ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 3/1 ojú ìwé 20-24
  • “Dípò Wúrà, Mo Rí Dáyámọ́ńdì”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Dípò Wúrà, Mo Rí Dáyámọ́ńdì”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Kan Tí Ó Ṣeyebíye Jù
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún ní Gíríìsì
  • Fífarada Àtakò
  • Ṣíṣiṣẹ́sìn ní Bẹ́tẹ́lì
  • Fífarada Àtakò Lẹ́ẹ̀kan Sí I
  • Kíkún fún Ayọ̀ Nínú Ìmúgbòòrò Tí Ń Bá A Nìṣó
  • Ṣíṣiṣẹ́ Sìn Lábẹ́ Ọwọ́ Ìfẹ́ Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Fífún Jèhófà Ní Ohun Tó Tọ́ Sí I
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ohun Tí Ó Lé Ní 50 Ọdún ‘Ríré Kọjá Wá’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Inú Mi Dùn Pé Mo Kópa Nínú Iṣẹ́ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tó Kárí Ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 3/1 ojú ìwé 20-24

“Dípò Wúrà, Mo Rí Dáyámọ́ńdì”

GẸ́GẸ́ BÍ MICHALIS KAMINARIS ṢE SỌ

Lẹ́yìn ọdún márùn-ún ní Gúúsù Áfíríkà níbi tí mo wá wúrà lọ, mo ń pa dà sílé pẹ̀lú ohun kan tí ó níye lórí gidigidi ju wúrà lọ. Jẹ́ kí n sọ fún ọ nípa ọrọ̀ tí mo ní báyìí, tí mo sì fẹ́ láti ṣàjọpín rẹ̀.

A BÍ mi ní 1904, sí Cephalonia ti erékùṣù ilẹ̀ Gíríìsì, nínú Òkun Ionia. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni àwọn òbí mi méjèèjì kú, nítorí náà, ọmọ òrukàn ni mí. Mo yán hànhàn fún ìrànlọ́wọ́, mo sì sábà máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run. Bí mo tilẹ̀ ń lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Ilẹ̀ Gíríìsì déédéé, òpè ni mí nínú Bíbélì. N kò rí ìtùnú kankan.

Ní 1929, mo pinnu láti fi orílẹ̀-èdè mi sílẹ̀, kí n sì máa wá ìgbésí ayé tí ó sàn jù kiri. Ní fífi erékùṣù mi tí ó jẹ́ aṣálẹ̀ sílẹ̀, mo wọkọ̀ òkun lọ sí Gúúsù Áfíríkà nípa gbígba ọ̀nà England. Lẹ́yìn ọjọ́ 17 lójú òkun, mo dé Cape Town, Gúúsù Áfíríkà, níbi tí ọkùnrin kan tí ó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè mi ti gbà mí síṣẹ́ lójú ẹsẹ̀. Ṣùgbọ́n, n kò rí ìtùnú nínú ọrọ̀ nípa ti ara.

Ohun Kan Tí Ó Ṣeyebíye Jù

Mo ti wà ní Gúúsù Áfíríkà fún nǹkan bí ọdún méjì kí ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ṣèbẹ̀wò sí ibi iṣẹ́ mi, tí ó sì fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní èdè Gíríìkì lọ̀ mí. Àwọn ìwé pẹlẹbẹ náà, Where Are the Dead? àti Oppression, When Will It End? wà lára wọn. Mo ṣì rántí ìháragàgà tí mo fi kà wọ́n, tí mo tilẹ̀ ń há gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a ṣàyọlò sórí. Lọ́jọ́ kan mo sọ fún òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ mi kan pé: “Mo ti rí ohun tí mo ti ń wá kiri láti àwọn ọdún wọ̀nyí. Wúrà ni mo wá wá sí Áfíríkà, ṣùgbọ́n dípò wúrà, mo rí dáyámọ́ńdì.”

