ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 10/1 ojú ìwé 22-25
  • Fífún Jèhófà Ní Ohun Tó Tọ́ Sí I

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fífún Jèhófà Ní Ohun Tó Tọ́ Sí I
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mo Gbé Ìgbésẹ̀ Lórí Ohun Tí Mo Kọ́
  • Wíwàásù Láìka Ìdíwọ́ Sí
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa ní Aidhonochori
  • Inúnibíni Burúkú
  • Ìbísí Láìfi Àtakò Pè
  • Ṣíṣiṣẹ́ Sìn Lábẹ́ Ọwọ́ Ìfẹ́ Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ohun Tí Ó Lé Ní 50 Ọdún ‘Ríré Kọjá Wá’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • “Dípò Wúrà, Mo Rí Dáyámọ́ńdì”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ọmọ Ọ̀rukàn Tí Kò Lẹ́bí Tí Kò Lárá, Rí Baba Onífẹ̀ẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 10/1 ojú ìwé 22-25

Fífún Jèhófà Ní Ohun Tó Tọ́ Sí I

GẸ́GẸ́ BÍ TIMOLEON VASILIOU ṢE SỌ Ọ́

Àwọn ọlọ́pàá mú mi nítorí pé mo ń fi Bíbélì kọ́ni ní abúlé Aidhonochori. Ni wọ́n bá yọ bàtà ẹsẹ̀ mi sọ nù, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi nǹkan lù mí ní àtẹ́lẹsẹ̀. Ìgbà tó pẹ́ tí wọ́n ti ń lù mí, lẹsẹ̀ mi wá kú tìpìrì tí nínà náà kò sì dùn mí mọ́. Kí n tó ṣàlàyé ohun tó fa irú ìwà ìkà yìí, tó jẹ́ pé irú rẹ̀ kò ṣàjèjì nílẹ̀ Gíríìsì nígbà náà, ẹ jẹ́ kí n sọ bí mo ṣe di ẹni tí ń fi Bíbélì kọ́ni.

GẸ́RẸ́ tí wọ́n bí mi lọ́dún 1921 ni ìdílé wa kó lọ sí ìlú Rodholívos, ní àríwá Gíríìsì. Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, ewèlè ọmọ ni mí. Ọmọ ọdún mọ́kànlá ni mí nígbà tí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í mu sìgá. Lẹ́yìn ìyẹn, mo di onímukúmu, mo sì ń ta tẹ́tẹ́, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo alẹ́ ni mò ń lọ sóde àríyá aláriwo. Mo lẹ́bùn orin kíkọ, èyí mú kí ń dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ olórin kan ládùúgbò wa. Ìgbà tí mo fi máa lo ọdún kan níbẹ̀, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí irin iṣẹ́ wọn tí n kò lè lò. Síbẹ̀, láàárín àkókò yẹn, mo ń kàwé gan-an n kò sì fẹ́ ìrẹ́jẹ.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1940, nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì ń lọ lọ́wọ́, wọ́n pe ẹgbẹ́ wa láti wá ṣeré níbi ìsìnkú ọmọbìnrin kékeré kan. Gbogbo ìbátan àtàwọn ọ̀rẹ́ ló sunkún àsun-ùn-dabọ̀ níbi ibojì náà. Bí wọn ò ṣe nírètí kankan ló wá kó ìdààmú ńláǹlà bá mi. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kàyéfì pé, ‘Èé ṣe tí a fi ń kú? Ṣé wíwà láàyè fún sáà díẹ̀ yìí náà ni òpin gbogbo ìrìn àjò ẹ̀dá, àbí ìrètí mìíràn tún ṣì wà? Níbo ni mo ti lè rí ìdáhùn?’

Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn ni mo rí ẹ̀dà Májẹ̀mú Tuntun kan ni ibi tí mò ń kówèé sí nínú ilé mi. Mo yọ ọ́ jáde, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í kà á. Ìgbà tí mo ka ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Mátíù 24:7 nípa bí ogun tí yóò wà káàkiri ṣe máa jẹ́ apá kan àmì wíwà níhìn-ín rẹ̀, ni mo wá lóye pé àkókò tiwa yìí ni àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ń tọ́ka sí. Ní àwọn ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, mo ka ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì yìí lọ́pọ̀ ìgbà.

