Ṣíṣiṣẹ́ Sìn Lábẹ́ Ọwọ́ Ìfẹ́ Jehofa
GẸ́GẸ́ BÍ LAMBROS ZOUMBOS ṢE SỌ Ọ́
Mo dojú kọ yíyàn pàtàkì kan: kí n tẹ́wọ́ gba ohun tí àbúrò bàbá mi fẹ́ fún mi, láti di alábòójútó ilẹ̀ àti ilé rẹpẹtẹ tí ó ní—kí n sì tipa bẹ́ẹ̀ yanjú àwọn ìṣòro ìnáwó ìdílé mi—tàbí kí n di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún fún Jehofa Ọlọrun. Jẹ́ kí n ṣàlàyé àwọn kókó abájọ tí ó nípa lórí ìpinnu tí mo ṣe nígbẹ̀yìn gbẹ́yín.
ABÍ mi ní ìlú Volos, ilẹ̀ Gíríìkì, ní 1919. Ẹ̀wù ọkùnrin ni bàbá mi ń tà, a sì gbádùn aásìkí nípa ti ara. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí ọrọ̀ ajé tí ó lọ sílẹ̀ ní ìparí àwọn ọdún 1920, ó di dandan fún Bàbá láti wọko gbèsè, ó sì pàdánù òwò rẹ̀. Gbogbo ìgbà tí mo bá wo ojú bàbá mi tí ó ti sọ̀rètí nù ni inú mí máa ń bàjẹ́.
Fún ìgbà díẹ̀, ìdílé mi tálákà ju èkúté ṣọ́ọ̀ṣì lọ. Lójoojúmọ́, mo máa ń fi wákàtí kan kúrò ní ilé ẹ̀kọ́ ṣáájú àkókò, kí n baà lè lọ tò fún oúnjẹ tí a ń bù fúnni. Síbẹ̀, láìka ipò òṣì wa sí, a gbádùn ìgbésí ayé ìdílé tí ó pa rọ́rọ́. Ohun tí ó wù mí ni pé kí n di dókítà, ṣùgbọ́n nígbà tí n kò tí ì pé ogún ọdún mo ní láti fi ilé ẹ̀kọ́ sílẹ̀, kí n sì máa ṣiṣẹ́ láti baà lè gbọ́ bùkátà ìdílé mi.
Lẹ́yìn èyí, nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, àwọn ará Germany àti Itali gba ilẹ̀ Gíríìkì, ìyàn ńlá sì mú. Mo sábà máa ń rí àwọn ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ tí ebi ń lù pa ní òpópónà—ìran kan tí n kò lè gbàgbé láé! Nígbà kan, odindi 40 ọjọ́ ni ìdílé wa kò fi rí búrẹ́dì jẹ, tí ó jẹ́ ọba oúnjẹ ní ilẹ̀ Gíríìkì. Láti lè máa wà láàyè lọ, èmi àti ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin lọ sí àwọn abúlé tí ó wà nítòsí láti lọ gba ọ̀dùnkún lọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ àti ìbátan.
Àmódi Di Ìbùkún
Ní kùtùkùtù ọdún 1944, àrùn pleura kọlù mí. Ní oṣù mẹ́ta tí mo fi wà ní ilé ìwòsàn, ìbátan mi kan mú ìwé pẹlẹbẹ méjì wá fún mi, ó sì wí pé: “Ka ìwọ̀nyí; mo mọ̀ pé ìwọ yóò nífẹ̀ẹ́ sí wọn.” Watch Tower Bible and Tract Society ni ó tẹ àwọn ìwé pẹlẹbẹ náà, Who Is God? àti Protection, jáde. Lẹ́yìn tí mo kà wọ́n, mo ṣàjọpín àwọn ohun tí ń bẹ nínú wọn pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ mi tí wọ́n ń gba ìtọ́jú.
Nígbà tí mo fi ilé ìwòsàn náà sílẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ Ìjọ Volos ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, fún oṣù kan, a sé mi mọ́lé gẹ́gẹ́ bí aláìsàn tí a ń lọ tọ́jú nínú ilé rẹ̀, nǹkan bíi wákàtí mẹ́fà sí mẹ́jọ lójúmọ́, ni mo fi ń ka àwọn ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà, bákan náà sì ni àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn tí Watch Tower Society tẹ̀. Ní ìyọrísí èyí, ìdàgbàsókè mi nípa tẹ̀mí yára kánkán.
