Aráyé Nílò Ìmọ̀ Ọlọrun
“Ìwọ óò mọ ìbẹ̀rù Oluwa, ìwọ óò sì rí ìmọ̀ Ọlọrun.”—OWE 2:5.
1. Èé ṣe tí a fi lè sọ pé ọkàn-àyà ẹ̀dá ènìyàn jẹ́ àgbà iṣẹ́ tí a ti ọwọ́ Ọlọrun dá?
NǸKAN bíi 5,600,000,000 ọkàn-àyà ẹ̀dá ènìyàn ni ń lù kì-kì-kì lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí lórí ilẹ̀ ayé. Lójoojúmọ́, ọkàn-àyà tìrẹ ń lù kì-kì-kì nígbà 100,000, ó sì ń tú iye tí ó tó 7,600 lítà ẹ̀jẹ̀ jáde kọjá nínú òpó ẹ̀jẹ̀ oní 100,000 kìlómítà inú ara rẹ. Kò sí iṣu ẹran mìíràn tí ń ṣiṣẹ́ kára tó àgbà iṣẹ́ tí a ti ọwọ́ Ọlọrun dá yìí.
2. Báwo ni o ṣe lè ṣàpèjúwe ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ?
2 Ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ tí iye rẹ̀ tó 5,600,000,000 wà lẹ́nu iṣẹ́ lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú. Inú ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ ni ìmọ̀lára wa, ìfẹ́ ọkàn wa àti ète ìsúnniṣe wa ń gbé. Ó jẹ́ ibùjókòó ìrònú wa, òye wa, àti ìfẹ́ inú wa. Ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ lè jẹ́ agbéraga tàbí onírẹ̀lẹ̀, ó lè pòrúrùu tàbí kí ó láyọ̀, ó lè ṣókùnkùn tàbí kí ó mọ́lẹ̀ kedere.—Nehemiah 2:2; Owe 16:5; Matteu 11:29; Ìṣe 14:17; 2 Korinti 4:6; Efesu 1:16-18.
3, 4. Báwo ni a ṣe ń mú ìhìn rere dé inú ọkàn-àyà?
3 Jehofa Ọlọrun lè mọ ọkàn-àyà ẹ̀dá ènìyàn. Owe 17:3 sọ pé: “Kóro ni fún fàdákà, àti ìléru fún wúrà: bẹ́ẹ̀ ni Oluwa ń dán [ọkàn-àyà, NW] wò.” Ṣùgbọ́n, dípò wíwulẹ̀ mọ ọkàn-àyà kọ̀ọ̀kan, kí ó sì kéde ìdájọ́, Jehofa ń lo àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ láti dé inú ọkàn-àyà ẹ̀dá ènìyàn pẹ̀lú ìhìn rere náà. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ aposteli Paulu pé: “‘Olúkúlùkù ẹni tí ń ké pe orúkọ Jehofa ni a óò gbàlà.’ Bí ó ti wù kí ó rí, bawo ni wọn yoo ṣe ké pe ẹni tí wọn kò lo ìgbàgbọ́ ninu rẹ̀? Bawo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yoo ṣe lo ìgbàgbọ́ ninu ẹni tí wọn kò gbọ́ nipa rẹ̀? Bawo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yoo ṣe gbọ́ láìsí ẹni kan lati wàásù? Bawo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yoo ṣe wàásù láìjẹ́ pé a ti rán wọn jáde? Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ẹsẹ̀ awọn wọnnì tí ń polongo ìhìnrere awọn ohun rere ti dára rèǹtè-rente tó!’”—Romu 10:13-15.
4 Ó tẹ́ Jehofa lọ́rùn láti rán àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ jáde lọ sí apá ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé, láti “polongo ìhìnrere awọn ohun rere,” kí wọ́n sì wá àwọn tí wọ́n ní ọkàn-àyà tí ó ṣí sílẹ̀ rí. A ti lé ní 5,000,000 báyìí—ìpíndọ́gba Ẹlẹ́rìí 1 sí nǹkan bíi 1,200 ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé. Mímú ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé kò rọrùn. Ṣùgbọ́n Ọlọrun ń lo Jesu Kristi láti darí iṣẹ́ yìí, ó sì ń fa àwọn aláìlábòsí ọkàn mọ́ra. Nípa báyìí, àsọtẹ́lẹ̀ tí a kọ sílẹ̀ nínú Isaiah 60:22 ń fẹ̀rí òtítọ́ hàn pé: “Ẹni kékeré kan ni yóò di ẹgbẹ̀rún, àti kékeré kan di alágbára orílẹ̀-èdè: èmi Oluwa yóò ṣe é kánkán ní àkókò rẹ̀.”
