Jèhófà—Ọlọ́run Tí Ń ṣí Àṣírí Payá
“Ọlọ́run kan wà ní ọ̀run tí ó jẹ́ Olùṣí àwọn àṣírí payá.”—DÁNÍẸ́LÌ 2:28, NW.
1, 2. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe yàtọ̀ sí Elénìní ńlá rẹ̀? (b) Báwo ni àwọn ẹ̀dá ènìyàn ṣe fi ìyàtọ̀ yí hàn?
JÈHÓFÀ, Ọlọ́run gíga jù lọ ní àgbáálá ayé, onífẹ̀ẹ́, Ẹlẹ́dàá kan ṣoṣo tí ń bẹ, jẹ́ Ọlọ́run ọlọ́gbọ́n àti onídàájọ́ òdodo. Kò sí ìdí kankan tí yóò fi fi irú ẹni tí ó jẹ́, iṣẹ́ rẹ̀, tàbí ète rẹ̀ pa mọ́. Ní àkókò tirẹ̀ àti ní lílo ọgbọ́n inú rẹ̀, ó ń ṣí irú ẹni tí ó jẹ́ payá. Lọ́nà yí, ó yàtọ̀ sí Elénìní rẹ̀, Sátánì Èṣù, tí ń gbìyànjú láti fi irú ẹni tí ó jẹ́ gan-an àti ète rẹ̀ pa mọ́.
2 Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà àti Sátánì ti yàtọ̀ síra pátápátá, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn olùjọsìn wọn yàtọ̀ síra pátápátá. Békebèke àti ẹ̀tàn ni a fi ń dá àwọn tí ń tẹ̀ lé ìdarí Sátánì mọ̀. Wọ́n ń gbìyànjú láti fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni rere, nígbà tí ó sì jẹ́ pé oníṣẹ́ òkùnkùn ni wọ́n. A sọ fún àwọn Kristẹni ní Kọ́ríńtì pé kí òkodoro òtítọ́ yìí má ṣe ṣe wọ́n ní kàyéfì. “Nítorí irúfẹ́ àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ jẹ́ èké àpọ́sítélì, àwọn oníṣẹ́ ẹ̀tàn, tí ń pa ara wọn dà di àpọ́sítélì Kristi. Kò sì ṣeni ní kàyéfì, nítorí Sátánì fúnra rẹ̀ a máa pa ara rẹ̀ dà di áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀.” (Kọ́ríńtì Kejì 11:13, 14) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn Kristẹni ń wo Kristi gẹ́gẹ́ bí Aṣáájú wọn. Nígbà tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fi àkópọ̀ ìwà Bàbá rẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run, hàn lọ́nà pípé pérépéré. (Hébérù 1:1-3) Nípa báyìí, nípa títẹ̀lé Kristi, àwọn Kristẹni ń fara wé Jèhófà, Ọlọ́run òtítọ́, tí kì í ṣe nǹkan ní bòókẹ́lẹ́, tí ó sì jẹ́ Ọlọ́run ìmọ́lẹ̀. Àwọn pẹ̀lú kò ní ìdí kankan láti fi irú ẹni tí wọ́n jẹ́, iṣẹ́ wọn, tàbí ète wọn pa mọ́.—Éfésù 4:17-19; 5:1, 2.
3. Báwo ni a ṣe lè fi hàn pé irọ́ ni ẹ̀sùn náà pé a ń fipá mú àwọn tí wọ́n bá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti dara pọ̀ mọ́ “ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀”?
