ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 11/1 ojú ìwé 22-27
  • Ohun Tí Ó Lé Ní 50 Ọdún ‘Ríré Kọjá Wá’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tí Ó Lé Ní 50 Ọdún ‘Ríré Kọjá Wá’
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Mi
  • Lábẹ́ Ìfàṣẹ-Ọba-Múni
  • Ẹjọ́ Ikú
  • Ìgbòkègbodò Ẹ̀yìn Ogun
  • N Kò Dá Wà Mọ́
  • Ìbùkún Dídọ́ṣọ̀ Láti Ọ̀dọ̀ Jèhófà
  • Ṣíṣiṣẹ́ Sìn Lábẹ́ Ọwọ́ Ìfẹ́ Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Fífún Jèhófà Ní Ohun Tó Tọ́ Sí I
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Fífi Sùúrù Dúró De Jèhófà Láti Ìgbà Èwe Mi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Èmi Ògbóǹkangí Olóṣèlú Tẹ́lẹ̀ Di Kristẹni Tí Kò Dá Sí Ìṣèlú Mọ́
    Jí!—2002
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 11/1 ojú ìwé 22-27

Ohun Tí Ó Lé Ní 50 Ọdún ‘Ríré Kọjá Wá’

GẸ́GẸ́ BÍ EMMANUEL PATERAKIS TI SỌ

Ní ọ̀rúndún 19 sẹ́yìn, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rí ìkésíni ṣíṣàjèjì kan gbà pé: “Ré kọjá wá sí Makedóníà kí o sì ràn wá lọ́wọ́.” Pọ́ọ̀lù fínnúfíndọ̀ tẹ́wọ́ gba àǹfààní tuntun yìí láti “polongo ìhìn rere.” (Ìṣe 16:9, 10) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìkésíni tí mo gbà kò tí ì pẹ́ tó ìyẹn, síbẹ̀ ó ti lé ní 50 ọdún sẹ́yìn, tí mo gbà láti “ré kọjá wá” sí àwọn agbègbè ìpínlẹ̀ tuntun pẹ̀lú ẹ̀mí Aísáyà 6:8 pé: “Èmi nìí; rán mi.” Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìrìn àjò mi fún mi ní orúkọ ìnagijẹ náà, Arìnrìn Àjò Afẹ́ Títí Lọ Kánrin, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn ìgbòkègbodò mi fi jọ ìrìn àjò afẹ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, tí mo bá dé yàrá hòtẹ́ẹ̀lì mi, n óò kúnlẹ̀ lórí eékún mi, n óò sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ààbò rẹ̀ lórí mi.

ABÍ mi ní January 16, 1916, ní Hierápetra, ní Kírétè, sínú ìdílé onífọkànsìn gidigidi nínú ìsìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì. Láti ìgbà kékeré mi, Màmá máa ń mú èmi àti àwọn arábìnrin mi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ní ọjọ́ Sunday. Ní ti bàbá mi, ó tẹ́ ẹ lọ́rùn jù láti jókòó sílé, kí ó sì máa ka Bíbélì. Mo fẹ́ràn bàbá mi púpọ̀—aláìlábòsí ẹ̀dá, ẹni rere, àti adáríjini ni—ikú rẹ̀ nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án sì gbò mí gidigidi.

Mo rántí pé nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún, mo ka àkọlé kan ní ilé ẹ̀kọ́, tí ó kà pé: “Ohun gbogbo tí ó yí wa ká ń polongo pé Ọlọ́run ń bẹ.” Bí mo ṣe ń dàgbà sí i, èyí túbọ̀ dá mi lójú sí i. Nípa báyìí, nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún 11, mo yàn láti kọ àròkọ kan, tí mo fi Orin Dáfídì 104:24 ṣe ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Olúwa iṣẹ́ rẹ ti pọ̀ tó! nínú ọgbọ́n ni ìwọ ṣe gbogbo wọn: ayé kún fún ẹ̀dá rẹ.” Àwọn àgbàyanu ìṣẹ̀dá fà mí lọ́kàn mọ́ra, kódà àwọn ohun kékeré bí hóró irúgbìn tí ó ní ìyẹ́ kéékèèké, kí afẹ́fẹ́ baà lè gbé wọn lọ kúrò lábẹ́ òjìji igi tí ó mú èso wọn jáde. Ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀ lé èyí tí mo fi àròkọ mi sílẹ̀, olùkọ́ mi kà á sétígbọ̀ọ́ gbogbo kíláàsì, lẹ́yìn náà ó kà á fún gbogbo ilé ẹ̀kọ́. Ní àkókò náà, àwọn olùkọ́ ń ta ko èròǹgbà ìjọba Kọ́múníìsì, inú wọn sì dùn láti gbọ́ ìgbèjà mi pé Ọlọ́run ń bẹ. Ní tèmi, inú mi ṣáà dùn láti sọ èrò ìgbàgbọ́ mi nínú Ẹlẹ́dàá jáde ni.

Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Mi

Bí mo ṣe ṣalábàápàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní kùtùkùtù àwọn ọdún 1930 ṣì jí pépé nínú ọpọlọ mi. Emmanuel Lionoudakis ti ń wàásù ní gbogbo ìlú àti ìletò Kírétè. Mo tẹ́wọ́ gba ọ̀pọ̀ ìwé pẹlẹbẹ lọ́wọ́ rẹ̀, àmọ́, ọ̀kan tí a pè ní Where Are the Dead? ni ó gba àfiyèsí mi jù lọ. Ẹ̀rù ikú máa ń bà mí tó bẹ́ẹ̀ tí ń kò fi lè wọ inú yàrá tí bàbà mi kú sí. Bí mo ti ń ka ìwé pẹlẹbẹ yìí ní àkàtúnkà, tí mo sì mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa ipò tí àwọn òkú wà, mo nímọ̀lára pé ìbẹ̀rù mi tí ó jẹ́ ti ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ti fò lọ.

Lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń bẹ ìlú wa wò, wọn sì máa ń mú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ sí i wá fún mi láti kà. Díẹ̀ díẹ̀, òye mi nínú Ìwé Mímọ́ ń gbèèrú, àmọ́, mo ń bá lílọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì nìṣó. Ṣùgbọ́n, ìwé náà Idande, ṣe ìyípadà pàtàkì nínú ìgbésí ayé mi. Ó fi ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín ètò àjọ Jèhófà àti ti Sátánì hàn kedere. Láti ìgbà yìí lọ, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ èyíkéyìí láti ọwọ́ Watch Tower Society tí ọwọ́ mi lè tẹ̀. Níwọ̀n bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wà lábẹ́ ìfòfindè ní ilẹ̀ Gíríìsì, mò ń kẹ́kọ̀ọ́ ní bòókẹ́lẹ́ lóru. Síbẹ̀síbẹ̀, ohun tí mo ń kọ́ kà mi lára tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí ǹ kò fi lè da ara mi lẹ́kun sísọ nípa rẹ̀ fún ẹni gbogbo. Kò pẹ́ púpọ̀ tí àwọn ọlọ́pàá fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ́ mi lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀, ní bíbẹ̀ mí wò déédéé ní gbogbo wákàtí ọ̀sán àti òru láti wá ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́.

Ní ọdún 1936, mo lọ sí ìpàdé fún ìgbà àkọ́kọ́, 120 kìlómítà sí wa, ní Iráklion. Mo láyọ̀ púpọ̀ láti bá àwọn Ẹlẹ́rìí pàdé. Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn jẹ́ tálákà, tí ọ̀pọ̀ jù lọ jẹ́ àgbẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n ṣèrànwọ́ láti mú un dá mi lójú pé òtítọ́ rèé. Lójú ẹsẹ̀ ni mo ṣe ìyàsímímọ́ mi fún Jèhófà.

Ìrìbọmi mi jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí n kò lè gbàgbé láé. Ní òru ọjọ́ kan ní ọdún 1938, nínú òkùnkùn biribiri, Arákùnrin Lionoudakis mú èmi àti méjì nínú àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi lọ sí etíkun. Lẹ́yìn gbígbàdúrà, ó rì wá bọ inú omi.

