ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 10/15 ojú ìwé 5-7
  • Báwo Lèèyàn Ṣe Lè Gba Ìmọ̀ Ọlọ́run Sínú?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Lèèyàn Ṣe Lè Gba Ìmọ̀ Ọlọ́run Sínú?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Èèyàn Ń Wá Òtítọ́
  • Bá A Ṣe Lè Mọ Àwọn Tí Ọlọ́run Ń Lò Láti Kọ́ Àwọn Èèyàn
  • “Jèhófà Fúnra Rẹ̀ Ní Ń Fúnni Ní Ọgbọ́n”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Jehofa Ọlọrun Ète
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Jèhófà—Ọlọ́run Tí Ń ṣí Àṣírí Payá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Aráyé Nílò Ìmọ̀ Ọlọrun
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 10/15 ojú ìwé 5-7

Báwo Lèèyàn Ṣe Lè Gba Ìmọ̀ Ọlọ́run Sínú?

Àwọn kan lè máa sọ pé àwọn ò rò pé Ọlọ́run fẹ́ káwa èèyàn mọ òun. Tó bá sì fẹ́ ká mọ òun, kí ló ń ṣe láti jẹ́ ká mọ̀ ọ́n?

ỌKÙNRIN aṣàtúnṣe-ìsìn kan tó ń jẹ́ John Calvin tó gbé ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún sọ pé àwa èèyàn ò lè dá mọ Ọlọ́run àyàfi bí Ọlọ́run bá sọ bóun ṣe jẹ́ fún wa. Òótọ́ sì lohun tí ọ̀gbẹ́ni yìí sọ. Àmọ́, àwọn kan lè máa sọ pé àwọn ò rò pé Ọlọ́run fẹ́ káwa èèyàn mọ òun. Tó bá sì fẹ́ ká mọ òun, kí ló ń ṣe láti jẹ́ ká mọ̀ ọ́n?

Jèhófà, ‘Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá,’ ní ìdí tó fi ń ṣe gbogbo nǹkan tó ń ṣe. Yàtọ̀ síyẹn, apá rẹ̀ ká àwọn ohun tó pinnu láti ṣe nítorí pé òun ni “Ọlọ́run Olódùmarè.” (Oníwàásù 12:1; Ẹ́kísódù 6:3) Ó dájú pé ó ti pẹ́ tí Ọlọ́run ti máa ń fẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tóun pinnu láti ṣe, nítorí ẹ̀mí mímọ́ sún Ámósì tó jẹ́ wòlíì Ọlọ́run láti kọ̀wé pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ kì yóò ṣe ohun kan láìjẹ́ pé ó ti ṣí ọ̀ràn àṣírí rẹ̀ payá fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì.” Àmọ́ kíyè sí i pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, ìyẹn àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tọkàntọkàn ni ẹsẹ yẹn sọ pé Ọlọ́run ṣí ohun tó pinnu láti ṣe payá fún. Ṣebí bó ṣe yẹ kó rí náà nìyẹn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ta lo máa ń sọ ọ̀rọ̀ àṣírí rẹ fún? Ṣé ẹnikẹ́ni tó o bá kàn rí ni àbí ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́?—Ámósì 3:7; Aísáyà 40:13, 25, 26.

Ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run máa ń mú káwọn onírẹ̀lẹ̀ gbà pé Ọlọ́run tóbi lọ́ba, bó sì ṣe yẹ kó rí nìyẹn. Àmọ́ ká tó lè ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ ṣe ju ká kàn gbà pé Ọlọ́run tóbi lọ́ba. Bíbélì fi yéni pé tá a bá fẹ́ ní ìmọ̀ Ọlọ́run a ní láti rẹ ara wa sílẹ̀. Bíbélì sọ pé: ‘Fi àwọn àṣẹ tèmi ṣúra sọ́dọ̀ rẹ. Dẹ etí rẹ sí ọgbọ́n. Fi ọkàn-àyà rẹ sí ìfòyemọ̀. Ké pe òye, kí o sì fọ ohùn rẹ jáde sí ìfòyemọ̀. Máa bá a nìṣó ní wíwá a bí fàdákà.’—Òwe 2:1-4.

Onírẹ̀lẹ̀ èèyàn tó bá ṣe bí ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe wí yóò lè mọ Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ inú ìwé Òwe yìí ń bá a lọ pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ ní ń fúnni ní ọgbọ́n; láti ẹnu rẹ̀ ni ìmọ̀ àti ìfòyemọ̀ ti ń wá.” Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn tó ń fi gbogbo ọkàn wọn wá òtítọ́ lè “lóye òdodo àti ìdájọ́ àti ìdúróṣánṣán, gbogbo ipa ọ̀nà ohun rere pátá.”—Òwe 2:6-9.