3 Ní àkókò yíyẹ jù lọ lójú rẹ̀, Jèhófà ń sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ète rẹ̀ àti nípa ọjọ́ ọ̀la tí àwọn ẹ̀dá ènìyàn kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ di mímọ̀. Lọ́nà yí, òun jẹ́ Ọlọ́run tí ń ṣí àṣírí payá. Nípa báyìí, a ké sí àwọn tí wọ́n fẹ́ láti ṣiṣẹ́ sìn ín—bẹ́ẹ̀ ni, a rọ̀ wọ́n—láti kọ́ irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ tí a ṣí payá. Ìwádìí kan tí a ṣe ní 1994, tí ó ní Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ó lé ní 145,000 nínú, ní orílẹ̀-èdè kan ní Europe, fi hàn pé ní ìpíndọ́gba, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn fúnra rẹ̀ wádìí ẹ̀kọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ọdún mẹ́ta, kí ó tó yàn láti di Ẹlẹ́rìí. Wọ́n gbé yíyàn náà karí òmìnira ìfẹ́ inú tiwọn fúnra wọn láìjẹ́ pé a fipá mú wọn. Wọ́n sì ń bá a nìṣó láti ní òmìnira ìfẹ́ inú àti ìgbésẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, nítorí pé àwọn mélòó kan kò fara mọ́ ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga ti ìwà híhù fún àwọn Kristẹni, nígbà tí ó yá, àwọn wọ̀nyí pinnu pé àwọn kò fẹ́ jẹ́ Ẹlẹ́rìí mọ́. Ṣùgbọ́n, ó dùn mọ́ni nínú pé ní ọdún márùn-ún tí ó kọjá, èyí tí ó pọ̀ jù lọ lára àwọn tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí tẹ́lẹ̀ rí wọ̀nyí gbé ìgbésẹ̀ láti pa dà dara pọ̀ mọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí, kí wọ́n sì máa lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò wọn.
4. Kí ni kò yẹ kí ó da àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́ láàmú, èé sì ti ṣe?
4 Àmọ́ ṣáá o, kì í ṣe gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí tẹ́lẹ̀ rí ni wọ́n ń pa dà, àwọn kan tí wọ́n ní ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ Kristẹni nígbà kan rí sì wà lára wọn. Kò yẹ kí èyí yà wá lẹ́nu, nítorí ọ̀kan nínú àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tí ó sún mọ́ ọn jù lọ pàápàá, àpọ́sítélì Júdásì, pẹ̀yìn dà. (Mátíù 26:14-16, 20-25) Ṣùgbọ́n èyí ha jẹ́ ìdí láti di ẹni tí ẹ̀sìn Kristẹni fúnra rẹ̀ kó ìdààmú bá bí? Èyí ha pagi dínà àṣeyọrí tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ní nínú ìgbòkègbodò ètò ẹ̀kọ́ wọn bí? Rárá o, níwọ̀n bí ìgbésẹ̀ ọ̀dàlẹ̀ tí Júdásì Ísíkáríótù gbé kò ti dá ète Ọlọ́run dúró.
Olódùmarè Síbẹ̀ Ó Jẹ́ Onífẹ̀ẹ́
5. Báwo ni a ṣe mọ̀ pé Jèhófà àti Jésù nífẹ̀ẹ́ ẹ̀dá ènìyàn, báwo sì ni wọ́n ṣe fi ìfẹ́ yìí hàn?
5 Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́. Ó bìkítà fún àwọn ènìyàn. (Jòhánù Kíní 4:7-11) Láìka ipò gíga rẹ̀ sí, ó ń gbádùn bíbá àwọn ẹ̀dá ènìyàn dọ́rẹ̀ẹ́. A kà nípa ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ìgbàanì pé: “‘Ábúráhámù lo ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, a sì kà á sí òdodo fún un,’ ó sì di ẹni tí a ń pè ní ‘ọ̀rẹ́ Jèhófà.’” (Jákọ́bù 2:23; Kíróníkà Kejì 20:7; Aísáyà 41:8) Bí ẹ̀dá ènìyàn ṣe ń fi ọ̀ràn ìkọ̀kọ̀, tàbí ọ̀ràn àṣírí han àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe ń fi han àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Jésù fara wé Bàbá rẹ̀ nínú èyí, nítorí ó bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dọ́rẹ̀ẹ́ ó sì fi àṣírí hàn wọ́n. Ó wí fún wọn pé: “Èmi kò pè yín ní ẹrú mọ́, nítorí pé ẹrú kì í mọ ohun tí ọ̀gá rẹ̀ ń ṣe. Ṣùgbọ́n èmi ti pè yín ní ọ̀rẹ́, nítorí pé gbogbo nǹkan tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Bàbá mi ni mo ti sọ di mímọ̀ fún yín.” (Jòhánù 15:15) Ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀, tàbí “àṣírí,” tí ó wà láàárín Jèhófà, Ọmọkùnrin rẹ̀, àti àwọn ọ̀rẹ́ wọn mú wọn wà ní ìṣọ̀kan nínú ìdè ìfẹ́ àti ìfọkànsìn tí kò lè já.—Kólósè 3:14.