Lẹ́yìn náà, ní December 1940, mo lọ kí ìdílé kan tó wà nítòsí—obìnrin opó kan àti àwọn ọmọ rẹ̀ márùn-ún. Mo rí pé ọ̀pọ̀ ìwé kékeré ni wọ́n kó jọ síbi tí wọ́n ń kówèé sí, mo wá rí ọ̀kan láàárín wọn tí wọ́n pé àkọlé rẹ̀ ní A Desirable Government, tí Watch Tower Bible and Tract Society tẹ̀ jáde. Mo lọ síbi ìkówèésí náà, mo sì ka ìwé kékeré náà láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin. Ohun tí mo kà wá jẹ́ kó túbọ̀ dá mi lójú pé lóòótọ́ là ń gbé ní àkókò tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” àti pé Jèhófà Ọlọ́run yóò mú ètò àwọn nǹkan yìí wá sópin láìpẹ́, yóò wá fi ayé tuntun òdodo rọ́pò rẹ̀.—2 Tímótì 3:1-5; 2 Pétérù 3:13.

Ohun tó wọ̀ mí lọ́kàn jù lọ ni ẹ̀rí tí Ìwé Mímọ́ fúnni pé àwọn olóòótọ́ yóò wà láàyè títí láé nínú párádísè kan lórí ilẹ̀ ayé, àti pé ìyà àti ikú kò ní í sí mọ́ nínú ayé tuntun yẹn, èyí tí yóò wà lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run. (Sáàmù 37:9-11, 29; Ìṣípayá 21:3, 4) Bí mo ṣe ń kàwé náà ni mo ń fàdúrà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún àwọn nǹkan wọ̀nyí, tí mo sì ń sọ pé kó fi àwọn nǹkan tó ń béèrè hàn mí. Ó wá hàn gbangba sí mi pé Jèhófà Ọlọ́run lẹni tó yẹ kí n fi tọkàntọkàn sìn.—Mátíù 22:37.

Mo Gbé Ìgbésẹ̀ Lórí Ohun Tí Mo Kọ́

Láti ìgbà yẹn lọ ni mo ti ṣíwọ́ sìgá mímu, tí n kò mutí yó mọ́, tí mo sì jáwọ́ nínú tẹ́tẹ́ títa. Mo wá kó àwọn ọmọ márààrún tí opó náà bí àtàwọn àbúrò mi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta jọ, mo sì ṣàlàyé ohun tí mo kọ́ nínú ìwé kékeré náà fún wọn. Kò pẹ́ táa fi bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ìwọ̀nba ohun táa mọ̀ fún àwọn èèyàn. A wá di ẹni tí gbogbo ará ìlú mọ̀ sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò bá Ẹlẹ́rìí kankan pàdé rí. Àtìbẹ̀rẹ̀ yẹn ni mo ti ń ya ohun tó ju ọgọ́rùn-ún wákàtí sọ́tọ̀ lóṣooṣù láti sọ àwọn nǹkan àgbàyanu tí mo ti kọ́ fún àwọn ẹlòmíràn.

Bí àlùfáà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Gíríìkì tó wà ládùúgbò wá ṣe gbọ̀nà ilé olórí ìlú lọ nìyẹn tó lọ fẹjọ́ wa sùn. Àmọ́, lọ́jọ́ díẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn, táwa ò tiẹ̀ mọ̀ rárá, ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí rí ẹṣin kan tó sọ nù, ó sì fà á lọ fún àwọn tó ni í. Nítorí irú ìṣòtítọ́ yẹn, olórí ìlú náà bọ̀wọ̀ fún àwọn Ẹlẹ́rìí, ó sì kọ̀ láti fetí sí ohun tí àlùfáà náà ń sọ.