5. Kí ni ìmọ̀, kí sì ni a lè sọ nípa ọgbọ́n ayé?
5 Àkókò náà nìyí, ohun kan sì ṣe kedere—ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé nílò ìmọ̀. Ní ti gidi, ìmọ̀ jẹ́ dídi ojúlùmọ̀ pẹ̀lú àwọn òkodoro òtítọ́ tí a jèrè nípa ìrírí, àkíyèsí tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́. Aráyé ti kó ìmọ̀ púpọ̀ jọ. A ti tẹ̀ síwájú nínú irú àwọn agbègbè ìrìnnà, àbójútó ìlera, àti ìbánisọ̀rọ̀pọ̀. Ṣùgbọ́n, ìmọ̀ ayé ha ni aráyé nílò ní ti gidi bí? Rárá o! Ogun, ìninilára, àìsàn àti ikú ń bá a nìṣó láti máa mú ìyọnu bá aráyé. Ìmọ̀ ayé ni a ti fi hàn pé kò dúró sójú kan, tí kò sì ṣeé gbára lé.
6. Ní ti ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀, báwo ni ìmọ̀ Ọlọrun ṣe yàtọ̀ sí ọgbọ́n ayé?
6 Láti ṣàpèjúwe: Ní ọ̀rúndún méjì sẹ́yìn, ó jẹ́ àṣà láti máa lo ìfàjẹ̀kúròlára gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìgbàtọ́jú tí a tànmọ́ọ̀. George Washington, ààrẹ àkọ́kọ́ ti United States, ni a fa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ léraléra ní àwọn wákàtí tí ó kẹ́yìn ìwàláàyè rẹ̀. Ní àkókò kan, ó wí pé: “Ẹ jẹ́ kí n rọra kú; n kò lè pẹ́ láyé.” Kò purọ́, nítorí pé ọjọ́ náà gan-an ni ó kú—December 14, 1799. Dípò ìfàjẹ̀kúròlára, lónìí, a gbé ìtẹnumọ́ karí fífa ẹ̀jẹ̀ sínú ara ẹ̀dá ènìyàn. Ọ̀nà ìgbàṣe méjèèjì ni ó kún fún ìṣòro aṣekúpani. Bí ó ti wù kí ó rí, ní gbogbo àkókò yìí, ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti sọ pé: “[Ẹ] máa takété . . . sí ẹ̀jẹ̀.” (Ìṣe 15:29) Ìmọ̀ Ọlọrun máa ń fìgbà gbogbo tọ̀nà, ó ṣeé gbára lé, ó sì bá ìgbà mu.
7. Báwo ni ìmọ̀ pípéye tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu ṣe yàtọ̀ sí ọgbọ́n ayé ní ti ọ̀ràn títọ́ ọmọ?
7 Gbé àpẹẹrẹ ọgbọ́n ayé tí kò ṣeé gbára lé mìíràn yẹ̀ wò. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn afìṣemọ̀rònú-ẹ̀dá ti ṣalágbàwí gbígbọ̀jẹ̀gẹ́ ní títọ́ ọmọ dàgbà, ṣùgbọ́n ọ̀kan lára àwọn alágbàwí rẹ̀ jẹ́wọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé, àṣìṣe ni èyí jẹ́. Nígbà kan, Ẹgbẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Èdè àti Lítíréṣọ̀ German sọ pé, “ó kéré tán, lọ́nà tí kò ṣe tààràtà,” ìgbọ̀jẹ̀gẹ́ ni “ó fa àwọn ìṣòro tí a ní pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ nísinsìnyí.” Ọgbọ́n ayé lè máa lọ síwá sẹ́yìn bí ẹni pé ẹ̀fúùfù ń gbé e, ṣùgbọ́n ìmọ̀ pípéye láti inú Ìwé Mímọ́ fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọn-ingbọn-in. Bibeli fún wa ní ìmọ̀ràn tí ó wà déédéé lórí títọ́ ọmọ dàgbà. Owe 29:17 sọ pé: “Tọ́ ọmọ rẹ, yóò sì fún ọ ní ìsinmi; yóò sì fi inú dídùn sí ọ ní ọkàn.” Irú ìbáwí bẹ́ẹ̀ ni a ní láti fúnni tìfẹ́tìfẹ́, nítorí Paulu kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin, baba, ẹ máṣe máa sún awọn ọmọ yín bínú, ṣugbọn ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà ninu ìbáwí ati ìlànà èrò-orí Jehofa.”—Efesu 6:4.