6. Èé ṣe tí kò fi sí ìdí kankan fún Jèhófà láti fi àwọn ète rẹ̀ pa mọ́?
6 Ìtumọ̀ orúkọ Jèhófà, “Ó Ń Mú Kí Ó Di,” fi agbára rẹ̀ hàn láti di ohunkóhun tí ó bá fẹ́ láti baà lè mú ète rẹ̀ ṣẹ. Láìdà bí ẹ̀dá ènìyàn, Jèhófà kò ní ìdí kankan láti fi àwọn ète rẹ̀ pa mọ́ nítorí bíbẹ̀rù pé àwọn mìíràn lè dí òun lọ́wọ́ láti mú wọn ṣẹ. Òun kò kúkú lè kùnà, nítorí náà, ní gbangba, ó ṣí ohun tí ó pète láti ṣe payá nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó ṣèlérí pé: “Ọ̀rọ̀ mi . . . kì yóò pa dà sọ́dọ̀ mi lófo, ṣùgbọ́n yóò ṣe èyí tí ó wù mí, yóò sì máa ṣe rere nínú ohun tí mo rán an.”—Aísáyà 55:11.
7. (a) Kí ni Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ ní Édẹ́nì, báwo sì ni Sátánì ṣe fi hàn pé Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́? (b) Báwo ni ìlànà Kọ́ríńtì Kejì 13:8 ṣe máa ń já sí òtítọ́ nígbà gbogbo?
7 Kété lẹ́yìn ìṣọ̀tẹ̀ ní Édẹ́nì, Jèhófà ṣí ohun tí yóò jẹ́ àbárèbábọ̀ awuyewuye tí ń lọ láàárín rẹ̀ àti Elénìní rẹ̀, Sátánì, payá lẹ́sẹẹsẹ. A óò pa Irú-Ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí náà lọ́nà tí yóò mú ìrora lọ́wọ́, ṣùgbọ́n a kì yóò pa á run, àmọ́, a óò pa Sátánì run ráúráú nígbẹ̀yìngbẹ́yín. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Èṣù pa Irú-Ọmọ náà, Kristi Jésù, nípa ṣíṣokùnfà ikú rẹ̀. Lọ́nà yí, Sátánì mú Ìwé Mímọ́ ṣẹ, lọ́wọ́ kan náà, ó fi hàn pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run òtítọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí kì í ṣe ète Sátánì ní ti gidi. Ìkórìíra tí ó ní fún òtítọ́ àti òdodo, àti ìwà ìgbéraga, aláìlẹ́mìí ìrònúpìwàdà rẹ̀, sún un láti ṣe ohun náà gan-an tí Ọlọ́run ti sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni, sí gbogbo àwọn alátakò òtítọ́, àní sí Sátánì fúnra rẹ̀ pàápàá, ìlànà náà jóòótọ́ pé: “Àwa kò lè ṣe ohunkóhun lòdì sí òtítọ́, bí kò ṣe kìkì fún òtítọ́.”—Kọ́ríńtì Kejì 13:8.
8, 9. (a) Kí ni Sátánì mọ̀, ṣùgbọ́n ohun tí ó mọ̀ yí ha ké mímú ète Jèhófà ṣẹ nígbèrí bí? (b) Ìkìlọ̀ ṣíṣe kedere wo ni àwọn alátakò Jèhófà kọ̀ sílẹ̀, èé sì ti ṣe?