Lábẹ́ Ìfàṣẹ-Ọba-Múni

Láìsọ àsọdùn, ìgbà àkọ́kọ́ pàá tí mo jáde lọ fún wíwàásù jẹ́ mánigbàgbé. Mo pàdé ọmọ kíláàsì mi àtijọ́ kan tí ó ti di àlùfáà, a sì ní ìjíròrò tí ó jíire pa pọ̀. Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn náà, ó ṣàlàyé pé ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ bíṣọ́ọ̀bù, òún gbọ́dọ̀ jẹ́ kí a fàṣẹ ọba mú mi. Nígbà tí a ṣì dúró nínú ọ́fíìsì olórí ìlú kí ọlọ́pàá fi dé láti ìletò kejì, èrò ti pé jọ síta. Nítorí náà, mo mú Bíbélì Májẹ̀mú Tuntun Lédè Gíríìkì tí ó wà ní ọ́fíìsì náà, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àsọyé lórí Mátíù orí 24. Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn ènìyàn náà kò fẹ́ gbọ́, ṣùgbọ́n àlùfáà náà dà sí i. Ó wí pé: “Ẹ jẹ́ kí ó sọ̀rọ̀. Bíbélì wa kúkú ni.” Mo sọ̀rọ̀ fún wákàtí kan àti ààbọ̀. Nípa báyìí, ọjọ́ tí mo kọ́kọ́ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ni mo kọ́kọ́ sọ àwíyé fún gbogbo ènìyàn. Níwọ̀n bí ọlọ́pàá kò tí ì dé títí mo fi parí ọ̀rọ̀ mi, olórí ìlú àti àlùfáà pinnu pé kí àwùjọ àwọn ọkùnrin fipá lé mi jáde kúrò ni ìlú náà. Ní ibi ìṣẹ́kọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ lójú ọ̀nà, mo sáré tete bí mo ṣe lè sáré tó, ki òkò tí wọn ń jù má baà bà mí.

Ní ọjọ́ kejì, ọlọ́pàá méjì tí bíṣọ́ọ̀bù tẹ̀ lé lẹ́yìn fàṣẹ ọba mú mi lẹ́nu iṣẹ́. Ní àgọ́ ọlọ́pàá, ó ṣeé ṣe fún mi láti jẹ́rìí fún wọn láti inú Bíbélì, àmọ́, níwọ̀n bí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi kò ti ní òǹtẹ̀ bíṣọ́ọ̀bù tí òfin béèrè fún, a fi ẹ̀sùn ìsọnidaláwọ̀ṣe àti pípín ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí kò bófin mu kàn mí. A dà mi sílẹ̀ kí ìgbẹ́jọ́ fi bẹ̀rẹ̀.

Ìgbẹ́jọ́ mi bẹ̀rẹ̀ ní oṣù kan lẹ́yìn náà. Nínú ìgbèjà mi, mo fi hàn pé kò sí ohun tí mo ṣe ju pé mo ń ṣègbọràn sí àṣẹ Kristi láti wàásù. (Mátíù 28:19, 20) Adájọ́ náà sọ lọ́nà tí kò bára dé pé: “Ọmọ mi, a kan Ẹni tí ó pàṣẹ yẹn gan-an mọ́ àgbélébùú ni. Ó dùn mí pé, n kò ní ọlá àṣẹ láti fi irú ìyà kan náà jẹ ọ́.” Ṣùgbọ́n, amòfin kan tí ń kò mọ̀ rí dìde dúró láti gbèjà mi, ní sísọ pé, bí èròǹgbà ìjọba Kọ́múníìsì àti àìgbọlọ́rungbọ́ ti gbilẹ̀ káàkiri tó, ó yẹ kí ilé ẹjọ́ náà lè dunnú pé irú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin báyìí wà, tí wọ́n ṣe tán láti gbèjà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà, ó wá bá mi, ó sì bá mi yọ̀ gidigidi fún ìgbèjà mi tí mo kọ, èyí tí ó wà nínú fáìlì mi. Nítorí pé bí mo ṣe jẹ́ ọ̀dọ́ wú u lórí, ó yọ̀ọ̀da láti gbèjà mi lọ́fẹ̀ẹ́. Dípò ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́ta ó kéré tán, a rán mi ní ẹ̀wọ̀n ọjọ́ mẹ́wàá péré àti 300-drachma owó ìtanràn. Irú àtakò bẹ́ẹ̀ wulẹ̀ fún mi lókun sí i ni láti pinnu láìyẹsẹ̀ láti ṣiṣẹ́ sin Jèhófà àti láti gbèjà òtítọ́.

Ní àkókò míràn, nígbà tí a fàṣẹ ọba mú mi, adájọ́ náà ṣàkíyèsí bí ó ṣe rọ̀ mí lọ́rùn tó láti yan ẹsẹ Bíbélì. Ó sọ fún bíṣọ́ọ̀bù pé kí ó fi ọ́fíìsì òun sílẹ̀, ní sísọ pé: “Ó ti ṣe iṣẹ́ rẹ. Èmi yóò bójú tó o.” Lẹ́yìn náà, ó mú Bíbélì rẹ̀, a sì sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run ní gbogbo ọ̀sán. Irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ fún mi níṣìírí láti máa bá a nìṣó láìka ìṣòro sí.

