ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 9/1 ojú ìwé 25-28
  • Ṣíṣiṣẹ́ Sin Ọlọ́run Tí Ó Ṣeé Gbẹ́kẹ̀ Lé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣíṣiṣẹ́ Sin Ọlọ́run Tí Ó Ṣeé Gbẹ́kẹ̀ Lé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Dídàgbà ní Ilẹ̀ Gíríìsì
  • Nígbà Tí Ogun Abẹ́lé Ń Jà Lọ́wọ́
  • Rírí Ìrètí Tí Ó Ṣeé Gbára Lé
  • Ọwọ́ Tẹ̀ Mí, A Sì Fi Mí Sẹ́wọ̀n
  • A Fẹ̀sùn Sísọni Daláwọ̀ṣe Kàn Mí
  • Ikú Ọmọkùnrin Mi
  • Ríran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
  • Ogún Tabua
  • Mo Pinnu Láti Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
  • Ṣíṣiṣẹ́ Sìn Lábẹ́ Ọwọ́ Ìfẹ́ Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Fífún Jèhófà Ní Ohun Tó Tọ́ Sí I
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ohun Tí Ó Lé Ní 50 Ọdún ‘Ríré Kọjá Wá’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • A Dàn Mi Wò Lọ́nà Tó Múná
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 9/1 ojú ìwé 25-28

Ṣíṣiṣẹ́ Sin Ọlọ́run Tí Ó Ṣeé Gbẹ́kẹ̀ Lé

Gẹ́gẹ́ bí Kimon Progakis ṣe sọ ọ́

Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan tí òtútù mú gan-an ní ọdún 1955. Ọkàn èmi àti aya mi, Giannoula, kò balẹ̀ mọ́, nítorí pé ọmọkùnrin wa ẹni ọdún 18, George, kò tí ì ti ṣọ́ọ̀bù tí ó ti ń ṣiṣẹ́ dé. Lójijì, ọlọ́pàá kan kanlẹ̀kùn wa. Ó wí pé: “Ọkọ̀ kọ lu ọmọ yín nígbà tí ó ń gun kẹ̀kẹ́ bọ̀ wálé, ó sì ti kú.” Lẹ́yìn náà, ó tẹ orí síwájú, ó sì sọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́ pé: “Wọn yóò wí fún un yín pé ìjàm̀bá ọkọ̀ ni, ṣùgbọ́n kí n má parọ́, wọ́n pa á ni.” Àlùfáà àdúgbò àti àwọn ọ̀gá ọmọ ogun olùrànlọ́wọ́ kan ni wọ́n dìtẹ̀ pa á.

NÍ ÀWỌN ọdún wọ̀nyẹn, nígbà tí ilẹ̀ Gíríìsì ń kọ́fẹ padà láti inú àkókò gbọ́nmisi-omi-ò-to àti ìnira, ó léwu láti jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo mọ̀ nípa agbára Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì àti àwọn ètò àjọ ọmọ ogun olùrànlọ́wọ́ ní tààràtà, nítorí pé, ó ti lé ní ọdún 15, tí mo fi jẹ́ ògbóṣáṣá mẹ́ḿbà wọn. Jẹ́ kí n fi àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó yọrí sí ọ̀ràn ìbànújẹ́ yìí nínú ìdílé mi ní èyí tí ó lé ní 40 ọdún sẹ́yìn tó ọ létí.

Dídàgbà ní Ilẹ̀ Gíríìsì

A bí mi ní ọdún 1902, sínú ìdílé kan tí ó rí jájẹ, ní ìletò kan nítòsí ìlú Chalcis, ní ilẹ̀ Gíríìsì. Bàbá mi jẹ́ ògbóṣáṣá nínú ọ̀ràn ìṣèlú àdúgbò, ìdílé wa sí jẹ́ mẹ́ḿbà olùfọkànsìn ti Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì. Nígbà tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọ ìlú mi jẹ́ púrúǹtù, mo di ẹni tí ń yán hànhàn fún kíka ìwé ìṣèlú àti ti ìsìn.

Ipò òṣì àti àìsídàájọ́ òdodo tí ó gbalé gbòde ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún jẹ́ kí ń ní ìfẹ́ ọkàn fún ayé kan tí ìpò rẹ̀ sàn jù. Mo ronú pé, ó yẹ kí ìsìn lè mú ipò ìbànújẹ́ tí àwọn ọmọ ìlú mí wà sunwọ̀n sí i. Nítorí tí mo ní ìtẹ̀sí fún ṣíṣe ìsìn, àwọn àgbààgbà abúlé mi pète pé kí n di àlùfáà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì ti àwùjọ wa. Ṣùgbọ́n, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti ṣèbẹ̀wò sí ọ̀pọ̀ ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé, tí mo sì bá àwọn bíṣọ́ọ̀bù àti olórí ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìsìn sọ̀rọ̀, n kò ṣe tán láti tẹ́wọ́ gba irú ẹrù iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ tàbí kí ń tilẹ̀ fi tinútinú gbà á.

