ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 10/1 ojú ìwé 26-27
  • Àwọn Àlọ́ Tí Ọlọ́run Mí Sí àti Ète Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Àlọ́ Tí Ọlọ́run Mí Sí àti Ète Ọlọ́run
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àlọ́ Inú Bíbélì Pọ̀ Rẹpẹtẹ
  • Jíjẹ́ Ká Lóye Àṣírí Mímọ́ Náà
  • Títan Ìmọ́lẹ̀ sí “Àwọn Ọ̀rọ̀ Tó Ṣókùnkùn”
  • Wíwo Ìmọ́lẹ̀ Náà
  • Ní Ọgbọ́n, Kí O Sì Gba Ìbáwí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • ‘Ọlọ́run, Rán Ìmọ́lẹ̀ Rẹ Jáde’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Àṣírí Tí Àwọn Kristẹni Kò Jẹ́ Pa mọ́!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Jèhófà—Ọlọ́run Tí Ń ṣí Àṣírí Payá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 10/1 ojú ìwé 26-27

Àwọn Àlọ́ Tí Ọlọ́run Mí Sí àti Ète Ọlọ́run

ÌGBÀ téèyàn ò bá lè túmọ̀ rẹ̀ ló máa ń jẹ́ bàbàrà; ṣùgbọ́n téèyàn bá ti mọ̀ ọ́n tán kì í jọ èèyàn lójú mọ́. Kí ni nǹkan náà? Àlọ́ ni.

Láwùjọ òde ìwòyí tó jẹ́ pé ká ṣáà ti sọjú abẹ níkòó làwọn èèyàn mọ̀, àwọn èèyàn ka àlọ́ sí erémọdé lásán, àmọ́, ìwé atúmọ̀ èdè náà, The Interpreter’s Dictionary of the Bible sọ pé láyé àtijọ́, àlọ́ “ni wọ́n fi ń mọ bí ọgbọ́n ẹnì kan ṣe tó.”—Fi wé Òwe 1:5, 6.

Nígbà mí-ìn, kàkà tí Jèhófà ì bá fi sọ ohun tó fẹ́ ṣe tàbí kó sọ ète rẹ̀ ní ṣàkó, ó máa ń mọ̀ọ́mọ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ lówelówe, nípa lílo àfiwé, “àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣókùnkùn” tó jẹ́ àdììtú ọ̀rọ̀, tàbí àwọn àlọ́ tó lè pinni lẹ́mìí. (Orin Dáfídì 78:2, Bibeli Mimọ; Númérì 12:8, The Emphasized Bible) Àní, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbà mẹ́tàdínlógún péré ni wọ́n lo ọ̀rọ̀ Hébérù tó dúró fún àlọ́ nínú Bíbélì, síbẹ̀ Ìwé Mímọ́ kún fún ọ̀pọ̀ àlọ́ àti òwe.

Àlọ́ Inú Bíbélì Pọ̀ Rẹpẹtẹ

Sólómọ́nì Ọba la ròyìn pé ó rí ojútùú sí àwọn ìbéèrè tí ń pinni lẹ́mìí jù lọ, tàbí lédè mìíràn, ó já àwọn àlọ́, tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀. (1 Àwọn Ọba 10:1, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Ó dájú pé ọgbọ́n tí Ọlọ́run fún un ló fi ṣe èyí. Bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni ìtàn àtijọ́ kan pé Sólómọ́nì fìgbà kan kùnà níbi ìdíje àlọ́ tó ṣe pẹ̀lú Hírámù Ọba Tírè, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé lẹ́yìn tó ti pàdánù ẹ̀mí Jèhófà nítorí tó di apẹ̀yìndà ni ìyẹn ṣẹlẹ̀. Bákan náà ni Sámúsìnì onídàájọ́ fẹ́ràn àlọ́ gan-an. Nígbà kan, ẹ̀mí mímọ́ tó ń ṣiṣẹ́ lára rẹ̀ mú kí ó kó jìnnìjìnnì bá àwọn ọ̀tá Ọlọ́run.—Onídàájọ́ 14:12-19.

