ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 4/22 ojú ìwé 12-18
  • Ìgbàgbọ́ Nínú Ọlọrun Ṣàkóso Mi Ní Ilẹ̀ Kọ́múníìsì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbàgbọ́ Nínú Ọlọrun Ṣàkóso Mi Ní Ilẹ̀ Kọ́múníìsì
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Dídi Onígbàgbọ́ Nínú Ọlọrun
  • Ìwákiri Mi Lérè
  • Àwọn Ìpinnu Tí Mo Dojú Kọ
  • Onímọ̀ Ìjìnlẹ̀ Kan Yí Ojú Ìwòye Rẹ̀ Padà
  • Wíwàásù Lábẹ́ Ìfòfindè
  • Jíjuwọ́ Sílẹ̀ fún Ìbáwí
  • Àwọn Ìbùkún Àgbàyanu
  • ‘Ahọ́n Àwọn Akólòlò Pàápàá Yóò Sọ̀rọ̀’
    Jí!—1996
  • Ìṣàkóso Ọlọ́run Làwá Fara Mọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Èmi Ògbóǹkangí Olóṣèlú Tẹ́lẹ̀ Di Kristẹni Tí Kò Dá Sí Ìṣèlú Mọ́
    Jí!—2002
  • Àdánwò Ìgbàgbọ́ ní Slovakia
    Jí!—2003
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 4/22 ojú ìwé 12-18

Ìgbàgbọ́ Nínú Ọlọrun Ṣàkóso Mi Ní Ilẹ̀ Kọ́múníìsì

GẸ́GẸ́ BÍ ONDREJ KADLEC ṢE SỌ Ọ́

NÍ ÌGBÀ ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1966, mò ń mú àwọn ènìyàn kiri láti wo ìlú tí a ti bí mi—Prague, Czechoslovakia. Níwọ̀n bí mo ti ní ìtara fún ìgbàgbọ́ tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ rí náà, mo ń sọ̀rọ̀ nípa Ọlọrun nígbà tí mò ń fi àwọn ṣọ́ọ̀ṣì àti ilé ìjọsìn wa fífani mọ́ra hàn àwọn ènìyàn náà.

Ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ ọ̀ràn ìnáwó kan tí ó jẹ́ ọmọ America béèrè pé: “Ṣe Ẹlẹ́rìí Jehofa ni ọ́ ni?”

Mo fèsì pé: “Rárá. N kò tí ì gbọ́ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa rí. Onísìn Roman Kátólíìkì ni mí.”

Dídi Onígbàgbọ́ Nínú Ọlọrun

Àwọn òbí tí wọ́n yọrí ọlá níbi ìmọ̀ ẹ̀kọ́, ìṣèlú, àti ìmọ̀ ìṣègùn ló wò mí dàgbà. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n bí mi ní ọdún 1944 àti lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e, bàbá mí di Kọ́múníìsì. Ní ti gidi, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ó dá àjọ alátùn-únṣe ti Kọ́múníìsì sílẹ̀, nígbà tí ó sì di ọdún 1966, ó di ọ̀gá àgbà fún Yunifásítì Ètò Ọrọ̀ Ajé tí ó wà ní Prague. Lẹ́yìn bí ọdún mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bíi mínísítà ètò ẹ̀kọ́ ní Czechoslovakia, tí ó jẹ́ orílẹ̀-èdè Kọ́múníìsì àti ti aláìgbọlọ́rungbọ́.

Ìyá jẹ́ obìnrin kan tí ó lẹ́bùn púpọ̀, tí ó sì jẹ́ olóòótọ́ hán-únhán-ún. Dókítà oníṣẹ́ abẹ ojú ni, àwọn ènìyàn sì mọ̀ ọ́n sí dókítà tí ó dára jù lọ ní orílẹ̀-èdè náà. Síbẹ̀, ó máa ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ fún àwọn aláìní lọ́fẹ̀ẹ́. Ó máa ń sọ pé: “Ẹ̀bùn yòówù tí ènìyàn bá ní, ènìyàn gbọ́dọ̀ lò ó láti fi ṣe àwùjọ àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè láǹfààní.” Kò tilẹ̀ gba ìsinmi kúrò lẹ́nu iṣẹ́ nígbà tí ó bí mi, kí ó baà lè wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní ilé ìtọ́jú aláìsàn rẹ̀.