Nígbà Tí Ogun Abẹ́lé Ń Jà Lọ́wọ́

Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ní April ọdún 1941, ilẹ̀ Gíríìsì bọ́ sábẹ́ ìdarí Nazi. Èyí jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ sáà ìbànújẹ́ ti ìpànìyàn, ìyàn, òfò, àti ìjìyà ẹ̀dá ènìyàn tí kò ṣeé fẹnu sọ. A dá àjọ ajàjàgbara kan tí ó lágbára sílẹ̀, mo sì dara pọ̀ mọ́ àwùjọ àwọn ọ̀jagun abẹ́lẹ̀ tí wọ́n bá àwọn Nazi onísùnmọ̀mí jà. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, a dáná sun ilé mi ní ọ̀pọ̀ ìgbà, a ta mí níbọn, a sì ba ohun ọ̀gbìn mi jẹ́. Ní kùtùkùtù ọdún 1943, kò sí ohun tí èmi àti ìdílé mi lè ṣe ju kí a sá lọ sí àwọn òkè gbágungbàgun. A wà níbẹ̀ títí tí àwọn ará Germany fi káńgárá wọn ní October ọdún 1944.

Gbọ́nmisi-omi-ò-to ti ìṣèlú àti ti abẹ́lé bẹ́ sílẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn ará Germany lọ. Àwùjọ ajàjàgbara, ọ̀jagun abẹ́lẹ̀, ti mo wà di ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ogun pàtàkì nínú ogun abẹ́lé náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo nífẹ̀ẹ́ sí èròǹgbà ìdájọ́ òdodo, àparò-kan-ò-ga-jùkan-lọ, àti jíjẹ́ mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ kan náà ti ìjọba Kọ́múníìsì, ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ohun tí mo rò pé ó jẹ́ òtítọ́ já mi kulẹ̀ pátápátá. Níwọ̀n bí mo ti wà ní ipò gíga láwùjọ náà, tààràtà ni mo rí i pe agbára máa ń gunni. Láìka àwọn àbá èrò orí àti èròǹgbà wíwúni lórí sí, ìmọtara-ẹni-nìkan àti àìpé máa ń ba èrò tí ó dára jù lọ ní ti ìṣèlú jẹ́.

Ohun tí ó yà mí lẹ́nu jù lọ ní pàtàkì ni pé, ní onírúurú ìhà tí ìforígbárí abẹ́lé náà ti ṣẹlẹ̀, àwùjọ àlùfáà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ń gbé ohun ìjà láti pa àwọn tí wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà ìsìn wọn! Mo ronú ara mi pé, ‘Báwo ni àwùjọ àlùfáà wọ̀nyí ṣe lè sọ pé àwọn ń ṣojú fún Jésù Kristi, ẹni tí ó kìlọ̀ pé: “Gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà”?’—Mátíù 26:52.

Nígbà ogun abẹ́lé náà, ní ọdún 1946, mo fara pamọ́ nítòsí ìlú Lamia, ní àárín gbùngbùn ilẹ̀ Gíríìsì. Aṣọ mi kò ṣeé rí mọ́ rárá, nítorí náà, mo pinnu láti díbọ́n, kí n lọ sọ́dọ̀ télọ̀ kan nínú ìlú, kó lè bá mi ran tuntun. Àríyànjiyàn gbígbóná janjan kan ń lọ́ lọ́wọ́ nígbà tí mo débẹ̀, ká wí ká fọ̀ èmi náà ti ń bá wọn dá sí i, kì í ṣe ọ̀rọ̀ ìṣèlú ni mo ń sọ, bí kò ṣe ohun tí mo nífẹ̀ẹ́ sí tẹ́lẹ̀, ìsìn. Nígbà tí wọ́n kíyè sí ojú ìwòye olóye tí mo ní, àwọn tí ń wò wá dámọ̀ràn pé kí n bá ‘ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ ìsìn’ kan báyìí sọ̀rọ̀. Kíá, wọ́n ti lọ pè é wá.