Mo Yọ Nínú Ewu
Ní ọjọ́ kan ní àárín ọdún 1944, mo wà lórí ìjókòó ọgbà ìtura kan ní Volos. Lójijì, ẹgbẹ́ ọmọ ogun olùrànlọ́wọ́ tí ń ṣètìlẹyìn fún àwọn ọmọ ogun Germany yí ibẹ̀ ká, wọ́n sì fàṣẹ ọba mú gbogbo ẹni tí ó wà níbẹ̀. A mú nǹkan bíi 24 nínú wa la ìgboro lọ sí orílé iṣẹ́ Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́, tí ó wà ní ilé kan tí a ń kó tábà pamọ́ sí.
Lẹ́yìn ìṣẹ́jú díẹ̀, mo gbọ́ tí ẹnì kan ń pe orúkọ mi àti orúkọ ẹni náà tí mo ń bá sọ̀rọ̀ nínú ọgbà ìtura náà. Ọ̀gá sójà ilẹ̀ Gíríìkì kan pè wá, ó sì wí fún wa pé, nígbà tí ọ̀kan nínú àwọn mọ̀lẹ́bí mi rí i tí àwọn sójà ń mú wa lọ, ó sọ fún òun pé, Ẹlẹ́rìí Jehofa ni wá. Ọ̀gá sójà ilẹ̀ Gíríìkì náà wá sọ fún wa pé, kí a máa lọ sílé, ó sì fún wa ní káàdì ibi iṣẹ́ rẹ̀ pé, kí a lò ó bí a bá tún fàṣẹ ọba mú wa.
Ní ọjọ́ kejì a gbọ́ pé, àwọn ará Germany ti pa ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn tí wọ́n fàṣẹ ọba mú, gẹ́gẹ́ bíi gbígbẹ̀san fún àwọn sójà ará Germany méjì tí àwọn agbábẹ́lẹ̀jagun ilẹ̀ Gíríìkì pa. Yàtọ̀ sí pé ó ṣeé ṣe láti gbà wá lọ́wọ́ ikú, àkókò yẹn ni mo kọ́ bí àìdásí tọ̀tún tòsì Kristian ṣe ṣeyebíye tó.
Ní ìgbà ìkórè 1944, mo fi àpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ mi hàn fún Jehofa nípa ṣíṣe ìrìbọmi. Ní ìgbà ẹ̀rùn tí ó tẹ̀ lé e, àwọn Ẹlẹ́rìí ṣètò pé kí n dara pọ̀ mọ́ Ìjọ Sklithro ni àwọn ibi olókè gíga, níbi tí ara mi ti lè tètè mókun tán. Ogun abẹ́lé tí ó wáyé tẹ̀ lé gbígbà tí àwọn ará Germany gba ilẹ̀ wa ń lọ lọ́wọ́ ní ilẹ̀ Gíríìkì nígbà náà. Ó ṣẹlẹ̀ pé abúlé tí mò ń gbé ni àwọn agbábẹ́lẹ̀jagun fi ṣe ibùdó. Àlùfáà àdúgbò náà àti ọkùnrin oníwà òǹrorò kan fẹ̀sùn kàn mí pé mò ń ṣamí fún àwọn ọmọ ogun ìjọba, wọ́n sì jẹ́ kí ilé ẹjọ́ agbábẹ́lẹ̀jagun tí wọ́n fúnra wọn yàn sípò fi ìbéèrè wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu mi.
Ọ̀gá àwọn agbábẹ́lẹ̀jagun ní agbègbè náà wà níbi ìgbẹ́jọ́ ilé ẹjọ́ arúmọjẹ náà. Nígbà tí mo parí ṣíṣàlàyé ìdí tí mo fi ń gbé ní abúlé náà, tí mo sì fi hàn pé, gẹ́gẹ́ bíi Kristian, mo wà láìdásí tọ̀tún tòsì nínú ogun abẹ́lé náà, ọ̀gá náà sọ fún àwọn yòókù pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fọwọ́ kan ọ̀gbẹ́ni yìí, èmi pẹ̀lú onítọ̀hún yóò kẹsẹ̀ bọ ṣòkòtò kan náà!”