Bí mo ṣe ń jẹ́rìí ní ọjà lọ́jọ́ kan, ní nǹkan bí October 1941, ni ẹnì kan sọ̀rọ̀ nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń gbé nílùú kan tó wà nítòsí. Ọlọ́pàá ni ẹni náà tẹ́lẹ̀, Christos Triantafillou sì lorúkọ rẹ̀. Bí mo ṣe lọ rí i nìyẹn, tí mo wá gbọ́ pé ó ti di Ẹlẹ́rìí láti ọdún 1932. Ẹ ò lè mọ bí inú mi ti dùn tó nígbà tó kó ọ̀pọ̀ ògbólógbòó ìwé Watch Tower Society fún mi! Ìwọ̀nyí ràn mí lọ́wọ́ gan-an láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.

Ní ọdún 1943, mo fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi sí Ọlọ́run hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi. Lákòókò yẹn, mo ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láwọn abúlé mẹ́ta tó wà nítòsí—Dhravískos, Palaeokomi, àti Mavrolofos. Ìwé Duru Ọlọrun ni mò ń lò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, mo láǹfààní àtirí pé a dá ìjọ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó jẹ́ ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ lágbègbè yìí.

Wíwàásù Láìka Ìdíwọ́ Sí

Lọ́dún 1944, Gíríìsì bọ́ lọ́wọ́ ogun tí Jámánì ń bá a jà, kò pẹ́ lẹ́yìn náà, mo láǹfààní láti máa bá ọ́fíìsì ẹ̀ka Watch Tower Society tó wà ní Áténì sọ̀rọ̀. Ọ́fíìsì ẹ̀ka náà pè mí láti wá máa wàásù ní ìpínlẹ̀ kan tó jẹ́ pé bóyá la fi rí ẹnì kan tó tí ì gbọ́ ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà níbẹ̀ rí. Nígba tí mo débẹ̀, mo kọ́kọ́ fi oṣù mẹ́ta ṣiṣẹ́ nínú oko kan níbẹ̀, mo sì lo àwọn oṣù tó kù nínú ọdún yẹn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.

Mo láyọ̀ lọ́dún yẹn láti rí i pé màmá mi ṣe ìrìbọmi, bákan náà ni opó yẹn àtàwọn ọmọ ẹ̀, àbíkẹ́yìn rẹ̀ obìnrin, Marianthi, wá ṣèrìbọmi tiẹ̀ ní 1943, ó sì di ayà mi ọ̀wọ́n ní November ọdún yẹn. Ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn náà, ìyẹn lọ́dún 1974, baba mi náà di Ẹlẹ́rìí tó ṣe ìrìbọmi.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1945, a gba ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ ti a kọ́kọ́ ṣàdàkọ rẹ̀ láti ẹ̀ka ọ́fíìsì. Àpilẹ̀kọ tí wọ́n gbé jáde lákànṣe nínú rẹ̀ ní wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní “Ẹ Lọ, Kí Ẹ Sì Sọ Orilẹ̀-Èdè Gbogbo Di Ọmọ Ẹ̀yìn.” (Mátíù 28:19, The Emphatic Diaglott) Kíá ni èmi àti Marianthi filé wa sílẹ̀ táa lọ ṣiṣẹ́ láwọn ìpínlẹ̀ tó jìnnà réré lápá ìlà oòrùn Odò Strymon. Lẹ́yìn náà làwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn wá dara pọ̀ mọ́ wa.

Ọ̀pọ̀ ìgbà la ń fẹsẹ̀ lásán rin dé abúlé kan, tó sì jẹ́ pé àwọn àfonífojì tóóró, tó dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́, tí ṣẹ́lẹ̀rú ti ń ṣàn àti àwọn òkè ńláńlà, ni ọ̀pọ̀ kìlómítà tí a ó gbà kọjá. A ń ṣe èyí kí bàtà wa má bàá tètè jẹ, tórí kò sí òmíràn tí a ó wọ̀ bí wọ́n bá gbó. Láàárín ọdún 1946 sí 1949, ogun abẹ́lé ń jà ní Gíríìsì, ó sì léwu gan-an láti rìnrìn àjò. Kò ṣàjèjì rárá láti rí àwọn òkú dígbadìgba lẹ́bàá ọ̀nà.