Rírí Ìrètí Tí Ó Ṣeé Gbára Lé

Nínú ìjíròrò tí ó tẹ̀ lé e, “ọ̀jọ̀gbọ́n” náà béèrè pé, orí kí ni mo gbé ìgbàgbọ́ mi kà. Mo fèsì pé: “Àwọn Bàbá Mímọ́ àti Ẹgbẹ́ Alákòóso Ìsìn Yíká Ayé ni.” Dípò títakò mí, ó ṣí Bíbélì kékeré tí ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀ sí Mátíù 23:9, 10, ó sì ní kí n ka àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ níbẹ̀ pé: “Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ má ṣe pe ẹnikẹ́ni ní bàbá yín lórí ilẹ̀ ayé, nítorí ọ̀kan ni Bàbá yín, Ẹni ti ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni kí a má ṣe pè yín ní ‘aṣáájú,’ nítorí ọ̀kan ni Aṣáájú yín, Kristi.”

Ìyẹn ni ó là mí lójú! Mo nímọ̀lára pé òtítọ́ ni ọkùnrin yìí ń sọ. Nígbà tí ó sọ pé ọ̀kan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni òun jẹ́, mo béèrè fún àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ díẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ láti kà. Ó bá mi mú ìwé náà, Light, tí ó jẹ́ àlàyé lórí ìwé Bíbélì náà, Ìṣípayá, wá, mo sì mú un lọ sí ibi tí mo fara pamọ́ sí. Fún ìgbà pípẹ́, àdììtú ni ẹranko ẹhànnà tí a tọ́ka sí nínú Ìṣípayá jẹ́ fún mi, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, mo kọ́ pé àwọn wọ̀nyí dúró fún àwọn ètò àjọ ìṣèlú tí ó wà ní ọ̀rúndún ogún tiwa. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í lóye pé, Bíbélì ní ìtumọ̀ ṣíṣeé múlò fún àkókò wa àti pè mo ní láti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, kí n sì mú kí ìgbésí ayé mi bá òtítọ́ rẹ̀ mu.

Ọwọ́ Tẹ̀ Mí, A Sì Fi Mí Sẹ́wọ̀n

Kété lẹ́yìn náà, àwọn sójà já wọ ibi tí mo fara pamọ́ sí, wọ́n sì fàṣẹ ọba mú mi. A jù mí sí àjàalẹ̀. Níwọ̀n bí ó ti pẹ́ díẹ̀ tí mo ti jẹ́ arúfin tí à ń wá kiri, ńṣe ni ó yẹ kí a yẹgi mọ́ mi. Níbẹ̀, nínú àhámọ́ tí mo wà, Ẹlẹ́rìí tí ó bá mi sọ̀rọ̀ lákọ̀ọ́kọ́ kàn sí mi. Ó fún mi níṣìírí láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, mo sì ṣe bẹ́ẹ̀. A rán mi ní ìgbèkùn fún oṣù mẹ́fà ní erékùṣù Aegea ti Ikaria.

Gbàrà tí mo débẹ̀, mo fi ara mi hàn gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí olójú ìwòye ìjọba Kọ́múníìsì. Àwọn mìíràn tí wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì wà ní ìgbèkùn níbẹ̀ pẹ̀lú, nítorí náà mo wá wọn kàn, a sì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀ déédéé. Wọ́n ràn mí lọ́wọ́ láti jèrè ìmọ̀ sí i láti inú Ìwé Mímọ́, kí ń sì túbọ̀ lóye Ọlọ́run wa tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, Jèhófà.

Ní ọdún 1947, nígbà tí àkókò ìfisẹ́wọ̀n mi dópin, a pè mí sí ọ́fíìsì agbẹjọ́rò fún gbogbo ènìyàn. Ó sọ fún mi pé, ìwà mi wú òun lórí àti pé mo lè fi òun ṣe onídùúró bí a óò bá tún padà rán mi nígbèkùn. Nígbà tí mo dé Áténì, ibi tí ìdílé mi ṣí lọ nígbà tí mo wà nígbèkùn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kò sì pẹ́ púpọ̀ tí mo fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi sí Jèhófà hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi.

