ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 11/1 ojú ìwé 24-28
  • Ìṣàkóso Ọlọ́run Làwá Fara Mọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìṣàkóso Ọlọ́run Làwá Fara Mọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Fojú Winá Wàhálà Ogun
  • A Wá Mọ̀ Pé Ìjọba Ọlọ́run Ń Bọ̀ Lóòótọ́
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Di Ohun Tá À Ń Ṣe Déédéé
  • Àwa Kristẹni Dojú Kọ Àdánwò Nítorí Àìdásí Ogun
  • A Rí Ìṣírí Tá A Nílò Gbà
  • “Ọ̀tá Ìjọba”
  • Ọjọ́ Ogbó Kò Tíì Dá Mi Dúró
  • Àdánwò Ìgbàgbọ́ ní Slovakia
    Jí!—2003
  • Mo Kọ́ Láti Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìgbàgbọ́ Nínú Ọlọrun Ṣàkóso Mi Ní Ilẹ̀ Kọ́múníìsì
    Jí!—1996
  • Fífún Jèhófà Ní Ohun Tó Tọ́ Sí I
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 11/1 ojú ìwé 24-28

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Ìṣàkóso Ọlọ́run Làwá Fara Mọ́

GẸ́GẸ́ BÍ MICHAL ŽOBRÁK ṢE SỌ Ọ́

Lẹ́yìn tí mo lo oṣù kan nínú àhámọ́ ànìkànwà, wọ́n wọ́ mi lọ sọ́dọ̀ ẹni tó máa fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò. Kíá, ojú rẹ̀ ti pọ́n, ó ń pariwo pé: “Amí ni ẹ́! Amí àwọn ará Amẹ́ríkà ni ẹ́!” Kí ló fà á tó fi bínú tó bẹ́ẹ̀? Ńṣe ló béèrè ìsìn tí mò ń ṣe lọ́wọ́ mi, mo sì sọ fún un pé: “Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí.”

ÈYÍ ṣẹlẹ̀ ní ohun tó lé ní àádọ́ta ọdún sẹ́yìn. Abẹ́ ìṣàkóso Kọ́múníìsì ní orílẹ̀-èdè tí mò ń gbé nígbà yẹn wà. Àmọ́, ó ti pẹ́ gan-an ṣáájú àkókò yẹn tí wọ́n ti ń ṣenúnibíni líle koko sí wa nítorí iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ táwa Kristẹni ń ṣe.

A Fojú Winá Wàhálà Ogun

Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni mí nígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914. Abẹ́ ìṣàkóso Ilẹ̀ Ọba Austria àti ti Hungary ni Zálužice tó jẹ́ abúlé mi wà lákòókò yẹn. Kì í ṣe pé ogun náà yí ipò ayé padà nìkan ni, ó tún sọ mi di ẹni tó ń gbé ẹrù àgbà. Sójà ni bàbá mi, ọdún tí ogun náà bẹ̀rẹ̀ gan-an ló sì kú. Èyí wá sọ èmi, màmá mi àtàwọn àbúrò mi obìnrin méjèèjì di ẹni tí ò ní nǹkan lọ́wọ́. Nítorí pé èmi nìkan lọ́mọ ọkùnrin, èmi ni mo sì dàgbà jù, kò pẹ́ tí ọ̀pọ̀ iṣẹ́ fi já lé mi léjìká nínú oko kékeré kan tá a ní àti láàárín ilé pẹ̀lú. Láti kékeré ni mo ti nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn. Kódà, òjíṣẹ́ Ọlọ́run ti Ṣọ́ọ̀ṣì Àwọn Ọmọlẹ́yìn Calvin tiẹ̀ sọ fún mi pé tóun ò bá ti sí nílé, kí n máa delé de òun, kí n máa kọ́ àwọn tá a jọ jẹ́ ọmọ ilé ìwé náà lẹ́kọ̀ọ́.

Nígbà tó di ọdún 1918, Ogun Àgbáyé Kìíní parí, inú wa sì dùn. Wọ́n ti gbàjọba lọ́wọ́ Ilẹ̀ Ọba Austria àti Hungary, a sì wá tipa bẹ́ẹ̀ di ọmọ ilẹ̀ olómìnira Czechoslovakia. Láìpẹ́, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ wa tí wọ́n lọ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà bẹ̀rẹ̀ sí í padà wálé. Michal Petrík, tó wá sí abúlé wa lọ́dún 1922 wà lára wọn. Nígbà tó wá kí ìdílé kan ládùúgbò wa, wọ́n pe èmi àti màmá mi síbẹ̀ pẹ̀lú.