“Ìmọ̀ Ọlọrun”
8, 9. Báwo ni o ṣe lè ṣàlàyé ohun tí Owe 2:1-6 sọ nípa ìmọ̀ tí aráyé nílò ní ti gidi?
8 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀mọ̀wé ní Paulu, ó sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni láàárín yín bá rò pé oun jẹ́ ọlọ́gbọ́n ninu ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan yii, kí ó di òmùgọ̀, kí ó baà lè di ọlọ́gbọ́n. Nitori ọgbọ́n ayé yii jẹ́ ìwà òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọrun.” (1 Korinti 3:18‚ 19) Ọlọrun nìkan ni ó lè pèsè ìmọ̀ tí aráyé nílò ní ti gidi. Owe 2:1-6 sọ nípa rẹ̀ pé: “Ọmọ mi, bí ìwọ́ bá fẹ́ gba ọ̀rọ̀ mi, kí ìwọ sì pa òfin mi mọ́ pẹ̀lú rẹ. Tí ìwọ dẹtí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n, tí ìwọ sì fi ọkàn sí òye; àní bí ìwọ bá ń ké tọ ìmọ̀ lẹ́yìn, tí ìwọ sì gbé ohùn rẹ sókè fún òye; bí ìwọ bá ṣàfẹ́rí rẹ̀ bíi fàdákà, tí ìwọ sì ń wá a kiri bí ìṣúra tí a pa mọ́; nígbà náà ni ìwọ óò mọ ìbẹ̀rù Oluwa, ìwọ óò sì rí ìmọ̀ Ọlọrun. Nítorí Oluwa ní í fi ọgbọ́n fúnni: láti ẹnu rẹ̀ jáde ni ìmọ̀ àti òye ti í wá.”
9 Àwọn tí ọkàn-àyà rere ń sún ṣiṣẹ́ ń fiyè sí ọgbọ́n nípa fífi ìmọ̀ tí Ọlọrun ń fúnni sílò lọ́nà títọ́. Wọ́n ń mú ọkàn-àyà wọn fà mọ́ ìfòyemọ̀, ní fífi tìṣọ́ratìṣọ́ra gbé àwọn òkodoro òtítọ́ tí wọ́n ń kọ́ wò. Ní tòótọ́, wọ́n ń kígbe jáde fún òye, tàbí agbára ìṣe láti rí bí àwọn apá kókó ẹ̀kọ́ kan ṣe so pọ̀ pẹ̀lú ara wọn. Àwọn ọlọ́kàn-àyà títọ́ ń ṣiṣẹ́ bí ẹni pé wọ́n ń walẹ̀ fún fàdákà, tí wọ́n sì ń wá ohun ìṣúra tí ó fara sin. Ṣùgbọ́n ohun ìṣúra ńláǹlà wo ni ọwọ́ àwọn tí wọ́n ní ọkàn-àyà tí ó ṣí sílẹ̀ ti tẹ̀? “Ìmọ̀ Ọlọrun” ni. Kí ni ìyẹn túmọ̀ sí? Ní ṣókí, ó jẹ́ ìmọ̀ tí a rí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli.