Wọ́n retí pé kí n máa gbégbá orókè níbi ẹ̀kọ́ mi. Bàbá yóò béèrè lọ́wọ́ mi pé: “Ẹnì kan ha wà tí ó mọ̀wé jù ọ́ lọ bí?” Ìbáradíje náà wá di ohun tí ń gbádùn mọ́ mi, níwọ̀n bí mo ti máa ń gba ẹ̀bùn ìwé kíkà nítorí pé mo yege. Mo kọ́ èdè Rọ́ṣíà, Gẹ̀ẹ́sì, àti German, mo sì rìnrìn àjò púpọ̀ káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè Kọ́múníìsì àti kọjá ibẹ̀. Mo fẹ́ràn kí n máa tako àwọn ìgbàgbọ́ ìsìn gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ tí kò fi làákàyè hàn. Bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé mo nígbàgbọ́ nínú àìgbọlọ́rungbọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀, mo ti wá bẹ̀rẹ̀ sí í kórìíra bí wọ́n ti ń lò ó nínú ọ̀ràn ìṣèlú.

Ìrìn àjò tí ó gbé mi lọ sí England ní ọdún 1965, nígbà tí mo ṣì jẹ́ ọmọ ọdún 21 péré, ní ipa jíjinlẹ̀ lórí mi. Mo bá àwọn ènìyàn tí wọ́n ń ṣalágbàwí fún ìgbàgbọ́ wọn nínú Ẹni Gíga Jù Lọ kan pẹ̀lú ìdánilójú àti ọgbọ́n orí pàdé. Lẹ́yìn tí mo padà sí Prague, ojúlùmọ̀ mi kan tí ó jẹ́ onísìn Roman Kátólíìkì dábàá pé: “Máa kàwé nípa ìsìn Kristian. Máa ka Bibeli.” Mo ṣe bẹ́ẹ̀. Ó gbà mí ní oṣù mẹ́ta láti kà á tán.

Ohun tí ó wú mi lórí ni ọ̀nà tí àwọn òǹkọ̀wé Bibeli gbà gbé ìhìn iṣẹ́ wọn kalẹ̀. Wọ́n sọ ojú abẹ níkòó, wọ́n sì sọ àṣìṣe ara wọn. Mo wá gbà gbọ́ pé ọjọ́ ọ̀la àgbàyanu tí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ jẹ́ ohun kan tí ó jẹ́ pé Ọlọrun tí ó jẹ́ ẹni gidi kan ni ó lè ronú nípa rẹ̀, kí ó sì pèsè rẹ̀.

Lẹ́yìn dídá ka Bibeli fún oṣù bíi mélòó kan, àti ṣíṣàṣàrò lórí rẹ̀, ó ṣe mi bíi pé kí n ko bàbá mi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi lójú. Mo mọ̀ pé wọn yóò tako ìgbàgbọ́ tuntun tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ rí. Lẹ́yìn ìyẹn, mo di ẹni tí ń sọ àwọn ènìyàn di aláwọ̀ṣe pẹ̀lú ìtara. Ó di dandan fún ẹni yòówù tí ó bá wà nítòsí mi—irú bí ọ̀jọ̀gbọ́n ọmọ America tí a mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀—láti gbọ́ nípa ìsọnidaláwọ̀ṣe mi. Mo tilẹ̀ gbé àgbélébùú kan kọ́ sára ògiri lókè ibùsùn mi kí gbogbo ènìyàn baà lè mọ̀ nípa ìgbàgbọ́ mi.

Bí ó ti wù kí ó rí, Ìyá yarí pé kò lè rọrùn fún mi láti jẹ́ Kristian, níwọ̀n bí mo ti jọ bàbá mi tí ó jẹ́ Kọ́múníìsì paraku. Síbẹ̀, mo ń bá a lọ. Mo ka Bibeli lẹ́ẹ̀kejì àti lẹ́ẹ̀kẹta. Nígbà yẹn ni mò tó wá mọ̀ pé, kí n tó lè ní ìlọsíwájú sí i, mo nílò ìtọ́sọ́nà.

Ìwákiri Mi Lérè

Mo kàn sí Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì. Ohun tí ó jẹ àlùfáà ọ̀dọ́ kan lógún jù lọ ni láti kọ́ mi ní àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì náà, èyí tí mo tẹ́wọ́ gbà pátápátá. Nígbà tí ó yá, ní ọdún 1966—ó dójú ti bàbá mi—nígbà tí mo ṣe ìrìbọmi. Lẹ́yìn tí àlùfáà náà ti fi omi wọ́n mi tán, ó dábàá pé kí n ka Bibeli, ó sì tún fi kún un pé: “Póòpù ti tẹ́wọ́ gba àbá-èrò-orí ẹfolúṣọ̀n ní tirẹ̀, nítorí náà, fọkàn balẹ̀; a óò ya èpò kúrò lára ọkà.” Ó yà mi lẹ́nu pé ìwé tí ó ti fún mi nígbàgbọ́ di ohun tí a ń ṣiyè méjì nípa rẹ̀.