Bó ti wù kó rí, ọ̀pọ̀ àwọn àlọ́ inú Bíbélì ló ní í ṣe pẹ̀lú ète Jèhófà ní tààràtà. Fún àpẹẹrẹ, gbé Jẹ́nẹ́sísì 3:15 yẹ̀ wò. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí, tó jẹ́ pé ohun gan-an ni ìpìlẹ̀ ẹṣin ọ̀rọ̀ Bíbélì látòkè délẹ̀ tún wá lọ jẹ́ nǹkan tí ń rúni lójú, ìyẹn “àṣírí mímọ́.” (Róòmù 16:25, 26) Yàtọ̀ sí pé a fi àwọn ìran tó kọjá agbára ẹ̀dá àti àwọn ìṣípayá han àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó tún rí “àwòrán fírífírí” apá kan nínú ète Ọlọ́run, tàbí ní ṣangiliti “àwọn ọ̀rọ̀ tó runi lójú” ni wọ́n jẹ́. (1 Kọ́ríńtì 13:12; 2 Kọ́ríńtì 12:1-4) Ọ̀pọ̀ èrò táwọn èèyàn ní nípa àdììtú nọ́ńbà tó wà lórí ẹranko ẹhànnà—ìyẹn ni “ọgọ́rùn-ún mẹ́fà, ẹẹ́wàá mẹ́fà, àti ẹyọ mẹ́fà”—tó ṣàdédé fara hàn láìsí àlàyé nínú Ìṣípayá 13:18 ńkọ́? Ta ló lè rí ojútùú sí àwọn àlọ́ tí Ọlọ́run mí sí wọ̀nyí, kí sì ni ète tí wọ́n wà fún?

Jíjẹ́ Ká Lóye Àṣírí Mímọ́ Náà

Ọ̀pọ̀ lára wa ló gbà pé, ojú ló ṣeyebíye jù lọ nínú àwọn ẹ̀yà ara márààrún tó wà fún ìmòye tó wà lára wa. Àmọ́, tí kò bá sí ìmọ́lẹ̀, ojú kò ní wúlò. Bí ẹni pé ojú wa fọ́ ló ṣe máa rí. Bẹ́ẹ̀ náà ni èrò inú ènìyàn. Ó ní àgbàyanu agbára láti kó nǹkan jọ, láti lo ọgbọ́n, kó sì tipa bẹ́ẹ̀ rí ojútùú sí àwọn ọ̀rọ̀ tó bá díjú. Síbẹ̀, a ṣì nílò ohun kan láti lè lóye àṣírí mímọ́ náà. Bí àwọn mìíràn tilẹ̀ lè sọ pé báyìí-báyìí nìtumọ̀ àwọn àlọ́ tó wà nínú Bíbélì, Orísun wọn, ìyẹn Jèhófà, Ọlọ́run ìmọ́lẹ̀, nìkan ṣoṣo ló lè sọ ohun tí wọ́n túmọ̀ sí gan-an fún wa.—1 Jòhánù 1:5.

Ó ṣeni láàánú pé, ìgbéraga àti ẹ̀mí tinúmi-ni-n-ó-ṣe ti pọ̀ jù láàárín àwọn ènìyàn, èyí kì í sì í jẹ́ kí wọ́n dúró de Jèhófà fún ìdáhùn. Níwọ̀n bí àwọn ohun tí ń rúni lójú náà kò ti jẹ́ kí àwọn kan gbádùn, pàápàá jù lọ àwọn tó jẹ́ pé ohun tí wọn yóò máa ronù lé lórí lásán ni wọ́n ń wá, tí òtítọ́ kò jẹ wọ́n lọ́kàn, wọ́n pa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tì, wọ́n wá ojútùú náà lọ síbòmíràn. Fún àpẹẹrẹ, àwọn Júù nínú iṣẹ́ awo àti ètò Kàbálà wọn a máa ṣàṣàrò lórí agbára idán tó wà nínú àwọn nọ́ńbà àti lẹ́tà inú ọ̀rọ̀ Hébérù kọ̀ọ̀kan. Ní ọ̀wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn Onímọ̀-awo tó wà ní ọ̀rúndún kejì, lo Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù àti ti Gíríìkì pẹ̀lú èrò láti rí àwọn ìtumọ̀ ìkọ̀kọ̀ nínú wọn.

