Bí Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Jèhófà Ṣe Ń Ràn Wá Lọ́wọ́
DÁFÍDÌ rí ìpọ́njú gan-an láyé rẹ̀. Sọ́ọ̀lù Ọba, tó jẹ́ bàbá ìyàwó rẹ̀ tó sì ń jowú rẹ̀, fojú rẹ̀ rí màbo. Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Sọ́ọ̀lù gbìyànjú láti fi ọ̀kọ̀ gún Dáfídì pa, ó sì níye ọdún tó fi lépa rẹ̀ kiri láìsinmi, tó mú kí Dáfídì di ìsáǹsá. (1 Sámúẹ́lì 18:11; 19:10; 26:20) Síbẹ̀, Jèhófà dúró ti Dáfídì. Kì í ṣe pé Jèhófà kó o yọ lọ́wọ́ Sọ́ọ̀lù nìkan ni, ó tún gbà á lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mìíràn. Abájọ tá a fi lè lóye bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára Dáfídì nígbà tó kọrin pé: “Jèhófà ni àpáta gàǹgà mi àti odi agbára mi àti Olùpèsè àsálà fún mi. . . . Ìwọ [Jèhófà] yóò sì fún mi ní apata ìgbàlà rẹ, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ rẹ sì ni ó sọ mí di ńlá.” (2 Sámúẹ́lì 22:2, 36) Dáfídì kì í ṣe ẹni yẹpẹrẹ rárá ní Ísírẹ́lì. Báwo ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ Jèhófà ṣe wá ràn án lọ́wọ́?
Nígbà tí Ìwé Mímọ́ bá sọ pé Jèhófà ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, kì í ṣe ohun tó ń sọ ni pé àwọn nǹkan kan wà tápá Jèhófà ò ká tàbí pé àwọn kan wà tí wọ́n jù ú lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí ànímọ́ dáradára yìí ń fi hàn ni pé àánú àwọn ẹ̀dá èèyàn máa ń ṣe é, ìyẹn àwọn tó ń fi gbogbo ọkàn sapá láti jèrè ojú rere rẹ̀, ó sì máa ń fi àánú yìí hàn sí wọn. Nínú Sáàmù 113:6, 7, a kà á pé: “[Jèhófà] ń rẹ ara rẹ̀ wálẹ̀ láti wo ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, ó ń gbé ẹni rírẹlẹ̀ dìde àní láti inú ekuru.” Ohun tí gbólóhùn náà “rẹ ara rẹ̀ wálẹ̀” túmọ̀ sí ni pé ‘ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ láti wò.’ (Bibeli Mimọ) Nítorí náà, Jèhófà ‘rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀’ láti ọ̀run kó bá a lè kíyè sí Dáfídì tó jẹ́ ẹ̀dá aláìpé àmọ́ tó ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó sì fi gbogbo ọkàn fẹ́ láti sin Ọlọ́run. Èyí ló mú kí ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé: “Jèhófà ga, síbẹ̀síbẹ̀, ó ń rí onírẹ̀lẹ̀.” (Sáàmù 138:6) Ó yẹ kí ọ̀nà tí Jèhófà gbà fi àánú, sùúrù àti ìyọ́nú bá Dáfídì lò jẹ́ ìṣírí fáwọn tó ń sapá láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ni ọba aláṣẹ, tí kò sì sẹ́ni tí ipò rẹ̀ ga tó tirẹ̀ láyé àti lọ́run, síbẹ̀ ó wù ú láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Èyí fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé a lè gbára lé ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, kódà bí a tiẹ̀ wà nínú ìṣòro tó le gan-an. Kò sídìí kankan fún wa láti máa bẹ̀rù pé yóò gbàgbé wa. Nígbà tí Bíbélì ń sọ nípa bí Jèhófà ṣe bá àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì lò, ó sọ ọ́ lọ́nà tó ṣe wẹ́kú pé: “Ẹni tí ó rántí [wọn] nínú ipò rírẹlẹ̀ [wọn]: nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Sáàmù 136:23.
Àwa tá a jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà lọ́jọ́ òní náà lè bára wa nínú ìpọ́njú bíi ti Dáfídì. Àwọn tí kò mọ Ọlọ́run lè máa fi wá ṣẹ̀sín tàbí kí àìsàn máa bá wa fínra tàbí kí èèyàn wa kan kú. Ipò yòówù tá a lè bá ara wa, bí ọkàn wa bá mọ́, a lè gbàdúrà sí Jèhófà, ká bẹ́ẹ̀ pé kó ṣàánú wa. Jèhófà yóò ‘rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀’ láti kíyè sí wa yóò sì tẹ́tí sí àdúrà wa. Onísáàmù náà tí Ọlọ́run mí sí kọ̀wé pé: “Ojú Jèhófà ń bẹ lọ́dọ̀ àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́.” (Sáàmù 34:15) Ǹjẹ́ ríronú lórí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó jẹ́ ànímọ́ fífanimọ́ra tí Jèhófà ní yìí ò wú ọ lórí?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Jèhófà gbọ́ àdúrà Dáfídì, ó ṣe tán láti gbọ́ àdúrà tiwa náà lóde òní