8 Níwọ̀n bí a ti gbé Ìjọba Ọlọ́run kalẹ̀ lọ́nà tí a kò lè fojú rí ní ọdún 1914, Ìṣípayá 12:12 ti ní ìmúṣẹ pé: “Ní tìtorí èyí ẹ máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin ọ̀run àti ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn! Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ní mímọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.” Síbẹ̀, mímọ̀ tí Sátánì mọ̀ pé àkókò òun kúrú ha mú kí ó yí ọ̀nà rẹ̀ pa dà bí? Ìyẹn yóò fi hàn pé Sátánì gbà pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run òtítọ́ àti pé òun ni Olùṣàkóso Gíga Jù Lọ, òun nìkan ṣoṣo ni ó sì yẹ kí a jọ́sìn. Ṣùgbọ́n, Èṣù kò ṣe tán láti túúbá, àní bí ó tilẹ̀ mọ àwọn òkodoro òtítọ́ wọ̀nyí.
9 Ní gbangba, Jèhófà ṣí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ nígbà tí Kristi bá dé láti ṣèdájọ́ ètò ìgbékalẹ̀ ayé Sátánì payá. (Mátíù 24:29-31; 25:31-46) Nípa èyí, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kéde nípa àwọn alákòóso ayé pé: “Ìgbà yòó wù tí ó jẹ́ tí wọ́n bá ń wí pé: ‘Àlàáfíà àti ààbò!’ nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn gan-an gẹ́gẹ́ bí ìrora gógó wàhálà lórí aboyún.” (Tẹsalóníkà Kíní 5:3) Àwọn tí ń tẹ̀ lé ìdarí Sátánì kò fetí sí ìkìlọ̀ kedere yìí. A fọ́ wọn lójú nítorí ọkàn àyà wọn burú, èyí kò sì jẹ́ kí wọ́n ronú pìwà dà nínú ọ̀nà búburú wọn, kí wọ́n sì yí ìwéwèé àti ète wọn láti ké ète Jèhófà nígbèrí pa dà.
10. (a) Ibo ni ó ṣeé ṣe kí Tẹsalóníkà Kíní 5:3 ti ní ìmúṣẹ dé, ṣùgbọ́n báwo ni ó ṣe yẹ kí àwọn ènìyàn Jèhófà hùwà pa dà? (b) Èé ṣe tí àwọn tí kò nígbàgbọ́ fi lè túbọ̀ gbójú gbóyà ní ọjọ́ ọ̀la láti ta ko àwọn ènìyàn Ọlọ́run?
10 Ní pàtàkì láti 1986, nígbà tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè kéde Ọdún Àlàáfíà Àgbáyé, ayé ti kún fún ọ̀rọ̀ àsọọ̀sọtán nípa àlàáfíà àti ààbò. Wọ́n ti gbé àwọn ìgbésẹ̀ tí ó ṣe gúnmọ́ nínú ìsapá láti mú ààbò àlàáfíà ayé dáni lójú, ó sì dà bí ẹni pé ìsapá yìí ti kẹ́sẹ járí díẹ̀. Gbogbo ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yí ha nìyí bí, àbí a ṣì lè máa retí irú àwọn ìkéde kan tí ń múni ta gìrì, ní ọjọ́ ọ̀la bí? Jèhófà yóò mú ọ̀ràn yẹn ṣe kedere nígbà tí ó bá tó àkókò ní ojú rẹ̀. Ní báyìí ná, ẹ jẹ́ kí a wà lójúfò nípa tẹ̀mí, “ní dídúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà àti fífi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí.” (Pétérù Kejì 3:12) Bí àkókò ti ń lọ, tí ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ àsọọ̀sọtán lórí àlàáfíà àti ààbò ṣì ń lọ lọ́wọ́, àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan tí wọ́n gbọ́ nípa ìkìlọ̀ yí, ṣùgbọ́n tí wọ́n yàn láti ṣàìkà á sí, lè túbọ̀ gbójú gbóyà sí i ní rírò pé Jèhófà kì yóò mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ, tàbí kò lè mú un ṣẹ. (Fi wé Oníwàásù 8:11-13; Pétérù Kejì 3:3, 4.) Ṣùgbọ́n àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ pé Jèhófà yóò mú ète rẹ̀ ṣẹ!