Pẹ̀lú ìdùnnú ńlá ni mo fi kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run ní orúkọ tirẹ̀ fúnra rẹ̀, Jèhófà, pé a ti fìdí Ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ ní ọ̀run, àti pé a ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti ìsinsìnyí. (Orin Dáfídì 83:18; Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:9, 10; 24:3-12; Tímótì Kejì 3:1-5; Ìṣípayá 12:7-12) Ẹ wo bí ó ti múni lórí yá tó láti kẹ́kọ̀ọ́ pé, Ìjọba Jèhófà yóò mú ìbùkún tí kò lópin wá fún gbogbo ẹ̀yà ìran aráyé! Òkodoro òtítọ́ mìíràn tí ó wú mi lórí ni pé, a ń wàásù àwọn òtítọ́ ṣíṣeyebíye wọ̀nyí káàkiri àgbáyé.—Aísáyà 9:6, 7; 11:6-9; Mátíù 24:14; Ìṣípayá 21:3, 4.

Kò pẹ́ tí mo wá sí ọ́fíìsì ẹ̀ka Watch Tower Society tí ó wà ní Cape Town kàn, mo sì gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì púpọ̀ sí i. Inú mi dùn jọjọ láti rí Bíbélì tèmi gbà. Ohun tí mo kà sún mi láti fẹ́ jẹ́rìí fúnni. Mo bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú fífi àwọn ìtẹ̀jáde Bíbélì ránṣẹ́ sí àwọn mọ̀lẹ́bí mi, àwọn ọ̀rẹ́ mi, àti àwọn ojúlùmọ̀ mi tí wọ́n wà ní ìlú mi, ní Lixoúrion. Láti inú ìkẹ́kọ̀ọ́ mi, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lóye pé, láti mú inú Jèhófà dùn, ẹnì kan ní láti ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún un. Nítorí náà, mo tètè ṣe bẹ́ẹ̀ nínú àdúrà.

Nígbà kan, mo lọ sí ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ṣùgbọ́n, níwọ̀n bí n kò ti gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì, n kò lóye ẹyọ ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo. Nígbà tí mo gbọ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì ń gbé ní Port Elizabeth, mo ṣí lọ síbẹ̀, ṣùgbọ́n n kò rí Ẹlẹ́rìí kankan tí ń sọ èdè Gíríìkì. Nítorí náà, mo pinnu láti pa dà sí Gíríìsì láti baà lè di ajíhìnrere alákòókò kíkún. Mo rántí sísọ fún ara mi pé, ‘n óò pa dà sí Gíríìsì kódà bí n óò bá fẹ́rẹ̀ẹ́ rìnhòòhò dẹ́bẹ̀.’

Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún ní Gíríìsì

Ìgbà ìrúwé 1934 bá mi nínú ọkọ̀ òkun àwọn ará Ítálì, Duilio. Mo dé Marseilles, nílẹ̀ Faransé, lẹ́yìn tí mo sì ti wà níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́wàá, mo wọ ọkọ̀ òkun, Patris, tí ó jẹ́ ọkọ̀ akérò, lọ sí Gíríìsì. Nígbà tí a wà lórí òkun, ẹ́ńjìnnì ọkọ̀ ojú omi náà yọnu, nígbà tí ó sì di òru, a pàṣẹ pé kí a ju àwọn ọkọ̀ tí a fi ń gba ẹ̀mí là sínú òkun. Lẹ́yìn náà, mo rántí èrò mi láti dé Gíríìsì bí yóò tilẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ní ìhòòhò. Ṣùgbọ́n, ọkọ ojú omi tí ń fa òkú ọkọ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ará Ítálì dé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó sì fà wá lọ sí Naples, Ítálì. Lẹ́yìn náà, a gúnlẹ̀ sí Piraiévs (Piraeus), Gíríìsì.