Ẹjọ́ Ikú

Ní ọdún 1940, a pè mí fún iṣẹ́ ológun, mo sì kọ lẹ́tà kan ní ṣíṣàlàyé ìdí tí n kò fi lè gbà láti di ológun. Ọjọ́ méjì lẹ́yìn náà, a fàṣẹ ọba mú mi, àwọn ọlọ́pàá sì lù mí bí ẹni lu bàrà. Lẹ́yìn náà, a rán mi lọ sí ojú ogun ní Albania, níbi tí mo ti fara hàn níwájú ilé ẹjọ́ àwọn ọmọ ogun nítorí pé mo kọ̀ láti jà. Àwọn aláṣẹ ológun sọ fún mi pé, àwọn kò fẹ́ mọ̀ bóyá mo jàre tàbí mo jẹ̀bi, kìkì ohun tí ó jẹ àwọn lógún ni ipa tí àpẹẹrẹ mi yóò ní lórí àwọn sójà. A dájọ́ ikú fún mi, àmọ́, nítorí ìkù-díẹ̀-káà-tó òfin kan, ìtura ńláǹlà ni ó jẹ́ fún mi, nígbà tí a yí ìdájọ́ ikú yìí padà sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára. Mo lo ìwọ̀nba oṣù mélòó kan tí ó tẹ̀ lé e nínú ìgbésí ayé mi ní ọgbà ẹ̀wọ̀n àwọn ọmọ ogun ní ilẹ̀ Gíríìsì lábẹ́ ipò tí ó nira gidigidi, èyí tí ràbàràbà rẹ̀ ṣì wà lára mi síbẹ̀.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọgbà ẹ̀wọ̀n kò dá mi lẹ́kun wíwàásù. Àgbẹdọ̀! Ó rọrùn láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò, níwọ̀n bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti ń ṣe kàyéfì ohun tó mú ará ìlú dé ọgbà ẹ̀wọ̀n àwọn ọmọ ogun. Ọ̀kan nínú irú àwọn ìjíròrò wọ̀nyí pẹ̀lú ọ̀dọ́mọkùnrin olóòótọ́ ọkàn kan yọrí sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú àgbàlá ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ọdún 38 lẹ́yìn náà, mo bá ọkùnrin yìí pàdé lẹ́ẹ̀kan sí i ní àpéjọ kan. Ó ti tẹ́wọ́ gba òtítọ́, ó sì ti ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó ìjọ ní erékùṣù Lefkás.

Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Hitler gbé sùnmọ̀mí wọ Yugoslavia ní ọdún 1941, a kó wa lọ sí ibi tí ó jìnnà gan-an ní ìhà gúúsù, ní Preveza. Nígbà ìrìn àjò náà, àwọn ará Germany tí ń ju bọ́m̀bù kọ lu àwùjọ àwa tí ń rìnrìn àjò, a kò sì fún àwa ẹlẹ́wọ̀n ní oúnjẹ. Nígbà tí búrẹ́dì kékeré tí mo ní tán, mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ rẹ ni pé kí ebí pa mí kú lẹ́yìn tí o ti yọ mí nínú ìdájọ́ ikú, jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ di ṣíṣe.”

Ní ọjọ́ kejì, ọ̀gágun kan pè mí sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan nígbà tí wọ́n ń pe orúkọ, lẹ́yìn tí ó sì ti mọ ibi tí mo ti wá, àti ẹni tí àwọn òbí mí jẹ́, àti ìdí tí mo fi wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n, ó ní kí n tẹ̀ lé òun. Ó mú mi lọ sí ilé ìgbafẹ́ àwọn ológun, tí ó wà ní ìgboro, ó sì ní kí n jókòó sídìí tábìlì kan tí búrẹ́dì, wàràkàṣì, àti àgùntàn díndín wà lórí rẹ̀, ó ní kí n máa fi ṣara rindi. Ṣùgbọ́n mo ṣàlàyé pé níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé àwọn 60 ẹlẹ́wọ̀n wà tí wọn kò ní ohunkóhun láti jẹ, ẹ̀rí ọkàn mi kì yóò jẹ́ kí n jẹun. Ọ̀gágun náà fèsì pé: “N kò lè bọ́ gbogbo ènìyàn! Bàbá rẹ lawọ́ sí mi púpọ̀. Mo ní ojúṣe ti ìwà rere tí mo gbọ́dọ̀ fi hàn sí ọ, ṣùgbọ́n kì í ṣe sí àwọn ẹlòmíràn.” Mo fèsì pé: “Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, èmi yóò padà sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ni.” Ó ronú fún ìgbà díẹ̀, ó sì fún mi ní àpò kan láti kó oúnjẹ tí mo bá lè kó sínú rẹ̀.