Àmọ́, ṣe ni gbogbo irú ìwádìí bẹ́ẹ̀ túbọ̀ tì wọ́n sínú ààtò kèfèrí tàbí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán, ó sì mú kí wọ́n lọ jìnnà sí òtítọ́ àtọ̀runwá. Àwọn Oníṣẹ́-awo náà ronú pé, ‘Họ́wù, tí ìwà ibi bá kún inú ayé, a jẹ́ pé Yahweh, tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ kò lè jẹ́ Ọlọ́run rere nìyẹn.’ Ṣe ibi tí èrò wọ́n mọ náà nìyí? Èrò ènìyàn mà kúrú púpọ̀ o! Abájọ tó fi jẹ́ pé nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń ta ko èrò apẹ̀yìndà tí àwọn ẹ̀ya ẹ̀sìn Onímọ̀-awo wá gbé dìde níkẹyìn, ó fúnni ní ìkìlọ̀ tó lágbára nínú lẹ́tà rẹ̀ pé: “Má ṣe ré kọjá àwọn ohun tí a ti kọ̀wé rẹ̀”!—1 Kọ́ríńtì 4:6.

Títan Ìmọ́lẹ̀ sí “Àwọn Ọ̀rọ̀ Tó Ṣókùnkùn”

Síbẹ̀, èé ṣe tí Ọlọ́run ìmọ́lẹ̀ yóò tiẹ̀ fi sọ “àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣókùnkùn”? Àlọ a máa dán bí ọpọlọ èèyàn ti jí pépé tó àti bí làákàyè rẹ̀ ti pọ̀ tó wò. Nítorí náà, báa ṣe lò ó káàkiri inú Ìwé Mímọ́ la lè fi wé iyán tó gbóná fẹlifẹli pẹ̀lú ọbẹ ẹ̀fọ́ táa yí lẹ́gùúsí, ìyẹn ni pé nígbà mìíràn, a ń lo àlọ́ kó lè ta ìfẹ́ àwọn ènìyàn jí tàbí kí ìhìn iṣẹ́ náà lè túbọ̀ ṣe kedere lọ́kàn wọn. Nígbà tí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, bí wọ́n bá ṣe ń pa àlọ́ náà tán ní àlàyé rẹ̀ máa ń tẹ̀ lé e.—Ìsíkíẹ́lì 17:1-18; Mátíù 18:23-35.

Jèhófà máa ń fúnni lọ́gbọ́n ní fàlàlà, àmọ́ ṣáá o kì í ṣàdédé fúnni. (Jákọ́bù 1:5-8) Gbé ìwé Òwe yẹ̀ wò, àkójọ àwọn àdììtú ọ̀rọ̀ tí a mí sí, tí àwọn kan lè pè ní àlọ́ ló kún inú rẹ̀. Yóò gba ọ̀pọ̀ àkókò àti àṣàrò ká tó lè lóye wọn. Àmọ́, àwọn mélòó ló ṣe tán láti ṣe ìsapá yẹn? Kìkì àwọn tí wọ́n bá ṣe tán láti wá irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ nìkan ló lè rí i.—Òwe 2:1-5.

