ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 3/15 ojú ìwé 10-15
  • Jehofa Ọlọrun Ète

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jehofa Ọlọrun Ète
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọlọrun Ète
  • A Ń Ṣí Wọn Payá ní Ṣísẹ̀-⁠N-Tẹ̀lé
  • Ìlàlóye
  • Ọ̀pọ̀ Yàn Láti Máṣe Mọ̀
  • Ẹ Tẹle Ìmólẹ̀ Ayé Naa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Awọn Olùtan Ìmọ́lẹ̀—Fun Ète Wo?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun”
    “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun”
  • Awọn Wo ni Wọn Ń Tẹle Ìmọ́lẹ̀ Ayé?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 3/15 ojú ìwé 10-15

Jehofa Ọlọrun Ète

“Lóòótọ́ gẹ́gẹ́ bí mo ti gbèrò, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí, àti gẹ́gẹ́ bi mo ti pinnu, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì dúró.”​—⁠ISAIAH 14:⁠24.

1, 2. Kí ni ọ̀pọ̀ ń sọ nípa ète ìgbésí-ayé?

ÀWỌN ènìyàn eníbi gbogbo ń béèrè pé: “Kí ni ète ìgbésí-ayé?” Aṣáájú òṣèlú kan ní ìhà Ìwọ̀-Oòrùn sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ènìyàn síi ju ti ìgbàkígbà rí lọ ń béèrè pé, ‘Ta ni àwa jẹ́? Kí ni ète wa?’” Nígbà tí ìwé-ìròyìn kan wádìí èrò àwọn ọ̀dọ́ lórí ìbéèrè náà nípa ohun tí ó jẹ́ ète ìgbésíayé, àpẹẹrẹ irú àwọn èsì tí ó rí gbà ni: “Láti ṣe ohunkóhun tí ọkàn-àyà rẹ bá fẹ́.” “Gbígbé ìgbésí-ayé dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ní gbogbo ìṣẹ́jú kọ̀ọ̀kan.” “Gbígbé ìgbésí-ayé onífàájì.” “Láti bí ọmọ, láti láyọ̀ àti lẹ́yìn náà kí a sì kú.” Ọ̀pọ̀ lérò pé ìgbésí-ayé yìí ni gbogbo ohun tí ó wà. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó sọ nípa ète onígbà gígùn kankan fún ìwàláàyè lórí ilẹ̀-ayé.

2 Ọ̀mọ̀wèé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan tí ó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Confucius sọ pé: “Òkodoro ìtumọ̀ ìgbésí-ayé ni a ń rí nínú ìwàláàyè wa ojoojúmọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn.” Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, a ó máa bí àwọn ènìyàn nìṣó, a ó ma jìjàkadì fún 70 tàbí 80 ọdún nìṣó, lẹ́yìn náà a óò kú a kì yóò sì wàláàyè mọ́ títíláé. Onímọ̀-ìjìnlẹ̀ ẹfolúṣọ̀n kan sọ pé: “A lè yánhànhàn fún ìdáhùn ‘gíga jù’ kan​—⁠ṣùgbọ́n kò sí ọ̀kankan.” Fún àwọn onígbàgbọ́ nínú ẹfolúṣọ̀n wọ̀nyí, ìgbésí-ayé jẹ́ ìjàkadì fún lílàájá, pẹ̀lú ikú tí ń fòpin sí gbogbo rẹ̀ pátá. Irú àwọn àbá-èrò-orí bẹ́ẹ̀ gbé ojú-ìwòye aláìnírètí nípa ìgbésí-ayé kalẹ̀.

3, 4. Báwo ni àwọn ipò ayé ṣe nípalórí ojú tí ọ̀pọ̀ fi ń wo ìgbésí-ayé?

