Ǹjẹ́ Èèyàn Tiẹ̀ Lè Mọ Ọlọ́run?
“Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ . . . Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú.”—JÒHÁNÙ 17:3.
ÀPỌ́SÍTÉLÌ PỌ́Ọ̀LÙ sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà pọ̀ o! Àwọn ìdájọ́ rẹ̀ ti jẹ́ àwámáridìí tó, àwọn ọ̀nà rẹ̀ sì ré kọjá àwákàn!” (Róòmù 11:33) Ṣé ó yẹ ká wá tìtorí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù yìí sọ pé kò ṣeé ṣe fáwa èèyàn láti ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run ni, pé kò ṣeé ṣe láti mọ Ọlọ́run àtàwọn ohun tó pinnu láti ṣe?
Èrò àwọn kan tó máa ń ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ni pé ọmọ aráyé ò lè mọ Ọlọ́run. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopedia of Religion sọ ọ̀rọ̀ kan nípa irú èrò yìí, ó ní: “Ọlọ́run ga ju gbogbo ohun téèyàn lè mọ̀ nípa Rẹ̀ lọ. . . . Èèyàn ò lè fún Ọlọ́run lórúkọ, èèyàn ò sì lè ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ gan-an. Ńṣe ni orúkọ èyíkéyìí téèyàn bá fún Ọlọ́run tàbí àlàyé èyíkéyìí téèyàn bá ṣe nípa rẹ̀ máa sọ Ọlọ́run dẹni tó ní ààlà, bẹ́ẹ̀ kẹ̀ Ọlọ́run ò ní ààlà. . . . Ọlọ́run kì í ṣe ẹnì kan téèyàn lè sọ pé òun fẹ́ wádìí rẹ̀ wò, nítorí pé kò ṣeé ṣe kéèyàn mọ Ọlọ́run.”a
Ìwé ìròyìn Newsweek sọ pé, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ò ti ka ẹ̀sìn sí ní “ìgbàgbọ́ tuntun” kan. Ìgbàgbọ́ ọ̀hún ni pé “ohun kan ṣoṣo ló jẹ́ òótọ́, ohun náà sì ni pé kò sí ohun tó ń jẹ́ òtítọ́.”
Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ni wọ́n fẹ́ mọ ìdí téèyàn fi wà láàyè àmọ́ wọn ò mọ̀ ọ́n. Wọ́n ń rí àwọn ìṣòro tó ń kó ìbànújẹ́ bá àwọn èèyàn, irú bí òṣì òun ìṣẹ́, àìsàn, àti ìwà ipá. Wọ́n tún wò ó pé ọ̀rọ̀ ilé ayé yìí tí kò dáni lójú lè mú káyé súni pátápátá. Àwọn èèyàn yìí lè fẹ́ mọ ìdí tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí fi rí bẹ́ẹ̀, àmọ́ nígbà tí wọn ò bá rí àlàyé kankan, wọ́n lè wò ó pé kò sí àlàyé níbikíbi. Ìdí rèé tí ọ̀pọ̀ lára wọn kì í fi í lọ sílé ẹ̀sìn mọ́, tí wọ́n á wá bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí wọ́n ṣe lè máa sin Ọlọ́run fúnra wọn, ìyẹn tí wọ́n bá ṣì gbà pé Ọlọ́run ń bẹ o.
Ohun Tí Bíbélì Sọ Lórí Ọ̀rọ̀ Yìí
Ó yẹ kí àwọn tó gba Bíbélì gbọ́ tí wọ́n sì gbà pé Jésù Kristi ni Agbọ̀rọ̀sọ fún Ọlọ́run fẹ́ láti mọ ohun tí Bíbélì wí nípa bóyá èèyàn lè mọ Ọlọ́run tàbí èèyàn ò lè mọ̀ ọ́n. Ó ṣeé ṣe kó o rántí pé, lákòókò kan, Jésù sọ̀rọ̀ nípa ojú ọ̀nà méjì, ìyẹn ‘ojú ọ̀nà fífẹ̀ àti aláyè gbígbòòrò tí ó lọ sínú ìparun’ àti ‘ojú ọ̀nà híhá tí ó lọ sínú ìyè.’ Jésù sọ ohun téèyàn lè fi dá àwọn tó ń rìn ní ojú ọ̀nà méjèèjì yìí mọ̀, ó ní: “Nípa àwọn èso wọn ni ẹ ó fi dá wọn mọ̀.” Irú àwọn èso wo? Jésù fi yéni pé kì í ṣe nípa ọ̀rọ̀ ẹnu wọn lásán la ó fi mọ̀ wọ́n bí kò ṣe nípa ìwà wọn, ó ní: “Kì í ṣe olúkúlùkù ẹni tí ń wí fún mi pé, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ ìjọba ọ̀run, bí kò ṣe ẹni tí ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run ni yóò wọ̀ ọ́.” Torí náà, yàtọ̀ sí pé ká fẹnu wa sọ pé a gba Ọlọ́run gbọ́, a tún gbọ́dọ̀ máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé èèyàn gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ní ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́ Ọlọ́run yìí.—Mátíù 7:13-23.
Kedere kèdèrè ni Jésù jẹ́ kó hàn pé ó ṣeé ṣe kéèyàn ní ìmọ̀ nípa Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Ọ̀rọ̀ Jésù yìí jẹ́ ká rí i kedere pé ó ṣeé ṣe kéèyàn ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ tí Ọlọ́run ṣí payá, àmọ́ a ní láti sapá gidigidi ká tó lè ní in. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, ẹ̀bùn tí Ọlọ́run máa fún àwọn tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ ni ìyè àìnípẹ̀kun. Ẹ ò rí i pé ohun tó dáa gan-an kéèyàn sapá láti ní ni ìmọ̀ yìí!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Irú èrò yìí làwọn ẹlẹ́sìn Híńdù, àwọn ẹlẹ́sìn Táò, àtàwọn ẹlẹ́sìn Búdà tí wọ́n wà ní ìlà oòrùn ayé ní.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Jésù sọ pé ojú ọ̀nà híhá ló lọ sí ìyè