Láti ibẹ̀, mo forí lé Áténì, níbi tí mo ti ṣèbẹ̀wò sí ọ́fíìsì ẹ̀ka ti Watch Tower Society. Nígbà tí mo ń bá Athanassios Karanassios, alábòójútó ẹ̀ka, sọ̀rọ̀, mo béèrè fún iṣẹ́ àyànfúnni wíwàásù lákòókò kíkún. Ní ọjọ́ kejì, mo ti wà lójú ọ̀nà sí Peloponnisos, ní apá gúúsù orí ilẹ̀ Gíríìsì gan-an. A yan gbogbo àgbègbè yí fún mi gẹ́gẹ́ bí àgbègbè ìpínlẹ̀ tèmi!

Pẹ̀lú ìtara tí kò láàlà, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù, ní lílọ láti ìlú dé ìlú, láti abúlé dé abúlé, láti oko dé oko, láti ilé àdádó sí ilé àdádó. Kò pẹ́ púpọ̀ tí Michael Triantafilopoulos, ẹni tí ó ṣe ìrìbọmi fún mi ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn 1935 fi dara pọ̀ mọ́ mi—ohun tí ó lé ní ọdún kan lẹ́yìn tí mo ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún! Kò sí ọkọ̀ tí ń ná ọ̀nà ibẹ̀, nítorí náà, ẹsẹ̀ ni a fi ń rìn lọ sí ibi gbogbo. Ìṣòro wa tí ó tóbi jù lọ ni àtakò àwùjọ àlùfáà, tí wọ́n ṣe tán láti ṣe ohunkóhun láti dá wa dúró. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, a dojú kọ ẹ̀tanú púpọ̀. Síbẹ̀, láìka àwọn ìdènà sí, a jẹ́rìí, a sì polongo orúkọ Jèhófà jákèjádò.

Fífarada Àtakò

Lówùúrọ̀ ọjọ́ kan, bí mo ṣe ń wàásù ní àwọn òkè àgbègbè Arcadia, mo dé abúlé Magouliana. Lẹ́yìn jíjẹ́rìí fún wákàtí kan, mo gbọ́ tí aago ṣọ́ọ̀ṣì dún, kò sì pẹ́ tí mo fi mọ̀ pé nítorí tèmi ni wọ́n ṣe laago! Àwùjọ ènìyànkénìyàn kan kóra jọ lábẹ́ ìdarí archimandrite ti Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ilẹ̀ Gíríìsì (àlùfáà olóyè ńlá kan tí ó rẹlẹ̀ sí ti bíṣọ́ọ̀bù nínú ṣọ́ọ̀ṣì). Kíá ni mo pa àpò ìjẹ́rìí mi dé, ti mo sì gbàdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́ sí Jèhófà. Archimandrite náà, pẹ̀lú ogunlọ́gọ̀ ọmọdé tí ń wọ́ tẹ̀ lé e, ń sáré tẹ̀ lé mi. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo pé, “Òun nìyẹn! Òun nìyẹn!”

Àwọn ọmọdé náà pagbo yí mi ká, àlùfáà náà sì bọ́ síwájú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ikùn rẹ̀ tí ó yọ bọnbọ tì mí, ní sísọ pé òun kò fẹ́ kí ọwọ́ òun kàn mí ‘nítorí kí òun má baà di aláìmọ́.’ Ó lọgun pé, “Ẹ lù ú! Ẹ lù ú!” Ṣùgbọ́n, ní àkókò náà gan-an ni ọlọ́pàá kan yọ, tí ó sì mú àwa méjèèjì lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá. A mú àlùfáà náà wá fún ìgbẹ́jọ́ fún ríru àwùjọ akọluni sókè, a sì ní kí ó san 300 drachma owó ìtanràn pẹ̀lú ìnáwó kóòtù. A dá mi sílẹ̀ lómìnira.