A Wá Mọ̀ Pé Ìjọba Ọlọ́run Ń Bọ̀ Lóòótọ́

Michal jẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn orúkọ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń jẹ́ nígbà yẹn, ó sì sọ̀rọ̀ nípa àwọn kókó pàtàkì tó wọ̀ mí lọ́kàn gan-an látinú Bíbélì. Èyí tó jọ mí lójú jù lọ nínú wọn ni pé Ìjọba Jèhófà ń bọ̀. (Dáníẹ́lì 2:44) Nígbà tó sọ pé àwọn yóò ṣe ìpàdé Kristẹni kan ní abúlé Záhor ní ọjọ́ Sunday tó ń bọ̀, mo pinnu láti wà níbẹ̀. Aago mẹ́rin àárọ̀ ni mo ti jí, mo sì fẹsẹ̀ rin nǹkan bíi kìlómítà mẹ́jọ dé ilé ìbátan mi kan kí n lè yá kẹ̀kẹ́ kan lọ́wọ́ rẹ̀. Lẹ́yìn tí mo tún táyà kẹ̀kẹ́ náà kan tó jò ṣe, mo wá gùn ún lọ sí Záhor tó wà ní kìlómítà mẹ́rìnlélógún síbi tí mo ti gba kẹ̀kẹ́ náà. Mi ò mọ ibi tá a ti máa ṣèpàdé ọ̀hún, mo wá rọra ń gun kẹ̀kẹ́ náà gba ojú pópó kan lọ. Ìgbà yẹn ni mo wá gbọ́ tí wọ́n ń kọrin Ìjọba Ọlọ́run nínú ilé kan. Inú mi dùn dọ́ba. Bí mo ṣe wọnú ilé náà nìyẹn, tí mo sì ṣàlàyé ìdí tí mo fi wá. Ọ̀dọ̀ ìdílé náà ni mo ti jẹ oúnjẹ àárọ̀, kí wọ́n tó mú mi lọ síbi ìpàdé náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo tún fi kẹ̀kẹ́ àti ẹsẹ̀ rin ìrìn kìlómítà méjìlélọ́gbọ̀n padà sílé, síbẹ̀ kò rẹ̀ mí rárá.—Aísáyà 40:31.

Àwọn àlàyé táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe látinú Bíbélì níbi ìpàdé náà wú mi lórí gan-an. Àǹfààní téèyàn máa ní láti gbádùn ìgbésí ayé aláyọ̀ tó sì tuni lára nínú ìṣàkóso Ọlọ́run wọ̀ mí lọ́kàn ṣinṣin. (Sáàmù 104:28) Ẹ̀yìn ìyẹn ní èmi àti màmá mi fún ṣọ́ọ̀ṣì wa ní lẹ́tà tá a fi sọ fún wọn pé a ò ní wá sí ṣọ́ọ̀ṣì náà mọ́. Èyí fa arukutu gan-an lábúlé wa. Àwọn kan tiẹ̀ bá wa yodì fúngbà díẹ̀, àmọ́ inú wa dùn láti wà láàárín ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lágbègbè wa. (Mátíù 5:11, 12) Kò pẹ́ lẹ́yìn àkókò yẹn ni mo ṣèrìbọmi ní Odò Uh.

Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Di Ohun Tá À Ń Ṣe Déédéé

Gbogbo ibi tí àyè ìwàásù bá ti yọ la ti máa ń wàásù nípa Ìjọba Jèhófà. (Mátíù 24:14) Àmọ́ iṣẹ́ ìwàásù tá a fètò sí lọ́jọọjọ́ Sunday la gbájú mọ́ jù lọ. Àwọn èèyàn máa ń tètè jí nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ìdí nìyẹn tá a fi máa ń bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù láàárọ̀ kùtù hàì. A tún ṣètò ìpàdé fún gbogbo èèyàn nírọ̀lẹ́. Ńṣe làwọn tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbẹ̀ máa ń sọ èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ọ̀rọ̀ wọn láìwòwèé. Wọ́n máa ń gba ti àwọn olùfìfẹ́hàn tó wá rò, wọ́n tún máa ń wo ìsìn tí wọ́n ń ṣe, àtàwọn ọ̀ràn tó kàn wọ́n.