Ní báyìí ná, ní ìgbà ìwọ́wé ọdún 1966, mo bá ọ̀rẹ́ mi kan tí ó wá láti inú ìdílé Kátólíìkì sọ̀rọ̀, mo sì sọ nípa ìgbàgbọ́ mi fún un. Òun náà mọ̀ nípa Bibeli, ó sì sọ fún mi nípa Armageddoni. (Ìṣípayá 16:16) Ó sọ pé òun ti pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, àwọn tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ nípa wọn ní nǹkan bí oṣù mélòó kan sẹ́yìn nígbà tí mo ń mú àwọn ènìyàn kan wo ìlú kiri gẹ́gẹ́ bí mo ti mẹ́nu kàn án ní ìbẹ̀rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, mo ka àwọn àwùjọ ìsìn rẹ̀ sí èyí tí kò já mọ́ nǹkan kan tí a bá fi wéra pẹ̀lú Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì tèmi, tí ó lágbára, tí ó lówó, tí ó sì ní ènìyàn púpọ̀.

Nígbà kan tí a tún ń jíròrò síwájú sí i, a gbé àwọn ọ̀ràn ńlá mẹ́ta kan yẹ̀ wò. Lákọ̀ọ́kọ́, Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì ha ni adelé ìsìn Kristian ọ̀rúndún kìíní bí? Èkejì, Kí ni ó yẹ kí á gbà gẹ́gẹ́ bí ọlá àṣẹ títóbi jù lọ—ṣọ́ọ̀ṣì mi tàbí Bibeli? Àti ẹ̀kẹta, Èwo ni ó tọ̀nà, ṣe ìròyìn tí Bibeli fúnni nípa ìṣẹ̀dá ni tàbí àbá-èrò-orí ẹfolúṣọ̀n?

Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé Bibeli ni orísun ìgbàgbọ́ fún àwa méjèèjì, ó rọrùn fún ọ̀rẹ́ mi láti mú kí n gbà gbọ́ pé àwọn ẹ̀kọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì yàtọ̀ pátápátá sí ti ìsìn Kristian ìpilẹ̀sẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, mo gbọ́ pé àwọn Kátólíìkì fúnra wọn sọ pé ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan tí ó gbalẹ̀ tí ṣọ́ọ̀ṣì náà ń kọ́ni kò ní ìpìlẹ̀ nínú àwọn ẹ̀kọ́ Jesu Kristi àti àwọn aposteli rẹ̀.

Ìyẹn ló mú kí a dé orí ìbéèrè tí ó jẹ mọ́ ọn nípa ohun tí ó yẹ kí ó jẹ́ ọlá àṣẹ wa títóbi jù lọ. Mo tọ́ka sí àyọkà St. Augustine pé: “Roma locuta est; causa finita est,” tí ó túmọ̀ sí pé, “Romu ti sọ̀rọ̀; ọ̀ràn ti parí.” Ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ mi ṣì gbà gbọ́ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli, ni ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ọlá àṣẹ gíga jù lọ fún wa. Mo ní láti gbà pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ aposteli Paulu pé: “Jẹ́ kí a rí Ọlọrun ní olóòótọ́, bí a tilẹ̀ rí olúkúlùkù ènìyàn ní òpùrọ́.”—Romu 3:4.

Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ọ̀rẹ́ mi fún mi ní ìwé títẹ̀ jákujàku kan, tí ó ní àkòrí náà, Evolution Versus the New World. Nítorí pé wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Czechoslovakia ní òpin àwọn ọdún 1940, wọ́n máa ń ṣe ẹ̀dà àwọn ìwé wọn, wọn yóò sì fi pẹ̀lú ìṣọ́ra wo ẹni tí wọn yóò fún. Ìgbà tí mo ti ka ìwé pẹlẹbẹ yìí ni mo ti mọ̀ pé òtítọ́ wà nínú rẹ̀. Ọ̀rẹ́ mi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú mi. Ó máa ń yá mi ní ọ̀pọ̀ àwọn ojú ewé ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli náà, “Jẹki Ọlọrun Jẹ Olõtọ” lẹ́ẹ̀kan náà, a óò sì jíròrò àwọn ojú ewé wọ̀nyí papọ̀.