Dípò tí a ó fi jẹ́ kí àwọn ìṣòro wọ̀nyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa, ńṣe la ń bá iṣẹ́ ìsìn wa nìṣó tìtaratìtara. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń ṣe mí bíi ti onísáàmù náà tó kọ̀wé pé: “Bí mo tilẹ̀ ń rìn ní àfonífojì ibú òjìji, èmi kò bẹ̀rù ohun búburú kankan, nítorí tí ìwọ wà pẹ̀lú mi; ọ̀pá rẹ àti ọ̀pá ìdaran rẹ ni àwọn nǹkan tí ń tù mí nínú.” (Sáàmù 23:4) Láàárín àkókò yìí, ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ la kì í sí nílé, mo sì máa ń lo àádọ́ta lé nígba wákàtí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà lóṣù nígbà mìíràn.

Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa ní Aidhonochori

Ọ̀kan nínú àwọn abúlé táa dé ní 1946 ni Aidhonochori, ṣóńṣó orí òkè kan ló wà. Ibẹ̀ lá ti pàdé ọkùnrin kan tó sọ fún wa pé àwọn ọkùnrin méjì kan wà lábúlé náà tí wọ́n fẹ́ gbọ́ ìhìn iṣẹ́ Bíbélì. Àmọ́, nítorí ẹ̀rù àwọn aládùúgbò, ọkùnrin náà kò fẹ́ darí wa sọ́dọ̀ wọn. Bó ti wù kó rí, a wá ilé wọn kàn, wọ́n sì gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀. Ká má fàrọ̀ gùn, láàárín ìṣẹ́jú díẹ̀, àwọn ènìyàn ti kún inú pálọ̀ náà bámúbámú! Àfàìmọ̀ ni wọn ò fi ní jẹ́ àwọn ìbátan tàbí àwọn ọ̀rẹ́ tó sún mọ́ wọn dáadáa. Ó yà mí lẹ́nu gan-an láti rí i bí wọ́n ṣe fara balẹ̀ jókòó tí wọ́n sì ń fetí sí wa. Kò pẹ́ táa fi wá mọ̀ pé ó pẹ́ tí wọ́n ti ń fẹ́ láti rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ṣùgbọ́n kò sí ọ̀kankan lágbègbè yẹn lákòókò tí Jámánì ṣígun débẹ̀. Kí ló mú wọn ní irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀?

Gbajúmọ̀ làwọn olórí ìdílé méjèèjì náà jẹ́ nínú Ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì tó wà ládùúgbò, wọ́n sì ti fi èrò Kọ́múníìsì sọ́kàn àwọn ènìyàn wọn. Àmọ́, ẹ̀dà ìwé Government, tí Watch Tower Society tẹ̀ jáde bọ́ sí wọn lọ́wọ́. Ìgbà tí wọ́n kà á tán ni wọ́n rì i gbangba pé ìrètí kan ṣoṣo fún ìṣàkóso pípé tó sì jẹ́ ìṣàkóso òdodo ni Ìjọba Ọlọ́run.

A bá àwọn ọkùnrin wọ̀nyí àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn sọ̀rọ̀ títí di ọ̀gànjọ́ òru. Bí a ṣe fi Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè wọ́n tẹ́ wọn lọ́rùn gan-an ni. Àmọ́, kò pẹ́ lẹ́yìn náà ti ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì tó wà lábúlé náà dìtẹ̀ láti pa mí nítorí wọ́n gbà pé èmi ni mo yí àwọn ọ̀gá wọ́n tẹ́lẹ̀ rí padà. Kẹ́ẹ sì wá wò ó o, ọkùnrin tó sọ fún wa pé àwọn kan wà lábúlé wa tí wọ́n fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa, wà níbẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó tẹ̀ síwájú nínú ìmọ̀ Bíbélì, ó ṣe ìrìbọmi, ó sì wá di Kristẹni alàgbà níkẹyìn.