Àwọn òtítọ́ Bíbélì tá à ń wàásù rẹ̀ jẹ́ kí àwọn ọlọ́kàn rere túbọ̀ lóye nǹkan tẹ̀mí sí i. Kété lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi ni mo lọ ń wàásù ní abúlé kan tí wọ́n ń pè ní Trhovište. Inú ọ̀kan nínú àwọn ilé tó wà níbẹ̀ ni mo ti bá Ìyá Ààfin Zuzana Moskal sọ̀rọ̀, obìnrin náà ṣèèyàn gan-an, ó sì lọ́yàyà. Ìjọ Àwọn Ọmọlẹ́yìn Calvin lòun àti ìdílé rẹ̀ ń lọ, ìjọ yẹn lèmi náà sì wà tẹ́lẹ̀. Pẹ̀lú bó ṣe ka Bíbélì tó, ó ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè tó ń wá ìdáhùn sí látinú Bíbélì. Wákàtí kan gbáko la fi jọ sọ̀rọ̀, mo sì fún un ní ìwé Duru Ọlọrun.a

Kíá ni ìdílé Moskal fi ìwé Duru náà kún ìwé tí wọ́n máa ń kà lákòókò tí wọ́n máa ń ka Bíbélì wọn. Àwọn ìdílé mìíràn tún fìfẹ́ hàn lábúlé náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá sáwọn ìpàdé wa. òjíṣẹ́ Ọlọ́run ní Ìjọ Àwọn Ọmọlẹ́yìn Calvin kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n ṣọ́ra fún àwa àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa. Ìgbà yẹn làwọn kan lára àwọn olùfìfẹ́hàn náà wá sọ fún òjíṣẹ́ ọ̀hún pé kó wá sí ìpàdé wa kò wá já àwọn ẹ̀kọ́ wa nírọ́ lákòókò táwọn èèyàn láǹfààní àtisọ èrò ọkàn wọn jáde.

Òjíṣẹ́ náà wá lóòótọ́, àmọ́ kò rí ohunkóhun látinú Bíbélì tó lè fi ti ẹ̀kọ́ tó fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́yìn. Ó wá fẹ́ gbèjà ara ẹ̀, ó ní: “A ò lè gba gbogbo nǹkan tó wà nínú Bíbélì gbọ́. Àwọn èèyàn ló kọ ọ́, oríṣiríṣi ọ̀nà lèèyàn sì lè gbà dáhùn àwọn ìbéèrè tó bá jẹ mọ́ ọ̀ràn ẹ̀sìn.” Ohun tó sọ yìí gan-an ló wá lé ọ̀pọ̀ èèyàn kúrò lẹ́yìn rẹ̀. Àwọn kan sọ fún òjíṣẹ́ náà pe tí ò bá ti gbà Bíbélì gbọ́, àwọn ò ní wá gbọ́ ìwàásù rẹ̀ mọ́. Bí wọ́n ṣe kúrò nínú Ìjọ Àwọn Ọmọlẹ́yìn Calvin nìyẹn, nǹkan bí ọgbọ̀n èèyàn láti abúlé yẹn sì fara mọ́ òtítọ́ Bíbélì.

Wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà wá di ohun tá a máa ń ṣe déédéé, ìdí nìyẹn tí mo fi fẹ́ fẹ́yàwó látinú ìdílé tí wọ́n ò ti fọwọ́ yẹpẹrẹ mú nǹkan tẹ̀mí. Ọ̀kan lára àwọn tá a jọ máa ń wàásù ni Ján Petruška, tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Mo fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ obìnrin, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mária gan-an nítorí bó ṣe máa ń múra tán láti wàásù fún gbogbo èèyàn bí bàbá rẹ̀ ṣe máa ń ṣe. A ṣe ìgbéyàwó lọ́dún 1936, àádọ́ta ọdún sì ni Mária fi jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ mi tòótọ́, kó tó di pé ó kú ní ọdún 1986. Ọdún 1938 la bi ọmọ kan ṣoṣo tá a ní, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Eduard. Àmọ́, ó dà bíi pé ogun mìíràn tún ti ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀ ní Yúróòpù lákòókò yẹn. Ipa wo ló máa ní lórí iṣẹ́ wa?