3 Ọ̀pọ̀ ṣiyèméjì pé ìgbésí-ayé ní ète kan nígbà tí wọ́n rí i pé ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn jẹ́ èyí tí ó kún fún ìṣẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀. Ní àkókò tiwa, nígbà tí ó yẹ kí ènìyàn ti dé ìpẹ̀kun àṣeyọrí níti iṣẹ́-àfẹ̀rọṣe àti ìmọ̀-ìjìnlẹ̀, nǹkan bíi billion ènìyàn kan kárí ayé ni àmódi ń ṣe lọ́nà líléwu tàbí tí wọn kò jẹun-⁠re-kánú. Irú àwọn okùnfà bẹ́ẹ̀ ń fa ikú àráádọ́ta-ọ̀kẹ́ àwọn ọmọ lọ́dọọdún. Ní àfikún, ọ̀rúndún ogún yìí ti ní ikú ogun lọ́nà tí ó fi ìlọ́po mẹ́rin ju ti àpapọ̀ irínwó ọdún tí ó ṣáájú lọ. Ìwà-ọ̀daràn, ìwà-ipá, ìlòkulò oògùn, ìwólulẹ̀ ìdílé, àrùn AIDS àti àwọn àrùn mìíràn tí ìbálòpọ̀ ń tàtaré rẹ̀​—⁠ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn kókó abájọ tí kò báradé náà ń pọ̀ síi. Àwọn aṣáájú ayé kò ní ojútùú sí àwọn ìṣòro wọ̀nyí.

4 Lójú-ìwòye irúfẹ́ àwọn ipò bẹ́ẹ̀, ẹnìkan sọ ohun tí ọ̀pọ̀ ènìyàn gbàgbọ́: “Kò sí àǹfààní kankan nínú ìgbésí-ayé. Bí gbogbo àwọn nǹkan búburú wọ̀nyí bá ń ṣẹlẹ̀, nígbà náà ìgbésí-ayé kò fi bẹ́ẹ̀ jámọ́ nǹkan.” Ọkùnrin àgbàlagbà kan sì sọ pé: “Mo ti ń béèrè ìdí tí mo fi wà níhìn-⁠ín lọ́pọ̀ ìgbà jùlọ nínú ìgbésí-ayé mi. Bí ète kan bá wà, èmi kò tún bìkítà mọ́.” Nítorí náà, nítorí pé ogunlọ́gọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ ìdí tí Ọlọrun fi fàyègba ìjìyà, àwọn ipò ayé tí ń daniláàmú kò mú kí wọ́n ní ìrètí gidi kankan fún ọjọ́-ọ̀la.

5. Èéṣe tí àwọn ìsìn ayé yìí fi dákún ìdàrúdàpọ̀ nípa ète ìgbésí-ayé?

5 Àwọn aṣáájú ìsìn pàápàá kò fohùnṣọ̀kan, wọn kò sì ní ìdánilójú, nípa ète ìgbésí-ayé. Àlùfáà-àgbà kan tẹ́lẹ̀rí ní ṣọ́ọ̀ṣì Katidira ti Paulu Mímọ́ ní London sọ pé: “Mo ti fi gbogbo ìgbésí-ayé mi jìjàkadì láti rí ète ìwàláàyè. . . . Mo ti kùnà.” Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ àwọn àlùfáà kọ́ni pé lẹ́yìn ikú àwọn ẹni rere a lọ sí ọ̀run àwọn ẹni búburú a sì lọ sínú iná ọ̀run-àpáàdì títíláé. Ṣùgbọ́n ojú-ìwòye yìí ṣì gbà fún aráyé lórí ilẹ̀-ayé láti máa bá ipa-ọ̀nà olóró rẹ̀ lọ. Bí ó bá sì jẹ́ pé ète Ọlọrun ni láti mú kí àwọn ènìyàn gbé ní ọ̀run, èéṣe tí kò kúkú fi dá wọn ní ẹ̀dá ọ̀run látilẹ̀ wá, gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn angẹli, kí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ kó àwọn ènìyàn yọ kúrò nínú ìjìyà púpọ̀? Nítorí náà ìdàrúdàpọ̀ níti ète ìgbésí-ayé tàbí kíkọ̀ láti gbàgbọ́ pé ó ní ète èyíkéyìí wọ́pọ̀.