Lẹ́yìn náà, mo padà sí Volos, ìlú mi, àní ìgbàgbọ́ mi lágbára ju ìlera mi nípa ti ara lọ.
Ìtẹ̀síwájú Nípa Tẹ̀mí
Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, a yàn mí ṣe ìránṣẹ́ alákọsílẹ̀ ìṣirò owó nínú ìjọ àdúgbò. Láìka ìnira tí ogun abẹ́lé náà mú wá sí—títí kan ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìfàṣẹ ọba múni nítorí ẹ̀sùn ìsọnidaláwọ̀ṣe tí àwùjọ àlùfáà ru sókè—nínípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristian mú ìdùnnú ńláǹlà wá fún èmi àti àwọn yòókù nínú ìjọ wa.
Nígbà tí ó ṣe, ní kùtùkùtù ọdún 1947, alábòójútó arìnrìn àjò ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bẹ̀ wá wò. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí a óò ní irú ìbẹ̀wò bẹ́ẹ̀ láti ìgbà tí Ogun Àgbáyé Kejì ti parí. Nígbà yẹn, a pín ìjọ wa tí ń gbilẹ̀ sí i ní Volos sí méjì, a sì yàn mí ṣe alábòójútó olùṣalága fún ọ̀kan nínú àwọn ìjọ náà. Ètò àjọ àwọn ọmọ ogun aṣèrànwọ́ àti àwọn onífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni ń tan ìbẹ̀rù kálẹ̀ láàárín àwọn ènìyàn. Àwùjọ àlùfáà lo àǹfààní ipò náà. Wọ́n dojú àwọn aláṣẹ kọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, nípa títan irọ́ kálẹ̀ pé, Kọ́múníìsì tàbí alátìlẹyìn àwọn àwùjọ oníyìípadà tegbò tigaga ni wá.
Ìfàṣẹ-Ọba-Múni àti Ìfinisẹ́wọ̀n
Ní ọdún 1947, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìgbà mẹ́wàá tí a fàṣẹ ọba mú mi, a sì gbẹ́jọ́ mi ní ìgbà mẹ́ta. Gbogbo ìgbà ni a ń dá mi sílẹ̀. Ní ìgbà ìrúwé ọdún 1948, a rán mi lẹ́wọ̀n oṣù mẹ́rin fún ìṣọnidaláwọ̀ṣe. Ọgbà ẹ̀wọ̀n Volos ni mo ti ṣẹ̀wọ̀n náà. Ní àkókò náà, àwọn olùpòkìkí Ìjọba tí ń bẹ nínú ìjọ wa di ìlọ́po méjì, ìdùnnú sì ṣubú láyọ̀ fún àwọn ará.
Ní October ọdún 1948, nígbà tí mo ń ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn mẹ́fà míràn tí ń mú ipò iwájú nínú ìjọ wa, àwọn ọlọ́pàá márùn-ún já wọ inú ilé náà, wọ́n sì fàṣẹ ọba mú wa pẹ̀lú dídojú ìbọn kọ wá. Wọ́n mú wa lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá láìṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi fàṣẹ ọba mú wa, wọ́n sì lù wá níbẹ̀. Ọlọ́pàá kan tí ó jẹ́ abẹ̀ṣẹ́-kù-bí-òjò tẹ́lẹ̀ di ìgbájú rù mí. Lẹ́yìn náà a jù wá sínú àhámọ́.
Nígbà tí ó ṣe, ọ̀gá tí ó wà nídìí ẹjọ́ náà pè mí sí ọ́fíìsì rẹ̀. Nígbà tí mo ṣí ilẹ̀kùn rẹ̀, ìgò tàdáwà ni ó jù lù mí, ṣùgbọ́n kò bà mí, ó sì fọ́ yángá sára ògiri. Ó ṣe èyí kí ó baà lè mú mi láyà pami. Lẹ́yìn náà ó fún mi ní bébà àti kálàmù, ó sì pàṣẹ pé: “Kọ orúkọ gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ó wà ní Volos sílẹ̀, kí o sì mú un wá fún mi ní òwúrọ̀ ọ̀la. Bí o kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, wà á rí ohun tí n óò fojú rẹ̀ rí!”