Àwa Kristẹni Dojú Kọ Àdánwò Nítorí Àìdásí Ogun

Abẹ́ ìjọba Násì ni Slovakia tó wá di orílẹ̀-èdè tó dá dúró wà nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀. Síbẹ̀, kò sí ohun pàtó kan tí ìjọba ṣe sí àjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, a rọra ń ṣe iṣẹ́ wa ní abẹ́lẹ̀, wọ́n tún máa ń yẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa wò fínnífínní. Síbẹ̀síbẹ̀, a fọgbọ́n ń bá iṣẹ́ wa lọ ní pẹrẹu.—Mátíù 10:16.

Nígbà tí ogun náà ń le sí i, wọ́n ní kí n wá wọṣẹ́ ológun, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti lé lẹ́nì ọdún márùnlélọ́gbọ̀n lákòókò yẹn. Nítorí Kristẹni tí mo jẹ́, mo kọ̀ mi ò bá wọn lọ́wọ́ sógun. (Aísáyà 2:2-4) Ayọ̀ ńlá ló jẹ́ pé káwọn aláṣẹ tó mọ ohun tí wọ́n máa ṣe fún mi, wọ́n ní kí gbogbo àwa tá a jọ wà ní ìsọ̀wọ́ ọjọ́ orí kan náà máa lọ.

A gbọ́ pé ó nira gan-an fáwọn arákùnrin wa tó wà láwọn ìlú ńlá láti gbọ́ bùkátà ara wọn ju ti àwa tá a wà nígbèríko. Bá a ṣe pinnu láti kó lára oúnjẹ wa lọ fún wọn nìyẹn. (2 Kọ́ríńtì 8:14) Nípa bẹ́ẹ̀, a máa ń kó ọ̀pọ̀ oúnjẹ tá a bá lè kó, a ó sì rin ìrìn àjò tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] kìlómítà láàárín orílẹ̀-èdè náà lọ sí ìlú Bratislava. Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ Kristẹni àti ìfẹ́ tó wà láàárín wa nígbà ogun yẹn ló gbé wa ró láwọn ọdún tí nǹkan le koko fún wa lẹ́yìn ogun.

A Rí Ìṣírí Tá A Nílò Gbà

Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, Slovakia tún di apá kan Czechoslovakia lẹ́ẹ̀kan sí i. Láàárín ọdún 1946 sí 1948, ńṣe là ń ṣe àpéjọ ńlá ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àṣegbà láàárín ìlú Brno àti Prague. Àwa tó wà ní ìhà ìlà oòrùn Slovakia wọ àwọn ọkọ ojú irin tí wọ́n dìídì ṣètò rẹ̀ fáwọn tó ń lọ síbi àpéjọ náà. Kódà, èèyàn lè pe àwọn ọkọ ojú irin náà ní ọkọ̀ ojú irin olórin, nítorí orin lá kọ látìgbà tá a ti gbéra títí tá a fi débẹ̀.—Ìṣe 16:25.

Mo tiẹ̀ rántí àpéjọ tá a ṣe ní Brno lọ́dún 1947 dáadáa, àwọn Kristẹni alábòójútó mẹ́tà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti orílé iṣẹ́ wa ló wà níbẹ̀, Arákùnrin Nathan H. Knorr sì wà lára wọn. Ọ̀pọ̀ jù lọ wa ló fẹsẹ̀ rìn la ìlú náà já láti polongo àsọyé tá a fẹ́ sọ fún gbogbo èèyàn ní àpéjọ náà, tá a sì gbé páálí tí àkòrí àsọyé náà wà lára rẹ̀ kọ́ àyà. Inú Eduard, ọmọ wa tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án péré nígbà yẹn ò dùn nítorí pé wọ́n ò fún un ní páálí. Àwọn arákùnrin wá ṣe páálí kéékèèké fún òun àti ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé mìíràn. Àwọn ọmọdé wọ̀nyí sì ṣe gudugudu méje nínú pípolongo àsọyé náà!