Ọlọrun Ète

6, 7. Kí ni Bibeli sọ fún wa nípa Ọba-Aláṣẹ Àgbáyé?

6 Síbẹ̀, ìwé tí ó ní ìpínkiri tí ó pọ̀ jùlọ nínú ọ̀rọ̀-ìtàn, Bibeli Mímọ́, sọ fún wa pé Jehofa, Ọba-Aláṣẹ àgbáyé, jẹ́ Ọlọrun ète. Ó fihàn wá pé òun ní ète onígbà-pípẹ́, nítòótọ́, ọ̀kan tí ó jẹ́ ti ayérayé, fún ìran aráyé lórí ilẹ̀-ayé. Nígbà tí Jehofa bá sì pète ohun kan, yóò ní ìmúṣẹ láìkùnà. Ọlọrun sọ pé, gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí òjò ti ń mú kí irúgbìn hù jáde “bẹ́ẹ̀ni ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde yóò rí: kì yóò padà sọ́dọ̀ mi lófo, ṣùgbọ́n yóò ṣe èyí tí ó wù mí, yóò sì máa ṣe rere nínú ohun tí mo rán an.” (Isaiah 55:​10, 11) Ohunkóhun tí Jehofa bá sọ pé òun yóò ṣe àṣeparí rẹ̀, ‘ni yóò dúró.’​—⁠Isaiah 14:⁠24.

7 Àwa ènìyàn lè ní ìgbọ́kànlé kíkún pé Olodumare yóò pa àwọn ìlérí rẹ̀ mọ́, nítorí pé Ọlọrun “kò lè ṣèké.” (Titu 1:2; Heberu 6:18) Nígbà tí ó bá sọ fún wa pé òun yóò ṣe ohun kan, ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí-ìdánilójú pé yóò ní ìmúṣẹ. Bí ẹni pé ó ti ní ìmúṣẹ tán ni. Ó polongo pé: “Èmi ni Ọlọrun, kò sì sí ẹlòmíràn, . . . kò sì sí ẹni tí ó dàbí èmi. Ẹni tí ń sọ òpin láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ wá, àti nǹkan tí kò tíì ṣe láti ìgbàanì wá, wí pé, Ìmọ̀ mi yóò dúró, èmi ó sì ṣe gbogbo ìfẹ́ mi. . . . Èmi ti sọ ọ́, èmi óò sì mú un ṣẹ; èmi ti pinnu rẹ̀, èmi óò sì ṣe é pẹ̀lú.”​—⁠Isaiah 46:​9-⁠11.

8. Àwọn wọnnì tí wọ́n fẹ́ láti mọ Ọlọrun nítòótọ́ ha lè rí i bí?

8 Síwájú síi, Jehofa “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó ṣègbé, bíkòṣe kí gbogbo ènìyàn kí ó wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Peteru 3:⁠9) Fún ìdí yìí, òun kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni má mọ̀ nípa òun. Wòlíì kan tí ń jẹ́ Asariah wí pé: “Bí ẹ bá wá [Ọlọrun] kiri, òun yóò jẹ́ kí ẹ rí òun, ṣùgbọ́n bí ẹ bá fi í sílẹ̀ òun yóò fi yín sílẹ̀.” (2 Kronika 15:​1, 2, NW) Fún ìdí yìí, àwọn tí wọ́n fẹ́ láti mọ Ọlọrun àti àwọn ète rẹ̀ nítòótọ́ ni ó dájú pé wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀ bí wọ́n bá ṣe ìsapá náà láti wá a kiri.

9, 10. (a) Kí ni a ti pèsè fún àwọn wọnnì tí wọ́n fẹ́ láti mọ Ọlọrun? (b) Kí ni wíwá inú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kiri mú kí ó ṣeéṣe fún wa?