Nígbà tí a dé àgbègbè tuntun, a fi ìlú ńlá kan ṣe ojúkò ìgbòkègbodò wa, láti ibẹ̀, a ń kárí gbogbo àgbègbè ìpínlẹ̀ láàárín ìrìn wákàtí mẹ́rin. Ìyẹn túmọ̀ sí pé a óò gbéra láàárọ̀ nígbà tí ilẹ̀ kò tí ì mọ́, a óò sì pa dà sílé lẹ́yìn ti ilẹ̀ ti ṣú, ní ṣíṣèbẹ̀wò sí abúlé kan tàbí méjì lọ́jọ́ kan ní gbogbogbòò. Lẹ́yìn kíkárí àwọn abúlé tí ó wà nítòsí, a wàásù ní ìlú tí a fi ṣe ojúkò, a sì lọ sí àgbègbè míràn. Lọ́pọ̀ ìgbà, a fàṣẹ ọba mú wa nítorí pé àwùjọ àlùfáà ru àwọn ènìyàn sókè sí wa. Ní ẹkùn Parnassus, ní àárín gbùngbùn Gíríìsì, àwọn ọlọ́pàá wá mi kiri fún ọ̀pọ̀ oṣù. Ṣùgbọ́n, ọwọ́ wọn kò tẹ̀ mí rí.

Lọ́jọ́ kan, èmi àti Arákùnrin Triantafilopoulos ń wàásù ní abúlé Mouríki ní àgbègbè Boeotia. A pín abúlé náà sí apá méjì, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ ní ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé èmi ni ó kéré jù. Lójijì mo gbọ́ igbe nísàlẹ̀. Bí mo ti ń sáré lọ sísàlẹ̀, mo ń dá ronú pé, ‘A ti ń lu Arákùnrin Triantafilopoulos.’ Àwọn ará abúlé ti pé jọ sínú ilé kọfí tí ó wà ládùúgbò, àlùfáà kan sì ń lọ sókè sódò bíi màlúù tí inú ń bí. Ó ń pariwó pé: “Àwọn ènìyàn wọ̀nyí pè wá ní ‘irú-ọmọ Ejò.’”

Àlùfáà náà ti dá ọ̀páàtilẹ̀ kan mọ́ Arákùnrin Triantafilopoulos lórí, ẹ̀jẹ̀ sì ń ṣàn wá sí ojú rẹ̀. Lẹ́yìn tí mo nu ẹ̀jẹ̀ náà tán, ó ṣeé ṣe fún wa láti lọ. A rìn fún wákàtí mẹ́ta kí a tó dé ìlú Thebes. Níbẹ̀, nínú ilé ìwòsàn kékeré kan, a tọ́jú ọgbẹ́ náà. A fi ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó àwọn ọlọ́pàá létí, a sì pẹjọ́. Ṣùgbọ́n, àlùfáà náà lẹ́sẹ̀, a sì dá a sílẹ̀ lómìnira lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.

Nígbà tí a ń ṣiṣẹ́ ní ìlú Leukas, àwọn ọmọlẹ́yìn ọ̀kan nínú àwọn aṣáájú òṣèlú ní àgbègbè náà “fàṣẹ ọba mú” wa, ó sì mú wa lọ sí ilé kọfí tí ó wà ní abúlé náà, níbi tí a ti bá ara wa tí a ń fẹ̀sùn kàn wá nínú kóòtù yẹ̀yẹ́ kan. Aṣáájú òṣèlù náà àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ ń lọ síwá sẹ́yìn níwájú wa, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀—wọ́n ń sọ̀rọ̀ burúkú léraléra—wọ́n sì ń fi ìkúùkù wọn tí wọ́n dì halẹ̀ mọ́ wa. Gbogbo wọn ti yó kẹ́ri. Ọ̀rọ̀ burúkú tí wọ́n ń sọ ń bá a nìṣó láti ọ̀sán títí di ìrọ̀lẹ́, ṣùgbọ́n a kò fòyà, a sì ń rẹ́rìn-ín músẹ́ bí a ti ń jẹ́wọ́ àìmọwọ́mẹsẹ̀ wa, tí a sì ń gbàdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́ sí Jèhófà Ọlọ́run wa láti ràn wá lọ́wọ́.

Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, àwọn ọlọ́pàá méjì gbà wá sílẹ̀. Wọ́n mú wa lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá, wọ́n sì tọ́jú wa dáradára. Láti lè dá ìgbésẹ̀ rẹ̀ láre, aṣáájú òṣèlú náà wá ní ọjọ́ kejì, ó sì fẹ̀sùn kàn wá pé a ń gbékèé yíde nípa Ọba ilẹ̀ Gíríìsì. Nítorí náà, àwọn ọlọ́pàá rán àwa àti àwọn ọkùnrin méjì lọ sí ìlú Lamia fún ìwádìí síwájú sí i. A fi wá sí àhámọ́ fún ọjọ́ méje, a sì mú wa lọ sí ìlú Larissa fún ìgbẹ́jọ́ pẹ̀lú ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ lọ́wọ́.

Àwọn Kristẹni arákùnrin wa ní Larissa, tí a ti sọ fún tẹ́lẹ̀ pé a ń bọ̀, ń dúró dè wá. Ìfẹ́ni ńláǹlà tí wọ́n fi hàn sí wa jẹ́ ẹ̀rí àtàtà fún àwọn ẹ̀ṣọ́. Agbẹjọ́rò wa, ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí ó sì jẹ́ ọ̀gágun tẹ́lẹ̀, jẹ́ ẹni tí a mọ̀ bí ẹni mowó ní ìlú náà. Nígbà tí ó fara hàn ní kóòtù, tí ó sì gbẹjọ́ wa rò, a tú ẹ̀sùn tí a fi kàn wá fó pé ó jẹ́ irọ́, a sì dá wa sílẹ̀ lómìnira.

Ìkẹ́sẹjárí gbogbogbòò tí ìwàásù Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní, yọrí sí àtakò mímúná sí i. A ṣòfin tí ó ka ìsọnidaláwọ̀ṣe léèwọ̀ ní 1938 àti 1939, èmi àti Michael sì fara gbá nínú ọ̀pọ̀ ìgbẹ́jọ́ kóòtù lórí ọ̀ràn yí. Lẹ́yìn náà, ọ́fíìsì ẹ̀ka rọ̀ wá láti ṣiṣẹ́ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, kí a má baà pe àfiyèsí púpọ̀ sórí ìgbòkègbodò wa. Ó ṣòro fún mi láti máà ní alábàáṣiṣẹ́. Síbẹ̀, ní gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà, mo fẹsẹ̀ rin àwọn àgbègbè Attica, Boeotia, Phthiotis, Euboea, Aetolia, Acarnania, Eurytania, àti àgbègbè Peloponnisos.

Ohun tí ó ràn mí lọ́wọ́ ní sáà yí ni àwọn ọ̀rọ̀ rere tí onísáàmù sọ nípa gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà pé: “Pẹ̀lú rẹ èmi súré la inú ogun lọ: àti pẹ̀lú Ọlọ́run mi èmi fo odi kan. Ọlọ́run ni ó fi agbára dì mí ní àmùrè, ó sì mú ọ̀nà mi pé. Ó ṣe ẹsẹ̀ mi bí ẹsẹ̀ àgbọ̀nrín, ó sì gbé mi ka ibi gíga.”—Orin Dáfídì 18:29, 32, 33.

Ní 1940, Ítálì gbógun dìde sí Gíríìsì, kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà tí àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Germany fi gbé sùnmọ̀mí wọ orílẹ̀-èdè náà. A gbé òfin ológun kalẹ̀, a sì fòfin de àwọn ìwé Watch Tower Society. Àwọn àkókò wọ̀nyẹn le koko fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Gíríìsì; síbẹ̀, wọ́n pọ̀ sí i ní iye lọ́nà tí ó múni jí gìrì—láti orí 178 Ẹlẹ́rìí ní 1940 sí 1,770 nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì dópin ní 1945!