Ní February 1948, àwọn Kọ́múníìsì tún gbàjọba. A mọ̀ pé kò ní pẹ́ rárá tí ìjọba máa gbẹ́sẹ̀ lé iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. A ṣe àpéjọ kan ní Prague ní September 1948, ọ̀pọ̀ nǹkan là ń rò, nítorí a mọ̀ pé wọ́n tún máa fòfin de ìpàdé ìta gbangba wa láìpẹ́, ìyẹn lẹ́yìn ọdún mẹ́ta péré tá a fi lómìnira láti máa pé jọ. Ká tó kúrò ní àpéjọ yẹn, a ṣe ìpinnu kan, lára ohun tó wà nínú ìpinnu náà ni pé: “Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a kóra wa jọ . . . , pinnu láti túbọ̀ mú kí iṣẹ́ ìsìn aláyọ̀ yìí tẹ̀ síwájú àti síwájú sí i, àti pé pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́ Olúwa, ká lè ní ìforítì ní àkókò tí nǹkan rọgbọ àti ní àkókò àdánwò, ká lè máa kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run pẹ̀lú ìtara tó pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.”

“Ọ̀tá Ìjọba”

Kò ju oṣù méjì péré lẹ́yìn àpéjọ tá a ṣe ní Prague yẹn ni àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ wá tú ilé Bẹ́tẹ́lì wa tó wà nítòsí Prague wò yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́. Wọ́n gba ilé náà, wọ́n sì kó gbogbo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n rí níbẹ̀ lọ, wọ́n tún kó gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì àtàwọn arákùnrin bíi mélòó kan. Àmọ́ ohun tójú wa máa rí ṣì pọ̀.

Ní òru February 3 sí 4, lọ́dún 1952, àwọn ọmọ ogun ẹ̀ṣọ́ wá gbogbo orílẹ̀-èdè náà wọ́n sì rí ọgọ́rùn-ún Ẹlẹ́rìí kó. Èmi náà wà lára wọn. Ní nǹkan bí aago mẹ́ta òru, àwọn ọlọ́pàá wá jí ìdílé mi lójú oorun. Láìṣe àlàyé kankan, wọ́n ní kí n tẹ̀ lé àwọn. Wọ́n dè mí wọ́n sì faṣọ bò mí lójú, wọ́n wá kó èmi àtàwọn bíi mélòó kan sí ẹ̀yìn ọkọ̀ akẹ́rù kan. Inú àhámọ́ ànìkànwà ni mo bá ara mi níkẹyìn.

Odindi oṣù kan kọjá láìrí ẹnikẹ́ni bá sọ̀rọ̀. Ẹnì kan ṣoṣo tí mo máa ń rí ni ẹ̀ṣọ́ tó máa ń ti oúnjẹ kékeré sí mi látinú ihò kan tó wà lára ilẹ̀kùn. Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni ẹni tí mo sọ pé ó fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò yẹn wá pè mí. Lẹ́yìn tó pè mí ni amí, ó wá ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Àìmọ̀kan ló mú káwọn èèyàn máa ṣe ẹ̀sìn. Ọlọ́run kò sí! A ò lè jẹ́ kó o máa tan àwọn òṣìṣẹ́ wa jẹ. Ńṣe la máa yẹgi fún ẹ tàbí kó o kú sọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Bí Ọlọ́run rẹ bá wá síbí pàápàá, pípa la máa pa òun náà!”

Níwọ̀n bí àwọn aláṣẹ ti mọ̀ pé kò sí òfin kankan tó sọ pé ìgbòkègbodò wa gẹ́gẹ́ bí Kristẹni lòdì, wọ́n wá fẹ́ wé nǹkan míì tó lòdì lábẹ́ òfin mọ́ wa lẹ́sẹ̀, wọ́n ní “ọ̀tá Ìjọba” ni wá, wọ́n tún ní a jẹ́ amí fún ilẹ̀ òkèèrè. Kí ọgbọ́n tí wọ́n dá yìí lè ṣiṣẹ́, wọ́n ní láti kọ́kọ́ ṣe wá bí ọṣẹ ṣe ń ṣojú kí wọ́n sì mú ká “jẹ́wọ́” ẹ̀ṣẹ̀ tá ò dá. Lẹ́yìn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò lóru ọjọ́ yẹn, wọn ò jẹ́ kí n sùn. Láàárín wákàtí díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí í fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò. Lọ́tẹ̀ yìí, ẹni tó ń fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò náà fẹ́ kí n buwọ́ lu ìwé kan tó kà pé: “Èmi tí mo jẹ́ ọ̀tá ilẹ̀ olómìnira ti Czechoslovakia kò dara pọ̀ mọ́ [àwọn èèyàn mi] nítorí pé mo ń dúró de àwọn ará Amẹ́ríkà.” Nígbà tí mo kọ̀ láti buwọ́ lu irú ìwé irọ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n gbé mi lọ sínú yàrá kékeré kan tí wọ́n ti ń kọ́ àwọn aláìgbọràn lọ́gbọ́n ní ọgbà ẹ̀wọ̀n náà.