Kò pẹ́ lẹ́yìn tí a bẹ̀rẹ̀ àwọn ìjíròrò wọ̀nyí—nígbà Kérésìmesì ọdún 1966—àwọn ọ̀rẹ́ mi tí wọ́n wà ní ìhà Ìwọ̀ Oòrùn Germany wá sí Prague láti wá kí mi. Nígbà ìjíròrò wa kan, wọ́n ń fi àwọn Kristian ṣe yẹ̀yẹ́ pé wọ́n jẹ́ adógunsílẹ̀ alárèékérekè. Wọ́n sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ogun orílẹ̀-èdè tí ó wà nínú àjọ NATO, a lè bá ẹ̀yin tí ẹ pe ara yín ní Kristian tí ń gbé orílẹ̀-èdè Kọ́múníìsì tí ó wà lábẹ́ Àdéhùn Ogun Warsaw, jà.” Ibi tí wọ́n parí gbogbo rẹ̀ sí ni pé: “Ó sàn kí ènìyàn jẹ́ kòṣeku-kòṣẹyẹ dípò kí ènìyàn jẹ́ alárèékérekè lọ.” Ó dà bí ẹni pé wọ́n tọ̀nà lójú mi. Nítorí náà, nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli mi tí ó tẹ̀ lé e, mo béèrè lọ́wọ́ ọ̀rẹ́ mi bóyá òtítọ́ ni pé àwọn Kristian ń ní ohunkóhun í ṣe pẹ̀lú ogun, tí wọ́n sì ń dá àwọn ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.

Àwọn Ìpinnu Tí Mo Dojú Kọ

Àlàyé tí ó ṣe kedere tí ọ̀rẹ́ mi ṣe yà mí lẹ́nu. Síbẹ̀, láti hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ Bibeli pé kí a ‘fi idà rọ ọ̀bẹ-plau’ yóò yí ìgbésí ayé mi àti iṣẹ́ tí mo fẹ́ máa ṣe padà pátápátá. (Isaiah 2:4) Ó ku oṣù márùn-ún kí n jáde ní yunifásítì ìmọ̀ ìṣègùn, tí wọn yóò sì sọ pé kí n ṣe iṣẹ́ ológun ọ̀ràn-anyàn fún àkókò kan. Kí ni n óò ṣe? Àyá kà mí. Nítorí náà, mo gbàdúrà sí Ọlọrun.

Lẹ́yìn tí mo ronú jinlẹ̀ jinlẹ̀ fún ọjọ́ mélòó kan, n kò rí ìdí tí n kò fi lè hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a béèrè lọ́wọ́ àwọn Kristian tòótọ́ pé kí wọ́n jẹ́ ènìyàn àlàáfíà. Lẹ́yìn tí mo jáde ní yunifásítì náà, mo pinnu pé títí tí wọn yóò fi tì mí mọ́lé nítorí pé mo jẹ́ alátakò paraku, n óò tẹ́wọ́ gba ipò kan ní ilé ìwòsàn. Nígbà tí ó yá ní mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Bibeli sọ nípa yíyẹra fún ẹ̀jẹ̀. Nígbà tí mo rò ó pé iṣẹ́ mi lè mú kí n lọ́wọ́ nínú fífa ẹ̀jẹ̀ sára àwọn ènìyàn, mo pinnu láti fi iṣẹ́ ilé ìwòsàn náà sílẹ̀. (Ìṣe 15:19, 20, 28, 29) Ìpinnu náà mú kí orúkọ mi bàjẹ́ lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn.

Lẹ́yìn tí bàbá mi ti rí i dájú pé n kò tí ì di oníjàngbọ̀n aṣetinú-ẹni kan tí ń wọ́nà láti ba iṣẹ́ òṣèlú rẹ̀ jẹ́, ó dá sí ọ̀ràn náà, ó sì jẹ́ kí wọ́n sún iṣẹ́ ológun ọ̀ràn-anyàn náà síwájú di ẹ̀yìn ọdún kan fún mi. Ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1967 yẹn nira fún mi. Ìwọ náà wo bí nǹkan ṣe rí fún mi: Mo jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tuntun kan tí olùdánilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, Ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo tí mo tíì bá pàdé, ti rìnrìn àjò ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn náà. Àkòrí bíi mélòó kan péré láti inú ìwé “Jẹki Ọlọrun Jẹ Olõtọ” ló sì fi sílẹ̀ fún mi láti máa fi dá kẹ́kọ̀ọ́. Ìwọ̀nyí àti Bibeli mi ni kìkì orísun ìtọ́sọ́nà tẹ̀mí tí mo ní.