Ṣíṣiṣẹ́sìn ní Bẹ́tẹ́lì

Ní 1945, a pè mí láti wá ṣiṣẹ́ sìn ní ọ́fíìsì ẹ̀ka ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ní Áténì. Bẹ́tẹ́lì, tí ó túmọ̀ sí “Ilé Ọlọ́run,” wà ní ilé kan tí a háyà nígbà náà lọ́hùn-ún, ní Òpópónà Lombardou. Àwọn ọ́fíìsì wà ní àjà kíní, ilé ìtẹ̀wé sì wà ní ìsàlẹ̀. Ó ní ẹ̀rọ ìtẹ̀wé kékeré kan àti ẹ̀rọ ìgétí ìwé. Lákọ̀ọ́kọ́, ẹni méjì péré ni òṣìṣẹ́ níbi ìtẹ̀wé, ṣùgbọ́n, láìpẹ́, àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni mìíràn bẹ̀rẹ̀ sí í fẹsẹ̀ rìn wá láti ilé wọn láti ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ náà.

A fìdí kíkàn sí orílé-iṣẹ́ Watch Tower Society ní Brooklyn, New York, múlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i ní 1945, a sì tún bẹ̀rẹ̀ títẹ Ilé Ìṣọ́ déédéé ní ọdún yẹn ní Gíríìsì. Lẹ́yìn náà, ní 1947, a gbé ẹ̀ka wa lọ sí 16 Òpópónà Tenedou, ṣùgbọ́n, ilé ìtẹ̀wé ṣì wà ní Òpópónà Lombardou. Lẹ́yìn náà, a kó ilé ìtẹ̀wé náà kúrò ní Òpópónà Lombardou lọ sí ilé iṣẹ́ kan tí ó jẹ́ ti Ẹlẹ́rìí kan ní nǹkan bíi kìlómítà márùn-ún sí ibẹ̀. Nítorí náà, fún ìgbà kan, a ń lọ síwá sẹ́yìn láàárín ibi mẹ́ta.

Mo lè rántí fífi ibùgbé wa sílẹ̀ ní Òpópónà Tenedou ní kòríni-kòmọni, tí n óò sì rìnrìn-àjò lọ sí ilé ìtẹ̀wé. Lẹ́yìn tí mo bá ṣiṣẹ́ níbẹ̀ di aago kan ọ̀sán, n óò lọ sí Òpópónà Lombardou níbi tí a ń kó àwọn bébà ìwé tí a ti tẹ̀ sí. Níbẹ̀ ni a óò ti ká wọn sí ìwé ìròyìn, a óò gán wọn pọ̀, a óò sì fi ọwọ́ tọ́ etí wọn gún. Lẹ́yìn náà, a óò kó àwọn ìwé ìròyìn tí a ti parí lọ sí ilé ìfìwéránṣẹ́, a óò kó wọn lọ sí àjà kẹta, a óò ran àwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀ lọ́wọ́ láti pín wọn, a óò sì lẹ sítáǹbù mọ́ ara àpòòwé wọn fún fífi wọ́n ránṣẹ́.

Nígbà tí yóò fi di 1954, iye Àwọn Ẹlẹ́rìí ní Gíríìsì ti ju 4,000 lọ, a sì nílò ilé lílò tí ó tóbi sí i. Nítorí náà, a ṣí lọ sí Bẹ́tẹ́lì tuntun alájà mẹ́ta, ní ìsàlẹ̀ ìlú Áténì, ní Òpópónà Kartali. Ní 1958, a ní kí n máa bójú tó ilé ìdáná, ìyẹn ṣì ni ẹrù iṣẹ́ mi títí di 1983. Láàárín àkókò náà, ní 1959, mo gbé Eleftheria níyàwó, ẹni tí ó jẹ́ adúróṣinṣin olùrànlọ́wọ́ mi nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.