Wọ́n ò jẹ́ kí n sùn, wọn ò jẹ́ kí n fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀, wọ́n ò sì jẹ́ kí n jókòó. Àfi kí n dúró sójú kan tàbí kí n máa rìn sókè sódò. Nígbà tí mi ò lókun kankan mọ́, mo dùbúlẹ̀ sí ilẹ̀yílẹ̀ tí wọ́n fi sìmẹ́ǹtì rẹ́. Ìgbà yẹn ni ẹ̀ṣọ́ náà wá mú mi padà lọ sí ọ́fíìsì ibi tí wọ́n ti ń fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò. Ẹni tó ń fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò wá sọ pé: “Ṣé wàá buwọ́ lu ìwé náà báyìí?” Nígbà tí mo tún kọ̀, ó gbá mi lójú. Ẹ̀jẹ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí í dà. Ó wá fìbínú sọ fún àwọn ẹ̀ṣọ́ náà pé: “Ó fẹ́ para ẹ̀ ni. Ẹ ṣọ́ ọ dáadáa kó má bàa para ẹ̀!” Wọ́n tún dá mi padà sínú àhámọ́ ànìkànwà. Odindi oṣù mẹ́fà ni wọ́n fi ń pè mí ṣáá tí wọ́n sì ń fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò lóríṣiríṣi ọ̀nà. Kò sí èyí tó lè jin ìpinnu tí mo ti ṣe láti pa ìwà títọ́ mi mọ́ sí Jèhófà lẹ́sẹ̀ nínú gbogbo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí wọ́n dá láti mú kí n gbà pé ọ̀tá Ìjọba ni mí.

Nígbà tó ku oṣù kan kí wọ́n gbẹ́jọ́ mi ni agbẹjọ́rò kan wá láti Prague tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọ̀rọ̀ wá àwa méjìlá tá a jẹ́ arákùnrin lẹ́nu wò. Ó bi mí pé: “Kí lo máa ṣe táwọn agbókèèrè ṣèjọba láti Ìwọ̀ Oòrùn ayé bá gbógun ti orílẹ̀-èdè wa?” Mo ní: “Ohun tí mo ṣe nígbà tí orílẹ̀-èdè yìí àti Hitler gbógun ti ilẹ̀ Rọ́ṣíà náà ni máa ṣe. Mi ò jagun nígbà yẹn, mi ò sì ní jagun báyìí nítorí pé Kristẹni ni mí, mi ò kì í lọ́wọ́ sógun.” Ó wá sọ fún mi pé: “A ò lè fàyè gba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. À ń wá àwọn sójà nítorí ìgbà táwọn agbókèèrè ṣèjọba láti Ìwọ̀ Oòrùn ayé bá gbógun dé, àwọn sójà tó máa jà fún àwọn èèyàn wa tó ń ṣiṣẹ́ ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé là ń wá.”

Wọ́n kó wa lọ sílé ẹjọ́ ní July 24, 1953. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ni wọ́n pe àwa méjèèjìlá síwájú ìgbìmọ̀ àwọn adájọ́. A fi àǹfààní yẹn jẹ́rìí nípa ìgbàgbọ́ wa. Lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ohun tá a sọ nípa ẹ̀sùn èké tí wọ́n fi kàn wá, agbẹjọ́rò kan dìde ó sọ pé: “Mo ti wà nínú ilé ẹjọ́ yìí lọ́pọ̀ ìgbà. Ohun tí mo sì sábà máa ń rí ni káwọn èèyàn máa jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kí wọ́n ronú pìwà dà, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ máa sunkún pàápàá. Àmọ́ ńṣe làwọn ọkùnrin wọ̀nyí túbọ̀ máa nígboyà ju ti ìgbà tí wọ́n débí lọ.” Níkẹyìn, wọ́n ní àwa méjèèjìlá jẹ̀bi ẹ̀sùn ìdìtẹ̀ mọ́ Ìjọba. Wọ́n sọ mí sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́ta, wọ́n sì sọ gbogbo ohun ìní mi di ti Ìjọba.