N kò gbin, ṣùgbọ́n nígbà tí mo padà sí àhámọ́ náà, èmi àti àwọn arákùnrin yòókù gbàdúrà sí Jehofa. Mo kọ orúkọ tèmi nìkan sórí bébà náà, mo sì ń retí kí wọ́n pè mí. Ṣùgbọ́n n kò gbọ́ ohunkóhun mọ́ láti ọ̀dọ̀ ọ̀gá náà. Agbo ọmọ ogun alátakò ti wá ní òru, ó sì ti kó àwọn ènìyàn rẹ̀ wá láti bá wọn jà. Nínú ìjà ráńpẹ́ tí ó tẹ̀ lé e, ó fara pa yánnayànna, wọ́n sì ní láti gé ẹsẹ̀ rẹ̀ kan. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, a gbọ́ ẹjọ́ wa, a sì fẹ̀sùn kan wa fún ṣíṣe ìpàdé tí kò bófin mu. A ran àwa méjèèje lọ sẹ́wọ̀n ọdún márùn-ún.
Níwọ̀n bí mo ti kọ̀ láti lọ sí Máàsì ọjọ́ Sunday nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n, a rán mi lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n àdádó. Ní ọjọ́ kẹta, wọ́n ní kí n bá olùdarí ọgbà ẹ̀wọ̀n náà sọ̀rọ̀. Mo sọ fún un pé: “Mo tọrọ gáfárà o, ó dà bí ẹni pé kò bọ́gbọ́n mu láti fìyà jẹ ẹnì kan tí ó múra tán láti lo ọdún márùn-ún ní ọgbà ẹ̀wọ̀n nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀.” Ó ronú gidigidi lórí ìyẹn, ó sọ fún mi níkẹyìn pé: “Láti ọ̀la lọ, ìwọ yóò máa ṣiṣẹ́ níhìn-ín lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi nínú ọ́fíìsì.”
Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n fún mi ni iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí igbá kejì dókítà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, mo kọ́ ohun púpọ̀ nípa ìtọ́jú ìlera, ohun kan tí ó wá wúlò fún mi gidigidi ní àwọn ọdún tí ó tẹ̀ lé e. Nígbà tí mo wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n, mo ní ọ̀pọ̀ àǹfààní láti wàásù, àwọn mẹ́ta sì dáhùn padà, wọ́n sì di Ẹlẹ́rìí Jehofa.
Lẹ́yìn wíwà lẹ́wọ̀n fún ọdún mẹ́rin, a dá mi sílẹ̀ nígbẹ̀yìn gbẹ́yín ní 1952 láti yẹ̀ mí wò fún sáà kan. Lẹ́yìn náà, mo ní láti fara hàn níwájú ilé ẹjọ́ ní Korinti lórí ọ̀ràn àìdásí-tọ̀tún-tòsì. (Isaiah 2:4) A fi mí sí ọgbà ẹ̀wọ̀n àwọn ológun fún ìgbà kúkúrú, ìpele ìwà ìkà míràn sì bẹ̀rẹ̀. Àwọn ọ̀gá kan jẹ́ eléte gan-an nínú bí wọ́n ṣe ń halẹ̀ mọ́ni, ní sísọ pé: “Màá fi dágà yọ ọkàn rẹ jáde ní wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́,” tàbí, “Má ṣe rò pé ìwọ yóò yára kú, nítorí díẹ̀díẹ̀ ni a óò máa gbẹ̀mí rẹ.”
Onírúurú Ìdánwò Tí Ó Yàtọ̀
Ṣùgbọ́n, láìpẹ́ láìjìnnà, mo pada sílé, mo sì tún ń ṣiṣẹ́ sìn pẹ̀lú Ìjọ Volos, mo sì ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ aláàbọ̀ṣẹ́. Ní ọjọ́ kan, mo rí lẹ́tà kan gbà láti ọ́fíìsì ẹ̀ka Watch Tower Society ní Ateni, tí wọ́n ké sí mi láti wá gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún ọ̀sẹ̀ méjì, kí n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa wò gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká. Ní àkókò kan náà, àbúrò bàbá mi kan, tí kò ní ọmọ, tí ó sì ní ilé àti ilẹ̀ rẹpẹtẹ, ní kí ń máa bá òun bójú tó àwọn dúkìá òun. Ìdílé mi ṣì wà nínú ipò òṣì síbẹ̀, iṣẹ́ yìí ì bá sì ti yanjú àwọn ìṣòro ọrọ̀ ajé wọn.