Ọ̀wọ̀ Yíyẹ fún Aṣojú Tí Jèhófà Ń Lò
11. Kí ni Dáníẹ́lì àti Jósẹ́fù kọ́ nípa Jèhófà?
11 Nígbà tí Ọba Nebukadinésárì, olùṣàkóso Ilẹ̀ Ọba Bábílónì Tuntun, lá àlá kan tí ó dà á láàmú, tí kò sì lè rántí rẹ̀, ó béèrè fún ìrànlọ́wọ́. Àwọn abọrẹ̀ rẹ̀, àwọn onídán, àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́ rẹ̀ kò lè rọ́ àlá tí ó lá fún un, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ó ṣeé ṣe fún Dáníẹ́lì, ìránṣẹ́ Ọlọ́run, láti ṣe bẹ́ẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó jẹ́wọ́ pé ṣíṣí àlá àti ìtumọ̀ rẹ̀ payá kì í ṣe nítorí ọgbọ́n òun. Dáníẹ́lì wí pé: “Ọlọ́run kan wà ní ọ̀run tí ó jẹ́ Olùṣí àwọn àṣírí payá, ó sì ti sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn ọjọ́ di mímọ̀ fún Ọba Nebukadinésárì.” (Dáníẹ́lì 2:1-30, NW) Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú ìgbà yẹn, Jósẹ́fù, tí òun pẹ̀lú jẹ́ wòlíì Ọlọ́run, ti ní ìrírí tí ó fara jọ ọ́ pé Jèhófà jẹ́ Olùṣí àṣírí payá.—Jẹ́nẹ́sísì 40:8-22; Ámósì 3:7, 8.
12, 13. (a) Ta ni wòlíì Ọlọ́run tí ó tóbi lọ́lá jù lọ, èé sì ti ṣe tí o fi dáhùn bẹ́ẹ̀? (b) Àwọn wo lónìí ní ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ‘ìríjú àṣírí ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run,’ ojú wo sì ni ó yẹ kí a fi wò wọ́n?
12 Jésù ni wòlíì títóbi lọ́lá jù lọ ti Jèhófà, tí ó tí ì ṣiṣẹ́ sìn lórí ilẹ̀ ayé rí. (Ìṣe 3:19-24) Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Ọlọ́run, ẹni tí ó tipasẹ̀ àwọn wòlíì bá àwọn baba ńlá wa sọ̀rọ̀ ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà àti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà, ti tipasẹ̀ Ọmọkùnrin kan bá wa sọ̀rọ̀ ní òpin àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, ẹni tí òun yàn sípò gẹ́gẹ́ bí ajogún ohun gbogbo, àti nípasẹ̀ ẹni tí òun dá àwọn ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan.”—Hébérù 1:1, 2.
13 Jèhófà tipasẹ̀ Ọmọkùnrin rẹ̀, Jésù, bá àwọn Kristẹni ìjímìjí sọ̀rọ̀, ẹni tí ó sọ àṣírí àtọ̀runwá di mímọ̀ fún wọn. Jésù wí fún wọn pé: ‘Ẹ̀yin ni a yọ̀ǹda fún láti lóye àwọn àṣírí ọlọ́wọ̀ ti ìjọba Ọlọ́run.’ (Lúùkù 8:10) Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró gẹ́gẹ́ bí ‘òṣìṣẹ́ ọmọ abẹ́ Kristi àti ìríjú àwọn àṣírí ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run.’ (Kọ́ríńtì Kíní 4:1) Lónìí, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ń bá a nìṣó láti ṣiṣẹ́ sìn ní irú ipò bẹ́ẹ̀, ní píparapọ̀ di ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú tí ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí ní àkókò bíbẹ́tọ̀ọ́mu nípasẹ̀ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso. (Mátíù 24:45-47) Bí a bá ní ọ̀wọ̀ gíga fún àwọn wòlíì tí Ọlọ́run mí sí ní ìgbà àtijọ́, àti ní pàtàkì Ọmọkùnrin Ọlọ́run, kò ha yẹ kí a bọ̀wọ̀ fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn aṣojú tí Jèhófà ń lò lónìí láti ṣí ìsọfúnni inú Bíbélì tí ó pọn dandan gidigidi fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní àwọn àkókò líle koko wọ̀nyí payá bí?—Tímótì Kejì 3:1-5, 13.