Àwọn Èèyàn Ń Wá Òtítọ́

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia of Religion sọ pé: “Ohun tó jẹ ọmọ èèyàn lógún ni bí wọ́n á ṣe mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní ti gidi àtohun téèyàn kàn ń rò lọ́kàn, láàárín ohun tó lágbára àtohun tí kò lágbára, láàárín ohun tó jẹ́ ojúlówó àti ayédèrú, láàárín ohun tó mọ́ àtohun ẹlẹ́gbin, láàárín ohun tó ṣe kedere àtohun tí kò ṣe kedere, àti láàárín ohun tó dà bíi pé ó tọ̀nà àtohun tí kò tọ̀nà rárá.” Kọ́mọ èèyàn lè mọ ìyàtọ̀ yìí ni wọ́n ṣe ń wá òtítọ́ lójú méjèèjì láti ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn. Àwọn tó wá òtítọ́ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà, ẹni tí onísáàmù kan pè ní “Ọlọ́run òtítọ́,” nínú wọ́n sì ń rí i.—Sáàmù 31:5.

Ohun tí orúkọ náà Jèhófà túmọ̀ sí ní olówuuru ni “Alèwílèṣe.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:4, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé NW) Nípa bẹ́ẹ̀, ìtumọ̀ orúkọ Ọlọ́run jẹ́ ká rí i pé òun ni Ẹlẹ́dàá, àti pé ó ní àwọn ohun kan tó pinnu láti ṣe. Àní, ohun kan téèyàn lè fi dá àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ mọ̀ ni pé wọ́n mọ orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, wọ́n sì ń lo orúkọ náà. Jésù náà mọ̀ bẹ́ẹ̀. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé nígbà tó ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, tó wá sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ó ní: “Mo . . . ti sọ orúkọ rẹ di mímọ̀ fún wọn, ṣe ni èmi yóò sì sọ ọ́ di mímọ̀, kí ìfẹ́ tí ìwọ fi nífẹ̀ẹ́ mi lè wà nínú wọn àti èmi ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú wọn.”—Jòhánù 17:26.

Ọkùnrin Hébérù ìgbàanì kan tó ń jẹ́ Jósẹ́fù jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà tí wọ́n ní kó wá sọ ìtumọ̀ àlá kan, pẹ̀lú ìdánilójú ló fi sọ pé: “Ìtúmọ̀ kò ha jẹ́ ti Ọlọ́run?”—Jẹ́nẹ́sísì 40:8; 41:15, 16.

Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn ìgbà yẹn, Nebukadinésárì ọba Bábílónì lá àlá kan tí àwọn ọlọ́gbọ́n tí ń bẹ láàfin rẹ̀ ò lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀. Wòlíì Dáníẹ́lì sọ fún ọba náà pé: “Ọlọ́run kan wà ní ọ̀run tí ó jẹ́ Olùṣí àwọn àṣírí payá, ó sì ti sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn ọjọ́ di mímọ̀ fún Ọba Nebukadinésárì.”—Dáníẹ́lì 2:28.

Àpẹẹrẹ Jósẹ́fù àti Dáníẹ́lì fi hàn pé àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run nìkan ló lè ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run. Tá a bá sì fẹ́ kí Ọlọ́run máa fi ojú rere wò wá, ó lè pọn dandan pé ká pa àwọn ohun tá a gbà gbọ́ tẹ́lẹ̀ tì. Ohun táwọn Júù tó di Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn. Nítorí pé láti kékeré ni wọ́n ti ń kọ́ wọn láti máa tẹ̀ lé àwọn òfin tí wọ́n gbé kalẹ̀ fáwọn Júù, kì í ṣe ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n gba Jésù gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà. Jésù yìí ló sì wá mú Òfin Mósè ṣẹ, ìyẹn òfin tó jẹ́ “òjìji àwọn ohun rere tí ń bọ̀.” (Hébérù 10:1; Mátíù 5:17; Lúùkù 24:44, 45) “Òfin Kristi” ló rọ́pò Òfin Mósè yìí, ó sì ta yọ Òfin Mósè ní gbogbo ọ̀nà.—Gálátíà 6:2; Róòmù 13:10; Jákọ́bù 2:8.

Inú ayé yìí ti wọ́n ti sọ di àjèjì sí Ọlọ́run ni wọ́n bí gbogbo wa sí. Ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá ti mú ká jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run látìgbà ìbí wa wá, èyí ò sì jẹ́ ká ní ìmọ̀ pípéye nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run pinnu láti ṣe. A tún jogún ọkàn tó ń ṣe àdàkàdekè. (Jeremáyà 17:9; Éfésù 2:12; 4:18; Kólósè 1:21) Torí náà ká tó lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti mú kí ìrònú wa bá ti Ọlọ́run mu. Àmọ́ èyí ò rọrùn o.

