìhùwà, olùṣòtítọ́ nínú ohun gbogbo.” (Tímótì Kìíní 3:11) Kristẹni ọkọ kan lè ṣe púpọ̀ láti ran aya rẹ̀ lọ́wọ́ láti lè bá àpèjúwe yìí mu.

Ojúṣe Tí Ìwé Mímọ́ Là Sílẹ̀ Láti Ṣe sí Aya

13, 14. Àní bí aya alàgbà kan kì í bá ṣe Ẹlẹ́rìí, èé ṣe tí ó fi yẹ kí ó máa gbé pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì jẹ́ ọkọ rere?

13 Dájúdájú, ìmọ̀ràn yìí tí a fún aya àwọn alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ fi hàn pé irú àwọn aya bẹ́ẹ̀ fúnra wọn jẹ́ Kristẹni olùṣèyàsímímọ́. Ní gbogbogbòò, bí ọ̀ràn ṣe sábà máa ń rí nìyí nítorí pé a béèrè pé kí Kristẹni kan gbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” (Kọ́ríńtì Kìíní 7:39) Ṣùgbọ́n kí ni nípa ti arákùnrin kan tí ó ti gbé aláìgbàgbọ́ kan níyàwó tẹ́lẹ̀ kí ó tó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, tàbí ti aya rẹ̀ ṣi ẹsẹ̀ gbé tí kì í sì í ṣe ẹ̀bi ọkọ náà?

14 Èyí fúnra rẹ̀, kò lè dì í lọ́wọ́ jíjẹ́ alàgbà. Bí ó ti wù kí ó rí, kì yóò sọ pípínyà pẹ̀lú aya rẹ̀ di ohun tí ó tọ́, kìkì nítorí pé kò ṣàjọpín ìgbàgbọ́ rẹ̀. Pọ́ọ̀lù gbani nímọ̀ràn pé: “A ha dè ọ́ mọ́ aya kan bí? Dẹ́kun wíwá ìtúsílẹ̀.” (Kọ́ríńtì Kìíní 7:27) Ó sọ síwájú sí i pé: “Bí arákùnrin èyíkéyìí bá ní aya tí kò gbà gbọ́, síbẹ̀ tí obìnrin náà sì fara mọ́ bíbá a gbé, kí òun má ṣe fi obìnrin náà sílẹ̀. Ṣùgbọ́n bí ẹni tí kò gbà gbọ́ náà bá tẹ̀ síwájú láti lọ, jẹ́ kí ó lọ; arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan kò sí ní ipò ẹrú lábẹ́ irúfẹ́ àwọn àyíká ipò bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti pè yín sí àlàáfíà. Nítorí, aya, báwo ni o ṣe mọ̀ bóyá ìwọ yóò gba ọkọ rẹ là? Tàbí, ọkọ, báwo ni o ṣe mọ̀ bóyá ìwọ yóò gba aya rẹ là?” (Kọ́ríńtì Kìíní 7:12, 15, 16) Àní bí aya rẹ̀ kì í bá ṣe Ẹlẹ́rìí pàápàá, alàgbà kan ní láti jẹ́ ọkọ rere.

15. Ìmọ̀ràn wo ni àpọ́sítélì Pétérù fún àwọn ọkọ Kristẹni, kí sì ni ó lè jẹ́ àbájáde rẹ̀ bí alàgbà kan bá jẹ́ aláìbìkítà ọkọ?

15 Yálà aya rẹ̀ jẹ́ onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tàbí kì í ṣe onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, Kristẹni alàgbà kan ní láti mọ̀ pé aya òun nílò àfiyèsí onífẹ̀ẹ́ òun. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní bíbá wọn gbé [àwọn aya] ní irú ọ̀nà kan náà ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀, kí ẹ máa fi ọlá fún wọn gẹ́gẹ́ bí fún ohun ìlò aláìlerató, ọ̀kan tí ó jẹ́ abo, níwọ̀n bí ẹ̀yin tún ti jẹ́ ajogún ojú rere ìyè tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí pẹ̀lú wọn, kí àdúrà yín má baà ní ìdílọ́wọ́.” (Pétérù Kìíní 3:7) Ọkọ kan tí ó mọ̀ọ́mọ̀ kọ̀ láti tọ́jú aya rẹ̀ ń wu ipò ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà léwu; ó lè dènà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà gẹ́gẹ́ bí “àwọ sánmà . . . kí àdúrà má lè là á kọjá.” (Ẹkun Jeremáyà 3:44) Èyí lè yọrí sí dídi ẹni tí kò tóótun mọ́ láti ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí Kristẹni alábòójútó.