Gbangba Ni Kí A Ti Ṣe É Tàbí Ní Bòókẹ́lẹ́?
14. Nígbà wo ni àwọn Kristẹni máa ń bá ìgbòkègbodò wọn lọ ní bòókẹ́lẹ́, àpẹẹrẹ ta ni wọ́n sì ń tẹ̀ lé nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀?
14 Ǹjẹ́ ṣíṣe tí Jèhófà kì í ṣe nǹkan ní bòókẹ́lẹ́ ní ti ṣíṣí nǹkan payá ha túmọ̀ sí pé àwọn Kristẹni ní láti ṣí gbogbo ohun tí wọ́n bá mọ̀ payá nígbà gbogbo àti lábẹ́ gbogbo àyíká ipò bí? Toò, àwọn Kristẹni ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ láti jẹ́ ‘oníṣọ̀ọ́ra gẹ́gẹ́ bí ejò síbẹ̀ kí wọ́n jẹ́ ọlọ́rùn mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àdàbà.’ (Mátíù 10:16) Bí a bá sọ fún wọn pé wọn kò lè jọ́sìn Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ọkàn wọn ti béèrè, àwọn Kristẹni yóò máa bá a nìṣó láti “ṣègbọràn sí Ọlọ́run,” nítorí wọ́n mọ̀ pé kò sí ẹ̀dá ènìyàn aṣojú kankan tí ó ní ẹ̀tọ́ láti pààlà sí ìjọsìn Jèhófà. (Ìṣe 5:29) Jésù fúnra rẹ̀ fi bí èyí ti jẹ́ ohun yíyẹ hàn. A kà pé: “Wàyí o lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí Jésù ń bá a lọ ní rírìn káàkiri ní Gálílì, nítorí pé kò fẹ́ rìn káàkiri ní Jùdíà, nítorí tí àwọn Júù ń wá ọ̀nà láti pa á. Bí ó ti wù kí ó rí, àjọyọ̀ àwọn Júù, àjọyọ̀ àwọn àgọ́ ìsìn, sún mọ́lé. Nítorí náà Jésù wí fún wọn [àwọn arákùnrin rẹ̀ nípa ti ara tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́] pé: . . . ‘Ẹ̀yin ẹ máa gòkè lọ sí àjọyọ̀ náà; kò tí ì yá mi tí èmi yóò gòkè lọ sí àjọyọ̀ yí, nítorí àkókò yíyẹ mi kò tí ì dé ní kíkún síbẹ̀.’ Nítorí náà lẹ́yìn tí ó sọ nǹkan wọ̀nyí fún wọn, ó dúró ní Gálílì. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ ti gòkè lọ sí àjọyọ̀ náà, nígbà náà ni òun fúnra rẹ̀ pẹ̀lú gòkè lọ, kì í ṣe ní gbangba wálíà ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bíi ní bòókẹ́lẹ́.”—Jòhánù 7:1, 2, 6, 8-10.
Ṣé Kí A Sọ Tàbí Kí A Má Sọ?
15. Báwo ni Jóṣẹ́fù ṣe fi hàn pé pípa àṣírí mọ́ jẹ́ ohun onífẹ̀ẹ́ láti ṣe nígbà míràn?
15 Nínú àwọn ọ̀ràn kan, pípa ọ̀ràn mọ́ láṣìírí kì í wulẹ̀ ṣe ìwà ọlọ́gbọ́n nìkan, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìwà onífẹ̀ẹ́ pẹ̀lú. Fún àpẹẹrẹ, báwo ni Jósẹ́fù, bàbá tí ó gba Jésù ṣọmọ, ṣe hùwà pa dà nígbà tí ó gbọ́ pé aya tí òun ń fẹ́ sọ́nà, Màríà, ti lóyún? A kà pé: “Bí ó ti wù kí ó rí, Jósẹ́fù ọkọ rẹ̀, nítorí tí òun jẹ́ olódodo tí kò sì fẹ́ sọ ọ́ di ìran àpéwò fún gbogbo ènìyàn, pètepèrò láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní bòókẹ́lẹ́.” (Mátíù 1:18, 19) Ẹ wo bí yóò ti jẹ́ ìwà ìkà tó láti sọ ọ́ di ìran àpéwò!