9 Wá a kiri níbo? Fún àwọn wọnnì tí wọ́n ń wá Ọlọrun kiri níti tòótọ́, òun ti pèsè Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli. Nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, ipá agbékánkánṣiṣẹ́ kan-náà tí ó lò láti ṣẹ̀dá àgbáyé, Ọlọrun darí àwọn ọkùnrin olùṣòtítọ́ láti kọ ohun tí a nílò láti mọ̀ nípa àwọn ète rẹ̀ sílẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, nípa àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli, aposteli Peteru wí pé: “Nítorí àsọtẹ́lẹ̀ kan kò ti ipa ìfẹ́ ènìyàn wá rí; ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ń sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun bí a ti ń darí wọn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ wá.” (2 Peteru 1:21) Bákan náà, aposteli Paulu polongo pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọrun mísí ó sì ṣàǹfààní fún ẹ̀kọ́, fún ìbániwí pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà, fún títún àwọn nǹkan ṣe, fún bíbániwí nínú òdodo, kí ènìyàn Ọlọrun lè yẹ ní kíkún, tí a mú gbaradì pátápátá fún iṣẹ́ dáradára gbogbo.”​—⁠2 Timoteu 3:​16, 17, NW; 1 Tessalonika 2:⁠13.

10 Ṣàkíyèsí pé Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ń mú kí ó ṣeéṣe fún wa láti “yẹ ní kíkún, tí a mú gbaradì pátápátá,” kìí ṣe lápákan tàbí láìpéye. Ó ń mú kí ó ṣeéṣe fún ẹnìkan láti ní ìdánilójú nípa ẹni tí Ọlọrun jẹ́, ohun tí àwọn ète rẹ̀ jẹ́, àti ohun tí ó béèrè lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Èyí ni ohun tí a gbọ́dọ̀ retí láti inú ìwé kan tí Ọlọrun ṣe. Òun sì ni orísun kanṣoṣo tí a lè wákiri láti ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọrun. (Owe 2:​1-⁠5; Johannu 17:⁠3) Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, àwa kì yóò tún “jẹ́ èwe mọ́, tí a ń fi gbogbo afẹ́fẹ́ ẹ̀kọ́ tì síwá tì sẹ́yìn, tí a sì fi ń gbá kiri, nípa ìtànjẹ ènìyàn nípa àrékérekè fún ọgbọ́nkọ́gbọ́n àtimúniṣìnà.” (Efesu 4:​13, 14) Onipsalmu náà sọ̀rọ̀ nípa ojú-ìwòye títọ́ pé: “Ọ̀rọ̀ [Ọlọrun] ni fìtílà fún ẹsẹ̀ mi, àti ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà mi.”​—⁠Orin Dafidi 119:105.

A Ń Ṣí Wọn Payá ní Ṣísẹ̀-⁠N-Tẹ̀lé

11. Báwo ni Jehofa ti ṣe ṣí àwọn ète rẹ̀ payá fún aráyé?

11 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìdílé ẹ̀dá ènìyàn gan-⁠an, Jehofa ṣí àwọn ète rẹ̀ nípa ilẹ̀-ayé àti àwọn ènìyàn tí wọ́n wà lórí rẹ̀ payá. (Genesisi 1:​26-⁠30) Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn òbí wa àkọ́kọ́ kọ ipò ọba-aláṣẹ Ọlọrun, aráyé ṣubú sínú òkùnkùn àti ikú tẹ̀mí. (Romu 5:12) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Jehofa mọ̀ pé àwọn wọnnì tí wọn yóò fẹ́ láti sin òun wà. Nítorí náà, láti àwọn ọ̀rúndún wọ̀nyí wá, ó ti ṣípayá àwọn ète rẹ̀ ní ṣísẹ̀-⁠n-tẹ̀lé fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olùṣòtítọ́. Díẹ̀ nínú àwọn ẹni tí òun bá sọ̀rọ̀pọ̀ ni Enoku (Genesisi 5:24; Juda 14, 15), Noa (Genesisi 6:​9, 13), Abrahamu (Genesisi 12:​1-⁠3), àti Mose (Eksodu 31:18; 34:27, 28). Wòlíì Ọlọrun Amosi kọ̀wé pé: “Oluwa Ọlọrun kì yóò ṣe nǹkankan, ṣùgbọ́n ó fi ohun ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ han àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ̀.”​—⁠Amosi 3:7; Danieli 2:​27, 28.