Nígbà tí mo padà dé ọgbà ẹ̀wọ̀n, mo gbé àpò náà kalẹ̀, mo sì wí pé: “Ẹ̀yin èèyàn, tiyín nìyí o.” Ó ṣe kòńgẹ́ pé, ní ìrọ̀lẹ́ tí ó ṣáájú ọjọ́ yẹn, a ti fẹ̀sùn kàn mí pé, èmi ni okùnfà ìjìyà àwọn ẹlẹ́wọ̀n yòó kù, nítorí pé, n kì í dara pọ̀ nínú gbígbàdúrà sí Màríà Wúńdíá. Ṣùgbọ́n, olójú ìwòye èròǹgbà ìjọba Kọ́múníìsì kan gbèjà mi. Wàyí o, ní rírí oúnjẹ náà, ó wí fún àwọn yòó kù pé: “‘Màríà Wúńdíà’ yín dà o? Ẹ sọ pé ọkùnrin yìí yóò ṣekú pa wá, síbẹ̀ òun ni ó gbé oúnjẹ wá fún wa.” Lẹ́yìn náà, ó yíjú sí mi, ó sì wí pé: “Emmanuel! Wá bá wa yà á sí mímọ́.”

Kété lẹ́yìn náà, bí àwọn ọmọ ogun Germany ṣe ń sún mọ́ wa mú kí àwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n fẹsẹ̀ fẹ́ẹ, ní mímú kí ìtúsílẹ̀ ṣeé ṣe. Mo gba Patras lọ láti baà lè rí àwọn Ẹlẹ́rìí yòó kù, kí n tó forí lé Áténì ní ìparí May 1941. Níbẹ̀, ó ṣeé ṣe fún mi láti rí aṣọ díẹ̀ àti bàtà, mo sì wẹ ìwẹ̀ àkọ́kọ́ láti ohun tí ó lé ní ọdún kan. Títí di ìgbà tí ìgbóguntì náà fi parí, àwọn ará Germany máa ń dá mi dúró nígbà gbogbo tí mo bá ń wàásù, ṣùgbọ́n wọn kò fàṣẹ ọba mú mi. Ọ̀kan nínú wọn wí pé: “Ní Germany a ń yìnbọn pa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ṣùgbọ́n níhìn-ín a ronú pé yóò dára kí gbogbo àwọn ọ̀tá wa jẹ́ Ẹlẹ́rìí!”

Ìgbòkègbodò Ẹ̀yìn Ogun

Àfi bí ẹni pé ogun tí ilẹ̀ Gíríìsì jà kò tí ì tó, ogun abẹ́lé túbọ̀ fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ láti ọdún 1946 sí 1949, tí ó sì ṣokùnfà ikú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn. Àwọn arákùnrin nílò ìṣírí púpọ̀ láti dúró gẹ́gẹ́ bí alágbára ní àkókò kan tí wíwulẹ̀ lọ sí ìpàdé lè yọrí sí ìfàṣẹ-ọba-múni. A dájọ́ ikú fún ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin nítorí ìdúró àìdásí tọ̀tún tòsì wọn. Ṣùgbọ́n láìka èyí sí, ọ̀pọ̀ ènìyàn dáhùn padà sí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà, ẹnì kan tàbí ẹni méjì sì ń ṣe ìrìbọmi lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ní ọdún 1947, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì Society ní Áténì lójú ọ̀sán, mo sì ń bẹ àwọn ìjọ wò ní òru gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn àjò.

Ní ọdún 1948, inú mi dùn pé a ké sí mi láti wá sí ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead, ní United States. Ṣùgbọ́n ìṣòro kan wà níbẹ̀. Nítorí pé a ti dá mi lẹ́bi fún ìwà ọ̀daràn rí, kò ṣeé ṣe fún mi láti rí ìwé ìrìnnà gbà. Ṣùgbọ́n, ọ̀kan nínú àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi jẹ́ ọ̀rẹ́ ọ̀gágun kan. Ọpẹ́lọpẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ yìí, láàárín ọ̀sẹ̀ díẹ̀, ìwé àṣẹ ìrìnnà mi tẹ̀ mí lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n ìdààmú ọkàn bá mi, nígbà tí ó kù díẹ̀ kí n lọ, tí a fàṣẹ ọba mú mi fún pípín Ilé Ìṣọ́. Ọlọ́pàá kan mú mi lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá àgbà Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ní Áténì. Ó yà mí lẹ́nu púpọ̀ pé, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn aládùúgbò mi! Ọlọ́pàá náà ṣàlàyé ìdí tí a fi fàṣẹ ọba mú mi, ó sì fún un ní ìdìpọ̀ àwọn ìwé ìròyìn náà. Aládùúgbò mi mú ọ̀kan nínú ìdìpọ̀ àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ jáde láti inú tábìlì rẹ̀, ó sì wí fún mi pé: “N kò tí ì rí ìtẹ̀jáde tí ó dé kẹ́yìn gbà. Ṣe kí n mú ẹ̀dà kan?” Ẹ wo bí ara ṣe tù mí tó láti rí i bí Jèhófà ṣe ń dá sí irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀!