A Fẹ̀sùn Sísọni Daláwọ̀ṣe Kàn Mí

Fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, ilẹ̀ Gíríìsì pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́jọ́ lábẹ́ òfin tí a ṣe ní ọdún 1938 àti 1939, tí ó ka sísọni daláwọ̀ṣe léèwọ̀. Nípa báyìí, láti ọdún 1938 sí 1992, 19,147 àwọn Ẹlẹ́rìí ni a fàṣẹ ọba mú ní ilẹ̀ Gíríìsì, kóòtù sì rán wọn ní ẹ̀wọ̀n tí àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ 753 ọdún, nínú èyí, wọ́n ṣẹ̀wọ̀n 593 ọdún ní ti gidi. Ní tèmi, ó ju 40 ìgbà lọ tí a fàṣẹ ọba mú mi fún wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, lápapọ̀, mo lo oṣù 27 nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Ọ̀kan nínú ìdí tí a fi fàṣẹ ọba mú mi jẹ́ nítorí lẹ́tà kan tí mo kọ sí àlùfáà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì kan ní Chalcis. Ní ọdún 1955, a rọ ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti fi ìwé pẹlẹbẹ náà, Christendom or Christianity—Which One Is “the Light of the World”?, ránṣẹ́ sí gbogbo àlùfáà. Ọ̀kan nínú àwọn àlùfáà onípò gíga tí mo ti kọ lẹ́tà sí pè mí lẹ́jọ́ fún sísọni daláwọ̀ṣe. Nígbà ìgbẹ́jọ́ náà, agbẹjọ́rò kan tí ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí àti agbẹjọ́rò kan ládùúgbò gbé ìgbèjà lọ́nà jíjá fáfá kalẹ̀, ní ṣíṣàlàyé ojúṣe àwọn Kristẹni tòótọ́ láti wàásù ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run.—Mátíù 24:14.

Adájọ́ kóòtù náà bi amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ bíṣọ́ọ̀bù (òye ṣọ́ọ̀ṣì tí kò tó ti bíṣọ́ọ̀bù) pé: “Ǹjẹ́ o ka lẹ́tà àti ìwé pẹlẹbẹ náà?”

Ó fi tìbínútìbínú fèsì pé: “Rárá o, gbàrà tí mo já àpòòwé náà mo fà wọ́n ya, mo sì kó wọn jùnù!”

Adájọ́ náà béèrè pé: “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo ni o ṣe lè sọ pé ọkùnrin yìí sọ ọ́ daláwọ̀ṣe?”

Lẹ́yìn èyí, agbẹjọ́rò wa fúnni ní àpẹẹrẹ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n àti àwọn mìíràn tí wọ́n fi ìwé rẹpẹtẹ ta àwọn ibi àkójọ ìwé kíkà ti gbogbogbòò lọ́rẹ. Ó béèrè pé: “Ìwọ yóò ha sọ pé àwọn ènìyàn wọ̀nyẹn gbìyànjú láti sọ ọ́ daláwọ̀ṣe bí?”

Ó hàn gbangba pé, irú ìgbòkègbodò bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ìsọnidaláwọ̀ṣe. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nígbà tí mo gbọ́ ìdájọ́ náà pé: “O kò jẹ̀bi.”

Ikú Ọmọkùnrin Mi

A kógun ti George, ọmọkùnrin mi, léraléra, lọ́pọ̀ ìgbà nígbà tí àwùjọ àlùfáà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì bá súnná sí i. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni a fàṣẹ ọba mú òun pẹ̀lú nítorí ìtara ọ̀dọ́ tí ó ní nínú pípolongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, àwọn ọ̀tá náà pinnu láti pa á, lọ́wọ́ kan náà, kí wọ́n sì ránṣẹ́ amúniláyàpami kan sí àwa yòó kù láti dáwọ́ wíwàásù dúró.

Ọlọ́pàá tí ó mú ìròyìn ikú George wá sílé wa wí pé, àlùfáà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì tí ó wà ládùúgbò àti àwọn ọ̀gá ọmọ ogun olùrànlọ́wọ́ ni wọ́n dìtẹ̀ pa ọmọkùnrin wa. Irú “ìjàm̀bá” bẹ́ẹ̀ wọ́ pọ̀ ní àwọn àkókò eléwu wọ̀nyẹn. Láìka ẹ̀dùn ọkàn tí ikú rẹ̀ mú wá sí, ńṣe ni a fún ìpinnu wa láti máa jẹ́ ògbóṣáṣá nínú iṣẹ́ ìwàásù àti láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá lókun.

Ríran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà

Ní àárín gbùngbùn àwọn ọdún 1960, aya mi àti àwọn ọmọ mi máa ń lo oṣù ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ní abúlé etíkun ti Skala Oropos, nǹkan bí 50 kìlómítà sí Áténì. Nígbà yẹn, kò sí Ẹlẹ́rìí kankan tí ń gbébẹ̀, nítorí náà a jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà fún àwọn aládùúgbò. Àwọn àgbẹ̀ àdúgbò kan dáhùn padà lọ́nà rere. Níwọ̀n bí àwọn ọkùnrin tí máa ń ṣiṣẹ́ fún àkókò pípẹ́ nínú oko lọ́wọ́ ọ̀sán, a ń bá wọn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní òru, àwọn kan nínú wọn sì di Ẹlẹ́rìí.