10. Kí ni a gbọ́dọ̀ ṣe láti gbádùn ìlera dídára nípa tẹ̀mí?
10 Ìmọ̀ Ọlọrun yè kooro, ó dúró gbọn-in, ó sì ń fúnni ní ìyè. Ó ń mú ìlera tẹ̀mí sunwọ̀n sí i. Paulu rọ Timoteu pé: “Máa di àpẹẹrẹ àwòṣe awọn ọ̀rọ̀ afúnninílera mú tí iwọ gbọ́ lati ọ̀dọ̀ mi pẹlu ìgbàgbọ́ ati ìfẹ́ tí ó wà ní ìsopọ̀ pẹlu Kristi Jesu.” (2 Timoteu 1:13) Èdè máa ń ní àpẹẹrẹ àwòṣe àwọn ọ̀rọ̀. Bákan náà, “èdè mímọ́gaara” ti òtítọ́ Ìwé Mímọ́ ní “àpẹẹrẹ àwòṣe awọn ọ̀rọ̀ afúnninílera,” tí a gbé karí ẹṣin ọ̀rọ̀ Bibeli ti ìdáláre ipò ọba aláṣẹ Jehofa nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ ní pàtàkì. (Sefaniah 3:9, NW) A ní láti fi àpẹẹrẹ àwòṣe àwọn ọ̀rọ̀ afúnninílera wọ̀nyí sínú àti sọ́kàn wa. Bí a bá ní láti yẹra fún wàhálà ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ, kí a sì ní ìlera nípa tẹ̀mí, a gbọ́dọ̀ fi Bibeli sílò nínú ìgbésí ayé wa, kí a sì lo àǹfààní àwọn ìpèsè tẹ̀mí tí Ọlọrun ń pèsè nípasẹ̀ “olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. (Matteu 24:45-47; Titu 2:2) Ẹ jẹ́ kí a máa rántí nígbà gbogbo pé, a nílò ìmọ̀ Ọlọrun fún ìlera tẹ̀mí tí ó jí pépé.
11. Àwọn ìdí wo ni aráyé fi nílò ìmọ̀ Ọlọrun?
11 Gbé àwọn ìdí mìíràn tí ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé fi nílò ìmọ̀ Ọlọrun yẹ̀ wò. Gbogbo wọn ha mọ bí ilẹ̀ ayé àti ẹ̀dá ènìyàn ṣe wà bí? Ó tì o, wọn kò mọ̀ ọ́n. Gbogbo aráyé ha mọ Ọlọrun tòótọ́ náà àti Ọmọkùnrin rẹ̀ bí? Gbogbo ènìyàn ha mọ̀ nípa àwọn ọ̀ràn àríyànjiyàn náà tí Satani gbé dìde nípa ipò ọba aláṣẹ Ọlọrun àti ìwà títọ́ ẹ̀dá ènìyàn bí? Bẹ́ẹ̀ kọ́ ṣì ni ìdáhùn náà. Àwọn ènìyàn ní gbogbogbòò ha mọ ìdí tí a fi ń darúgbó, tí a sì ń kú bí? Lẹ́ẹ̀kan sí i, a gbọ́dọ̀ sọ pé, bẹ́ẹ̀ kọ́. Gbogbo àwọn olùgbé ayé ha mọ̀ pé Ìjọba Ọlọrun ti ń ṣàkóso nísinsìnyí, àti pé a ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn bí? Wọ́n ha mọ̀ nípa ẹgbẹ́ agbo àwọn ẹ̀mí burúkú bí? Gbogbo ẹ̀dá ènìyàn ha ní ìmọ̀ tí ó ṣeé gbára lé nípa bí a ṣe lè ní ìgbésí ayé ìdílé aláyọ̀ bí? Àwọn mùtúmùwà ha sì mọ̀ pé ìgbésí ayé aláyọ̀ nínú Paradise jẹ́ ète Ẹlẹ́dàá wa fún aráyé onígbọràn bí? Bẹ́ẹ̀ kọ́ ni ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí pẹ̀lú. Nígbà náà, ní kedere, aráyé nílò ìmọ̀ Ọlọrun.