12. Báwo ni Jesu ṣe tànmọ́lẹ̀ púpọ̀ síi sórí àwọn ète Ọlọrun?

12 Nígbà tí Ọmọkùnrin Ọlọrun, Jesu Kristi, wà lórí ilẹ̀-ayé ní nǹkan bíi 4,000 ọdún lẹ́yìn ìṣọ̀tẹ̀ ní Edeni, ọ̀pọ̀ kúlẹ̀kúlẹ̀ síi nípa àwọn ète Jehofa ni a ṣípayá. Ní pàtàkì ni èyí rí bẹ́ẹ̀ nípa ète Ọlọrun láti gbé Ìjọba ti ọ̀run kan kalẹ̀ láti ṣàkóso lórí ilẹ̀-ayé. (Danieli 2:44) Jesu fi Ìjọba náà ṣe ẹṣin-ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀. (Matteu 4:17; 6:10) Òun àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kọ́ni pé lábẹ́ Ìjọba náà, ète Ọlọrun fún ilẹ̀-ayé àti aráyé ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ ni yóò ní ìmúṣẹ. Ilẹ̀-ayé ni a óò sọ di paradise kan nínú èyí tí àwọn ẹ̀dá ènìyàn pípé tí wọn yóò wàláàyè títíláé yóò gbé. (Orin Dafidi 37:29; Matteu 5:5; Luku 23:43; 2 Peteru 3:13; Ìfihàn 21:⁠4) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ fi ohun tí yóò wáyé nínú ayé titun yẹn hàn nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́-ìyanu tí Ọlọrun fún wọn lágbára láti ṣe.​—⁠Matteu 10:1, 8; 15:30, 31; Johannu 11:​25-⁠44.

13. Nípa ti ìbálò Ọlọrun pẹ̀lú ìran aráyé, ìyípadà wo ni ó wáyé ní Pentekosti 33 C.E.?

13 Ní Pentekosti 33 C.E., 50 ọjọ́ lẹ́yìn àjíǹde Jesu, ẹ̀mí Ọlọrun ni a tú jáde sórí ìjọ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi. Ó rọ́pò Israeli aláìṣòtítọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn tí Jehofa bá dá májẹ̀mú. (Matteu 21:43; 27:51; Iṣe 2:​1-⁠4) Ìtújáde ẹ̀mí mímọ́ ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn jẹ́ ẹ̀rí pé, láti ìgbà náà lọ, Ọlọrun yóò ṣípayá àwọn òtítọ́ nípa ète rẹ̀ nípasẹ̀ aṣojú titun yìí. (Efesu 3:10) Ní ọ̀rúndún kìn-⁠ín-⁠ní C.E., ọ̀nà-ìgbékalẹ̀ elétò-àjọ ti ìjọ Kristian ni a fìdí rẹ̀ múlẹ̀.​—⁠1 Korinti 12:​27-⁠31; Efesu 4:​11, 12.