Kíláàsì kẹrìndínlógún ti Gilead, ní ọdún 1950, jẹ́ ìrírí amúnisunwọ̀n sí i. Nígbà tí ó parí, a yàn mí sí Kípírọ́sì, níbi tí mo ti rí i láìpẹ́ pé àtakò àwùjọ àlùfáà gbóná janjan bíi ti ilẹ̀ Gíríìsì ni. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni a ní láti dojú kọ ogunlọ́gọ̀ agbawèrèmẹ́sìn tí àwọn àlùfáà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì tí mẹ́mìí wọn gbóná. Ní ọdún 1953, a kò tún ìwé àṣẹ mi fún gbígbé ní Kípírọ́sì ṣe, a sì tún mi yàn sí Istanbul, Turkey. Níhìn-ín lẹ́ẹ̀kan sí i, n kò dúró pẹ́. Pákáǹleke ìṣèlú láàárín Turkey àti ilẹ̀ Gíríìsì yọrí sí pé, láìka èso rere nínú iṣẹ́ ìwàásù sí, mo ní láti fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí ibi iṣẹ́ àyànfúnni mìíràn—Íjíbítì.

Nígbà tí mo wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n, Orin Dáfídì 55:6, 7 máa ń wá sọ́kàn mi. Níbẹ̀, Dáfídì sọ ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ láti sá lọ sínú aginjù jáde. N kò ronú rẹ̀ rí láé pé ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí mi lọ́jọ́ kan nìyẹn. Ní ọdún 1954, lẹ́yìn ìrìn àjò ọ̀pọ̀ ọjọ́, tí ń tánni lókun, nínú ọkọ̀ ojú irin àti ọkọ̀ ojú omi lórí Odò Nile, mo dé ibi tí mò ń lọ nígbẹ̀yìngbẹ́yín—Khartoum, ní Sudan. Gbogbo ohun tí mo fẹ́ ṣe ni kí n wẹ̀, kí n sì lọ sùn. Ṣùgbọ́n mo gbàgbé pé ọ̀sán gangan ni. Omi, tí a tọ́jú sínú táǹkì lórí òrùlé ilé, bó mi lórí, ó di dandan fún mi láti máa dé àkẹtẹ̀ fún ọ̀pọ̀ oṣù títí tí àpá orí mi fi san.

Lọ́pọ̀ ìgbà, mo máa ń nímọ̀lára pé mo wà ní àdádó, pé mo wà ní èmi nìkan ní àárín gbùngbùn Sahara, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ibùsọ̀ sí ìjọ tí ó wà nítòsí jù lọ, ṣùgbọ́n Jèhófà mú mi dúró, ó sì fún mi ní okun láti máa bá a nìṣó. Nígbà míràn ìṣírí máa ń wà láti àwọn orísun tí ń kò retí. Lọ́jọ́ kan, mo pàdé olùdarí Ilé Àkójọ Ohun Ìṣẹ̀m̀báyé ti Khartoum. Ó máa ń gba ojú ìwòye tẹlòmíràn yẹ̀ wò, a sì ní ìjíròrò tí ó jíire. Nígbà tí ó mọ́ pé Gíríìkì pọ́ńbélé ni mí, ó béèrè bóyá n óò lè ṣoore kan fún òun, nípa lílọ sí ilé àkójọ ohun ìṣẹ̀m̀báyé náà láti túmọ̀ àwọn àkọlé kan tí ó wà lórí iṣẹ́ ọnà kan tí a rí nínú ṣọ́ọ̀ṣì ọ̀rúndún kẹfà kan. Lẹ́yìn wákàtí márùn-ún nínú àjàalẹ̀ kan tí atẹ́gùn tí ń wọ ibẹ̀ kò tó nǹkan, mo rí àwo kòtò kan tí a kọ orúkọ Jèhófà sí, YHWH! Ẹ wo bí inú mi ti dùn tó! Ní ilẹ̀ Europe kò ṣàjèjì láti rí orúkọ àtọ̀runwá náà nínú ṣọ́ọ̀ṣì, àmọ́ ti àárín gbùngbùn Sahara jọni lójú púpọ̀!