12. Báwo ni a ṣe lè jọ́sìn Ọlọrun “ní ẹ̀mí ati òtítọ́”?
12 Aráyé tún nílò ìmọ̀ Ọlọrun nítorí ohun tí Jesu sọ nínú àdúrà ní alẹ́ ọjọ́ tí ó kẹ́yìn ìgbésí ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn aposteli rẹ̀ ni a ti ní láti ru sókè gan-an nígbà tí wọ́n gbọ́ tí ó sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ iwọ, Ọlọrun tòótọ́ kanṣoṣo naa sínú, ati ti ẹni naa tí iwọ rán jáde, Jesu Kristi.” (Johannu 17:3) Fífi irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ sílò ni ọ̀nà kan ṣoṣo láti jọ́sìn Ọlọrun ní ọ̀nà tí ó tẹ́wọ́ gbà. Jesu sọ pé: “Ọlọrun jẹ́ Ẹ̀mí, awọn wọnnì tí ń jọ́sìn rẹ̀ sì gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn ní ẹ̀mí ati òtítọ́.” (Johannu 4:24) A ń jọ́sìn Ọlọrun “ní ẹ̀mí” nígbà tí ọkàn-àyà tí ó kún fún ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ bá sún wá láti ṣe bẹ́ẹ̀. Báwo ni a ṣe ń sìn ín ‘ní òtítọ́’? Nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti jíjọ́sìn rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú òtítọ́ rẹ̀ tí ó ṣí payá—“ìmọ̀ Ọlọrun.”
13. Ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni a kọ sílẹ̀ nínú Ìṣe 16:25-34, kí sì ni a lè kọ́ láti ibẹ̀?
13 Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn Jehofa lọ́dọọdún. Síbẹ̀, a ha gbọ́dọ̀ darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn olùfìfẹ́hàn fún ìgbà pípẹ́ bí, àbí, ó ha ṣeé ṣe láti ran àwọn aláìlábòsí ọkàn lọ́wọ́ láti túbọ̀ ṣe batisí ní kíákíá bí? Ó dára, ronú nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ti ọ̀ràn onítúbú àti agbo ilé rẹ̀, tí a mẹ́nu kàn nínú Ìṣe 16:25-34. A ti ju Paulu àti Sila sẹ́wọ̀n ní Filippi, ṣùgbọ́n ní ọ̀gànjọ́ òru, ìmìtìtì ilẹ̀ ńláǹlà kan ṣí ilẹ̀kùn ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. Ní ríronú pé gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n ti sá lọ àti pé, a óò fi ìyà tí ó tó ìyà jẹ òun, onítúbú náà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa ara rẹ̀, nígbà tí Paulu sọ fún un pé, gbogbo wọn wà níbẹ̀. Paulu àti Sila “sọ ọ̀rọ̀ Jehofa fún un papọ̀ pẹlu gbogbo awọn wọnnì tí ń bẹ ní ilé rẹ̀.” Onítúbú náà àti ìdílé rẹ̀ jẹ́ Kèfèrí, tí kò mọ ohun kankan nínú Ìwé Mímọ́. Síbẹ̀, ní òru ọjọ́ kan ṣoṣo náà, wọ́n di onígbàgbọ́. Ní àfikún sí i, “gbogbo wọn lẹ́nìkọ̀ọ̀kan, oun ati awọn tirẹ̀ ni a sì batisí.” Ipò wọ̀nyí kò wọ́ pọ̀, ṣùgbọ́n àwọn ẹni tuntun ni a ń kọ́ ní àwọn òtítọ́ ìpìlẹ̀, wọ́n sì ń kọ́ àwọn nǹkan yòókù ní àwọn ìpàdé ìjọ. Ó yẹ kí ohun kan tí ó fara jọ ọ́ ṣeé ṣe lónìí.
Ìkórè Pọ̀!
14. Èé ṣe tí a fi ní láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí ó gbéṣẹ́, tí ó túbọ̀ pọ̀ sí i ní àkókò tí ó túbọ̀ kúrú sí i?
14 Yóò dára bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bá lè darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli gbígbéṣẹ́ tí ó túbọ̀ pọ̀ sí i, ní àkókò tí ó túbọ̀ kúrú sí i. Àìní gidi wà fún èyí. Fún àpẹẹrẹ, ní àwọn ilẹ̀ Ìlà Oòrun Europe, àwọn ènìyàn ní láti dúró dìgbà tí ó bá kàn wọ́n, kí a tó lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú wọn. Bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀ràn rí níbòmíràn. Ní ìlú kan ní Dominican Republic, àwọn Ẹlẹ́rìí márùn-ún ní ọ̀pọ̀ láti bá kẹ́kọ̀ọ́ débi pé, wọn kò lè kájú gbogbo ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Kí ni wọ́n ṣe? Wọ́n fún àwọn olùfìfẹ́hàn ní ìṣírí láti máa wá sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, kí wọ́n sì dúró dìgbà tí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli bá kàn wọ́n. Ipò nǹkan ń rí bẹ́ẹ̀ ní ibi púpọ̀ káàkiri ayé.