16. Kókó pàtàkì wo ni Pọ́ọ̀lù sọ, èrò wo ni ó sì yẹ kí àwọn alàgbà ní nípa èyí?

16 Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàkíyèsí, lájorí ìtumọ̀ ìjiyàn Pọ́ọ̀lù ni pé nígbà tí ọkùnrin kan bá gbéyàwó, yóò jọ̀wọ́ ìwọ̀nba òmìnira tí ó ní gẹ́gẹ́ bí àpọ́nkùnrin tí ó yọ̀ọ̀da fún un láti “ṣiṣẹ́ sin Olúwa nígbà gbogbo láìsí ìpínyà ọkàn.” (Kọ́ríńtì Kìíní 7:35) Ìròyìn fi hàn pé àwọn alàgbà kan tí wọ́n ti gbéyàwó kì í fìgbà gbogbo wà déédéé ní ríronú lórí àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí tí Pọ́ọ̀lù sọ. Nínú ìfẹ́ ọkàn wọn láti ṣàṣeparí ohun tí wọ́n rò pé ó yẹ kí àwọn alàgbà rere ṣe, wọ́n lè gbójú fo díẹ̀ nínú ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bí ọkọ. Ó máa ń ṣòro fún àwọn kan láti kọ àǹfààní kan nínú ìjọ, àní bí ó bá tilẹ̀ ṣe kedere pé èyí yóò jẹ́ ewu fún ipò tẹ̀mí àwọn aya wọn. Wọ́n ń gbádùn àwọn àǹfààní tí ń bá ìgbéyàwó rìn, ṣùgbọ́n wọ́n ha múra tán láti bójú tó àwọn ẹrù iṣẹ́ tí ń bá a rìn bí?

17. Kí ni ó ti ṣẹlẹ̀ sí díẹ̀ nínú aya àwọn alábòójútó, báwo sì ni a ṣe lè yẹra fún èyí?

17 Ó dájú pé, ìtara gẹ́gẹ́ bí alàgbà jẹ́ ohun tí ó yẹ kí a gbóríyìn fún. Síbẹ̀, Kristẹni kan ha wà déédéé bí ó bá jẹ́ pé nínú bíbójú tó ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ nínú ìjọ, òun kò ka àwọn ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ sí aya rẹ̀ lójú ìwòye Ìwé Mímọ́ sí? Bí ó ṣe ń fẹ́ láti ran àwọn tí ó wà nínú ìjọ lọ́wọ́, alàgbà kan tí ó wà déédéé yóò jẹ́ kí ipò tẹ̀mí aya rẹ̀ jẹ ẹ́ lógún pẹ̀lú. Àwọn kan nínú aya àwọn alàgbà ti di aláìlera nípa tẹ̀mí, àwọn kan sì ti nírìírí “rírì ọkọ̀” nípa tẹ̀mí. (Tímótì Kìíní 1:19) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹrù iṣẹ́ aya kan ni láti fúnra rẹ̀ ṣiṣẹ́ fún ìgbàlà ara rẹ̀, nínú àwọn ọ̀ràn kan, ìṣòro tẹ̀mí náà ti lè ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ bí alàgbà náà bá ‘ti bọ́’ aya rẹ̀, tí ó sì “ṣìkẹ́” rẹ̀, “gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti ń ṣe sí ìjọ.” (Éfésù 5:28, 29) Láti bọ́ lọ́wọ́ ewu, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ ‘kíyè sí ara wọn àti gbogbo agbo.’ (Ìṣe 20:28) Bí wọ́n bá ti gbéyàwó, èyí ní àwọn aya wọn nínú.

“Ìpọ́njú Nínú Ẹran Ara”

18. Kí ni díẹ̀ nínú àwọn apá “ìpọ́njú” tí àwọn Kristẹni tí ó ti gbéyàwó ń nírìírí rẹ̀, báwo sì ni èyí ṣe lè nípa lórí ìgbòkègbodò alàgbà kan?

18 Àpọ́sítélì náà tún kọ̀wé pé: “Bí wúńdíá ènìyàn kan bá sì gbéyàwó, irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn wọnnì tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ yóò ní ìpọ́njú nínú ẹran ara wọn. Ṣùgbọ́n èmi ń dá yín sí.” (Kọ́ríńtì Kìíní 7:28) Pọ́ọ̀lù fẹ́ láti gba àwọn tí wọ́n bá lè tẹ́ lè àpẹẹrẹ rẹ̀ ti wíwà lápọ̀n-ọ́n kúrò lọ́wọ́ ìdààmú tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ tí ń bá ìgbéyàwó rìn. Àní fún àwọn tọkọtaya tí wọn kò tí ì bímọ pàápàá, àwọn ìdààmú wọ̀nyí lè ní nínú, ìṣòro ìlera tàbí ìṣòro ìṣúnná owó pẹ̀lú ẹrù iṣẹ́ tí Ìwé Mímọ́ lá sílẹ̀ láti ṣe fún àwọn òbí alábàáṣègbéyàwó ẹni tí wọ́n ti dàgbà. (Tímótì Kìíní 5:4, 8) Alàgbà kan gbọ́dọ̀ gbà láti bójú tó àwọn ẹrù iṣẹ́ wọ̀nyí lọ́nà àwòfiṣàpẹẹrẹ, nígbà míràn, èyí sì lè nípa lórí àwọn ìgbòkègbodò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristẹni alábòójútó. Ó dùn mọ́ni pé, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn alàgbà ń ṣe iṣẹ́ rere ní ti bíbójú tó ẹrù iṣẹ́ wọn nínú ìdílé àti nínú ìjọ.

19. Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tí ó wí pé: “Kí àwọn wọnnì tí wọ́n ní aya dà bí ẹni pé wọn kò ní”?

19 Pọ́ọ̀lù fi kún un pé: “Àkókò tí ó ṣẹ́kù sílẹ̀ ti dín kù. Láti ìsinsìnyí lọ kí àwọn wọnnì tí wọ́n ní aya dà bí ẹni pé wọn kò ní.” (Kọ́ríńtì Kìíní 7:29) Àmọ́ ṣáá o, lójú ìwòye ohun tí ó ti kọ ṣáájú nínú orí yìí sí àwọn ará Kọ́ríńtì, ó ṣe kedere pé, kò ní in lọ́kàn pé àwọn Kristẹni tí wọ́n ti gbéyàwó ní láti pa àwọn aya wọn tì lọ́nà kan ṣá. (Kọ́ríńtì Kìíní 7:2, 3, 33) Ó fi ohun tí ó ní lọ́kàn hàn, nígbà tí ó kọ̀wé pé: “[Kí] àwọn wọnnì tí ń lo ayé [dà] bí àwọn wọnnì tí kò lò ó dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́; nítorí ìrísí ìran ayé yìí ń yí padà.” (Kọ́ríńtì Kìíní 7:31) Àní gan-an nísinsìnyí ju bí ó ṣe rí ní ọjọ́ Pọ́ọ̀lù tàbí ọjọ́ àpọ́sítélì Jòhánù lọ, “ayé ń kọjá lọ.” (Jòhánù Kìíní 2:15-17) Nítorí náà, àwọn Kristẹni tí wọ́n ti gbéyàwó tí wọ́n sì lóye ìjẹ́pàtàkì ṣíṣe àwọn ìrúbọ díẹ̀ ní títẹ̀ lé Kristi kò lè ri ara wọn bọ inú adùn àti àǹfààní inú ìgbéyàwó pátápátá.—Kọ́ríńtì Kìíní 7:5.

Àwọn Aya Tí Ń Fara Wọn Rúbọ

20, 21. (a) Àwọn ìrúbọ wo ni ọ̀pọ̀ Kristẹni aya ń múra tán láti ṣe? (b) Kí ni aya kan lè fi ẹ̀tọ́ retí láti ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀, kódà bí ó bá jẹ́ alàgbà?

20 Gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn alàgbà ṣe ń ṣe ìrúbọ láti lè ṣàǹfààní fún àwọn ẹlòmíràn, ọ̀pọ̀ aya àwọn alàgbà ti sakun láti fi ire Ìjọba tí ó ṣe pàtàkì mú àwọn ẹrù iṣẹ́ wọn nínú ìgbéyàwó wà déédéé. Ní pàtàkì níhà ọ̀dọ̀ aya àwọn alàgbà àti àwọn alábòójútó arìnrìn àjò, fífi ìgbéyàwó sí ayè rẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ire Ìjọba ń béèrè ìfara-ẹni-rúbọ púpọ̀. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Kristẹni obìnrin ń láyọ̀ láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ọkọ wọn láti lè bójú tó ẹrù iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn nítorí èyí, ó sì ń bù kún ẹ̀mí rere tí wọ́n fi hàn. (Fílémónì 25) Síbẹ̀síbẹ̀, ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù tí ó wà déédéé fi hàn pé aya àwọn alábòójútó lè fi ẹ̀tọ́ retí àkókò àti àfiyèsí tí ó mọ níwọ̀n láti ọ̀dọ̀ àwọn ọkọ wọn. Yíyọ̀ọ̀da àkókò tí ó tó fún àwọn aya wọn, láti baà lè mú kí ẹrù iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ọkọ àti alábòójútó wà déédéé jẹ́ ojúṣe tí Ìwé Mímọ́ là sílẹ̀ fún àwọn alàgbà tí wọ́n ti gbéyàwó.

21 Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé ní àfikún sí jíjẹ́ ọkọ, Kristẹni alàgbà kan tún jẹ́ bàbá ńkọ́? Èyí fi kún ẹrù iṣẹ́ rẹ̀, ó sì ṣí agbègbè àbójútó mìíràn sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a óò ṣe rí i nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e.

Fún Àtúnyẹ̀wò

◻ Òkodoro òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́ wo ni ó fi hàn pé Kristẹni alábòójútó kan lè jẹ́ ọkùnrin tí ó ti gbéyàwó?

◻ Bí alàgbà kan tí ó jẹ́ àpọ́n bá gbéyàwó, kí ni ó gbọ́dọ̀ mọ̀?

◻ Ọ̀nà wo ni Kristẹni kan tí ó ti gbéyàwó gbà fi “ń ṣàníyàn fún àwọn ohun ti ayé”?

◻ Báwo ni ọ̀pọ̀ aya àwọn alábòójútó ṣe ń fi ẹ̀mí rere ti ìfara-ẹni-rúbọ hàn?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Àní bí ọwọ́ rẹ̀ bá dí fún ìgbòkègbodò ìṣàkóso Ọlọ́run pàápàá, alàgbà kan ní láti fún aya rẹ̀ ní àfiyèsí onífẹ̀ẹ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́