Inúnibíni Burúkú

Kò pẹ́ táa bá àwọn tí wọ́n jẹ́ Kọ́múníìsì tẹ́lẹ̀ wọ̀nyí pàdé tí àwọn ọlọ́pàá méjì fi já wọlé, a sì ń ṣèpàdé lọ́wọ́. Ni wọ́n bá na ìbọn sí àwa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, pé táa bá sá, iná yóò dáhùn lára wa, bí wọ́n ṣe kó wa lọ ságọ̀ọ́ wọn nìyẹn. Ibẹ̀ ni ọ̀gá ọlọ́pàá tó wà níbẹ̀, tó jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ fún àwọn àlùfáà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Gíríìkì, wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀kò ọ̀rọ̀ lù wá. Níkẹyìn, ó béèrè pé, “Tóò, ìyà wo ni kí n fi jẹ yín?”

Gbogbo àwọn ọlọ́pàá tó dúró sẹ́yìn wa pariwo lẹ́ẹ̀kan náà pé: “Ẹ jẹ́ ka fi lílù dárà sí wọn lára!”

Ilẹ̀ ti wá ṣú gan-an nígbà yẹn. Làwọn ọlọ́pàá náà bá tì wá mọ́ àjà ilẹ̀, ni wọ́n bá lọ sílé ọtí tó wà ní yàrá kejì sí tiwa. Nígbà tí wọ́n mutí yó kẹ́ri tán, wọ́n padà wá, wọ́n sì mú mi lọ sórí òkè.

Bí mo ṣe rí bí wọ́n ṣe ń ṣe, mo mọ̀ pé ìgbàkígbà ni wọ́n lè pa mí. Mo wá gbàdúrà sí Ọlọ́run láti fún mi lókun kí n lè fara da ìyà èyíkéyìí tí wọ́n bá fi jẹ mí. Gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ níbẹ̀rẹ̀ ìtàn yìí, wọ́n yọ kóńdó, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kó o bo àtẹ́lẹsẹ̀ mi. Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni wọ́n lù mí ní gbogbo ara, tí wọ́n sì tún taari mi padà sínú àjà ilẹ̀ náà. Ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n mú ẹlòmíràn jáde tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í lù ú.

Bíyẹn ṣe ń lọ lọ́wọ́, mo sáré lo àǹfààní díẹ̀ tí mo ní láti mú kí àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí méjì tó kù gbára dì de ìdánwò tó wà níwájú wọn. Àmọ́, àwọn ọlọ́pàá náà tún mú mi padà sórí òkè. Wọ́n bọ́ gbogbo aṣọ lọ́rùn mi, àwọn márààrún sì lù mí fún nǹkan bíi wákàtí kan, tí wọ́n sì ń fi bàtà sójà tó wà lẹ́sẹ̀ wọn tẹ̀ mí lórí. Ìgbà tí wọ́n ṣèyẹn títí, wọ́n tún jù mi sísàlẹ̀, ibẹ̀ ni mo dákú sí fún wákàtí méjìlá.

Nígbà tí wọ́n wá fi wá sílẹ̀ níkẹyìn, ìdílé kan lábúlé yẹn gbà wá sílé di ọjọ́ kejì, wọ́n sì tọ́jú wa. Ọjọ́ kejì la fi ibẹ̀ sílẹ̀ táa sì padà sílé. Lílù tí wọ́n lù wá mú kó rẹ̀ wá tẹnutẹnu débi pé ìrìn àjò táa máa ń fi wákàtí méjì rìn gbà wá ní wákàtí mẹ́jọ gbáko. Nítorí lílù tí wọ́n lù mí, gúdugùdu ni gbogbo ara mi rí, débi pé agbára káká ni Marianthi fi dá mi mọ̀.