Lẹ́yìn àpéjọ àgbáyé ní ọdún 1958, a yàn mí gẹ́gẹ́ bí alábòójútó ẹkùn láti bẹ àwọn ará wò ní orílẹ̀-èdè 26 àti agbègbè ìpínlẹ̀ Àárín Gbùngbùn àti Itòsí Ìlà Oòrùn Ayé àti agbègbè òkun Mẹditaréníà. Lọ́pọ̀ ìgbà, n kì í mọ bí n óò ṣe yọ nínú ipò ìṣòro, ṣùgbọ́n Jèhófà máa ń ṣe ọ̀nà àbáyọ nígbà gbogbo.

Ìgbà gbogbo ni orí mi máa ń wú nítorí ìtọ́jú tí ètò àjọ Jèhófà ń fi hàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n wà ní àdádó, ní àwọn orílẹ̀-èdè kan pàtó. Ní àkókò kan, mo pàdé arákùnrin ará India kan tí ń ṣiṣẹ́ ní ibi tí a ti ń fa epo. Ó hàn gbangba pé òun nìkan ṣoṣo ni Ẹlẹ́rìí tí ó wà ní orílẹ̀-èdè yẹn. Nínú àpótí rẹ̀, ó ní àwọn ìtẹ̀jáde ní èdè 18 ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, èyí tí ó fún àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀. Àní níhìn-ín pàápàá, níbi tí a ti ka gbogbo ìsìn àjèjì léèwọ̀ pátápátá, arákùnrin wa kò gbàgbé ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ láti wàásù ìhìn rere náà. Orí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ wú láti rí i pé a rán aṣojú ìsìn rẹ̀ láti wá bẹ̀ ẹ́ wò.

Ọdún 1959 ni mo ṣèbẹ̀wò sí Sípéènì àti ilẹ̀ Potogí. Àwọn méjèèjì wà lábẹ́ ìjọba ológun aláṣẹ bóo fẹ́ bóo kọ̀ nígbà yẹn, iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì wà lábẹ́ ìfòfindè pátápátá. Láàárín oṣù kan, ó ṣeé ṣe fún mi láti darí ohun tí ó lé ní ọgọ́rùn-ún ìpàdé, ní fífún àwọn ará níṣìírí láti má ṣe juwọ́ sílẹ̀ láìka ìṣòro sí.

N Kò Dá Wà Mọ́

Fún ohun tí ó lé ní 20 ọdún, mo ti ń ṣiṣẹ́ sin Jèhófà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí àpọ́nkùnrin, ṣùgbọ́n, lójijì àárẹ̀ rínrin ìrìn àjò ìgbà gbogbo láìní ibi kan tí ń óò fìdí kalẹ̀ sí sú mi. Àárín àkókò yìí ni mo bá Annie Bianucci pàdé, aṣáájú ọ̀nà àkànṣe ní Tunisia. A ṣègbéyàwó ní ọdún 1963. Ìfẹ́ rẹ̀ fún Jèhófà àti òtítọ́, ìfọkànsìn rẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, àti ìmọ̀ èdè púpọ̀ tí ó ní, jẹ́ ìbùkún gidi nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì àti iṣẹ́ àyíká wa ní àríwá àti ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà àti ní Ítálì.

Ní August 1965, a rán èmi àti aya mi lọ sí Dakar, Senegal, níbi tí mo ti ní àǹfààní ṣíṣètò ọ́fíìsì ẹ̀ka àdúgbò. Senegal jẹ́ orílẹ̀-èdè kan tí ó gbajúmọ̀ fún fífàyè gba ìsìn, kò sí iyè méjì pé èyí jẹ́ tìtorí ààrẹ rẹ̀, Léopold Senghor, ọ̀kan nínú àwọn olórí Orílẹ̀-Èdè ilẹ̀ Áfíríkà tí ó kọ̀wé sí Ààrẹ Banda ti ilẹ̀ Màláwì, ní títí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́yìn nígbà inúnibíni búburú jáì tí ó wáyé ní Màláwì ní àwọn ọdún 1970.