Fífarada Àtakò Lẹ́ẹ̀kan Sí I

Ní 1967, àwùjọ ológun kan gbàjọba, a sì fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa lẹ́ẹ̀kan sí i. Bí ó ti wù kí ó rí, nítorí ìrírí wa àtẹ̀yìnwá ní kíkojú fífòfinde àwọn ìgbòkègbodò wa, a tètè mú ara wa bá ipò mu, tí a sì ń bá iṣẹ́ wa lọ ní pẹrẹwu lábẹ́lẹ̀.

A ń ṣe ìpàdé wa ní àwọn ilé àdáni, a sì ń lo ìṣọ́ra nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà. Síbẹ̀síbẹ̀, a máa ń fàṣẹ ọba mú àwọn arákùnrin wa nígbà gbogbo, ẹjọ́ ní kóòtù sì ń pọ̀ sí i. Àwọn agbẹjọ́rò wa máa ń rìnrìn-àjò nígbà gbogbo láti lè bójú tó ìgbẹ́jọ́ tí a ń ṣe ní apa ibi púpọ̀ ní orílẹ̀-èdè náà. Láìka àtakò sí, ọ̀pọ̀ jù lọ Àwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣe déédéé nínú ìgbòkègbodò ìwàásù wọn, ní pàtàkì, ní àwọn òpin ọ̀sẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí àṣà, ní ọjọ́ Saturday tàbí Sunday kan lẹ́yìn tí a bá ti parí ìwàásù wa fún ọjọ́ náà, a óò ṣàyẹ̀wò láti mọ ẹni tí kò sí nínú àwùjọ wa. Ní gbogbogbòò, àwọn tí a kò bá rí ni a ti dá dúró sí àgọ́ ọlọ́pàá tí ó sún mọ́ wa jù lọ. Nítorí náà, a óò mú kúbùsù àti oúnjẹ lọ fún wọn, a óò sì fún wọn níṣìírí. Nítorí náà, a óò fi tó àwọn agbẹjọ́rò wa létí, wọ́n yóò sì fara hàn ní ọjọ́ Monday ṣáájú kí agbẹjọ́rò olùpẹ̀jọ́ tó gbẹjọ́ àwọn tí a tì mọ́lé rò. A fi ayọ̀ dojú kọ ipò yí, nítorí pé, a ń jìyà nítorí òtítọ́!

Nígbà ìfòfindè náà, a ti ilé ìtẹ̀wé wa ní Bẹ́tẹ́lì pa. Nítorí náà, ilé tí èmi àti Eleftheria ń gbé ní ẹ̀yìn odi Áténì di ilé ìtẹ̀wé kan. Eleftheria yóò tẹ àwọn ẹ̀dà àpilẹ̀kọ Ilé Ìṣọ́ ní lílo ẹ̀rọ ìtẹ̀wé aláfọwọ́tẹ̀ ńlá kan. Yóò fi bébà mẹ́wàá sínú ẹ̀rọ ìtẹ̀wé aláfọwọ́tẹ̀ náà lẹ́ẹ̀kan, yóò sì fi agbára tẹ̀ ẹ́ kanlẹ̀ dáradára, kí àwọn lẹ́tà náà baà lè hàn lórí wọn. Lẹ́yìn náà, n óò kò àwọn ojú ìwé náà, ń óò sì gán wọn pọ̀. Èyí ń bá a lọ ní gbogbo ìrọ̀lẹ́ títí di ọ̀gànjọ́ òru. Ọlọ́pàá kan ń gbé ní ìsàlẹ̀, a ṣì ń ṣe kàyéfì ìdí tí kò fi fura.

