ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/96 ojú ìwé 7
  • Àpótí Ìbéèrè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àpótí Ìbéèrè
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àyẹ̀wò Tó Ń Tẹ̀ Síwájú Nípa Ìjẹ́kánjúkánjú Iṣẹ́ Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Bí A Óò Ṣe Fi Ìwé Ìmọ̀ Sọ Àwọn Ènìyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Wa Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi—Apá Kejì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 10/96 ojú ìwé 7

Àpótí Ìbéèrè

◼ Báwo ni ó ṣe yẹ kí àkókò tí a fi ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ẹnì kan nínú ìwé Ìmọ̀ gùn tó?

Jèhófà ń bù kún ètò àjọ rẹ̀ lónìí. A ń rí ẹ̀rí èyí lọ́dọọdún, bí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ẹni tuntun ti ń mú ìdúró wọn fún òtítọ́. Ìwé Ìmọ̀ ń fẹ̀rì hàn pé òún jẹ̀ irin iṣẹ́ gbígbéṣẹ́ nínú ṣíṣàṣeparí èyí. Ilé-Ìṣọ́nà, ti January 15, 1996, sọ pé, a ṣe ìwé yìí láti ran akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti tètè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, bóyá dóri ṣíṣe batisí láàárín oṣù díẹ̀.

Fún ìdí yìí, Ilé-Ìṣọ́nà kan náà, ní ojú ìwé 17, sọ pé: “Lẹ́yìn tí ẹnì kan bá ti parí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀ nínú ìwé náà, Ìmọ̀, tí ó sì ti ṣe batisí, ó lè má pọn dandan láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìwé kejì.”

Ẹni tí kò ṣe batisí lẹ́yìn tí ó ti parí ìwé Ìmọ̀ ńkọ́? Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, ti June 1996, ní ojú ìwé 6, ìpínrọ̀ 23, rán wa létí àwọn kókó tí a ṣàlàyé nínú Ilé-Ìṣọ́nà, pé kí á máà kẹ́kọ̀ọ́ ìwé kejì pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́ kan náà, lẹ́yìn tí ó ti parí ìwé Ìmọ̀. Èyí ha túmọ̀ sí pé, a kò fẹ́ẹ́ ran akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan lọ́wọ́ kọjá ibí yìí ni bí? Rárá. A fẹ́ kí àwọn ènìyàn ní ìpìlẹ̀ ìmọ̀ òtítọ́. Síbẹ̀, a retí pé láàárín àkókò kúkúrú kan ní ìfiwéra, yóò ṣeé ṣe fún olùkọ́ dídáńgájíá kan láti ran akẹ́kọ̀ọ́ olótìítọ́ inú lọ́wọ́ láti gba ìmọ̀ tí ó pọ̀ tó láti lè ṣe ìpinnu tí ó lọ́gbọ́n nínú láti sin Jèhófà. Ó lè jẹ́ pé, nítorí àyíká ipò wọn, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan lè fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ ju ẹ̀ẹ̀kan lọ lọ́sẹ̀.

A gbà pé, ìtẹ̀síwájú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan yóò falẹ̀ ju ti àwọn mìíràn lọ. Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀, tí ó lè ti gbà ju àkókò tí ó yẹ kí ó gbà lọ, bí ẹnì kan kò bá tí ì pinnu pé òún fẹ́ dara pọ̀ mọ́ ìjọ, akéde náà yóò ṣe dáradára láti jíròrò ọ̀ràn náà pẹ̀lú ọ̀kan lára àwọn alàgbà tí ó wà nínú Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ. Bí ipò tí ń mọ́ràn fúyẹ́ tàbí tí ó ṣàrà ọ̀tọ̀ bá wé mọ́ ọn, ó lè béèrè fún ìrànlọ́wọ́ síwájú sí i. Èyí bára mú pẹ̀lú ìlànà tí ó wà nídìí ohun tí a sọ ní ìpínrọ̀ 11 àti 12, ní ojú ìwé 17, Ilé-Ìṣọ́nà, January 15, 1996.

Ìmọrírì fún jíjèrè ìpìlẹ̀ ìmọ̀ òtítọ́ ti tó láti sún akẹ́kọ̀ọ́ kan láti máa lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni. Èyí lè sún akẹ́kọ̀ọ́ náà láti fi ẹ̀rí tí ó ṣe kedere nípa ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ láti sin Jèhófà hàn. Bí irú ìmọrírì ohun tẹ̀mí bẹ́ẹ̀ kò bá fara hàn, lẹ́yìn tí a ti dárí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ fún àkókò gígùn kan, ó lè bọ́gbọ́n mu láti ṣíwọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́