Ìbùkún Dídọ́ṣọ̀ Láti Ọ̀dọ̀ Jèhófà

Ní ọdún 1950, nígbà tí mo fi ilé ẹ̀kọ́ Gilead sílẹ̀ lọ sí Kípírọ́sì, mo rìnrìn àjò pẹ̀lú àpò ẹrù méje. Nígbà tí n óò fi fi Turkey sílẹ̀, márùn-ún péré ni mo ní. Ṣùgbọ́n nítorí pé mo ń rìnrìn àjò púpọ̀, mo ní láti jẹ́ kí gbígbé ẹrù tí kò ju 20 kìlógíráàmù mọ́ mi lára, èyí ní fáìlì mi àti ẹ̀rọ ìtẹ̀wé “kóńkóló” mi nínú. Lọ́jọ́ kan, mo sọ fún Arákùnrin Knorr, ẹni tí ó jẹ́ ààrẹ Watch Tower Society nígbà náà pé: “O dáàbò bò mí kúrò lọ́wọ́ ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì. O mú kí ń máa gbé ìgbésí ayé pẹ̀lú ẹrù oníkìlógíráàmù 20, nǹkan sì ń ṣẹnuure fún mi.” N kò fìgbà kankan nímọ̀lára pé a fi nǹkan dù mí nítorí pé n kò ní ọ̀pọ̀ nǹkan.

Olórí ìṣòro mi nígbà ìrìn àjò mi ni, wíwọlé àti jíjáde nínú orílẹ̀-èdè. Lọ́jọ́ kan, ní ilẹ̀ kan tí a ti fòfin de iṣẹ́ wa, ọ̀gá òṣìṣẹ́ aṣọ́bodè kan bẹ̀rẹ̀ sí i gbọn fáìlì mi yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́. Èyí fi àwọn Ẹlẹ́rìí tí ó wà ní orílẹ̀-èdè náà sínú ewu, nítorí náà mo mú lẹ́tà kan tí aya mi kọ jáde láti inú àpò ẹ̀wù àwọ̀lékè mi, mo sì sọ fún ọ̀gá òṣìṣẹ́ aṣọ́bodè náà pé: “Mo rí i pé o fẹ́ràn kíka lẹ́tà. Ìwọ yóò ha fẹ́ láti ka lẹ́tà yìí tí aya mi kọ sí mi, èyí tí kò sí nínú fáìlì yẹn bí?” Ara rẹ̀ kó tìọ̀, ó sì tọrọ gáfárà, ó sì nì kí n máa lọ.

Láti ọdún 1982, èmi àti aya mi ti ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì ní Nice, ní gúúsù ilẹ̀ Faransé. Nítorí ìlera tí kò dára tó, n kò lè ṣe tó bí mo ti ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n ìyẹn kò túmọ̀ sí pé ìdùnnú wa ti dín kù. A ti rí i pé, ‘òpò wa kì í ṣe asán.’ (Kọ́ríńtì Kìíní 15:58) Inú mi dùn láti rí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn tí mo ti ní àǹfààní láti bá kẹ́kọ̀ọ́ jálẹ̀ àwọn ọdún wọ̀nyí àti iye tí ó lé ní 40 nínú mẹ́ḿbà ìdílé mi, tí wọ́n ń fi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹ́ sin Jèhófà.

N kò kábàámọ̀ àwọn ìrúbọ tí mo ti ṣe láti lè gbé ìgbésí ayé tí ‘ríré kọjá’ ń fẹ́. Ó ṣe tán, kò sí ìrúbọ kankan tí ẹnì kan lè ṣe tí a lè fi wé ohun tí Jèhófà àti Ọmọkùnrin rẹ̀, Kristi Jésù, ti ṣe fún wa. Nígbà tí mo bá ronú padà sí 60 ọdún tí ó ti kọjá, tí mo ti mọ òtítọ́, mo lè sọ pé Jèhófà ti bù kún mi ní yanturu. Gẹ́gẹ́ bí Òwe 10:22 ti wí, “ìbùkún Olúwa ní í mú ni í là.”

Láìsí iyè méjì, ‘ìṣeun ìfẹ́ Jèhófà sàn ju ìyè lọ.’ (Orin Dáfídì 63:3) Bí àwọn ipò tí kò wọ̀ tí ọjọ́ ogbó ń mú wá, ti ń pọ̀ sí i, àwọn ọ̀rọ̀ onísáàmù náà tí a mí sí ń fìgbà gbogbo hàn nínú àdúrà mi pé: “Jèhófà, ìwọ ni mo sá di. Máà jẹ́ kí ojú tì mí láé. Nítorí ìwọ ni ìrètí mi, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ìgbọ́kànlé mi láti ìgbà èwe mi. Ọlọ́run, o ti kọ́ mi láti ìgbà èwe mi wá, títí di ìsinsìnyí èmi sì ń bá a nìṣó ní sísọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ àgbàyanu rẹ. Àní títí di ìgbà ọjọ́ ogbó àti ìgbà orí ewú, Ọlọ́run, má ṣe fi mí sílẹ̀.”—Orin Dáfídì 71:1, 5, 17, 18, NW.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Pẹ̀lú aya mi, Annie, lónìí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́