Ní rírí bí Jèhófà ṣe ń bù kún ìsapá wa, fún nǹkan bí ọdún 15, a ń rìnrìn àjò lọ síbẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti baà lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn olùfìfẹ́hàn. Nǹkan bí 30 ènìyàn tí a ń bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀ ti tẹ̀ síwájú dórí ṣíṣe ìrìbọmi. Ní ìbẹ̀rẹ̀, a dá àwùjọ ìkẹ́kọ̀ọ́ kan sílẹ̀, a sì yàn mí láti máa darí ìpàdé náà. Lẹ́yìn náà, àwùjọ náà di ìjọ, àwọn Ẹlẹ́rìí tí ó lé ní ọgọ́rùn-ún láti agbègbè yẹn sì ni wọ́n para pọ̀ jẹ́ Ìjọ Malakasa lónìí. Inú wa dùn pé, mẹ́rin nínú àwọn tí a ràn lọ́wọ́ ń ṣiṣẹ́ sìn nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.

Ogún Tabua

Kété lẹ́yìn tí mo ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún Jèhófà, aya mi bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ó sì ṣe ìrìbọmi. Ní sáà líle koko tí a ń ṣe inúnibíni sí wa, ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára síbẹ̀, ó sì dúró ṣinṣin láìyẹsẹ̀ nínú ìwà títọ́ rẹ̀. Kò ráhùn rí nípa ọ̀pọ̀ ìyà tí ń jẹ wá nítorí fífi mí sẹ́wọ̀n léraléra.

Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, a ti darí ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀, ó sì ti ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ lọ́nà gbígbéṣẹ́ nípa gbígbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà rírọrùn àti pẹ̀lú ìtara. Ní lọ́ọ́lọ́ọ́, ó ní ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn tí ó ní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ẹni tí òun ń fún ní ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! déédéé.

Lọ́nà púpọ̀ nítorí ìtìlẹyìn alábàáṣègbéyàwó mi onífẹ̀ẹ́, gbogbo àwọn ọmọ wa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ó wà láàyè àti ìdílé wọn, tí ó ní ọmọ-ọmọ mẹ́fà àti ọmọ ọmọ-ọmọ mẹ́rin nínú, jẹ́ ògbóṣáṣá nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò kojú inúnibíni àti àtakò gbígbóná janjan tí èmi àti aya mi ti kojú, wọ́n ti fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn kíkún sínú Jèhófà, wọ́n sì ń bá rírìn nínú ọ̀nà rẹ̀ nìṣó. Ẹ wo irú ìdùnnú tí yóò jẹ́ fún gbogbo wa láti padà wà pa pọ̀ pẹ̀lú George wa ọ̀wọ́n, nígbà tí ó bá padà wá nínú àjíǹde!

Mo Pinnu Láti Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà

Ní àwọn ọdún wọ̀nyí, mo ti rí bí ẹ̀mí Jèhófà ṣe ń ṣiṣẹ́ lórí àwọn ènìyàn rẹ̀. Ètò àjọ rẹ̀ tí ẹ̀mí ń darí ti ràn mí lọ́wọ́ láti rí i pé, ìsapá ẹ̀dá ènìyàn kò ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. Àwọn ìlérí wọn fún ọjọ́ ọ̀la tí ó sàn jù kò níláárí, irọ́ ńlá ni wọ́n ń já sí.—Orin Dáfídì 146:3, 4.

Láìka ọjọ́ ogbó tí ń dé sí mi àti ìṣòro àìlera mi sí, mo pa gbogbo àfiyèsí mi pọ̀ sórí ìjótìítọ́ ìrètí Ìjọba náà. Ní tòótọ́, mo kábàámọ̀ àwọn ọdún tí mo fi fara jin ìsìn èké, tí mo sì fi gbìyànjú láti lo ọ̀nà ìṣèlú láti mú ipò àwọn nǹkan sunwọ̀n sí i. Ká ni mo tún lè tún ìgbésí ayé mi gbé lẹ́ẹ̀kan sí i ni, kò sí iyè méjì pé n óò tún pinnu láti ṣiṣẹ́ sin Jèhófà, Ọlọ́run tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé.

(Kimon Progakis sùn nínú ikú láìpẹ́ yìí. Ó ní ìrètí gbígbé ní orí ilẹ̀ ayé.)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Fọ́tò tí Kimon yà pẹ̀lú aya rẹ̀, Giannoula, láìpẹ́ yìí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́