Mo bẹ àbúrò bàbá mi wò láti fi ìmoore mi hàn fún ohun tí ó fún mi, ṣùgbọ́n mo fi tó o létí pé, mo ti pinnu láti tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ àyànfúnni àrà ọ̀tọ̀ kan nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristian. Látàrí èyí, ó dìde, ó wò mí tàánútàánú, ó sì kù gìrì jáde kúrò nínú iyàrá náà. Ó padà wá pẹ̀lú ẹ̀bùn owó tabua tí ó lè tó ìdílé mí ná fún àwọn oṣù díẹ̀. Ó wí pé: “Gba eléyìí, kí o sì ná an bí o bá ṣe fẹ́.” Títí di òní olónìí, n kò lè ṣàpèjúwe bí ìmọ̀lára mi ti rí ní ìṣẹ́jú yẹn. Ṣe ni ó dà bí ẹni pé mo gbọ́ ohun Jehofa tí ń sọ fún mi pé, ‘O ti ṣe ìpinnu tí ó tọ̀nà. Mo wà pẹ̀lú rẹ.’
Pẹ̀lú ìbùkún ìdílé mi, mo gbéra lọ sí Ateni ní December 1953. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ìyá mi nìkan ni ó di Ẹlẹ́rìí, àwọn mẹ́ḿbà míràn nínú ìdílé mi kò ta ko ìgbòkègbodò Kristian mi. Nígbà tí mo lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì ní Ateni, ohun ìyàlẹ́nu mìíràn ti ń dúró dè mí. Wáyà kan láti ọ̀dọ̀ àbúrò mi obìnrin ti wà níbẹ̀, tí ó sọ pé ìjàkadì ọdún méjì tí Bàbá ti ń jà láti rí owó ìfẹ̀yìntì gbà ti bọ́ sí i ní ọjọ́ yẹn. Kí ni mo tún ń fẹ́? Ó dà bíi pé kí n ní ìyẹ́, kí n sì fò lọ sókè rere nínú iṣẹ́ ìsìn Jehofa!
Lílo Ìṣọ́ra
Ní àwọn ọdún mi àkọ́kọ́ nínú iṣẹ́ àyíká, mo ni láti ṣọ́ra gan-an nítorí pé, àwọn aláṣẹ ìsìn àti ti ìṣèlú ń ṣe inúnibíni líle koko sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Láti bẹ àwọn Kristian arákùnrin wa wò, ní pàtàkì, àwọn tí wọ́n ń gbé ní àwọn ìlú kéékèèké àti abúlé, mo fi ọ̀pọ̀ wákàtí rìn ní òru. Àwọn arákùnrin náà, tí wọn kò bìkítà pé kí a fàṣẹ ọba mú wọn, yóò ti kóra jọ, wọ́n yóò sì máa fi sùúrù dúró dè mí ní ilé kan. Ẹ wo irú pàṣípààrọ̀ ìṣírí àtàtà tí àwọn ìbẹ̀wò wọ̀nyẹn mú wá fún gbogbo wa!—Romu 1:11, 12.
Láti yẹra fún títú mi fó, nígbà míràn, mo máa ń díbọ́n. Nígbà kan, mo múra bí olùṣọ́ àgùntàn láti baà lè kọjá ní ibi tí àwọn ọlọ́pàá ti ń ṣàyẹ̀wò láti lè dé ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin tí wọ́n kóra jọ tí wọ́n nílò ṣíṣe olùṣọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nípa tẹ̀mí. Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ míràn, ní 1955, èmi àti Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ mi kan díbọ́n pé a ń ta aáyù láti yẹra fún mímú kí àwọn ọlọ́pàá fura sí wa. Iṣẹ́ àyànfúnni wa ni láti kàn sí àwọn Kristian arákùnrin kan tí wọn kò ṣe déédéé mọ́ ní ìlú kékeré náà, Árgos Orestikón.