Ọjọ́ Ogbó Kò Tíì Dá Mi Dúró

Lẹ́yìn tí mo padà sílé, àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ṣì ń ṣọ́ mi tọwọ́tẹsẹ̀. Pẹ̀lú gbogbo ìyẹn náà, mo padà sẹ́nu iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ní pẹrẹu, wọ́n tún fún mi ní iṣẹ́ àbójútó nípa tẹ̀mí nínú ìjọ wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbà ká máa gbénú ilé wa tí wọ́n ti gbẹ́sẹ̀ lé, síbẹ̀ nǹkan bí ogójì ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá ilé náà padà fún wa lábẹ́ òfin, ìyẹn lẹ́yìn tí ìjọba Kọ́múníìsì ṣubú.

Èmi nìkan kọ́ ló lọ sẹ́wọ̀n nínú ìdílé mi. Ọdún mẹ́ta péré ni mo tíì lò nílé nígbà tí wọ́n ní kí Eduard wá wọṣẹ́ ológun. Ó kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tó ti fi Bíbélì kọ́, wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n. Kódà ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìyẹn, Peter, tó jẹ́ ọmọ ọmọ mi náà ṣẹ̀wọ̀n lórí ọ̀ràn kan náà yìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara rẹ̀ kò le.

Nígbà tó fi máa di ọdún 1989, Ìjọba Kọ́múníìsì Czechoslovakia kógbá sílé. Inú mi má dùn o, pé lẹ́yìn ogójì ọdún tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa, mo tún láǹfààní láti wàásù fàlàlà láti ilé dé ilé! (Ìṣe 20:20) Mò máa ń gbádùn iṣẹ́ ìsìn yìí gan-an nígbàkigbà tí ara mi bá lè láti ṣe é. Mo ti di ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́rùn-ún báyìí, ará sì ti dara àgbà, àmọ́ inú mi dùn pé mo ṣì lè jẹ́rìí fáwọn èèyàn nípa àwọn nǹkan ológo tí Jèhófà sọ pé òun máa ṣe ní ọjọ́ ọ̀la.

Mo lè ka àwọn méjìlá tí wọ́n jẹ́ olórí orílẹ̀-èdè márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n ti ṣàkóso lórí ìlú mi. Àwọn apàṣẹwàá wà lára wọn, àwọn ààrẹ, àti ọba kan. Kò sí èyíkéyìí lára wọn tó yanjú ìṣòro tó ń dààmú àwọn èèyàn tí wọ́n ṣàkóso lé lórí. (Sáàmù 146:3, 4) Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó jẹ́ kí n mọ òun láti kékeré mi. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe fún mi láti mọ̀ nípa bó ṣe máa yanjú àwọn ìṣòro wa nípasẹ̀ Ìjọba Mèsáyà, ó sì tún yọ mí nínú asán tó wà nínú gbígbé ayé láìmọ Ọlọ́run. Mo ti wàásù ìhìn rere tó dára jù lọ náà tọkàntara fún ohun tó lé ní ọdún márùndínlọ́gọ́rin báyìí, ó sì ti jẹ́ kí ìgbésí ayé mi nítumọ̀ gan-an, ó ti fún mi láyọ̀, ó sì jẹ́ kí n máa retí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé. Kí ló tún lè dára ju èyí lọ?b

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde, àmọ́ a ò tẹ ìwé náà mọ́ báyìí.

b Ó ṣeni láàánú pé ìgbà tá à fẹ́ gbé àpilẹ̀kọ yìí jáde ni Arákùnrin Michal Žobrák ṣaláìsí. Ó ṣe olóòótọ́ títí tó fi kú, ó si ní ìrètí àjíǹde tó dájú.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Kété lẹ́yìn ìgbéyàwó wa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Èmi àti Eduard níbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1940

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

À ń polongo àpéjọ tá a ṣe ní ìlú Brno lọ́dún 1947

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́