Àpótí Ìbéèrè
◼ Nísinsìnyí tí a ti ní ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, báwo ni ó ṣe yẹ kí àkókò tí a óò fi ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé fún ẹnì kan gùn tó?
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 1993 dábàá pé kí a máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé kan lọ pẹ̀lú olùfìfẹ́hàn tuntun kan títí tí yóò fi kẹ́kọ̀ọ́ ìwé méjì parí. Nísinsìnyí tí a ti ni ìwé Ìmọ̀, ó dàbí ohun tí ó bọ́gbọ́n mu láti ṣe àtúnṣe sí ọ̀nà ìgbàkẹ́kọ̀ọ́ yìí, gẹ́gẹ́ bí a ṣe là á lẹ́sẹẹsẹ sí ojú ìwé 13 àti 14 ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà, January 15, 1996.
A pète ìwé Ìmọ̀ láti ran àwọn ‘tí wọ́n ní ìtẹ̀sí ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun’ lọ́wọ́ láti kọ́ nípa ohun tí ó yẹ kí wọ́n mọ̀ kí wọ́n baà lè ṣe ìyàsímímọ́ sí Jehofa, kí wọ́n sì ṣe ìrìbọmi. (Ìṣe 13:48) Nítorí náà, lẹ́yìn tí akẹ́kọ̀ọ́ kan bá ti parí ìtẹ̀jáde yìí, kò pọn dandan kí á tún kẹ́kọ̀ọ́ ìwé mìíràn pẹ̀lú rẹ̀ mọ́. Bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rẹ ṣe ń tẹ́wọ́ gba òtítọ́, ó lè máa fún wọn ní ìṣírí ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀le láti máa mú ìmọ̀ wọn gbòòrò sí i nípa lílọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa àti nípa kíka Bibeli àti onírúurú ìtẹ̀jáde Kristian.
Bí o bá mọ àwọn ìbéèrè tí ó wà ní ojú ìwé 175 sí 218 ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa dunjúdunjú dáradára, èyí lè ṣèrànwọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kò ní láti tọ́ka sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí tàbí kí ó ṣàtúnyẹ̀wò wọn pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rẹ, ó lè jẹ́ ohun tí ó dára láti tẹnu mọ́ àwọn kókó tí ó wà nínú ìwé Ìmọ̀ tí yóò mú kí ó ṣeé ṣe fún akẹ́kọ̀ọ́ náà láti sọ òye àwọn lájorí òtítọ́ Bibeli jáde nígbà tí àwọn alàgbà bá ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìbéèrè pẹ̀lú àwọn tí ó fẹ́ ṣe ìrìbọmi.
Kò sí ìdí láti wá àfikún ìsọfúnni sí àwọn ìsọfúnni tí ó wà nínú ìwé Ìmọ̀, ní mímú àwọn àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí kì í ṣe ara rẹ̀ tàbí àwọn kókó mìíràn wọlé láti fi ti àwọn ẹ̀kọ́ Bibeli lẹ́yìn tàbí láti fi bi àwọn ẹ̀kọ́ èké lulẹ̀. Èyí yóò wulẹ̀ mú kí àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ náà gùn sí i ni. Kàkà bẹ́ẹ̀, a nírètí pé a lè kárí ìwé náà kíákíá, bóyá ní bí oṣù mẹ́fà. Èyí tẹnu mọ́ ìdí tí ó fi ṣe pàtàkì pé kí á kẹ́kọ̀ọ́ àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà dáradára ṣáájú àkókò kí á baà lè gbé e kalẹ̀ lọ́nà tí ó ṣe kedere, tí ó sì lọ tààràtà sórí kókó. Bákan náà, ó yẹ kí a rọ akẹ́kọ̀ọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ṣáájú àkókò, kí ó yẹ àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ tí a tọ́ka sí wò, kí ó sì tiraka láti lóye dáradára ohun tí ìwé náà ń kọ́ni ní orí kọ̀ọ̀kan.
Ilé-Ìṣọ́nà ti tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli gbígbéṣẹ́ tí ó pọ̀ sí i ní àárín àkókò kúkúrú. (Wo Isaiah 60:22.) Lílo ìwé Ìmọ̀ lọ́nà tí ó gbéṣẹ́ lè ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ láti jèrè ìmọ̀ tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun, kí wọ́n sì gbé ìgbésẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀.—Joh. 17:3.