A pàtẹ ọjà wa sí ibi ọjà gbogbogbòò tí ó wà ní ìlú náà. Ṣùgbọ́n, ọ̀dọ́ ọlọ́pàá kan tí ń lọ tí ń bọ̀ ní agbègbè náà fura, gbogbo ìgbà tí ó bá sì kọjá, ni ó ń wò wá tìṣọ́ratìsọ́ra. Níkẹyìn, ó sọ fún mi pé: “O kò jọ àwọn tí ń ta aáyù.” Lẹ́sẹ̀ kan náà, àwọn obìnrin mẹ́ta wá, wọ́n sì ní àwọ́n fẹ́ ra aáyù. Ní títọ́ka sí ọjà mí, mo lọgun pé: “Àṣé ọ̀dọ́ ọlọ́pàá yìí mọ aáyù jẹ tó báyìí, abájọ tí ó fi taagun, tí ó sì rẹwà!” Àwọn obìnrin náà wo ọlọ́pàá náà, wọ́n sì bú sẹ́rìn-ín. Òun pẹ̀lú rẹ́rìn-ín músẹ́, ó sì bá tirẹ̀ lọ.
Nígbà tí ó lọ tán, mo lo àǹfààní náà láti lọ sí ilé ìtajà tí àwọn arákùnrin wa nípa tẹ̀mí ti ń ránṣọ. Mo ní kí ọ̀kan nínú wọ́n bá mi so bọ́tìnì tí mo ti já lára jákẹ́ẹ̀tì mi. Bí ó ti ń ṣe èyí lọ́wọ́, mo fetí kò ó létí, mo sì bá a sọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́ pé: “Ẹ̀yin ni mo wá rí láti ọ́fíìsì ẹ̀ka.” Lákọ̀ọ́kọ́ ẹ̀rù ba àwọn arákùnrin náà, níwọ̀n bí wọn kò ti rí Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ wọn kankan fún ọ̀pọ̀ ọdún. Mo fún wọn níṣìírí dé ibi tí mo lè ṣe dé, mo sì ṣètò láti pàdé wọn lẹ́yìn náà ní itẹ́ òkú ìlú náà láti túbọ̀ sọ̀rọ̀ sí i. Ó dùn mọ́ni pé, ìbẹ̀wò náà jẹ́ afúnniníṣìírí, wọ́n sì di onítara lẹ́ẹ̀kan sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristian.
Rírí Aya Tí Ó Jẹ́ Olùṣòtítọ́
Ní 1956, ọdún mẹ́ta lẹ́yìn tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ arìnrìn àjò, mo pàdé Niki, ọ̀dọ́mọbìnrin Kristian kan tí ó fẹ́ràn iṣẹ́ ìwàásù púpọ̀púpọ̀, tí ó sì ní ọkàn ìfẹ́ láti lo ìgbésí ayé rẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Ìfẹ́ wọ àwa méjèèjì lọ́kàn, a sì ṣègbéyàwó ní June 1957. Mo ń ṣe kàyéfì bóyá Niki yóò lè dé ojú àmì ohun tí iṣẹ́ arìnrìn àjò ń béèrè lábẹ́ ipò oníkèéta tí ó gbòde kan fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní ilẹ̀ Gíríìkì nígbà yẹn. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jehofa, ó gbìyànjú, ó tipa bẹ́ẹ̀ di obìnrin tí ó kọ́kọ́ bá ọkọ rẹ̀ lọ sẹ́nu iṣẹ́ àyíká ní ilẹ̀ Gíríìkì.
A jọ ń bá a nìṣó nínú iṣẹ́ arìnrìn àjò fún ọdún mẹ́wàá, ní ṣíṣiṣẹ́ sìn ní ìjọ tí ó pọ̀ jù lọ ní ilẹ̀ Gíríìkì. Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń díbọ́n, pẹ̀lú àpò ìfàlọ́wọ́ wa, a óò rìn ní òru fún ọ̀pọ̀ wákàtí láti lè dé ìjọ kan. Láìka àtakò ńláǹlà tí a dojú kọ lọ́pọ̀ ìgbà sí, inú wá dùn láti rí ìdàgbàsókè àkọ́kọ́ tí ó bùáyà, nínú iye àwọn Ẹlẹ́rìí.