Nígbà tí ó yá, mo di ojúlùmọ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn, nígbà tí ó sì di oṣù March 8, 1968, mo fi ìrìbọmi ṣàpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ mi sí Jehofa Ọlọrun. Ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e, wọ́n pè mí fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́dún méjì kan ní Yunifásítì Oxford ní England, fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ti gboyè àkọ́kọ́. Àwọn kan dábàá pé kí ń tẹ́wọ́ gba ìkésíni náà, kí n sì lọ sí England níbi ti mo ti lè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ní ilẹ̀ kan tí iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí kò ti sí lábẹ́ ìfòfindè. Bákan náà, mo lè máa múra fún iṣẹ́ gidi kan tí ó dára. Síbẹ̀, alàgbà Kristian kan sọ pé wọn kò nílò iṣẹ́ mi ní England tó bí wọ́n ṣe nílò rẹ̀ ní Czechoslovakia. Nítorí náà, mo pinnu láti kọ ìkésíni náà pé kí n wa lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ti ayé sí i, mo sì dúró ní Czechoslovakia láti ṣèrànwọ́ níbi ìgbòkègbodò ìwàásù lábẹ́lẹ̀ tí à ń ṣe.

Ní ọdún 1969, wọ́n ké sí mi láti wá lọ sí ibi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba, tí ń fúnni ní ìtọ́ni tí ó wà fún kìkì àwọn Kristian alábòójútó. Ní ọdún yẹn kan náà, mo gba ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́ onímọ̀ ìpòògùn tí ó fakọ yọ jù lọ ní Czechoslovakia. Nítorí èyí, mo lọ sí àpéjọ Ìgbìmọ̀ Àwọn Àpòògùn Lágbàáyé ní Switzerland.

Onímọ̀ Ìjìnlẹ̀ Kan Yí Ojú Ìwòye Rẹ̀ Padà

Nígbà àwíyé kan tí mo lọ ní ọdún 1970, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Frantis̆ek Vyskočil ṣàlàyé ẹ̀kọ́ tí ó díjú ti ọ̀nà ìgbésọfúnni kiri ti àwọn iṣan ìmọ̀lára. Ó sọ pé nígbàkúùgbà tí a bá kojú àìní kan nínú ìṣẹ̀dá kan, ojútùú títayọ lọ́lá kan yóò wà. Ó parí rẹ̀ pé: “Ìṣẹ̀dá, Àràmàǹdà Obìnrin náà, mọ bí ó ṣe lè ṣe é.”

Lẹ́yìn àwíyé náà, mo tọ̀ ọ́ lọ. Mo bèèrè pé: “Ìwọ kò ha rò pé gbogbo ògo ìṣètò kíkàmàmà tí ó wà nínú àwọn ohun alààyè yẹ kí ó lọ sọ́dọ̀ Ọlọrun?” Ìbéèrè mi bá a lójijì, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ aláìgbọlọ́rungbọ́. Ó fi àwọn ìbéèrè míràn dáhùn ìbéèrè mi. Ó bèèrè pé: “Ibo ni ìṣe búburú ti wá?” àti, “Ta ni ó yẹ́ kí a dá lẹ́bi fún ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tí ń di ọmọ òrukàn?”

Nígbà tí mo pèsè àwọn ìdáhùn tí ó lọ́gbọ́n nínú, tí a gbé karí Bibeli, ó ru ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ sókè. Àmọ́, ó bèèrè ìdí tí Bibeli kò fi fún wa ní ìṣọfúnni tí ó jẹ́ ti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tí ó ṣe pàtó, irú bí àpèjúwe bí sẹ́ẹ̀lì ṣe rí, kí àwọn ènìyàn baà lè tètè mọ̀ pé ẹni tí ó kọ ọ́ ni Ẹlẹ́dàá. Mo dáhùn pé: “Èwo ló ṣòro ju, láti ṣàpèjúwe nǹkan tàbí láti ṣẹ̀dá rẹ̀?” Mo yá a ní ìwé Did Man Get Here by Evolution or by Creation?