Ó lè má rọrùn fún wa láti jáwọ́ nínú àwọn àṣà ìsìn tí kò bá ìlànà Bíbélì mu tàbí ká kọ àwọn ìgbàgbọ́ èké sílẹ̀, àgàgà tó bá jẹ́ pé láti kékeré la ti ń bá irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bọ̀. Àmọ́, ṣé ó bọ́gbọ́n mu kéèyàn rí i pé ọ̀nà tóun ń tọ̀ tàbí ohun tóun ń ṣe kò tọ̀nà kó sì máa bá a lọ bẹ́ẹ̀? Rárá o! Ó dájú pé ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kéèyàn yí èrò rẹ̀ padà kó bàa lè rí ojú rere Ọlọ́run.

Bá A Ṣe Lè Mọ Àwọn Tí Ọlọ́run Ń Lò Láti Kọ́ Àwọn Èèyàn

Àwọn wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ká sì lè máa fi í sílò nígbèésí ayé wa? Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, Ọlọ́run yan àwọn ọkùnrin tó ṣeé fọkàn tán tí wọ́n sì jẹ́ adúróṣinṣin sí ipò àbójútó láti máa darí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè náà. Bákan náà, Kristi tí í ṣe Orí ìjọ Kristẹni lónìí ń darí àwọn tí wọ́n ń fi tọkàntọkàn wá òtítọ́. Àwọn tó sì ń lò láti ṣe èyí ni àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ adúróṣinṣin tí wọ́n ṣeé fọkàn tán, ìyẹn àwọn tó ń darí àwọn èèyàn tó ń fi tọkàntọkàn wá òtítọ́ tí wọ́n sì ń dáàbò bò wọ́n nípa tẹ̀mí. (Mátíù 24:45-47; Kólósè 1:18) Àmọ́, báwo lèèyàn ṣe lè dá àwọn tí Ọlọ́run ń lò láti máa kọ́ àwọn èèyàn mọ̀?

Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi tòótọ́ máa ń sa gbogbo ipá wọn láti rí i pé àwọn ní irú àwọn ànímọ́ tí Jésù ní nígbà tó wà láyé. Bí àwọn ọmọlẹ́yìn yìí ṣe ń fi àwọn ànímọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ wọ̀nyí hàn nínú ayé tó túbọ̀ ń burú sí i yìí mú kó rọrùn fáwọn èèyàn láti dá wọn mọ̀. (Wo àpótí tó wà lójú ewé 6.) Ǹjẹ́ àwọn tó wà nínú ẹ̀sìn rẹ tàbí àwọn tó wà nínú ẹ̀sìn àwọn aládùúgbò rẹ ń fi irú àwọn ànímọ́ wọ̀nyí hàn? Á dára kó o fi Bíbélì ṣe ìwádìí ọ̀rọ̀ yìí láti mọ bó ṣe jẹ́ gan-an.

A rọ ìwọ tó ò ń ka ìwé ìròyìn yìí pé kó o ṣe ìwádìí náà nípa ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lọ́dún tó kọjá, ní ìpíndọ́gba, ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà [6,000,000] èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti gẹ́gẹ́ bí ìdílé tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí ní igba ó lé márùndínlógójì [235] orílẹ̀-èdè. Tó bá dọ̀rọ̀ pé kéèyàn kẹ́kọ̀ọ́ láti ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run, ohun téèyàn á máa ṣe títí lọ ni, ó ń fúnni láyọ̀, ó sì ń ṣeni láǹfààní. O ò ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó o lè ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run? Mọ̀ dájú pé tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o ò ní kábàámọ̀ láé. Bẹ́ẹ̀ ni o, ó ṣeé ṣe fún àwa èèyàn láti mọ Ọlọ́run!

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

OHUN TÁ A LÈ FI DÁ ÀWỌN TÓ Ń TẸ̀ LÉ ÌLÀNÀ ỌLỌ́RUN MỌ̀ NI PÉ:

wọn kì í lọ́wọ́ nínú ogun.—Aísáyà 2:4.

wọ́n máa ń so èso rere nípa ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.—Mátíù 7:13-23.

wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn látọkànwá. —Jòhánù 13:35; 1 Jòhánù 4:20.

wọ́n ṣọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ wọn.—Míkà 2:12.

wọn kì í fara wé àwọn èèyàn ayé nínú ìwà àti ìṣe wọn tí kò dára.—Jòhánù 17:16.

wọ́n máa ń wàásù ọ̀rọ̀ òtítọ́, wọ́n sì máa ń sọ àwọn èèyàn di ọmọlẹ́yìn. —Mátíù 24:14; 28:19, 20.

wọ́n máa ń pàdé pọ̀ déédéé láti fún ara wọn níṣìírí.—Hébérù 10:25.

wọ́n jọ máa ń yin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan tó kárí ayé. —Ìṣípayá 7:9, 10.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Èèyàn lè ní ìmọ̀ Ọlọ́run nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ti ara ẹni, ti ìdílé àti nínú ìjọ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́