14. Báwo ni àwọn olùwá òtítọ́ kiri ṣe lè dá ìjọ Kristian tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀?

14 Lónìí, àwọn olùwá òtítọ́ kiri lè dá ìjọ Kristian tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀ nípa fífi tí ó ń fi ìfẹ́, ànímọ́ Ọlọrun tí ó gba iwájú jùlọ hàn lọ́nà ṣíṣedéédéé. (1 Johannu 4:​8, 16) Nítòótọ́, ìfẹ́ ará ni àmì ìdánimọ̀ fún ojúlówó Ìsìn-Kristian. Jesu wí pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ẹ̀yin jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi, bí ẹ̀yin bá ní ìfẹ́ láàárín araayín.” “Èyí ni òfin mi, pé kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn araayín, gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹ́ràn yín.” (Johannu 13:35, NW; 15:12) Jesu sì rán àwọn olùgbọ́ rẹ̀ létí pé: “Ọ̀rẹ́ mi ni ẹ̀yin íṣe, bí ẹ bá ṣe ohun tí èmi paláṣẹ fún yín.” (Johannu 15:14) Nítorí náà àwọn ìránṣẹ́ tòótọ́ fún Ọlọrun ni àwọn wọnnì tí wọ́n gbé ní ìbámu pẹ̀lú òfin ìfẹ́. Wọn kò wulẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nìkan, nítorí “ìgbàgbọ́ ní àìsí iṣẹ́ jẹ́ òkú.”​—⁠Jakọbu 2:⁠26.

Ìlàlóye

15. Kí ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun lè ní ìdánilójú nípa rẹ̀?

15 Jesu sọtẹ́lẹ̀ pé bí àkókò ti ń rékọjá, ìjọ Kristian tòótọ́ ni a óò làlóye síwájú àti síwájú síi nípa àwọn ète Ọlọrun. Ó ṣèlérí fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Olùtùnú náà, Ẹ̀mí Mímọ́, ẹni tí Baba yóò rán ní orúkọ mi, òun ni yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo.” (Johannu 14:26) Jesu tún sọ pé: “Kíyèsí i, èmi wà pẹ̀lú yín nígbà gbogbo, títí ó fi dé òpin ayé.” (Matteu 28:20) Nípa báyìí, ìlàlóye tí ó níí ṣe pẹ̀lú òtítọ́ nípa Ọlọrun àti àwọn ète rẹ̀ ń pọ̀ síi láàárín àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun. Bẹ́ẹ̀ni, “ipa-ọ̀nà àwọn olóòótọ́ dàbí títàn ìmọ́lẹ̀, tí ó ń tàn síwájú àti síwájú títí di ọ̀sángangan.”​—⁠Owe 4:⁠18.

16. Kí ni ìlàlóye tẹ̀mí wa sọ fún wa nípa ibi tí a wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ète Ọlọrun?

16 Lónìí, ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí yẹn ń mọ́lẹ̀ síi ju ti ìgbàkígbà rí lọ, nítorí pé a wà ní àkókò náà nínú èyí tí ọ̀pọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli ń ní ìmúṣẹ tàbí tí wọ́n ń súnmọ́ ìmúṣẹ wọn. Ìwọ̀nyí fi hàn wá pé àwa ń gbé nínú “ìkẹyìn ọjọ́” ti ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan búburú yìí. Èyí ni sáà àkókò náà tí a pè ní “òpin ayé”; ayé titun Ọlọrun yóò sì tẹ̀lé e. (2 Timoteu 3:​1-5, 13; Matteu 24:​3-⁠13) Gẹ́gẹ́ bí Danieli ti sọtẹ́lẹ̀, láìpẹ́ Ìjọba ọ̀run ti Ọlọrun yóò “fọ́ túútúú, yóò sì pa gbogbo ìjọba wọ̀nyí [tí ó wà nísinsìnyí] run, ṣùgbọ́n òun óò dúró títí láéláé.”​—⁠Danieli 2:⁠44.

17, 18. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ títóbilọ́lá wo ni ń ní ìmúṣẹ nísinsìnyí?