Lẹ́yìn tí Frantis̆ek kàn kà á gààràgà, ó pè é ní ìwé tí kò níláárí, tí kò sì tọ̀nà. O tilẹ̀ tún ṣàríwísí ohun tí Bibeli sọ nípa níní alábàágbéyàwó púpọ̀, ìwà panṣágà Dafidi, àti pípa tí Dafidi pa ọkùnrin aláìmọwọ́mẹsẹ̀ kan. (Genesisi 29:23-29; 2 Samueli 11:1-25) Mo kọ àwọn àtakò rẹ̀, mo sì tọ́ka sí i pé Bibeli fi pẹ̀lú ìṣòtítọ́ sọ ìròyìn àwọn àṣìṣe àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun pàápàá, papọ̀ pẹ̀lú ìfun àti ẹ̀dọ̀ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, nígbà ìjíròrò wa kan, mo sọ fún Frantis̆ek pé bí ẹnì kan kò bá ní èrò inú tí ó dára, bí kò bá ní ìfẹ́ òtítọ́, kò sí àlàyé tàbí ìgbèrò tí ó lè mú kí ó gbà gbọ́ pé Ọlọrun wà. Bí mo ti fẹ́ máa lọ, ó dá mi dúró, ó sì béèrè bí mo bá lè máa bá òun ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Ó sọ pé òun yóò tún ìwé Did Man Get Here by Evolution or by Creation? kà—lọ́tẹ̀ yìí, pẹ̀lú ẹ̀mí àìṣègbè. Lẹ́yìn náà, ìwà rẹ̀ yí padà pátápátá, gẹ́gẹ́ bí àyọkà tí ó tẹ̀ lé e yìí tí ó fi kún ọ̀kan lára àwọn lẹ́tà rẹ̀ ṣe fi ẹ̀rí hàn: “A óò sì tẹ orí ìgbéraga ènìyàn balẹ̀, ìrera àwọn ènìyàn ni a óò sì rẹ̀ sílẹ̀; Oluwa nìkan ṣoṣo ni a óò gbé ga ní ọjọ́ náà.”—Isaiah 2:17.

Ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1973, Frantis̆ek àti ìyàwó rẹ̀ ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ní báyìí, ó ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà kan ní ọ̀kan lára àwọn ìjọ Prague.

Wíwàásù Lábẹ́ Ìfòfindè

Nígbà ìfòfindè náà, wọ́n sọ fún wa kí a máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lọ pẹ̀lú ìṣọ́ra púpọ̀. Nígbà kan, ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan ń yọ mí lẹ́nu pé kí n mú òun lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ó ń ṣiyè méjì pé bóyá ni àwọn tí ń mú ipò iwájú nínú ètò àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa gan-an alára ń lọ sẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́. A gbádùn àìmọye ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa tí kì í ṣe bí àṣà. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, a pàdé ọkùnrin kan, tí ó dá mi mọ̀ láti inú fọ́tò tí ó rí nínú àkójọ fọ́tò àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ìpínlẹ̀ náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò fura nígbà náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò mú mi, láti ìgbà náà ni wọ́n ti ń ṣọ́ mi tọwọ́tẹsẹ̀ pẹ̀lú àṣẹ ìjọba, èyí tí ó fawọ́ ìjáfáfá mi sẹ́yìn nínú ìgbòkègbodò ìwàásù abẹ́lẹ̀.

Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1983, gẹ́gẹ́ bí ìṣe mi, mo kó àwùjọ àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan jọ kí a lè lo ọjọ́ bíi mélòó kan láti fi wàásù láìjẹ́ bí àṣà ní apá àrọko kan ní orílẹ̀-èdè náà. Nítorí pé n kò tẹ́tí sílẹ̀ sí ìtọ́ni tí ó lọ́gbọ́n nínú, mo lo ọkọ̀ mi nítorí pé ó rọrùn ju àwọn ọkọ̀ èrò lọ. Nígbà tí a ṣíwọ́ díẹ̀ láti ra àwọn nǹkan bíi mélòó kan ní ilé ìtajà ńlá kan, mo gbé ọkọ̀ mi síta. Nígbà tí mò ń sanwó fún àwọn nǹkan tí mo rà, mo nàka sí àwọn ọ̀dọ́ òǹtajà kan, mo sì sọ fún alágbàtà kan tí ó jẹ́ àgbàlagbà pé: “Ní ọjọ́ ọ̀la, gbogbo wa lè di ọ̀dọ́.” Obìnrin náà rẹ́rìn-ín músẹ́. Mò ń bá ọ̀rọ̀ mi lọ pé: “Bí ó ti wù kí ó rí, kì í ṣe pẹ̀lú agbára wa. A nílò ìrànwọ́ àtọ̀runwá.”