Bákan náà ni Jésù lo àwọn àpèjúwe láti tú èrò tó wà ní ọkàn àwọn olùgbọ́ rẹ̀ fó. Ogunlọ́gọ̀ ènìyàn ló ń rọ̀gbà yí i ká. Àwọn ìtàn tó ń sọ ń gbádùn mọ́ wọn. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀. Síbẹ̀, àwọn mélòó ló ṣe tán láti yí ìgbésí ayé wọ́n padà kí wọ́n sì tẹ̀ lé e? Wọ́n mà yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù o, àwọn tó jẹ́ pé léraléra ni wọ́n máa ń wá bí wọ́n ṣe máa lóye àwọn ẹ̀kọ́ ti Jésù ń kọ́ wọn, tí wọ́n sì ṣe tán láti sẹ́ ara wọn, kí wọ́n lè di ọmọlẹ́yìn rẹ̀!—Mátíù 13:10-23, 34, 35; 16:24; Jòhánù 16:25, 29.

Wíwo Ìmọ́lẹ̀ Náà

Ìwé kan sọ pé: “Ó dà bí pé ìgbà tí òye èèyàn bá sọ jí, la máa ń fẹ́ láti mọ ohun tí àlọ́ kan túmọ̀ sí.” Àǹfààní ńlá la ní lónìí pé à ń gbé ní àkókò tí “ìmọ́lẹ̀ ti kọ mànà” nípa tẹ̀mí fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run. (Sáàmù 97:11; Dáníẹ́lì 12:4, 9) Ǹjẹ́ a lè fi sùúrù dúró de Jèhófà láti ṣí àwọn ète rẹ̀ payá ní ìbámu pẹ̀lú àkókò tí òun ti ṣètò? Ní pàtàkì, ǹjẹ́ a ń gbégbèésẹ̀ kánmọ́ láti yí ìgbésí ayé wa padà nígbà tí a bá rí i pé àwọn àtúnṣe kan wà táa gbọ́dọ̀ ṣe láti túbọ̀ mú ìgbésí ayé wa bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu? (Sáàmù 1:1-3; Jákọ́bù 1:22-25) Báa bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà yóò bù kún ìsapá wa, tó fi jẹ́ pé bí awò ojú ṣe ń tún ojú tó ti di bàìbàì ṣe, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀mí mímọ́ yóò ṣe jẹ́ kí àwọn ohun mèremère tó wà nínú ète Ọlọ́run ṣe kedere sí ojú inú wa, tí yóò sì mú kí ojú wa nípa tẹ̀mí túbọ̀ lè ríran rekete.—1 Kọ́ríńtì 2:7, 9, 10.

Láìsí àní-àní, àwọn àlọ́ inú Ìwé Mímọ́ ń fi Jèhófà hàn gẹ́gẹ́ bí “Olùṣí àwọn àṣírí payá.” (Dáníẹ́lì 2:28, 29) Ní àfikún sí i, ó tún jẹ́ Olùṣàyẹ̀wò ọkàn-àyà. (1 Kíróníkà 28:9) Kò yẹ kó yà wá lẹ́nu láti mọ̀ pé kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ àtọ̀runwá náà túbọ̀ ń mọ́lẹ̀ yòò sí i. (Òwe 4:18; Róòmù 16:25, 26) Kàkà tí a ó fi lo ọgbọ́n awo tàbí ọgbọ́n ènìyàn tí kò tó nǹkan láti wá ìmọ̀ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run, tó sì jẹ́ pé asán lórí asán ni yóò já sí, ẹ jẹ́ kí a fí ìgbọ́kànlé yíjú sí Jèhófà Ọlọ́run láti tan ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ sórí “àwọn ọ̀rọ̀ ṣíṣókùnkùn” tó ti sọ, kí ó sì sọ àwọn ète àgbàyanu rẹ̀ di mímọ̀ fún àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ní àkókò tí ó yàn.—Ámósì 3:7; Mátíù 24:25-27.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]

Biblia Hebraica Stuttgartensia, Deutsche Bibelgesellschaft Stuttgart

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́