Iṣẹ́ Ìsìn Beteli
Ní January 1967, a ké sí èmi àti Niki láti ṣiṣẹ́ sìn ní Beteli, bí a ṣe ń pe ọ́fíìsì ẹ̀ka àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ìkésíni náà ya àwa méjèèjì lẹ́nu, ṣùgbọ́n a tẹ́wọ́ gbà á, a sì ní ìgbọ́kànlé pé Jehofa ni ó ń darí ọ̀ràn. Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, a wá mọrírì àǹfààní ńláǹlà tí ó jẹ́ láti ṣiṣẹ́ sìn ní àárín gbùngbùn ìgbòkègbodò ìṣàkóso Ọlọrun yìí.
Oṣù mẹ́ta lẹ́yìn tí a wọnú iṣẹ́ ìsìn Beteli, ìgbìmọ̀ ológun kan gba ìjọba, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sì ní láti máa bá iṣẹ́ náà lọ ní abẹ́lẹ̀. A bẹ̀rẹ̀ sí í pàdé ní àwùjọ kéékèèké, a ń ṣe àpéjọ wa nínú igbó, a ń dọ́gbọ́n wàásù, a sì ń tẹ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, tí a sì ń pín wọn kiri lábẹ́lẹ̀. Kò ṣòro láti mú ara wa bá àwọn ipò wọ̀nyí mu, níwọ̀n bí a wulẹ̀ ti padà sí àwọn ọ̀nà tí a gbà ń ṣe àwọn ìgbòkègbodò wa ní àwọn ọdún tí ó kọjá. Láìka ìkálọ́wọ́kò náà sí, iye àwọn Ẹlẹ́rìí ga sókè láti iye tí kò tó 11,000 ní 1967 sí iye tí ó lé ní 17,000 ní 1974.
Lẹ́yìn ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 30 ọdún nínú iṣẹ́ ìsìn ní Beteli, èmi àti Niki ń gbádùn àwọn ìbùkún wa nípa tẹ̀mí lọ, láìka ibi tí ìlera àti ọjọ́ orí mú kí a lè ṣe mọ sí. Fún ohun tí ó lé ní ọdún mẹ́wàá, a gbé nínú ẹ̀ka tí ó wà ní Òpópónà Kartali ní Ateni. Ní 1979, a ya ẹ̀ka tuntun sí mímọ́ ní Marousi, ẹ̀yìn odi Ateni. Ṣùgbọ́n láti 1991, a ti ń gbádùn àwọn ilé lílò gbígbòòrò sí i ti ẹ̀ka tuntun ní Eleona, 60 kìlómítà sí àríwá Ateni. Níhìn-ín ni mo ti ń ṣiṣẹ́ sìn ní ẹ̀ka ìtọ́jú àwọn aláìsàn ní Beteli, níbi tí ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí mo gbà gẹ́gẹ́ bí igbá kejì dókítà ọgbà ẹ̀wọ̀n ti wúlò gidigidi.
Ní èyí tí ó lé ní 40 ọdún tí mo fi wà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, gẹ́gẹ́ bíi Jeremiah, mo ti wá mọ òtítọ́ ìlérí Jehofa náà pé: “Wọn óò bá ọ jà, wọn kì yóò sì lè borí rẹ; nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ, ni Oluwa wí, láti gbà ọ́.” (Jeremiah 1:19) Bẹ́ẹ̀ ni, èmi àti Niki ti gbádùn ago tí ó kún àkúnwọ́sílẹ̀ fún àwọn ìbùkún Jehofa. Ìgbà gbogbo ni a ń yọ̀ nínú àníyàn onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ yanturu àti inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀.
Ọ̀rọ̀ ìyànjú tí mo ní fún àwọn ọ̀dọ́ nínú ètò àjọ Jehofa ni pé kí wọ́n lépa iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Lọ́nà yìí, wọ́n lè tẹ́wọ́ gba ìkésíni Jehofa pé kí a dán òun wò bí òun kì yóò bá mú ìlérí òun ṣẹ ‘láti ṣí àwọn fèrèsé ọ̀run, kí òún sì tú ìbùkún jáde, tó bẹ́ẹ̀ tí àyè kì yóò tó láti gbà á.’ (Malaki 3:10) Láti inú ìrírí ara mi, mo lè fi ọkàn ẹ̀yin ọ̀dọ́ balẹ̀ pé, ní tòótọ́, Jehofa yóò bù kún gbogbo ẹ̀yin tí ẹ gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Lambros Zoumbros àti aya rẹ̀, Niki