16. Ẹrù iṣẹ́ wo ni àwọn alàgbà, àti gbogbo mẹ́ńbà yòó kù nínú ìjọ ní, ní ti ọ̀ràn àṣírí?
16 Kó yẹ kí a tú ọ̀ràn àṣírí tí ó lè fa ìtìjú tàbí ẹ̀dùn ọkàn síta fún àwọn tí kó láṣẹ láti gbọ́ nípa rẹ̀. Àwọn Kristẹni alàgbà ń fi èyí sọ́kàn nígbà tí ó bá pọn dandan fún wọn láti fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn ní ìmọ̀ràn tàbí láti tù wọ́n nínú tàbí ó tilẹ̀ lé jẹ́ láti bá wọn wí fún dídẹ́sẹ̀ búburú jáì sí Jèhófà. Yíyanjú àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí ní ọ̀nà tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu pọn dandan; kò sí ìdí kankan láti tú kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀ràn àṣírí fún àwọn tí ọ̀ràn kò kàn, ó sì jẹ́ ìwà ìkà. Dájúdájú, àwọn mẹ́ńbà ìjọ Kristẹni kì yóò gbìyànjú láti lu àwọn alàgbà lẹ́nu gbọ́ ọ̀rọ̀ àṣírí, ṣùgbọ́n wọn yóò bọ̀wọ̀ fún ẹrù iṣẹ́ àwọn alàgbà láti pa nǹkan àṣírí mọ́. Òwe 25:9 sọ pé: “Bá ẹnì kejì rẹ ja ìjà rẹ̀; ṣùgbọ́n àṣírí ẹlòmíràn ni ìwọ kò gbọdọ̀ fi hàn.”
17. Èé ṣe tí àwọn Kristẹni nínú ọ̀pọ̀ jù lọ ọ̀ràn ń fi ọ̀ràn àṣírí pa mọ́, ṣùgbọ́n èé ṣe tí wọn kò lè fìgbà gbogbo ṣe bẹ́ẹ̀?
17 Ìlànà yí tún múlẹ̀ láàárín agbo ìdílé tàbí láàárín àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Pípa àwọn ọ̀ràn kan mọ́ láṣìírí ṣe kókó láti yẹra fún èdè àìyedè àti gbúngbùngbún. “Afẹ́fẹ́ àríwá mú òjò wá, bẹ́ẹ̀ ni ahọ́n ìṣọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn ń mú ojú kíkorò wá.” (Òwe 25:23) Àmọ́ ṣáá o, ìdúróṣinṣin sí Jèhófà àti ìlànà òdodo rẹ̀, àti ìfẹ́ fún ẹnì kan tí ó ṣàṣìṣe, lè mú kí ó pọn dandan lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti sọ ọ̀rọ̀ àṣírí pàápàá fún àwọn òbí, àwọn Kristẹni alàgbà, tàbí àwọn tí wọ́n láṣẹ láti gbọ́ nípa rẹ̀.a Ṣùgbọ́n nínú ọ̀ràn tí ó pọ̀ jù lọ, àwọn Kristẹni ń pa ọ̀ràn àṣírí àwọn ẹlòmíràn mọ́, ní pípa á mọ́ bí wọn yóò ṣe pa ti ara wọn mọ́.
18. Àwọn ànímọ́ mẹ́ta tí ó jẹ́ ti Kristẹni wo ni ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti pinnu ohun tí ó yẹ kí a sọ àti ohun tí kò yẹ kí a sọ?