Kíkún fún Ayọ̀ Nínú Ìmúgbòòrò Tí Ń Bá A Nìṣó

A dá ìjọba tiwa-n-tiwa pa dà sí Gíríìsì ní 1974, a sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá iṣẹ́ ìwàásù wa lọ ní gbangba lẹ́ẹ̀kan sí i. Síbẹ̀, ní gbogbo ọdún méje tí a fi fòfin de iṣẹ́ wa, a gbádùn ìbísí kíkàmàmà ti iye tí ó ju 6,000 Àwọn Ẹlẹ́rìí tuntun, ní díde iye tí ó lé ní 17,000 àwọn olùpòkìkí Ìjọba lápapọ̀.

A tún bẹ̀rẹ̀ ìgbòkègbodò ìtẹ̀wé wa ní àyíká ẹ̀ka náà lẹ́ẹ̀kan sí i. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, ilé lílò Bẹ́tẹ́lì ní Òpópónà Kartali kò gbà wá mọ́. Nítorí náà, a ra ilẹ̀ hẹ́kítà kan ní ẹ̀yìn odi Áténì ti Marousi. A kọ́ ilé Bẹ́tẹ́lì tuntun tí ó ní yàrá 27, ilé ìtẹ̀wé, ọ́fíìsì, àti àwọn ilé lílò míràn. A ya ìwọ̀nyí sí mímọ́ ní October 1979.

Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, a tún ṣì nílò àyè púpọ̀ sí i. Nítorí náà, a ra hẹ́kítà 22 ní nǹkan bí 60 kìlómítà ní ìhà àríwá Áténì. Ilẹ̀ náà wà ní Eleona, lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè tí a ti lè máa wo àwọn òkè ńlá àti àfonífojì tí omi rin gbingbin. Níbẹ̀, ní April 1991, a ya ilé lílò tí ó tóbi ju ti tẹ́lẹ̀ lọ tí ó ní ilé 22 sí mímọ́, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan sì lè gba ènìyàn mẹ́jọ.

Lẹ́yìn lílo 60 ọdún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, a ṣì fi ìlera jíjí pépé jíǹkí mi. Mo láyọ̀ pé, mò ń “so èso níbẹ̀ nígbà ogbó.” (Orin Dáfídì 92:14) Mo dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ Jèhófà pé, mo wà láàyè láti fojú ara mi rí ìbísí kíkọyọyọ nínú iye àwọn olùjọsìn rẹ̀ tòótọ́. Wòlíì Aísáyà sàsọtẹ́lẹ̀ irú ìbísí bẹ́ẹ̀ pé: “Àwọn ààsẹ̀ rẹ yóò ṣí sílẹ̀ nígbà gbogbo; a kì yóò sé wọn lọ́sàn-án tàbí lóru, kí a lè mú ọlá àwọn Kèfèrí wá sọ́dọ̀ rẹ, kí a baà sì mú àwọn ọba wọn wá.”—Aísáyà 60:11.

Ẹ wo bí ó ti jẹ́ àgbàyanu tó láti rí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn láti orílẹ̀-èdè gbogbo tí ń rọ́ wọnú ètò àjọ Jèhófà, tí a sì ń kọ́ wọn láti la ìpọ́njú ńlá já sínú ayé tuntun Ọlọ́run! (Pétérù Kejì 3:13) Mo lè sọ ní tòótọ́ pé, iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti ṣeyebíye fún mi ju ohunkóhun mìíràn tí ayé ní láti fi fúnni lọ. Bẹ́ẹ̀ ni, kì í ṣe ìṣura wúrà ni mo rí, bí kò ṣe dáyámọ́ńdì tẹ̀mí tí ó ti mú ìgbésí ayé mi sunwọ̀n sí i ju bí mo ti rò lọ.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Michalis àti Eleftheria Kaminaris

(Ọwọ́ ọ̀tún) Ilé ìtẹ̀wé tí ó wà ní Òpópónà Lombardou

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́