17 Lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí ń ní ìmúṣẹ nísinsìnyí ni ọ̀kan tí a kọsílẹ̀ ní ẹsẹ 14 nínú Matteu orí 24. Jesu sọ níbẹ̀ pé: “A óò sì wàásù ìhìnrere ìjọba yìí ní gbogbo ayé láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” Jákèjádò ilẹ̀-ayé, iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba yẹn ni àráádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń ṣe. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún ènìyàn sì ń darapọ̀ mọ́ wọn lọ́dọọdún. Èyí wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ inú Isaiah 2:​2, 3, tí ó sọ pé “ní ọjọ́ ìkẹyìn” ti ayé búburú yìí, àwọn ènìyàn láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè yóò wá sínú ìjọsìn tòótọ́ ti Jehofa, ‘òun óò sì kọ́ wọn ní ọ̀nà rẹ̀, wọn óò sì máa rìn ní ipa rẹ̀.’

18 Àwọn ẹni titun wọ̀nyí ń rọ́ wá sínú ìjọsìn Jehofa “bí àwọsánmà,” gẹ́gẹ́ bí a ti sọtẹ́lẹ̀ ní Isaiah orí 60, ẹsẹ 8. Ẹsẹ 22 fikún un pé: “Ẹni kékeré kan ni yóò di ẹgbẹ̀rún, àti kékeré kan di alágbára orílẹ̀-èdè: èmi Oluwa yóò ṣe é kánkán ní àkókò rẹ̀.” Ẹ̀rí fihàn pé ìsinsìnyí gan-⁠an ni àkókò náà. Àwọn ẹni titun sì lè ní ìgbọ́kànlé pé nípa kíkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, wọ́n ti ṣalábàápàdé ìjọ Kristian tòótọ́.

19. Èéṣe tí a fi sọ pé àwọn ẹni titun tí wọ́n ń darapọ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń wá sínú ìjọ Kristian tòótọ́?

19 Èéṣe tí a fi lè sọ èyí pẹ̀lú ìdánilójú? Nítorí pé àwọn ẹni titun wọ̀nyí, pẹ̀lú àwọn àráádọ́ta ọ̀kẹ́ tí wọ́n ti wà nínú ètò-àjọ Jehofa tẹ́lẹ̀, ti ya ìgbésí-ayé wọn sí mímọ́ fún Ọlọrun wọ́n sì ń ṣe ìfẹ́-inú rẹ̀. Èyí wémọ́ gbígbé ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú òfin ìfẹ́ Ọlọrun. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí kan nípa èyí, àwọn Kristian wọ̀nyí ti ‘fi idà wọn rọ ọ̀bẹ-plau, wọ́n sì ti fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé wọn kò sì kọ́ ogun jíjà mọ́.’ (Isaiah 2:⁠4) Gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kárí-ayé ti ṣe èyí nítorí pé wọ́n ń fi ìfẹ́ sílò. Èyí túmọ̀sí pé wọn kò lè gbé ohun-ìjà sókè lòdìsí araawọn tàbí ẹnikẹ́ni mìíràn láé. Nínú èyí wọ́n jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́​—⁠láìdàbí àwọn ìsìn ayé. (Johannu 13:34, 35; 1 Johannu 3:​10-12, 15) Wọn kìí lọ́wọ́ nínú ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni tí ń pínniníyà, nítorí pé wọ́n parapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ́ àwọn ará kárí-ayé kan tí a sopọ̀ nípasẹ̀ ìfẹ́, “àmùrè ìrẹ́pọ̀ pípé.”​—⁠Kolosse 3:14; Matteu 23:8; 1 Johannu 4:​20, 21.