18 Lákòótán, Kristẹni kan ń fara wé Jèhófà nípa pípa àwọn ọ̀ràn kan mọ́ láṣìírí nígbà tí ó bá pọn dandan, ní ṣíṣí wọn payá kìkì nígbà tí ó bá yẹ. Ìrẹ̀lẹ̀, ìgbàgbọ́, àti ìfẹ́ ni ó ń pinnu ohun tí ó yẹ kí ó sọ àti ohun tí kò yẹ kí ó sọ. Ìrẹ̀lẹ̀ kì í jẹ́ kí ó ka ara rẹ̀ sí ẹni bàbàrà, ní gbígbìyànjú láti fa àwọn ẹlòmíràn lọ́kàn mọ́ra yálà nípa sísọ gbogbo ohun tí ó mọ̀ tàbí nípa fífi àṣírí tí òun kò lè sọ ru ìmọ̀lára wọn sókè. Ìgbàgbọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Jèhófà àti ìjọ Kristẹni ń sún un láti wàásù àwọn ìsọfúnni àtọ̀runwá tí ó wà nínú Bíbélì, nígbà tí yóò sì máa ṣọ́ra láti yẹra fún sísọ nǹkan tí ó lè tètè bí àwọn ẹlòmíràn nínú. Bẹ́ẹ̀ ni, ìfẹ́ ń sún un láti má ṣe fọ̀rọ̀ pa mọ́, ní sísọ ohun tí ń fi ògo fún Ọlọ́run àti ohun tí àwọn ènìyàn ní láti mọ̀ kí wọ́n baà lè jèrè ìyè. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, òun kò ní tú ọ̀ràn àṣírí ara ẹni síta, ní mímọ̀ pé nínú ọ̀ràn tí ó pọ̀ jù lọ, títú wọn síta yóò túmọ̀ sí àìní ìfẹ́.
19. Ìgbésẹ̀ wo ni ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ́ yàtọ̀, kí sì ni ó ń yọrí sí?
19 Ojú ìwòye tí ó wà déédéé yìí ń ranni lọ́wọ́ láti dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀. Wọn kì í fi irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ pa mọ́ nípa ṣíṣàìlo orúkọ rẹ̀ tàbí nípa gbígbé ẹ̀kọ́ àdììtú Mẹ́talọ́kan, tí kò ṣeé ṣàláyé lárugẹ. Ìsìn èké ni ó ń ní àwọn ọlọ́run àìmọ̀, kì í ṣe ìsìn tòótọ́. (Wo Ìṣe 17:22, 23.) Àwọn Ẹlẹ́rìí ẹni àmì òróró Jèhófà mọrírì àǹfààní jíjẹ́ ‘ìríjú àwọn àṣírí ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run’ ní tòótọ́. Nípa títú àṣírí wọ̀nyí fún àwọn ẹlòmíràn láìfi ọ̀rọ̀ pa mọ́, wọ́n ń ṣèrànwọ́ láti fa àwọn aláìlábòsí ọkàn mọ́ra láti wá ọ̀nà láti bá Jèhófà dọ́rẹ̀ẹ́.—Kọ́ríńtì Kíní 4:1; 14:22-25; Sekaráyà 8:23; Málákì 3:18.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo “Maṣe Nipin ninu Ẹṣẹ Awọn Ẹlomiran” nínú Ilé-Ìṣọ́nà, July 1, 1986.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Èé ṣe tí kò fi sí ìdí kankan fún Jèhófà láti fi ète rẹ̀ pa mọ́?
◻ Àwọn wo ni Jèhófà ń ṣí àṣírí rẹ̀ payá fún?
◻ Ẹrù iṣẹ́ wo ni àwọn Kristẹni ní, ní ti ọ̀ràn àṣírí?
◻ Ànímọ́ mẹ́ta wo ni yóò ran àwọn Kristẹni lọ́wọ́ láti mọ ohun tí ó yẹ kí wọ́n sọ àti ohun tí kò yẹ kí wọ́n sọ?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Jèhófà ń ṣí àṣírí payá nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