15, 16. Kí ni a pèsè láti mú kí ìmọ̀ Ọlọrun túbọ̀ tàn kálẹ̀ ní kíákíá, kí sì ni àwọn òkodoro òtítọ́ díẹ̀ nípa rẹ̀?
15 Àwọn agbègbè ìpínlẹ̀ rẹpẹtẹ—pápá oko ńlá fún kíkórè—ń ṣí sílẹ̀ fún àwọn ènìyàn Ọlọrun. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jehofa, “Ọ̀gá ìkórè,” ń rán àwọn òṣìṣẹ́ púpọ̀ sí i síta, síbẹ̀ púpọ̀ ṣì wà láti ṣe. (Matteu 9:37‚ 38) Nítorí náà, láti lè mú kí ìmọ̀ Ọlọrun túbọ̀ tàn kálẹ̀ kíákíá, ‘olùṣòtítọ́ ẹrú’ ti pèsè ohun kan tí ó fúnni ní ìsọfúnni pàtó lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú, kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli baà lè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan. Ó jẹ́ ìtẹ̀jáde tuntun tí a lè kárí rẹ̀ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé ní kíákíá—bóyá láàárín oṣù mélòó kan. Ó sì rọrùn láti mú un sínú àpò ìfàlọ́wọ́ wa, àpamọ́wọ́ wa, àní àpò ẹ̀wù wa pàápàá! Ìdùnnú ńláǹlà ni ó jẹ́ fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún tí ó pésẹ̀ sí àwọn Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn” ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa láti gba ìwé tuntun olójú ewé 192 yìí, tí a pè ní, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun.
16 Àwọn òǹkọ̀wé láti onírúurú ilẹ̀ ti pèsè àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí a fara balẹ̀ kó pa pọ̀ sínú ìwé Ìmọ̀. Nígbà náà, ó yẹ kí ó fa gbogbo ènìyàn jákèjádò ayé mọ́ra. Ṣùgbọ́n, yóò ha pẹ́ kí a tó mú ìwé tuntun yìí jáde ní èdè tí àwọn ènìyàn ń sọ káàkiri ayé bí? Rárá o, nítorí pé a lè tètè túmọ̀ ìwé olójú ewé 192 ju àwọn ìwé ńlá lọ. Ní October 1995, Ìgbìmọ̀ Ìwé Kíkọ ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti fọwọ́ sí títúmọ̀ ìwé yìí láti èdè Gẹ̀ẹ́sì sí àwọn èdè tí ó lé ní 130.
17. Àwọn kókó wo ni ó yẹ kí ó mú kí ìwé Ìmọ̀ rọrùn láti lò?
17 Àwọn kókó pàtó ní àwọn orí kọ̀ọ̀kan nínú ìwé Ìmọ̀ yẹ kí ó ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti ní ìtẹ̀síwájú tí ó yára kánkán nípa tẹ̀mí. Ìwé náà gbé òtítọ́ Ìwé Mímọ́ kalẹ̀ ní ọ̀nà tí ń gbéni ró. Kò sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ èké. Èdè tí ó ṣe kedere àti ìgbékalẹ̀ tí ó mọ́gbọ́n dání yẹ kí ó mú kí lílo ìwé náà rọrùn láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, kí ó sì ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti lóye ìmọ̀ Ọlọrun. Ní àfikún sí àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ tí a ṣàyọlò, àwọn ẹsẹ Bibeli tí a yàn ń bẹ, tí akẹ́kọ̀ọ́ náà lè wò nígbà tí ó bá ń múra sílẹ̀ fún ìjíròrò náà. A lè kà wọ́n nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ náà bí àkókò bá ti yọ̀ǹda tó, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, kò bọ́gbọ́n mu láti ṣe àfikún àwọn àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí ó lè da àwọn kókó pàtàkì rú. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn tí ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ní láti fòye mọ̀, kí wọ́n sì gbin ohun tí ìwé náà ń sọ ní orí kọ̀ọ̀kan sínú akẹ́kọ̀ọ́ náà. Èyí túmọ̀ sí pé, olùkọ́ náà gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ìwé yìí taápọntaápọn, kí àwọn kókó pàtàkì baà lè ṣe kedere nínú ọkàn rẹ̀.