Ìbísí Láìfi Àtakò Pè

Nígbà tí ogun náà ṣì ń lọ lọ́wọ́ ni 1949, a kó lọ sí Tẹsalóníkà. Wọ́n yàn mí láti sìn bí olùrànlọ́wọ́ ìránṣẹ́ ìjọ ní ọ̀kan lára àwọn ìjọ mẹ́rin tó wà nílùú náà. Lẹ́yìn ọdún kan, ìjọ náà pọ̀ sí i débi pé a ní láti dá òmíràn sílẹ̀, wọ́n sì fi mí ṣe ìránṣẹ́ ìjọ, tàbí alábòójútó olùṣalága. Ìgbà tó tún fi máa tó ọdún kan sí i, ìjọ tuntun náà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po méjì iye àwọn tó bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, a sì tún ní láti dá ìjọ mìíràn sílẹ̀!

Inú àwọn alátakò kò dùn sí ìbísí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ní ní Tẹsalóníkà. Ṣe ni mo ṣàdédé tibi iṣẹ́ dé lọ́jọ́ kan, lọ́dún 1952, ni mo bá rí i pé wọ́n ti jó ilé wa kanlẹ̀. Díẹ̀ báyìí lọlọ́run fi yọ Marianthi. Nígbà táa dépàdé lálẹ́ ọjọ́ yẹn, ṣe la bẹ̀rẹ̀ sí ṣàlàyé ohun tó fà á táa fi wọ aṣọ tó dọ̀tí wá—gbogbo nǹkan tó kù pátá la ti pàdánù. Àwọn Kristẹni arákùnrin wa bá wa kẹ́dùn gan-an ni, wọ́n sì ràn wá lọ́wọ́.

Ní 1961, wọ́n yàn mí sí iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò, tí mo ń bẹ ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wò lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti fún àwọn arákùnrin lókun nípa tẹ̀mí. Ní ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n tó tẹ̀ lé e, èmi àti Marianthi bẹ àwọn àyíká àti àgbègbè tó wà ní Makedóníà, Thrace, àti Thessaly wò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé láti ọdún 1948 ni Marianthi, olólùfẹ̀ mi, kò ti ríran mọ́, ó fi tìgboyà-tìgboyà sìn pẹ̀lú mi, ó sì fara da ọ̀pọ̀ ìdánwò ìgbàgbọ́. Wọ́n mú òun náà, wọ́n wọ́ ọ lọ sílé ẹjọ́, wọ́n sì fi í sẹ́wọ̀n lọ́pọ̀ ìgbà. Nígbà tó yá, ara rẹ̀ ò le mọ́, ó sì kú ní 1988 lẹ́yìn tó ti bá àrùn jẹjẹrẹ yí fún ìgbà pípẹ́.

Lọ́dún yẹn kan náà, wọ́n yàn mí láti sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ni Tẹsalóníkà. Ní báyìí, lẹ́yìn ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta tí mo ti ń sin Jèhófà, mo ṣì lè ṣe iṣẹ́ àṣekára, kí ń sì kópa nínú gbogbo apá iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Nígbà mìíràn, àwọn olùfìfẹ́hàn tí mo ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́sẹ̀ kọ̀ọ̀kan máa ń tó ogún.

Mo ti wá mọ̀ ní tòótọ́ pé, ìbẹ̀rẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ tó ga la wà yìí, ètò ẹ̀kọ́ náà yóò sì máa bá a nìṣó títí tí a óò fi dé inú ayé tuntun Jèhófà, yóò sì tún wà fún ẹgbẹ̀rún ọdún sí i. Síbẹ̀, mo rò pé kì í ṣe àkókò yìí ló yẹ ká dẹwọ́ nínú ohun tí à ń ṣe, kí á máa fònídónìí-fọ̀ladọ́la, tàbí kí a máa fi àkókò wa tẹ́ ìfẹ́ ti ara wa lọ́rùn. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé ó ràn mí lọ́wọ́ láti mú ìlérí tí mo ṣe lákọ̀ọ́kọ́ pàá ṣẹ nítorí ní ti tòótọ́, Jèhófà ló yẹ kí a máa fi tọkàntọkàn jọ́sìn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Ibi tí mo ti ń sọ àsọyé nígbà tí wọ́n fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Èmi àti Marianthi, aya mi

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́