Níwọ̀n bí kò ti sọ ohunkóhun mọ́, mo fi ibẹ̀ sílẹ̀. Alágbàtà náà fura pé mò ń gbé àwọn ojú ìwòye ìsìn lárugẹ, ó ń ṣọ́ mi láti ojú fèrèsé bi mo ti ń kó ẹrù náà sínú ọkọ̀ mi tí èmi kò sì mọ̀. Lẹ́yìn náà ni ó fi tó àwọn ọlọ́pàá létí. Ní wákàtí bíi mélòó kan lẹ́yìn náà, lẹ́yìn tí mo ti lọ wàásù láìjẹ́ bí àṣà ni àwọn apá ibòmíràn ní ìlú yẹn, èmi àti alábàáṣiṣẹ́ mi padà sídìí ọkọ̀. Lójijì, àwọn ọlọ́pàá méjì yọ, wọ́n sì fi wá sínú àkámọ́.

Ní àgọ́ ọlọ́pàá, wọ́n fi ọ̀rọ̀ wá wa lẹ́nu wò fún ọ̀pọ̀ wákàtí kí wọ́n tó sọ fún wa pé kí a máa lọ. Ohun tí ó kọ́kọ́ wá sọ́kàn mi ni ohun tí n óò ṣe pẹ̀lú àdírẹ́sì àwọn olùfìfẹ́hàn tí a ní ní ọjọ́ yẹn. Nítorí náà, mo lọ sí ilé ìgbọ̀nsẹ̀ láti fomi ṣàn wọ́n dànù sínu ṣáláńgá. Ṣùgbọ́n ọwọ́ líle koko ọlọ́pàá kan dì mí mú bí mo ṣe fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Ó tún àwọn pépà náà kó jáde láti inú àwo ìgbọ̀nsẹ̀, ó sì nù wọ́n nù. Èyí mú kí ọkàn mi dààmú sí i, níwọ̀n bí mo ti kó àwọn ènìyàn tí wọ́n fún mi ní àdírẹ́sì wọn sínú wàhálà.

Lẹ́yìn náà, wọ́n mú gbogbo wa lọ sí hòtẹ́ẹ̀lì wa, níbi tí ọlọ́pàá ti tu gbogbo yàrá wa. Ṣùgbọ́n wọn kò rí àwọn àdírẹ́sì àwọn olùfìfẹ́hàn míràn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò kó wọn pamọ́ dáadáa. Lẹ́yìn náà, níbi tí mo ti ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi onímọ̀ ìṣègùn nípa iṣan ara, wọ́n bá mi wí débi tí gbogbo ènìyàn fi gbọ́ sí i nítorí lílọ́wọ́ tí mò ń lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò tí kò bófin mu. Bákan náà, alábòójútó iṣẹ́ ìwàásù ní Czechoslovakia, tí ó ti kìlọ̀ fún mi tẹ́lẹ̀ pé kí ń má lo ọkọ̀ mi nígbà tí a bá ń lọ sẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́, bá mi wí.

Jíjuwọ́ Sílẹ̀ fún Ìbáwí

Ní ọdún 1976, wọ́n ti yàn mi láti máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìgbìmọ̀ tí ń ṣàbójútó iṣẹ́ ìwàásù àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Czechoslovakia. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ti ń tọpa ìgbésí ayé mi fínnífínní, nítorí àìlo làákàyè nínú irú àwọn ọ̀ràn bí èyí tí a mẹ́nu kàn, wọ́n yọ orúkọ mi kúrò lára àwọn tí ń ṣiṣẹ́ nínú ìgbìmọ̀ orílẹ̀-èdè náà, àti kúrò nínú àwọn ipò àǹfààní mìíràn. Ọ̀kan lára àwọn ipò àǹfààní yìí tí mo kà sí iyebíye gan-an ni ti kíkọ́ àwọn ènìyàn ní ilé ẹ̀kọ́ àwọn alábòójútó arìnrìn àjò àti àwọn aṣáájú ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bí a ti ń pé àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.

Mo tẹ́wọ́ gba ìbáwí tí wọ́n fún mi náà, àmọ́, àkókò yìí, ní ìdajì àwọn ọdún 1980 jẹ́ èyí tí ó nira gan-an fún ṣíṣàyẹ̀wò ara mi. Èmi yóò ha kọ́ láti fi ọgbọ́n inú ṣiṣẹ́, kí n sì yẹra fún àìlo ọgbọ́n inú, bíi ti tẹ́lẹ̀ bí? Orin Dafidi orí 30, ẹsẹ 5, sọ pé: “Bí ẹkún pẹ́ di alẹ́ kan, ṣùgbọ́n ayọ̀ ń bọ̀ ní òwúrọ̀.” Òwúrọ̀ yẹn dé fún mi nígbà tí ìjọba Kọ́múníìsì ṣubú ní Czechoslovakia ní oṣù November 1989.