Ọ̀pọ̀ Yàn Láti Máṣe Mọ̀

20, 21. Èéṣe tí ọ̀pọ̀ jùlọ nínú aráyé fi wà nínú òkùnkùn tẹ̀mí? (2 Korinti 4:4; 1 Johannu 5:⁠19)

20 Nígbà tí ó jẹ́ pé ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí tí ń bẹ láàárín àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ń mọ́lẹ̀ síi, àwọn yòókù lára àwọn ènìyàn ayé ń jìn sínú òkùnkùn tẹ̀mí tí ó túbọ̀ ń dúdú kiríkirí síi. Wọn kò mọ Jehofa tàbí àwọn ète rẹ̀. Wòlíì Ọlọrun ṣàpèjúwe àkókò yìí nígbà tí ó sọ pé: “Kíyèsí i, òkùnkùn bo ayé mọ́lẹ̀, àti òkùnkùn biribiri bo àwọn ènìyàn.” (Isaiah 60:⁠2) Èyí ń rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé àwọn ènìyàn kò fi ọkàn-ìfẹ́ tòótọ́ hàn nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọrun, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò fi ìfẹ́-ọkàn hàn pé wọ́n fẹ́ láti gbìyànjú láti mú inú rẹ̀ dùn. Jesu wí pé: “Èyí ni ìdájọ́ náà pé, ìmọ́lẹ̀ wá sí ayé, àwọn ènìyàn sì fẹ́ òkùnkùn ju ìmọ́lẹ̀ lọ, nítorí tí iṣẹ́ wọn burú. Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ó bá hùwà búburú níí kórìíra ìmọ́lẹ̀, kìí sìí wá sí ìmọ́lẹ̀, kí a máṣe bá iṣẹ́ rẹ̀ wí.”​—⁠Johannu 3:​19, 20.

21 Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò ní ojúlówó ọkàn-ìfẹ́ nínú ṣíṣàwárí ìfẹ́-inú Ọlọrun. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n lè pa ìgbésí-ayé wọn pọ̀ sórí ṣíṣe ìfẹ́-inú tiwọn. Nípa ṣíṣàìnáání ìfẹ́-inú Ọlọrun, wọ́n fi araawọn sí àyè-ipò tí ó léwu, nítorí tí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ polongo pé: “Ẹni tí ó mú etí rẹ̀ kúrò láti gbọ́ òfin, àní àdúrà rẹ̀ pàápàá yóò di ìríra.” (Owe 28:⁠9) Wọn yóò faragbá àwọn àbájáde ipa-ọ̀nà wọn tí wọ́n yàn. Aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Kí a máṣe tàn yín jẹ; a kò lè gan Ọlọrun: nítorí ohunkóhun tí ènìyàn bá fúnrúgbìn, òun ni yóò sì ká.”​—⁠Galatia 6:⁠7.

22. Kí ni àwọn ogunlọ́gọ̀ ènìyàn tí wọ́n fẹ́ lati mọ Ọlọrun ń ṣe nísinsìnyí?

22 Bí ó ti wù kí ó rí, ogunlọ́gọ̀ ènìyàn ń bẹ tí wọ́n fẹ́ láti mọ ìfẹ́-inú Ọlọrun, tí wọ́n ń fi òtítọ́-inú wá a, tí wọ́n sì fà súnmọ́ ọn. “Ẹ súnmọ́ Ọlọrun, òun ó sì súnmọ́ yín,” ní Jakọbu 4:⁠8 sọ. Nípa irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ Jesu wí pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣe òtítọ́ níí wá sínú ìmọ́lẹ̀, kí iṣẹ́ rẹ̀ kí ó lè fí ara hàn pé, a ṣe wọ́n nípa ti Ọlọrun.” (Johannu 3:21) Ẹ sì wo ọjọ́-ọ̀la àgbàyanu tí Ọlọrun ti pète fún àwọn wọnnì tí wọ́n wá sínú ìmọ́lẹ̀! Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ wa tí ó tẹ̀lé e yóò jíròrò àwọn ìfojúsọ́nà tí ń múnilóríyá náà.

Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?

◻ Kí ni ọ̀pọ̀ ń sọ nípa ète ìgbésí-ayé?

◻ Báwo ni Jehofa ṣe fi araarẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ète?

◻ Ìlàlóye ńlá wo ni ó wáyé ní ọ̀rúndún kìn-⁠ín-⁠ní C.E.?

◻ Báwo ni a ṣe lè dá ìjọ Kristian tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀ lónìí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́