18. Àwọn àbá wo ni a dá nípa lílo ìwé Ìmọ̀?
18 Báwo ni ìwé náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, ṣe lè mú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn yá kíákíá? Ìwé olójú ewé 192 yìí ni a lè kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ tán ní àkókò tí o kúrú gan-an, àwọn “tí wọ́n sì ní ìtẹ̀sí ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” yẹ kí wọ́n kọ́ ohun tí ó pọ̀ tó nípasẹ̀ kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ láti ṣe ìyàsímímọ́ sí Jehofa, kí wọ́n sì ṣe batisí. (Ìṣe 13:48) Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a lo ìwé Ìmọ̀ lọ́nà rere nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Bí akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan bá ti lọ jìnnà nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé mìíràn, ó lè jẹ́ ohun tí ó bọ́gbọ́n mu láti parí rẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a dábàá pé kí á bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìwé Ìmọ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli náà. Lẹ́yìn píparí ìwé tuntun yìí, a kò dábàá pé kí a ka ìwé kejì pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́ kan náà. Àwọn tí wọ́n tẹ́wọ́ gba òtítọ́ lè mú ìmọ̀ wọn dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́ nípa pípésẹ̀ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa àti nípa kíka Bibeli àti onírúurú àwọn ìtẹ̀jáde Kristian fúnra wọn.—2 Johannu 1.
19. Ṣáájú dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli nínú ìwé Ìmọ̀, èé ṣe tí ó fi ṣèrànwọ́ láti ṣàtúnyẹ̀wò ojú ìwé 175 sí 218 nínú ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa?
19 Ìwé Ìmọ̀ ni a kọ pẹ̀lú ète ríran ẹnì kan lọ́wọ́ láti dáhùn àwọn ìbéèrè tí àwọn alàgbà ń ṣàtúnyẹ̀wò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn akéde tí wọn kò tíì ṣèrìbọmi, tí ń fẹ́ láti ṣe batisí gẹ́gẹ́ bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Nítorí náà, ṣáájú kí o tó yí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rẹ̀ padà sí ìtẹ̀jáde tuntun yìí, a dábàá pé kí o lo wákàtí díẹ̀ ní ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ìbéèrè tí ó wà ní ojú ìwé 175 sí 218 nínú ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa.a Èyí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti tẹnu mọ́ àwọn ìdáhùn sí irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ nígbà tí o bá ń lo ìwé Ìmọ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli.
20. Kí ni o wéwèé láti fi ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun ṣe?
20 Àwọn ènìyàn níbi gbogbo ní láti gbọ́ ìhìn rere náà. Àní, aráyé nílò ìmọ̀ Ọlọrun, Jehofa sì ní àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ láti sọ ọ́ di mímọ̀. Wàyí o, a ní ìwé tuntun kan tí Bàbá wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ pèsè nípasẹ̀ olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú. Ìwọ yóò ha lò ó láti kọ́ni ní òtítọ́, kí o sì mú ọlá wá fún orúkọ mímọ́ Jehofa bí? Dájúdájú, Jehofa yóò bù kún ọ, bí o ti ń sa gbogbo ipá láti mú kí ìmọ̀ tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún ọ̀pọ̀lọpọ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Báwo ni o ṣe lè ṣàpèjúwe ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ?
◻ Kí ni ìmọ̀ Ọlọrun?
◻ Èé ṣe tí aráyé fi nílò ìmọ̀ Ọlọrun?
◻ Ìwé tuntun wo ni ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó, báwo ni o sì ṣe wéwèé láti lò ó?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ìdí púpọ̀ wà tí ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù olùgbé ilẹ̀ ayé fi nílò ìmọ̀ Ọlọrun