Àwọn Ìbùkún Àgbàyanu

Ẹ wo irú ìyípadà tí ó jẹ́ láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ fàlàlà, àti láti gbádùn ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ fàlàlà pẹ̀lú orílé iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Brooklyn, New York! Kò pẹ́ tí wọ́n fi yàn mí gẹ́gẹ́ alábòójútó arìnrìn àjò, mo sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yìí ní oṣù January 1990.

Lẹ́yìn náà, ní ọdún 1991, mo ní àǹfààní láti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ní Manchester, England. Ẹ wo irú ìbùkún tí ó jẹ́ láti lo oṣù méjì ní gbígbádùn ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Kristian tí wọ́n dàgbàdénú, àti láti gba ìsọfúnni láti ọ̀dọ̀ wọn! Ní gbogbo àkókò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, àwa akẹ́kọ̀ọ́ ní iṣẹ́ kan tí wọ́n yàn fún wa láti ṣe, èyí tí ń mú kí ara tù wá kúrò lẹ́nu ìtọ́ni ẹ̀kọ́ ìwé gbígbóná janjan tí wọ́n ń fún wa. Iṣẹ́ tí wọ́n fún èmi ni láti máa nu fèrèsé.

Gbàrà tí mo padà dé láti England, mo bẹ̀rẹ̀ síí ṣèrànwọ́ láti ṣètò fún àpéjọ pípinminrin kan tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fẹ́ ṣe ní oṣù August 9 sí 11, ní Gbọ̀ngàn Ìṣeré ńlá ti Strahov ní Prague. Nígbà ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, 74,587 ènìyàn, láti ọ̀pọ̀ ilẹ̀ ló pàdé fàlàlà láti jọ́sìn Ọlọrun wa, Jehofa!

Ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e, mo pa iṣẹ́ onímọ̀ ìṣègùn iṣan ara tì. Ó ti tó ọdún mẹ́rin tí mo ti ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì tí ó wà ní Prague, níbi tí mo tún ti ń sìn lẹ́ẹ̀kan sí i níbi ìgbìmọ̀ tí ń ṣàbójútó iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti Czech. Láìpẹ́ yìí, a tún ilé alájà mẹ́wàá kan, tí wọ́n fi tọrẹ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe, a sì ń lò ó gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Ní oṣù May 28, 1994, a ya ilé dídára yìí sí mímọ́ fún iṣẹ́ ìsìn Jehofa.

Lára àwọn ìbùkún tí mo ti ní ni àǹfààní ṣíṣàjọpín òtítọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, títí kan àwọn ìbátan mi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé bàbá àti ìyá mi kò tí ì di Ẹlẹ́rìí síbẹ̀, wọn kò ta ko iṣẹ́ mi mọ́ nísinsìnyí. Ní àwọn ọdún bíi mélòó kan tí ó ti kọjá lọ, wọ́n ti lọ sí díẹ̀ lára àwọn ìpàdé wa.

Ìrètí mi tọkàntọkàn ni pé, kí àwọn, àti àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn olótìítọ́ ọkàn míràn sí i, fi tìrẹ̀lẹ̀ tìrẹ̀lẹ̀ tẹríba fún ìṣàkóso Ìjọba Ọlọrun, kí wọ́n sì gbádùn àwọn ìbùkún ayérayé tí Ọlọrun ní ní ìpamọ́ fún àwọn tí wọ́n bá yàn láti sìn ín.

(Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ló ṣe àwọn ìtẹ̀jáde tí a tọ́ka sí nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí.)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Nígbà tí mo jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní yunifásítì

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Bàbá mi, tí ó di mínísítà ètò ẹ̀kọ́ ní Czechoslovakia, àti ìyá mi, tí ó jẹ́ oníṣẹ́ abẹ ojú tí ó yọrí ọlá

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Frantis̆ek Vyskočil, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ àti aláìgbọlọ́rungbọ́, tí ó di Ẹlẹ́rìí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

Láti ìgbà tí ìjọba Kọ́múníìsì ti ṣubú ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ń ṣe ọ̀pọ̀ àpéjọpọ̀ ńláńlá ní Ìlà Oòrùn Europe. Àwọn ènìyàn tí ó ju 74,000 lọ ló pésẹ̀ síbi eléyìí ní Prague ni ọdún 1991

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Àkókò tí mò ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ nígbà tí mo lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ní England

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ilé ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Prague, tí a yà sí mímọ́ ní May 28, 1994

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́